Lesson 296 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: Kiyesi i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹru rè̩, lara awọn ti nreti ninu ānu rè̩; Lati gba ọkan wọn la lọwọ iku, ati lati pa wọn mọ lāye ni igba iyan” (Orin Dafidi 33:18, 19).Cross References
I Ijọba Buburu Ahabu
1. Iwa buburu Ahabu tayọ ti gbogbo awọn ọba Israẹli ti o ti jẹ ṣiwaju rẹ, I Awọn Ọba 16:29-34
2. Elijah, ẹni ti o le gbadura pupọ, ba Ahabu wi, I Awọn Ọba 17:1; Jakọbu 5:17, 18
II Aabo ati Ipese Ọlọrun fun Elijah
1. Awọn ẹyẹ iwo n bọ Elijah, I Awọn Ọba 17:2-7; Luku 12:24; Orin Dafidi 147:9; Matteu 6:25-33
2. A pese fun Eljah ni ile obinrin opó kan, I Awọn Ọba 17:8-16; Matteu 10:41, 42; Luku 4:25, 26
3. Elijah ji ọmọ obinrin opo naa dide kuro ninu oku, I Awọn Ọba 17:17-24
Notes
ALAYÉIsin Baali
Nigba ti Jeroboamu ọmọ Nebati ya ere ẹgbọrọ malu wura meji ti o si wi pe, “Israẹli, wo awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wa,” ti o si mu Israẹli dẹṣẹ ibọriṣa, o dabi ẹni pe o ṣe afojudi ti ko lẹgbẹ si Ọlọrun Olodumare. Sibẹ loju Ahabu, o dabi ẹni pe ohun kekere ni fun un lati maa rin ninu ẹṣẹ Jeroboamu. O dẹṣẹ-mẹṣẹ nipa mimu isin Baali wa si Israẹli, pẹlu oniruuru iwa ibajẹ ati ipaniyan rè̩. Awọn ọmọ Israẹli bẹrẹ si dẹṣẹ kan naa ti o mu ki Ọlọrun paṣẹ pe ki a pa awọn ara Kenaani run. Apaniyan patapata ni awọn woli Baali i ṣe, nitori pe ibọriṣa Baali mu fifi ọmọ wẹwẹ rubọ lọwọ.
Itara Elijah
Ko ya ni lẹnu pe ọkan Elijah gbọgbẹ nipa iru ipo ti Israẹli wa; nitori ti o mọ egun ti a sọ ninu iwe Ofin wi pe yoo wa sori Israẹli nitori awọn ẹṣẹ yi. O ka pe Oluwa yoo se ọrun, ki yoo si rọ òjò Rè̩ silẹ bi wọn ba kọ lati fetisi ofin Rè̩. O ri i pe akoko to wayi ti a gbọdọ mu ohun kan ṣe nipa iru ipo ti Israẹli wà ni akoko yi; nitori naa “o gbadura gidigidi pe ki ojo maṣe rọ, ojo ko si rọ sori ilẹ fun ọdun mẹta on oṣu mẹfa” (Jakọbu 5:17). Aniyan awọn eniyan Elijah wa lọkan rè̩; o fẹ ki Israẹli yipada si Oluwa bi o ti wu ki o ri. Elijah kò fẹ wo iṣoro, wahala, tabi inira ti yoo gba a, ki isin Baali sa ti parun raurau. Tifẹtifẹ ni o fi fẹ ba awọn ti o ti dẹṣẹ jiya, ki Ọlọrun sa ti da wọn lẹkun iwa-ibi wọn. Aye ode-oni n fẹ awọn eniyan bi Elijah lọkunrin ati lobinrin, ti itara yoo gba ọkan wọn kan lati ri i pe awọn eniyan yipada kuro ninu ọna ẹṣẹ wọn.
Diduro Niwaju Ọlọrun
“Bi OLUWA Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, ki yio si ìri tabi ojo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi” (I Awọn Ọba 17:1). Ohun ti o tobi fun ẹda lati sọ ni eyi, -- wi pe ọrun yoo rọjo tabi kì yoo rọjo – nipa ọrọ oun. Ọrọ yi ki i ṣe ohun ti a sọ ninu iwarapapa, ṣugbọn adura gbigbona agbayọri fun wakati pupọ ni n bẹ lẹhin rè̩. Ki i ṣe lati inu ọkan ifẹkufẹ ni ọrọ wọnyi ti jade wa bi ko ṣe lati inu ọkan mimọ ti o ni idapọ pẹlu Ọlọrun alaaye.
