II Kronika 14:1-15; 15:1-19; 16:1-14

Lesson 295 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa pẹlu nyin, nitoriti ẹnyin ti wa pẹlu rè̩; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rè̩, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyn ba kọ ọ, on o si kọ nyin” (II Kronika 15:2).
Cross References

I Asa Bẹrẹ Daradara

1. O pa ibọriṣa run, II Kronika 14:1-3; 15:8, 16, 17

2. O gba ẹya Juda niyanju lati wa Ọlọrun, II Kronika 14:4

3. O fi fadaka ati wura fun Ọlọrun, II Kronika 15:18; Malaki 3:8-12

4. O gbọran si Woli lẹnu, II Kronika 15:1-8

5. O ba Ọlọrun da majẹmu kan, II Kronika 15:9-15

6. O gbadura, II Kronika 14:11

II Eso Iṣẹ Rere Asa

1. Ilẹ rè̩ ni isinmi, II Kronika 14:5, 6; 15:19; Deuteronomi 28:1-14

2. Wọn kọ ile, wọn si ni ọrọ, II Kronika 14:7, 8

3. Ọlọrun dahun adura Asa, II Kronika 14:9-15

III Ikuna Asa

1. Asa ba awọn alaiwa-bi-Ọlọrun mulẹ, II Kronika 16:1-6; II Kọrinti 6:14, 17, 18; Orin Dafidi 118:8, 9

2. Ọlọrun da a lẹbi fun iru irẹpọ ti o ni yi, II Kronika 16:7-9; Orin Dafidi 33:16; 146:3; Isaiah 31:1

3. Asa binu si Ọrọ Oluwa, II Kronika 16:10; I Peteru 2:20

4. Asa yipada lati wa iranwọ lọdọ awọn oniṣegun, II Kronika 16:11, 12; Jeremiah 17:5-8; Jobu 13:15

5. Asa kú, II Kronika 16:13, 14; Esekiẹli 33:13

IV Igbẹkẹle Wa ninu Ọlọrun fun Iwosan

1. Iwosan n bẹ ninu Etutu ti Jesu ṣe, Isaiah 53:4, 5

2. A ni lati pe awọn alagba, Jakọbu 5:13-15; Iṣe Awọn Apọsteli 19:11, 12

3. A ṣe ileri iwosan fun wa, Marku 16:18

Notes
ALAYÉ

Asa Gbogun Ti Ibọriṣa

Asa bẹrẹ ijọba rè̩ pẹlu igbogun ti ibọriṣa, “ o mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, ati ibi giga wọnni.” S̩ugbọn a ka a pe “ibi giga wọnni ni a ko mu kuro” (I Awọn Ọba 15:14). O daju pe Asa fi iyatọ si awọn ibi giga ti a gbe n tẹ pẹpẹ fun awọn ọlọrun ajeji ati ibi giga wọnni ti a gbe ti n rubọ si Ọlọrun alaaye (Wo I Samuẹli 9:12; 10:5; I Awọn Ọba 3:4). “S̩ugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro, sibẹ ọkan Asa pe pẹlu OLUWA li ọjọ aiye rè̩ gbogbo.” Eyi fi han pe ifẹ Ọlọrun ni pe ki a mu gbogbo ibi giga kuro, ki o si jẹ pe ni Tẹmpili ti n bẹ ni Jerusalẹmu nikan ni a gbe n ṣe irubọ. (Wo Deuteronomi 12:13, 14). Eyi fi han wa pẹlu pe Asa kò yipada si ibọriṣa rara. Ọkàn Asa ti a sọ fun ni pe o pé pẹlu Oluwa ni ọjọ aye rè̩ gbogbo n tọka si ọran ibọriṣa nikan, ko sọ nipa gbogbo iwa aye rẹ bẹẹ ni kò tọka si pipe Onigbagbọ gẹgẹ bi a ti mọ ọn lode oni.

