I Awọn Ọba 18:1-46

Lesson 297 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahun; ati bi nwọn ba ti nsọrọ lọwọ, emi o gbọ” (Isaiah 65:24).
Cross References

I Ipadabọ Elijah

1. Elijah pade Obadiah ẹni ti o ran Ahabu lati lọ pade rè̩, I Awọn Ọba 18:1-16

2. Ahabu sun Elijah lẹsun pe o n yọ Israẹli lẹnu, I Awọn Ọba 18:17, 18; 21:20; I Samuẹli 1:14; 17:28

II Idanwo Nipasẹ Ina

1. Elijah sọ fun Ahabu lati ko gbogbo Israẹli ati awọn woli Baali jọ, I Awọn Ọba 18:19, 20

2. Awọn eniyan gba lati ṣe idanwo kan ti yoo fi han bi Oluwa tabi Baali ni Ọlọrun otitọ, I Awọn Ọba 18:21-24; Isaiah 41:21-26; 43:9

3. Ọlọrun ti o ba fi ina dahun ni wọn yoo gba ni Ọlọrun otitọ, I Awọn Ọba 18:24; Lefitiku 9:24; Awọn Onidajọ 6:21; I Kronika 21:26; II Kronika 7:1, 3

4. Awọn woli Baali ke pe ọlọrun wọn ni gbogbo ọjọ ṣugbọn wọn ko ri esi gba, I Awon Ọba 18:25-29; Isaiah 45:20; Jeremiah 10:5; 51:17, 18; Daniẹli 5:23

5. Elijah tun pẹpẹ Oluwa ṣe gẹgẹ bi ọrọ Oluwa ti tọ ọ, I Awọn Ọba 18:30-35; Ẹksodu 24:4; Jọṣua 4:3, 4

6. Ọlọrun fi woli Rè̩ han nipa fifi ina sun pẹpẹ naa ati ohun ti n bẹ lori rè̩, I Awọn Ọba 18:36-39; Numeri 16:28-30; Isaiah 28:21, 22; Sẹkariah 14:4, 5

7. Elijah pa awọn woli Baali, I Awọn Ọba 18:40

III Adura Gbigbona Ti O S̩iṣẹ

1. Elijah gbadura, Ọlọrun si ran ojo, I Awọn Ọba 18:41-46; Jakọbu 5:16, 17

Notes
ALAYÉ

Ọrọ Oluwa

“Yio si ṣe, bi iwọ ko ba fetisi ohun OLUWA Ọlọrun rẹ, lati mā kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rè̩ ati ilana rè̩ ti mo fi lelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bà ọ ... Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jé̩ idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio jé̩ irin. OLUWA yio sọ òjo ilẹ rẹ di bus ati ekuru: lati ọrun ni yio ti ma sọkalẹ si ọ, titi iwọ o fi run” (Deuteronomi 28:15, 23, 24). Nigboṣe, Israẹli mọ pe ikilọ yi lati ọdọ Ọlọrun wa ki i ṣe ọrọ ti a fi ṣe ète lọṣọ lasan. Elijah ara Tiṣbi fara han Ahabu o si wi pe, “Bi OLUWA Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi ojo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi” (I Awọn Ọba 17:1). O si ri bẹẹ. Fun ọdun mẹta ati aabọ a kò ri ẹyọ ẹkan ojo kan pere tabi iri ni Israẹli. Bi o tilẹ jẹ pe Ahabu wa gbogbo orilẹ-ede Israẹli kiri, ko ri Woli Elijah, ojo ko si rọ.

