I Awọn Ọba 21:1-29

Lesson 300 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹbun yio ye” (Owe 15:27).
Cross References

I I Ọgba – Ajara ti o S̩ojukokoro rè̩

1 Ahabu n fẹ ra ọgba-ajara Naboti, I Awọn Ọba 21:1, 2

2 Kikọ ti Naboti kọ lati ta a jẹ gẹgẹ bi ilana Ofin, I Awọn Ọba 21:3; Lefitiku 25:23; Numeri 36:7; Esekiẹli 46:18

3 Ahabu wugbọ nitori inu rè̩ bajẹ, I Awọn Ọba 21:4

II II Jesebeli di Rikiṣi Buburu

1. O kẹgan Ofin, I Awọn Ọba 21:5-7

2. O pete ipaniyan, I Awọn Ọba 21:8-10

3. O mu ete ipaniyan rè̩ ṣẹ, I Awọn Ọba 21:11-14

4. Ahabu gba ọgba naa, I Awọn Ọba 21:15, 16

III Elijah Sọ Idajọ ti yoo wa sori Ahabu

1. Ọrọ Oluwa tọ Elijah wa nipa Ahabu, I Awọn Ọba 21:17-19

2. Ahabu mọ iya ẹṣẹ rẹ lara nigba ti a ri i mu, I Awọn Ọba 21:20

3. Ahabu gbọ idajọ ti yoo wa sori ile rè̩, I Awọn Ọba 21:21-24

4. A darukọ Jesebeli bi ẹni ti o ti Ahabu si iwa buburu ati ibọriṣa, I Awọn Ọba 21:25, 26; 16:31; 18:13

5. Iwa irẹlẹ Ahabu fun un ni anfaani, I Awọn Ọba 21:27-29; Orin Dafidi 86:5; Ẹkun Jeremiah 3:22

Notes
ALAYÉ

Ofin Ilẹ-Ini

Bi a ba fi oju ti a fi n-duna-du-ra ilẹ tita ati rira ni ode-oni wo o, yoo dabi ẹni pe ohun ti Ahabu fi lọ Naboti nipa ọgba-ajara rè̩ dara pupọ. Ahabu ṣeleri lati fun Naboti ni ọgba-ajara miran ti o dara jù tabi ki o fun un ni owo dipo ọgba-ajara rè̩. S̩ugbọn ofin ilẹ-ini ni Israẹli yatọ si ti wa nitori pe Ọlọrun ti paṣẹ pe, “Ẹnyin ko gbọdọ ta ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ; nitoripe alejo ati atipo ni nyin lọdọ mi” (Lefitiku 25:23). Nipa bayi a ri i pe ohun ti Ahabu fẹ ṣe yi lodi si ofin Ọlọrun.

Ofin ti Ọlọrun fi lelẹ fun Israẹli nipa ilẹ-ini wọn ba ofin ọja tita ati rira ti ode-oni mu o si tọna bi o tilẹ jẹ pe ko le tẹ awọn olojukokoro lọrun. Bi ẹni kan ba ta ilẹ-ini rè̩ nitori aini, a ni lati da a pada fun un ni Ọdun Jubeli, eyi ti a n ṣe ni araadọta ọdun. Nipa bayi ẹni kan ko le ni ilẹ-ini lọ rẹpẹtẹ ki awọn miran si jẹ mẹkunnu labẹ rè̩. A fi ofin de awọn alaṣẹ ilu nipa nkan yi pe, “Olori na ki yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rè̩ lara ini ti ontikararẹ: ki awọn enia mi ki o ma ba tuka, olukuluku kuro ni ini rè̩” (Esekiẹli 46:18). Ọlọrun ko fẹ ki awọn ti i ṣe olori ni Israẹli ki o ni awọn eniyan lara tabi ki wọn gba ohun-ini wọn. O gba awọn ti i ṣe alakoso Ijọ ni ode-oni niyanju pe, “Ẹ mā tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ larin nyin, ẹ mā bojuto o, ki iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkan ti o mura tan. Bẹni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo” (I Peteru 5:2, 3).

Irapada ati Jubeli

Bi ẹni kan ba ta ilẹ-ini rè̩, yoo ta a fun iwọn iba ti o ku ki akoko Ọdun Jubeli fi to; fun apẹẹrẹ, bi Ọdun Jubeli ba ku ọdun mejidinlogun, ti owo ilẹ kan si jẹ bi ọrinlelẹgbẹta pọun, lọdọọdun ni owo ilẹ naa yoo maa fi bi pọun mẹtadinlogoji din titi di akoko Ọdun Jubeli ti a ki yoo gba owo lori ilẹ naa mọ rara. Nigbakuugba ti ẹni ti o ni ilẹ tabi ibatan rè̩ ba fẹ, o le ra ilẹ naa pada nipa sisan iye owo ti o kù lori ilẹ naa gẹgẹ bi akoko ti o kù ki Ọdun Jubeli to.

