Lesson 305 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ikú li ère è̩ṣẹ; ṣugbọn è̩bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6:23).Cross References
I Jehoṣafati bẹ Ahabu wo
1. Jehoṣafati dara pọ mọ Ahabu, I Awọn Ọba 22:1, 2; II Kronika 18:1, 2; 19:2; OrinDafidi 1:1
2. Ahabu bẹ Jehoṣafati lati ba a lọ jagun ni Ramọti-Gileadi, I Awọn Ọba 22:3, 4; II Kronika 18:2, 3
3. Jehoṣafati fẹ beere lọdọ Oluwa, I Awọn Ọba 22:5; II Kronika 19:3; Orin Dafidi 27:8
II Woli Tootọ ati Woli Eke
1. Ahabu kó irinwo woli eke jọ, I Awọn Ọba 22:6; Jeremiah 23:13-40
2. Jehoṣafati wá woli tootọ, I Awọn Ọba 22:7-10; Amọsi 8:11, 12
3. Awọn woli eke wi pe, “Lọ ... ki o si ṣe rere,” I Awọn Ọba 22:11, 12; Isaiah 30:10; Jeremiah 28:1-11
4. Mikaiah sọ otitọ, I Awọn Ọba 22:13-25; Jeremiah 28:12-17
III Ogun ni Ramoti-Gileadi
1. Ahabu pa ara rè̩ dà, I Awọn Ọba 22:29-33; Matteu 10:26; I Kọrinti 4:5
2. Ahabu gba ọgbé̩ o si kú, I Awọn Ọba 22:34-37
3. Asọtẹlẹ Elijah ṣẹ, I Awọn Ọba 22:38-40; 21:17-24
Notes
ALAYÉIbarẹ Aye
“Emi bi iwọ.” Ọrọ ti Jehoṣafati fi da Ahabu lohun yi buru jai bi o ti jẹ pe ko si ẹni ti o buru to Ahabu. S̩ugbọn Jehoṣafati jẹ ẹni ti o wá Ọlọrun ti o si n rin ni ọna Rè̩. Nigba ti Jehoṣafati dabi Ahabu, ko mu Ahabu mọ ọna rere ti oun ti mọ, kaka bẹẹ o rẹ ara rè̩ silẹ lati ba Ahabu dọgba. O ba Ahabu ṣọrẹ, ṣugbọn o sọ ibarẹ Ọlọrun nu. “Ẹ kò mọ pe ibarẹ aiye iṣọta Ọlọrun ni? Nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ ọrẹ aiye di ọta Ọlọrun” (Jakọbu 4:4). Tani ọrẹ rẹ? tani ọta rẹ?
Awọn Woli Samaria Alasọdun
A ri ohun kan yi sọ nipa Jehoṣafati pe o fẹ lati beere lọwọ Oluwa ki o to ba Ahabu lọ si Ramọti-Gileadi. Yoo ti dara to bi o ba jẹ pe o kọ beere lọwọ Oluwa ki o to lọ si Samaria lati dara pọ mọ Ahabu? Ni ti Ahabu, o beere lọwọ Oluwa nipa pipe awọn irinwo woli “sa gbọ ti ọga.” Jẹsebẹli ti pa ọpọlọpọ ojulowo woli, o si ti le awọn ti o kù lugbẹ, o si dabi ẹni pe kò ku ẹni kan bi ko ṣe awọn eke woli wọnni – agabagebe – ti wọn ṣetan lati ba ẹṣẹ, aye ati èṣu mulẹ nigbakuugba. Ọrọ yi ba wọn mu rẹgi wi pe, “Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ itanjẹ” (Isaiah 30:10).
Nigba ti Elijah wà ni ori Oke Karmẹli, aadọtalenirinwo woli Baali ni o dojukọ ẹyọ woli Ọlọrun kan. Ni Samaria, irinwo woli eke ni o dojukọ Mikaiah nikan ṣoṣo, ẹni ti o sọ otitọ. Awọn wọnni ti o di gbogbo otitọ Ọrọ Ọlọrun mu lọjọ oni kere lọpọlọpọ. Awọn eniyan bi Johannu Baptisti, ti o le fi igboya duro lati sọ fun ọba wi pe kò tọ fun un lati ṣe panṣaga ni gbigba iyawo Filippi arakunrin rè̩, ṣọwọn ninu iran panṣaga yi. Awọn oniwaasu ti o ni igbagbọ ninu Ọlọrun Ẹlẹda, ti wọn kò ni igbagbọ ninu ọgbọnkọgbọn ọmọ-eniyan ti o wi pe ninu legbelegbe ni ọmọ-eniyan ti jade wa, kere lọpọlọpọ. Iwọn iba oniwaasu diẹ ni o le gboju-gboya lati waasu pe Onigbagbọ le gbe igbesi-aye ailẹṣẹ, nitori pe awọn oniwaasu bẹẹ ko gbajumọ ninu aye ẹṣẹ yi. Diẹ ni awọn ti n kọ ni wi pe awọn oninu funfun nikan ni yoo ri Ọlọrun. Ẹwẹ, larin awọn ti n kọ ni nipa isọdi-mimọ, melo ni o gbagbọ pe a ni lati gba Agbara Ẹmi Mimọ, pẹlu ifedefọ ti i ṣe ami ti Bibeli sọ fun ni pe yoo fara han nigba ti a ba gba ẹbun yi, ki a ba le jẹ aṣẹgun? Awọn eniyan ti o fẹ otitọ ti wọn si ni igboya bi Elijah, Mikaiah ati Johannu Baptisti ṣọwọn laye ode-oni.
