Lesson 300 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Kiyesara ki ẹ si mā ṣọra nitori ojukòkòro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọpọ ohun ti o ni” (Luku 12:15).Notes
Ète Titun
Ọlọrun ti sọrọ idajọ fun Ahabu fun iwa buburu rẹ. S̩ugbọn dipo ki o ronupiwada ẹṣẹ rẹ nigba ti o mọ pe opin oun ko jinna mọ, iwa ibi miran ni o tun n pete rè̩.
Ọkan ninu awọn aladugbo Ahabu ni ọgba-ajara kan ti o wu Ahabu lati ni. O fẹ lati san owo fun un, o si gbiyanju lati ṣe adehun nipa rè̩. S̩ugbọn Ọlọrun ti paṣẹ pe awọn Ọmọ Israẹli ko gbọdọ ta ilẹ wọn; Naboti ti o ni ọgba-ajara naa bọwọ fun Ofin Ọlọrun ju ọba lọ. Idahun Naboti ni pe: “OLUWA ma jẹ ki emi fi ogun awọn baba mi fun ọ.” Naboti i ba ṣe awawi pe niwọn bi o ti ṣe pe ọba ni o paṣẹ, o di ọranyan fun oun lati ta a, ohunkohun ti o wu ki Ofin Ọlọrun sọ. Ko ṣoro fun awọn miran lati wi awijare nigba ti wọn ba gba ọjẹgẹ pẹlu nkan ti wọn mọ pe ki i ṣe ifẹ Ọlọrun. S̩ugbọn Naboti ni igboya lati mu iduro lori otitọ, bi o tilẹ jẹ pe nipa bẹẹ ko tẹ ọba lọrun.
Ète Jesebeli
Dajudaju inu Ahabu bajẹ nigba ti o gbọ pe Naboti ko ni ta ilẹ naa fun oun. Ahabu huwa bi ọmọ ti a kẹ bajẹ, o bọ sori ibusun rẹ, o si wugbọ. S̩ugbọn iyawo rè̩ buburu, Jesebeli, yoo ṣe e ti Ahabu yoo fi ni ohun ti o n fẹ dandan. Ọlọgbọn arekereke sa ni oun, o si bẹrẹ si i ta ọgbọn bi oun o ti ṣe ja ọgba ajara naa gba lọwọ Naboti lati fi i fun ọkọ rẹ ti inu rè̩ bajẹ yi. S̩e bi oun ni Ọba lori Israẹli? Kin ni ṣe ti a o fi ohunkohun ti o ba n fẹ du u?
Lakọkọ Jesebeli kọwe ni orukọ ọba, o si fi wọn ṣọwọ sọdọ awọn agbaagba ti o wa ni ilu ti Naboti n gbe. Aṣẹ wa ninu awọn iwe naa lati kede aawẹ, ati lati fi Naboti si gbangba niwaju gbogbo awọn eniyan. Boya wọn fẹ ki o ro pe wọn fẹ fi oun si ipo ọla ni. S̩ugbọn a ni ki wọn pe eniyan buburu meji lati fi ẹsun sùn un pe o sọrọ odi. Lai ṣe aniani, a mọ pe ẹlẹri-eke ni awọn wọnyi, nitori pe Naboti ko hu iwa ibi kan.
Ofin sọ pe a ko le da ẹnikẹni lẹbi iku bi awọn ẹlẹri ko ba to meji. “Li ẹnu ẹlẹri meji tabi ẹlẹri mẹta, li a o pa ẹniti o yẹ si ikú; ṣugbọn li ẹnu ẹlẹri kan, a ki yio pa a” (Deuteronomi 17:6). Ko ṣoro lati ri ẹlẹri eke meji ti wọn o ba tipa bẹẹ ri owo gba. Ọpọlọpọ alaiṣootọ eniyan wà ti wọn tilẹ le fi ọrẹ wọn han nitori owo.