Itan Rutu jẹ apẹẹrẹ ti o gbadun lori ọran yi bi o ti fi ye wa gẹgẹ bi Boasi ti i ṣe ibatan Naomi ti ṣe ra ohun-ini ti i ṣe ti Naomi pada, ti o si fi Rutu ṣe aya. Nipa bayi, Rutu jẹ apẹẹrẹ iyawo Kristi lati inu iran Keferi wa. A ti ta wa sabẹ isinru ẹṣẹ titi Kristi Olugbala wa fi ra wa pada pẹlu Ẹjẹ Rè̩ iyebiye ti o si fun wa ni “ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti ki iṣá ti a fi pamọ li ọrun” (I Peteru 1:4). Iwọ ha fi ọwọ danindanin mu ogún ti rẹ gẹgẹ bi Naboti ti ṣe fi ọwọ danindanin mu ogún ti rẹ? O wi fun Ahabu pe, “Oluwa má jẹ ki emi fi ogún awọn baba mi fun ọ” (I Awọn Ọba 21:3).

Ojukokoro

Nitori ti ọkan rè̩ ti o kun fun ojukokoro ko ri ohun ti o n fẹ, Ahabu wugbọ gẹgẹ bi ọmọ ti a ti kẹ bajẹ ti o si ti rà, o “dubulẹ lori akete rè̩, o si yi oju rè̩ pada, ko si fẹ ijẹun.” Eyi fi han bi ọkan rè̩ ti kun fun ojukokoro to. Ofin kẹwa ti Ọlọrun fi fun awọn Ọmọ Israẹli sọ bayi pe, “Iwọ ko gbọdọ ṣojukokoro si ... ohun gbogbo ti i ṣe ti ẹnikeji rẹ” (Ẹksodu 20:17). Lati ori ogiri aafin rẹ ni Ahabu gbe ri ọgba-ajara daradara yi ti o si ro ninu ọkan ara rè̩ pe yoo dara pupọ lati fi ṣe ọgba ewebẹ. O dabi ẹni pe ko si ohun ti o buru ni ti pe o ni ifẹ si ilẹ ti o sun mọ aafin rè̩ yi, ṣugbọn Ọlọrun wi pe Agbẹdọ! Bi aladugbo wa ba ni ohun ti o dara ti o si n gbadun rè̩, anfaani rè̩ ni eyi jẹ. Bi o ba ni lọwọ ju wa lọ, ko buru; ti rẹ ni i ṣe, a si ni lati pa oju wa mọ ki o má ṣe tè̩ mọ ohun-olohun to bẹẹ ti oungbẹ ohun-ini ẹlomiran yoo fi maa gbẹ ọkan wa.

Ojukokoro ni isopọ pẹlu ẹṣẹ ti ọmọ-eniyan kọkọ da, oun si ni o n ṣe okunfa iṣubu ogunlọgọ eniyan lode oni. Boya ohun ti Satani ṣe ni pe o mu ki Efa maa rin yika igi kan ki o si tẹjumọ eso rè̩ titi ifẹ rẹ fi fa si i. O jẹ ninu rẹ, o si ti gbogbo ẹda eniyan sinu ẹṣẹ. Lọti si gbe oju rè̩ soke si agbegbe Jọrdani ti o li omi, o si pa agọ rè̩ si iha Sodomu, ṣugbọn agbara kaka ni o fi sa jade laaye. Laarin ikogun Jẹriko, Akani ri ẹwu Babeli daradara kan, igba ṣekeli fadaka ati dindi wura kan: o ṣojukokoro wọn, o si mu wọn; ṣugbọn a sọ ọ li okuta, oun ati awọn ara ile rè̩. Gehasi ri ẹbun Namani o si sa tọ wọn lọ; ṣugbọn o gba ẹtẹ Namani pẹlu. Judasi tẹjumọ owo, o si ta Oluwa rè̩ fun ọgbọn owo fadaka; ṣugbọn o gba ẹmi ara rè̩ nikẹhin. Abajọ ti a fi kilọ fun ni wi pe: “Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba ko si ninu rè̩. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba bikoṣe ti aiye” (I Johannu 2:15, 16).

Iṣura ni Ọrun

Ki i ṣe pe a kilọ fun ni wi pe ki a maṣe ṣojukokoro awọn ohun aye yi nikan, ṣugbọn a sọ fun wa ibi ti ifẹ ati iṣura wa ni lati wà. “Ẹ to iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kokoro ati ipara ko le ba a jẹ, ati nibiti awọn ole ko le runlẹ ki nwọn si jale. Nitori nibiti iṣura nyin ba gbe wà, nibẹ li ọkan nyin yio gbe wa pẹlu” (Matteu 6:20, 21). “Ẹ mā ronu awọn nkan ti mbẹ loke kì iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye” (Kolosse 3:2). Jesu wi fun ijoye ọdọmọkunrin ọlọrọ naa pe, “Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ ta ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talaka, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mā tọ mi lẹhin” (Matteu 19:21).

