I Awọn Ọba 20:1-43

Lesson 299 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ ọ silẹ” (I Awọn Ọba 20:11).
Notes

Igbagbọ Lai Si Ironupiwada

Ninu idanwo Elijah lori Oke Karmẹli, Ọlọrun ti fi ara Rè̩ han pe Oun ni Ọlọrun otitọ ni Ọrun ati ni aye nipa riran ina sọkalẹ lati Ọrun lati jo ẹbọ naa ti Elijah ṣe. Nigba ti gbogbo Israẹli n wi pe “OLUWA On li Ọlọrun,” lai si aniani Ahabu naa yoo wi bẹ pẹlu. S̩ugbọn Ahabu ko ronupiwada.

Ọpọlọpọ eniyan ni o gbagbọ pe Ọlọrun kan wa; awọn miran a tilẹ gbadura si I nigba ti wọn ba wa ninu wahala. S̩ugbọn niwọn igba ti wọn ko ba ronupiwada ẹṣẹ wọn, wọn ki i ṣe Onigbagbọ. Awọn miran tilẹ wi pe awọn gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe, ṣugbọn wọn n ṣe bi o ti wu wọn sibẹ, wọn ko si ni ki ẹnikẹni dariji wọn. Ọmọ Ọlọrun tootọ ni ẹni ti ki i ṣe wi pe o gba Ọlọrun ayeraye ati Ọmọ mimọ Rè̩ gbọ nikan ṣoṣo, ṣugbọn ẹni ti o mọ pe oun ti dẹṣẹ si Ọlọrun mimọ yi ati pe oun ni lati ronupiwada ki a si gba oun la kuro ninu ẹṣẹ oun.

Anfaani Miran

Ọlọrun fun Ahabu ni anfaani miran. Lẹẹkan sii Ọlọrun yoo fi han fun Ahabu pe gbogbo agbara ni Ọrun ati ni aye wa ni ọwọ Oun.

Bẹnhadadi, Ọba Siria, gba ogun nlá nlà jọ pẹlu ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹkẹ ẹṣin, o si do ti ilu Samaria. Ọba mejilelọgbọn (32) ni o wa pẹlu ogun rẹ, gbogbo wọn si mura tan lati ba Israẹli ja. Ni akoko yi Samaria ni olu-ilu ẹya mẹwa ni Israẹli lori eyi ti Ahabu ati Jesebeli n ṣakoso.

Ibẹru Ọlọrun a maa sọ eniyan di akọni, ṣugbọn ibẹru eniyan a maa sọ eniyan di ojo. Ojo ni Ahabu; nigba ti Bẹnhadadi beere owo-ode, ati ẹbi Ahabu paapaa, Ahabu fi ibẹru-bojo wi pe, “Oluwa mi, ọba, gẹgẹ bi ọrọ rẹ tirẹ li emi, ati ohun gbogbo ti mo ni.”

Ahabu ni a pe ni alakoso awọn ayanfẹ Ọlọrun, ṣugbọn ko tilẹ beere pe ki Ọlọrun ran oun lọwọ. Bawo ni ijọba rè̩ i ba ti yatọ to bi o ba ṣe pe o gbadura bi ti Sọlomọni pe: “Fi ọkan imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ to yi?” (I Awọn Ọba 3:9).

Nigba ti Bẹnhadadi rii pe Ahabu jọwọ silẹ kiakia bẹẹ, o tun beere ohun ti o pọ jù bẹẹ lọ. S̩ugbọn ni igba yi o wa beere ju ohun ti Ahabu le fi silẹ lọ. Kin ni Ahabu le ṣe? Awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Siria ti o pọ lọpọlọpọ ni o yi awọn odi ilu ka yi, ninu odi yi si ni Ọba Israẹli ati awọn eniyan rè̩ ti è̩ru n bà wà.

Itọju Ọlọrun fun Awọn Eniyan Rè̩

Ahabu pe awọn agbaagba ni Israẹli jọ fun amọran. O ni lati jẹ pe wọn ni igbagbọ ninu Ọlọrun nitori pe wọn fi igboya sọ fun Ahabu pe ki o ma ṣe fi eti si ti Bẹnhadadi; jade lọ ki o si lọ ba ọba alaiwa-bi-Ọlọrun yi ja. Lai si iranlọwọ Ọlọrun fifi ọwọ ara ẹni pa ara ẹni ni eyi i ba yọri si, ṣugbọn Ọlọrun n ṣọ ẹṣọ lori Israẹli awọn eniyan Rè̩ sibẹ bi o tilẹ jẹ pe eniyan buburu ni o n ṣakoso wọn.

