Iṣe Awọn Apọsteli 6:8-15; 7:1-60

Lesson 289 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Mo ṣiro rè̩ pe, ìya igba isisiyi ko yẹ lati fi ṣe akawe ogo ti a o fihàn ninu wa” (Romu 8:18).
Notes

Ajẹriku Kinni

Ọdọmọkunrin kan ti a n pè ni Stefanu ni ajẹriku kinni fun Ẹsin Kristi. A ti yan Stefanu lati jẹ diakoni ninu Ijọ, o si fi gbogbo ọkan rè̩ di iṣẹ naa mu girigiri. Iranwọ ti o n ṣe fun awọn alaini ati fifi ounjẹ fun awọn ti ebi n pa ko mu ki o ṣe alai ni akoko fun adura.

Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ ki o ran awọn ti o jẹ alai ni ounjẹ ati aṣọ ati awọn ohun elo ti ara lọwọ. Ibukun ti o tun pọ ju eyi paapaa lọ ni yoo wà lori ẹbun wa bi a ba gbadura pe ki Ọlọrun ran ibukun Rè̩ si ori ẹbun naa. Ju gbogbo eyi lọ iṣẹ rere ti a ṣe ko le nikan mu igbala wa fun wa. A ni lati gbadura pupọ lati mu ki Ẹmi Ọlọrun wà lori aye wa ki awa tikara wa ba le wà ni imurasilẹ lati pade Jesu, ki a si jẹ iranlọwọ fun awọn ẹlomiran.

Stefanu kun fun Ẹmi Ọlọrun; nipasẹ igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun, o ṣe iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu laarin awọn eniyan naa. S̩ugbọn awọn ẹlẹsìn ti o wà ni akoko Stefanu ko mọ riri iṣẹ rere rè̩, nitori pe ni orukọ Jesu ni a ṣe awọn iṣẹ naa. Wọn huwa si Stefanu gẹgẹ bi wọn ti ṣe si Jesu. Awọn Farisi n jowu rè̩, wọn si ro pe ẹkọ Jesu lodi si Ofin Mose. Wọn ti fara balẹ kọ ẹkọ ninu Ofin Mose, wọn si n ṣogo ninu aayan pupọ ti wọn n ṣe lati pa ọpọlọpọ awọn ilana ati ofin mọ. Ọpọlọpọ iran awọn alufa wọn ati awọn akọwe wọn ko ha ti ṣe itumọ Ofun fun wọn lọna ti o tẹ ifẹ okàn wọn lọrun? Kin ni ṣe ti wọn ni lati feti si nkan miran ti o yatọ, ti ẹni kan ti wọn kò mọ n sọ fun wọn?

Igbagbọ ninu Oluwa

S̩ugbọn Stefanu ti mọ nipa Jesu. A ti gba Stefanu la kuro ninu ẹṣẹ rè̩, o si ni igbagbọ pipe ninu Jesu Kristi Oluwa gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun. O da a loju pe Jesu ni Ọmọ Ọlọrun to bẹẹ ti o mura tan lati ku fun igbagbọ rè̩. Igbagbọ rè̩ mu ki o ni agbara lati duro tiiri si awọn ti o n fi Jesu ṣe ẹlẹya.

Awọn ti kò fẹ lati gbọ iwaasu Stefanu pe e wa siwaju igbimọ, tabi ile-ẹjọ, wọn si gba awọn ẹlẹri eke lati tako o. Awọn ẹlẹri-eke naa wi pe o sọ blasfeme, ṣugbọn kiki ohun ti Jesu sọ ni o sọ. Kò bikita nipa awọn irọ ti wọn pa mọ ọn. Igbagbọ rè̩ wà ninu Jesu, ogo Oluwa si sọkalẹ o si kun un to bẹẹ ti awọn eniyan fi wi pe oju rè̩ dabi ti angẹli.

Nikẹhin, olori alufa, ẹni ti i ṣe onidajọ beere lọwọ Stefanu bi awọn è̩sùn ti a fi kan Stefanu ba jẹ otitọ. Otitọ ni pe o sọrọ odi si Mose, ati Ọlọrun? O ha ti sọrọ buburu nipa Tẹmpili mimọ wọn? Kin ni ṣe ti Stefanu sọrọ nipa wiwo Tẹmpili wọn palẹ?

