I Awọn Ọba 19:1-18

Lesson 298 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Oluwa mọ bi ā ti íyọ awọn ẹni iwabi-Ọlọrun kuro ninu idanwo, ati bi ā ti ipa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ de ọjọ idajọ” (II Peteru 2:9).
Cross References

I Iha ti Jesebeli kọ si Ọlọrun

1. Awọn iṣẹ iyanu atẹhinwa ko yi Jesebeli pada, eyi fi han pe iṣẹ iyanu nikan ko le yi alaiwa-bi-Ọlọrun pada si Ọlọrun, I Awọn Ọba 19:1-3; 18:21-46; Orin Dafidi 78:12-61; Fi Matteu 14:3-11 we Matteu 3:1-17; ati 11:7-14; I Samuẹli 24:1-22; 26:1-25; 27:1

2. Jesebeli ọta Ọlọrun ati ti iwabi-Ọlọrun gbiyanju ni oniruru ọna lati mu ipinnu ọkan rẹ ṣẹ, I Awọn Ọba 19:1, 2; 18:13; 21:7-16, 25

3. Jesebeli ku ni aipẹ ọjọ nitori ẹṣẹ rè̩, II Awọn Ọba 9:30-37

II Elijah ati Ihà ti o kọ si Ọlọrun

1. Idanwo nla ati aarẹ ara a maa wa nigba miran fun awọn olododo lẹhin iṣẹgun nla nla nipa ti ẹmi, I Awọn Ọba 18:1, 17-46; Numeri 11:1-15; Jọṣua 7:6-9; Jobu 3:1-26; 10:1; Orin Dafidi 31:1-24; Mika 7:1-7

2. Ọlọrun paṣẹ fun Elijah lati fi ara pamọ nigba inunibini ti akọkọ, I Awọn Ọba 17:1-16

3. Sisalọ Elijah lakoko yi fi han pe o le jẹ pe o gba a si ifẹ Ọlọrun nitori ohun ti o ti ṣẹlẹ lakọkọ, I Awọn Ọba 19:4

III Suuru Ọlọrun fun Woli Rè̩

1. Ọlọrun ko binu, bẹẹ ni ko ṣe alai ni suuru pẹlu Elijah, ṣugbọn o ki i laya O si ran ounjẹ si i, I Awọn Ọba 19:5-8; Orin Dafidi 103:13, 14, 17, 18; Matteu 4:11; Luku 22:43; Heberu 4:14-16; Isaiah 40:31; 41:10

2. Elijah n ba irin-ajo rè̩ lọ siwaju si Oke Sinai, I Awọn Ọba 19:8

3. Ni Sinai, Ọlọrun fi han gbangba pe Oun n bẹ, ati pe Oun ki i ṣe ẹda tabi ohun ti a da sinu aye, I Awọn Ọba 19:9-14; Ẹksodu 20:1; 33:11, 18-23; 34:1-8

4. A fi iṣẹ kan ran Elijah, ti o fi han pe Woli Ọlọrun ni i ṣe sibẹ, I Awọn Ọba 19:15-17

5. Ni gbogbo igba ni Ọlọrun i maa ni awọn eniyan diẹ ti o jẹ olootọ si I, I Awọn Ọba 19:18; Romu 11:2-5; Luku 12:32; Isaiah 1:9; 40:11; Ifihan 3:4-12

Notes
ALAYÉ

Ogun nla ti ṣẹ nipa ti ẹmi. A ti pa awọn Woli Baali a si ti fi han fun orilẹ-ede Israẹli pe Ọlọrun Abrahamu baba wọn nikan ni Ọlọrun Oun si ni Ọlọrun otitọ. Eyi ṣẹlẹ nipa pipade ti Elijah pade Obadiah, ati pipade ti Elijah pade Ahabu ẹni ti o sun Elijah ni ẹsun pe oun ni o ṣe okunfa iyan, ọda ati iyọnu ti o de ba Israẹli. Elijah tako ọba yi, o si jẹ ki o mọ daju pe ọba yi ni o ṣe okunfa iyọnu naa nitori pe o ti yipada kuro ni sisin Ọlọrun lati maa sin Baali.

