I Awọn Ọba 18:1-46

Lesson 297 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi OLUWA ba ni Ọlọrun, ẹ mā tọ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni, ẹ mā tọ ọ lẹhin!” (I Awọn Ọba 18:21).
Notes

Iyàn Kan

Ni igba ijọba Ahabu, ọba Israẹli, iyan kan mu nitori pe Ọlọrun ko ran ojo tabi iri fun ọdun mẹta abọ. Idajọ Ọlọrun ni eyi. Iwa buburu Ahabu pọ pupọ jù ti ọbakọba ti o jẹ ṣiwaju rè̩ lọ. Ahabu ti fẹ obinrin keferi kan, ti orukọ rẹ n jẹ Jesebeli, o si gba a laye lati maa bọ oriṣa rè̩. Lai pẹ jọjọ Ahabu ati awọn Ọmọ Israẹli naa bẹrẹ si i bọ Baali. Ahabu ṣe pẹpẹ kan fun Baali, o si ṣe igbo oriṣa kan fun ibọriṣa. O ṣe ohun ti o buru ju ti gbogbo awọn ọba ti o ṣaaju rè̩ lọ lati mu Ọlọrun binu.

Elijah ni ẹni ti o sọ ọrọ ti Ọlọrun ran pe ki yoo si ojo. Nigba ti ọrọ wọnyi ṣẹ, awọn odo-ṣiṣan gbẹ, koriko rọ, ohun jijẹ ko to nkan mọ, Ahabu si bẹrẹ si wa Elijah. Ahabu wa gbogbo ilẹ naa jakejado. Ko si orilẹ-ède kan tabi ijọba kan ti a ko wa Elijah de. Bi o ba ṣe pe Ahabu ti wa Ọlọrun gẹgẹ bi o ti wa Elijah, ki o si ti ronupiwada, boya Ọlọrun i ba ti mu ki ojo tete rọ.

Obadiah

Ọkunrin kan wa ni ile Ahabu ti a n pe ni Obadiah, ẹni ti a le pe ni alabojuto ile Ahabu. Obadiah jẹ ẹni ti o bẹru Oluwa lati igba ewe rè̩. O ti fi ẹmi ara rè̩ wewu nipa fifi ọgọrun ninu awọn woli Oluwa pamọ ti o si n fun wọn ni ounjẹ ni akoko ti Jesebeli pa awọn woli Ọlọrun. Ni ọjọ kan Obadiah n wa koriko kiri fun awọn ẹṣin ati ibaka. Elijah fara han an o si ni ki o lọ sọ fun Ahabu pe Elijah wa nibẹ. Ni akọkọ Obadiah bẹru lati sọ fun Ahabu. S̩ugbọn nigba ti a fun un ni idaniloju pe Elijah yoo pade Ahabu, Obadiah lọ sọ ọrọ naa fun ọba.

A S̩eleri Ojo

Aṣẹ Ọlọrun ni Elijah n mu ṣẹ. Ahabu ko ri Elijah tẹlẹ nitori pe Ọlọrun ni o fi Elijah pamọ. Ọlọrun sọ ibi ti Elijah yoo lọ fun un ati ibi ti yoo ti ri ounjẹ ati omi ni akoko iyan naa. Nisinsinyi Ọlọrun ti fara han fun Elijah O si ti ṣeleri pe ojo yoo rọ. S̩ugbọn Oluwa sọ fun Elijah pe ki o lọ ri Ahabu. Elijah le bẹru lati jẹ ki Ahabu ri oun ṣugbọn nipa ṣiṣe eyi ni Ọlọrun yoo ran ojo.