Awọn Ajẹriku
Ọpọlọpọ ni wọn ti di ajẹriku nitori pe awọn ẹlẹri-eke tako wọn, a si da wọn lẹbi iku. Ani wọn tilẹ bẹ awọn ẹlẹri-eke kan lati tako Jesu tikara Rè̩. Jesu si ti wi pe: “Ọmọ ọdọ ko tobi jù oluwa rẹ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu” (Johannu 15:20). Awọn ọmọlẹhin Jesu Kristi ko gbọdọ rẹwẹsi bẹẹ ni wọn ko gbọdọ jaya nitori iya ti o le de ba wọn nitori ti Rè̩. O wi pe, “Ẹ tujuka; mo ti ṣẹgun aiye” (Johannu 16:33), bi o tilẹ dabi ẹni pe awọn ọta Rè̩ ti bori Rè̩.
Nigba ti a ba jẹ ọmọ Ọlọrun, a jẹ “ajumọjogun pẹlu Kristi.” Bi o ba ṣe pe awa ba A jiya, a o ṣe wa logo pẹlu Rè̩ (Romu 8:17).
A Sọ Naboti Lokuta
Naboti jiya o si fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori ipinnu rẹ lati pa Ofin Ọlọrun mọ. Wọn mu un jade kuro ni ilu, wọn si sọ ọ ni oluta titi o fi ku. Ogo rè̩ yoo ti pọ to nigba ti o de ọdọ Ẹlẹda rè̩, ani Ọlọrun rè̩ ti o ti fi ẹmi rè̩ lelẹ fun! Naboti ti wọ iye ainipẹkun lọ lati maa gbe titi ayeraye lọdọ Ọlọrun.
Sisọ ti a sọ Naboti lokuta pa ran wa leti nipa Stefanu ajẹriku kinni fun Kristi. Ẹru ko ba Stefanu lati ku fun Jesu, nigba ti o si fi aye yi silẹ o bọ sinu Ijọba Ọrun pẹlu ikinikaabọ ologo.
Aṣiiri Rikiṣi Tu
Nisinsinyi ọwọ Ahabu ti tẹ ogba-ajara naa. Oun yoo ha gbadun rè̩ bi? Iwọra rè̩ ati ojukokoro rè̩ ni o fa iku ọkunrin alaiṣẹ. Inu Ahabu le dùn bi?
Nigba pupọ ni a maa n sọ fun awọn ọmọde pe gbogbo ohun ti wọn n ṣe ni Ọlọrun n kiyesi. Ki i ṣe ọmọde nikan ni Ọlọrun n ri. Ọlọrun ti ri iwugbọ Ahabu, ati rikiṣi Jesebeli. Ọlọrun ti ri iku Naboti iranṣẹ Rè̩; a si ti kọ ọ pe, “Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi o gbẹsan” (Romu 12:19). Ki i ṣe ti wa lati fẹ gbẹsan lara ẹni ti o ba ṣẹ wa. Ọjọ idajọ n bọ ti Ọlọrun yoo ṣe ẹtọ fun olukuluku. “Ki o si da nyin loju pe, ẹṣẹ nyin yio fi nyin han” (Numeri 32:23).
Ahabu jẹbi ole jija ati ipaniyan, Ọlọrun yoo si jẹ ẹ niya. Bayi oun ni ọba Israẹli, ṣugbọn ogo ori itẹ ko ni duro ninu idile rè̩ mọ. Ko si ọmọ rè̩ ọkunrin ti yoo jọba lẹhin rè̩, nitori Ọlọrun ti wi pe gbogbo ọmọ rè̩ ọkunrin ni yoo ku – a ko tilẹ ni fun wọn ni isinku ti o lọla. Iku itiju ni iyawo rè̩ naa yoo ku, nitori ẹṣẹ rè̩. Gbogbo nkan wọnyi jẹ ere fun ẹṣẹ Ahabu. Ki i ṣe gbogbo eniyan ni o n gbọ iru iya ti oun yoo jẹ ṣiwaju akoko; nigba miran o si le dabi ẹni pe awọn eniyan buburu ko ni jiya ẹṣẹ wọn. S̩ugbọn Bibeli wi pe, “Iku li ere ẹṣẹ” – eyi si jẹ iku ayeraye. Gbogbo ẹṣẹ ni Ọlọrun ti ri, ijiya yoo si tẹle e dandan ti a ko ba ronupiwada.
