II Kronika 19:1-11; 20:1-37

Lesson 306 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Jẹ ki è̩ru OLUWA ki o wà lara nyin, ẹ mā ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti kò si aiṣedede kan lọdọ OLUWA Ọlọrun wa, tabi ojusaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ” (II Kronika 19:7).
Cross References

I Biba Jehoṣafati Wi ati Ipadabọ rè̩ sọdọ Ọlọrun

1. A ba Jehoṣafati wi fun idapọ rè̩ pẹlu Ahabu, II Kronika 19:1-3; II Kọrinti 6:14-18; Amọsi 3:3; Matteu 6:24

2. Jehoṣafati yan awọn onidajọ o si paṣẹ fun wọn lati bẹru Oluwa, II Kronika 19:4-11

II Iṣẹgun lori Moabu

1. Moabu gbogun ti Juda, II Kronika 20:1, 2

2. Jehoṣafati kede aawẹ, II Kronika 20:3, 4

3. Jehoṣafati ati gbogbo Juda gbadura, II Kronika 20:5-13

4. Ọlọrun da Jehoṣafati lohun, II Kronika 20:14-19

5. Jehoṣafati rú ina igbagbọ ati iyin soke, II Kronika 20:20, 21

6. Ọlọrun ja fun Juda, II Kronika 20:22-24

7. Juda pada bọ pẹlu ayọ, Ọlọrun si fi alaafia fun wọn, II Kronika 20:25-34

III Ibaṣepọ miran ti o lodi si ifẹ Ọlọrun

1. Jehoṣafati dara pọ mọ Ahasiah lati kan ọkọ oju-omi, II Kronika 20:35, 36

2. Ọlọrun ba a wi, O si fọ awọn ọkọ naa, II Kronika 20:37

Notes
ALAYÉ

Eniyan Ọtọ

“Iwọ o ha mā ran enia buburu lowọ, iwọ o si fẹran awon ti o korira OLUWA? Njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ OLUWA.” Ọlọrun ti o pe Abrahamu lati fi ẹbi ati ile baba rè̩ silẹ lati lọ si ilẹ kan ti Oun yoo fi han an, n fẹ nigba gbogbo pe ki awọn eniyan Rè̩ ya ara wọn sọtọ kuro lọdọ awọn ẹlẹṣẹ. Oluwa sọ fun Israẹli lati ẹnu Mose pe, “Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ gbà ohùn mi gbọ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ, nigbana li ẹnyin yio jẹ iṣura fun mi ju gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. Ẹnyin o si ma jẹ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ” (Ẹksodu 19:5, 6). Ahabu jẹ ọba Israẹli o si jẹ iran Abrahamu, ṣugbọn abọriṣa ati apaniyan ni oun i ṣe. O fi awọn woli Ọlọrun sinu tubu, o si pa wọn. Lọna miran ẹwẹ, Jehoṣafati Ọba Juda wá Oluwa o si rin ninu ofin Rè̩. Nipa ti ara, wọn jẹ iyekan, ṣugbọn nipa ti ẹmi, wọn jinna reré si ara wọn.

Ninu Aye, ṣugbọn ki i ṣe ti Aye

Ifẹ Ọlọrun ni lati jinlẹ ju ti ara ati ti ẹjẹ. Ofin pa a laṣẹ wi pe, “Bi arakọnrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkọnrin, tabi ọmọ rẹ obirin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọré̩ rẹ, ti o dabi ọkan ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a mā sin ọlọrun miran, ... iwọ kò gbọdọ jẹ fun u, bẹni iwọ kò gbọdọ fetisi tirè̩; bẹni ki oju ki o máṣe ro ọ, bẹni ki iwọ ki o máṣe da a si, bẹni ki iwọ ki o máṣe bò o; ṣugbọn pipa ni ki o pa a; ọwọ rẹ ni yio kọ wà lara rè̩ lati pa a” (Deuteronomi 13:6-9). Lati jẹ ẹni ọtọ fun Ọlọrun nigba miran gbà pe ki a kọ ẹbi ati iyekan wa silẹ; gẹgẹ bi Onigbagbọ, a wà ninu aye, a ki i ṣe ti ayé. A kò le ṣalai ni iṣepọ pẹlu awọn ẹlẹṣẹ rara, gẹgẹ bi Paulu ṣe sọ asọye fun ni bayi pe, “Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn agbere kẹgbẹ pọ: ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn agbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukokoro, tabi awọn alọnilọwọgba, tabi awọn aboriṣa; nitori nigbana ẹ ko le ṣaima ti aiye kuro” (I Kọrinti 5:9, 10). Jesu rin mọ awọn ẹlẹṣẹ ki O ba le fi ọna igbala han wọn. O jẹ ipe lati ba wọn jẹun, wọn si sun Un ni ẹsun wi pe ọjẹun ati ọmuti ni, ọrẹ agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ (Matteu 11:19).

