Iṣe Awọn Apọsteli 11:1-26

Lesson 304 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi; ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ” (Romu 9:25).
Cross References

I Jija fun Otitọ

1. Awọn onitara arakunrin ti o wà ni Judea ba Peteru wijọ nitori pe o ba awọn Keferi jẹun pọ, Iṣe Awọn Apọsteli 11:1-3

2. Peteru ṣe irohin kikun nipa ibẹwo ti o lọ ṣe ni ile Kọrneliu, Iṣe Awọn Apọsteli 11:4-10

3. Ẹmi Ọlọrun ni o rọ Peteru lati ba awọn iranṣẹ Kọrneliu lọ, Iṣe Awọn Apọsteli 11:11, 12

4. Ọlọrun tipasẹ iwaasu Peteru ṣiṣẹ, nitori Ẹmi Mimọ bà le awọn Keferi, Iṣe Awọn Apọsteli 11:13-16

5. Awọn arakunrin ti i ṣe Ju pa ẹnu wọn mọ, wọn si yin Ọlọrun logo bi Peteru ti pari alaye rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 11:17, 18

II Ijọ Ọlọrun n Tankalẹ

1. Inunibini tu awọn arakunrin kaakiri lọ si ibi gbogbo, Iṣe Awọn Apọsteli 11:19

2. Itan Jesu Oluwa n gbona ni ọkàn awọn ọmọ-ẹhin to bẹẹ ti wọn n waasu rè̩ ni gbogbo ilu ti wọn de, Iṣe Awọn Apọsteli 11:20, 21

III Isọji ni Antioku

1. Ọrọ Oluwa ṣiṣẹ pataki ni Antioku, nitori naa ijọ ti o wà ni Jerusalẹmu rán Barnaba lati lọ ràn wọn lọwọ, Iṣe Awọn Apọsteli 11:22

2. Barnaba ri ọwọ agbara Ọlọrun nibẹ, o si gba awọn eniyan naa niyanju lati fara mọ Oluwa, Iṣe Awọn Apọsteli 11: 23, 24

3. Oluwa ṣe ọna Barnaba ni rere, o si lọ si Tarsu lati ṣe awari Saulu, Iṣe Awọn Apọsteli 11:25, 26

4. Ni Antiọku ni a kọ pe awọn ọmọ-ẹhin ni Kristiani, Iṣe Awọn Apọsteli 11:26

Notes
ALAYÉ

Ọna Là

Peteru bẹrẹ iwaasu rè̩ ni ile Kọrneliu nipa sisọ otitọ kan ti a ti kọ si i (Peteru) ni ọkan: “Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojusaju enia” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34). Otitọ yi ko yipada, nitori pe ni atetekọṣe, Ọlọrun wi pe, “Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ?” (Gẹnẹsisi 4:7). S̩ugbọn nitori ẹkọ awọn Ju, ofin atọwọdọwọ ati ẹta’nu wọn, Peteru ko mọ titi o fi di ọjọ naa pe gbogbo eniyan ni otitọ yi wà fun.

Nigba ti Ijọ kọ bẹrẹ, o dabi ẹni pe ti awọn Ju nikan ni; ṣugbọn nipa ipe Kọrneliu ati awọn ara ile rè̩, Ọlọrun ṣe ayipada nla O si jẹ ki o di mimọ wi pe ifẹ Oun ni lati kó awọn Keferi pọ ninu eto Irapada Rè̩. Awọn Apọsteli ati awọn ọmọ-ẹhin ti ni ero wi pe awọn Ọmọ Israẹli nikan ati awọn Keferi ti o wa ni abẹ Ofin Mose nikan ni o ni ẹtọ si isin Ọlọrun; ṣugbọn nisinsinyi, ilẹkun igbagbọ ti ṣi silẹ fun ẹnikẹni ti o ba fẹ wọle. Awọn ipààla igbekalẹ Ofin Mose ti wa sopin; ninu Kristi Jesu ko si “Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira” (Kolosse 3:11).

