Iṣe Awọn Apọsteli 8:1-25

Lesson 290 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39).
Notes

Ohun ti a Mọ nipa Paulu

Wo iru ohun buburu ti a kọ mọ nipa Paulu Apọsteli! Ẹni ti n bọ wa di Apọsteli nla fun awọn Keferi bẹrẹ nipa ṣiṣe inunibini si Ijọ. O jẹ ayọ ọkàn rè̩ lati jẹ ẹlẹri iku Stefanu, ajẹriku kinni ninu awọn Onigbagbọ. Gẹgẹ bi olori alufa ti rò, oun naa rò ninu ọkàn rè̩ pe blasfeme ni awọn Onigbagbọ yi n sọ si Ọlọrun, o si fi itara lakaka lati jẹ olugbeja Ofin.

Yatọ si pipa ti a pa Stefanu, a mu pupọ awọn miran ninu awọn Onigbagbọ kuro ni ile wọn, a si sọ wọn sinu tubu; a tilẹ pa ninu wọn. Rò bi o ti buru to pe ki agbo awọn Onigbagbọ kan joko ninu ile wọn ki wọn maa kọrin tabi ki wọn maa ka Bibeli, lojiji ki a si mu wọn ki a sọ wọn sinu tubu nitori eyi. Ni ilẹ wa nibi ti a gbe ni ominira nipa ẹsìn, o ṣoro fun wa lati woye iru iwa bayi; ṣugbọn Onigbagbọ pupọ ni iya ti jẹ lọna bayi nitori igbagbọ wọn ninu Ọlọrun.

Paulu tikala rè̩ sọ bayi nipa iṣe rè̩ si awọn Onigbagbọ: “Nigba pipọ ni mo ṣé̩ wọn niṣẹ ninu gbogbo sinagọgu, mo ndù u lati mu wọn sọ blasfeme; nigbati mo ṣoro si wọn gidigidi, mo ṣe inunibini si wọn de ajeji ilu” (Iṣe Awọn Apọsteli 26:11). O tilẹ tẹle wọn nigba ti wọn gbiyanju lati sa asala nipa fifi ilu silẹ. S̩ugbọn o sọ bayi nigba ti o ṣe, “Mo ri ānu gbà, nitori mo ṣe e li aimọ ninu aigbagbọ” (I Timoteu 1:13).

Wiwaasu Nibi Gbogbo

Pẹlu Paulu, awọn alufa sa ipa wọn pupọ lati pa Ijọ Onigbagbọ run ni Jerusalẹmu, to bẹẹ ti ogunlọgọ awọn Onigbagbọ fi kuro nibẹ. S̩ugbọn nibikibi ti wọn ba de, wọn waasu nipa Jesu. Inunibini naa ko pa wọn lẹnu mọ. Kaka ki a pa Ihinrere rẹ, n ṣe ni o gbilẹ de ilẹ pupọ.

Jakejado Judea ati Samaria ni awọn ọmọlẹhin Jesu waasu pe Jesu ni Ọmọ Ọlọrun, pe O ti ku O si ti tun jinde. Lai si aniani wọn ko ni ṣai sọ nipa iran Kristi bi O ti wa ninu ogo, eyi ti Stefanu ri. Eyi tun jẹ ẹri kan si i pe Jesu wà laaye; ati pe Oun ki i tun ṣe Onirẹlẹ ara Galili mọ, Ọkunrin ara Nasarẹti, bi ko ṣe Kristi ti a ti ṣe logo. Wo iru Olugbala ti wọn n waasu Rè̩! Bi o tilẹ jẹ pe o le mu wọn padanu ẹmi wọn, wọn ko dẹkun lati maa sọ fun awọn eniyan kaakiri wi pe Jesu ni Messia ti wọṅ ti n reti pẹ, Oludande Israẹli.

Isọji Filippi ni Samaria

Ẹlomiran ti a yàn ṣe diakoni pẹlu Stefanu ni ọkunrin kan ti o n jẹ Filippi. Sisọ ti a sọ Stefanu ni okuta pa kò fo Filippi laya, bẹẹ ni kò si da iwaasu rè̩ duro. O tẹwọgba ipenija naa, o si n waasu lọ ṣaa; Ọlọrun si tipa rè̩ ṣiṣẹ iyanu nlá nlà. Gẹgẹ bi abajade iṣẹ iranṣẹ Filippi, a ṣe dida ara awọn alaisan, awọn ẹmi aimọ si fi awọn ti wọn n pọn loju silẹ. Jesu ti wi pe iru ami wọnyi ni yoo maa tẹle iwaasu Ihinrere, Filippi si fi otitọ ọrọ yi hàn. Ẹmi Ọlọrun wà lara rè̩, awọn eniyan si tẹti silẹ. Inu wọn dun lati fi ọkàn gba Ihinrere ayọ ti o mu wa. “Ayọ pipọ si wa ni ilu na.”

