I Awọn Ọba 13:1-34; II Awọn Ọba 23:15-18

Lesson 293 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA ỌLỌRUN wa li awa o mā sìn, ohùn rè̩ li awa o si mā gbọ” (Jọṣua 24:24).
Notes

Ibọriṣa

A ranti Aarọni ẹni ti o ṣe ẹgbọrọ malu wura ti o si kede fun awọn ẹniyan pe, “Israẹli wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ góke lati ilẹ Egipti wá” (Ẹksodu 32:4). Eyi lodi si ofin kinni: “Iwọ kò gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi” (Ẹksodu 20:3). Ẹgbọrọ malu ti a fi wura ṣe! Wo iru ohun ti ko ni laari ti awọn eniyan fi dipo Ọlọrun ti o tobi, Ẹni ti o ti ṣe ohun rere lọpọlọpọ bẹẹ fun awọn eniyan Rè̩!

Ni ọpọlọpọ ọdun lẹhin eyi a tun ri ọkunrin miran, Jeroboamu Ọba, ti o ṣe ẹgbọrọ malu wura meji ti o si kede fun awọn eniyan pe: “Israẹli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá” (I Awọn Ọba 12:28). Ete miran lati fi ẹgbọrọ malu wura dipo Ọlọrun nla ti Ọrun ati aye, ṣugbọn eyi pẹlu ja si ikuna!

Bi ọdun ti n gori ọdun ni awọn eniyan n gbe awọn oriṣa kalẹ ti wọn si n sin wọn dipo ki wọn sin Ọlọrun. Ni tootọ, ni ilẹ ọlaju yi, awọn eniyan le ṣe alai ṣe ẹgbọrọ malu ki wọn si wolẹ ki wọn si maa gbadura si i. Sibẹsibẹ oriṣiriṣi iwa ibọriṣa ni o wà. Awọn ti o ti di baraku fun lati maa lọ si ile-iworan, ibi ijo, ibi iṣire bọlu, ati awọn ibi ohun idaraya aye yi ti sọ ọlọrun afẹ di oriṣa ti wọn n bọ. Ọjọ kan n bọ ti Ọlọrun yoo mu awọn ti kò fẹran Rè̩ ti wọn kò si sin In pẹlu gbogbo ọkàn wọn wá si idajọ.

Eniyan Ọlọrun Kan

Ni ọjọ kan bi Jeroboamu ọba ti duro lẹba pẹpẹ naa lati sun turari si awọn ẹgbọrọ malu ti o ti ṣe, eniyan Ọlọrun kan ti Juda de, o si sọ asọtẹlẹ nipa ibi Josiah, eyi ti o ṣẹ ni ojidinnirinwo (360) ọdun lẹhin asọtẹlẹ naa; o tun sọ pẹlu pe a o sun egungun awọn alufa buburu lori pẹpẹ kan naa ni ọjọ kan. Gẹgẹ bi ami pe nkan yi yoo ṣẹ, Oluwa mu ki pẹpẹ naa ki o faya eeru ori rè̩ si danu.

Asọtẹlẹ yi mu ki ibinu Jeroboamu ru soke, o si na ọwọ rè̩ o si wi pe, “Ẹ mu u.” Bi o si ti gbiyanju lati fa ọwọ rè̩ pada, ko ṣe e ṣe fun un mọ, nitori pe o ti gbẹ o si gan sibẹ. O si wi pe, “Tu OLUWA Ọlọrun rẹ loju nisisiyi, ki o si gbadura fun mi, ki a ba le tun mu ọwọ mi bọ sipo fun mi.”

Jeroboamu n mura lọwọ lati sun turari si ọlọrun eke; ṣugbọn nisinsinyi o n fẹ iranlọwọ, o n beere lọdọ Oluwa Ọlọrun. Eniyan Ọlọrun gbadura, ọwọ ọba naa si sàn. Bẹẹ gẹgẹ ni o ri pẹlu ọpọlọpọ eniyan: ẹsìnkẹsin ni o té̩ wọn lọrun niwọn igba ti ohun gbogbo ba n lọ deedee; ṣugbọn nigba ti wahala ba de lojiji, wọn a maa ni ki awọn eniyan Ọlọrun ti Ọlọrun n gbọ ohun wọn ti o si n dahun adura wọn ki o gbadura fun wọn.

Ọba naa sọ pe ki eniyan Ọlọrun naa ba oun kalọ si ile lati jẹun. “Emi o si ta ọ li ọrẹ.” S̩ugbọn eniyan Ọlọrun naa kọ lati ba ọba lọ nitori Ọlọrun ti paṣẹ fun un pe kò gbọdọ jẹ ounjẹ kan, kò si gbọdọ mu omi, ki o si ba ọna miran pada. Idi rè̩ ti ọkunrin yi ko gbọdọ ba wọn kẹgbẹ pọ ni pe awọn eniyan wọnyi ti yipada kuro lati maa sin Ọlọrun otitọ. Ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun, o bẹrẹ irin-ajo rè̩ pada si ile nipa gbigba ọna miran ti ki i ṣe eyi ti o gba wá.