Wọn ṣe adehun ohun ti wọn yoo ṣe lati mọ ẹni ti i ṣe Ọlọrun otitọ. A fi aye silẹ fun awọn Woli Baali lori ilẹ wọn ati ninu ohun kan ti yoo rọrun fun Baali, ọlọrun-oorun lati ṣe daradara – bi oun ba i ṣe ọlọrun otitọ ti o ni iye ati agbara. S̩ugbọn omulẹmofo ni isin Baali yọri si, nitori naa gbogbo orilẹ-ede Israẹli yi oju wọn pada si Elijah, ẹni ti o gbadura si Ọlọrun Israẹli ti o si ri idahun adura rè̩ gba lẹsẹkẹsẹ. Bi awọn ọmọ Israẹli ti fi ironupiwada han ti wọn si gba Ọlọrun ni Ọlọrun otitọ, Elijah gbadura pe ki Ọlọrun ki O rọ ojo, Ọlọrun si dahun adura rẹ ni kikun, lẹhin igba ti Elijah ti sure sọkalẹ lati ori oke wa si Jesreeli ti a sọ fun ni pe o to iwọn mile mẹẹdogun.

Iṣẹ Iyanu ati Ilo Wọn

Nigba ti Jesu n ṣe iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ ni aye, igba pupọ ni a beere ami ati iṣẹ iyanu lọwọ Rè̩ lati fi han pe O ni aṣẹ ati pe Ọlọrun ni Oun i ṣe. Nigba ti O ba ri i pe ami tabi iṣẹ iyanu yoo ṣe anfaani lati mu ki awọn eniyan mọ nipa ododo tabi aṣẹ ti i ṣe ti Rè̩, Oun ko ni lọra lati ṣe iṣẹ iyanu tabi lati fun wọn ni ami bẹẹ. S̩ugbọn gẹgẹ bi a ti sọ nigba pupọ ninu ẹkọ wa, Ọlọrun ki i ṣe iṣẹ iyanu bẹẹ ni ki i fun ni ni ami lati tẹ ifẹkufẹ eniyan lọrun, tabi ki o da wọn lara ya lasan, tabi ki o maa dabira ohun ti o tayọ oye ati agbara wọn fun wọn. Nigbakuugba ti a ba fun ni ni ami tabi ti iṣẹ iyanu ba ṣe, a ṣe e ki Ọlọrun le di ayinlogo, fun ọlá orukọ Ọlọrun ati Ọmọ Rè̩, Jesu Kristi, ki a le mu awọn eniyan wa si ironupiwada, fun itunu ati imulọkanle. Bi a ti n kẹkọ nipa igbesi aye ati iṣẹ iranṣẹ Jesu, a ri i pe eredi rè̩ ni yi ti o fi ṣe awọn iṣẹ iyanu ti o ṣe.

Ọran Jesebeli ati awọn miran ninu Bibeli fi han wa pe iṣẹ iyanu nikan ko to lati mu wọn wa si imọ Ọlọrun ati iwa-bi-Ọlọrun. Lai jẹ pe alaiwa-bi-Ọlọrun ba n ṣe afẹri ododo ninu ọkan rè̩, ko si ọpọ iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami ti o le yi wọn lọkan pada si Ọlọrun otitọ. Ọkan ninu awọn ohun ti o jẹ dandan ti ẹni ti o n wa ibukun Ọlọrun ni lati ni ni igbagbọ pe Ọlọrun wa, ati pe Oun ni Ọlọrun otitọ ati Oluṣẹsan fun awọn ti o ba fara balẹ wa A. Ọlọrun le lo iṣẹ iyanu lati ṣi ope ti iyemeji n ṣe tabi ẹni ti ko fi mimọ ṣe aimọ nipa agbara tabi wiwà Ọlọrun niye.

Jesu tọka awọn ti o beere ami lọwọ rè̩ si awọn ami ti a fi han ninu Ọrọ Ọlọrun. O sọ wi pe bi wọn ko ba gba awọn ami wọnni, wọn ki yoo gba ami ti Oun yoo fi han fun wọn. Wọn mọọmọ yọọda ara wọn fun ibi. Jesu fi eyi kun un pe a o ṣe idajọ wọn, a o si da wọn lẹbi nipa ami ti a ti fi fun wọn.

Jesebeli ri iṣẹ iyanu Ọlọrun ni idahun si adura iranṣẹ Rè̩. A ti se ojo mọ, a si ti rọ ojo silẹ. Ina bọ sori pẹpẹ Ọlọrun lai fọta pe, nigba ti gbogbo awọn woli Baali, ninu aṣerege wọn kuna lati fi han lọna diẹ kinun pe ọlọrun ti o n gbọran ni Baali i ṣe, ki a ma tilẹ sọ ni ti pe ọlọrun ti o le gbọ adura wọn ni. Eré mile mẹẹdogun ti woli yi sa jẹ iṣẹ iyanu atata ti o yẹ lati fi han fun Jesebeli pe Ọlọrun wà pẹlu woli Rè̩, bi o ba fẹ gbagbọ. S̩ugbọn o ni ifẹ si ẹṣẹ rè̩, o si kọ lati ri aṣiṣe rè̩. Nitori ti o jingiri sinu iṣọtẹ rè̩ ati ainaani aanu Ọlọrun, ti o si yan ọna ẹṣẹ rè̩, o di ẹni iparun lai si atunṣe.

