Lesson 298 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA Ọlọrun mi, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le; gbà mi lọwọ gbogbo awọn ti nṣe inunibini si mi, ki o si yọ mi kuro” (Orin Dafidi 7:1).Notes
Irohin
Ahabu sọ ohun ti o ṣẹlẹ ni Oke Karmẹli fun Jesebeli. A ko ka pe Ahabu sọ fun un nipa ohun ti Ọlọrun ti ṣe bi ko ṣe ohun ti Elijah ti ṣe. Ahabu rohin pe Elijah “ti fi ida pa gbogbo awọn woli.” Ahabu wi pe, “gbogbo awọn woli” bi ẹni pe awọn nikan ni woli, ati bi ẹni pe wọn tọ si ọlá ti o yẹ awon woli tootọ. Woli eke ni gbogbo awọn aadọtalenirinwo (450) woli Baali wọnnì jẹ. Wọn ti ṣi awọn eniyan lọna kuro ninu ijọsin otitọ. Pipa ni o tọ ki a pa wọn, gẹgẹ bi ofin ti sọ: “Ati woli na ... ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sọ iṣọtẹ si OLUWA Ọlọrun nyin ... lati tì ọ kuro li oju ọna ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rin ninu rè̩” (Deuteronomi 13:5).
Ahabu ko gbe ọwọ le Elijah ṣugbọn o sọ fun Jesebeli, obinrin buburu ti o mọ pe yoo wa ọna ati jẹ Elijah niya. Ko ha jẹbi riru ti o ru ibinu Jesebeli soke lati ṣe inunibini si Elijah? O ṣe e ṣe ki awọn ọmọde kan má jale ṣugbọn ki wọn kin awọn ọmọde miran lẹhin lati jale; o ṣe e ṣe ki ọmọde kan má purọ, ṣugbọn ki o wi pe ki ọmọde miran lọ purọ; nitori naa wọn o jọ ru ẹbi naa ni. Ọrọ ti Ahabu sọ ru ibinu obinrin buburu yi soke si Ọlọrun ati Woli Ọlọrun gẹgẹ bi irohin miran lode oni ti i maa mu ki awọn eniyan ba Ọlọrun ja ki wọn si dẹṣẹ. I ba jẹ ye wa pe irohin nipa Oluwa ti a n sọ fun awọn ẹlomiran le sun wọn yala lati wa Ọlọrun tabi lati ṣiyemeji Rè̩! Dafidi gbadura pe ki ọrọ ẹnu oun le ṣe itẹwọgba ni oju Oluwa (Orin Dafidi 19:14).
Ihalẹ
Ọkan Jesebeli bajẹ, o si pinnu lati gbẹsan. Oun ko ni ṣai mọ pe a ti doju ti Baali oriṣa rè̩. Sibẹ ko jẹ gba wi pe oun ti ṣina nipa ẹsin rè̩ bẹẹ ni ko dẹkun ati maa ṣe inunibini si awọn woli Ọlọrun. Jesebeli ranṣẹ si Elijah pe, ki wakati mẹrinlelogun to kọja, oun o pa Elijah bi o ti pa awọn woli eke rè̩. Idanwo ni ihalẹ Jesebeli yi jẹ fun Elijah. Nipa agbara Oluwa, o ti ni iṣẹgun nlá nlà lori Oke Karmẹli. Nigba pupọ, lẹhin iru iṣẹgun bi eyi, idanwo nla ni o maa n tẹle e.
Eniyan i ba ro pe lẹhin ti Ọlọrun ti dahun adura Elijah nipa riran ina ati ojò, o yẹ ki o le gbẹkẹle Ọlọrun. A le nireti pe ki Elijah ranti bi Ọlọrun ti duro ti awọn ẹlomiran nigba ti ẹmi wọn wa ninu ewu. Ọta Mose ati awọn Ọmọ Israẹli ti pinnu pe pipa ni oun o pa wọn run (Ẹksodu 15:9), ṣugbọn Ọlọrun gbe iranwọ dide O si la ọna silẹ fun wọn lati sa asala. Saulu jowu Dafidi pupọ, to bẹẹ ti o fi gbiyanju lati pa a (I Samuẹli 18:10, 11). Ọlọrun ran Dafidi lọwọ lati yẹ Saulu silẹ, o si bọ.
Adura
Boya Elijah ranti pe Ọlọrun ti sọ fun oun lati lọ kuro nigba ti Ahabu n lepa rè̩ (I Awọn Ọba 17:3). Ihalẹ Jesebeli obinrin buburu nì fi ibẹru sọkan Elijah o si “lọ fun ẹmi rè̩.” O dabi ẹni pe Elijah ko gbadura, o kan sa lọ fi ara rè̩ pamọ ni.