Awọn Ileri Ọlọrun

Ọpọlọpọ ileri Ọlọrun ni o wà ninu Bibeli. Pẹlu awọn ileri wọnyi ni a fun wa ni awọn itọsọna ti a ni lati tẹle, ki a ba le ri awọn ileri wọnyi gba. Nigba ti a ba ṣe ohun ti Ọlọrun wi, nigba naa ni Ọlọrun yoo mu ileri Rè̩ ṣẹ. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ, ileri kan wa fun awọn ti o gbadura ti wọn si ni igbagbọ: “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ pe, ẹ ti ri wọn gba na, yio si ri bẹ fun nyin” (Marku 11:24). Ninu iwe Owe a kà nipa ohun ti a ni i ṣe ki a to ri aanu gba: “Ẹniti o bo ẹṣẹ rẹ mọlẹ ki yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ānu” (Owe 28:13). Wọnyi ni diẹ ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti n sọ nipa ohun ti a ni lati ṣe ki a to ri ileri naa gba: “Ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rè̩ le OLUWA li a o gbe leke” (Owe 29:25). “Ẹ rẹ ara nyin silẹ niwaju OLUWA, on o si gbe nyin ga” (Jakọbu 4:10); ati “Bère a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin” (Matteu 7:7). Bi o ba ṣe alaini ohun kan ti Ọlọrun ti ṣeleri, o le ni ohun naa nipa gbigbọran ati gbigba Ọlọrun gbọ. Ohun ti Ọlọrun ba ṣeleri, O lagbara lati ṣe e nigba ti a ba ṣe ipa ti wa ti a si ṣe ohun ti O beere.

Dida Ọlọrun ati Awọn Eniyan Rè̩ Lẹbi

Nigba ti Obadiah jiṣẹ fun Ahabu, o jade lati lọ pade Elijah. Ahabu fi ọrọ wọnyi ki Elijah: “Iwọ li ẹniti nyọ Israẹli li ẹnu!” Ahabu n gbiyanju lati ba Woli Ọlọrun wijọ pe oun ni o fa iyan naa. S̩ugbọn Elijah sọ ohun ti o mu wahala wa fun Ahabu: Ahabu ati awọn eniyan naa ti kọ ofin Ọlọrun silẹ, wọn si n sin oriṣa Baali. Nitori eyi ni a ṣe ran ijiya si wọn. Nigba ti wọn ṣaigbọran si Ọlọrun, a jẹ wọn niya fun un.

Nigba miran ni iru akoko yi awọn eniyan a maa da Ọlọrun lẹbi nigba ti idajọ ba de ba wọn nitori ẹṣẹ ati aigbọran wọn. Wọn si le maa gbiyanju lati di ẹbi naa le ori awọn eniyan Ọlọrun – nipa ohun kan ti wọn ti sọ tabi ti wọn ti ṣe. Bibeli wi bayi pe, “Idajọ OLUWA li otitọ, ododo ni gbogbo wọn” (Orin Dafidi 19:9). Nigba ti Ọlọrun ba fa ìyọnu Rè̩ sẹhin, idi kan wa ti o fi ri bẹẹ. Jẹ ki ẹni naa kọkọ wa ọkan rẹ ri; bi ọna rẹ ba mọ niwaju Ọlọrun, jẹ ki o mọ pe Ọlọrun n ṣiṣẹ lati mu ohun rere kan jade ninu igbesi-aye oun ni, nitori pe o mọ pe “ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pe gẹgẹ bi ipinnu rè̩” (Romu 8:28). S̩ugbọn nigba ti o ba wadi ọkan rè̩ niwaju Ọlọrun, bi o ba ni idalẹbi ti o si ri i pe oun ti ṣe ohun ti ko tọ, o ni lati jẹ olootọ to bẹẹ lati jẹwọ ikuna rè̩ ki o si beere pe ki Ọlọrun dariji oun. Bi ẹlomiran paapaa ba tilẹ ti sọ ọrọ tabi hu iwa ti ko ye ni, sibẹ ẹni ti nkan yi ṣẹlẹ si ni o jẹbi niwọn igba ti o ti kuna niwaju Ọlọrun.