Idahun Stefanu

Stefanu bẹrẹ idahun rè̩ bayi, “Alàgba, ara, ati baba.” Boya pupọ ninu awọn igbimọ naa dagba ju u lọ, o si bu ọlá fun wọn nitori ọjọ ori wọn ati pẹlu nitori ipo wọn. Stefanu bẹrẹ si i fi han pe oun kò sọ ọrọ odi. Gẹgẹ bi awọn akọwe ati awọn Farisi ti bu ọlá fun Abrahamu, bẹẹ gẹgẹ ni oun naa bu ọlá ti o pọ lọpọlọpọ fun un. Awọn Ju pe Abrahamu ni baba igbagbọ wọn, ṣugbọn wọn gboju fo otitọ yi pe nipa igbagbọ (ki i ṣe nipa iṣẹ rè̩) ni a fi gba Abrahamu là. “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ, a si ka a si fun u li ododo.”

Jesu ti sọ ṣiwaju eyi pe, “Abrahamu baba nyin yọ lati ri ọjọ mi: o si ri i o si yọ” (Johannu 8:56). Abrahamu ti gbe igbesi-aye rè̩ nipa igbagbọ -- igbagbọ ninu Jesu Ẹni ti a kò i ti bi si aye – o si ti di olododo nipasẹ igbagbọ yi. S̩ugbọn awọn ọmọ Baba Abrahamu kò gba Jesu gbọ nigba ti wọn tilẹ ri I ni ojukoju laarin wọn; wọn si kan An mọ agbelebu ninu ibinu nla.

Abrahamu ti jẹ olododo ni ọpọlọpọ ọdun ṣaaju akoko ti a fun ni ni Ofin. Imọ nipa ohun ti o tọ ati eyi ti ko tọ ti wà lati atetekọṣe, Abrahamu si ti ni imọ yi ninu ọkàn rè̩. O gbe igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi otitọ Ihinrere: “Olododo ni yio ye nipa igbagbọ.”

Ọlọrun ti sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn ọmọ Abrahamu fun un. Ni akọkọ, O ba Abrahamu da majẹmu pe lati inu iru-ọmọ rè̩ ni a o ti bukun fun gbogbo idile aye. Eyi yi n tọka si igba ti Jesu yoo mu igbala wá fun gbogbo eniyan. Njẹ bi awọn Ju ba ti farabalẹ kọ nipa igbesi-aye Abrahamu, bawo ni wọn ti ṣe gboju fo otitọ yi? Stefanu ti ri otitọ yi nigba ti o ka Iwe Mimọ; nigba ti o si ri Jesu o gbagbọ pe Oun ni imuṣẹ asọtẹlẹ ti a tipasẹ Abrahamu sọ.

Ìtàn Awọn Ju

Stefanu tẹ siwaju lati sọ itan awọn Ju ni kikun, titi wa de igba kikọ Tẹmpili Sọlomọni. O sọ gbogbo itan awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn wa ni igbekun ni Egipti, o si tẹnumọ ọn pe Ọlọrun rán Mose lati jẹ olugbala wọn. A n fi è̩sun kan Stefanu pe o ṣe aibọwọ fun Ofin Mose, lọna bayi o ṣe aibọwọ fun Mose tikara rè̩, ṣugbọn o fi han pe oun ni imọ nipa Mose ju awọn paapaa lọ.

Stefanu tọka si i pe lati ibẹrẹ igbesi-aye Mose ni Ọlọrun ti pe Mose lati jẹ olugbala Israẹli, ṣugbọn eyi ko ye awọn Ọmọ Israẹli. Mose ti ni suuru di igba ti o to ogoji ọdun ki o to gbiyanju lati ran awọn eniyan rè̩ lọwọ, laarin akoko yi a si ti kọ ọ ni è̩kọ ti o dara ju lọ ti a le kọ ẹnikẹni ni akoko naa ni agbala ọba Egipti. Nigba ti awọn eniyan rè̩ kọ ọ silẹ, o salọ si ilẹ miran nibi ti o gbe fun ogoji ọdun miran, ni akoko yi awọn Ọmọ Israẹli ti wọn kọ iranlọwọ rè̩ silẹ n jiya gẹgẹ bi ẹru ni Egipti. Ọlọrun ti wi pe Mose ni yoo jẹ aṣaaju fun Israẹli, ipe naa kò si yipada.

Titobi Mose

Bi Stefanu ti n sọ itan Israẹli, o tẹnumọ titobi Mose. Mose ni Ọlọrun fi Ofin le lọwọ. Ọlọrun pe Mose lati jẹ aṣoju Rè̩ fun awọn eniyan naa. Mose si ti ṣeleri kan fun awọn Ọmọ Israẹli pe: “Woli kan li Oluwa Ọlọrun nyin yio gbe dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ki ẹ gbọ tirè̩.”