Bi a ba wo titobi ati iṣoro ti n bẹ ninu iyipada ẹkọ ati aṣa laelae nì ti o doju-kọ Ijọ tikara rè̩, a o ri eredi rè̩ ti Ọlọrun fi ṣi ọna silẹ pẹlu ọpọ iṣẹ iyanu. Ifarahan angẹli ti o sọ fun Kọrneliu lati ranṣẹ pe Peteru; pẹlupẹlu, iran ti Ọlọrun fi han Peteru ati itọni ti o fun un ni oke pẹtẹsi nikẹhin eyi ti a sọ wi pe, “Ba wọn lọ maṣe kọminu ohunkohun,” ati itujade Ẹmi Mimọ sori awọn ti o pejọ ni ile Kọrneliu, fi han gbangba fun Peteru ati awọn arakunrin ti o ba a lọ si Kesarea pe Ọlọrun ni o ṣe e. Wọn ba awọn eniyan naa yọ wi pe Ọlọrun ti ṣilẹkun Ijọ Rè̩ silẹ fun awọn Keferi gẹgẹ bi O ti ṣi i fun awọn Ju pẹlu.

Ihinrere ti n Tè̩ Siwaju

Nigba ti Peteru pada bọ si Jerusalẹmu lati Kesarea, o ba awọn ọmọ-ẹhin onitara pade, awọn ẹni ti o ba a ṣe ọpẹ-alaye ni ti pe o lọ si ile Kọrneliu o si ba awọn Keferi jẹun. Eyi rú awọn Onigbagbọ ti n bẹ ni Jerusalẹmu loju, nitori pe o lodi si aṣa ti o ti wà lati igba laelae; ṣugbọn Peteru sọ ohun gbogbo ti o ṣẹlẹ lati ibẹrẹ o si ṣe alaye fun wọn. Peteru pari ọrọ i sọ bayi pe, “Tali emi ti emi o fi le de Ọlọrun li ọna?” Nigba ti wọn ti gbọ ọrọ wọnyi, wọn kò sọrọ mọ, wọn si yin Ọlọrun logo, wi pe, “Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si iye fun awọn Keferi pẹlu.” Ọmọ-ẹhin tootọ ni wọn i ṣe, nitori pe wọn fi tọkantọkan gbe ero ti ara wọn tì si apa kan nigba ti ifẹ Ọlọrun di mimọ fun wọn.

Awọn ẹlomiran korira itẹsiwaju, paapaa ju lọ nipa ti ọrọ ẹsin. Niwọn igba ti ijọ ba ti rọ mọ aṣa ati igbekalẹ wọn atẹhinwa, ija ko si, ṣugbọn nigba ti a ba ṣe eto itẹsiwaju Ihinrere ti a si bẹrẹ si mu un ṣe, awọn wọnyi yoo maa kẹgan iru eto bẹẹ. Wọn yoo wi pe, “Ijọ yi kò dabi ti atijọ mọ,” awọn miran yoo wi pe, “Aṣiṣe patapata ni eyi jasi” tabi pe, “A kò ri iru eyi ri.” Ọlọrun ni Olupilẹṣẹ Ijọ. Ẹ jẹ ki O ṣe ayipada ti o ba tọ ni oju Rè̩ ninu igbekalẹ ijọ. Ti wa ni lati jẹ ojulowo Onigbagbọ to bẹẹ ti a o fi le mọ awọn eto Ọlọrun ti a o si fi ara mọ ọn.

Ọlọrun ko yipada, eto igbala pẹlu ko yipada; ṣugbọn ọna tabi ohun ti Ọlọrun n lo lati ba ọkan ẹlẹṣẹ sọrọ a maa yipada nigba miran. Ẹnikẹni ti ọkan rè̩ ba tako awọn iyipada ti Ọlọrun ṣe yoo ri i pe ara ko ni rọ oun mọ nibi ti o jẹ wi pe oun gbe ti ni idapọ didun tẹlẹ ri. Ẹnikẹni ti ko ba dàgbà mọ ninu oore-ọfẹ ati ninu imọ Oluwa ati Olugbala Jesu Kristi ko ni le ba Ijọ Kristi ti o n tẹ siwaju rin pọ. Ijọ ti ko ba ntẹ siwaju ki i ṣe Ijọ Kristi.