Ibukun ati Idanwo

“Ododo ni igbé orilẹ-ede leke; ṣugbọn ẹṣẹ li ẹgan orilẹ-ede” (Owe 14:34). Ọlọrun ṣeleri ọpọlọpọ ibukun fun awọn ti o ba feti si ohun Rè̩: “Ibukun ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko ... Ibukun ni fun agbọn rẹ ati fun ọpọn-ipo-akara rẹ” (Deuteronomi 28:3, 5). Juda gbadun ibukun wọnyi labẹ ijọba Asa, Ọlọrun si fun wọn ni alaafia fun ọdun mẹwa ni ibẹrẹ ijọba rẹ. “Bẹni nwọn kọ wọn, nwọn si ṣe rere” (II Kronika 14:6).

Nigba ti eniyan ba ri ojurere Ọlọrun, ti ohun gbogbo n lọ deedee, ti o si dabi ẹni pe oluwarẹ n rin lori iyẹ apa afẹfẹ, o le ni ero pe ohun gbogbo yoo maa lọ bẹẹ nigba gbogbo. Igba ko lọ bi òrere. Igbi idanwo a maa de nigba miran – lojiji ati lai si afọwọfa. Aadọta ọkẹ ọmọ-ogun dide si Asa. Nigba ti o dabi ẹni pe Juda wa ninu alaafia ati irọrun, ogun nla yi lati Etiopia dide si wọn. S̩ugbọn Asa ko ti i gbagbe Ọlọrun; o ti gbaradi ni igba itura. Igba pupọ ni awọn eniyan i maa gbagbe Ọlọrun nigba ti ohun gbogbo ba n lọ deedee fun wọn, ṣugbọn ohun ti o ṣe e ṣe ni lati ni ajẹ-sara ti ẹmi to bẹẹ ti a ko fi ni le gba wa lọ ni akoko ti iṣoro ba de. (Wo Juda 20, 21). Lootọ a ni lati yẹ ọkàn wa wo ki a si tun è̩jé̩ wa jẹ nigba idanwo, ṣugbọn bi ọkàn wa ba ti wa ni iduro-ṣinṣin, a o le sọ bayi pe: “OLUWA! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ran alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, OLUWA Ọlọrun wa; nitoriti awa gbẹkẹ le ọ” (II Kronika 14:10).

Bẹli OLUWA kọlu awọn ara Etiopia niwaju Asa” (II Kronika 14:11). Ohun danindanin ni lati di ara wa ni amure nipa ọpọlọpọ adura gbigba, ki a si wà ni iduro-ṣinṣin nigba gbogbo to bẹẹ ti igbagbọ wa yoo fi duro gbọnin ni akoko idagiri. Ohun ti o dara ni pe ki a ni idaniloju pe kò si ohun kọlọfin kan laarin awa ati Ọlọrun nigba ti aisan tabi ipọnju ba de ati pe awa wa lọwọ Rè̩. Oluwa fi iṣẹgun nla fun Asa ninu ogun yi. Awọn eniyan ti o wà lọdọ rè̩ ko ikogun ti o pọ, agutan ati rakunmi lọpọlọpọ. Bẹẹ gẹgẹ ni a o sọ idanwo wa di iṣẹgun bi a ba fi ara wa sabẹ itọju Ọlọrun. “Nigbati ẹnyin ba bọ sinu onirru idanwo, ẹ ka a si ayọ gbogbo” (Jakọbu 1:2). “Ki idanwo igbagbọ nyin, ti o ni iyelori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe ina li a fi ndan a wò, ki a le ri i fun iyin ati ọlá ati ninu ogo” (I Peteru 1:7).

