II Kronika 14:1-15; 15:1-19; 16:1-14

Lesson 295 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rè̩, ẹniti ọkàn rè̩ si ṣi kuro lọdọ OLUWA!” (Jeremiah 17:5).
Notes

Pipa Awọn Oriṣa Run

Nigba ti Asa di ọba kẹta ni Juda, alaafia wà fun ọdun mẹwa. “Asa si ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ li oju OLUWA.” Asa rú ọkàn awọn eniyan soke lati wá Ọlọrun ati lati gbọran si aṣẹ Rè̩. O mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, o bẹ igbo oriṣa wọn lulẹ, o si pa awọn ere oriṣa run.

Awọn obi Asa ki i ṣe olusin Ọlọrun otitọ. Ijọba baba rè̩ lori Juda jẹ ijọba buburu. Iya Asa ti yá ere kan fun oriṣa rè̩ (I Awọn Ọba 15:13). Bi o tilẹ jẹ pe awọn obi Asa ko sin Ọlọrun, Asa ṣe eyi ti o dara ni oju Ọlọrun. Ẹṣẹ, ibọriṣa ati apẹẹrẹ buburu wà ni gbogbo ayika rè̩, ṣugbọn Asa ṣe ohun ti o mọ pe o tọ. Ọkan awa naa le balẹ pe Ọlọrun yoo wa pẹlu wa ki O si ran wa lọwọ nigba ti a ba ṣe ohun ti o tọ bi o tilẹ jẹ pe awọn miran ti o yi wa ka ko gbọran si Ọlọrun lẹnu.

Ni Igba Alaafia

Asa sọ fun awọn eniyan pe Oluwa ti fun wọn ni alaafia, nitori pe wọn wá Ọlọrun. Ni igba alaafia, ọwọ wọn kun fun iṣẹ. Wọn sọ awọn ilu wọn di alagbara nipa mimọ odi yi wọn ka, ati ile iṣọ, ilẹkun, ati ọpa-idabu. Awọn eniyan kọ wọn, wọn si ṣe rere. A sọ awọn ọmọ-ogun Asa di nla wọn si di alagbara ju ti atẹhinwa lọ. Ni igba alaafia ọwọ Asa kun fun iṣe imura-silẹ fun akoko ti ọta yoo dide si i. Ohun rere ni fun Onigbagbọ lati maa sọ ara rè̩ di alagbara pẹlu. Dipo ti i ba fi maa ṣe ọlẹ, Onigbagbọ ni lati kun fun kika Ọrọ Ọlọrun nitori pe eyi ni yoo fun un ni agbara, igbagbọ ati igboya. A sọ fun wa pe Ọrọ Ọlọrun ni “ida Ẹmi” (Efesu 6:17). Pẹlupẹlu nipa adura, a o sọ Onigbagbọ di alagbara, a o si wọ ọ ni ẹwu ihamọra Ọlọrun ninu eyi ti aṣibori igbala, igbaya ododo, ati apata igbagbọ wà.

Adura ati Iṣẹgun

Lai pẹ jọjọ Sera ara Etiopia gbe ogun dide si Asa. Awọn ọmọ-ogun awọn ọta fẹrẹ to ilọpo meji awọn ọmọ-ogun Asa, lẹhin pe wọn ni ọdunrun (300) kẹkẹ-ẹṣin. S̩ugbọn ẹru kò ba Asa nitori pe igbẹkẹle rè̩ wa ninu Ọlọrun. Asa gbadura o si beere pe ki Ọlọrun ran oun lọwọ. Asa wi pe: “Ràn wa lọwọ, OLUWA Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹle ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọpọlọpọ yi lọ.” Asa ti sọ ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ di nla o si ti sọ ilẹ rè̩ di alagbara. S̩ugbọn Ọlọrun ni o gbẹkẹle lati gba a. Asa kò nireti wi pe Ọlọrun nikan ni yoo ja gbogbo ijà naa bẹẹ ni ko si fi igbẹkẹle rè̩ sinu awọn eniyan ati ohun-ija.

