Lesson 303 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin ọkọnrin ati awọn ọmọ nyin obirin yio mā sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkọnrin nyin yio si mā ri iran, awọn arugbo nyin yio si mā lá alá” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:17).Cross References
I Peteru ni Kesarea
1. Peteru ba Kọrneliu o n duro de e, Iṣe Awọn Apọsteli 10:24
2. Kọrneliu i ba fori balẹ fun Peteru, ṣugbọn Peteru da a lẹkun, Iṣe Awọn Apọsteli 10:25, 26; 14:11-18; Ifihan 19:10
3. Awọn ibatan ati ọrẹ ti o pọ niye ti pejọ pọ si ile Kọrneliu lati gbọ ọrọ Peteru, Iṣe Awọn Apọsteli 10:27
4. Peteru beere o si gbọ idi rè̩ ti Kọrneliu fi ranṣẹ pe e, Iṣe Awọn Apọsteli 10:28-33
II Iwaasu Peteru
1. Imọlẹ ọrọ otitọ fi hàn pe Ọlọrun ki i ṣe ojusaju eniyan, Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 35; Matteu 5:45; Romu 10:12
2. Tẹlẹtẹlẹ awọn eniyan yi ti ni imọ diẹ nipa Jesu, Iṣe Awọn Apọsteli 10:36-38
3. Iwaasu Peteru tubọ sọ asọye otitọ ati ẹkúnrẹrẹ ti Ihinrere, Iṣe Awọn Apọsteli 10:39-43; I Timoteu 3:16
III Ẹmi Mimọ ti a ti S̩eleri
1. Ẹmi Mimọ bà le gbogbo wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 10:44; 2:1-4; 19:1-7
2. Ẹnu ya Peteru ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 10:45, 46
3. Peteru gbà wọn niyanju, o si paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ẹhin titun wọnyi ṣe iribọmi, Iṣe Awọn Apọsteli 10:47, 48; Matteu 28:19
Notes
ALAYÉ“Ba wọn lọ, máṣe kọminu ohunkohun: nitori emi li o rán wọn.” Awọn onṣẹ lati ọdọ Kọrneliu wà ni ẹnu ọna ile Simoni alawọ; Ọlọrun si n pese ọkan Peteru silẹ lati gba awọn Keferi wọnyi ki o si ba wọn lọ si Kesarea. Peteru pe awọn eniyan wọnyi wọle, ni ọjọ keji o mu irin ajo ọna ọdọ balogun ọrun pọn pẹlu wọn. Ẹko yi ti wọnu Apọsteli pataki yi ṣinṣin: wi pe bi a ba ti tete mu ohun ti Ọlọrun palaṣẹ ṣe to ni yoo ti rọrun to lati ṣe e. Nigba ti iran yi ṣi n gbona lọkan Peteru sibẹ, o dide pẹlu ọkan akin; ṣugbọn bi o ba lọra tabi ki o maa fa tikọ, iṣẹ ti o wà niwaju rè̩ yi yoo tubọ maa ṣoro sii fun un lati ṣe.
Peteru ati awọn arakunrin ti o wà lọdọ rè̩ ni Joppa mọ iha ti awọn ti n bẹ ni Jerusalẹmu kọ si idapọ pẹlu awọn Keferi. Wọn ka a si eewọ fun Ju lati ba Keferi jẹun – ki i ṣe pe Ọlọrun fi ofin bẹẹ lelẹ nigba kan ri, ṣugbọn nitori pe ofin atọwọdọwọ yi ti wa lati irandiran. Ọlọrun ran Peteru lọwọ, O gba a kuro lọwọ agalamaṣa ọjọ pipẹ yi laarin iba iṣẹju diẹ, ṣugbọn Peteru huwa ọlọgbọn ni ti pe o tara ṣaṣa lati mu aṣẹ Ọlọrun ṣẹ kánkan. Onigbagbọ ti o ba fẹ gbe igbesi-aye iṣẹgun ni lati tẹle apẹẹrẹ yi.
Ẹgbẹ Kan Naa
Nigba ti Peteru ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ de ọhun, Kọrneliu fi ayọ pade wọn, ayọ naa pọ to bẹẹ ti o fi wolẹ lẹsẹ Peteru lati fori balẹ fun un. Awọn ara Ila-oorun a saba maa wolẹ fun awọn ti o ju wọn lọ, boya Kọrneliu gba pe onṣẹ pataki lati ọdọ Ọlọrun wa ni Peteru i ṣe, ti angẹli ran si i. Bi o ti wu ki o ri, Peteru ṣe alaye ọran yi, nitori pe o gbe e dide, o si wi pe, “Dide; enia li emi tikarami pẹlu.” Iran ti Ọlọrun fi han Peteru ti kọ ọ li ẹkọ pataki kan sii. Awọn Ju a maa sọrọ si awọn Keferi bi aja, o ṣoro fun wọn lati gba pe ẹlẹgbẹ wọn ni awọn eniyan orilẹ-ède miran; ṣugbọn Peteru ba Kọrneliu sọrọ bi eniyan – bi ẹlẹgbẹ rè̩.