Ipadabọ Elijah

A ko da Ahabu si kuro ninu ọrọ idajọ Ọlọrun ti o wa sori ilẹ naa ati awọn eniyan, nitori pe nigba ti o pade Elijah nikẹhin ohun ti o kọ wi fun un ni pe, “Iwọ li ẹniti nyọ Israẹli li ẹnu!” Ero Ahabu ni pe Elijah ni ẹni ti n ṣe okunfa gbogbo iyọnu ti o de ba oun; o si ṣe tan lati di ẹbi ru Woli Ọlọrun yi kaka ki o gbà pe ẹṣẹ oun ni o da gbogbo wahala naa silẹ. Elijah fun un ni esi ti o tọ: “Emi ko yọ Israẹli li ẹnu; bikoṣe iwọ ati ile baba rẹ, ninu eyiti ẹnyn ti kọ ofin OLUWA silẹ, ti iwọ si ntọ Baalimu lẹhin.”

Ipe si Isin

Gbogbo Israẹli ati awọn woli Baali pejọ lati gbọ ohun ti Elijah, ọkunrin ti o le se ọrun ki ojo ma ṣe rọ fẹ sọ. Ohun ti o fi siwaju wọn rọrun, o si ye gbogbo eniyan: Ẹ tẹ pẹpẹ kan, ki ẹ si ru ẹbọ lori rè̩; Ọlọrun naa ti o ba fi ina dahun ni Ọlọrun otitọ ati Ọlọrun alaaye, Oun ni ki wọn si maa sin. Ipenija nla ni Elijah fi siwaju wọn yi. Aadọtalenirinwo woli Baali ati irinwo woli ere-oriṣa ni o wa nibẹ; ṣugbọn loju Elijah, oun nikan ni aṣoju Oluwa. Igboya ti o ti inu akọ igbagbọ mimọ ninu Ọlọrun Olodumare wa ni o wa ninu Elijah, o si mọ pe Ọlọrun ko ni i fi bi awọn ti pọ to ṣe. Elijah mọ pe ko si iye tabi agbara ninu odi oriṣa Baali ti awọn ọmọ Israẹli n fi were tọ lẹhin ti wọn si n sin. Ọlọrun n gba ọna lile lati fi han fun awọn Ọmọ Israẹli pe ko si ohun ti wọn le ṣe tabi ti wọn ko le ṣe ti o le yi ohun ti Ọlọrun n ṣe pada lọnakọna. Jẹ ki awọn woli Baali ki o fi han lẹẹkan ṣoṣo yi pe ọlọrun tootọ ati alagbara ni oriṣa wọn tabi ki wọn kọ ọ silẹ gẹgẹ bi ẹlẹtan. Eyi ni koko ọrọ Elijah ti o ba awọn eniyan wọnyi sọ, wọn si gba ipenija rè̩.

Odi Oriṣa

Ifẹ kan wa ni ọkan ọmọ-eniyan lati sin ohun kan; nigba pupọ ni eṣu maa n lo ifẹ isin ti o wa lọkan eniyan yi lati de wọn ni igbekun lati tẹ ifẹ ara rè̩ lọrun. Igba pupọ ni o n fi isin atọwọdọwọ ati ibẹrubojo kun ọkan eniyan lati mu ki wọn maa sin orisa, nkan wọnyi si ti ko wọn lẹru, wọn ko si le bọ kuro labẹ isinru eṣu afi nipa agbara Ọlọrun. Israẹli ti kọ isin Ọlọrun otitọ silẹ, isin atọwọdọwọ awọn keferi ati ibọriṣa si ti di wọn ni igbekun. Wọn ṣe orire pupọ nitori pe Ọlọrun n ṣe aniyan wọn sibẹ ni ti pe O ran eniyan bi Elijah si wọn lati pa isin ibọriṣa naa run ati lati yi ọkan wọn pada si Oluwa lẹẹkan si i.

Awọn woli Baali fi gbogbo ọjọ naa kigbe, wọn si fi were ya ara wọn lọbẹ, wọn si n lọ ibosi gee bi ẹhanna ni ireti pe oriṣa wọn yoo ṣe iṣẹ iyanu fun wọn. Eyi jẹ apẹẹrẹ pataki kan lati inu Bibeli ti o fi aṣerege ẹsin han. Elijah fi wọn ṣe ẹlẹya o si gba wọn láyè odidi ọjọ kan lati fi pe ina sọkalẹ lati Ọrun wa. S̩ugbọn ko si idahun. Ọna bẹẹ kọ ni esi fi le tẹ wọn lọwọ.