Nigba ti Ahabu ranṣẹ pada si Bẹnhadadi pe oun ki yoo ṣe ohun ti o wi, Bẹnhadadi binu lọpọlọpọ. S̩ugbọn ninu igberaga rè̩ o ṣi ni ero pe oun le ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli diẹ ti wọn wa ni Samaria. Ko ha ni ẹgbẹ ogun nla pẹlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ ẹṣin, ko ha si awọn ọba meji-le-lọgbọn pẹlu rẹ? Boya o tilẹ fi Ahabu rẹrin ẹlẹya pe o ro pe o le ba oun jà. Bẹnhadadi fi ọkan buburu sọ fun Ahabu pe gbogbo awọn ọmọ-ogun israẹli ni yoo fi idanu wọn tẹle oun paapaa bi a ba fun wọn ni aye lati yan.

Idahun Ahabu wa di owe: “Má jẹ ki ẹniti nhamọra ki o halẹ bi ẹniti o mbọ ọ silẹ.” O fẹrẹ jẹ bakan naa pẹlu owe yi, “Máṣe ṣiro iye ti oromọ-adiẹ rẹ yio jẹ titi di igba ti awọn ẹyin ti adiẹ rẹ yé yoo pamọ.” Jẹ ki Bẹnhadadi duro ki o si fi oju ara rè̩ rii bi awọṅ eniyan naa yoo ba tẹle oun. Ọlọrun ki yoo jẹ ki ọba Keferi yi bori awọn eniyan Rè̩, nitori naa O ran woli kan lati sọ fun Ahabu pe ki o mura ogun; O si ṣeleri pe iṣẹgun yoo jẹ ti Ahabu. Ki yoo jẹ nipa agbara Ahabu ati awọn ọmọ-ogun rè̩, ṣugbọn Ọlọrun yoo fi agbara Rè̩ han lẹẹkan si i gẹgẹ bi Oluwa Ọlọrun.

Imutipara

Awọn ọmọ-ogun Bẹnhadadi pọ, o si gbẹkẹle ọpọlọpọ awọn ọmọ-alade rè̩ ati awọn ọmọ-ogun rè̩ lati fun un ni iṣẹgun. Ninu idaniloju ọkan wọn, oun ati awọn ọmọ-alade rẹ bẹrẹ si i mu ọti, wọn si mu un titi wọn fi mu amupara. Ọpọlọpọ ogun ni awọn ọmọ-ogun ti kuna ninu rè̩ nitori pe ọti mimu ti mu ki ọpọlọ awọn ọgagun di alailera. Awọn orilẹ-ède paapaa ti ṣubu lulẹ nitori imutipara awọn alakoso wọn. Ọkunrin ọlọgbọn nì ti fun wa ni amọran bayi: “Iwọ maṣe wo ọti-waini pe o pọn, nigbati o ba fi àwọ rè̩ han ninu ago ... Nikẹhin on a buniṣan bi ejo, a si bunijẹ bi paramọlẹ” (Owe 23:31, 32).

Nigba ti awọn ọmọ-ogun Israẹli kọlu awọn ẹgbẹ ogun nla Siria, wọn ko tilẹ ja rara. Ẹni kọọkan ninu awọn ọmọ-ogun Israẹli pa ọmọ-ogun Siria kan, Bẹnhadadi ati awọn ọmọ-ogun iyoku si sa asala fun ẹmi wọn.

Ọlọrun Afonifoji ati Oke

Ọlọrun ti fun Israẹli ni iṣẹgun; ṣugbọn eyi ki i ṣe idanwo ikẹhin fun Israẹli. Woli naa tọ Ahabu wa o si wi fun un pe lẹhin ọdun kan awọn ọmọ-ogun Siria yoo tun gba ara wọn jọ, wọn yoo si tun wa gbogun ti awọn Ọmọ Israẹli.

A maa n yọ nigba ti a ba ni iṣẹgun kan lori ọta ẹmi wa, ṣugbọn ko tọ fun wa lati tu amure wa silẹ ni akoko naa. Niwọn igba ti a ṣi wa lori ilẹ aye, Satani yoo gbiyanju lati mu wa pada sẹhin kuro ninu ọna igbagbọ. A ni lati wa ni ojufo nigba gbogbo ki a ba le kọjuja si awọn ogun rè̩ ti o n fi arekereke gbe dide. Bi ko ba le ṣẹgun wa ni ọna kan, yoo gba ọna miran. Bẹnhadadi ti ṣe awawi pe idi rè̩ ti oun fi sọ ogun kinni nu ni pe Ọlọrun Israẹli jẹ Ọlọrun awọn oke, pe ti Israẹli ba ni lati ja ni pẹtẹlẹ, Ọlọrun wọn ki yoo le ran wọn lọwọ. Ọlọrun tẹtisilẹ O si n gbọ gbogbo ifunnu Bẹnhadadi.

