Lesson 292 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹ lọ, ẹ mā kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si mā baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19).Notes
Iṣẹ Iyanu S̩e
Nibi isọji ti o ṣẹlẹ ni Samaria awọn eniyan ti gbọ iwaasu ti o kun fun imisi agbara Ọlọrun, ati ẹri ti o muni lọkan. Wọn ti ṣe isin iribọmi pẹlu. Gbogbo nkan wọnyi n ran wa leti nipa ajọ-agọ ọdọọdun ti a maa n ṣe ni ilu Eko, ni Nigeria. Ni opin ajọ-agọ awọn alufa ati awọn oṣiṣẹ a maa pada si ile wọn lati maa ba iṣẹ wọn lọ nipa titan Ihinrere kalẹ.
Ọkan ninu awọn ti o ti waasu ni Samaria ni Filippi, ẹni ti a tun n pe ni Diakoni Ajihinrere. A ranti pe o pẹlu awọn ti a yàn lati maa bojuto ohun-ini ijọ. Nigba gbogbo ni Onigbagbọ tootọ maa n fẹ lati ṣe iranwọ, lọnakọna ti iṣẹ ba pè.
Awọn ti ọkàn wọn ṣe ọkan tẹti si Filippi bi o ti n waasu, iṣẹ ami pupọ si ṣẹlẹ nibi awọn iwassu rè̩: a tu awọn ti ẹmi aimọ n ba jà silẹ, awọn alaisan ati amukun si ri iwosan. Filippi ni awọn ọmọbinrin mẹrin ti awọn paapaa tun n waasu.
O lọ si Iju
Ni ọjọ kan angẹli Oluwa pade Filippi o si sọ fun un pe ki o maa lọ si iha guusu ni ọna iju Gasa. O ṣe e ṣe fun un lati sọ wi pe lilọ si ibẹ ko le yọri si ire kan bi ko ṣe fifi akoko ṣofo; tabi oun le beere pe, Kin ni ṣe ti n o fi lọ sibẹ? gẹgẹ bi awọn ọmọde ti maa n ṣe nigba pupọ. S̩ugbọn oun ko yẹ ọrọ angẹli naa wo, kaka bẹẹ o ṣe bi ti Abrahamu ni igba nì nigba ti o “jade lọ, lai mọ ibiti on nrè” (Heberu 11:8). Njẹ loni awa le tẹle Oluwa ni ayekaye tabi ni ipokipo? Njẹ a fẹ lati wi pe, “Oluwa, yi ipinnu mi pada ti o ba lodi si ifẹ ti Rẹ fun mi”?
Ọna ti Filippi rin jìn o si kun fun aarè̩ pupọ. Boya nipa igbagbọ ni o fi gbe iṣisẹ kọọkan. Bi o ti n tẹsiwaju ni ipinnu rè̩ n le sii. Bi o ti n lọ, bẹẹ ni iyanrin aṣalè̩ naa n gbona mọ ọn lẹsẹ, ṣugbọn n ṣe ni ipinnu ọkan rè̩ n jinlẹ sii lati lọ si ibi ti Oluwa ti ran an.
A ki i ri ero pupọ loju ọna ninu ijù; ṣugbọn, wo o na, kẹkẹ kan n bọ lọkankan. “Lọ ki o si da ara rẹ pọ mọ kẹkẹ yi” ni Ẹmi wi jẹjẹ fun Filippi. O sure tẹle kẹkẹ naa, o si ri iwẹfa kan ti o joko ninu kẹkẹ ti o si n ka Bibeli rè̩. O bi i leere pe, “Ohun ti iwọ nka ni, o yé ọ?” Idahun ti ọgbẹni ti o jẹ olori gbogbo iṣura ọbabinrin awọn ara Etiopia fi dahun ni pe, “Yio ha ṣe ye mi, bikoṣepe ẹnikan tọ mi si ọna?”
Iwẹfa jẹ ẹni kan ti a maa n gba fun iṣẹ ti o ṣe pataki, o si daju pe ọkunrin yi jẹ ẹni rere gidigidi. Ni Jerusalẹmu oun kò ni ṣai ti gbọ nipa ijiya ati iku Jesu ti o ti ṣẹlẹ niwọn ọdun kan ṣaaju akoko yi. Sibẹ nigba ti o n ka Iwe Isaiah, oye ko ye e to bẹẹ pe nipa Jesu ni oun n kà. Lati Etiopia lọhun ni o ti dide wa si Tẹmpili ni Jerusalẹmu lati sin Ọlọrun, ṣugbọn ko ri ohun ti ọkàn rè̩ n fẹ. Filippi Oniwaasu ya ẹnu rè̩ o si waasu Jesu, o n fi ye iwẹfa naa pe Jesu ni Ẹni naa ti Woli Isaiah sọ nipa Rè̩.
Ojuṣe Wa
Bi o tilẹ jẹ pe lọna jinjin ninu aginju ni Filippi dá nikan wà, Filippi ko lọra lati sọ gbolohun kan fun Jesu. Iwọ ha n sa gbogbo ipa rẹ lati tọ awọn ẹlẹṣẹ si ọna igbala? A ha ri ọmọkunrin tabi ọmọbinrin kan ni ile-iwe rẹ ti n poungbẹ lati ri Jesu ti o si n sọ bi iwẹfa nì pe, “Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ mi si ọna?” Ẹ jẹ ki a kiyesi igbesi-aye wa ki a si rii daju pe a kò fi anfaani kankan ṣofo nipa kikuna lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Jesu. Boya Oluwa n sọ fun ẹni kan loni pe, “Dide ki o si mā lọ si iha gusu,” tabi ni ede miran, “Lọ si ọna ibi ti n o ran ọ ki o ba le pade ẹni kan ti ebi n pa.”
