I Awọn Ọba 20:1-43

Lesson 299 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin on ni yio si ká” (Galatia 6:7).
Cross References

I A Gbogun ti Samaria

1. Bẹnhadadi ati ọba mejilelọgbọn gbogun ti Samaria, wọn si ba a ja, I Awọn Ọba 20:1

2. A ranṣẹ si Ahabu pe ki o kó gbogbo ohun-ini rè̩ ti o ṣe iyebiye ju lọ wa, I Awọn Ọba 20:2, 3

3. Ọba israẹli gbà lati ṣe bẹẹ, I Awọn Ọba 20:4

4. A tun ranṣẹ miran ti o le gidigidi, I Awọn Ọba 20:5, 6

5. Ahabu ati awọn agba Israẹli kọ lati fara mọ ịṣẹ ti a ran si wọn ni ẹẹkeji, I Awọn Ọba 20:7-9

II Ogun Naa

1. Bẹnhadadi leri lọpọlọpọ nipa agbara ati ipa ti oun ni, ṣugbọn Ahabu ko naani rè̩, o si pa owe kan fun un, I Awọn Ọba 20:10, 11

2. Ẹgbẹ ogun Siria wa tẹgun, I Awọn Ọba 20:12

3. Awọn ọdọmọkunrin ti o jẹ ọmọ-alade igberiko gbogbo ni o ṣiwaju ogun Israẹli, Ahabu si n ṣe ọgagun, I Awọn Ọba 20:13-19

4. Awọn ọkunrin Israẹli pa olukuluku eniyan kọọkan, wọn si tu ogun Siria ká, I Awọn Ọba 20:20, 21

5. Woli kilọ fun Ahabu pe ogun Siria yoo tun pada wa, I Awọn Ọba 20:22

6. Lati fi agbara Rè̩ han, Ọlọrun fi ogun Siria keji le Israẹli lọwọ, I Awọn Ọba 20:23-30

III Iwa Alailọgbọn ti Ahabu hu

1. Bẹnhadadi ti a ti ṣẹgun rè̩ ranṣẹ si Ahabu lati beere ohun ti wọṅ yoo ṣe ki alaafia le wà, I Awọn Ọba 20:31, 32

2. Ahabu ranṣẹ pe Bẹnhadadi o si ba a da majẹmu, I Awọn Ọba 20:33, 34; I Samuẹli 15:3, 8, 9

3. Woli kan parada o si fi Ọrọ Oluwa siwaju Ahabu gẹgẹ bi owe, I Awọn Ọba 20:35-40

4. Ahabu ṣe idajọ ara rè̩, I Awọn Ọba 20:40-43

Notes
ALAYÉ

Oju Aye Re e

Ninu akọsilẹ awọn ogun ati ibalo ti o wa laarin Ahabu ọba Israẹli ati Bẹnhadadi ọba Siria, a le ri i bi aye ti ri. Ahabu ti wà ni ẹẹdẹgbẹrun ọdun ṣaaju Kristi, sibẹ iha ti o kọ si Ọlọrun ko yatọ si iha ti awọn eniyan aye ode-oni kọ si Ọlọrun. Ahabu jẹ ọba lori Israẹli fun nkan bi ọdun mejidinlogun ki Bẹnhadadi to gbogun ti ilẹ naa, ṣugbọn ibọriṣa ati iwa buburu gba gbogbo akoko yi kan. Ki i ṣe pe ọba yi n dẹṣẹ lai mọ nitori pe lori awọn Ọmọ Israẹli, awọn eniyan ti Ọlọrun yan, ni o n jọba, Ọlọrun ko si lọra lati kilọ fun un ni oniruuru ọna nipa idajọ gbigbona ati ẹsan ti ẹṣẹ rè̩ yoo mu wa, ṣugbọn ọba yi taku sinu iwa buburu rè̩. Boya o ro pe ere ẹṣẹ ki yoo pọ to bi awọn woli ti sọ tẹlẹ.

