Iṣe Awọn Apọsteli 9:32-43; 10:1-23

Lesson 302 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kò si iyatọ ninu Ju ati Helleni: nitori Oluwa kanna l’Oluwa gbogbo wọn, o si pọ li ọrọ fun gbogbo awọn ti nke pe e” (Romu 10:12).
Cross References

I Ibẹwo Peteru laarin awọn Ọmọ-ẹhin

1 Ni Lidda, Ọlọrun lo Peteru gidigidi, Iṣe Awọn Apọsteli 9:32-35; 3:7-12; 1:8; I Peteru 2:9

2 Ni Joppa, Peteru ati awọn eniyan mimọ ri ifarahan agbara Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 9:36-43; Johannu 14:12-14; 15:16

II Ipe Peteru lọ si Joppa

1. Kọrneliu, ọkunrin kan ti o bẹru Ọlọrun ri iṣẹ ti o fi ọkan rẹ balẹ gba lati ọdọ Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 10:1-8; I Tẹssalonika 5:17; I Johannu 3:14, 17; Oniwasu 12:13; Matteu 19:21; 22:36-40; Orin Dafidi 18:6; 34:17; Mika 7:7; Daniẹli 10:1-12; Luku 1:13

2. Nipa imisi Ọlọrun, Peteru lọ gbadura ni akoko ti o wọ, Iṣe Awọn Apọsteli 10:9; Romu 8:26, 27

3. Peteru ri iran ti o ṣe pataki, eyi ti a kò fi fun un lati fi dipo Ọrọ Ọlọrun bi ko ṣe lati fi itumọ rẹ han, Iṣe Awọn Apọsteli 10:10-16; Efesu 1:9, 10; Gẹnẹsisi 1:1-6; 46:1-4; Esekiẹli 37:1-14; Iṣe Awọn Apọsteli 9:10; Heberu 1:1, 2; Galatia 1:8, 9

4. Peteru gbọran kankan si iṣẹ ti Ọlọrun ran si i lẹhin ti a ti fi idi rè̩ mulẹ fun un lọna gbogbo, Iṣe Awọn Apọsteli 10:17-23; Johannu 16:13; I Johannu 4:1; I Tẹssalonika 5:21; Efesu 1:10

Notes
ALAYÉ

Ninu episteli Peteru kinni si awọn ijọ ti o wà ni Asia -- awọn Ijọ ti Paulu Apọsteli dá silẹ -- o gba awọn alagba ijọ wọnyi niyanju lati “mā tọju agbo Ọlọrun” ki wọn si maa boju to o; “kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ erè ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan. Bẹni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo” (I Peteru 5:2, 3). Ninu iwe ti a yan fun ẹkọ yi, a ri Peteru, nigba ti Ijọ ṣẹṣẹ bẹrẹ bi o ti n ṣe ohun ni ti o wá ṣe akọsilẹ rè̩ nigbooṣe, gẹgẹ bi ọrọ iyanju fun anfaani awọn ẹlomiran.

Kristi ti pe Peteru bi ọmọ-ẹhin, O si yan an sipò Apọsteli, o si ni anfaani lati ri okodoro oriṣiriṣi awọn ohun iyanu ti o ṣẹlẹ ni akoko ti Kristi wà laye. Peteru ri Jesu ninu ogo lori Oke Ipalarada. O ri iṣẹ iyanu ti o ṣe lara awọn ẹbi oun paapaa, ati lara awọn wọnni ti wọn tọ Jesu wá fun iwosan ati igbala. Peteru wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin ni Ọjọ Pẹntikọsti, oun naa gba Ẹmi Mimọ, ni igbọran si aṣẹ ti Jesu fi fun un. Agbara ẹmi ti wọnu Peteru lọtun ki o to fi Yara Oke silẹ, Ọlọrun si n lo o lati waasu igbala fun ọpọlọpọ eniyan.