Isin igbagbọ ni o leke ni ti pe o mu ki gbogbo eniyan wa ni idọgba. Ọpọlọpọ orilẹ-ède ni o ti ṣe ofin lati tẹ ọran yi mọ awọn ara ilu wọn leti; ọpọ igbimọ ni o ti ṣe ipade fun wakati aimoye lati fi opin si ọran yi, ṣugbọn igbagbọ nikan ni o kapa ọran adiitu yi. Nigba ti ẹni kan ba di ẹbi Ọlọrun, o di ara kan naa pẹlu awọn ọmọ-ẹgbẹ agbo Kristi, ohunkohun ti o wu ki ipo, àwọ, tabi ẹsin ti o ti dimu tẹlẹ ki o jẹ. Ẹgbẹ pupọ n bẹ ti i maa jalankato nipa ifẹ-ará ati iṣọkan ti wọn ni si ara wọn, ṣugbọn nigba ti akoko lati hu u niwa ba de, wọn a kuna patapata. Igbagbọ tootọ ko le kuna ninu eyi rara.
Bi Peteru ti wọle Kọrneliu, o ba eniyan pupọ ti o n duro de e nibẹ. O beere lọwọ wọn eredi rè̩ ti wọn fi ranṣẹ pe oun, lẹsẹ kan naa ni o fi ye wọn iru iyọṣutisi, eebu ati inunibini ti Ju ti o ba dara pọ mọ orilẹ-ede miran yoo ba pade. Kọrneliu dahun lọgan. O ranṣẹ lọ i pe Peteru nitori pe angẹli kan lati ọdọ Ọlọrun ni o sọ fun un lati ṣe bẹẹ, Kọrneliu si wi pe, “Iwọ si ṣeun ti o fi wá.” Gẹgẹ bi agbọrọsọ fun awọn ti o wà nibẹ lati gbọ ọrọ peteru, Kọrneliu tẹ siwaju ninu ọrọ rè̩ wi pe, “Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ ohun gbogbo ti a pa laṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá.” Awọn ọkan ti ebi n pa niwọnyi nitootọ! “Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo nitori nwọn ó yo” (Matteu 5:6).
Isọji
Ohun ti angẹli nì sọ fun Kọrneliu ti o mu ki o ranṣẹ si Peteru ni pe, “On ni yio sọ fun ọ bi iwọ o ti ṣe.” ṣugbọn Kọrneliu ko fẹ dá nikan gbọ ọrọ iyanu ti iye. Ọpọ ninu awọn ojulumọ, iyekan ati ọrẹ Kọrneliu n bẹ ni Kesarea ti ọkan wọn fà mọ ọna iwa-bi-Ọlọrun tootọ gẹgẹ bi o ti ri fun Kọrneliu. Lai si aniani, Kọrneliu ti ba awọn eniyan yi sọrọ nipa ọrọ ẹsin nigba pupọ, bi ẹni kọọkan tabi ni apapọ. S̩ugbọn ohun kan daju: Kọrneliu fẹ ki iṣẹ-iranṣẹ Peteru ni Kesarea yọri si rere. Eniyan Ọlọrun n bọwa! Isọji de tan bi olukuluku ba ṣe ipa ti rẹ. S̩ugbọn ni ti ọran yi, ọwọ Kọrneliu nikan ni ojuṣe naa wà, nitori pe oun nikan ni o mọ pe Peteru n bọ. Kọrneliu ṣe iṣẹ yi yanju, nitori pe ọpọlọpọ eniyan ni o pejọ lati gbọ ọrọ Peteru, Ọlọrun ko si fi akanṣe ibukun Rè̩ du wọn.
Ilana isọji ni yi fun gbogbo ijọ: adura ati ẹbẹ titi Ọlọrun yoo fi fun awọn eniyan Rè̩ ni idaniloju pe Oun yoo ran iranwọ, ati pe ki a tun kede fun gbogbo eniyan pe eniyan Ọlọrun kan n bọ lati kede Ihinrere ti Igbala. Gbogbo awọn eniyan ti wọn ba si wọ ẹnu ọna ile Oluwa ṣe bẹẹ pẹlu ọkàn kan, “lati gbọ ohun gbogbo ti a pa laṣẹ ... lati ọdọ Ọlọrun wa.”
