Iṣe Awọn Apọsteli 6:1-7; I Timoteu 3:1-16; 5:17-19; Titu 1:5-9;I Peteru 5:1-5

Lesson 288 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ mā gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mā tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin” (Heberu 13:17).
Notes

Idagbasoke

Bi awọn ọmọ-ẹhin ti n waasu Jesu ni eniyan pupọ n dara pọ mọ wọn. Agbo awọn ti o gbagbọ tubọ n kun siwaju ati siwaju titi ọwọ awọn Apọsteli nikan ko fi le ka gbogbo iṣẹ naa. Ikunsinu wa dide laarin awọn Hellene wi pe a ko bojuto awọn opo wọn. O ti jẹ ara ojuṣe awọn Apọsteli lati ṣe ipinfunni awọn nkan ti ara fun awọn ti wọn jẹ alaini (Iṣe Awọn Apọsteli 4:35).

Bi awọn Apọsteli ti jẹ Heberu, o le dabi ẹni pe wọn ṣe ojusaju ni, nitori pe a ko sọrọ rara pe wọn gbagbe awọn opo Heberu. S̩ugbọn o fẹrẹ daju wi pe a ko mọọmọ gboju fo wọn da. Bibeli kọ ni pe a ko gbọdọ ṣe ojusaju (Owe 24:23; Jobu 13:10; Lefitiku 19:15). Paulu kọwe bayi si Timoteu, “Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ati awọn angẹli ayanfẹ, ki iwọ ki o mā ṣakiyesi nkan wọnyi, laiṣe ojusaju, lai fi ègbe ṣe ohunkohun” (I Timoteu 5:21).

Ikunsinu

A ko sọ fun ni ẹni ti wọn rojọ fun. Nigba miran awọn eniyan a maa rojọ fun awọn ọrẹ ati aladugbo wọn, ṣugbọn wọn ko ni jẹ lọ sọdọ alakoso wọn ti o le tun ọran naa ṣe. S̩ugbọn a ri olootọ kan ti o sọ ọrọ naa fun awọn Apọsteli, a si mu ohun ti o fa ikunsinu naa kuro.

Ti a ko ba fun ọ ni iwe nigba ti a n pin wọn ni ile-iwe, o ko ha ni sọ fun olukọ rẹ pe a ti gboju fo ọ da? Ti a ba fi ẹran sinu ọbẹ gbogbo eniyan, ṣugbọn ki o ma si ẹran ninu ọbẹ ti rẹ nikan ṣoṣo, n jẹ o ko ni sọ fun iya rẹ pe wọn ko fi ẹran sinu ọbẹ rẹ? Ki ha ṣe ohun ti o tọna bi lati sọ fun awọn alakoso nigba ti ohunkohun ba dabi ẹni pe ko lọ deedee?

A ko mọ boya ikunsinu naa fidi mulẹ tabi ko fidi mulẹ. Yala è̩sun naa jẹ ootọ tabi bẹẹ kọ, a sa mu ohun ti o fa ikunsinu naa kuro. A pe ipade, ogunlọgọ awọn ọmọ-ẹhin si pejọ sibẹ. Wọn jọ da ọrọ ikunsinu yi rò.

Ifara-rubọ ti o Jinlẹ

Jesu ti pe awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lati ṣiṣẹ fun Un. Fun awọn kan O wi pe, “Ẹ mā tọ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia” (Matteu 4:19). Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ wi pe ki i ṣe awọn ni o yan Oun ṣugbọn Oun ni O yàn wọn, ti Oun si fi wọn sipo, ki wọn ki o le lọ, ki wọn si so eso (Johannu 15:16). Jesu pe awọn Apọsteli mejila O si ran wọn jade lati lọ waasu Ihinrere ati lati wo awọn olokunrun san (Matteu 10:1-8). Lẹhin ti Jesu lọ si Ọrun (Iṣe Awọn Apọsteli 1:9), o wa di ojuṣe awọn Apọsteli mejeejila lati maa waasu Ihinrere ati lati maa tan ihin ayọ ti igbala kalẹ. Eyi ni iṣẹ ti ẹmi ti a ti pe wọn si.

Bi awọn ti wọn gbagbọ ti n pọ sii, bẹẹ ni iṣẹ n pọ sii. Awọn Apọsteli mejeejila sọ pe ki awọn ijọ eniyan yan ọkunrin meje ti yoo gba apa kan iṣẹ naa ṣe – bibojuto ohun ti ara. Eyi yoo fun awọn mejeejila ni anfaani lati maa “duro ṣinṣin ninu adura igba, ati ninu iṣẹ iranṣẹ ọrọ na.” Wọn woye pe ko yẹ ki a gba akoko wọn ati ọkan wọn kuro ninu iṣẹ ti Ọlọrun ti pe wọn si.