Ọdun mẹjọ ti kọja lẹhin Ọjọ Pẹntikọsti. Peteru n lọ kaakiri, o n bẹ ijọ ati ipejọpọ ti o gbagbọ wo, o n ki wọn laya, o n gba wọn niyanju, o n fi ounjẹ ẹmi bọ wọn, o si n bojuto wọn. Niwọn igba ti “àgbẹ ti o nṣe lālā li o ni lati kọ mu ninu eso wọnni” (II Timoteu 2:6), Peteru n ṣe ohun kan naa gan an ti o n gba awọn alagbà ti o wa ni Asia niyanju nigbooṣe lati ṣe. Oun ko ṣe iṣẹ-iranṣẹ rè̩ fun Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni ti n lo agbara “lori ijọ.” Oun kò wa “ere ijẹkujẹ” fun iṣẹ-iranṣẹ rè̩. O ni “ọkàn ti o mura tan,” o si n bẹ awọn eniyan yi wo, ki i ṣe pẹlu “afipaṣe, bikoṣe tifẹtifẹ.” O jẹ apẹẹrẹ fun agbo, o si mọ daju pe oun yoo gba ère nigba ti “Olori Oluṣọ-agutan” ba fara han. Nigba naa ni yoo “gba ade ogo ti ki iṣa.”

Ọla ti a Fun Kristi ni Lidda

Agbo ọmọlẹhin Kristi kan wà ni Lidda. Peteru lọ bẹ wọn wò. A kò mọ pupọ nipa agbo kekere yi nitori iwọn iba akọsilẹ diẹ ni o wà ninu Iwe Mimọ nipa wọn. S̩ugbọn eniyan mimọ ni a pe wọn. A mọ pe igbagbọ wọn ati igbagbọ ti n bẹ ni ookan-aya Peteru Apọsteli, le sii nipa idapọ mimọ ti wọn ni nipa ibẹwo yi.

Lidda wa ni eti ebute agbegbe S̩aroni, lai si aniani, igbagbọ ati iduro awọn eniyan mimọ ti n bẹ ni Lidda di mimọ fun awọn ti n bẹ ni ẹkùn yi, nitori pe ihin iṣẹ iyanu ti o ṣe nibẹ tàn ani titi de Joppa. Mìmi agbara Ẹmi Mimọ mi de Kesarea, ti o to nkan bi ọgbọn mile si Joppa, o si ṣe e ṣe ki o ju nkan bi ogoji mile si Lidda, nitori Ẹmi otitọ Ọlọrun tikara Rè̩ tan ihin yi kalẹ ni gbogbo ẹkùn nì ti o han gbangba pe awọn eniyan Ọlọrun wọnyi ko i ti i bẹwo tẹlẹ.

Peteru ba ọkunrin kan pade ni Lidda, ẹni ti o ti wà ni idubulẹ arun è̩gbà fun ọdun mẹjọ. Ebi ẹmi ati ifẹ ti n bẹ ni ọkan ọkunrin yi ti a n pe ni Enea pọ to bẹẹ ti Ẹmi Oluwa fi dari Peteru wa si tosi akete rè̩. Igbagbọ si n bẹ ninu ọkan Enea to bẹẹ ti o fi gbọran si aṣẹ Peteru wi pe ki o dide kuro lori akete rè̩.

O gbà ki oungbẹ ati ebi ẹmi wà ninu ọkan kan ki Ẹmi Mimọ to le ran ihin Ihinrere ati ibukun si iru ọkan naa. Eyi ni i maa wà lọkan awọn keferi ti wọn ni oungbẹ fun ohun kan ti awọn paapaa kò mọ, ohun kan ti ko si ninu oriṣa ti wọn jogun ba, tabi ninu igbesi-aye oṣi ati ofin atọwọdọwọ ti wọn n gbe.

Oungbẹ fun ohun ti ẹmi ti n bẹ ninu ọkan Abrahamu ni o mu ki o jẹ ipe Ọlọrun. Awọn miran ni ilẹ Uri ko fara balẹ to lati gbọ ohun Ẹmi, ṣugbọn Abrahamu gbọ, o si gbọran. Bẹẹ naa ni o ri lati igba ti Alaye ti da aye, bakan naa ni o si ri titi di oni-oloni. Awọn ti ebi Ẹmi ba n pa ni a n mu lọ si Orisun ibukun. Awọn ti wọn tẹjumọ “ilu ti o ni ipilè̩: eyiti Ọlọrun tè̩do ti o si kọ” (Heberu 11:10), ni Ọlọrun ti ki i ṣe ojusaju eniyan yoo mu de ilu nì.