Ọlọrun dahun adura Asa. Ọlọrun si kọlu awọn ara Etiopia niwaju Asa. Nigba ti wọn sa, Asa ati awọn eniyan rè̩ lepa wọn a si bi awọn ọta naa ṣubu. Ọlọrun fun awọn eniyan Juda ni iṣẹgun lori awọn ọta wọn – ati ju bẹẹ lọ paapaa. Asa ati awọn ọmọ-ogun ṣẹgun awọn ilu ti o wà ni agbegbe, wọn si ko awọn agbo, ẹran-ọsin, agutan, ati ibakasiẹ, wọn si ni ju eyi ti wọn ni ki ogun to bẹrẹ. Nitori pe Asa ṣe eyi ti o tọ, Ọlọrun fun un ni isinmi, aṣeyọri, ati iṣẹgun, O si gbọ adura rè̩. Njẹ o rò pe o lere fun Asa lati ṣe eyi ti o wu Ọlọrun? O ha lere lati sin Ọlọrun ati lati ṣe eyi ti o tọ loni?

Ikilọ

Asariah ọmọ Odedi ni iṣẹ kan lati jẹ fun Asa ati awọn eniyan naa. O ni, “OLUWA pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rè̩; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rè̩, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ ọ, on o si kọ nyin.” Wọn ti ri idaniloju apa kinni ọrọ Asariah. Asa ko ha ti wa iranlọwọ Ọlọrun, wọn si ti ni iṣẹgun ninu ogun? Wọn ko fẹ ki Ọlọrun kọ wọn silẹ, nitori naa wọn fi ọkàn wọn si ikilọ Woli naa. O ti wi pe, “Ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ owọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ere.”

Isin Tootọ

Asa tun pẹpẹ Oluwa ṣe o si pe awọn eniyan lati wá jọsin. Wọn si wá Ọlọrun “tinutinu wọn ati tọkantọkan wọn.” Wọn ba Oluwa da majẹmu wọn si mu ẹbọ wa fun Un. Wọn jẹ ẹjé̩ fun Ọlọrun pe ẹnikẹni ti ko ba gbadura ki o si wá Ọlọrun, pipa ni awọn yoo pa a. Ayaba paapaa, iya Asa, ẹni ti o ti ṣe ere kan ninu igbo-oriṣa ni a mu kuro ni ipo rè̩. Asa ke ere rè̩ lulẹ, o si fi ina sun un lẹba odo Kidroni.

Awọn eniyan naa mu ẹbọ wa fun Oluwa gẹgẹ bi awọn Onigbagbọ isinsinyi ti maa n ṣe ifararubọ fun Oluwa. Nigba ti awọn eniyan Juda fi gbogbo ọkàn wọn ati “gbogbo ifẹ inu wọn,” wa Oluwa, wọn si ri I. Wọn si yọ ayọ nla pẹlu ariwo, ati pẹlu ipe ati pẹlu fere. Ọlọrun fun wọn ni alaafia ati isinmi, kò si si ogun fun ọpọlọpọ ọdun.

Awọn eniyan le ni alaafia nipa ti ẹmi ni akoko yi pẹlu nipa wiwa Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn wọn, nipa jijẹ è̩jẹ fun Ọlọrun, ati nipa fifi nkan fun Un nipa ifararubọ. A gbọdọ ranti ọrọ Woli Asariah. Oluwa yoo wà pẹlu wa nigba ti a ba wà pẹlu Rè̩, ṣugbọn Oluwa yoo fi wa silẹ bi awa naa ba kọ Ọ silẹ.

