I Awọn Ọba 16:29-34; 17:1-24

Lesson 296 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ikoko iyẹfun na kò ṣofo, bẹni kòlobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọrọ OLUWA” (I Awọn Ọba 17:16).
Notes

Ẹṣẹ ati Ẹlẹṣẹ

A kà ninu Iwe Gẹnẹsisi pe iwa buburu eniyan di pipọ ni aye to bẹẹ ti o fi dun Oluwa pe Oun da eniyan. O wi pe, “Emi o pa enia ti mo ti da run” (Gẹnẹsisi 6:7). A ranti pe a ti kẹkọ nipa Ikun-omi ti o run gbogbo eniyan ayafi Noah ati idile rẹ. Titi di oni ni inu Ọlọrun n bajẹ si ẹṣẹ, Oun o si tun ran iparun wa sori awọn ẹlẹṣẹ ni ọjọ kan. Ninu ẹkọ ti oni a kà pe Ọba Ahabu “ṣe ju gbogbo awọn ọba Israẹli lọ, ti o ti wà ṣaju rè̩, lati mu ki OLUWA Ọlọrun Israẹli binu” (I Awọn Ọba 16:33).

A o kẹkọ pupọ lara Woli Elijah, ẹni ti o ṣe olootọ si Ọlọrun, ti ọrọ ẹṣẹ ati ibọriṣa ni Isarẹli ba lọkàn jẹ gidigidi. Lai ṣe ojusaju eniyan, o kede fun ọba yi ni ọjọ kan pe: “Bi OLUWA Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, ki yio si iri tabi ojo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi” (I Awọn Ọba 17:1). Ohun kan ni ilepa Elijah: a gbọdọ mu ẹṣẹ kuro, oun si mura lati jiya bi awọn Ọmọ Israẹli yoo ba tipa bẹẹ yipada sọdọ Ọlọrun.

A Dawọ Ojo Duro

Ọkan wa ti yọ to nitori awọn eniyan Ọlọrun ti ko bẹru lati mu iduro wọn fun otitọ! Mose na ọpa rè̩ si oju okun, omi si pinya (Ẹksodu 14:21); ọkunrin miran, Joṣua paṣẹ fun oorun ati oṣupa, wọn si duro jẹ. Elijah sọrọ, a si dawọ ojo ati iri paapaa duro patapata. O mọ wi pe Ọlọrun yoo fawọ ojo sẹhin; ṣugbọn a o dan igbagbọ rè̩ wo. Nigba ti ọda ba de, ounjẹ ki i to; ti iyan ba si mu ni ilẹ Israẹli, ko le ṣai kan oun naa. Elijah, o le gbẹkẹle Ọlọrun bi?

Nigba ti ilẹ bẹrẹ si i gbẹ ti ounjẹ si bẹrẹ si i wọn, Ọlọrun wa lọdọ rẹ lati sọ fun un ibi ti o yẹ ki o lọ. Ọba buburu yi ti n wa Elijah kiri. Ọba naa ko ni ṣai sọ fun un pe “Iwọ ni o fa gbogbo ọda yi.”

A fi Elijah pamọ ni alaafia kuro lọwọ ọba lẹba ipa odo kan ti n ṣan ti o si mọ gaara. Nibẹ o n mu omi lati inu odo naa, o si n jẹ akara pẹlu ẹran ti awọn ẹyẹ iwo n gbe wa fun un loroowurọ ati ni alaalẹ. O da wa loju pe Ọlọrun ni O ṣakoso awọn ẹyẹ iwo naa si ibi ti wọṅ ti le ri ounjẹ. S̩ugbọn, duro na, ọjọ iyiiriwo ṣi ku niwaju. Diẹ-diẹ omi odo ṣiṣan naa bẹrẹ si i gbẹ, titi o fi di ọjọ kan ti a ko tilẹ ri ikan omi kan nibẹ. Ẹn hẹn! Nipa ọrọ rẹ ni ojo ko fi rọ. Nisinsinyi iwọ naa ko ni ri omi mu mọ. Elijah, ko ha tan nidi rẹ bi?

Opo Kan ati Ọmọ Rè̩

A ko ro pe ọkan Elijah rẹwẹsi nigba ti o n duro de itọni Oluwa. Boya ọna-ọfun rè̩ ti lẹ mọ ara wọn oun si ti n fi ọkan ipoungbẹ wo isalẹ odo naa ti o ti gbẹ tan patapata ni akoko yi. S̩ugbọn ki o to pẹ jù ohun Ọlọrun fọ si i pe, “Dide, lọ si Sarefati ... ki o si ma gbe ibẹ; kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obirin opo kan nibẹ lati mā bọ ọ” (I Awọn Ọba 17:9).