Njẹ iru akitiyan bi eyi le kuna? Agbẹdọ! Iru eyi ha le ṣẹlẹ ni ode-oni ti o kun fun ẹṣẹ, ati iwa buburu, ti afẹ aye yi si gbilẹ kan dipo iwa-bi-Ọlọrun? O ṣe e ṣe bi awọn eniyan Ọlọrun ba tẹramọ adura kikankikan lori ọran yi, ti wọn ba si ṣe olootọ lati maa rọ awọn iyekan ati ọrẹ wọn lati wa si ile Ọlọrun.
Igbala ati Isọdi-mimọ
Otitọ ti a tẹnumọ ju lọ ni ibẹrẹ Iṣe Awọn Apọsteli ni fifi agbara Ẹmi Mimọ wọ ni, sibẹ awọn ti o gba ẹbun yi ni lati jẹ alabapin oore-ọfẹ ti awọn ti igba nì ni lakoko ti wọn – atunbi (Idalare) ati isọdi-mimọ patapata – ki wọn to le ni anfaani lati gba agbara Ẹmi Mimọ. Ọlọrun ki i pa otitọ ati imọlẹ ti o ti wà tẹlẹ ti, tabi ki O ṣe lodi si i, ṣugbọn otitọ miran ti o ba fara han yoo jẹ eyi ti o tàn imọlẹ si otitọ ti o ti wà tẹlẹ. Eyi ni ofin ti o n ṣakoso iṣipaya lati ọdọ Ọlọrun wá. Nisinsinyi ti Ọlọrun n tú Ẹmi Mimọ jade sara eniyan gbogbo, Oun ko pa idalare tì, eyi ti o fi han fun Abrahamu olododo, ṣugbọn O tubọ jẹ ki a ri i kedere. Bakan naa ni ko pa isọdi-mimọ patapata tì, ṣugbọn ni akoko Oore-ọfẹ yi, O tubọ fi han fun ni gbangba kedere, O si fi han bi o ti ṣe pataki to.
Awọn ara ile Kọrneliu ti ni idalare ati isọdi-mimọ ki Ẹmi Mimọ to bà le wọn. Kọrneliu jẹ olufọkansin ati ẹni ti o “bẹru Ọlọrun tiletilé rè̩ gbogbo” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:2). Ẹnikẹni ti i ṣe olufọkansin ni lati jẹ ẹni ti n rin ninu gbogbo imọlẹ ti o tàn si ọnà rè̩. Wọn ti gbọ “ọrọ ti Ọlọrun ràn si awọn Ọmọ Israẹli, nigba ti o waasu alaafia nipa Jesu Kristi.” Peteru wi pe, “Ẹnyin na mọ orọ na ti a kede rè̩ yika gbogbo Judea” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:36, 37). Pẹlupẹlu, Ọlọrun sọ fun Peteru ninu iran wi pe, “Ohun ti Ọlọrun ba ti wè̩nu, iwọ máṣe pe e li èwọ mọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:15). Paulu, nipa imisi Ẹmi Mimọ sọ wi pe, “Kristi si ti fẹran ijọ, ti o si fi ara rè̩ fun un; ki on ki o le sọ ọ di mimọ lẹhin ti a ti fi ọrọ wẹ ẹ mọ ninu agbada omi. Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rè̩ bi ijọ ti o li ogo li aini abawọn tabi alebu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ ati alaini abuku” (Efesu 5:25-27).
Peteru sọ fun ni pe, “Ọlọrun, ti iṣe olumọ-ọkan, o jẹ wọn li ẹri, o nfun wọn li Ẹmi Mimọ, gẹgẹ bi awa; ko si fi iyatọ si arin awa ati awọn, o nfi igbagbọ wẹ wọn li ọkan mọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 15:8, 9). Ninu ede Griki, itumọ ọrọ ti a gbe kalẹ yi ni pe a ti ṣe ohun naa pari tẹlẹtẹlẹ. O han gbangba kedere wi pe awọn eniyan wọnyi ti ni idalare ati isọdi-mimọ ki Ẹmi Mimọ to bà le wọn.
Awọn ẹlomiran n kọ ni wi pe awọn eniyan wọnyi ko ti i ni igbala nitori pe angẹli nì sọ fun Kọrneliu pe, “Peteru ... yio sọ ọrọ fun ọ, nipa eyiti a o fi gbà iwọ ati gbogbo ile rẹ là” (Iṣe Awọn Apọsteli 11:13, 14). Eyi ko fi han pe wọn ko ni igbala bi a ko ti le sọ wi pe awọn Apọsteli ko ni igbala nigba ti wọn wi pe, “S̩ugbọn awa gbagbọ pe nipa ore-ọfẹ Oluwa Jesu awa o là, gẹgẹ bi awọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 15:11). Itumọ kan naa ni awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi ni pẹlu ọrọ ti Jesu sọ pe, “Ẹniti o ba foriti i titi de opin, on na li a o gbalà” (Marku 13:13).