Yiyan

Elijah mọ pe Ahabu ati awọn Ọmọ Israẹli ko le wa ninu ibọriṣa ati ẹṣẹ sibẹ ki wọn si ri ibukun Ọlọrun gba. Elijah mọ pe wọn ni lati pa ẹṣẹ ti o mu idajọ Ọlọrun wa si ori wọn run. Elijah n fẹ lati ran awọn Ọmọ Israẹli lọwọ. Ko sọ fun wọn pe bi wọn fẹ bi wọn kọ wọn ni lati sin Ọlọrun otitọ ati alaaye, ṣugbọn Elijah ni ki awọn eniyan naa yan eyi ti wọn fẹ. Elijah duro niwaju gbogbo awọn enyan naa o si wi pe, “Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi OLUWA ba ni Ọlọrun, ẹ mā tọ ọ lẹhin; ṣugbọn bi Baali ni ẹ mā tọ ọ lẹhin.”

Awọn ọrọ ti Elijah sọ yi yẹ ki o jẹ ipenija fun olukuluku loni. Awọn eniyan miran a maa gbiyanju lati ni inu-didun ninu ọna aye ki wọn si tun ni ifẹ si Ọlọrun; wọn a maa gbiyanju lati ni ibukun Ọlọrun ati igbadun ẹṣẹ aye papọ, ṣugbọn awọn mejeeji lodi si ara wọn a ko si le da wọn pọ. Ko ṣe e ṣe fun eniyan lati sin Ọlọrun ati mammoni. Yala yoo fẹ ọkan yoo si korira ekeji tabi yoo fara mọ ọkan yoo si yan ekeji ni ipọsi (Matteu 6:24). Awọn ti a ti gba ọkan wọn la a maa sin Ọlọrun nitori pe wọn fẹran Ọlọrun, wọn si ti yàn lati tẹle E. Awọn ti ki i ṣe eniyan Ọlọrun ti yan lati jẹ ọmọ eṣu. Ewo ni iwọ yàn?

Idanwo Kan

Elijah n fẹ ki awọn Ọmọ Israẹli wadi tikara wọn ki wọn si mọ tikara wọn pe Oluwa Oun ni Ọlọrun otitọ ati Ọlọrun alayè. Wọn ṣeto pe ki awọn aadọta-le-nirinwo woli Baali ru ẹbọ kan si ọlọrun wọn, ki Elijah – Woli Oluwa kan ṣoṣo – ru ẹbọ si Ọlọrun. Wọn ṣe adehun pe Ọlọrun ti o ba fi ina dahun ni wọn o gba ni Ọlọrun otitọ.

Awọn woli Baali ṣe eto ẹbọ wọn, wọn si ke pe orukọ Baali lati owurọ titi di ọsan gangan. “S̩ugbọn ko si ohun, bẹẹ ni ko si idahun.” Pẹlu itara gbigbona ni awọn woli Baali fi n ṣe e. Wọn fo sori pẹpẹ naa lati ru Baali soke. Sibẹsibẹ ko si idahun. Ni ọsan wọn tubọ kigbe kikan-kikan si ọlọrun wọn. Elijah ti sọ fun wọn pe o le jẹ pe Baali lọ si irin-ajo ni, tabi o sun o si yẹ ki wọn ji i. Ninu itara wọn awọn olusin Baali yi kigbe ni ohun rara ju bẹẹ lọ. Lai kọ ohun ti o le da, wọn fi ọbẹ ya ara wọn titi ẹjẹ fi tu jade lara wọn. Sibẹ ko si idahun, nitori pe oriṣa ni Baali i ṣe ko si le ran wọn lọwọ bi o tilẹ ṣe e ṣe paapaa pe ki o gbọ ohun wọn ki o si ri wọn. Awọn woli Baali fi titara-titara ṣafẹri rè̩ ṣugbọn ki i ṣe orukọ Ọlorun otitọ ati Ọlọrun alaaye ni wọn n ke pe -- Ẹni kan ṣoṣo naa ti ki i ṣe pe O n gbọ O si n ri nikan ṣoṣo, ṣugbọn ti O maa n dahun ti O si n ran ni lọwọ pẹlu.