Awọn ara Lidda ati awọn ti n bẹ ni ẹkùn S̩aroni ri iṣẹ iyanu kan nitori igbagbọ Enea ati ijolootọ Peteru. Peteru tọka gbogbo wọn si Jesu, ko fi ogo fun ara rè̩ rara. “Jesu Kristi mu ọ larada” ni ohùn ti o fọ si ọkunrin alaisan yi, ati nitori pe Peteru n gbe Jesu ga ninu ohunkohun ti o ba n ṣe, gbogbo ilu mì titi, “wọn si yipada si Oluwa.” Awọn ara ilu yi ko yipada si Peteru. Wọn ko wo o bi ẹni kan ti o ni agbara tabi ẹbun agbayanu kan. Wọn yipada si Oluwa, ninu Rẹ ni wọn si gbe ri igbala; nitori pe ninu orukọ Rè̩, ati igbagbọ ninu orukọ Rè̩ nikan ni a gbe n gba ni là ti iṣẹ iwosan si n ṣe.

A ko le ri i ka nibikibi ninu Iwe Mimọ ti eniyan Ọlọrun tootọ yoo gbe dari ọkan awọn eniyan ti n bẹ labẹ akoso rè̩ kuro lọdọ Ọlọrun, Jesu Kristi Ọmọ Rè̩, tabi Ẹmi Mimọ olootọ. Gbogbo awọn eniyan Ọlọrun ni o mọ pe wọn ko jamọ nkankan ṣugbọn wọn jẹ ohun-elo lọwọ Ọlọrun. Wọn gba pe Ọlọrun ni o n ṣe iṣẹ-iyanu, ti n gba ọkan là, lọwọ Rè̩ si ni ẹmi ọmọ-eniyan wà. Nigba ti eniyan ba gba ogo fun ara rè̩ dipo Ọlọrun, Ẹmi Mimọ ki yoo lo iru ẹni bẹẹ mọ. Igberaga ninu ọkàn yoo di Ọlọrun Ọrun lọwọ lati ṣiṣẹ bi Oun i ba ti ṣe bi o ba ṣe pe a fi iyin ati ogo fun Ẹni ti o tọ si fun gbogbo iṣẹ Rè̩. Ọna ti Ọlọrun là silẹ ni eyi. Ọna miran ko si. Ọna naa si ti dara to!

Ọla ti a Fun Kristi ni Joppa

Ihin iṣẹ-iyanu ati isọji ti o bẹ silẹ ni Lidda tàn de Joppa, nkan bi mile mejila si Lidda. Joppa nigba nì ati ni oni-oloni yi jẹ ilu ti o wà ni ebute okun; alaini ati ọlọrọ si n bẹ ninu awọn olugbe rè̩. S̩ugbọn ni ilu ti n gbèru yi ni agbo awọn ti o gbagbọ kan gbe wà.

Aisan nla kọlu ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ni Joppa; pẹlu gbogbo aajo ati iranlọwọ wọn, o kú. Dọrka jẹ ẹni kan pataki ninu agbo. O kún fun ọpọ iṣẹ oore ati ọpọ oore-ọfẹ pẹlu. Ọmọlẹhin Kristi ni oun i ṣe, ko si fi iṣẹ rè̩ si Ọlọrun ati si eniyan jafara. Ọwọ rè̩ ko dilẹ nigba kan bi o ti n ran awọn alaini lọwọ. Awọn opó wà ninu awọn ti o n ran lọwọ. O fi ẹmi otitọ han eyi ti awọn eniyan ti o ni ifẹ Ọlọrun ninu wọn i maa ni, awọn ti ko gbagbe aini awọn arakunrin wọn. (Ka I Johannu 3:16-18). S̩ugbọn Dọrka ti kọja lọ mọ wọn lọwọ, wọn si ri i pe iranwọ rẹ ti o n ṣe fun wọn dopin. Wọn ranṣẹ si Peteru nitori pe wọn mọ pe Ọlọrun wà pẹlu rè̩, lai si aniani wọn ni ireti wi pe yoo gbadura fun wọn boya Ọlọrun yoo ṣaanu fun wọn ni akoko ibanujẹ wọn yi.