Ohun ti o yẹ ki Elijah ti ṣe ni lati gbadura ati lati beere lọwọ Ọlọrun ohun ti o yẹ ki oun ṣe. Bi a ti n ba ẹkọ yi lọ a o ri pe ki i ṣe ifẹ Ọlọrun fun Elijah lati sa. Oluwa ni iṣẹ fun Elijah, ki i si i ṣe ibi iho lori oke ni iṣẹ naa wa. Bi o ba ṣe pe Elijah ti gbadura, Ọlọrun i ba ti sọ fun Elijah ohun ti o yẹ ki o ṣe. Ọlọrun le mu irẹwẹsi kuro ti a ba gbẹkẹle E. Ẹ jẹ ki a kọ ẹkọ yi nipa igbesi aye Elijah – lati maa gbadura nigba gbogbo. Nigba miran Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ sọrọ. Nigba miran è̩wẹ, Oun a fẹ ki wọn dakẹ jẹẹ. Ki a ba le maa mọ ifẹ Ọlọrun, ẹ jẹ ki a ranti lati maa gbadura. Nigbakuugba ti o ko ba ni idaniloju, gbadura ki o si beere pe ki Ọlọrun tọ ọ. Onipsalmu wi pe, “Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi iku” (Orin Dafidi 48:14).
Ninu Aginju
Elijah rin lọ si ọna jijin kuro ni Jesreeli nibi ti Jesebeli n gbe. O sa lọ si Beerṣeba, ilu kan ni ilẹ Juda, ti o jẹ ọpọlọpọ ibusọ si iha gusu. Lati ibẹ o rin irin ọjọ kan sinu aginju. Bi Elijah ti joko labẹ igi juniperi kan, inu rè̩ ko dun rara, nitori pe ki i ṣe ibi ti Ọlọrun ti n fẹ ẹ ni o wa. O wa pinnu pe kiku ni oun n fẹ ku bayi. Wo ẹni ti o ti sa pe ki Jesebeli ma ba gba ẹmi rè̩; nisinsinyi iku ni o n fẹ ku bayi.
Awọn Angẹli ti n ṣe Iranṣẹ
Oluwa mọ ibi ti Elijah wa, ati pe o n fẹ iranwọ. Oluwa fi ounjẹ ran angẹli kan si Elijah, o jẹ akara ti a din lori ẹyin ina. O mu omi lati inu igo pẹlu. Ninu agbara ounjẹ yi Elijah tẹ siwaju ninu irin-ajo rè̩ ninu aginju fun ogoji ọjọ. Njẹ o le sọ ọna meji miran ti Oluwa gba fi bọ Elijah? (Wo I Awọn Ọba 17:6, 13-16).
Ọlọrun a saba maa ran awọn angẹli Rè̩ lati ran awọn eniyan Rè̩ lọwọ. Nigba ti Mose ati awọn Ọmọ Israẹli n jade lọ kuro ni ilẹ Egipti, Oluwa ran angẹli kan lati ran wọn lọwọ (Ẹksodu 14:19; 23:20). Oluwa ran angẹli kan lati di ẹnu awọn kinniun nigba ti a gbe Daniẹli sọ sinu iho wọn (Daniẹli 6:23). Angẹli kan gba Peteru, ati awọn ọmọ-ẹhin iyoku silẹ ninu tubu (Iṣe Awọn Apọsteli 12:7; 5:19). Awọn angẹli ṣe iranṣẹ fun Jesu nigba ti O wa ni iju (Marku 1:13). Nigba ti Lasaru alagbe ku, awọn angẹli ni wọn gbe e lọ si ookan-aya Abrahamu (Luku 16:22). A le ma fi igba gbogbo ri awọn angẹli naa, ṣugbọn Ọlọrun a maa ran wọn lọ lati maa ran awọn eniyan Rè̩ lọwọ (Heberu 1:14). A ka ninu awọn Psalmu pe, “Yio fi aṣẹ fun awọn angẹli rè̩ nitori rẹ, lati pa ọ mọ li ọna rẹ gbogbo. Nwọn o gbé ọ soke li ọwọ wọn, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbun okuta” (Orin Dafidi 91:11, 12).