Woli Agba

Awọn ọmọdekunrin kan ti n tẹti si ọrọ ti Jeroboamu ati eniyan Ọlọrun naa n sọ. Wọn si ti ṣe akiyesi ọna ti eniyan Ọlọrun naa ba pada si ile, wọn si yara lọ lati sọ ohun gbogbo ti o ṣẹlẹ fun baba wọn. Baba wọn, woli agba kan ni Bẹtẹli si beere pe, “Ọna wo li o gbà?” Nigba ti wọn sọ fun un tan o ni, “Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi.” Woli agba yi mu ọna rè̩ pọn tete. Nigba ti o si le eniyan Ọlọrun naa ba o beere lọwọ rè̩ pe, “Iwọ li enia Ọlọrun na ti o ti Juda wá?’ Eniyan Ọlọrun naa ti o joko labẹ igi oaku si da a lohun pe, “Emi ni.” Woli agba yi si bẹẹ pe, “Ba mi lọ ile, ki o si jẹ onjẹ.”

Bi o tilẹ jẹ pe aarẹ ti mu un, oungbẹ n gbẹ ẹ, ebi n pa a, ṣugbọn nitori pe o pinnu lati pa gbogbo aṣẹ ti Oluwa fun un mọ, eniyan Ọlọrun naa wi pe a ti sọ fun oun pe ki oun ma ṣe jẹ ounjẹ tabi mu omi, ki oun ma si ṣe gba ọna ti oun gba wa pada.

A Pa a Lọkan Dà

Nigba pupọ ni Satani ki i bori ninu aba rè̩ akọkọ lati bi ọmọ Ọlọrun ṣubu. S̩ugbọn yoo tun gbiyanju lẹẹkan si i, boya yoo gba ọna miran. Woli agba naa ko tete rẹwẹsi. O pinnu pe, oun yoo tun gbiyanju. Dipo ti i ba kan fi wi pe, “Oluwa li o ba mi sọrọ,” o ni: “Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angẹli si sọ fun mi nipa ọrọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi.” Wo iru irọ ti o fi arekereke gbe kalẹ yi! Bẹẹ gẹgẹ ni eṣu ti n ṣe lati fi irọ gbe ohun ti o n sọ ki o ba le bori.

A Dẹkun Mu un

Bi o ba ṣe pe eniyan Ọlọrun naa kò duro labẹ igi oaku ni, ọkunrin agba buburu yi ki ba ti le ba a. O duro; o joko; o tẹti silẹ; o si fi ọrọ we ọrọ pẹlu ọta. Nigba naa ni o yipada o si lọ si ile woli agba naa; o jẹ ounjẹ o si mu omi pẹlu rè̩. A ti mu un ninu idẹkun ọta!

S̩ugbọn itan ibanujẹ eniyan Ọlọrun yi ko mọ sibẹ. Bi awọn mejeeji ti joko ti ounjẹ, woli agba naa sọ idajọ ti yoo wa sori ọkunrin yi ti Ọlọrun ran niṣẹ lati ṣe ohun kan: Nitori pe o ṣe aigbọran si Oluwa ti o si pada ti o si ti jẹun ti o si mu omi, ko ni pada si ile laaye. Bi o ti n lọ ni ọna rè̩ pada si ile, kinniun kan pade rè̩ o si pa a.

Ọlọrun ti fun un ni iṣẹ kan lati ṣe, o si ti ṣe e daradara. S̩ugbọn nigba ti o n pada bọ si ile, o yà kuro loju ọna rè̩. Lẹhin ti Ọlọrun ti paṣẹ fun un nipa ohun ti o gbọdọ ṣe ati ohun ti kò gbọdọ ṣe, kin ni ṣe ti o feti si woli eke nì ti o sọ pe a ran oun ni iṣẹ miran ti o lodi si eyi ti o ti gbọ?