Awọn eniyan lode oni kọ lati fi ọkan wọn si ipa ọgbọn nipa agbara, ifẹ ati aanu Ọlọrun ti o fara han ti o si yi wọn ka, nitori ti wọn fẹ ẹṣẹ ju iwa mimọ, wọn fẹ iwa ibajẹ ju ododo lọ, wọn fẹ isinru labẹ Eṣu dipo isọdọmọ Ọlọrun, ainireti dipo ireti “aidibajẹ ati ailabawọn ati eyiti ki iṣá” (I Peteru 1:3, 4). Ami pupọ ni a fi fun ni fun ire gbogbo eniyan, ṣugbọn iwọn iba eniyan ni iye wọn ṣi lati mọ ire Ọlọrun Olodumare.

Iṣẹ iyanu ni iṣẹ atunbi ti o ṣẹlẹ ninu olukuluku ẹni ti o di ọmọ Ọlọrun. Bakan naa ni ọjọ kọọkan ni igbesi-aye rè̩ bi Onigbagbọ jẹ iṣẹ iyanu. Idasilẹ ẹni kan kuro ninu ẹṣẹ ni aye yi jẹ ami ti o to lati jẹ idalẹbi fun olukuluku ọkan ti o ri igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun ti ẹni naa n gbe, ti wọn kọ ipe Ihinrere ti a ran si wọn nipasẹ igbesi-aye awọn wọnni ti a yi pada. Iwosan nipa agbara Ọlọrun to lati fi han pe Ọlọrun wà ati pe Etutu ti Jesu fi Ẹjẹ Rè̩ ṣe to fun gbogbo ẹda. Ọlọrun ti ran ọpọlọpọ ami, o si ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu lati fi han pe Oun wa ati lati mu ki awọn eniyan mọ aanu ati agbara Ọlọrun.

Aarẹ Ẹmi ati ti Ara ti Awọn Ẹni Iwa-bi-Ọlọrun maa n ni

Gbogbo ọjọ ni o dara fun awọn Onigbagbọ. Ọjọ arokan ati abamọ fun ẹṣẹ ati iwa wọbia atijọ ti kọja lọ. Onigbagbọ a maa gbe igbesi-aye rè̩ fun ogo Ọlọrun a si maa lakaka lati wu Ọlọrun ninu ohun gbogbo ti o ba n ṣe. Gbogbo ipa ati agbara rè̩ ni o ti jọwọ rè̩ lọwọ lọ fun iṣẹ ododo. Ko si tabitabi pe tọkan-tara ni awọn iranṣẹ Ọlọrun n lo lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun, ati pe nigba ti iranṣẹ Ọlọrun ba n lo ipa ati agbara rè̩ nipa ti ara ati nipa ti ẹmi ninu iṣẹ isin Ọlọrun lọna bayi, dajudaju irẹwẹsi ati aarẹ le de ba a.

A ko le gboju fo ọwọ ikẹ ti Ọlọrun fi n ba Elijah lo da. Awọn ohun ribiribi ti o ṣẹlẹ ni wakati diẹ sẹhin ati ọtẹ ti Jesebeli ṣe si Ọlọrun ni gbangba ode ko le ṣai mu irẹwẹsi ba Elijah tabi ẹnikẹni miran ti i ṣe eniyan Ọlọrun. Bi a ba fi oju ẹmi wo o, isọji ti ko lẹsẹ nilẹ ni o wa ni Israẹli ni akoko naa. Elijah mọ pe bi ko ṣe pe awọn olori ni Israẹli ba yipada si Ọlọrun, gbogbo awọn eniyan orilẹ-ede naa ki yoo yipada. A ki yoo le bẹrẹ si ṣe isin ni Tẹmpili lai jẹ pe ọba yọọda pe ki a ṣe bẹẹ. Elijah mọ pe Israẹli yoo tun pada si ibọriṣa bi wọn ko ba fi tọkantọkan tẹra mọ isin Ọlọrun otitọ ni ẹmi ati ni ododo. Nigba ti o fi oju ara wo gbogbo laalaa rè̩, o dabi ẹni pe o ti ja si asan.

