Lesson 294 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Kò si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ” (Matteu 10:26).Notes
Awọn Ẹṣẹ Jeroboamu
A mọ awọn kan ninu Bibeli fun igbagbọ wọn, awọn miran fun suuru wọn, a si mọ awọn miran è̩wẹ fun iwa akikanju ti wọn hù. S̩ugbọn a darukọ awọn miran, a si n ranti wọn fun aṣiṣe wọn ati ikuna wọn. Titi aye ni a o maa sọrọ Jeroboamu ti a o si maa darukọ rè̩ pẹlu ọrọ marun yi pe oun ni “ẹniti o mu Israẹli dẹṣè̩.” Igba mọkandinlogun ni a tẹnu mọ ọrọ wọnyi ninu Bibeli nipa Jeroboamu. O ti ba ni lọkàn jẹ to pe iru ọrọ bayi ni a sọ nipa ẹni ti o yẹ ki o jẹ olootọ aṣaaju fun awọn eniyan Ọlọrun! A ranti pe Jeroboamu ni ẹni ti o ya ẹgbọrọ malu wura meji, ti o rubọ si wọn ti o si sọ fun awọn eniyan pe o pọ jù fun wọn lati maa goke lọ si Jerusalẹmu lati lọ jọsin; nitori naa awọn pẹlu bẹrẹ si sin awọn ẹgbọrọ malu wura naa.
Ki i ṣe awọn eniyan Israẹli nikan ni è̩ṣẹ ọkunrin buburu yi ko ba, ṣugbọn o ko ba awọn ẹbi oun tikara rè̩ pẹlu. O yẹ ki a maa ranti nigba gbogbo pe gbogbo olukuluku eniyan ti a n ba pade ni iwa wa nkàn lara. “Nitori kò si ẹnikan ninu wa ti o wà lāye fun ara rè̩, kò si si ẹniti o nkú fun ara rè̩” (Romu 14:7). A ka ninu Bibeli pe “Iṣe ọmọde pāpa li a fi imọ ọ, bi ìwa rè̩ ṣe rere ati titọ” (Owe 20:11).
Bibeere Imọràn
Ni akoko kan ọmọ Jeroboamu ṣe aisan. Jeroboamu wa mu ki aya rè̩ pa ara rè̩ dà ki o si lọ sọdọ Woli Ahijah ni S̩ilo lati beere bi ọmọ naa yoo san. Iya ti ọkan rè̩ kò balẹ yi dide lati lọ ba eniyan Ọlọrun, o si di ẹru ẹbun pupọ gẹgẹ bi aṣa awọn eniyan naa nigba ti wọn ba n tọ woli lọ. Ko ṣanfaani kankan fun aya Jeroboamu lati pa ara rè̩ dà nitori ti Woli Ọlọrun naa ti fọ loju; ṣugbọn oju rè̩ nipa ti ẹmi muna, kò si jafara rara lati mọ iro ẹsẹ obinrin naa yatọ. “Eti” ọkàn rè̩ kò si wuwo pẹlu nitori lẹsẹkẹsẹ ni o ti gbọ ohun Ọlọrun ti O wi fun un pe obinrin naa n bọ, ti O si kọ ọ ni ohun ti yoo sọ fun un.
Olufihan Aṣiiri
Nigba pupọ Ọlọrun a maa fi ohun aṣiiri tabi ohun ti o pamọ han fun awọn eniyan Rè̩. Ni akoko kan awọn ọdọmọkunrin meji kan fọ ile kan, wọn wọ inu rè̩ wọn si ji owo nibẹ nigba ti wọn mọ pe awọn ara ile naa lọ si ile-isin. Nigba ti wọn pada si ile ti wọn si rii pe ole ti kó ẹru wọn lọ, lẹsẹkẹsẹ ni iya ile ti wi pe oun mọ awọn ẹni ti o ṣe e. Ni ọjọ keji awọn ọlọpa lọ ba awọn ọmọde naa lati wi pe ki wọn jẹwọ. Nigba ti wọn de ọdọ awọn ti a ti kó lẹru, awọn ọmọ naa beere idi rè̩ ti a fi fura si wọn. Iya naa sọ fun awọn ọmọ naa pe Ọlọrun Ọrun ni o fi awọn ti o ṣe han oun. O tun sọ pe o yẹ ki wọn maa ranti nigba gbogbo pe ohun gbogbo ti wọn n ṣe ni Ọlọrun n ri, ati pe O ni ọna ti o fi n fi aṣiiri nkan wọnyi han fun awọn ti Rè̩. “Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba ati olufihàn gbogbo aṣiri” (Daniẹli 2:47).