Atilẹba

Nibi ti awọn kan kò ti fẹ eto ti o mu itẹsiwaju wa, nibẹ ni awọn miran gbe wà ti o ṣe pe ọna ti wọn nikan ni o dara loju wọn -- wọn ko fẹ tọ ipasẹ ẹlomiran. Ewu n bẹ ninu pe ki a pọn si ọwọ ọtun tabi si ọwọ osi pupọ ju. S̩ugbọn ẹni ti o ba n tẹle ifẹ pipe Ọlọrun yoo dabi ẹni pe kò tilẹ ṣe awokọ ẹnikẹni rara. Ọlọrun yoo maa mi si awọn eniyan Rè̩ lati ṣe ohun pupọ ti o tayọ ọgbọn ati oye awọn paapaa, ṣugbọn Onigbagbọ ni lati ṣọra gidigidi lati ri pe lati ọdọ Ọlọrun ni iru imisi bẹẹ ti jade wá. Gbogbo imisi Ọlọrun ni o n ṣe rẹgi pẹlu Ọrọ Ọlọrun. Peteru kò kugbu ṣe ohunkohun. Ọlọrun fi ipinnu Rè̩ han gbangba kedere nipa imisi ati ifarahan lọpọlọpọ titi Peteru fi ni idaniloju ohun ti Ọlọrun n fẹ gan an. Awọn ti ọrọ naa ti rú loju tẹlẹ ri fara mọ ohun ti Peteru ṣe nigba ti wọn gbọ alaye rè̩.

Nigba ti Ọlọrun ba fẹ ran ọkan kan jade lati lọ bẹrẹ iṣẹ nibi kan, Oun yoo jẹ ki ohun gbogbo di mimọ lai si ani-ani. Olukuluku ọkan ni lati duro de Ọlọrun gidigidi ninu adura lati mọ daju pe Ọlọrun ni o pe oun lati ṣe ohun kan tabi iṣẹ kan pato. Awọn wọnni ti n lọ ṣaju aṣẹ Ọlọrun, ti o gba ọna abuja dipo ọna taara ti Ọlọrun là silẹ ti mu ọpọlọpọ abuku ba Ihinrere Kristi. Ọlọrun yoo ran ipe Rè̩ jade ju igba kan ṣoṣo lọ gẹgẹ bi O ti ṣe fun Samuẹli, bi eyi ba tọ bẹẹ ni oju Rè̩. Leke gbogbo rè̩, awọn eniyan Ọlọrun yoo mọ ipe Ọlọrun yatọ. A ko le fi gbogbo ọkan gbe ara le ipe ti o jẹ pe ẹni ti a n pe nikan ni o ni idaniloju rè̩; ṣugbọn nigba ti ipe ba daju, lai si ani-ani, ti awọn miran ti n rin nipa ti ẹmi ba ri i daju, jẹ ki a fi gbogbo ọkan karamọ ọn titi de opin lai ka iṣoro tabi inunibini si.

Ni Antioku

Nigba ti awọn Apọsteli ati awọn ọmọ-ẹhin Jesu ri i pe a ti ṣilẹkun Ihinrere fun awọn Keferi, wọn bẹrẹ si i waasu ọrọ naa fun wọn ati fun awọn Ju pẹlu. Gbogbo ẹda eniyan ni o ni anfaani lati wa gba igbala. Inunibini ti tu awọn ọmọ-ẹhin kaakiri, ṣugbọn ko le ja ifẹ Jesu Kristi ati ireti ajinde gba kuro lọkan wọn. Itan Jesu ko kuro ni ete wọn nibikibi ti wọn ba wà. Ipe awọn Keferi sinu agbo Ijọ Ọlọrun mu ki iṣẹ wọn fẹrẹ ki o si fi idi mulẹ. Nigba pupọ ni awon Keferi n fi ayọ gba Ihinrere.

Awọn ara Antioku jẹ apẹẹrẹ kan. Ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin lati ẹkùn Kipru ati Kirene wá si ilu yi, wọn si bẹrẹ si waasu Ihinrere fun awọn Hellene nipa Jesu. Ọpọlọpọ gbagbọ wọn si yipada si Oluwa, ihin isọji yi si tan de eti igbọ Ijọ ni Jerusalẹmu. Awọn Apọsteli ran Barnaba lati lọ ṣe iranwọ. Boya iyemeji n ṣe awọn Apọsteli bi isọji tootọ ni o bẹ silẹ ni Antioku tabi bẹẹ kọ nitori pe a ko gbọ okiki awọn ọmọ-ẹhin ti o lọ waasu nibẹ to bẹẹ. A ko sọ orukọ wọn fun ni ninu akọsilẹ yi, ṣugbọn Barnaba ri i pe awọn ọmọ-ẹhin naa jẹ ọmọ-ẹhin tootọ ati pe isọji naa paapaa nilaari. Oore-ọfẹ Ọlọrun wà pẹlu awon eniyan wọnyi, inu Barnaba si dun. Iwaasu rè̩ ti o kún fun imisi Ọlọrun rú ọkan awọn ara Antioku soke, nipa bẹẹ a yan ọpọlọpọ ọkan kún Ijọ.