Bi igbi idanwo tilẹ n ja yi wa ka, ti o si dabi ẹni pe iṣẹ wa ko mu eso pupọ wa, ṣugbọn bi a ba ni idaniloju pe a wà ninu ifẹ Ọlọrun, a ko gbọdọ sọ ireti nu tabi ki a fasẹhin kuro ninu iṣẹ ti Ọlọrun fi le wa lọwọ. Ọlọrun yoo ran wa lọwọ titi de opin ti a ba le gbẹkẹ wa le E. Oju Rè̩ ki yoo kuro lara wa titi yoo fi pe wa lọ si Ọrun. A ni iṣẹ lati ṣe fun Un niwọn igba ti ẹmi wa ba wa laaye. Iṣẹ naa le yipada bi ọdun ti n yi lu ọdun gẹgẹ bi ipa ati agbara wa ti n yipada, ṣugbọn iṣẹ Ọlọrun ni yoo jẹ nigba gbogbo, anfaani ni yoo si jẹ fun wa lati tẹra mọ iṣẹ naa titi oun yoo fi pe wa lati lọ gba ère ayeraye.

Elijah le maa ro pe sisa ti oun sa kuro niwaju Jesebeli ni akoko yi jẹ ifẹ Ọlọrun, nitori ni akoko kan ṣaaju eyi, a sọ fun un pe ki o fi ara pamọ kuro ninu ibinu onikupani ni. S̩ugbọn ẹlẹgbẹrun ọna ni Ọlọrun. Nitori pe Ọlọrun paṣẹ fun wa lati ṣe ohun kan nigba kan ko fi han pe Oun yoo tun fẹ ki a ṣe bẹẹ nigba miran. Oun yoo jẹ ki ifẹ Rè̩ di mimọ fun wa, ṣugbọn ohun ti ifẹ Rè̩ yoo jẹ ni ọla le ṣai di mimọ fun wa loni.

Angẹli Oluwa bọ Elijah, o si salọ sori oke Sinai, nibẹ ni Oluwa gbe fara han an. Nigba aarẹ ati irẹwẹsi, o ṣanfaani lati lọ sọdọ Ọlọrun nitori pe nibẹ ni a gbe le fun wa ni agbara ki a si di wa ni amure lati le dojukọ ogun ati awọn iṣoro ti n bẹ niwaju wa. A ko le ri agbara gba nipa ilana ọmọ-eniyan. Ọdọ Ọlọrun nikan ṣoṣo ni Orisun itẹlọrun gbe wa. Lori Oke Sinai, tabi Oke Horebu, Ọlọrun fi ijinlẹ otitọ han Elijah, lẹsẹ kan naa O fun un ni iṣẹ lati ṣe fun anfaani Ijọ ti Majẹmu Laelae.

Iriri Elijah yi ati ti Mose lori oke kan naa jọ ara wọn pupọ. Awọn eniyan Ọlọrun mejeeji wọnyi ri ohun iyanu ti o si lagbara, ti o ṣẹlẹ nipa ti ẹda, ṣugbọn oju wọn tayọ nkan wọnyi. Oju wọn lọ taara si ọdọ Ọlọrun Ọrun ti o ga ju gbogbo agbara irọkẹkẹ, ẹmi tabi ilana kan. Wọn ri i pe Ọlọrun tayọ aará, manamana, afẹfẹ, isẹlẹ tabi ina agbagbayiyi. Awọn eniyan Ọlọrun wọnyi, ati gbogbo awọn eniyan Ọlọrun, ri Ọlọrun gẹgẹ bi O ti ri -- Ọlọrun Baba, ọkan ninu Mẹtalọkan Ayeraye.

Elijah ati Mose pade Ọlọrun lori Oke Sinai. Awọn mejeeji wà nibẹ, ni ayika yi, nitori ti wọn jẹ isansa kuro niwaju awọn onikupani ti o pinnu lati gbà ẹmi wọn. Mose duro gẹgẹ bi aṣoju Ofin; Elijah jẹ aṣoju awọn woli; awọn mejeeji ni o si fara han nigba Ipalarada Kristi. Awọn mejeeji ni o gbọ ohun Ọlọrun. Woli ni awọn mejeeji i ṣe. Awọn mejeeji ni o n ja fun orukọ Ọlọrun laarin awọn abọriṣa.