Gbogbo nkan wọnyi ni Stefanu sọ fun awọn alatako rè̩. Jesu ni woli naa ti Mose ṣeleri, Stefanu si gba A gbọ. S̩ugbọn awọn Farisi wọnyi ti o kún fun ododo ti ara wọn ko gba A gbọ, wọn si dojuja kọ Stefanu pe o n bu Mose ni ọlá kù nipa wiwaasu Jesu.

Tẹmpili

Lẹhin ti wọn ti gba ilẹ Kenaani, Sọlomọni ti kọ Tẹmpili nla kan ti o ni ẹwa pupọ ni Jerusalẹmu fun isin Ọlọrun. Eyi ni o si wa di ibi ipejọpọ fun isin otitọ. S̩ugbọn ni ọjọ ti a yà Tẹmpili naa si mimọ, Sọlomọni gbadura pe: “Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ!” (II Kronika 6:18). Ọlọrun ti Sọlomọni gbadura si tobi to bẹẹ gẹẹ ti awọn ọrun kò le gba A.

Ọlọrun si ti tipasẹ Woli Isaiah sọrọ pe: “Ọrun ni ité̩ mi, aiye si ni apoti itisè̩ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ fun mi gbe wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà? Nitori gbogbo nkan wọnni li ọwọ mi sa ti ṣe” (Isaiah 66:1, 2). Ọlọrun tobi ju Tẹmpili lọ. Jesu ba Ọlọrun dọgba ninu dida aye, bi agbara Baba si ti tó bẹẹ gẹgẹ ni ti Rè̩ to pẹlu. Jesu ko ha ju Tẹmpili lọ? Bawo ni awọn Farisi ti ṣe ni lati maa sọ pe Stefanu n sọ blasfeme si Ọlọrun nipa wiwaasu ọrọ Jesu?

Awọn Eniyan Ọlọrùn-lile

Nigba ti Stefanu sọ itan rè̩ de ibi yi, ọkan rè̩ gbina nitori agabagebe awọn alatakò rè̩ to bẹẹ ti kò le pa a mọra mọ. O ri i pe alaye Ihinrere ti oun n ṣe kò tilẹ mu iyipada kankan wa sinu ọkàn wọn; o si wi fun wọn pe: “Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on eti, nigbagbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmi Mimọ.” Ẹmi Ọlọrun ti gbiyanju lati ba wọn sọ asọye lati fi otitọ Ihinrere hàn wọn, lati fi han wọn pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe. S̩ugbọn gẹgẹbi awọn baba wọn ti ṣe inunibini si awọn woli, bẹẹ naa ni wọn n ṣe. Wọn si mu ago ẹṣẹ wọn kun nipa kikan Jesu mọ agbelebu, Ẹni Mimọ nì.

Wo o bi ọrọ wọnni ti ru ibinu awọn Ju ti o kun fun ododo ti ara wọn wọnyi soke to! Ohun gbogbo ti Stefanu sọ ni wọn jẹbi rè̩, ẹbi wọn si tubọ mu ki gbigbona ibinu wọn tubọ ru soke ju bẹẹ lọ. Wọn bẹrẹ si i gbe okuta lati sọ lu iranṣẹ Ọlọrun mimọ ati alailẹṣẹ yi pẹlu gbogbo agbara wọn. S̩ugbọn Stefanu kò tilẹ sunrakì ninu irora naa. Ọkunrin yi kún fun Ẹmi Mimọ, bi o si ti gboju soke o ri iran Oluwa rè̩, Ẹni iyanu nì. Olugbala naa ti o ti gbagbọ ti o si waasu nipa Rè̩ ni Ọmọ Ọlọrun ni tootọ, O si n duro lati fi ayọ gba Stefanu si ilẹ Ologo naa. Stefanu sọ fun awọn eniyan naa pe: “Wo o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ ọtún Ọlọrun.” O n duro! Nigba ti Jesu lọ si Ọrun o joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun (Heberu 10:12), lati maa bẹbẹ fun wa. S̩ugbọn nigba ti Stefanu n fẹ fi aye yi silẹ gẹgẹ bi ajẹriku, Jesu dide duro lati bu ọlá fun un fun iduro gangan rè̩ ninu igbagbọ titi de opin.

Ibinu awọn Ju ru to bẹẹ ti wọn fi kigbe ni ohun rara lati bo ọrọ ti o n sọ mọlẹ, wọn si di eti wọn ki wọn ma ba gbọ ohun ti wọn rò pe o jẹ ọrọ blafeme. Wọn si wọ Stefanu sẹhin odi ilu, wọn bẹrẹ si i sọ okuta nla nla lu u kikankikan titi o fi ku.