Awọn Ojiṣẹ Eṣu
Pẹlu gbogbo ẹwu ẹtan ti wọn gbe wọ, iye Jehoṣafati ṣi lati mọ wi pe awọn irinwo woli yi ki i ṣe woli Ọlọrun tootọ. “Satani tikararẹ npa ara rè̩ dà di angẹli imọlẹ. Nitorina ki iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rè̩ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo” (II Kọrinti 11:14, 15). Ọran awọn irinwo woli eke ti igba Ahabu ko kan wa, bi ti awọn ọmọ wọn ti o ti pọ bẹẹrẹ. Peteru kilọ fun ni gidigidi wi pe, “Awọn woli eke wà larin awọn enia na pẹlu, gẹgẹbi awọn olukọni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ mu adámọ egbé wọ inu nyin wá ani ti yio sé̩ Oluwa ti o rà wọn, ... Ọpọlọpọ ni yio si mā tẹle iwa wọbia wọn; nipa awọn ẹni ti a o fi mā sọ blasfeme si ọna otitọ” (II Peteru 2:1, 2). Jesu sọ bayi nigba ti O n sọrọ nipa akoko ti a wà yi pe, “woli eke pupọ ni yio dide, nwọn o si tan ọpọlọpọ jẹ” (Matteu 24:11). Iwọ ko ha gbọ ti ọkan ninu awọn woli eke ni wi pe, “Ahabu, arakunrin, mā lọ si Ramọti-Gileadi. Iwọ kò gbọdọ ṣaniyan pe iwọ yio ṣegbe; ọmọ igbalà kò ni ṣegbé, iwọ si jẹ ọkan ninu awọn ti a ti yan lati gbalà, Ọlọrun yoo pa ọ mọ, ohunkohun ti o wu ki iwọ ki o mā ṣe.”
Ko ni Ifẹ Otitọ
“Kò si woli OLUWA kan nihin pẹlu, ti awa iba bere lọwọ rẹ?” “Ọkunrin kan mbẹ sibẹ ... ṣugbọn emi korira rè̩.” Apamọ-àpabò pupọ ati ifẹ ẹṣẹ n bẹ ni igbesi-aye Ahabu to bẹẹ ti ko fi fẹ ṣe afẹri otitọ. Iwe Mimọ sọ fun ni wi pe, “igba yio de, ti nwọn ki yio le gbà ẹkọ ti o ye koro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan” (II Timoteu 4:3, 4).
Ọrọ yi, “Nwọn ó si yi eti wọn pada kuro ninu otitọ,” fi han fun ni wi pe oluwarẹ mọọmọ ṣe bẹẹ; ṣugbọn ọrọ ti o tẹle e wi pe wọn o si “yipada si ìtan asan,” fi han pe ki i ṣe oluwarẹ ni yoo ṣe eyi tikara rẹ, agbara kan ti o ga ju ti rẹ lọ ni yoo mu un ṣe bẹẹ. A sọ fun ni ni ibomiran ninu Iwe Mimọ wi pe “Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ: ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ, ṣugbọn ti nwọn ni inudidùn ninu aiṣododo” (II Tẹssalonika 2:11, 12). Bi ẹni kan ba de àyè kan ninu aye rè̩ ti ko tun ni ifẹ otitọ mọ, ṣugbọn gẹgẹbi Ahabu, ti o ba korira otitọ ati awọn ti n sọ otitọ, o wà ni ibi ti o lewu lọpọlọpọ. Oun yoo ba ara rè̩ nibi ti Ọlọrun yoo gbe mu Ọrọ Rè̩ ṣẹ, ti o wi pe, “Emi pẹlu yio yàn itanjẹ wọn” (Isaiah 66:4). Ireti wo ni n bẹ fun ẹlẹran ara nigba ti Ọlọrun Olodumare ba yàn itanjẹ wọn ti Ẹmi Rè̩ si dẹkun lati maa ba wọn sọrọ. Ifẹ fun otitọ ṣe pataki ninu igbesi-aye gbogbo eniyan.