Awa pẹlu ko le ṣalai rin mọ awọn ẹlẹṣẹ lati mu wọn wá sọdọ Kristi, ṣugbọn a ko gbọdọ lọwọ ninu iṣẹ buburu wọn. A le ba ẹlẹṣẹ ṣiṣẹ, a tilẹ le gbà wọn si iṣẹ, ṣugbọn a ko gbọdọ ba wọn da òwo tabi iṣé̩ pọ. “Ẹ máṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori idapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? idapọ kini imọlẹ si ni pẹlu okunkun? Irẹpọ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ ni pẹlu alaigbagbọ? ... Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọtọ, li Oluwa wi, ki ẹ maṣe fi ọwọ kàn ohun aimọ” (II Kọrinti 6:14-17).

Gẹgẹ bi Onigbagbọ, a pe wa lati jẹ ẹni ọtọ, nitori eyi, a ko lọwọ ninu ẹgbẹ awo tabi ẹgbẹ imulẹ. A ko si gbọdọ gbe alaiwabi-Ọlọrun niyawo; ṣugbọn bi a ba ti gbeyawo tẹlẹ, a ko gbọdọ fi ọkọ tabi aya alaiwabi-Ọlọrun naa silẹ (Wo I Kọrinti 7:12, 13). O ṣe pataki fun Onigbagbọ lati fi awọn ti n gbe igbesi-aye iwa-mimọ ṣe ẹgbẹ ati ọgba rè̩. “Ki a má tan nyin jẹ ẹgbẹ buburu bà ìwa rere jẹ” (I Kọrinti 15:33). “Ẹniti o mba ọlọgbọn rin yio gbọn; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe” (Owe 13:20). Jehoṣafati ko huwa ọlọgbọn nigba ti o yan Ahabu ni ọrẹ, o si fa ibinu Ọlọrun. “Ibarẹ aiye iṣọtá Ọlọrun ni” (Jakọbu 4:4).

Isọji

Nigba ti Mikaiah Woli kilọ fun Ahabu, Ahabu gbe e sọ sinu tubu; ṣugbọn a ri i pe iwa Jehoṣafati yatọ si eyi. Ọrọ Ọlọrun ko sọ fun ni ohun ti Jehoṣafati ṣe lẹsẹkẹsẹ ti Jehu Woli ba a wi, ṣugbọn ohun ti Jehoṣafati ṣe ni pe o n lọ kaakiri Juda, o n yi ọkan awọn eniyan pada sọdọ Ọlọrun. O yan awọn onidajọ o si sọ fun wọn pe: “Ẹ kiyesi ohun ti ẹnyin nṣe: nitori ti ẹnyin ko dajọ fun enia bikoṣe fun OLUWA ti o wà pẹlu nyin ninu ọran idajọ. Njẹ nisisiyi, jẹki è̩ru OLUWA ki o wà lara nyin, ẹ ma ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti ko si aiṣedede kan lodọ OLUWA Ọlọrun wa, tabi ojusaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ.”

Ajalu

Lai si aniani, iduro awọn eniyan Juda nipa ti ẹmi dara nigba ti awọn kan tọ Jehoṣafati wá wi pe ọpọlọpọ eniyan n bọ wa baa ja. Ohun ti o dara pupọ ni lati mọ pe iduro wa pẹlu Ọlọrun dara nigbakuugba ti ohunkohun ba ṣẹlẹ. Lootọ ẹru ba Jehoṣafati, ṣugbọn eyi tubọ mu un sun mọ Ọlọrun timọtimọ. “O si fi ara rẹ si ati wá OLUWA, o si kede awẹ ja gbogbo Juda.” Ọlọrun yẹ iru aawẹ bayi si, wọn ko ṣe e ki eniyan ki o ba le ri wọn, ṣugbọn wọn ṣe e tọkantọkan.