Ọlọrun ki i gbagbe awọn ti ọfọ ṣẹ. O n boju wolẹ O si n ṣaanu fun awọn eniyan Rè̩ gbogbo, O si n tù awọn onirobinujẹ ọkàn ninu, O si n di wọn mu ni akoko iṣoro wọn. Jesu ri omije opó Naini, O si ji ọmọ rè̩ dide kuro ninu oku. O tu Maria ati Marta ninu O si ji arakunrin wọn dide kuro ninu oku. Elijah, Woli Ọlọrun ri i pe oju obinrin ti oun wọ si ile rè̩ faro, o si gbadura ki Ọlọrun dá ẹmi ọmọ rè̩ pada. Eliṣa pẹlu ri ibanujẹ ati igbagbọ obinrin S̩unemu nì; nipa adura igbagbọ, Ọlọrun dá ẹmi ọmọ obinrin yi pada.

Ọlọrun ni eto ati ipinnu Rè̩ ninu ohun ti o ṣẹlẹ wọnyi. Ga rekọja itura ati itunu ti a fi fun ọlọfọ kọọkan wọnyi, nipa jiji awọn olufẹ wọn ti o ti kú dide, Ọlọrun ṣe ohun kan fun Ogo Rè̩ nipa iṣẹ-iyanu wọnyi. O fi idi otitọ yi mulẹ wi pe, Ọmọ Ọlọrun ni Jesu I ṣe, a fi han pe O lagbara lori iku nipa dida ẹmi awọn wọnni ti o ti kú pada. Ellijah ati Eliṣa jẹ eniyan Ọlọrun laarin orilẹ-ede ti o kọ Ọlọrun silẹ ti o si di abọriṣa. Ọlọrun n ba Israẹli lo, O fẹ mu wọn pada sọdọ ara Rè̩, O si lo awọn ohun ti o ṣẹlẹ wọnyi lati fi agbara Rè̩ ati ẹni ti i ṣe Woli Rè̩ han, ki Israẹli le gba iṣẹ ti Ọlọrun ran si wọn. Ọlọrun ji Dọrka dide fun idi pataki kan, iṣẹ kan si ṣe fun ogo Ọlọrun nipa rẹ eyi ti ki yoo fi igba gbogbo ri bẹẹ bi o ba ṣe pe awọn ẹlomiran ni a ji dide bẹẹ. A sọ fun ni pe “o si di mimọ yi gbogbo Joppa ka; ọpọlọpọ si gbà Oluwa gbọ.” Nihinyi, Ọlọrun ji iranṣẹ Rè̩ dide ki Oun ki o le gba ogo ati ọla ki awọn eniyan si le ri igbala lọkunrin ati lobinrin.

Ohun ti o ba ni ninujẹ ni pe ọkàn buburu ọmọ-eniyan ki i fi igba gbogbo gbọ ti Ẹmi Ọlọrun, bi iṣẹ-iyanu ti o to bayi tilẹ ṣe. A sọ fun ọkunrin ọlọrọ nì ti o wà ni ọrun apaadi nipa awọn arakunrin rè̩ pe, “Bi nwọn kò ba gbọ ti Mose ati ti awọn woli, a kì yio yi wọn li ọkàn pada bi ẹnikan tilẹ ti inu okú dide” (Luku 16:31). Ọlọrun ṣiṣẹ iyanu nibi ti ogo Rè̩ yoo gbe han, O si le ṣe bẹẹ loni, Oun yoo si ṣe e nigbakuugba ati nibikibi ti yoo gbe mu ipinnu Ọlọrun ṣẹ.