Mose sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe: “Mọ li oni, ki o si ro li ọkan rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: Kò si ẹlomiran” (Deuteronomi 4:39). Igbagbọ pe Ọlọrun wà ati pe Oun ni oluṣẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wa A ni kọkọrọ ti a fi n ṣi ilẹkun ibukun Ọlọrun (Heberu 11:6). Ọlọrun a maa ṣe akiyesi ọna ti awọn eniyan gba lati tọ Ọ wa, nitori naa o ṣe danindanin pe ki a ṣe isin Ọlọrun lọna ti Ọrọ Ọlọrun la silẹ.

Pẹpẹ Ọlọrun

Nigba ti adura gbigba si Baali su awọn woli Baali, Elijah tẹ pẹpẹ kan si Oluwa, gẹgẹ bi Ọrọ Oluwa, o to okuta mejila jọ, okuta kan fun ẹya Israẹli kọọkan. Nigba ti Elijah fẹ ṣe irubọ ti rè̩, o pe gbogbo eniyan lati sunmọ tosi. Lai si aniani Elijah fẹ ki awọn eniyan wo oun fin daradara ki wọn le mọ pe ko si ọgbọn arekereke kan ninu irubọ rè̩ ati pe gbogbo ohun ti o ṣe ni o ṣe gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun. Lẹhin igba ti o ti gbe egbọrọ malu kan le ori pẹpẹ naa ti o si ti wa yara yi i ka, Elijah paṣẹ fun awọn eniyan naa lati tu omi sori pẹpẹ ati ẹbọ ti o wa lori rè̩ nigba mẹta. Ko gbọdọ si ina ajeji nibẹ. Ohun ti o niyelori ju lọ ni ilẹ naa – omi—ni a fifun Ọlọrun Israẹli pẹlu ẹbọ naa.

Ni akoko ẹbọ aṣalẹ, akoko ti Ọlọrun ti yan, Elijah gbadura si Ọlọrun. O gbadura wẹrẹ, adura naa ko si gun, ṣugbọn o kun fun igbagbọ. O ran Ọlọrun leti pe oun n ṣe nkan wọnyi gẹgẹ bi aṣẹ Rè̩, nitori naa ki O fi ara Rè̩ han, ki O si yi ọkan awọn eniyan pada sọdọ ara Rè̩. Ina Ọlọrun sọkalẹ ni idahun si adura yi, o si jo ẹbọ naa ati pẹpẹ ati omi ti o wa ninu yara! Gbogbo awọn eniyan si doju bolẹ bi ẹni kan wọn si jẹwọ pe, “OLUWA, Oun ni Ọlọrun.”

Awọn eniyan si mu awọn woli Baali a si ti ọwọ Elijah pa wọn. Bẹẹ gẹgẹ ni olukuluku woli eke ati oniwaasu isin eke yoo ri idajọ Ọlọrun wọṅ yoo si gba idalẹbi ayeraye. A o fi wọn han nikẹhin gẹgẹ bi abọriṣa ati ọmọlẹhin Satani, wọn yoo si gba idalẹbi kan naa pẹlu Satani.