Awọn Olootọ Diẹ ti o S̩ẹku

Ẹri wi pe bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ba Elijah wi ṣugbọn ko binu si i fara han ninu eyi pe Ọlọrun tun fi iṣẹ kan le e lọwọ lati ṣe ni akoko yi. Ọlọrun paṣẹ fun Elijah lati yan Hasaeli ni ọba lori Siria. Hasaeli ki i ṣe ọmọ Israẹli, bẹẹ ni orilẹ-ede ti yoo jọba le lori ki i ṣe ti Israẹli. A ri i nipa eyi pe “awọn alaṣẹ ti o si wà lati ọdọ Ọlọrun li a ti lana rẹ wá” (Romu 13:1) ati pe Ọlọrun n ṣe abojuto awọn nkan ti n ṣẹlẹ ninu aye yi. Sibẹsibẹ labẹ eto ijọba ilẹ wa awọn eniyan ni o n yan awọn aṣoju; ọmọ Ọlọrun ni ẹtọ lati dibo fun ẹni ti o ba tọ loju rè̩ tabi igbekalẹ ti o dara lai fi ti ẹgbẹ oṣelu kankan pe rara.

Ninu Iwe-Mimọ, a ka awọn ijoye si iranṣẹ Ọlọrun, i baa ṣe keferi tabi ẹni-iwa-bi-Ọlọrun. Isaiah pe Kirusi ni iranṣẹ Ọlọrun ni nkan bi aadọjọ ọdun ṣaaju ki a to bi ọba naa. A ka Nebukadnessari paapaa si iranṣẹ Ọlọrun. Awọn eniyan wọnji jẹ iranṣẹ lọna bayi pe Ọlọrun lo wọn fun imuṣẹ eto Rè̩, nigba pupọ lati jẹ orilẹ-ede Israẹli niya. Ẹkọ nipa igbesi-aye Hasaeli fi han pe Ọlọrun lo o fun idi pataki yi.

A paṣẹ pe ki a yan Jehu ni ọba lori Israẹli lati jẹ ọkan ninu awọn ti yoo gun ori oye lẹhin Ahabu. Ọlọrun fẹ lo oun paapaa lati mu ifẹ Rè̩ ṣẹ lori Israẹli. S̩ugbọn ifororoyan kan ti o tayọ awọn wọnyi ni ti Eliṣa ti yoo rọpo Elijah. Eliṣa ni yoo jẹ alakoso Israẹli nipa ti ẹmi, o si ṣe eyi tọkantọkan fun ọdun pupọ.

Akọsilẹ iṣẹ-iranṣẹ Elijah titi di akoko yi jẹ nkan bi ọdun mẹta ati aabọ, o fẹrẹ jẹ iye ọdun kan naa pẹlu eyi ti Oluwa wa fi ṣe iṣẹ iranṣẹ ti Rè̩. S̩ugbọn laarin akoko yi, o ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu nipa iranlọwọ Ọlọrun, eyi ti o jẹ apẹẹrẹ fun awọn eniyan Ọlọrun lati igba nì. Loju Elijah o dabi ẹni pe oun nikan ni o ku silẹ ni akoko yi, ati pe iṣẹ rẹ fun ijọba Ọlọrun ko mu eso wa to bẹẹ, ṣugbọn Ọlọrun jẹ ki o di mimọ fun un pe awọn olootọ eniyan ku sibẹ ti wọn ko fi eekun wọn wolẹ fun Baali.

O dabi eni pe ọọdẹgbaarin pọ ni iye ṣugbọn bi a ba wo iye awọn eniyan Israẹli -- orilẹ-ede ti o ti ba Ọlọrun da majẹmu lati jẹ eniyan ọtọ fun Un – a ri i pe ko to ẹni kan ninu ọgọrun awọn eniyan Israẹli ti o wa ninu ẹgbẹ olootọ yi. Jesu wi pe awọn ti n tẹle Oun jẹ “agbo kekere.” Oun ko fun wa ni idaniloju pe isọji yoo bẹ silẹ ti yoo kari gbogbo agbaye ni opin ọjọ nipa eyi ti a o gba awọn ti o pọju ninu eniyan aye la. S̩ugbọn O sọ fun wa pe diẹ ni awọn ti yoo ṣetan lati pade Oun.

“Nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ li aiye?” (Luku 18:8). Olukuluku wa ni lati beere ibeere yi bi a ti n boju wo ilẹ aye ti o kun fun awọn alaigbagbọ. Eyi ni lati fi itara ilọpo meji sinu ọkan wa lati ṣe aapọn gidigidi pe ki Ihinrere le tan kaakiri gbogbo agbaye. S̩ugbọn a ni lati fi ọrọ naa ro ara wa wo. A ni lati beere ibeere naa lọwọ ara wa paapaa.