Ninu Iho
Elijah sa lọ si Horebu, tabi Oke Sinai, “oke Ọlọrun.” Nibẹ ni o gbe fi ara pamọ ninu iho kan. Ko si ẹlomiran ti o wa lọdọ Elijah: ko ṣe iṣẹ kankan, o si daju pe inu rè̩ ko le dun pupọ bayi. Jesebeli ti mu un rẹwẹsi. Ọrọ ti o sọ ni o ba a lẹru ti o fi sa. A ti dí iṣẹ rè̩ fun Oluwa lọwọ, o si kaanu fun ara rè̩. Bi Elijah ti fi ara pamọ sinu iho nì, bẹẹ ni iji kan bẹrẹ si i ja. Ẹfuufu naa ja to bẹẹ ti o fi fọ awọn apata tuutuu. Lẹhin eyi isẹlẹ kan mi ibi ti Elijah sa pamọ si. Lẹhin eyi iná bẹrẹ si i jo. Lẹhin eyi, o gbọ Ohun kẹlẹ kekere kan, Elijah si mọ pe Oluwa ni Ẹni ti n sọrọ naa.
Mose
Iru iriri kan naa ni awọn Ọmọ Israẹli ati Mose ni nigba ti Oluwa fun wọn ni Ofin Mẹwa. Awọn eniyan jade lati ibudo wa lati ba Ọlọrun pade. Gbogbo oke naa si jẹ kiki eefi “nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rè̩ ninu ina” (Ẹksodu 19:18). Isẹlẹ kan sẹ eyi ti o mu gbogbo oke mi titi. Ipe kan dun kikankikan o si milẹ kijikiji. Mose ba Ọlọrun sọrọ, ohun Ọlọrun si pe Mose lati gun ori oke naa lọ pade Rè̩. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ri manamana ati eefi ti o bo oke naa, ti wọn si gbọ ara ati ohun ipe, jinnijinni mu wọn, wọn si bi sẹhin. S̩ugbọn “Mose si sunmọ ibi okunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbe wà” (Ẹksodu 20:21). Nigba ti Ọlọrun n ba Mose sọrọ ti O si fun un ni Ofin Mẹwa, “Ogo OLUWA si sọkalẹ sori oke Sinai” (Ẹksodu 24:16). Awọn Ọmọ Israẹli duro ni okere rere, ṣugbọn Mose ba Ọlọrun duro.
Ohun Kẹlẹ Kekere
Bi o tilẹ jẹ pe Jesebeli ko ri Elijah, Ọlọrun ti rii. Oluwa mọ ibi ti Elijah wa, O si mọ ibi ti ọmọ Rè̩ kọọkan wa pẹlu. Ni akoko miran, Oluwa sọ bayi: “Ẹnikẹni le fi ara rẹ pamọ ni ibi ikọkọ, ti emi ki yio ri i ... Emi ko ha kún ọrun on aiye?” (Jeremiah 23:24). Dafidi sọ pe ibikibi ti o wu ki oun lọ, Oluwa wà nibẹ: “Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ otun rẹ yio si di mi mu” (Orin Dafidi 139:9, 10). Nibikibi ti a ba lọ ni Oluwa wa lati ba wa sọrọ, lari ran wa lọwọ, ati lati ki wa laya.
Lẹhin ariwo iji, mimi isẹlẹ, ati tita ti ina ta, Elijah gbọ Ohun kẹlẹ kekere ti Ọlọrun. Elijah mọ pe Ọlọrun ni O ni Ohùn naa. O duro niwaju Oluwa tọwọtọwọ, o si tẹtisilẹ.
Awọn ẹlomiran ti gbọ Ohùn kẹlẹ kekere ti Ọlọrun pẹlu, ṣugbọn ko ye awọn miran pe Oluwa ni O sọrọ. Nigba ti Ọlọrun pe Samuẹli ni orukọ, oun ko mọ pe Oluwa ni O pe oun titi Eli fi sọ fun un pe Ọlọrun ni O pe e lorukọ. (Wo Ẹkọ 200). Oluwa ba Saulu sọrọ nigba ti o n lọ si Damasku. Saulu gbọ ti Oluwa wi pe “Saulu, Saulu ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?” (Iṣe Awọn Apọsteli 9:4). Kẹkẹ pa mọ awọn ọkunrin ti wọn n ba Saulu lọ lẹnu nigba ti wọn gbọ Ohun naa ti wọn ko si ri ẹni kan, ṣugbọn o wa ye Saulu pe Ọlọrun ni O n ba oun sọrọ. Ẹni ti o bẹrẹ iṣẹ Ihinrere Igbagbọ Apọsteli, Florence L. Crawford gbọ nigba ti Ohun kẹlẹ kekere naa n sọ pe “Ọmọbinrin fi ọkan rẹ fun Mi” bi o ti n jo ni ile-ijo. Ọlọrun ti ba awọn miran sọrọ nipa sisọ ẹsẹ Iwe Mimọ fun wọn. Ohùn Ọlọrun ti kilọ fun awọn miran nipa ẹri ọkan wọn. Boya Oluwa ti fi Ohun kẹlẹ kekere ba ọ sọrọ. Boya ọwọ rẹ ti di to bẹẹ ti o ko fi eti silẹ tabi ti o ko tilẹ mọ pe Oluwa n ba ọ sọrọ.
