Orin Dafidi 46:1-11; 90:1-17

Lesson 291 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bẹni ki iwọ ki o kọ wa lati mā ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọn” (Orin Dafidi 90:12).
Notes

Oluwa wà ni Tosi fun Iranlọwọ

Awọn ẹni ti o kọ awọn Psalmu ti kọ lati gbẹkẹle Ọlọrun. Ẹnikẹni ti o wu ki o jẹ ninu wọn – i baa ṣe Dafidi, Mose, tabi ẹlomiran ti o kọ awọn orin naa silẹ -- o ti ri Ẹni kan ti o le tọ lọ nigba ti o ba wà ninu wahala, lati gba iranlọwọ.

Ninu awọn ọrọ ti o bẹrẹ Psalmu ikẹrindinlaadọta, alakọsilẹ naa wi pe: “Ọlọrun li abo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwo ni igba ipọnju.” O wà lẹgbẹ wa pẹkipẹki lati ran wa lọwọ nigbakuugba ti a ba ke pe E.

Ni ọjọ wọnni nigba ti awọn Ọmọ Israẹli n lọ ni irin ajo wọn si ilẹ Kenaani, Mose kọ iru ọrọ kan naa silẹ: “Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbe rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà” (Deuteronomi 33:27). Nigba miran ti a ba wà ninu wahala a maa n ro pe a ti gba ohun gbogbo lọ kuro lọdọ wa patapata; a le ro pe a n ṣubu lọ -- bi ẹni pe ipilẹ wa ti yè̩. S̩ugbọn bi igbẹkẹle wa ba wà ninu Ọlọrun ayeraye, apa Rè̩ wa nisalẹ wa, Oun ki yoo si jẹ ki a ṣubu.

Ọlọrun wi fun Isaiah pe, “Emi ti ṣe e, emi o si gbe, nitõtọ emi o rù, emi o si gbàla” (Isaiah 46:4). Nigba ti Paulu n kọwe si ọdọmọkunrin oniwaasu nì, Timoteu, o wi pe: “Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbà mi de inu ijọba rè̩ ọrun” (II Timoteu 4:18).

Ọlọrun Aabo Wa

Ibi aabo jẹ ibi ti ko sewu, abẹ ojiji. A ni awọn ibi aabo ti a ti ya sọtọ ninu igbo ti awọn ẹranko n gbe nibi ti wọn bọ lọwọ awọn ọdẹ ti o le ta wọn nibọn. Nibomiran paapaa a kò gba awọn eniyan laye lati pa iru awọn ẹranko bi agbọnrín tabi ẹyẹ ni agbegbe kan. O dabi ẹni pe awọn ẹranko wọnyi mọ nipa aabo yi, wọn a maa rin kaakiri ni ẹgbẹẹgbẹ nla lai bẹru laarin igbo wọnyi – paapaa jù lọ ni akoko ti awọn ọlọdẹ maa n dẹ igbo, ti awọn ẹranko wọnyi yoo wà ninu ewu bi wọn ba jade kuro nibi aabo yi.

Ọlọrun n fẹ ki eniyan mọ pe oun yoo ri aabo ninu Oluwa. Satani n ta ọfa rè̩ si awọn eniyan nibi gbogbo, ọpọlọpọ ninu awọn ti ọfa rè̩ n bà kò si mọ ibi ti wọn gbe le ri aabo. Bi wọn ba le wo inu Bibeli, wọn o rii pe Ọlọrun ni aabo wa titi lae, gẹgẹ bi Onipsalmu ti mọ. Awọn ti o sa tọ Ọlọrun fun iranlọwọ a maa ri alaafia fun ọkàn idaamu wọn.

A kò le fi oju ri awọn ọfa ti Satani n ta, ṣugbọn a le ri wahala ti wọn n mu wa. Nipa ọfa rè̩ ni ohun buburu gbogbo ti n wa: ibanujẹ, owú, igberaga, ati ikorira. Nigba ti ogun nla ba bẹ silẹ ti awọn ọmọ-ogun si doju-ija kọ ara wọn ti wọn si n ta ohun ija oloro si ara wọn lọpọlọpọ, a mọ pe Satani ni o bẹrẹ gbogbo eyi nipa tita awọn ọfa oloro rẹ kékèké.