Onigbagbọ ni iye ainipẹkun, o si ni lati maa wo ohun ti o tayọ awọn ohun igba isinsinyi, ani awọn nkan wọnni ti yoo wa titi. Ahabu ri ogba-ajara. Kin ni iwọ ri? Nibo ni iwọ fi oju rẹ si? Abrahamu “nreti ilu ti o ni ipilẹ; eyiti Ọlọrun tẹdo ti o si kọ” (Heberu 11:10). O jẹ ọkan ninu awọn ti o “jẹwọ pe alejo ati atipo li awọn lori ilẹ aiye. Nitoripe awọn ti o nsọ iru ohun bẹ, fihan gbangba pe, nwọn nṣe afẹri ilu kan ti iṣe tiwọn” (Heberu 11:13, 14). Afẹri kin ni iwọ n ṣe? Ahabu ṣe afẹri ọgba ajara; Jesebeli gba a fun un.

Jesebeli

“S̩ugbọn ko si ẹnikan bi Ahabu ti o ta ara rè̩ lati ṣiṣẹ buburu niwaju OLUWA, ẹniti Jesebeli aya rè̩ ntì” (I Awọn Ọba 21:25). A ri apẹẹrẹ bi Jesebeli ti n ti Ahabu nigba ti o wi pe: “Iwọ ko ha jọba lori Israẹli nisisiyi? Dide, jẹun, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dun! Emi o fun ọ ni ọgba-ajara Naboti ara Jesreeli” (I Awọn Ọba 21:7). Nipa ọrọ yi, jesebeli gbimọ lati pa Naboti. O ri i pe a ṣiṣẹ ibi naa, o si ran Ahabu lati gba ọgba-ajara naa. Iru iwa ipaniyan ni ipa-ailaanu yi ko jamọ nkankan loju obinrin olusin Baali ti o fi atike kun oju gbúgbu yi. O pa awọn woli Oluwa sibẹ o n fi ounjẹ bọ ọtalelẹgbẹrin o din mẹwa (850) woli oriṣa lori tabili rè̩. O le pa bi o ti fẹ pẹlu ẹtan yi pe o n gbe orukọ oriṣa rè̩ ga, sibẹ o sa jẹ onitara olusin Baali. Iwa itiju pupọ ti awọn eniyan ti fi ọran ẹsin ṣe bojuboju lati hu ti jẹ abawọn lati irandiran.

Idajọ ati Aanu

S̩ugbọn ki ẹnikẹni ki o má ṣe ro pe oju Ọlọrun ko ri nkan wọnyi; o pẹ ni, o ya ni, Ọlọrun yoo ran idajọ. Ọlọrun mu ki Elijah wà ni tosi lati ba Ahabu wi nigba ti o n lọ lati gba ọgba-ajara Naboti. Elijah sọ ohun ti yoo de ba Ahabu ati ile rè̩ fun un. Aja ni yoo jẹ Jesebeli ninu yàra Jesreeli, gbogbo iran Ahabu ni a o si ke kuro. Lọna kan awọn idajọ Ọlọrun lati ẹnu woli Rè̩ ti o mu bi ina wọ ọkan ọba buburu yi. O wọ aṣọ ọfọ, o si n ṣe pẹlẹpẹlẹ. Wo bi ifẹ Ọlọrun wa ti pọ to ti O tun le fi aanu han fun Ahabu nigba ti o rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Eredi rè̩ ti Naboti ko fi ta ọgba-ajara rè̩ fun Ahabu?

  2. 2 Kin ni fi han pe Ahabu jẹ olojukokoro?

  3. 3 Kin ni ofin wi nipa ojukokoro?

  4. 4 Sọ awọn miran ti o ti ipa ojukokoro ṣubu.

  5. 5 Ọna wo ni Jesebeli gba lati gba ọgba-ajara Naboti fun Ahabu?

  6. 6 Kin ni fi han pe Ahabu ni ẹbi ninu ọran naa?

  7. 7 Tani ẹlomiran ti o tun ni ẹbi ninu iditẹ naa?

  8. 8 S̩e alaye nipa ofin ilẹ tita ni Israẹli.

  9. 9 Nigba wo ati nibo ni Elijah gbe pade Ahabu?

  10. 10 Idajọ wo ni a ṣe fun Ahabu?

  11. 11 Kin ni idajọ naa ti ri ni ọkan Ahabu?

  12. 12 Bawo ni Ọlọrun ṣe fi aanu han fun Ahabu?

1