Nigba pupọ ni a n pe awọn eniyan Ọlọrun ni alamọga nitori pe wọn ko fara mọ idapọ pẹlu “gbogbo afẹfẹ ẹkọ.” Ẹgbẹ kan n bẹ kaakiri gbogbo agbaye loni ti o n du lati pa gbogbo ijọ pọ ṣọkan; ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun kilọ fun wa pe, “Ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmi gbọ, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmi wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ ti jade lọ sinu aiye” (I Johannu 4:1). Igbagbọ tootọ ko ṣẹṣẹ ni i wa ofin tabi ẹgbẹ kan lati mu wọn ṣọkan, nitori pe awọn Onigbagbọ tootọ a maa ni idapọ pẹlu ara wọn lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba ri ara wọn nibikibi ti o wu ki wọn gbe ri ara wọn. Lẹsẹkẹsẹ ti Barnaba ti ri oore-ọfẹ Ọlọrun laarin awọn eniyan yi ni ayọ rè̩ ti kún. Ko si ọrọ didun kan tabi aperò lori isọji, tabi eto igboke-gbodo isin ajumọṣe ni ilu Antioku ati agbegbe rẹ ti o le mu inu ajihinrere ti o wá lati Jerusalẹmu yi dun bi oore-ọfẹ Ọlọrun ti n bẹ lọkàn awọn eniyan yi. Isọji yi larinrin to bẹẹ ti Barnaba fi wá Saulu lọ si Tarsu ti o si mu un wa si Antioku. Wọn jumọ ṣiṣẹ pọ ninu ọgba-ajara Oluwa fun ọdun kan gbako, iṣẹ wọn si mu eso pupọ jade fun Ọlọrun.

Awọn Onigbagbọ

“Ohun titun kan” n bẹ “labẹ ọrun” ni Antioku. Si iyalẹnu awọn ara ilu yi, a ri awọn Ju diẹ ti o sa wá lati Jerusalẹmu wọn n sọ itan aladun kan. Fun igba kinni, awọn Keferi Hellene ti o wà ni ilu yi gbọ itan Jesu, Ọmọ Ọlọrun ti O wa saye, ti O kú ti o si tun jinde. Ọpọ ninu awọn Hellene gbagbọ, wọn si gba ọrọ naa yẹwo. Wọn gbadura si Oluwa, wọn kepè E fun aanu, wọn ronupiwada ẹṣẹ wọn, wọn si kọ ọna ti wọn ti n tọ silẹ. Ọlọrun gbọ adura wọn, O fi È̩jẹ ni wẹ ọkàn wọn, O si fun wọn ni agbara lati gbe igbesi-aye ti ko lẹṣẹ; “ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i nwọn si di titun” (II Kọrinti 5:17).

Awọn ara Antioku ko mọ bi a ti le ro ti awọn ọkunrin wọnyi si. Awọn Ju n pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni “awọn ara Nasarẹti” tabi “awọn ara Galili” pẹlu ẹgàn ati iyọṣuti si ti ko ṣe e fẹnusọ; ṣugbọn awọn ara ilu yi jẹ Keferi, ọna wọn si jin si ibi ti Jesu gbe ṣe iṣẹ-iranṣẹ Rè̩. A ni lati wa orukọ titun miran, awọn ara Antioku ni o si le sọ oju abẹ niko, arofọ, awada wọn ati sisọ eniyan ni orukọ ànijé̩ ko lẹgbẹ. Awọn eniyan wọnyi jẹ ọmọlẹhin Jesu Kristi – eniyan Kristi – nitori naa wọn sọ wọn ni Kristiani. Boya awọn afiniṣẹsin ni o pe wọn bẹẹ lati fi wọn ṣẹfẹ, ṣugbọn orukọ yi ti di orukọ ti a fi n pe awọn ọmọlẹhin Jesu Kristi kaakiri gbogbo agbaye, tayọtayọ ni awọn paapaa si fi n pe ara wọn bẹẹ.