Ọrọ ti Elijah sọ bayi pe, “Bi OLUWA Ọlọrun ti wa, niwaju ẹniti emi duro,” fi han pe o n gbe igbesi-aye rè̩ o si n rin bi ẹni pe niwaju Ọlọrun alaaye ni o wà nigba gbogbo. Awa ti ode-oni ni lati mọ pe Ọlọrun mọ gbogbo ero ọkan wa; gbogbo ọrọ ati iṣe wa ni o ṣipaya niwaju Rè̩. Jẹ ki ọkunrin ati obinrin ati ọmọde ki o mọ pe oun duro niwaju Ọlọrun Olodumare lati iṣẹju ati lati wakati de wakati ni gbogbo ọjọ.
Ni Odo Keriti
Kin ni Elijah yoo ri ni odo Keriti? Ahere tabi iho apata ha wà nibẹ bi? tabi awọsanma ni yoo fi ṣe ibori ti yoo si maa gbe abẹ rè̩? Elijah ko ni ohunkohun lati mọ nipa eyi; o wà nibi ti Ọlọrun paṣẹ fun un pe ki o lọ. “Iwọ o mu ninu odo na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ ìwò lati ma bọ ọ nibẹ.”
Ẹyẹ iwo! Bawo ni ounjẹ naa yoo ti ri? Kin ni ẹyẹ iwo le mu wa ti yoo dara fun eniyan Ọlọrun yi lati jẹ? Bibeli wi pe: “Ẹ kiyesi awọn iwò; nwọn ki ifọnrugbin, bḝni nwọn ki kore, nwọn ko li aká, bẹni nwọn ko li aba” (Luku 12:24). Awọn ẹyẹ wọnyi ni yoo maa mu ounjẹ wa fun Elijah lojoojumọ. Dajudaju igbesi-aye ịgbagbọ ni Ọlọrun n fẹ lọwọ Elijah, Elijah si ni igbagbọ. Ọlọrun n bọ awọn ẹyẹ iwo, awọn ẹyẹ iwo si n bọ Elijah. Tani fẹ mọ bawo tabi ibi ti ounjẹ gbe ti wa niwọn igba ti o ba sa ti jẹ pe Ọlọrun ni Orisun rè̩. “Ẹmi sa ju onjẹ lọ, ara si ju aṣọ lọ” (Luku 12:23). “Oju OLUWA mbẹ lara awọn olododo, eti rè̩ si ṣi si igbe wọn” (Orin Dafidi 34:15). Ọlọrun Elijah wa sibẹ, bakan naa ni awọn ẹyẹ iwo pẹlu. Ohun ti o ṣọwọn lọjọ oni ni iru igbagbọ ti Elijah ni
A dan igbagbọ Elijah wo. Odo naa gbẹ! Ifojusọna pe ki awọn ẹyẹ gbe ounjẹ rè̩ wa ko to, ṣugbọn odo ti o ti n mu omi gbẹ, ani odo Keriti nibi ti Ọlọrun dari rè̩ si. Elijah ko pe Ọlọrun lẹjọ ṣugbọn o joko leti bebe odo ti o gbẹ naa titi “Ọrọ OLUWA fi tọ ọ wa wipe, Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ; kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obirin opó kan nibẹ lati ma bọ ọ.”
Opo Ara Sidoni
Iyan mu ni ilu Sarefati. Agbara kaka ni obinrin opo naa fi n ri ounjẹ jẹ. Lọhun nì ni o n ṣa igi diẹ jọ. Kin ni yoo ti ri ni oju rẹ bi a ba sọ fun ọ lati lọ ṣe atipo ninu ile kan nibi ti obinrin kan ati ọmọ rè̩ gbe wa lai si ounjẹ bi ko ṣe iwọn iba diẹ ti wọn yoo jẹ lẹẹkan ṣoṣo, ti ireti ati ri ounjẹ miran jẹ lẹhin eyi ko si si? Iwọ yoo ha ni igboya lati beere pe, “Tete kọ ṣe akara kekere kan fun mi” tabi igbagbọ rẹ yoo ha to lati le wi pe, “Ikoko iyẹfun na ki yio ṣofo, bẹni kolobo ororo na ki yio gbẹ, titi di ọjọ ti OLUWA yio rọ ojo si ori ilẹ?” Tabi iwọ ha le ni ireti pe obinrin ti ebi n pa yoo fi iwọn iba ounjẹ ti o ku lọwọ rẹ fun alejo nigba ti ọmọ oun tikara rè̩ wa lai ri ounjẹ jẹ? Fun ọpọlọpọ ọjọ ni o ti n ṣọ ounjẹ jẹ ti o si ti n ṣọ ororo naa lo. Nisinsinyi ikunwọ iyẹfun kan ati iwọn ẹkun ṣibi melo kan ni ororo naa ku!