Idẹkun Loju Ọna

Lati igba naa wa Satani ti tun ni iriri ẹgbẹẹdogun (3,000) ọdun ninu gbigbiyanju lati yi ọkan awọn eniyan Oluwa kuro loju ọna tooro nì. Gẹgẹ bi arekereke rè̩ ti pọ to nigba aye Jeroboamu lati le awọn eniyan Ọlọrun ba, bẹẹ ni o ṣi wa di oni oloni; bẹẹ gẹgẹ ni o ṣi kun fun ọgbọn è̩wẹ lati yi wọn lọkàn pada lati joko labẹ igi oaku lati sinmi. Yoo ja si ere pupọ fun wa lati kiyesara ki a mọ daju pe ohùn jẹjẹ kekere ti Ẹmi ni a n tẹti si ki a ma si ṣe fetisi ohun ipe aye tabi Satani. Ọmọkunrin tabi ọmọbinrin kan le wi pe, “Wá, jẹ ki a lọ si ile iworan ere.” O le fesi pe, “Onigbagbọ ni emi, emi ki i lọ si iru ibẹ.” S̩ugbọn o le fi eyi gbe ọrọ rè̩ lẹsẹ pe, “Onigbagbọ ni emi naa, emi a si maa lọ nigba gbogbo.” Bi ọkàn rẹ ba “wa ni iṣọkan” pẹlu awọn ohun ti Ọrun, ohun kan yoo sọ fun ọ pe ile iworan ere bẹẹ ki i ṣe ibi ti Onigbagbọ tootọ ni lati lọ.

Eṣu atijọ nì a maa rẹrin, a si maa fi ọmọ Ọlọrun ti o pada sẹhin ṣẹfẹ gẹgẹ bi woli agbà nì ti fi eniyan Ọlọrun nì ṣẹsin. Wo iru janba ti o ba ẹni ti Ọlọrun ti n ṣamọna rè̩ nigba kan ri ti o si ti n gbọran si ohun Ọlọrun nigba kan ri. Dajudaju iboji rè̩ jẹ ohun-iranti fun aigbọran ati iṣubu. Ọpọlọpọ awọn ti o ba mọ nipa rè̩ ni yoo maa sọ itan aigbọran, ikuna ati yiya kuro lọdọ Oluwa nipa ti ọkunrin yi. Ida iná ni iha ila-oorun Ọgba Edẹni ni o jẹ ami ni ibi ti aigbọran akọkọ gbe ṣẹlẹ ninu aye (Gẹnẹsisi 3:24). Ọwọn iyọ ni o jẹ ami ni ibi kan ti obinrin kan ti yipada kuro ni titẹle Oluwa (Gẹnẹsisi 19:26). Okiti okuta lẹhin odi ilu ni o jẹ ami ni ibi ti Akani gbe ku iku aitọjọ nitori ẹṣẹ rè̩ (Jọṣua 7:26).

Loju Ọna si Ile

A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe bẹẹ ni awọn ohun-iranti wà nipa aṣeyọri ni oju ọna ti o lọ lati aye si Ogo. Ọrọ Ọlọrun kun fun akọsilẹ awọn ọkunrin ati obinrin ti kò yipada si ọwọ ọtun tabi si ọwọ osi, ti ko si pada sẹhin, ti wọn si ti rin irin-ajo wọn ni arin-yọri si rere de “Ile.” Ka Heberu ori kọkanla (11) ti o n sọ ni ṣoki fun wa akọsilẹ awọn ti o ṣegun nipa igbagbọ. Ka itan ẹni kọọkan ninu awọn aṣẹgun wọnyi. Yoo mu ki igbagbọ rẹ pọ sii lati mọ nipa awọn ti o fori tii titi de opin.

Bi awa naa ni akoko yi ba pinnu ninu ọkàn wa lati maa wo Amọna wa Tootọ, ki igbọran wa ma ṣe jẹ si diẹ ninu awọn aṣẹ Rè̩, ṣugbọn si gbogbo aṣẹ Rè̩, awa paapaa le pẹlu awọn ti wọn ti ja ti wọṅ si pa igbagbọ mọ.

“Nitorina ja, pẹlu igboiya, tiri si ibi gbogbo;

Máṣe sa, má si ṣe fasẹhin.

B’o ba nfẹ j’aṣẹgun f’Ọlọrun

Sa duro ninu Jesu.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ami wo ni o fi han pe ọrọ asọtẹlẹ eniyan Ọlọrun naa jẹ otitọ?
  2. Tani Jeroboamu yipada si fun iwosan ọwọ rè̩?
  3. Kin ni o ro pe o jẹ eredi rè̩ ti Jeroboamu fi bẹ eniyan Ọlọrun naa lati ba oun lọ sile?
  4. Kin ni ṣe ti o kọ lati lọ?
  5. Kin ni aṣiṣe kinni ti eniyan Ọlọrun naa ṣe?
  6. Kin ni eredi ti woli naa sọ lati fi mu un pada lọ si ile pẹlu rè̩?
  7. Sọ nipa iku ibanujẹ ti eniyan Ọlọrun naa ku?
  8. Kin ni ṣe ti o jẹ ohun ti o lẹru lọpọlọpọ lati ṣe aigbọran si ohùn Ọlọrun?
2