Awọn Diakoni

A saba maa n pe awọn oṣiṣẹ meje inu ijọ wọnyi ni “diakoni.” A yan wọn lati ran awọn Apọsteli lọwọ ati lati bojuto ipinfunni ounjẹ fun awọn alaini. Ki a to yàn wọn, awọn Apọsteli sọ fun awọn eniyan pe, “Ẹ wò ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmi Mimọ ati fun ọgbọn.” Wọnyi ni ohun ti a beere -- olorukọ rere, ẹni ti o kun fun Ẹmi Mimọ ati fun ọgbọn. Awọn ohun amuyẹ wọnyi ga ni tootọ, ṣugbọn o yẹ ki awọn ti o ba fẹ jẹ oṣiṣẹ fun Oluwa gbe igbesi-aye rere ti o kun fun ẹmi Ọlọrun.

Awọn ọkunrin meje olorukọ rere naa ni iduro rere laarin awọn eniyan. Iwa wọn dara, wọn si jẹ alailẹgan. Awọn eniyan yoo le fi ọkan tan iru awọn eniyan bẹẹ. Awọn ọkunrin meje wọnyi tun ni ẹbun ti ẹmi pẹlu. Wọn kun fun Ẹmi Mimọ. A ti fi agbara Ẹmi Mimọ wọ wọn, eyi ti i ṣe ẹbun Ọlọrun (Iṣe Awọn Apọsteli 2:38; 10:45), eyi ti n ṣe eniyan ni ẹlẹri fun Oluwa, ti o si n fun un ni agbara fun iṣẹ isin (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Wọn ti n lo agbara yi ki wọn ma ba sọ ọ nù. Wọn ti tẹsiwaju lati maa gbadura ati lati maa fi aye wọn rubọ fun Ọlọrun. O jẹ ibukun ribiribi lati ri agbara Ẹmi Mimọ gba, ṣugbọn o ṣe dandan gidigidi fun eniyan lati pa awọn ibukun Ọlọrun mọ ninu igbesi aye rè̩.

A beere pe ki awọn diakoni mejeeje kun fun ọgbọn pẹlu. Awa naa le woye pe o yẹ ki awọn eniyan wọnyi ti ni oye ti yoo le mu ki o ṣe e ṣe fun wọn lati bojuto iṣẹ ti a fi le wọn lọwọ daradara.

Awọn ijọ yan awọn diakoni meje naa. Awọn Apọsteli fọwọ si i, wọn si fi adura yan wọn sipo. A ri pe o ṣe e ṣe lati fi iyára ati irọrun mu ki ede-aiyede pari. Ki i ṣe pe awọn Apọsteli n wa agbara fun ara wọn lati le maa jẹ gàba. Awọn diakoni meje wọnyi ni a fun ni iṣẹ ti awọn ẹlomiran le ṣe ninu iṣẹ iranṣẹ awọn Apọsteli. Ki i ṣe pe awọn Apọsteli yẹ iṣẹ ti wọn silẹ, wọn ba awọn ẹlomiran pin in ni. Ifẹ ati ogbọn ni wọn lo nigba ti wọn fi awọn ọkunrin ti wọn ṣe e fọkan tan wọnyi ṣe alabojuto awọn nkan ti ara. Eto naa ko ni ṣai dun mọ Ọlọrun ninu, nitori iye awọn ti wọn gbagbọ pọ sii, Ọrọ Ọlọrun ti a n waasu si fidi mulẹ.

Awọn Iriju Miran Ninu Ijọ

Nigba ti awọn eniyan n pọ sii ti a si n da awọn ijọ silẹ nibomiran, o wa di ọranyan fun wọn lati ni diakoni ati awọn iriju miran sii ninu ijọ. Ninu awọn iwe ti Paulu ati Peteru kọ, a ri awọn itọsọna nipa awọn biṣọpu ati awọn alagba ati awọn diakoni pẹlu. Awọn biṣọpu ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn n ṣe abojuto awọn ijọ. A gba wọn niyanju lati di “ọrọ otitọ mu ṣinṣin” ki wọn ba le maa “gba-ni-niyanju ninu ẹkọ ti o yè kõro ki wọn si le maa fi oye yé” awọn ti n gbọ (Titu 1:9). Awọn miran ninu awọn oniwaasu, pẹlu awọn kan ninu awọn oṣiṣẹ ni a pe ni alagba. A sọ fun awọn naa lati “mā tọju agbo Ọlọrun.” Eyi ni pe ki wọn ṣe iranwọ nipa ti ẹmi (I Peteru 5:2). Nipa igbesi-aye wọn, a beere pe ki wọn jẹ apẹẹrẹ fun awọn eniyan Ọlọrun.