Abajọ ti Jesu fi wi pe, “ṣugbọn mo wi fun nyin nitõtọ, opo pipọ li o wa ni Israẹli nigba ọjọ woli Elijah, nigbati ọrun fi se li ọdun mẹta on oṣu mẹfa, nigbati iyan nla fi mu ka ilẹ gbogbo; ko si si ẹnikan ninu wọn ti a ran Eljah si, bikoṣe si obirin opo kan ni Sarefati, ilu kan ni Sidoni” (Luku 4:25, 26).
Nihin yi a ri obinrin kan ti iru iwa rere rè̩ ṣọwọn; ẹni ti o ṣe tan lati gbọ ti Ọlọrun loju ebi ati iku. Ọlọrun boju wolẹ wo awọn opo ti o wa ni Israẹli yika ṣugbọn ko ri ẹni ti Oun le gbẹkẹle bi alejo ara Sidoni yi. Bi Ọlọrun ti n wo yika Ijọ lọjọ oni, n jẹ O le ri iwa rere ti o jẹ didun inu Rè̩? tabi yoo ni lati pe alejo ti yoo maa bọ woli Rè̩? “Tani yio ri obirin oni iwa-rere? Nitoriti iye rè̩ kọja iyun” (Owe 31:10).
O ṣe e ṣe ki obinrin opo ara Sarefati yi ti gbọ nipa Ọlọrun Israẹli ki Elijah to de ọdọ rè̩. Ọlọrun wi fun Elijah pe, “Emi ti paṣẹ fun obirin opo kan nibẹ lati ma bọ ọ.” Imọ nipa Ọlọrun ti O bọ Israẹli fun ogoji ọdun ni aginju, ti O fi ounjẹ angẹli bọ wọn, ti O si mu omi jade fun wọn lati inu apata, to lati fun olukuluku eniyan ni ikiya lati gbẹkẹle Ọlọrun. Sibẹsibẹ ohun kan ni lati gbagbọ pe Ọlọrun le ṣe iṣẹ iyanu ati pe O ti n ṣe e, ohun miran si ni lati gbẹkẹle E ni igba iṣoro – nigba ti awa ati ọmọ wa wa laarin iku ati iye. Ileri Ọlọrun daju. Iwe Mimọ sọ fun ni pe, “Nitori bayi li OLUWA Ọlọrun Israẹli wi: Ikoko iyẹfun na ki yio ṣofo, bẹni kolobo ororo na ki yio gbẹ,” ohun ti o tun tẹle e ni pe, “Ikoko iyẹfun na ko ṣofo, bẹni kolobo ororo na ko gbẹ.” Atobiju ni Ọlọrun wa!
Iye lati inu Oku
Lẹẹkan si i a fi ina dan igbagbọ Elijah wo, o si jade lọtun bi fadaka ati wura. Ni akoko yi, ọmọ obinrin naa ṣaisan, o si ku. Elijah wọ inu iyẹwu rè̩ lọ, o si gbe ọmọ ti o ku naa sori akete rè̩, o si ke pe Ọlọrun. Li ẹrinmẹta ni o na ara rẹ lori ọmọde yi, “OLUWA si gbọ ohun Elijah; ẹmi ọmọde na si tun pada sinu rè̩, o si sọji.” Iru eniyan wo ni eyi! Iru igbagbọ wo si ni eyi ti o le sọ oku di alaaye!
Questions
AWỌN IBEERE- Tani iyawo Ahabu?
- Orilẹ-ede wo ni o ti wa? Kin ni ẹsin rè̩?
- Eredi rẹ ti Elijah fi gbadura pe ki ojo ma ṣe rọ?
- Bawo ni Elijah yoo ṣe maa ri ounjẹ jẹ ni ẹba odo Keriti ti o gbe wa?
- Kin ni mu ki odo naa gbẹ?
- Orilẹ-ede wo ni ilu Sarefati wa?
- Ki lo faa ti Jesu ṣe mẹnu kan ọran opo ara Sarefati yi?
- Iṣẹ iyanu meji wo ni a ṣe ninu ile opo yi?
- Sọ oriṣiriṣi ọna, gẹgẹ bi o ti fara han ninu ẹkọ yi, ti a ba fi dan igbagbọ Elijah wo.
- Kin ni fun obinrin yi ni idaniloju pe eniyan Ọlọrun ni Elijah i ṣe?