Ko ṣanfaani fun aya Jeroboamu lati sọ aya ẹni ti oun i ṣe – a ko tilẹ fun ni aye lati sọrọ. Woli Ọlọrun nikan ni o sọrọ, o si ba a wi gidigidi fun è̩tan rè̩. Eniyan le fi iwa è̩tan ṣe bojuboju fun araye; nipa “hihu iwa agabagebe,” awọn miran le dabi ẹni pe wọn n “tẹsiwaju” ninu ẹsìn. O si le dabi ẹni pe awọn miran n ri ojurere alakoso tabi oniwaasu wọn nipa fifun un ni ẹbun tabi nipa ṣiṣe agabagebe pe awọn jẹ ohun ti wọn ko jẹ, ṣugbọn Ọlọrun n kiyesi gbogbo rè̩ ni Ọrun, Oun yoo si fi otitọ han ni ọjọ kan.
Bawo ni o ti jẹ iwa omugọ to lati ro pe oju eniyan Ọlọrun ko le ri kọja aṣọ è̩tan ti eniyan fi bora! Ọmọ Ọlọrun tootọ kì i ni ohunkohun lati fi pamọ tabi bo mọlẹ. Iwe ti a ṣi silẹ ni igbesi-aye rè̩ jẹ, eyi ti gbogbo eniyan ti ka ti wọn si ti mọ (II Kọrinti 3:2). Ẹru ki i ba a bẹẹ ni oju ki i ti i lati duro niwaju Onigbagbọ miran tabi ẹlẹṣẹ.
Iṣẹ Ahijah
Ahijah sọ fun iyawo Jeroboamu wi pe “iṣẹ wuwo” ni oun ni fun un, eyi ni pe ọrọ ti o korò. O wi fun un pe ki o pada ki o si jiṣẹ fun ọkọ rè̩ pe niwọn bi oun gẹgẹ bi ọba kò ti pa aṣẹ Oluwa mọ, ṣugbọn ti o ti ṣe ibi nipa yiyan ọlọrun miran ati ṣiṣa Oluwa tì sẹhin rè̩, Oluwa Ọlọrun Israẹli wi pe Oun yoo mu ibi wa sori ile Jeroboamu. Ko tilẹ si ẹni ti a ó sin ninu awọn okú wọn. Awọn ti o ba kú ni igboro ajá ni yoo jẹ wọn; ẹni ti o ba si kú ni igbẹ ni awọn ẹyẹ yoo jẹ. O si wi pe, “Nitorina, iwọ dide, lọ si ile rẹ: nigbati ẹsẹ rẹ ba si wọ ilu, ọmọ na yio kú.” Esi ibeere rè̩ ni yi!
Ni ti awọn eniyan Israẹli, Ahijah wi pe a o fa wọn tu kuro ni ilẹ rere wọn, a o si fọ wọn ka si ọna ti o jin rere. O wa fi ọrọ idajọ kikoro yi pari asọtẹlẹ rè̩, “Yio (OLUWA) si kọ Israẹli silẹ nitori ẹṣẹ Jeroboamu, ẹniti o ṣẹ, ti o si mu Israẹli dẹṣẹ.”
Ọrọ Ọlọrun S̩ẹ
Dajudaju pẹlu ọkàn ibanujẹ gidigidi ni iya yi fi mu ọna ile pọn. Abijah ọmọ rè̩ yoo ku dandan, gbogbo awọn ara ile rè̩ ni yoo si ku lai jẹ pe a tilẹ sin wọn. Nigba ti o de ẹnu ilẹkun, ọmọ rè̩ naa ku. S̩ugbọn ṣa, ninu gbogbo idile Jeroboamu ọmọkunrin yi nikan ṣoṣo ni o ni iboji, nitori lọdọ rè̩ ni a ri ohun rere diẹ sipa ti Oluwa Ọlọrun. A kà pe ni akoko ijọba Ọba Asa, gbogbo ile Jeroboamu ni a pa to bẹẹ ti ko kù fun un “ẹniti nmí, titi o fi run u gẹgẹ bi ọrọ OLUWA ti o sọ nipa ọwọ iranṣẹ rè̩, Ahijah” (I Awọn Ọba 15:29).
Gbogbo wa ni a mọ pe a tu awọn Ọmọ Israẹli, awọn Ju, kaakiri gbogbo agbaye. Ọrọ Ọlọrun ki i ṣalai ṣẹ bẹẹ ni ẹṣẹ kò le lọ lai jẹ pe ijiya tẹle e.
Questions
AWỌN IBEERE- Kin ni ipo Jeroboamu ni akoko yi?
- Eredi rè̩ ti Jeroboamu fi ran iyawo rè̩ lọ ba Woli?
- Bawo ni Ahijah ṣe mọ pe iyawo Jeroboamu n bọ wa ri oun?
- O le fi Jeroboamu wé Dafidi?
- Ni ṣoki, sọ idajọ ti a mu wa sori ile Jeroboamu; ati sori Israẹli.
- Kin ni ṣẹlẹ si ọmọ Jeroboamu ti o ti n ṣaisan?
- Nitori idi wo ni ọmọ yi ṣe ni anfaani pe ki a sin in?
- Darukọ awọn miran ninu Bibeli ti wọn gbiyanju lati bo ẹṣẹ mọlẹ.