Ko si ẹnikẹni ti o ti i gba awọn oore-ọfẹ Ọlọrun ni agbapọ lẹẹkan ṣoṣo. A ko sọ fun ni nibikibi ninu Iwe Mimọ pe awọn Apọsteli, awọn ara Efesu, Samaria, ara ile Kọrneliu tabi ẹnikẹni miran ri igbalà ati isọdi-mimọ gba pọ lẹẹkan ṣoṣo. Bi a ko tilẹ mọ igba ti awọn Apọsteli ati awọn ti o gba Ẹmi Mimọ ni Ọjọ Pẹntikọsti ri igbala ati isọdi-mimọ gbà, sibẹ ko si aniani ni ti pe wọn ti ri awọn iṣẹ oore-ọfẹ wọnyi gba ṣaaju Ọjọ Pẹntikọsti.
A ko ri i ka ninu Iwe Mimọ tabi iwe miran wi pe woli, Apọsteli, ajẹriku tabi awọn akọni ninu igbagbọ kan ni iyipada ọkan a si tu irugbin ẹṣẹ abinibi kuro ninu ọkan rẹ lẹẹkan ṣoṣo naa; ṣugbọn ẹri ogunlọgọ eniyan mimọ Ọlọrun fi han wi pe wọn ri iṣẹ oore-ọfẹ keji ti o yanju gba lẹhin iyipada ọkàn wọn. Ninu wọn ni a gbe le ri ijimi ninu ẹkọ, awọn ti o fara mọ Ọlọrun timọ-timọ ati awọn eniyan mimọ Ọlọrun ti Ọlọrun bu iyin fun, lati igba awọn Apọsteli.
Baptismu Ẹmi Mimọ
Bi Peteru ti n waasu fun awọn Keferi ni ile Kọrneliu, Ẹmi Mimọ bà le awọn ti n gbọ ọrọ rè̩. Ẹnu ya Peteru ati awọn arakunrin ti o wá lati Joppa lati ri i pe Ọlọrun fi iru ẹbun kan naa ti awọn Ju ri gba ni Ọjọ Pẹntikọsti fun awọn Keferi. Nihin pẹlu, awọn Ju ro pe Ẹmi Mimọ Ọlọrun – Ifarahan itanṣan ogo Ọlọrun ninu Agọ ati Tẹmpili – ko tayọ ilẹ Israẹli ati iru ọmọ Abrahamu, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin wọnyi ri i pe a kò ha Ọlọrun mọ ibi kan tabi ọdọ awọn eniyan kan. Nigba ti Peteru ri i pe Ọlọrun tẹwọ gba awọn eniyan wọnyi patapata, o paṣẹ pe ki a baptisi wọn ki a si gba wọn sinu agbo Ijọ, nipa bayi o fi han fun ẹnikẹni wi pe awọn iriju Ọlọrun ni ayé ki i fi aṣẹ Ọlọrun falẹ.
Ẹbun ti Ẹmi Mimọ ti Kọrneliu ati awọn ọrẹ rè̩ gba yi ko ṣe e fẹnusọ. O fi idi otitọ ti n bẹ ninu ọrẹ ti Peteru sọ mulẹ fun awọn Keferi – ani ikede nipa igbesi-aye Jesu, iku ati ajinde Rè̩. O ṣilẹkun oore-ọfẹ ati igbagbọ silẹ fun awọn Keferi, wọn si wà dọgba-dọgba pẹlu awọn Ju loju awọn Apọsteli. O mu ki ọgba-ajara Ọlọrun ki o gbooro tayọ agbegbe Palẹstini de gbogbo agbaye. Nkan bi ẹgbaa ọdun ti kọja lati igba naa; ṣugbọn iṣẹ naa pọ sibẹ bi ti igba nì. Ọgba-ajara Oluwa n fẹ oṣiṣẹ sibẹsibẹ. Iṣẹ pupọ ni o wà lati ṣe; n jẹ kin ni Oluwa Ikore yoo ha sọ fun wa nigba ti a ba duro niwaju Rè̩? Yoo ha wi pe “Eṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe?” Tabi yoo ha le wi pe, “O ṣeun, iwọ ọmọ¬-ọdọ rere ati olootọ.”
Questions
AWỌN IBEERE- Eeṣe ti Peteru ati awọn ọrẹ rè̩ fi lọ si Kesarea?
- Tani n duro de Peteru ni Kesarea?
- Awọn tani Peteru waasu fun?
- Sọ o kere tan awọn otitọ pataki mẹta ti Peteru fayọ ninu iwaasu rè̩.
- Kin ni ohun pataki ti o ṣẹlẹ lẹhin iwaasu Peteru?
- Eeṣe ti ẹnu fi ya Peteru ati awọn ọmọ-ẹhin?
- Kin ni imọran Peteru nigba ti o ri i pe awọn Keferi ti gba Ẹmi Mimọ?