Ogun Miran

Ọkan Asa pe ni gbogbo ọjọ ti o ba Ọlọrun rin. Akoko kan tun de nigba ti wahala tun de ba ilẹ naa. Eniyan le nireti pe Asa yoo gbadura si Oluwa fun iranlọwọ, yoo si gbẹkẹle Ọlọrun. Ọlọrun ti gba Asa lọwọ awọn ara Etiopia. Woli Asariah ti kilọ fun wọn pe Ọlọrun yoo fi wọn silẹ bi wọn ba fi Ọlọrun silẹ. Wọn ti ba Ọlọrun da majẹmu lati fi gbogbo ọkàn wọn wa A. Kin ni wọn ṣe ni igba wahala? Njẹ wọn pa è̩jẹ ati majẹmu wọn ti wọn ṣe niwaju Ọlọrun mọ?

Asa wá iranlọwọ lọ sọdọ Bẹnhadadi, Ọba Siria, ẹni ti kò ṣe ọrẹ awọn Ọmọ Israẹli ri rara, ti ko si ṣe oore kan fun wọn ri. Asa ko awọn iṣura jade lati inu ile Oluwa. Ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin, o ti ya wura ati fadaka wọnyi si mimọ fun Oluwa, ṣugbọn nisinsinyi o kó wọn pada. Lati fi wá ojurere Bẹnhadadi, Asa fi fun un ninu awọn iṣura wọnyi eyi ti ki i ṣe ti Asa lati lo lọna bẹẹ. Asa ba Bẹnhadadi da majẹmu, nipa ṣiṣe bẹ o ba majẹmu rè̩ pẹlu Oluwa jẹ. Asa kò tun gbẹkẹle Oluwa lati ja fun un mọ. Nisinsinyi Asa gbe ẹkẹ rè̩ le eniyan.

Majẹmu Kan

Njẹ o buru fun Asa lati ba Bẹnhadadi da majẹmu? Majẹmu yi fi han pe Asa gbẹkẹle Bẹnhadadi, ko si tun gbẹkẹle Ọlọrun lati gbà a mọ. A kà ninu Bibeli pe: “Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọpọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ gba silẹ” (Orin Dafidi 33:16). A ti sọ ọrọ idajọ ègbé ti yoo wa sori awọn ti o fi igbẹkẹle wọn sinu eniyan ati ohun ija dipo pe ki wọn gbẹkẹle Ọlọrun ki wọn si wa A (Isaiah 31:1). A ti sọ ọrọ ègun kan sori ẹni ti o gbẹkẹle eniyan ti o si yipada kuro lati maa gbẹkẹle Oluwa (Jeremiah 17:5).

Bẹnhadadi ko fẹran Ọlọrun tabi awọn eniyan Ọlọrun. Ọta awọn Ọmọ Israẹli lati ilẹ wa ni i ṣe. Awọn eniyan Bẹnhadadi ti mu wahala ba awọn Ọmọ Israẹli wọn si ti gbe ogun ti wọṅ ni ọpọlọpọ igbà. Lai si aniani idi rè̩ ti Bẹnhadadi fi ṣe majẹmu naa pẹlu Asa ni lati gba fadaka ati wura wọnni. Ki i ṣe pe o bikita to bẹẹ nipa Asa ati awọn eniyan rè̩.

Bẹnhadadi duro fun aye ni apẹẹrẹ, eyi ti ki i ṣe ọrẹ awọn eniyan Ọlọrun. Ọlọrun ko fẹ ki awa ti akoko yi sowọ pọ pẹlu Satani (ọta wa) tabi ẹnikẹni ninu awọn ọmọ-ẹhin rè̩. Bẹnhadadi fara han bi ẹni ti o n ran Asa lọwọ ṣugbọn kò bikita nipa ire Asa tabi ibalo rè̩ pẹlu Oluwa.

Kin ni abayọri si majẹmu yi pẹlu Bẹnhadadi? Awọn ara Siria ran awọn ọmọ-ogun wọn lati lọ ba awọn ọta Juda ja, wọn si ṣẹgun ọpọlọpọ ilu, ṣugbọn Asa ko ni alaafia. Laarin awọn ọdun ti o ti rekọja, Asa ti wi pe Oluwa ti fun wọn ni isinmi nitori pe wọn wa Ọlọrun. Nigba ti wọn kò tun wá Ọlọrun mọ, kò si alaafia ati isinmi.