Awọn ọmọ ẹhin ni Jesu n ba sọrọ nigba ti o sọ nipa ipadabọ Rè̩ lẹẹkeji ni airo tẹlẹ, ati ipinya ti yoo wa ni akoko naa. Awọn ti o gba Orukọ Rè̩ gbọ ti wọn si n ru ẹgan Rè̩, ti wọn si fi ohun gbogbo silẹ ni Peteru kilọ fun pe, “Biobaṣepe agbara kaka li a fi gba olododo là, nibo ni alaiwà-bi-Ọlọrun on ẹlẹṣẹ yio gbe yọju si?” (I Peteru 4:18). Bi o ba ṣe pe awọn ti o ti fi ohun gbogbo silẹ, ti o si ti fi igboya duro fun Orukọ iyebiye ti o tayọ gbogbo orukọ, awọn ti o gba lati fi ẹmi wọn lelẹ nitori ẹkọ Rè̩, ti wọṅ si ti gbe agbelebu Rè̩ lati maa tọ Ọ lẹhin, ti wọn si ru Ẹgan Rè̩ -- bi o ba jẹ pe lọwọ wọn ni a gbe beere bi igbagbọ yoo wa, kin ni a o ha sọ nipa awọn ti kò ṣe to ti awọn eniyan wọnyi?

Awọn olootọ diẹ yoo wa, ṣugbọn iba diẹ ni yoo jẹ. Aṣẹkù ni ohun ti o kù silẹ ninu odidi. Aṣẹku jẹ ohun ti o kere pupọ si odidi. Aṣẹku ko niyelori pupọ ni ọja. Owo pọọku ni a n ta wọn. Wo iru ojulowo apẹẹrẹ ti Ẹmi Mimọ lo lati ṣe apejuwe Ijọ ti a o palarada gẹgẹ bi Iyawo Kristi. Wọn jẹ aṣẹkù olootọ ti aye ko ka si ṣugbọn ti Ọlọrun fẹran!

S̩ugbọn odidi n kọ? Bi o ba ṣe pe lati jẹ apa kan ninu odidi a ni lati ṣe gbogbo ohun ti awọn eniyan aye pe ni ifararubọ, kin ni yoo gba wa lati jẹ ọkan ninu awọn aṣẹku olootọ? Idahun si ibeere yi wa ninu Ọrọ Ọlọrun. Igbagbọ ti Kristi sọ pe a ki yoo ri ninu ọpọlọpọ ni opin aye jẹ ọkan ninu awọn ohun ti a ko gbọdọ ṣe alaini. Ki Ọlọrun jọwọ jẹ ki gbogbo awọn ti yoo ka ọrọ wọnyi le “ja gidigidi fun igbagbọ” ki wọn si jẹ ọkan ninu awọn aṣẹkù olootọ!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ diẹ ninu awọn iṣẹ iyanu ti o yẹ ki o mu ki Jesebeli mọ ipo ẹṣẹ ati were rè̩.
  2. N jẹ awọn iṣẹ iyanu naa ṣe Jesebeli ni ire? Mẹnu baa, ni kókó eredi ti o fi dahun bẹẹ.
  3. Yatọ si iṣẹ iyanu, kin ni ohun ti o ṣe danindanin lati gba awọn eniyan la kuro ninu ẹṣẹ wọn?
  4. Sọ awọn ohun ti o ṣẹlẹ ni igbesi-aye Elijah ti o fara jọ ohun ti o ṣẹlẹ ni igbesi-aye Mose.
  5. Akọsilẹ ti ọdun melo ni a ri ka nipa iṣẹ-iranṣẹ Elijah?
  6. Tani rọpo Elijah?
  7. N jẹ o dun mọ Ọlọrun ninu tabi O binu si Elijah nitori pe o sa kuro niwaju jesebeli?
  8. Eredi rè̩ ti Elijah ko ṣe fi ọwọ ti o fi han nigba ti o gbọ Ohun jẹjẹ nì han nigba ti o ri afẹfẹ, iji ati ina?
  9. Kin ni Ohun jẹjẹ ni fi han wa nipa Ọlọrun?
  10. Ọna wo ni a fi le pe ijoye alai-wa-bi-Ọlọrun ni iranṣẹ Ọlọrun?
1