O dabi ẹni pe awọn ọmọ-ogun Siria kun gbogbo ilẹ naa. Awọn ọmọ-ogun ati ẹṣin ati kẹkẹ-ẹṣin tò lọ bẹẹrẹ bi ẹni pe wọn ko lopin. Ninu afonifoji ni awọn ọmọ-ogun israẹli gbe do si “gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji.” Ọna wo ni awọn ọmọ-ogun Israẹli le gba fi ni iṣẹgun?

Nibẹ gan an ninu afonifoji naa, Ọlọrun fi han pe Ọlọrun afonifoji ni Oun I ṣe pẹlu. Ọlọrun Israẹli ṣe tan lati ran gbogbo awọn ti o ba ke pe E lọwọ, wọn i ba wa ni ori oke tabi ni afonifoji. Fun ọjọ meje ni awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun mejeeji fi duro ti wọn n ṣọ ara wọn. Ija wa bẹrẹ. Wo iru iṣẹgun ti Israẹli ni! Awọn ọmọ-ogun Israẹli “agbo ọmọ ewurẹ kekere meji” nì pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ (100,000) ninu awọn ọmọ-ogun Bẹnhadadi; ogiri si wo lu ẹgbaa mẹtala le ẹgbẹrun (27,000) sii nigba ti wọn gbiyanju lati sa lọ ki wọn si fi ara pamọ.

Kikuna

Anfaani ti Ahabu ni niyi lati pa gbogbo awọn Keferi ti o wa ni ilẹ naa run. Awọn iṣẹgun ti o logo yi yẹ ki o fun un ni ikiya pupọ lati ja ogun Oluwa ki o si pa ẹṣẹ run. S̩ugbọn o ṣe gẹgẹ bi ọba miran ni israẹli ti ṣe – o da ọba naa si laaye nigba ti Ọlọrun ni ki o parun patapata. Awọn eniyan wọnyi ti jẹ ẹlẹṣẹ pupọ rekọja, o si to akoko ni oju Ọlọrun lati ran idajọ si wọn. A ti yan Ahabu lati jẹ ohun-elo lati ṣe iṣẹ yi fun Oluwa – o si kuna; o kuna ninu iṣẹ ti a fun un lati ṣe.

Bayi ni o ti ṣe gba ọjẹgẹ. Awọn iranṣẹ Bẹnhadadi lọ sọdọ Ahabu ninu aṣọ-ọfọ lati fi rirẹ-ara-wọn-silẹ han, lati bẹbẹ fun ẹmi ọba wọn. Dipo ti Ahabu i ba fi mu iduro rè̩ fun otitọ, o pe ọba Keferi yi ni arakunrin rè̩. Ipo rè̩ ninu aye ti mu ki oju Ahabu fọ si ẹṣẹ rè̩.

Bibeli sọ fun wa pe bi ẹni kan ba wa si aarin wa ninu aṣọ daradara, tabi ki o jẹ eniyan pataki kan ninu aye ti a si ṣe ojusaju fun un tabi a fun un ni ibujoko ti o dara ju lọ lati joko nigba ti a ṣe alainaani talaka, a n ṣe ojusaju ni. “Ẹnyin kò ha nda ara nyin si meji ninu ara nyin, ẹ kò ha si di onidajọ ti o ni ero buburu?” (Jakọbu 2:2-4). Ipo eniyan ati bi o ti lokiki si ninu aye a maa bo awọn ẹlomiran loju lati ri ẹṣẹ ti o wa ninu aye rè̩.

Nitori pe Bẹnhadadi jẹ ọba, Ahabu ṣe ojusaju fun un o si pe e ni arakunrin. Awọn iranṣẹ wọnyi ṣakiyesi lẹsẹkẹsẹ wọn si yara gba ohun ti o ti ọdọ rè̩ wa mu pe, “Bẹnhadadi arakunrin rẹ.” Ahabu jẹ ọkan ninu orilẹ-ède ayanfẹ Ọlọrun, oun i ba si pa ara rè̩ mọ kuro ninu ẹgbẹ buburu. Dipo eyi Ahabu pe Bẹnhadadi lati wa sọdọ rè̩, bi wọn si ti n lọ ninu kẹkẹ-ẹṣin kan wọn ṣe adehun kan ti o jasi anfaani fun Bẹnhadadi, bẹẹ ni Israẹli tun padanu lẹẹkan sii.