Isọji Lọnakọna

Awọn akọsilẹ wọnyi ninu Ọrọ Ọlọrun ti o sọ nipa idagbasoke ipe ifẹ Ọlọrun si gbogbo eniyan ni lati rú ifẹ ọkan gbogbo Onigbagbọ tootọ soke lati gbadura pe ki isọji nlanla ti yoo tan jakejado gbogbo agbaye ki o bẹ silẹ. “Igbagbọ ti a ti fi lé awọn enia mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” ni o mu ki awọn eniyan Ọlọrun wọnyi lọ si gbogbo ẹkun aye igbaani pẹlu adura kikan ni ookan aya wọn fun gbogbo ẹda, ti ete wọn si n sọ itan iyanu ti idande. Wọn waasu pẹlu igboya ati aṣẹ, isọji si n tẹle e. Kọrneliu ṣe alabapin isọji. Eeṣe? Angẹli Ọlọrun wi pe, “Adura rẹ ati ọrẹ-ānu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlorun fun iranti” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:4). Kọrneliu n gbadura, o si n gbaawẹ ni wakati kẹsan ọjọ -- agogo mẹta ọsan. Ọpọlọpọ eniyan ni yoo maa gboke-gbodo nidi iṣẹ tabi afẹ, wọn o tẹra mọ iṣẹ oojọ wọn tabi ki wọn maa ṣe ohunkohun ti wọn ti yan lati maa ṣe nigba ti ọwọ ba dilẹ, wọṅ le maa jẹun tabi ki wọn maa sinmi – ohunkohun ni a le ba lọwọ wọn, yatọ si adura, ni agogo mẹta ọsan. Iṣẹ Ọlọrun ni lati leke lọkàn ẹnikẹni ti o n pe ara rè̩ ni Onigbagbọ; ṣugbọn wo bi ọpọlọpọ wa ti kuna ninu ohun ti o tọ fun wa lati ṣe. S̩iro ọpọ akoko ati ohun miran gbogbo ti awọn eniyan n lo fun ara wọn ki o si wo iwọn iba diẹ ti wọn n lo fun Ọlọrun. Wo ọpọ ọkàn ti n lọ si iparun nitori pe ẹni kan kọ lati nawo-nara lati jẹ ẹlẹri fun Kristi. Isọji ti yoo gbilẹ kan ko le bẹ silẹ afi bi Ijọ Ọlọrun ba le san ohun ti yoo gba a.

Ifẹ Ọlọrun ni pe ki O jọba lọkàn ọmọ-eniyan ki O si maa ṣe akoso rè̩. Ilẹ aye ti n ṣu lọ yi beere pe ki a maa gbadura nigba gbogbo, gẹgẹ bi Kọrneliu – ki a má ṣe kọ isẹra-ẹni ti yoo gbà wa bi ẹni kọọkan – lati tubọ ni idapọ pipe pẹlu imọ Ọlọrun lati kede yi fun gbogbo agbaye. Ẹsẹ ọmọ-ogun Kristi ti o ba jẹ alagbayọri adura yoo maa lọ geere si Ọrun ni opopo ọna iwa-mimọ. Oun ki yoo nikan rin; nitori pe awọn miran ti o ri irin ajagun-ṣẹgun ti o n nrin, yoo tẹle e lati ba a rin.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eeṣe ti awọn ọmọ-ẹhin ni Jerusalẹmu fi n ba Peteru ṣe opẹ-alaye?
  2. Bawo ni Peteru ṣe fesi si ariwisi wọn?
  3. Kin ni ohun mẹrin ti o fi ọkan Peteru balẹ pe Ọlọrun ni o ran an si Kọrneliu?
  4. Kin ni Ẹmi Mimọ ti o bà le awọn Keferi ṣe fun Ijọ Ọlọrun?
  5. Kin ni ohun pataki ti o tu awọn ọmọ-ẹhin kaakiri gbogbo ibi ti wọn mọ ni agbaye nigba nì?
  6. Tani waasu fun awọn ara Antioku?
  7. Lọna wo ni iwaasu wọn fi yatọ si ti awọn ọmọ-ẹhin miran?
  8. Tani a ran lati Jerusalẹmu lati lọ ṣe iranwọ ninu isọji Antioku?
  9. Kin ni orukọ ti awọn ara Antioku pe awọn ọmọlẹhin Kristi?
1