Olukuluku Onigbagbọ tootọ ni o mọ alaafia ati ayọ ti o jinlẹ ninu ọkan rè̩. Ko si ọna miran ti a le fi ni ayọ ati alaafia yi ju nipa riri idariji è̩ṣẹ wa gbà. Ọlọrun ti Onigbagbọ n sin jẹ Baba Onifẹ ti n beere igbọran ati ọwọ lowọ awọn ọmọ Rè̩, ṣugbọn ti O tun ntú ifẹ ati ibukun da sori wọn. Inu wa dun lati gbọ ti Rè̩ nitori pe a fẹran Rè̩. Jesu pe awọn ọmọde paapaa sọdọ Rè̩ O si wi pe, “Iru wọn ni ijọba ọrun.” Bawo ni inu wa ti dùn to pe Ọlọrun wa fẹran wa ati pe nigba gbogbo ni O maa n fẹ ṣe ohun rere fun wa!

Awọn ọlọrun awọn Keferi kò ri bẹẹ. Ohun ti awọn woli eke n sọ fun awọn eniyan ni pe wọn ni lati ṣe irubọ ìka ati ailaanu ki wọn ba le tu ibinu awọn oriṣa wọn ninu; nigba miran wọn tilẹ n sọ fun awọn eniyan lati fi ọmọ wọn rubọ. Ohun è̩ru saba maa n wà ninu ijọsin wọn nigba ti wọn ba n gbiyanju lati ṣe atunṣe fun ẹṣẹ wọn ati lati fa inudidun wa sinu ọkàn wọn. S̩ugbọn kiki ibanujẹ ati ikoro ọkan ni wọn maa n ni. Inu wa dùn pe awa mọ ọna kan ti o san jù, a si le sọ itan ti ifẹ Jesu ti o maa n fun awọn ọmọ Rè̩ ni ayọ.

Inu awọn ti o tẹti si iwaasu Filippi dùn lati gbọ ọrọ rè̩ to bẹẹ ti ọpọlọpọ fi gbà ohun ti o sọ gbọ. O sọ fun wọn nipa alaafia ti ọkàn wọn ti n poungbẹ rè̩.

Iṣẹ Iyanu Satani

Ọkunrin kan wà ti o n jẹ Simoni, ẹni ti o ti n fi agbara Satani ṣiṣẹ iyanu laarin awọn ara Samaria. Awọn eniyan ti n fi i pe oriṣa nitori agbara ti o n lo yi. S̩ugbọn wọn kò ri ayọ kankan gba nipa titẹle e. O ti fi ẹtan eṣu bo wọn loju. Ki i ṣe gbogbo ẹni ti n ṣe iṣẹ iyanu ni o jẹ eniyan Ọlọrun.

Ninu Bibeli, a sọ nipa awọn àjẹ, alafọṣẹ ati alalupayida, ṣugbọn a kilọ fun awọn ọmọ Ọlọrun ki wọn ma ba wọn lo rara. Lati ọdọ Satani ni agbara wọn ti wa, Onigbagbọ ko gbọdọ tẹti si ti wọn rara. Ọlọrun pe wọn ni ohun irira. O sọ siwaju bayi pe: “Máṣe yipada tọ awọn ti o ní imọ afọṣẹ, bẹni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jé̩: Emi li OLUWA ỌLỌRUN nyin” (Lefitiku 19:31).

Nigba ti Simoni oṣo ri bi inu awọn eniyan ti dùn to, awọn ti o gba Jesu gbọ ti a si n baptisi gẹgẹ bi Jesu ti kọ ni, oun naa gbagbọ pẹlu; bẹẹ ni o sa ṣe jẹwọ, o si ba awọn ti wọn gbọ ọrọ Filippi joko papọ lati maa gbadun anfaani igbala. Ohun ti Simoni ri ti Filippi ṣe ni orukọ Jesu tobi ju ohunkohun ti oun le ṣe latẹhinwa.

Peteru ati Johannu ni Samaria

Nigba ti awọn Apọsteli ni Jerusalẹmu gbọ nipa isọji nlá nlà ti o wà ni Samaria, wọn ran Peteru ati Johannu lati lọ ran wọn lọwọ. Bi o tilẹ jẹ pe ogunlọgọ eniyan ni wọn ti ri igbala ati isọdimimọ nipa iwaasu Filippi, ti a si ṣe iribọmi fun wọn, kò si ẹni kan ninu wọn ti o ti i ri ifiwọni Agbara Ẹmi Mimọ. Nigba ti Peteru ati Johannu de, wọn bẹrẹ si gbadura pe ki a le fi Agbara Ẹmi Mimọ wọ gbogbo wọn.