Adura Igba Meje

Iṣẹ Elijah ko ti i pari, nitori ti ojo ko i ti rọ. Ọlọrun ti fi han pe Oun wa sibẹ, ṣugbọn Elijah ni lati gba agbayọri adura pe ki Ọlọrun ki o le rọ ojo silẹ. Elijah gun ori oke lọ o si bẹrẹ si i gbadura. Lai si aniani ọkan Elijah kun fun igbagbọ ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun, nitori ti o wi fun Ahabu pe, “Iro ọpọlọpọ ojo mbọ.” Bi o tilẹ jẹ pe Elijah ni lati gbadura leralera, sibẹ agara adura gbigba ko da a. Elijah ṣẹṣẹ ti ibi ti Ọlọrun gbe fi agbara ati ipa nla Rè̩ han wá, dajudaju eyi fi idi igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun mulẹ. O bẹbẹ fun awọn eniyan naa, ọkan rè̩ si gbọgbẹ gidigidi. Igba meje tọtọ ni o ran ọmọ-ọdọ rè̩ lati wo bi ojo ba n bọ; ṣugbọn ọkan Elijah rọ mọ Ọlọrun oun ki yoo si jẹ ki O lọ -- gẹgẹ bi ti Jakọbu ti o taku ti Ọlọrun ninu adura ti ko si jẹ ki angẹli Ọlọrun ni ki o lọ titi ibukun rè̩ fi tẹ ẹ lọwọ. Nigba ti iranṣẹ Elijah de ti o si wi fun un pe oun ri awọsanma kekere kan gẹgẹ bi ọwọ eniyan, ẹri yi to fun Elijah. O mọ pe ọpọlọpọ ojo n bọ wa lai pẹ. Lẹhin ti Elijah ti sọ fun Ahabu pe ki o sọkalẹ lati ori oke ki ojo ki o ma ba da a duro, Elijah sare niwaju kẹkẹ Ahabu pẹlu ayọ ati ọkan ọpẹ si Ọlọrun.

Ẹlẹran ara bi awa ni Elijah i ṣe. Jakọbu sọ fun wa pe “Enia oniru iwa bi awa ni Elijah” (Jakọbu 5:17); eyi fi han pe oun ko ni iwa rere tabi ẹbun kan ti awọn Onigbagbọ ko le ni. “O gbadura gidigidi pe ki ojo ki o maṣe rọ, ojo ko si rọ sori ilẹ fun ọdun mẹta on oṣu mẹfa. O si tun gbadura, ọrun si tun rọjo, ilẹ si so eso rẹ jade.” A le mi ọwọ Ọlọrun lati gbé ogo orukọ Rè̩ ga bi awọn eniyan Rè̩ ba le gbadura kikankikan gẹgẹ bi Elijah ti ṣe. Aile-gbadura kikankikan ni ko jẹ ki ọpọlọpọ Onigbagbọ ni agbara Ọlọrun pupọ. Lati fi ọgbọn ori mọ pe Ọlọrun wa ko le mu ki a ri ohunkohun gba lọdọ Ọlọrun. A ni lati fi igbagbọ kigbe si Ọlọrun lati odo ọkan wa wa. A ko gbọdọ jẹ ki iyemeji wa ninu ọkan wa ni ti pe Ọlọrun wa ati pe yoo gbọ yoo si dahun adura. Nigba naa a o ri i pe ina yoo sọkalẹ lati Ọrun wa sori ẹbọ wa gẹgẹ bi o ti sọkalẹ sori ẹbọ Elijah. Ifẹ Ọlọrun ni lati maa fi ara Rè̩ han fun awọn eniyan Rè̩, Oun yoo si maa ṣe bẹẹ lati igba de igba bi a ba le gbadura pẹlu igbagbọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eeṣe ti ojo ko fi rọ ni Israẹli fun ọdun mẹta ati aabọ?
  2. Kin ni Elijah ṣe nipa ojo ti ko rọ?
  3. Eeṣe ti Elijah fi pe awọn eniyan naa jọ?
  4. Eredi rè̩ ti awọn woli Baali ko fi ri idahun lati ọdọ Baali?
  5. Eredi rè̩ ti Elijah fi okuta majila tẹ pẹpẹ?
  6. Eeṣe ti Ọlọrun da Elijah lohun ti ko si da awọn woli Baali lohun?
  7. Bawo ni Elijah ṣe mọ pe ojo yoo rọ?
  8. Eeṣe ti Elijah fi ni lati gbadura fun ojo nigba meje?
  9. Eredi rè̩ ti Elijah fi ṣe aṣeyọri ninu adura rè̩ si Ọlọrun?
1