A gbọ nipa itan kekere kan ti awọn eniyan fi ọkan ro pe o ṣẹlẹ laarin Jesu ati Gabriẹli ati bi wọn ti n ba ara wọn sọrọ. O dabi ẹni pe nipa ọna ti Ihinrere yoo fi tàn kalẹ lẹhin ti Jesu ba ti goke lọ sọdọ Baba Rè̩ ni Ọrun ni wọn n sọ. Jesu wi fun Gabriẹli pe Oun ti ran awọn ọmọ-ẹhin jade lọ sọ fun araye nipa Kristi. Gabriẹli wa beere pe, “S̩ugbọn ti nwọn kò ba lọ n kọ?” Gẹgẹ bi itan naa ti wi, esi Jesu ni pe, “N ko ni ọna miran.”
Ẹyin ọrẹ mi Onigbagbọ, ojuṣe wa ni lati sọ itan Jesu fun awọn ọkan ti o wà ninu okunkun. A ko fẹ de ibi itẹ idajọ Kristi ki a ri ẹni kan ti a ti n ba pade lojoojumọ ni ile-iwe, ni ibi-iṣẹ tabi loju titi, ki o yọ ọwọ si wa ki o si wi pe, “O kò sọ fun mi nipa Jesu; o kò pe mi lọ si ile-isin.”
Igbagbọ lati inu Ọkàn wa
Siwaju ati siwaju ni kẹkẹ gbe Filippi ati iwẹfa naa lọ. Loju kan naa ni imọlẹ là ninu ọkàn ọgbẹni arin-rin-ajo ara Etiopia yi. Adagun omi tabi odo kan wa ni gẹrẹ-gẹrẹ iwaju wọn. “Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi?” ni ibeere ẹni ti o ṣẹṣẹ yipada yi. Filippi dahun pe, “Bi iwọ ba gbagbọ tọkantọkan, a le baptisi rẹ.” Ni tootọ tọkan-tọkan ni iwẹfa yi fi sọ pe, “Mo gbagbọ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni.” Ayọ kun inu ọkàn rè̩. O ti ni iriri pẹlu Ẹni ti Isaiah kọ nipa Rè̩ pe, “O si ru ẹṣẹ ọpọlọpọ” (Isaiah 53:12).
Iribọmi
O daniloju pe a ko beere ohunkohun nipa ọna ti a o gba fi ṣe iribọmi ni ọjọ naa, yatọ si bi o ti n ri lode oni. Ọna kan ṣoṣo ni o tọna -- ọna ti Bibeli. Bi o tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ni eto iribọmi ti a maa n ri ninu aye, ti ariyanjiyan kankan ba wà lori ododo ẹkọ Bibeli yi a le wo inu Ọrọ Ọlọrun ki a si ri idahun nibẹ. Nigba ti a ba ri eniyan bọ inu omi, eyi n tọka sii pe oluwarè̩ ti ku a ti sin in, o si ti jinde pẹlu Kristi (Romu 6:3, 4). Okú nikan ni a maa n sin; kiki awọn ti wọn ba si ti di oku si ẹṣẹ, aye, ara ati eṣu nikan ni wọn ni ẹtọ pe ki a sin wọn nipa iribọmi. Lati ọwọ Johannu ni a ti ri Jesu bọmi. Iṣẹ ti O ran awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ kẹhin ni pe: “Nitorina ẹ lọ, ẹ mā kọ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19).
Apẹẹrẹ iribọmi iru eyi ti o tọna wo ni a tun le ri ju eyi ti a kọ silẹ ninu Iṣe Awọn Apọsteli 8:38, pe “Awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa; o si baptisi rè̩.” Ẹsẹ ti o tẹle e sọ bayi: “Nigbati nwọn si jade kuro ninu omi, Ẹmi Oluwa ta Filippi pá, iwẹfa ko si ri i mọ.”
Kẹkẹ Ihinrere
Ara le ti ta iwẹfa naa pe oun ko tun ri Filippi mọ, ṣugbọn bi o tilẹ jẹ pe ko ri olukọ rẹ mọ, o ti ri Messia. Ẹni Ikaanu ti o ti kà nipa rè̩ ko tun jẹ ajeji si i mọ. Kristi ti sọ ọkan rè̩ di ominira.
Kẹkẹ naa n ba ọna rè̩ lọ, o n gbe iwẹfa nì lọ si ilẹ Etiopia ti oun ti Ihinrere nipa Igbala. Titi di oni, “Kẹkẹ Ihinrere” kò dẹkun lati maa sure tete gbe ihin ti o mu ireti sọji ninu ọkan kaakiri. Gbogbo ẹni ti o ba n wa idasilẹ kuro ninu ẹṣẹ, ibanujẹ ati wahala, le da ara pọ mọ kẹkẹ yi ki wọn si fi ayọ maa ba ọna wọn lọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Nibo ni Filippi wà nigba ti a ran an lọ si Gasa?
- Kin ni ṣe ti iwẹfa naa fi lọ si Jerusalẹmu?
- Kin ni o n ṣe nigba ti Filippi kọ pade rè̩?
- Inu rè̩ ha dùn lati ri Filippi?
- Apa ibo ni o n kà ninu Iwe Mimọ?
- Iyipada nlá-nlà wo ni o ṣẹlẹ ninu igbesi-aye rè̩?
- Sọ nkan ti o ṣẹlẹ si Filippi lẹhin ti o ti ṣe iribọmi fun iwẹfa naa?
- Awọn ẹkọ pataki wo ni a ri kọ nipa akọsilẹ yi?