O le ta ọfa rè̩ si wa ki o si mu ero buburu wá, ọrọ kòbakungbé, ati iwa imọti-ara-ẹni-nikan. Iru awọn nkan bẹẹ ki i ṣe ti Ọlọrun, a ko si fé̩ ki wọn wà ninu igbesi-aye wa. Bawo ni a ti ṣe le bọ? Nipa sisa tọ Aabo wa lọ, Ọlọrun ayeraye. È̩jẹ Jesu yoo wẹ ohun gbogbo ti Oun ko fẹ kuro, yoo dari è̩ṣẹ ji, yoo si mu awọn ero buburu kuro ninu gbogbo awọn ti o ba beere bẹẹ lọwọ Rè̩.

Kò si Ibẹru

Nigba ti a ba wà labẹ aabo yi ko si ohun kan ti a ni lati bẹru mọ. Jesu wà lọdọ wa timọtimọ, “lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju.” Onipsalmu sọ pe oun ki yoo tilẹ bẹru bi isẹlẹ nla ṣi oke ni idi lọ si inu okun. Ọpọlọpọ eniyan ni ẹru maa n ba bi isẹlẹ kekere kan ba ṣẹlẹ. Ronu bi ẹru wọn yoo ti pọ to bi awọn oke ba ṣidi lọ sinu okun! Nigba kan ti isè̩lè̩ kan sè̩ ni ileto kekere kan, ẹru ba awọn eniyan ti n gbe ibẹ lọpọlọpọ -- gbogbo wọn patapata afi obinrin arugbo kan ti o dabi ẹni pe igbadun ni o jẹ fun un. Gbogbo awọn eniyan naa ni o mọ ọn, ọkan ninu wọn si wa beere pe, “Mama ẹru kò ba ọ ni?” “Rara” ni idahun rè̩, “Mo yọ lati mọ pe mo ni Ọlọrun kan ti o lagbara lati mi aye.”

Bẹẹ gẹgẹ ni ẹru iji lori okun kò ba Onipsalmu. O ni igbẹkẹle pe Ọlọrun yoo paṣẹ idakẹrọrọ sori igbi omi naa. Oun kò si ninu ọkọ kekere pẹlu Jesu nigba ti awọn ọmọ-ẹhin wà lori Okun Galili nigba ti Jesu wi pe, “Dakẹ jẹ,” ti igbi naa si duro; ṣugbọn o mọ pe Ọlọrun lagbara lati ṣe e. O ti kọ lati mọ Ọlọrun ti o da okun ati ilẹ, o si mọ pe awọn igbi omi nla ati ifofo wọn n sọ ti agbara Ọlọrun Ẹni ti aṣẹ lori afẹfẹ ati awọn okun wà lọwọ Rè̩. A kà ninu ọkan ninu awọn Psalmu pe, “O paṣẹ o si mu iji fẹ ti o gbé ríru rè̩ soke. ... O sọ iji di idakẹ-rọrọ, bẹni riru omi rè̩ duro jẹ” (Orin Dafidi 107:25, 29).

Agbara Ọlọrun Fara Han

Ọjọ nla kan n bọ ti gbogbo aye yoo ri agbara Ọlọrun ti wọn o si jẹri si i. Nipa iró ohùn Rè̩ aye yoo yọ ninu ooru gbigbona. Ohùn kan naa ti o sọrọ ti aye si wà ni yoo pa aye naa run ni ọjọ idajọ.

S̩ugbọn ki a to pa aye run igba alaafia kan yoo wà lori aye yi. Ninu Psalmu yi a gbọ orin kan nipa Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, nigba ti Oluwa yoo mu ki gbogbo ogun-jija dẹkun. Ko si eniyan kan ti o le da ogun duro -- awọn igbimọ ọpọlọpọ orilẹ-ède ko tilẹ le ṣe e. S̩ugbọn Jesu le ṣe e. Nigba ti O ba si de lati fi opin si wọn ko ni si ija mọ. Yoo fi han lọjọ naa fun gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ati awọn alaigbagbọ pe gbogbo agbara wà lọwọ Oun, pe Oun ni o n ṣe akoso gbogbo aye.