Wo iru ipade adura nla ti wọn ni! Awọn eniyan mimọ titun wọnyi fẹ ki a fi agbara Ọlọrun kún wọn gẹgẹ bi o ti ri fun awọn ọmọ-ẹhin ni Ọjọ Pẹntikọsti. N jẹ o le ṣe e ṣe fun awọn naa lati ri agbara yi gba?

Si Ara Eniyan Gbogbo

Woli Joẹli sọ pe: “Yio si ṣe, nikẹhin emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo” (Joẹli 2:28). Peteru pẹlu ti wi pe “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39).

Nisinsinyi, bi awọn ara Samaria wọnyi yoo ba gbagbọ ki wọn si fi ara wọn fun ifẹ Ọlọrun patapata, awọn naa le ri ifiwọni Agbara Ẹmi Mimọ gba. O ha jẹ wọn lọkan to bẹẹ? Dajudaju. Nigba ti Peteru ati Johannu si ba wọn gbadura ti wọn si gbe ọwọ le wọn, wọn gba Agbara Ẹmi Mimọ. Bawo ni ayọ eniyan ti n pọ to nigba ti o ba di Tẹmpili Ẹmi Mimọ!

Ki i S̩e Pẹlu Fadaka

Simoni ri bi Ẹmi Ọlọrun ti ba le awọn eniyan mimọ wọnyi ni idahun si adura Peteru ati Johannu, oun naa si fẹ ni agbara ti wọn ni. O fẹ lati fi owo ra a. Ha, oju rè̩ ti fọ to lati rò pe oun le fi owo ra agbara Ọlọrun! Ti o ba ṣe pe owo ni wọn fi n ra igbala o daju pe awọn Onigbagbọ i ba pọ ju bayi lọ ninu aye loni. S̩ugbọn kin ni owo jamọ? Kò le duro pẹ. Wura ati fadaka paapaa yoo dipẹta.

Ọlọrun n fẹ ohun ti o wà titi lae ninu wa: ẹmi wa, ifẹ wa, ati ọkàn wa. Nigba ti a ba fi eyi fun Un, a o le jẹ ti Rè̩ fun ohunkohun ti O le fẹ fi wa ṣe. Ohun ti Simoni ṣe ko tẹ Peteru lọrun to bẹẹ ti o fi wi pe: “Ki owo rẹ ṣegbe pẹlu rẹ, nitoriti iwọ ro lati fi owo ra ẹbun Ọlọrun.”

Ọpọlọpọ awọn ẹlẹsìn ni wọn ti ba ijọ wọn jẹ nipa gbigbe owo niyi ju Ẹmi Ọlọrun lọ. Jesu wi pe, “Ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni.”

Ojuṣe wa ni lati waasu igbala fun awọn ti n ṣegbe, lati fun ni lọfẹ ninu eyi ti Ọlọrun ti fi fun ni. A si ni lati gbe igbesi aye wa loju awọn eniyan lọjọọjọ lọna ti wọn o fi mọ pe Onigbagbọ ni wa. Nigba ti a ba ni iwuwo ọkàn fun iṣẹ Oluwa, a o ná ninu owo wa lati ti i lẹhin -- tọkantọkan. Onigbagbọ a maa fẹran Ọlọrun pupọ to bẹẹ ti o fi n san idamẹwa ati ọrẹ rè̩ tayọtayọ.

Ireti ko pin fun Simoni. Ti o ba ronupiwada, Oluwa yoo bukun fun un. O le ri agbara ti o beere ti oun ba fun Oluwa ni ohun ti O n bere -- ọkàn rè̩ ati ifẹ rè̩. Titi di ọjọ oni, eniyan le ri agbara nì, ifiwọni agbara Ẹmi Mimọ gbà, ti o ba jẹ pe ni tootọ ni o ti ri isọdimimọ, ti o gba ileri Ọlọrun gbọ, ti o si fi gbogbo ọkàn rè̩ ṣafẹri iriri ologo yi.

Peteru ati Johannu pada si Jerusalẹmu lẹhin ipade naa, awọn iyoku ninu awọn ọmọ-ẹhin si n tẹ siwaju lati maa waasu ninu ileto pupọ ti i ṣe ti awọn ara Samaria.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Kin ni ohun kinni ti a gbọ nipa Paulu?
  2. Kin ni ṣe ti Ọlọrun ṣaanu fun Paulu?
  3. Tani ṣe isọji ni Samaria? Kin ni ṣe ti o fi wa ni Samaria?
  4. Iru ọkàn wo ni awọn eniyan fi gba a?
  5. Tani Simoni i ṣe? Kin ni o si n beere?
  6. Kin ni awọn ara Samaria ri gba nigba ti Peteru ati Johannu de?
  7. Bawo ni a ṣe le ri agbara gbà lati ọdọ Ọlọrun?
2