Iforiti titi de Opin

Nigba ti Asa pada bọ si Jerusalẹmu pẹlu ikogun, Woli Asariah pade rè̩ o si jiṣẹ ti Ọlọrun ran si i pe, “OLUWA pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rè̩; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rè̩, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ ọ, on o si kọ nyin” (II Kronika 15:2). Eyi jẹ ikilọ fun gbogbo awọn ti o fẹ fi Ọrun ṣe ile wọn: pe ohun danindanin ni lati “foriti i titi de opin” (Matteu 24:13). Ọrọ Oluwa lati ẹnu Woli Esekiẹli tẹnumọ ọn kikankikan wi pe, “Nigbati emi o wi fun olododo pe yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rè̩, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rè̩ li a ki yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ kú” (Esekiẹli 33:13). Iye ainipẹkun gbà pe ki a duro ṣinṣin titi de opin.

Lati inu iwe itan, Woli yi fi han fun Juda, akoko ti Israẹli wa lai si Ọlọrun otitọ, lai si alufa ti n kọ ni ati lai si ofin. Igba yi buru pupọ -- akoko ti alaafia kò si. A ri i ka wi pe “awọn ọna opópo da, awọn èro si n rin li ọna ikọkọ. Enia kò si ninu awọn ileto mọ” (Awọn Onidajọ 5:6, 7), nitori awọn Ọmọ Israẹli n gbe inu iho ilẹ ati iho apata. Gbogbo eyi de ba wọn nitori ti wọn kọ Oluwa silẹ: “OLUWA pẹlu nyin nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rè̩; ... ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ ọ on o si kọ nyin” (II Kronika 15:2).

Isin Atọkanwa

Asa Ọba ati awọn eniyan Juda gba ọrọ Woli naa gbọ wọn si da majẹmu lati sin Oluwa. Wọn fi ẹẹdẹgbẹrin akọmalú ati ẹẹdẹgbaarin agutan ti Oluwa fi fun wọn ninu ogun ṣe irubọ lori pẹpẹ, a si fi edidi di majẹmu naa pe, “Ẹnikẹni ti ko ba wá OLUWA Ọlọrun Israẹli, pipa li a o pa a” (II Kronika 15:13). Ibura ti o le ni eyi, sugbọn Ọlọrun yẹ ẹ si. Inu Ọlọrun dùn: “Gbogbo Juda si yọ si ibura na: nitoriti nwọn fi tinutinu wọn bura, nwọn si fi gbogbo ifẹ inu wọn wa a; nwọn si ri i” (II Kronika 15:15). Bi iwọ ba le ṣafẹri Rè̩ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, Ọlọrun ṣeleri pe “Ẹ o si ri mi” (Jeremiah 29:13, 14). Ọlọrun n fẹ isin atọkan wa, inu Rè̩ kò dùn si isin ajambaku. Ọlọrun yoo pọ awọn kò-gbóná-kò-tutù jade kuro ni ẹnu Rè̩.

Ikuna

Ni ọdun kẹrindinlogoji ijọba Asa ni ẹsẹ rè̩ bẹrẹ si yẹ. Ro o wo! Isin atọkanwa ọdun marundinlogoji, ire ìje rere fun ọdun marundinlogoji, ọdun marundinlogoji ti o kún fun iṣẹ rere -- lẹhin eyi, ikuna! Eyi fi han bi ifi-ara-ẹni-rubọ ojoojumọ, ikiyesara ati adura ti ṣe paaki to. “Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ?” (Galatia 5:7). Kinla! Asa? O ha ṣe pe o gbagbe lati gbadura ni? Iwọ ti to tan, o si ti tobi loju ara rẹ to bẹẹ ti iwọ fi ro pe iwọ lè da ohunkohun ṣe lai si iranlọwọ Ọlọrun? O ha ṣe pe ọrọ rẹ pọ to bẹẹ ti iwọ fi ro pe owo le ṣe oju-ọna rẹ ni rere dipo ki iwọ gbe oju rẹ soke si Oluwa? Tabi iwọ ti jinna si Ọlọrun to bẹẹ ti ọrọ Woli Rè̩ fi di ẹtì fun ọ? Asa, rẹ ara rẹ silẹ, Oluwa yoo si gbọ ti rẹ. S̩ugbọn Asa kò rẹ ara rè̩ silẹ. O se aya rẹ le, o si fi Woli naa sinu tubu, o si pọn awọn eniyan loju pẹlu.