“Irù ọkunrin kili eyi! Nitori o ba ... wi, nwọn si gbọ tirè̩” (Luku 8:25). Awọn ẹyẹ iwo ṣe ifẹ Ọlọrun; obinrin opo yi gbọran si aṣẹ Rè̩. Awọn ẹfuufu ati omi, gbogbo ilẹ, okun ati ofurufu, ati awọn ẹranko pẹlu, wọn n mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ. Afi awọn ẹlẹṣẹ nikan ni wọn kọ lati gbọ ti Rè̩!

Irin rẹ de Sarefati jẹ eyi ti o gun ti o si le ko aarẹ ara ba ni: boya o to ọgọrun ibusọ; eyi yoo gba pe ki o gbẹkẹle Ọlọrun fun ririn ibusọ kọọkan ninu ọna-ajo naa. Eniyan oniru iwa bi awa sa ni oun i ṣe, ti o mọ ebi ati oungbẹ bi ti wa loni (Jakọbu 5:17). S̩ugbọn bi o ti n wọ ilu lọ ni o ri obinrin opo yi ti o n ṣa igi. Aarẹ ti mu Elijah oungbẹ si ti gbẹ ẹ pupọ nitori irin-ajo naa, o si daju pe ebi ti pa a pupọ gidigidi, nitori bẹẹ o wi fun un pe, “J bu omi diẹ fun mi wa ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu.” Bi o ti n lọ, o tun ke si i, o wi pe, “J mu okele ounjẹ diẹ fun mi wa lọwọ rẹ.”

A San Ere fun Igbọran Rè̩

Lootọ o ni omi diẹ, ṣugbọn ounjẹ rè̩ ko to nkankan mọ. O wi fun un pe oun ko ni ju ikunwọ iyẹfun ninu ikoko ati ororo diẹ ninu kolobo eyi ti o n fẹ ṣe fun ara rè̩ ati ọmọ rè̩, “ki awa le jẹ ẹ, ki a si ku.” Elijah wa sọ ọrọ iṣiri meji wọnni ti a le ri kaakiri ninu Bibeli. Ninu Gẹnẹsisi 15:1 a ka a pe “Ma bẹru”; ninu Ifihan 1:17, “Maṣe bẹru.” Nigba pupọ ni a n ri ka ninu Bibeli pe, “Ma bẹru.” Ọpẹ wa ti pọ to fun ọrọ wọnni! O ko ha ro pe ọkan otoṣi opo yi yọ lati gbọ ọrọ itura wọnni?

O sure lati gbọ ti Elijah. O kọkọ ṣe akara kan wa fun un; lẹhin naa o ṣe omiran fun ara rè̩ ati ọmọ rè̩. O daju pe ti a ba n ro ọrọ ti ẹlomiran ṣaaju, a o ni ibukun Oluwa lori wa. Bẹẹ ni o si ri fun obinrin opo yi, nitori oun ati ọmọ rẹ ri ounjẹ jẹ tẹrun fun igba pipẹ. Titi iyan naa fi pari, iyẹfun ko tan ninu ikoko naa, bẹẹ ni ororo ko gbẹ ninu kolobo rè̩ (I Awọn Ọba 17:14-16). O ko ro pe tiyanutiyanu ni ọmọ kekere naa fi duro ti o n wo bi iya rẹ ti n bu iyẹfun jade lati inu ikoko naa, pe nibo ni gbogbo eyi ti wa? O ko ha si gbagbọ pe iya naa yoo sọ fun ọmọ rè̩ pe Ọlọrun ni n fi kun iyẹfun naa nitori pe oun ṣe Woli Rè̩ loore?

Idanwo Miran

Ni ọjọ kan ọmọ kekere naa ṣaisan, o si ku. Ọkọ obinrin yi ti ku tẹlẹ, ọmọ rẹ tun tẹle e bayi. O dabi ẹni pe n ṣe ni Oluwa doju ibinu kọ obinrin opo naa, ṣugbọn eyi kan ri bẹẹ ni lati fi han fun un pe ni tootọ, eniyan Ọlọrun ni Elijah i ṣe. Loju kan naa o lọ sọdọ Elijah fun iranwọ. Oun gba ọmọ naa o si gbe e lọ sinu iyara ti rè̩, o si tẹ ẹ sori ibusun rè̩. Idanwo miran niyi fun igbagbọ Elijah, ṣugbọn Ọlọrun ko i ti ja a tilẹ ri: o ti jẹ akara ati ẹran ti awọn ẹyẹ iwo gbe wa; o ti mu omi lati inu odo; o ti jẹun lori tabili obinrin opo naa.