Ohun amuyẹ kan naa ni a beere lọwọ gbogbo awọn iriju wọnyi. Ọlọrun beere pe ki gbogbo awọn ti wọn jẹ iriju yala ninu ohun ti ẹmi tabi ohun ti ara gbe igbesi-aye rere, ailẹgan, ailabuku, ati irẹlẹ.

Awọn Iriju Ijọ Loni

Ninu ijọ ti wa, Apostolic Faith, a ni awọn iriju bi ti awọn ijọ awọn Apọsteli igbà nì. Ni iya-ijọ wa ni Portland, Oregon, a ni Alabojuto Gbogbogboo ti o n ṣe akoso gbogbo iṣẹ naa. O ni igbakeji lati ran an lọwọ ninu iṣẹ nlá nlà naa. Bi a ko tilẹ yan awọn kan ni alagba ati diakoni awọṅ kan wà ti awọn eniyan mọ ti wọn si n ṣe iṣẹ awọn diakoni ati alagba. Awọn ti n ṣe iranwọ fun awọn alufa ni a pe ni “Oṣiṣẹ.”

Awọn alufa ati oṣiṣẹ kan wà ti a le pe ni alagba. Wọn a maa gbadura fun awọn alaisan, wọn a maa ba alakoso jiroro lori awọn nkan ti ẹmi, wọn a si maa gbani-niyanju. Awọn kan tun wà, bi diakoni, ti n ṣe abojuto awọn nkan ti ara. Lara iṣẹ wọn ni bibojuto titò awọn mọto, ṣiṣe eto awọn aṣọde, kikọ ile titun, iṣẹ ibi itẹwe, ati awọn iru nkan bẹẹ ti o jẹ mọ nkan ti ara. Iṣẹ nipa nkan ti ẹmi ati nkan ti ara jọ wà ninu Ihinrere ni, a ko si le ṣe aṣeyọri ọkan ninu wọn lai si iranwọ ekeji.

Bi a ti n fi ọkàn ati ọwọ wa rubọ, Ẹmi Ọlọrun n wa olukuluku ri, O si n yan an si ipo iṣẹ ti rè̩. Eniyan le ṣe olootọ nidi iṣẹ kan fun saa kan, ki Ọlọrun si tun fun un ni iṣẹ miran lati ṣe. Ninu awọn meje ti a kọ yan ṣe diakoni, o to ẹni meji ti o tun ṣe iṣẹ miran. Stefanu ti o “kún fun õre-ọfẹ ati agbara, o ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami nla lārin awọn enia ... Nwọn ko si le ko ọgbọn ati ẹmi ti o fi nsọrọ loju” (Iṣe Awọn Apọsteli 6:8, 10). Iwaasu Stefanu gún awọn Ju lọkan to bẹẹ ti wọn fi “mu awọn ẹlẹri eke wa” lati tako o, wọn si sọ ọ ni okuta. Oun ni o ni anfaani lati jẹ ajẹriku kinni laarin awọn Onigbagbọ. Filippi pẹlu di oniwaasu. Ninu isọji nlá nlà kan ti o bẹ silẹ ni Samaria o “wasu Kristi” to bẹẹ ti ọpọ eniyan fi gbagbọ ti wọn si ri igbala (Iṣe Awọn Apọsteli 8:5, 12). A ran an lọ ba iwẹfa ara Etiopia, o si ran iwẹfa naa lọwọ lati ni iyipada ọkàn (Iṣe Awọn Apọsteli 8:27, 37). A ni laarin isin wa ọkunrin kan ti o ti jẹ olori awọn adena wa. O ṣe olootọ nidi iṣẹ rè̩, Ọlọrun si pe e lati di ayè miran. Fun ọpọlọpọ ọdun bayi ni o ti n ṣe oniwaasu, o si ti fi otitọ ọkan waasu Ihinrere.

Ọpọlọpọ ewe ati awọn ọdọ ni wọn ti ni itara lati jẹ oṣiṣẹ fun Oluwa. Wọn ti ya aye wọn sọtọ fun Ọlọrun, ki wọn ba le jẹ ohun-elo “si ọlá, ti a yà si ọtọ, ti o si yẹ fun ilo bāle, ti a si ti pese silẹ si iṣẹ rere gbogbo” (II Timoteu 2:21). Ẹmi Ọlọrun ti ṣe iranwọ fun wọn lati de oju ami ohun ti a n beere lọwọ awọn ti o fẹ jẹ alufa tabi oṣiṣẹ. Wọn ti gbe igbesi-aye alailabuku, mimọ, ọlọwọ, titọ, ati ti airekọja. Wọn ti fẹran awọn eniyan Ọlọrun, wọn si ti ni inurere lati gba wọn ni alejo ati lati tọju wọn. Wọn ti kó ara wọn ni ijanu, wọn si ti ṣe olootọ ninu ohun gbogbo. Nipa bayi, wọn ti pese ara wọn silẹ fun Ọlọrun lati lo. Ni igba ti o ṣe, Ọlọrun ti fun wọn ni anfaani lati di olukọ Ile-Ẹkọ Ọjọ-Isinmi, oṣiṣẹ ati oniwaasu.