Ina lati Ọrun

Ni igba ẹbọ aṣaalẹ o wa kan Elijah lati ke pe Ọlọrun pe ki O ran ina sọkalẹ. Elijah kiyesara lati tun pẹpẹ Oluwa ti wọn ti wo lulẹ kọ. O mu okuta mejila eyi ti o duro fun awọn ẹya Israẹli mejila lati fi kọ pẹpẹ fun orukọ Oluwa. O to awọn igi naa lẹsẹẹsẹ, malu ti o ti ge si wẹwẹ ni o to si ori rè̩. Ni ayika pẹpẹ naa, o wa yàrà tabi koto yi i ka. A da omi si ori ẹbọ naa, ati igi, ati pẹpẹ, omi naa si ṣan silẹ o si kun inu yàrà naa. Lẹhin ti ohun gbogbo ti wa leto ti a si ti ṣe e tan gẹgẹ bi aṣẹ Oluwa, Elijah gbadura. O ni ki Ọlọrun dahun adura oun, ki awọn eniyan naa ba le mọ pe Oluwa Oun ni Ọlọrun.

Lai si aniani awọn eniyan naa sun mọ tosi wọn si n wo o pẹlu gbogbo ọkan wọn. Njẹ Ọlọrun Elijah yoo dahun? Njẹ Ọlọrun yoo dahun adura ọkunrin kan nigba ti Baali ko dahun ti awọn aadọtalenirinwo woli rè̩? Njẹ Ọlọrun Elijah ni agbara lati ran ina wa lati Ọrun? Njẹ ẹbọ naa yoo jo lẹhin ti omi ti rin in to bayi? Boya wọn tilẹ n ro o ninu ọkan wọn pe bawo ni yoo ti pẹ to ti Elijah yoo fi ke pe Ọlọrun rè̩.

Bi awọn eniyan wọnyi ti duro nibẹ wọn ri i bi “ina OLUWA” ti bọ silẹ. Ati ẹbọ naa ati igi naa ni o jó patapata, ṣugbọn ina naa ko duro. O tubọ jo awọn okuta paapaa ati erupẹ, o si la omi ti o wa ninu yàrà naa gbẹ. Lotitọ iṣẹ iyanu yi ṣẹlẹ loju wọn. Ọlọrun Elijah lagbara lati ran ina sọkalẹ! Ọlọrun Elijah dahun adura rè̩! Awọn eniyan naa foribalẹ fun Oluwa wọn si wi pe, “OLUWA, on li Ọlọrun; OLUWA on li Ọlọrun.”

Wọn ni lati pa awọn woli Baali nitori pe awọn ni o n ru ọkan awọn eniyan soke ti wọn si n ran wọn lọwọ lati sin ọlọrun eke. Bi o ba ṣe pe wọn da awọn woli Baali si, boya wọn o tun yi ọkan awọn eniyan pada lati kọ Ọlọrun ki wọn si lọ sin oriṣa.

Ojò

Kin ni ṣe ti Elijah ṣe gbogbo nkan yi? Lati mu ẹṣẹ ti o fa idajọ Ọlọrun wa kuro ni. Nigba ti a ṣe eyi awọn eniyan naa le reti ojò ti a ṣeleri. Elijah sọ fun wọn pe ọpọ ojo n bọ. Wọn gba Elijah gbọ wọn si gbọran si aṣẹ rè̩.