Aanu
Ninu aanu Rè̩, Ọlọrun a maa dariji nigba ti a ba ronupiwada. A sọ nipa Ahabu pe ohun ti o ṣe lati bi Oluwa Ọlọrun ninu ju ti eyikeyi ninu awọn ọba Israẹli ti wọn ti jọba ṣiwaju rẹ; sibẹ, nigba ti Elijah, Woli Ọlọrun, lọ ba a lati sọ ohun ti yoo de ba a nitori ẹṣẹ rè̩, Ahabu rẹ ara rè̩ silẹ, o fi aṣọ ọfọ si ara rè̩, o si gbadura. Ọlọrun ri eyi naa pẹlu, O si tun ran Elijah lati lọ sọ fun Ahabu pe nitori ti o rẹ ara rè̩ silẹ, a ko ni mu gbogbo idajọ naa ṣẹ sori ile Ahabu titi fi di ẹhin iku rè̩.
“Anu OLUWA ni, ti awa ko parun tan, nitori irọnu-ānu rè̩ ko li opin” (Ẹkun Jeremiah 3:22). Ẹṣẹ ẹnikẹni le dabi ẹni pe ko to nkan, ṣugbọn gbogbo eniyan ni wọn ti ṣẹ, ti wọn si ni lati ronupiwada ki wọṅ si ri igbala. Boya ẹni kan ko gbero ati paniyan ki ohun ti o n fẹ ba le tẹ ẹ lọwọ; boya o kan ṣe ainaani iṣẹ-isin rẹ fun Oluwa nitori ati ni itura ati ọrọ ti o kọja iwọntunwọnsi: eyi yoo jẹ ẹṣẹ, o si ni lati ronupiwada fun un.
Ojukokoro
Ẹṣẹ ojukokoro le ti ibi kekere bẹrẹ. Ohun kan ti ẹlomiran ni le wu wa. Eyi ko buru rara ti o ba jẹ pe inu wa dun pe o jẹ ti ẹni naa, ti ki i ṣe pe a fẹ lati ni i. S̩ugbọn nigba ti a ba bẹrẹ si i fẹ ohun ti a ko le ni, ti a si n lepa lati ni i, gẹgẹ bi Ahabu ti ṣe, yoo wa di ẹṣẹ. Bibeli sọ fun wa pe ojukokoro jẹ ibọriṣa. Fun olojukokoro, awọn ohun miran ti ṣe pataki ju ifẹ Ọlọrun lọ. “Ki ọkan nyin ki o maṣe fa si ifẹ owo.” Ki i ṣe igba gbogbo ni ki o fi maa sọ ohun ti o fẹ ni fun ilo ara rẹ, tabi ohun ti o fẹ dà. Ibukun rẹ yoo pọ sii ti o ba n sọ nipa nkan ti Ọlọrun, ati bi o ti ṣe le ran awọn ẹlomiran lọwọ: “Ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ” (Heberu 13:5).
Questions
AWỌN IBEERE- Kin ni Ahabu nfẹ?
- Kin ni ṣe ti Naboti ko fi fẹ fi i fun un?
- Kin ni ohun ti Ahabu ṣe nigba ti ko le ri i gba?
- Ọna wo ni Jesebeli gba lati mu ki Ahabu gba nkan ti o n fẹ?
- Iru eniyan wo ni Naboti?
- Njẹ a ri ohun ti Naboti ati Stefanu fi jọ ara wọn?
- Kin ni ojukokoro?
- Ileri wo ni Ọlọrun ṣe fun awọn ti wọn jẹ ki ohun ti wọn ni ki o té̩ wọn lọrun? 2