Loni awọn ọmọde ati awọn ọdọ kan wa ti wọn ni ilepa ati itara mimọ lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun. Ti Oluwa ba fa bibọ Rè̩ sẹhin, wọn o di iriju fun Ijọ. Bawo ni inu Ọlọrun yoo ti dun to nigba ti awọn ọmọde ba n pese aye wọn silẹ fun iṣẹ-isin Rè̩ ti wọn si n foju sọna si akoko ti Oun yoo yàn wọn lati dí aye kan ninu iṣẹ Rè̩!

Ọwọ

“Awọn alàgba ti o ṣe akoso daradara ni ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe lālā ni ọrọ ati ni kikọni” (I Timoteu 5:17). O yẹ ki a fi ọwọ fun awọn ti Ọlọrun ti fi si ipo ti O si ti gbe iṣẹ le lọwọ. O ha yẹ ki a ṣe din si eyi? A n yẹ wọn si a si n bu “ọlá fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn” (I Tẹssalonika 5:13). A n fi ọwọ ti a ni fun wọn han nipa titẹriba fun wọn -- gbigbọran si wọn lẹnu (I Peteru 5:5; Heberu 13:17). Bi o ti wu ki a ti mọ wọn to, ohun ti o tọna ti o si yẹ ni ki a maa pe awọn oniwaasu ati oṣiṣẹ wa ni “Arakunrin” ati “Arabinrin” dipo ki a kan maa la orukọ mọ wọn lori ṣaa. O yẹ ki awọn ọmọde ati awọn ọdọ maa bu iru ọlá bẹẹ fun awọn ti a ti tipa ọwọ Ọlọrun yàn si ipo pataki.

Itọju

A ko fun awọn Ọmọ Israẹli ti wọn jẹ ẹya Lefi ni ipin kankan ni ilẹ Kenaani. Oluwa ni ini wọn (Deuteronomi 10:9). Ninu Tẹmpili ni wọn ti n ṣiṣẹ isin, ninu ohun ti a mu wa sibẹ ni wọn si ti n jẹ, gẹgẹ bi Oluwa ti ṣeleri. “Gẹgẹ bẹli Oluwa si ṣe ilana pe, awọn ti nwāsu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere” (I Kọrinti 9:13, 14). Awọn Apọsteli, alagba ati diakoni ko gba owo oṣu. Nigba ti Jesu ran awọn Apọsteli jade lati waasu ati lati wo gbogbo arun san, O wi pe, “Onjẹ oniṣẹ yẹ fun u” (Matteu 10:10). A pese fun ohun ti wọn o jẹ, ibugbe, aṣọ wiwọ, inawo fun igbokegbodo ati iru nkan bẹẹ ti wọn ko le ṣe alaini, ṣugbọn wọn ko gba owo oṣu. Bẹẹ naa ni o ri lọdọ wa: Ihinrere ni o n bojuto awọn ti a n beere gbogbo akoko wọn ti wọn ko si ni ọna miran lati fi gbọ bukata ara wọn. Awọn ti ko lo gbogbo akoko wọn a maa fi ọwọ ara wọn ṣiṣẹ fun ounjẹ oojọ wọn. Fun gbogbo awọn wọnyi ere ti wọn ni ayọ ti o wà ninu iṣẹ naa.

Fun gbogbo wa Ọlọrun ti fi aṣẹ yi lelẹ: “Ẹ mā gbọ ti awọn ti n ṣe olori nyin, ki ẹ si mā tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin” (Heberu 13:17).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lẹhin ti Jesu lọ si Ọrun, awọn wo ni a fi iṣẹ itankalẹ Ihinrere le lọwọ?
  2. Kin ni ṣe ti a fi yan diakoni meje akọkọ?
  3. Kin ni iṣẹ wọn?
  4. Bawo ni a ti ṣe yan wọn?
  5. Iru eniyan wo ni o yẹ lati fi ṣe diakoni?
  6. Awọn iriju ijọ wo ni a tun yàn lẹhin naa?
  7. Iru eniyan wo ni o le jẹ iriju ninu ijọ wa loni?
  8. Kin ni ọmọde le ṣe lati pese aye rè̩ silẹ lati jẹ oṣiṣẹ fun Ọlọrun?
  9. Ọna wo ni a fi le bọwọ fun awọn ti Ọlọrun ti yan si ipo akoso?
  10. Bawo ni a ti ṣe n yan awọn iriju ninu ijọ loni?
2