Ipe Peteru lọ si Joppa

Akọsilẹ nipa Kọrneliu, balogun ọrun ti ẹgbẹ ọmọ-ogun ti n bẹ ni Kesarea fi han wi pe gbogbo aye ni ipe Ọlọrun wà fun. Filippi ajihinrere ti wà ni ilu yi fun ọdun pupọ lẹhin ti o ba iwẹfa ara Etiopia nì pade ni aṣalẹ ti o wà ni iha isalẹ iwọ-oorun Jerusalẹmu. Filippi jẹ ọkan ninu awọn diakoni meje ti a yàn lati maa ran awọn Apọsteli lọwọ ni akọbẹrẹ Ijọ, (Iṣe Awọn Apọsteli 6:5; 8:40; 21:8). Lai si aniani, iwa-bi-Ọlọrun rè̩ di mimọ ni ilu yi bi o tilẹ jẹ pe o ṣe e ṣe ki gbogbo awọn ara ilu má mọ ọn ni ojukoju, Ẹmi Mimọ si ti bẹrẹ si ṣiṣẹ ninu ọkan ọmọ-ogun yi ti i ṣe iran Keferi.

Kọrneliu bẹru Ọlọrun, o si n gbadura si Ọlọrun nigba gbogbo. Ẹmi adura ti ba le e, igba gbogbo ni ọkan rè̩ n gbadura. O jẹ olufọkansin, o si “ni orukọ rere lọdọ gbogbo orilẹ-ede awọn Ju.” O n ṣe itọrẹ-aanu rè̩ lọna ti o tọ, bakan naa ni adura rè̩ pẹlu, nitori ti wọn goke lọ “iwaju Ọlọrun fun iranti.” Ọlọrun ki i gbe iranti kalẹ fun agabagebe tabi aiṣootọ. Nitori naa a mọ pe ẹni iwabi-Ọlọrun ni ọkunrin yi. A o ri i bi o ti ṣe gba Ẹmi Mimọ ninu ẹkọ wa ti ọjọ iwaju; ninu ori iwe miran siwaju si i, a o ri i ka pe eniyan Ọlọrun yi ti ni idalare ati isọdimimọ ṣaaju akoko ti Peteru lọ si ile rè̩ (Ka Iṣe Awọn Apọsteli 15:7-9).

Ẹkọ pupọ ni o n bẹ fun gbogbo wa nipa ọna ti Ọlọrun gba lati mu Peteru wa si ile jagunjagun yi. Ọlọrun a maa pese ọkan ti ebi n pa silẹ lati gba Ọrọ Rè̩; Oun a si tun ṣeto eniyan ti yoo mu Ọrọ naa tọ oluwarè̩ lọ. Lẹsẹ kan naa, Ọlọrun yoo ma là ọnà silẹ; yoo si maa ṣe e lọna ti o ṣe wi pe nigba ti akoko Rè̩ ba to, a o pese ohun gbogbo, ohun gbogbo yoo si ti wa letoleto lati mu ifẹ Rè̩ ṣẹ. Bi t’ọkunrin, t’obinrin ba jẹ le kọ lati jọwọ ara wọn lọwọ fun ifẹ pipe Ọlọrun, ki wọn si duro de akoko Ọlọrun ninu ohun gbogbo, ohun ti wọn fẹ ṣe fun Ọlọrun ko ni pẹ yanju rara.

Ọpọlọpọ eniyan ni o ti n gbadura kikankikan fun ọjọ pipẹ nipa igbala awọn ẹbi wọn tabi fun ẹlẹṣẹ ti o wà yi wọn ka, ṣugbọn wọn ti fọ ohun ti wọn n gbadura fun loju nipa ṣiṣaaju Ọlọrun, wọn si dena ohun ti O n ṣe lati ṣikẹ awọn ọkàn ti ọwọ wọn fẹrẹ tẹ igbala yi. Ilẹ pupọ ni a o gbà fun Ọlọrun bi a ba fara balẹ fun Un lati tẹ ifẹ Rè̩ lọrun, ki O si ṣiṣẹ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ ni oju Rè̩.

Ọlọrun ti pese ọkàn Kọrneliu silẹ lọna gbogbo fun imọlẹ ti o fẹ fi fun un. Ebi ẹmi n pa Kọrneliu o si n gbadura kikankikan fun ifẹ Ọlọrun ati oore-ọfẹ Rè̩. A ko mọ bi o ti ni oye to nipa iriri ati ifiyesi, ṣugbọn a mọ pe ẹni ti a ti sọdi mimọ ni oun i ṣe, ati pe oju ẹmi rè̩ ti ri firi-firi ibukun ti o wà ni ipamọ fun un, ani ibukun ti o tayọ idalare ati isọdi-mimọ patapata. Oungbẹ Ileri Baba, ani Olutunu nì n gbẹ ẹ, Ọlọrun si n ṣe eto bi yoo ti ṣe ri ibukun nla ni gbà.