Akoko to, ẹṣẹ Ahabu si wa a ri. Ọlọrun lo Bẹnhadadi gẹgẹ bi ohun-elo lati mu Ahabu wa sinu iṣiro. Ẹgbaagbeje ọmọ-ọgun, ẹṣin ati kẹkẹ -- akopọ awọn ogun ati ohun-elo ogun awọn ọba mejilelọgbọn ti o wà pẹlu Bẹnhadadi yi ilu Samaria ka. Bẹnhadadi fi alaafia lọ Samaria lori adehun; bi o tilẹ jẹ pe ohun ti a beere lọwọ Ahabu ninu ipinhun alaafia yi ga rekọja, sibẹ Ahabu fesi pe oun yoo fara mọ ọn. Kò si ohun miran ti Ahabu le ṣe nitori pe iwọn iba ẹgbẹ ọmọ-ogun diẹ ti o wa ni Samaria ko lagbara lati ko ogun ti o yi i ka loju lai si iranlọwọ ẹlomiran. Ahabu ko si ni iha Ọlọrun ti i ba fi le ke pe E fun iranlọwọ. Baali ti o n sin ko si lagbara lati ṣe iranlọwọ. Ahabu ti fi ara fun ẹṣẹ o si ni lati gba ere ẹṣẹ.

Ère Ẹṣẹ

Ọlọrun jẹ olootọ si gbogbo ọkan. Awọn ti n dẹṣẹ n ṣe bẹẹ lodi si ẹri ọkan wọn ati ohùn Ọlọrun ti o fẹ tọ wọn si ipa-ọna ododo. Ohun kan n bẹ ninu ọkan ọmọ-eniyan ti n ran an leti pe idajọ n bọ. O fẹrẹ jẹ pe gbogbo eniyan ni o gba pe ẹni ti o ba gbin èbu ẹṣẹ yoo kore rè̩ nigbooṣe, paapaa ju lọ bi oluwarẹ ko ba yipada kuro ni ọna ẹṣẹ rè̩. Ọpọlọpọ ẹlẹṣẹ ni eṣu ti tanjẹ nipa mimu wọn ro pe wọn le jẹ adun ẹṣẹ fun igba diẹ, bi o ti wu ki ẹṣẹ naa ti buru to, lẹhin eyi ni wọn si le yi pada kuro ninu awọn ẹṣẹ ti o buru pupọ naa, nipa bẹẹ wọn ni ero pe awọn yoo bọ lọwọ ọpọlọpọ ijiya ẹṣẹ. Awọn ẹlẹṣẹ paapaa mọ pe ẹṣẹ dida ko lọ lọfẹ ṣugbọn wọn ro pe wọn o fi ohun ti o ba gba fun un bi wọn ti n lọ ninu ẹṣẹ. Ko kọ lati kó èle ori owo eesú ẹṣẹ ti o n da ṣugbọn o ni ero pe oun ki yoo ko eesu iya ẹṣẹ gidi ti oun n da ni akopọ. Abajọ ti Ọlọrun fi wi pe, “Ki a maṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7).

Ko ni Itẹlọrun

Bi o tilẹ jẹ pe Ahabu gba lati fara mọ ohun ti Bẹnhadadi beere lọwọ rẹ ni igba ikinni, sibẹ eyi ko tẹ Bẹnhadadi lọrun. Ahabu ṣeleri pe, “Tirẹ li emi ati ohun gbogbo ti mo ni” -- awọn aya, ọmọ, wura ati fadaka. Ibeere keji ti a fi siwaju Ahabu ni pe ki oṣi ilu Samaria silẹ fun awọn iranṣẹ Bẹnhadadi ki wọn le mu ohunkohun ti o ba dara loju wọn. Ibeere yi pọ ju ohun ti Ahabu ati awọn agbagba Israẹli le fara mọ lọ: wọn yan lati ku ju ati fara mọ iru iwọsi bayi. O ya ni lẹnu pe Ahabu le mu iru iduro yi lẹhin ti o ti ṣeleri gbogbo ohun ti o ni fun ọba Siria. Ahabu, gẹgẹ bi ogunlọgọ awọn eniyan lode oni, ro pe oun le fi ikọwọ-bọ-iwe ṣeleri pe oun yoo ṣe ohun kan, ṣugbọn oju rè̩ dá wai nigba ti Bẹnhadadi fi ye e pe o ni lati mu ileri rè̩ ṣẹ lai si aniani.