Gbigbẹkẹle Ọlọrun

Ẹ jẹ ki a kọ ẹkọ lara iriri Asa. Ẹ jẹ ki a maa wo Oluwa fun iranlọwọ wa, a o si ni alaafia ati isinmi. Ẹ má ṣe jẹ ki a maa ba aye sowọ pọ ati awọn eniyan gẹgẹ bi Asa ti ṣe pẹlu Siria awọn ti wọn ti jẹ ọta rè̩ lati ipilẹ, ti wọn o si tun maa jẹ ọta rè̩ ni igba ti n bọ pẹlu. Ọlọrun ti wà pẹlu wa ni igba ti o ti kọja, bi a kò ba kọ ọ silẹ, yoo wà pẹlu wa ni gbogbo ọjọ ti n bọ.

Ọpọlọpọ ibukun ati ileri wà fun awọn ti o gbọran si aṣẹ Ọlọrun (Deuteronomi 28:1-14). Ọpọlọpọ itọka ni o wa ninu Bibeli nibi ti a gbe sọ fun wa pe ki a gbẹkẹle Ọlọrun. “O ya lati gbẹkẹle OLUWA, ju ati gbẹkẹle enia lọ” (Orin Dafidi 118:8). “Ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rè̩ le OLUWA li a o gbe leke” (Owe 29:25).

A ti kọ ẹkọ nipa Dafidi ọba awọn Ọmọ Israẹli. Dafidi gbẹkẹle Ọlọrun a si gba a lọwọ awọn ọta rè̩. O fi iyin fun Oluwa fun iranlọwọ Rè̩ (Wo Ẹkọ 244). Kà ninu awọn Psalmu ohun ti Dafidi kọ silẹ nipa gbigbẹkẹle Oluwa (Orin Dafidi 18:31; 32:1, 2; 34:20: 37:3).

Jobu ni ọkunrin miran ti o gbe ẹkẹ rè̩ le Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ pe Jobu padanu awọn ọmọ rè̩, agbo ẹran rè̩, ti o fẹrẹ jẹ pe gbogbo ohun ti o ni ni o padanu, sibẹ o gbẹkẹle Oluwa. Satani, ọta Jobu ati ọta awa naa pẹlu, pọn Jobu loju “pẹlu õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rè̩ lọ de atari rè̩” (Jobu 2:7), ṣugbọn Jobu gbẹkẹle Ọlọrun. Nigba ti awọn ọrẹ rè̩ wa lati tu u ninu o jẹ ki wọn mọ pe igbẹkẹle oun wa ninu Ọlọrun. Jobu ni “Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e” (Jobu 13:15). Nitori igbẹkẹle Jobu, “OLUWA si busi ohun gbogbo ti Jobu ni ri ni iṣẹpo meji.” Oluwa si bukun igbẹhin aye Jobu jù iṣaaju rè̩ lọ (Jobu 42:10-12).

Alaafia

Jobu ri ere gba nipa gbigbẹkẹle Ọlọrun. S̩ugbọn Asa ha ri ere kan nipa gbigbẹkẹle Bẹnhadadi? Igbẹhin aye Asa yatọ pupọ si igbesi-aye awọn ti o gbẹkẹle Ọlọrun. “Iwọ o pa a mọ li alafia pipe, ọkan ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ” (Isaiah 26:3). Bi o tilẹ jẹ pe a le awọn ọta Asa lọ fun igba diẹ ti o si fi ikogun naa kọ ilu meji, Asa mu ara rè̩ kuro labẹ aabo Ọlọrun ati itọju Rè̩, ko si ni alaafia.

Hanani Woli ba Asa sọrọ. O ran Asa leti pe Ọlọrun ti gba awọn ọmọ ogun Asa silẹ lọwọ ẹgbẹ ogun nlá-nlà ti awọn ọta nigba ti o gbẹkẹle Oluwa. Hanani sọ fun Asa pe o ti huwa aṣiwere, ati pe ki yoo ni alaafia, ṣugbọn ogun. Awọn ọrọ wọnyi ṣẹ. Ogun wa laarin Asa ati Baaṣa, Ọba Israẹli ni gbogbo iyoku ọjọ aye wọn. Lẹhin eyi, awọn ara Siria ti Asa ba da majẹmu, gbogun ti ọmọ Asa ẹni ti o jọba lẹhin rè̩.