Nigba ti Ahabu lọ lati jẹ ati lati mu, Elijah gbadura. Ọlọrun ti ṣeleri lati ran ojò, ṣugbọn ipa ti Elijah sibẹ ni lati gbadura. Ki a ba le ri ileri Ọlọrun gba loni awọn eniyan Ọlọrun ni lati tubọ gbadura si i. Lẹhin ti wọn ba ri igbala, wọn a gbadura pe ki a sọ wọn di mimọ. Jesu gbadura pe ki a sọ awọn eniyan Rè̩ di mimọ (Johannu 17:17-20); a si ka a pe, “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwa ni mimọ nyin” (I Tẹssalonika 4:3). S̩ugbọn awọn eniyan Ọlọrun ni lati gbadura ki wọn si ṣe ifararubọ aye wọn fun Un ki wọn ba le ri i gba. Lẹhin ti wọn ba ti ri isọdimimọ, wọn ni lati beere lọwọ Ọlọrun pe ki O fi Ẹmi Mimọ wọ wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 1:5). A ti ṣeleri iriri yi pẹlu fun ni (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8; Johannu 14:16, 26; 15:26; 16:7), ṣugbọn awọn ti o ri i gba ri i gba nitori pe wọn fi gbogbo ọkan wọn gbadura wọn si gba Ọlọrun gbọ.

Gbigbadura

Nibẹ lori Oke Karmẹli, Elijah wolẹ niwaju Oluwa o si gbadura. Lẹhin eyi o ran iranṣẹ rè̩ lati lọ wo bi o ba ri apẹẹrẹ pe ojò fẹ rọ. Ko si apẹẹrẹ kan. Nitori naa Elijah gbadura siwaju ati siwaju. Lẹhin ti Elijah ti gbadura ni igba keje, iranṣẹ rè̩ ni oun ri ikuuku kan ti o to iwọn ọwọ eniyan. Eleyi to fun Elijah ni ami pe Ọlọrun n ran ojò bọ. O ranṣẹ si Ahabu pe, “Di kẹkẹ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki ojò ki o ma ba da ọ duro.”

Lori Oke Karmẹli kan naa ni Elijah ti gbadura ti Ọlọrun si ran ina lati Ọrun. Ohun abami ni eyi, ṣugbọn Ọlọrun dahun adura Elijah ki awọn eniyan naa ba le gbagbọ pe Oluwa Oun ni Ọlọrun. Elijah ni lati gbadura nigba meje ki Ọlọrun to ran ojò. Elijah jẹ apẹẹrẹ rere fun wa. O gbadura titi o fi ri eyi ti Ọlọrun ṣeleri gba. Ikuuku naa kere lọpọlọpọ bẹẹ ni fun ọdun mẹta abọ ni ko ti si ojò, ṣugbọn Elijah gba Ọlọrun gbọ nitori naa a dahun adura rè̩.

Elijah Olootọ

Ki wọn to de ilu, oju ọrun ti ṣu dudu fun ikuuku ati iji. Ọpọlọpọ ojò ti ilẹ ati awọn eniyan ti n fẹ si rọ. Awọn eniyan naa ri ibukun nipa ti ẹmi ati ti ara gba nitori pe Elijah fẹ lati gbọran si aṣẹ Ọlọrun o fi igboya duro niwaju Ahabu eniyan buburu, o si fi ikiya pa awọn woli Baali. A bu ọla fun Ọlọrun a si tun mu awọn eniyan naa pada nitori pe Elijah mu iduro rè̩ fun Oluwa ati otitọ -- ọkunrin kan ṣoṣo laarin aadọtalenirinwo woli Baali.

Tani mọ ohun ti a le ṣe fun Oluwa ati fun awọn ẹlomiran bi olukuluku ọmọkunrin ati ọmọbinrin ni Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi yoo ba gbọran si aṣẹ Ọlọrun ki o si mu iduro rè̩ fun ohun ti o tọ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Iru ọba wo ni Ahabu?
  2. Kin ni ṣe ti ojò ko si?
  3. Tani Elijah i ṣe?
  4. Bawo ni awọn woli Baali ti ṣe ke pe ọlọrun wọn?
  5. Kin ni ṣe ti Baali ko dahun?
  6. Sọ nipa adura Elijah?
  7. Tani awọn eniyan naa yan?
  8. Kin ni ṣe ti o fi yẹ lati pa awọn woli Baali?
  9. Kin ni ṣe ti Elijah tun gbadura lẹhin ti Ọlọrun ti ṣeleri lati ran ojò?
  10. Ami wo ni o fara han pe ojò yoo rọ?
2