Kò si ọba kan tabi awọn alaṣẹ ti yoo le duro niwaju Jesu -- Ọba wa nigba ti O ba de. Gbogbo agbara wọn ni a o ṣẹ patapata nigba ti wọn ba gbọ ohun nì lati Ọrun, ti Kristi si dé lati tẹ itẹ Rè̩ lori ilẹ aye yi. Awa gẹgẹ bi Onigbagbọ ti ni Oluwa awọn ọmọ-ogun pẹlu wa. “Ọlọrun Jakọbu li abo wa.”

Ireti Wa

Igba aye wa nihin kúru lọpọlọpọ nigba ti a ba fi wé ayeraye. Ohun pataki jù lọ fun wa loni yi ni pe ki a wà ni imurasilẹ fun aye ti n bọ. Awọn ti wọn mura silẹ lati ṣakoso pẹlu Kristi ki i gba ohunkohun laye lati pààlà laarin wọn ati isin wọn fun Ọba ayeraye.

Bi Peteru Apọsteli ti n foju sọna fun aye didan ti o dara ju yi, o kọ akọsilẹ yi: “S̩ugbọn gẹgẹ bi ileri rè̩, awa nreti awọn ọrun titun ati aiye titun, ninu eyiti ododo ngbe. Nitorina, olufẹ, bi ẹnyin ti nreti iru nkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le bá nyin li alafia, li ailabawọn, ati li ailabuku li oju rè̩” (II Peteru 3:13, 14). A n fẹ lati wà ninu aye titun nibi ti ohun gbogbo yoo lẹwa ti yoo si jẹ pipe, ṣugbọn a ni nkan lati ṣe ki a ba le yẹ fun ibẹ. È̩ṣẹ tabi iwa ikà kan kò le wọ ibẹ, nitori naa a ni lati wẹ wa mọ kuro ninu gbogbo è̩ṣẹ wa nihin, nipa È̩jẹ Jesu, ki a to le wà ni imurasilẹ lati wọ ibi ologo yi.

Ninu Psalmu Mose yi, o gbadura pe, “Bẹni ki iwọ ki o kọ wa lati mā ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọn.” Ẹ jẹ ki a ṣiro iye ọjọ aye wa nihin, ki a si lo ọjọ kọọkan lọna ti o lere. Awọn miran a maa huwa bi ẹni pe wọn o wa ni aye yi titi lae ati pe wọn kò si ni ohunkohun lati ṣe ni imurasilẹ lati fara han niwaju Ọlọrun. Bi a ba n gbe igbesi-aye wa lojoojumọ bi ẹni pe a gbagbọ pe Jesu yoo de ni opin ọjọ naa, a o maa ṣọra nipa iṣe wa ki a ma ba bi I ninu.

A kò mọ bi a o pari aye wa nipa janba ojiji tabi aisan, a o si lọ fara han niwaju Oluwa. Igba aye eniyan kò daju rara, ṣugbọn iku daju – afi bi Jesu ba kọ wá mu wa lọ. A fẹ gbe igbesi-aye wa lojoojumọ lọna ti è̩ru ki yoo fi ba wa lati fi aye yi silẹ.

Bi Ala ti a n Rọ

Bi a ba tilẹ pẹ ni aye to aadọrin tabi ọgọrin ọdun gẹgẹ bi Mose ti kọ silẹ, kin ni eyi nì bi a ba fi we ayeraye? Mose sọ pe iru igbesi-aye ti o gùn to bẹẹ paapaa dabi “àla ti a nrọ.” Ẹni kan le sọ itan kan fun ọ, iwọ a si gbagbe lẹsẹkẹsẹ. Bi o ba si jẹ pe itan ti o mu eniyan lọkan ṣinṣin ni, o le ranti rè̩ fun igba diẹ: ṣugbọn kò mu iyatọ kan wa sinu igbesi-aye rẹ.

Ronu nipa ẹgbẹẹgbẹrun ọna ẹgbẹrun ailonka awọn irawọ ti Ọlọrun n boju to ti O si mu ki wọn wà ni ipa wọn bi wọn ti n yipo ni oju ọrun. Ronu nipa ọkẹ aimoye eniyan ti o ti gbe lori ilẹ aye yi laarin ẹgbaa mẹta ọdun (6,000) ti o ti kọja. Kin ni eniyan kan jamọ laarin ọpọlọpọ aimoye eniyan bẹẹ, ati ọpọlọpọ ọdun aimoye bẹẹ? A fi bi a ba ṣe ohun kan ti o ṣe pataki lọpọlọpọ, kò si ẹni ti yoo mọ tabi ti yoo bikita ni nkan bi ọgọrun ọdun sii tabi ju bẹẹ lọ pe a gbe ni aye yi nigba kan ri. Fun akoko diẹ ni a si maa n ṣe iranti awọn ẹni nla lẹhin iku wọn.