Bakan naa ni o ti di mimọ fun ọpọlọpọ ẹlẹṣẹ pe eṣu ki i gba pe ki eniyan dẹṣẹ diẹ ki o mọwọ kuro nibẹ. Akoniṣiṣẹ ti ko laanu ni eṣu i ṣe, a si maa ti awọn ẹrú rè̩ sinu ẹṣẹ siwaju ati siwaju. Ere ẹṣẹ ga lọpọlọpọ; bi o tilẹ jẹ pe ẹlẹṣẹ le maa ro o ninu ọkan rè̩ pe oun yoo ko eesu igbesi-aye ẹṣẹ, sibẹ nigba ti o ba de ibi kan, ẹlẹṣẹ a maa fa tikọ, ko si ni fẹ lati tẹ siwaju ninu ẹṣẹ mọ. O di mimọ fun Ahabu, bi o ti di mimọ fun awọn ẹlẹṣẹ pe, wọn n bẹ labẹ akoso kan ti o ga ju agbara wọn lọ. Nipa ero ẹda, ko si aba ati là.

Iranwọ lati Ode wa

Boya Ahabu le ti maa funnu pe oun ki yoo mu ibeere Bẹnhadadi ṣẹ; ṣugbọn ki yoo pẹ jọjọ ti agbara ogun Siria i ba wo ogiri ilu Samaria lulẹ tabi ti ogun ti o do ti wọn i ba ti mu ki iyan mu laarin ilu to bẹẹ ti agbara ko ni si mọ lati doju kọ ogun naa. Lai si iranlọwọ lati ode wa, Samaria ati Ahabu i ba ṣegbe, ṣugbọn iranlọwọ ti ode wa fun Ahabu! Iranlọwọ dide lati ibomiran ti Ahabu ko ni ẹtọ si rara -- iranlọwọ naa ti ọwọ Ọlọrun wa. Ahabu ko gbadura ṣugbọn a ko le fẹ awọn olododo eniyan diẹ ku ninu ilu naa ti n gbadura. Nipa adura ẹbẹ Abrahamu fun ilu Sodomu, Ọlọrun ṣe ileri pe Oun yoo da ilu naa si bi olododo mẹwa ba wa nibẹ. Ẹnu ya Ahabu gidigidi, o si yẹ ki ẹnu ya a, nigba ti woli mu irohin wa wi pe Ọlọrun yoo da ilu naa si. Ki i ṣe ọranyan fun Ọlọrun lati ran eniyan buburu lọwọ, paapaa ju lọ, ẹni ti o yipada kuro lọna ododo ati imọlẹ gẹgẹ bi Ahabu ti ṣe. Woli naa ba Ahabu wewe ogun naa, Ọlọrun si fun wọn ni iṣẹgun gẹgẹ bi O ti ṣeleri. Wo bi aanu Ọlọrun wa ti pọ to, ti O dide fun igbala ọba buburu ti a n pe ni Ahabu yi!

Iranwọ lati ode wa n bẹ fun ẹlẹṣẹ pẹlu! Bi ẹni naa tilẹ buru jai, ti o si wa ni ipo ainireti, ani ti ko si agbara fun un lati ja ide ẹṣẹ, Ọlọrun ti pese ọna idande kuro ninu ẹṣẹ silẹ: “Emi ẹni oṣi! Tani yio gbà mi lọwọ ara iku yi? Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa” (Romu 7:24, 25). “Nitori ọmọ-enia de lati wa awọn ti o nù kiri, ati lati gba wọn là” (Luku 19:10). “Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun ki iṣe ojusaju enia ... ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ, yio ri imukuro ẹṣẹ gbà” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 43). Jesu Kristi Oluwa wa wa si aye yi, O gbe ninu aye, O ku O si jinde kuro ninu oku ki O le da ẹlẹṣẹ silẹ kuro ninu igbekun ẹṣẹ ki o si di ero Ijọba Ọrun. Ahabu bọ lọwọ iṣubu, boya nipa adura ẹlomiran; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ni lati gbadura tikara rẹ bi o ba fẹ ni igbala. Ẹnikẹni ni o le wa sọdọ Oluwa – ko si ẹni ti a ta nù; ṣugbọn ọna kan naa ni gbogbo wọn ni lati gba wa: nipa igbagbọ ninu Jesu Kristi; nipa ironupiwada gbogbo ẹṣẹ ti wọn ti da ati nipa igbọran si Ọrọ Ọlọrun bi imọlẹ ti n tan siwaju ati siwaju fun awọn ẹlẹṣẹ. Wo bi oore Ọlọrun ti pọ to! Ẹlẹṣẹ paraku ti o buru ju lọ le tọ Ọlọrun wa fun idande lọna kan naa pẹlu ẹni ti i ṣe ọmọluwabi oniwa rere. Ẹnikẹni ti o ba mọ pe oun gbe ati pe ireti ko si fun oun mọ nipa ti ẹda, yoo ri idande ti o ba tọ Ọlọrun wa.