A Ba Ahabu Wi

Ọlọrun ran woli kan lati sọ fun Ahabu pe o ti ṣe ohun ti ko tọ. Woli naa fi iṣẹlẹ kan ṣe akawe ọrọ fun Ahabu lati mu ki oye ye e bi o ti ṣe ohun pataki to lati bojuto iṣẹ Oluwa. O ni ẹni kan fi arufin kan si itọju oun; ṣugbọn bi oun ti n ṣiṣẹ nihin ati lọhun, a fẹ arufin naa ku. Ohun ti o buru pupọ ni eyi; nitori pe bi a ko ba ri arufin naa, ẹni ti a fi i si lọwọ lati pa a mọ ni yoo fi ẹmi rè̩ lelẹ dipo ti arufin naa. Ahabu ro pe olutọju ti o sọ itan naa ti huwa ijafara lọpọlọpọ, o si yẹ lati ku. O yẹ ki o mọ pe bi oun ko ba ṣe ojuṣe rè̩ o ni lati san ẹsan fun un.

Woli naa mu ohun ti o fi pa oju rè̩ da kuro, Ahabu si mọ ọn. O ma ṣe o, Ahabu! Oun ni ẹni ti a fun ni iṣẹ lati ṣe fun Oluwa, ti o ti jẹ ki arufin naa sa lọ. Ọlọrun fẹ ki Ahabu pa Bẹnhadadi run, ṣugbọn Ahabu ti ba a ṣe adehun gẹgẹ bi ọrẹ, o si ti jọwọ rè̩ lati wa laaye. Ijiya rè̩ ni pe oun ati awọn eniyan rè̩ ni yoo fi ẹmi wọn dipo fun kikuna lati mu aṣẹ Oluwa ṣẹ.

Iṣẹ Wa

Ọlọrun ti fun wa ni ohun kan lati pamọ. A ni iṣẹ lati ṣe fun Un -- iṣẹ pataki ti jijere ọkan fun Ijọba Rè̩. S̩ugbọn a ha kun fun iṣẹ pupọ nihin ati lọhun, ṣiṣe nihin ati ṣiṣe lọhun, to bẹẹ ti a ko fi ri aye lati jere ọkan fun Jesu? Ẹ jẹ ki a ṣiro ohun ti a n ṣe. A ha ni Ẹmi Ọlọrun ninu ohun ti a n ṣe, to bẹẹ ti awọn ọkan fi n ri igbala? Ẹmi Ọlọrun ni o n pe awọn eniyan si ironupiwada, ko si si bi aayan wa le ti pọ to ti o le fi ni ere bi Ẹmi Ọlọrun ko ba si nibẹ. Ohun ti a si n ṣe a ni lati ṣe e fun ogo Ọlọrun bi a ba n reti ere lọdọ Rè̩.

Iṣẹ wa ni lati jere ọkan fun Jesu. Bi a ko ba ṣe e, kin ni a o sọ nigba ti a ba duro niwaju Adajọ nla nì? Jesu tikara Rè̩ wi pe: “Ki iṣe gbogbo ẹniti npe mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọle ijọba ọrun; bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun” (Matteu 7:21).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Tani Bẹnhadadi i ṣe?
  2. Nibo ni o ti wa gbogun ti Israẹli?
  3. Kin ni idahun Ahabu si ifunnu Bẹnhadadi pe oun yoo mu ki gbogbo Israẹli tẹle oun?
  4. Kin ni ohun ti o fa iṣubu Bẹnhadadi?
  5. Bawo ni o ti pẹ to ki ogun awọn ara Siria to tun wa do ti awọn Ọmọ Israẹli?
  6. Kin ni awọn ọmọ-ogun Israẹli ti to nigba ti a ba fi we ti awọn ara Siria?
  7. Awọn ara Siria melo ni a pa ninu ogun naa?
  8. Iṣẹ wo ni Ọlọrun ni fun Ahabu ni akoko yi? Njẹ Ahabu ṣe e?
  9. Kin ni iṣẹ wa ninu isin Ọlọrun?
  10. Kin ni n mu ki iṣẹ wa fun Jesu ni ere?
2