Ère Stefanu

Stefanu ko bẹbẹ fun aanu tabi ki o gbiyanju lati sa lọ mọ awọn ọta rè̩ lọwọ. O kan gbe oju rè̩ soke si Ọlọrun o si gbadura bayi: “Jesu Oluwa, gba ẹmi mi.” Awọn ọrọ ikẹhin rè̩ jẹ ọrọ idariji: “Oluwa, má ka è̩ṣẹ yi si wọn li ọrun,” o si sun lati ji si Ọrun. Iṣisẹ kan pere ni si Itẹ Ọlọrun, nibi ti Jesu gbe n duro de e lati fi ayọ gbà a. Ohun ti Stefanu fi lelẹ kò pọ ju bi a ba fi we ère ti o gba. “Wahala ọna na ki yio jamọ nkankan nigbati mo ba de opin ọna na.”

Ijiya ki i daya fo igbagbọ awọn Onigbagbọ tootọ. Lẹhin eyi, nigba ti a n da awọn Onigbagbọ loro labẹ akoso awọn Kesari alailaanu, igbagbọ wọn ati igboya wọn mu ki ọpọlọpọ ninu awọn ẹṣọ ara Romu ọlọkan lile wọnni fi ọkan wọn fun Jesu. Wọn wi bayi pe bi awọn Onigbagbọ ti a n da loro bayi ba le maa kọrin nipa Ọrun ati Olugbala wọn nigba ti a n ran wọn lọ si oju iku tabi si oju igbà (ijà) nibi ti awọn kinniun yoo gbe jẹ wọn, o daju pe Ọlọrun kan wa ti o n ṣe alatilẹhin fun wọn; o daju pe otitọ ni pe Ọrun wà ati pe wọn n lọ si ibẹ. Ifẹ Jesu sọ ọkàn okuta awọn ọmọ-ogun Romu wọnni di yiyọ, awọn paapaa si fi ẹmi wọn lelẹ nitori Kristi.

Ki Ọlọrun ma ṣai fi ẹmi naa ti yoo mu wa jẹ olootọ si Oluwa wa sinu ọkan wa bi o tilẹ gbà pe ki a fi ẹmi wa lelẹ fun igbagbọ wa! Ọpọlọpọ eniyan ni o ti fi ifẹ wọn si Jesu han nipa fifi ẹmi wọn lelẹ ni igba aye ọlaju yi dipo pe ki wọn sẹ Ẹ. Dajudaju ere wọn yoo pọ ni Ọrun. Ifẹ Ọlọrun pọ ninu ọkàn wọn to bẹẹ ti wọn fi le dariji awọn ti o n ṣe inunibini si wọn gẹgẹ bi Stefanu ti ṣe, ati gẹgẹ bi Oluwa wa tikara Rè̩ ti ṣe: “Baba, dariji wọn; nitoriti wọn kò mọ ohun ti nwọn nṣe” (Luku 23:34).

Saulu Lohun si i

Ọdọmọkunrin kan wà laarin awọn ọkunrin ti o sọ Stefanu ni okuta, ẹni ti o ti lo akoko pupọ lati kọ Ofin ṣugbọn ti o ti ṣe inunibini si Ijọ Kristi nitori o rò pe awọn ti o n tẹle Jesu n ṣe aibọwọ fun Ofin. Oun ni o gba aṣọ awọn ti o pa Stefanu lọwọ, o si lohun si pe Stefanu ni lati kú. Saulu ni orukọ ọdọmọkunrin yi, ẹni ti a wá mọ lẹhin eyi gẹgẹ bi Paulu Apọsteli nla. Titi di igba yi, Saulu ko i ti pade Jesu, ṣugbọn igba naa n bọ ti oun paapaa yoo di Onigbagbọ, yoo jiyà, yoo si kú fun Jesu kan naa, ẹni ti Stefanu fi ẹmi rè̩ lelẹ fun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Tani Stefanu i ṣe?
  2. Kin ni ṣe ti awọn Farisi kò fẹ gbọ iwaasu Stefanu?
  3. Bawo ni Abrahamu ti ṣe ri igbala?
  4. Bawo ni a ti ṣe mọ pe Abrahamu gba Jesu gbọ?
  5. Kin ni Stefanu mọ nipa Mose?
  6. Kin ni ohun ti Mose sọ nipa Jesu?
  7. Kin ni Stefanu pe awọn akọwe ati awọn Farisi?
  8. Kin ni awọn Ju ṣe si Stefanu?
  9. Kin ni Stefanu ri ki o to ku?
  10. Kin ni awọn ọrọ ikẹhin Stefanu?
2