Idande

“Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ ki o si wo ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ ọ wa” (I Awọn Ọba 20:22). Woli naa wa sọdọ Ahabu lẹẹkeji pẹlu ikilọ yi. Ọlọrun ti gba awọn eniyan naa silẹ kuro lọwọ ọta: ṣugbọn O sọ fun wọn pe ọta yoo pada ni akoko kan naa ni amọdun. Otitọ ni Ọrọ Ọlọrun. Ọba Siria gbá gbogbo ogun rè̩ jọ, o si fi awọn olori-ogun ṣe akoso ẹgbẹ-ogun kọọkan dipo awọn ọba ti o fi ṣe olori-ogun ni iṣaaju. Awọn ogun Siria pinnu lati ba awọn Ọmọ Israẹli ja ni pẹtẹlẹ ninu ogun yi nitori ti wọn lero pe Ọlọrun oke nikan ni Ọlọrun Israẹli, ki I si i ṣe Ọlọrun afonifoji. Awọn ara Siria dide si awọn Ọmọ Israẹli pẹlu Igboya nlá nlà. Ogun awọn ara Siria lọ bẹẹrẹbẹ, ṣugbọn ogun awọn Ọmọ Israẹli do siwaju wọn “gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji” ṣugbọn ogun pupọ ati ọpọ eniyan ko jamọ nkan fun Ọlọrun wa. Ọlọrun fi iṣẹgun fun Israẹli lati fi han fun awọn abọriṣa ara Siria pe Ọlọrun Israẹli lagbara lori ohun gbogbo ati pe O kun gbogbo aye.

Ọna pupọ ni eyi fi fara jọ igbesi-aye Onigbagbọ. Ọlọrun pe ẹlẹṣẹ jade kuro ninu igbesi-aye buburu O si da a nide kuro ninu gbogbo iwa buburu, O si fi opin si oungbẹ ẹṣẹ. Ẹni naa di ẹda titun ninu Kristi Jesu, o bẹrẹ igbesi-aye ọtun; ṣugbọn Ọlọrun n kilọ fun oluwarẹ lati rin ninu imọlẹ Ọrọ Ọlọrun, ki o jẹ alagbara ninu Oluwa ki o si gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ; nitori ti idanwo ki yoo ṣalai de ba a. Eṣu, ọta ẹmi, yoo pada lati yiiri Onigbagbọ ati lati mì ipilẹ igbagbọ rè̩ wo. Bi Onigbagbọ naa ba jẹ olootọ si Ọlọrun, ọta ki yoo le bori rara nitori “ẹniti mbẹ ninu nyin tobi ju ẹniti mbẹ ninu aiye lọ” (I Johannu 4:4). Ati pe “Ko si idanwò kan ti o ti iba nyin, bikoṣe iru eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti ki yio jẹ ki a dan nyin wo ju bi ẹnyin ti le gba; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò naa, ki ẹnyin ki o ba le gba a” (I Kọrinti 10:13).