Otitọ ṣoro fun ẹlẹṣẹ lati gbà. Otitọ fi han pe orun apaadi duro de e bi ko ba ronupiwada. Otitọ jade wi pe a o pa Ahabu ni Ramọti-Gileadi. Bi otitọ ti fara han to nì, sibẹsibẹ Ahabu kọ eti didi si otitọ, a si yi i pada si itan asan. Itan asan dun mọ ọn gidigidi. Wọn fi ọkan rè̩ balẹ ninu itan asan wi pe yoo ṣe rere yoo si moke. S̩ugbọn otitọ leke. Ahabu paṣẹ pe ki a “fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi onjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ ọ titi emi o fi pada bọ li alafia.” A fi Mikaiah sinu tubu, ṣugbọn Ahabu kò pada bọ ni alaafia – oku rè̩ ni a gbe pada bọ. O gba ọrọ awọn irinwo alasọdun woli -- ṣugbọn otitọ ti Mikaiah ti o korira sọ ni o ṣẹ.
Ojo
A ko ha le beere wi pe: “Kin ni kọlu ọ, iwọ Jehoṣafati? Iwọ beere Ọrọ Oluwa. Iwọ gbọ ọ, ṣugbọn sibẹ o kọ eti didi si i, o si lọ si Ramọti-Gileadi nigba ti o ti mọ pe ibiṣubu n duro de yin lọhun. Iwọ pẹlu ha jẹ ki ọrọ didun awọn woli eke wọnyi ki o ṣi ọ lọna? tabi iwọ jẹ ojo to bẹẹ ti iwọ kò fi le sọ fun ọrẹ rẹ pe, Agbẹdọ? Bi iwọ ba ti mu iduro rẹ pẹlu woli Ọlọrun, iwọ i ba ti le da ẹmi Ahabu si; kaka bẹẹ, iwọ ba Ahabu lọ si Ramọti-Gileadi, si iparun rè̩. Iwọ gbọ otitọ, otitọ naa si ṣẹ. Bi iwọ ba ti mu iduro rẹ, iwọ le mu ki Ahabu yipada si otitọ -- otitọ ti i ba gba ọkàn rè̩ la kuro ninu egbe ayeraye.”
Boju-boju ati Agabagebe
O dabi ẹni pe ibẹru diẹ n bẹ lọkan Ahabu wi pe ọrọ Mikaiah yoo ṣẹ, nitori pe Ahabu para da ki o to lọ si ogun. S̩ugbọn iparada kan ko le di imuṣẹ Ọrọ Ọlọrun lọwọ. Ọpọlọpọ agabagebe ni o ti fi ẹsin ṣe boju-boju loju araye, ṣugbọn isalẹ ọkan wọn kun fun ẹgbin. Jesu wi pe, “Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin dabi iboji funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu, nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo. Gẹgẹ bẹli ẹnyin pẹlu farahàn li ode bi olododo fun enia, ṣugbọn ninu, ẹ kún fun agabagebe ati è̩ṣẹ” (Matteu 23:27, 28). Ire kin ni wà ninu ẹtàn ati agabagebe bi o ba jẹ pe ikú ati iparun ni opin rè̩?
Ọkan Ahabu rọ nigba ti o gbọ ọrọ Elijah ṣugbọn o kọ lati gbọ ti Mikaiah. Elijah sọtẹlẹ pe ibi n bọ wa sori Ahabu, ṣugbọn nigba ti o rẹ ara rè̩ silẹ, Ọlọrun fun un ni anfaani kan si i. Ahabu kọ anfaani yi, ọrọ ti Oluwa ti ẹnu Mikaiah ati Elijah sọ si ṣẹ. “Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7).
Questions
AWỌN IBEERE- Eeṣe ti kò fi tọna fun Jehoṣafati lati ba Ahabu lọ si ogun?
- Eeṣe ti Jehoṣafati fi fẹ woli miran yatọ si irinwo woli ti Ahabu pe?
- Eeṣe ti Ahabu fi korira Mikaiah?
- Kin ni awọn irinwo woli nì sọ nipa ijadelọ Ahabu si Ramọti Gileadi?
- Wo ibi pupọ ninu Iwe Mimọ nipa woli èké.
- Eeṣe ti a fi gbe Mikaiah ju sinu tubu?
- Bawo ni a ṣe pa Ahabu?
- Kin ni asọtẹlẹ ti Elijah sọ nipa ikú Ahabu?
- Tọka si awọn ẹri ti o le ri ninu ori iwe yi lati fi han pe Ahabu kò sin Ọlọrun.
- Fi asọtẹlẹ Mikaiah ati awọn ohun ti o ṣẹlẹ we ara wọn.