Orilẹ-ède paapaa a maa dide a si tun maa wo lulẹ, wọn a si gbagbe wọn. Ọlọrun wi pe: “Kiyesi i, awọn orilẹ-ede dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si ka wọn bi ekuru kiun ninu iwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekuṣu bi ohun diẹ kiun” (Isaiah 40:15).

Ti Rè̩ Laelae

Bi a ti n wo ara wa ninu awọn akawe ti a n ṣe yi a rii pe ni tootọ a kò to nkan bẹẹ ni a ko si jamọ nkankan. Bi igbesi-aye wa nihin yoo ba rekọja bi ikuukuu ni ofurufu, tabi bi koriko ti o hu ni owurọ ṣugbọn ti a si ke lulẹ ni aṣalẹ; niwọn igba ti iṣẹ wa nipa ti ara yoo parun, kin ni ohun ti o ṣe pataki nigba naa? Kin ni ohun ti o wa titi? Kin ni idi rè̩ ti a fi wà nihin?

Jesu dá wa fun ara Rè̩, ki a ba le wà ki a si le gbadun ayeraye pẹlu Rè̩. “Iwọ li o da ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni wọn fi wà ti a si dá wọn” (Ifihan 4:11). Igbesi-aye wa nihin ni lati pese wa silẹ fun ogo aye ti n bọ, ti yoo wà titi laelae.

Igbesi-aye wa ni aye yi le dabi “ala ti a nrọ;” ṣugbọn Ọlọrun wa wà lae ati laelae. Ọlọrun ayeraye yi ni aabo wa, ibi isadi wa. Oun ni Ireti wa, Igbala wa, Itunu wa, Amọna wa. Ninu Rè̩ ni a ni ayọ nisinsinyi, a o si mọ ayọ nla ti iye ainipẹkun.

Mose gbadura pe, “Fi ānu rẹ tẹ wa li ọrun ni kutukutu.” O ṣe e ṣe ki itumọ eyi jẹ nigba ti a wà ni ọmọde. Aanu Ọlọrun maa n tọ wa wá ni igba ọdọ paapaa. Gẹgẹ bi ọmọde ati ọdọ ifẹ Rè̩ si wa maa n mu itẹlọrun wa fun wa bi a ti n fi ọkàn wa fun Un ni kutukutu ọjọ aye wa.

Mose tun gbadura pe ki a fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ. O n fẹ lati ṣe awọn nkan ti ko ni jona nigba ti Jesu ba de. Awọn nkan ti a ṣe fun Jesu nitori pe a fẹran Rè̩, a si fẹran awọn eniyan Rè̩ yoo duro titi laelae. Ko si iṣẹ ti o tobi jù jijere ọkàn kan fun Jesu. Iru iṣẹ yi dabi wura ati fadaka ti ina ko le bajẹ -- kiki pe yoo wẹ ẹ mọ yoo si mu ki o dara jù bẹẹ lọ. Daniẹli Woli kọ akọsilẹ pe awọn ti o n jere ọkàn fun Jesu yoo maa tan “bi irawọ lai ati lailai” (Daniẹli 12:3).

Ẹ jẹ ki gbogbo wa gẹgẹ bi ẹni kọọkan mura silẹ nigba ọdọ wa fun ogo aye ti o n bọ. Bayi ni a o ni itẹlọrun nihin, a o si tun gbadun ijọba ayeraye titi laelae pẹlu Oluwa wa ati Ọba wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Kin ni aabo?
  2. Tani aabo Onigbagbọ?
  3. Kin ni a gbà wa là kuro ninu rè̩ nigba ti a wà lai lewu ninu aabo naa?
  4. Nibo ni a ni lati lọ lati ri Jesu?
  5. Bawo ni igbesi-aye ti Ọlọrun ṣeleri fun wa ti gùn to?
  6. Bawo ni eyi ti gun to nigba ti a ba fi we ayeraye?
  7. Kin ni Mose sọ fun wa pe ki a maa ṣe lojoojumọ?
  8. Iṣẹ wo ni yoo duro titi ayeraye?
2