Ninu iyara rè̩ o nikan gbadura tọkantọkan si Ọlọrun nitori ọmọ naa. Lẹẹkan si i ni akoko iṣoro yi Ọlọrun dahun adura rè̩ O si da ẹmi ọmọ naa pada. “Wò o, ọmọ rẹ ye” ni o wi nigba ti o gbe ọmọ naa pada fun iya rè̩. “Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ pe enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe ọrọ OLUWA li ẹnu rẹ, otitọ ni” (I Awọn Ọba 17:24). O ti woye pe o jẹ eniyan Ọlọrun nigba ti iyẹfun ati ororo pọ si i, ṣugbọn nisinsinyi o mọ pe Elijah jẹ eniyan Ọlọrun ni tootọ. Oju igbagbọ rè̩ ti riran kọja eniyan Ọlọrun yi si Ọlọrun ti o n sin. O daju pe Oun ni o ti ran Elijah si i, nitori a ka pe opo pipọ ni o wa ni Israẹli ni ijọ wọnni, nigba ti iyan nla mu ni ilẹ naa, ṣugbọn ko si ẹni kan ninu wọn ti a ran Elijah si (Luku 4:25). Ọlọrun mọ pe obinrin yi, ti o wa ni bebe ati ku yoo gbọran si aṣẹ Elijah. Ọlọrun ri ẹmi aimọ-ti-ara-ẹni-nikan ti o wa ninu ọkan rè̩, ati ẹmi imoore ati ifẹ ti yoo fi han fun Elijah. O mọ pe yoo ni igbagbọ si awọn iṣẹ iyanu ti eniyan Ọlọrun naa yoo ṣe. Bẹẹ naa ni o si ri.

Gbigbẹkẹle Ọlọrun

Obinrin kan jẹri ninu isin kan pe oun ko i ti ni anfaani ki ebi pa oun nitori Ihinrere. Ti a ba fi wa si ipo Elijah tabi obinrin opo ara Sarefati, a o ha le gbẹkẹle Ọlọrun? Jesu wi pe, “Ẹ kiyesi awọn iwo ... Ọlọrun sa mbọ wọn: melomelo li ẹnyin san ju ẹiye lọ?” “Ẹ kiyesi awọn lili ... Njẹ bi Ọlọrun ba wọ koriko igbẹ li aṣọ ... melomelo ni yio wọ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ kekere?” (Luku 12:24, 27, 28). Ileri fun ounjẹ ati aṣọ ni iwọnyi. A tun sọ fun ni pe: “Gbogbo irun-iyirun ori nyin li a ka pe ṣanṣan” (Matteu 10:30); “Nitorina ẹ ma foya, ẹnyin ni iye lori ju ọpọ ologoṣẹ lo” (Matteu 10:31). Ninu Orin Dafidi 147:9 a ka pe, “O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwo ti ndun.” Ti Ọlọrun ba n ṣe aniyan lori awọn ẹyẹ iwo, melomelo ni yoo pese fun aini awọn opo ati alaini baba (Orin Dafidi 146:9) ati fun gbogbo wa. Njẹ a le gbẹkẹle E nigba ti nkan ko ba lọ deedee fun wa?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni a sọ fun Elijah pe ki o lọ fi ara rè̩ pamọ si?
  2. Iru ẹyẹ wo ni o n gbe ounjẹ wa fun un?
  3. Sọ ẹsẹ Iwe Mimọ miran ti o sọ nipa awọn ẹyẹ wọnyi.
  4. Nibo ni a ran Elijah lọ nigba ti odo naa gbẹ?
  5. Kin ni o kọkọ tọrọ lọwọ obinrin opo naa? Kin ni o tun beere?
  6. Titi di akoko wo ni Elijah wi pe iyẹfun ati ororo naa yoo wa fun ilo obinrin yi?
  7. Sọ nkan ti o ṣẹlẹ nigba ti ọmọ obinrin opo naa ku.
  8. Kin ni idi rè̩ ti o fi ro pe ọdọ opo yi gan an ni a ran Elijah si?
2