Ileri Satani

Iṣẹgun nla nla ni Ọlọrun fun Ahabu ati awọn Ọmọ Israẹli lori ogun Siria ni igba meji leralera. O yẹ ki Ahabu le mọ nigba naa pe Ọlọrun n ba awọn ara Siria ja bi o tilẹ jẹ pe Bẹnhadadi sa asala, o si wa laaye sibẹ. Bẹnhadadi ranṣẹ si Ahabu fun aanu bi ko tilẹ mọ iru ọkan ti Ahabu yoo fi gba ọran yi, ṣugbọn ihin asala Bẹnhadadi dun mọ Ahabu o si fi ayọ gba a, o si pe e ni “arakunrin.” A pe ipade kan laarin awọn ọba mejeeji, wọn si da majẹmu nipa eyi ti Bẹnhadadi pada si ilẹ Siria ni alaafia. O ṣe ileri fun Ahabu pe, “Awọn ilu ti Baba mi gba lọwọ baba rẹ, emi o mu wọn pada, iwọ o si la ọna fun ara rẹ ni Damasku, bi baba mi ti ṣe ni Samaria.” Wo bi arekereke eṣu ti pọ to! Ahabu i ba ti ko ogun lọ si Siria lati gba gbogbo ilẹ naa, ṣugbọn dipo eyi, o ti dá majẹmu, a si ti ṣe ileri ilẹ diẹ fun un.

Satani a maa leri ohun nla fun Onigbagbọ bi o ba le yipada kuro lọdọ Ọlọrun lati sin eṣu; ṣugbọn ofo ni ileri ogo asan aye, ère igba diẹ ati okiki ti eṣu n ṣeleri. Eṣu a maa leri ohun gbogbo lai fun ni ni ohun kan bi ko ṣe ibanujẹ, ṣugbọn Ọlọrun a maa ṣeleri pupọ fun ni O si maa n fun ni ju bi ọkan ti n fẹ lọ. Wo bi were awọn wọnni ti pọ to ti wọn ni igbẹkẹle si ileri ẹṣẹ ti wọn si gba lati rọ mọ alumọni ati ohun asan aye yi ti ko duro pẹ! Ọlọrun ti fi iṣẹgun ti o daju, ileri iye ainipẹkun ati iṣura ayeraye ti n bọ fun awọn Onigbagbọ. Ohunkohun ha wà ti o niyelori bi eyi! Ndao! Ko si rara!

Atubọtan

Woli kan tọ Ahabu wa nigba kẹta, ṣugbọn ki i ṣe pẹlu irohin alaafia tabi ikiya ni akoko yi. Ọlọrun fi owe kan siwaju ọba yi ni ọna ti o ṣe pe oun tikara rẹ ni yoo pinnu ohun ti yoo fi dahun lọna ti o tọ. Kiakia ni ọba yi dahun wi pe, “Bẹni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti da a.” Ọba naa si wariri nigba ti woli naa mu eeru kuro ni oju rè̩, ti o si wi pe: “Bayi li OLUWA wi, nitoriti iwọ jọwọ rè̩ lowọ lọ ọkunrin ti emi ti yan si iparun patapata, ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rè̩ ati enia rẹ fun enia rè̩.”

Ọlọrun fun eniyan ni ẹtọ lati yan ohun ti o ba fẹ, i baa ṣe rere tabi buburu. Ẹnikẹni ti o ba yan lati sin Ọlọrun, lati gba Kristi gbọ gẹgẹ bi Olugbala rè̩ yoo wọ Ọrun lẹhin ti o ba fi aye yi silẹ gẹgẹ bi olododo; ṣugbọn ẹni ti o kọ lati feti si agogo ti n lù ninu ọkan rè̩ ti o si yan ọna aye ati ẹṣẹ, ti o si n sin eṣu yoo di ero ọrun apaadi nikẹhin aye rẹ. Yan ire! “Bẹni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti da a.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Iṣẹ wo ni Bẹnhadadi ran si Ahabu?
  2. N jẹ esi Ahabu tẹ Bẹnhadadi lọrun?
  3. Kin ni ipinnu Ahabu ati awọn agbaagba Israẹli lori iṣẹ keji ti Bẹnhadadi ran?
  4. Tani ṣẹgun ninu ogun naa? Eeṣe?
  5. Eredi rè̩ ti woli ni fi tọ Ahabu wa nigba keji?
  6. Ọwọ wo ni Ahabu fi mu Bẹnhadadi onde?
  7. Eredi rè̩ ti ohun ti Ahabu ṣe ko fi jẹ didun inu Ọlọrun?
  8. Ọna wo ni Ọlọrun gba lati sọ fun Ahabu pe ko ṣe ohun ti o tọ?
1