Inu Asa ko dun si awọn ọrọ Hanani Woli, bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ otitọ. Asa kò huwa ẹni ti o fẹ Oluwa. O fi Woli yi sinu tubu nitori ọrọ r “nitoriti o binu si i niti eyi na.” Ki i ṣe Hanani nikan ni Asa ni lara. Bẹẹ ni o ni awọn miran lara ninu awọn eniyan naa ni akoko yi.

Alaiṣootọ

Wo o bi o ti ba ni ninu jẹ to lati ka iru awọn ọrọ bayi nipa Asa ẹni ti o bẹrẹ ni ọna daradara bẹẹ lati sin ati lati ṣiṣẹ fun Oluwa! Jesu ni, “Ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a o gbalà” (Matteu 10:22). Bibeli kọ wa pe awọn ti o ba jẹ olootọ titi de opin aye wọn ni ere naa wà fun. Bibẹrẹ lati tẹle Kristi ko to fun wa, a ni lati pari aye wa sinu gbigbẹkẹle Oluwa. Ni opin igbesi-aye Paulu, o ni: “Emi ti jà ija rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ mọ: lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi” (II Timoteu 4:7, 8).

Ninu Ibanujẹ ati Aisan

Igbẹhin ọjọ aye Asa kun fun ibanujẹ ati ailadun. Ọkàn rè̩ kò le balẹ nipa fifi Woli Oluwa sinu tubu. O daju pe yoo ni idalẹbi ọkàn fun nini awọn eniyan naa lara. Kò si idi ti a le fi gbagbọ pe o ronupiwada o si ni ki Ọlọrun dariji oun. Ninu iru ipo bayi, inu Asa kò le dùn. Lẹhin gbogbo eyi, o tun ṣaisan. O ṣe aisan ni ẹsẹ rè̩, “titi arun rè̩ fi pọ gidigidi.” Sibẹ Asa ko wá Ọlọrun.

Awọn miran ninu Bibeli gbẹkẹle Ọlọrun fun iwosan. A mọ pe Ọlọrun a maa wo awọn ti o n ṣaisan san ni igba yi. Bibeli sọ ohun ti a ni i ṣe fun wa nigba ti a ba n ṣaisan: “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura ... Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rè̩, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbe e dide” (Jakọbu 5:13-15).

S̩ugbọn Asa wa awọn oniṣegun, o si kú. Ni tootọ ni a sinku rè̩ lọna daradara ti wọn si lo ikunra oloorun didun lati kun un lara, ti wọn si fi ọpọlọpọ turari oloorun didun jona fun un, bawo ni i ba ti dara to bi a ba le sọ wi pe o gbẹkẹle Oluwa titi de opin aye rè̩, ati pe o ti ri ere naa gbà ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn olootọ. “Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia!” (Orin Dafidi 31:19).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Asa ti ṣe bẹrẹ ijọba rè̩?
  2. Ni ọna wo ni o gbẹkẹle Oluwa?
  3. Kin ni ohun ti o ṣe lati fi idi isin otitọ mulẹ?
  4. Kin ni ṣẹlẹ si ere-oriṣa iya rè̩?
  5. Tani ran Asa lọwọ ninu ogun rè̩ pẹlu awọn ara Etiopia?
  6. Kin ni ṣe ti Asa ni isinmi kuro lọwọ ogun?
  7. Kin ni aṣiṣe Asa?
  8. Tani gbogun ti ọmọ Asa?
  9. Ẹkọ wo ni a le kọ ninu igbesi-aye Asa?
  10. Sọ diẹ ninu awọn ileri Ọlọrun fun awọn ti o gbẹkẹle E.
2