A Ran an Ni Iṣẹ
Elijah mọ pe Ọlọrun ni O n sọrọ. O duro niwaju Oluwa lati gbọ ọrọ Rè̩ gẹgẹ bi Mose ti duro niwaju Oluwa nigba ti a pe e lati lọ gba awọn Ọmọ Israẹli la kuro ninu igbekun Egipti. Ibi yi gan an ni Mose ti wá, “Horebu, oke-Ọlọrun,” nigba ti o yipada si apa kan lati wo igbẹ ti n jo ati lati gbọ Ohun Ọlọrun (Ẹksodu 3:1-4).
Elijah gbọ ti Ọlọrun wi pe, “Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah?” Ni idahun, Elijah bẹrẹ si i ṣe awawi o si gbiyanju lati ṣe alaye idi rè̩ ti oun fi sa pamọ sinu iho. O wi pe awọn Ọmọ Israẹli ti jẹ ki a pa awọn woli Oluwa tootọ ti o ṣẹku ati pe Jesebeli ti leri lati pa oun, nitori bẹẹ ni oun ṣe sa. Oluwa sọ fun Elijah pe ọọdẹgbaarin (7,000) eniyan ṣi wà ni Israẹli ti wọn jẹ olootọ ti wọn ko sin Baali.
Oluwa ni iṣẹ fun Elijah lati ṣe. A paṣẹ fun Elijah lati kun fun iṣẹ dipo ki o maa fara pamọ. Iṣẹ mẹta ni Ọlọrun ran Elijah lati ṣe: ki o fi ororo yan Hasaeli ni ọba lori Siria; ki o fi ororo yan Jehu ni ọba lori israẹli, ki o si fi ororo yan Eliṣa lati jẹ Woli ti yoo gba ipo Elijah. Elijah ko le ṣe iṣẹ yi nigba ti o joko sinu iho. Lẹhin ti o ti ba Oluwa sọrọ, ko ni ẹmi irẹwẹsi mọ. Nigba ti ọwọ Elijah kun fun iṣẹ ti o si wa ni aye ti o fi le ṣiṣẹ fun Ọlọrun, irẹwẹsi rè̩ fo lọ.
Oluwa ni iṣẹ fun awọn eniyan Rè̩ loni. Inu Rè̩ ko dun pe ki wọn maa fara pamọ tabi ki wọn joko lasan lai ṣe nkankan. Inu Rè̩ ko dun pe ki ọkan wọn rẹwẹsi. Ranti pe nigba ti irẹwẹsi mu awọn Ọmọ Israẹli ni ọna, wọn kun wọn si dẹṣẹ nipa sisọrọ si Ọlọrun ati Mose (Numeri 21:4-7). Fun idajọ wọn, a ran ejo amubina saarin wọn, pupọ ninu awọn Ọmọ Israẹli si ku (Wo Ẹkọ 108).
O maa n dun mọ Ọlọrun ninu nigba ti awọn eniyan Rè̩ ba wa nidi iṣẹ Rè̩. Ifẹ Rè̩ ni pe ki awọn eniyan Rè̩ maa gbadura fun itọsọna ninu ohun gbogbo ati nigba gbogbo. Jesu ni apẹẹrẹ wa. Nigba ti Jesu wa ni ọmọde, O wi pe, “Emi ko le ṣaima wa nibi iṣẹ Baba mi” (Luku 2:49). Nigba ti Jesu di ọdọmọkunrin, O wi pe: “Emi ko le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o ran mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ wa nigbati ẹnikan ki o le ṣe iṣẹ” (Johannu 9:4). Anfaani wa nisinsinyi fun awọn ọmọ Ọlọrun lati ṣiṣẹ fun Un, ati lati jẹ ọmọ-lẹhin Oluwa ni tootọ. O ti wi pe, “Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e” (Oniwasu 9:10).
Questions
AWỌN IBEERE- Irohin wo ni Ahabu sọ fun Jesebeli?
- Kin ni Jesebeli leri lati ṣe fun Elijah?
- Kin ni mu ki Elijah sa lọ si iju?
- Bawo ni Angẹli Oluwa ti ṣe ran Elijah lọwọ?
- Nibo ni Elijah fara pamọ si?
- Ọna wo ni Ọlọrun gba fi ba Elijah sọrọ?
- Ẹlomiran wo ni o ti gbọ Ohun Ọlọrun ni iru ọna bayi?
- Kin ni Ọlọrun sọ fun Elijah?
- Kin ni ṣe ti irẹwẹsi mu Elijah?
- Iṣẹ wo ni Oluwa ni fun Elijah lati ṣe?