S̩ugbọn bi Ọlọrun ti pese ọkan Kọrneliu silẹ ni O ṣe tun ni lati pese ohun-elo ti yoo lo fun iṣẹ yi pẹlu. Bawo ni o ti dun to pe Ọlọrun ri Peteru bi ohun-elo ti Oun le pese silẹ fun iṣẹ ribiribi yi. Ọpọlọpọ ọkan kọ ni o ha ni talẹnti nipa ti ara ṣugbọn ti wọn kuna lati gba ihamọra ti ẹmi ti o le mu ki Ọlọrun mu ifẹ Rè̩ ṣẹ ninu wọn. Iwarapapa ko wọ Peteru lẹwu mọ lọna ti Ọlorun ko fi ni le mu ifẹ Rè̩ ṣẹ ninu rè̩. Nisinsinyi, ọkan rè̩ tẹ lati gba ẹkọ, o si ṣetan lati gbọran si aṣẹ Oluwa.

Ọlọrun ba Peteru sọrọ lọna iyanu, O fi iran han an ti o ye e yekeyeke nigba ti awọn onṣẹ de lati ọdọ Kọrneliu. Nipa iran yi, Peteru mọ pe ipe Ọlọrun wà fun gbogbo aye. Fun igba kinni, Peteru ri i gbangba kedere wi pe igbala ki i ṣe fun orilẹ-ede ayanfẹ nì nikan, ṣugbọn pe “Ọlọrun kì iṣe ojusaju enia” ati pe “ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bè̩ru rè̩, (Ọlọrun), ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rè̩” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 35).

Peteru ko fi igbọran si Ọlọrun falẹ; nitori pe o mọ pe ohunkohun ti Ọlọrun ba dawọle lati ṣe yoo yọri si rere; nigba ti Ọlọrun ba lana silẹ, yoo mu ni de opin ọna naa; ati pe nibikibi ti Ọlọrun ba nawọ ipe Rè̩ si, ọkan kan ti wa nibẹ ti o ti n ṣafẹri Ihinrere. Inu ẹkọ wa ti ọjọ iwaju, a o ri i bi Ọlorun ti mu eto Rè̩ lati pe awọn Keferi sọdọ ara Rè̩ ṣẹ, nipa bẹẹ a tan Ihinrere ka gbogbo aye nipa iṣẹ awọn Ijọ igba nì, ni ọdun wọnni ti o tẹle itujade Ẹmi Mimọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. S̩e apejuwe ilu ti Lidda, Joppa ati Kesarea wà ati bi ọkọọkan ti jinna si ara wọn ati si Jerusalẹmu to.
  2. Bawo ni orukọ Jesu Kristi ṣe di ayinlogo ni Lidda?
  3. Bawo ni orukọ Jesu ṣe di ayinlogo laarin agbo awọn ọmọ-ẹhin ni Joppa?
  4. Bawo ni a ṣe mọ pe Dọrka jẹ Onigbagbọ?
  5. Tani Peteru sọ wi pe o ṣe iṣẹ-iyanu wọnyi?
  6. Kin ni abayọrisi awọn iṣẹ-iyanu ti a ṣe ni Lidda ati Joppa?
  7. Ajihinrere nla wo ni o n gbe Kesarea? Sọ diẹ ninu awọn ohun ti o ṣẹlẹ ninu igbesi-aye ajihinrere yi.
  8. Sọ bi a ṣe mọ pe ẹni iwabi-Ọlọrun ni Kọrneliu.
  9. Sọ bi Ọlọrun ti ṣe pese ọkan Peteru silẹ fun iṣẹ ti O fẹ fun un ṣe ni Kesarea.
  10. Nigba ti Kọrneliu ran awọn onṣẹ lọ si Joppa, o yan olufọkansin ọmọ-ogun kan pẹlu. Kin ni eyi fi han nipa iwa aye Kọrneliu?
1