Iwosan nipa Agbara Ọlọrun

Bayi ni ohun ti a kọ sinu Ọrọ Ọlọrun nipa iṣe Asa pari afi lati fi eyi kun un pe “Ati li ọdun kọkandinlogoji ijọba rè̩, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rè̩ titi arun rè̩ fi pọ gidigidi: sibẹ ninu aisan rè̩ on kò wá OLUWA, bikòṣe awọn oniṣegun” (II Kronika 16:12). Lẹẹkan sii Asa fi han pe oun kò ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun, o si gbẹkẹle ẹlẹran ara. “Egbe ni fun enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rè̩, ẹniti ọkàn rẹ si ṣi kuro lọdọ OLUWA” (Jeremiah 17:5). Awọn miran ro pe Oluwa a maa ṣe iwosan nipasẹ iṣẹ ọwọ awọn oniṣegun, awọn miran si rò pe a le yàn lati gbẹkẹle Ọlọrun fun iwosan ti a ba fẹ -- ki a fara mọ ọn bi a ba ni igbagbọ lati ṣe bẹẹ tabi ki a ṣa a tì bi o ba tọ bẹẹ loju wa. S̩ugbọn ẹkọ ti a kọ nihin yi ni pe Asa ṣe aṣiṣe: lọna kinni, nitori pe oun kò wa Oluwa; lọna keji ẹwẹ, nitori ti o tọ awọn oniṣegun lọ.

Bibeli kọ wa ni ẹkọ ti o yanju kedere nipa iwosan nipa agbara Ọlọrun ninu Majẹmu Laelae ati Majẹmu Titun. “Emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá” (Ẹksodu 15:26). “Fi ibukun fun OLUWA, iwọ ọkàn mi, ma si ṣe gbagbe gbogbo õre rè̩: ẹniti o dari gbogbo è̩ṣẹ rẹ ji; Ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ” (Orin Dafidi 103:2, 3). “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. ...Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pe awọn àgbà ijọ, ki nwọn si gbadura sori rè̩, ki wọn si fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: adura igbagbọ yio si gbà alaisan naa la, Oluwa yio si gbe e dide” (Jakọbu 5:13-15). Ki Ọlọrun ki O ran awọn eniyan Rè̩ lọwọ lati gbẹkẹ wọn le E, ki wọn ma ṣe fi ẹlẹran ara ṣe igbẹkẹle. “Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia ... Ibukun ni fun ẹniti o gbẹkẹle OLUWA” (Jeremiah 17:5, 7). Iwọ ha fẹ dabi Asa ti o wá awọn oniṣegun, tabi bi ti Jobu ti o wi pe “Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e” (Jobu 13:15).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lori ilu wo ni Asa jọba?
  2. Sọ nipa ibẹrẹ ijọba Asa.
  3. Ọdun melo ni Asa fi jọba ki a to gbọ buburu nipa rè̩?
  4. Bawo ni ogun Etiopia ti o dide si Asa ti pọ to?
  5. Sọ ìgbà meji ti Asa kùnà lati gbẹkẹle Ọlọrun.
  6. Kin ni a fi ẹni ti o gbẹkẹle eniyan we? ati ẹni ti o gbẹkẹle Oluwa?
  7. Fi idi rè̩ mulẹ lati inu Bibeli pe o ṣe e ṣe lati fa sẹhin ki a si ṣegbe.
  8. Fi ẹsẹ Bibeli gbe e lẹsẹ pe idanwo le mu ire ba wa gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ si Asa ninu ogun Etiopia ti o dide si i.
  9. Tọka si ohun mẹrin ninu ẹkọ yi ti o fi idi rè̩ mulẹ pe Juda fi tọkàntọkàn wa Ọlọrun.
  10. Fi ipọnju Jobu ati igbẹkẹle rè̩ ninu Ọlọrun we igbesi aye Asa.
1