Ni akoko idagiri yi Juda kó ara wọn jọ ni idahun si ipe Jehoṣafati. “Juda si kó ara wọn jọ, lati wá iranwọ lọdọ OLUWA: pẹlupẹlu nwọn wá lati inu gbogbo ilu Juda lati wá OLUWA ... Gbogbo Juda si duro niwaju OLUWA, pẹlu awọn ọmọ wẹrẹ wọn, obirin wọn, ati ọmọ wọn.” Bawo ni yoo ti dara to loju Ọlọrun lati ri i pe awọn eniyan fi imọ ṣọkan lati wá oju Rè̩! Jehoṣafati duro niwaju wọn ni ọjọ naa o si bẹrẹ si i jẹwọ agbara Ọlọrun; o si ran Ọlọrun leti ileri wọnni ti O ti ṣe, o si gbe ohun ẹbẹ rè̩ soke. O jẹwọ pe oun jẹ alailagbara, lẹhin naa pẹlu ireti ati igbagbọ, o mu ọrọ rè̩ wá si opin bayi pe, “S̩ugbọn oju wa mbẹ lara rè̩.”

Idahun

Gẹrẹ ti Jehoṣafati dakẹ ọrọ i sọ ni Ẹmi Ọlọrun mu esi wa wi pe, “Ẹ máṣe bè̩ru, bẹni ki ẹ má si ṣe foya nitori ọpọlọpo enia yi; nitori ogun na ki iṣe ti nyin bikoṣe ti Ọlọrun.” Gbogbo è̩ru wa ni yoo fo lọ nigba ti a ba kó ẹdun wa tọ Ọlọrun lọ. A ko ni ohunkohun lati bẹru nigba ti a ba ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun. “OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bè̩ru? OLUWA li agbara ẹmi mi, aiya tani yio fò mi?” (Orin Dafidi 27:1). “Jehoṣafati tẹ ori rè̩ ba silẹ: ati gbogbo Juda, ati awọn olugbe Jerusalẹmu wolẹ niwaju OLUWA lati sin OLUWA.” Jehoṣafati ko ṣiyemeji si idahun ti o ti ọdọ Ọlọrun wa. Igba pupọ ni aigbagbọ n gbọn iṣẹgun bọ -- nipa kikuna lati di ileri Ọlọrun mu. “Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ, nigbati ẹ ba n gbadura, ẹ gbagbọ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bḝ fun nyin” (Marku 11:24).

O lo Igbagbọ

Ki i ṣe pe Jehoṣafati ni igbagbọ ninu Ọlọrun nikan, o gba awọn eniyan Juda niyanju pẹlu pe, “Ẹ gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ, bẹli a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ gbọ, bẹli ẹnyin o si ṣe rere.” Lẹhin ti o ti gba awọn eniyan Juda niyanju bayi tan, Jehoṣafati dawọ le ohun ti o jẹ ọkan ninu awọn ohun ribiribi ti a ni akọsilẹ nipa rè̩ nipa igbagbọ. Kaka ki o ran awọn akọni ọmọ-ogun rè̩ lọ soju ija, “o yàn awọn akọrin si OLUWA, ti yio ma yìn ẹwa iwa-mimọ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati mā wipe, Ẹ yìn OLUWA; nitoriti ānu rè̩ duro lailai.” “Nigba ti wọn bè̩rẹ si ikọrin ati si iyìn,” Oluwa bẹrẹ si ja fun wọn, a si lu ọta wọn bolẹ. Gẹrẹ ti awọn ọmọ Ọlọrun ba fi igbagbọ rọ mọ ileri Ọlọrun ti iyin si gba ẹnu wọn kan, lai si aniani, Ọlọrun yoo mu ileri Rè̩ ṣẹ. Ro o wo! A ko fa ẹyọ ida kan ṣoṣo yọ, a ko gbe ẹyọ ọkọ kan soke bẹẹ ni a ko ta ẹyọ ọfa kan – ndao, a ko tilẹ fi ẹyọ kannakanna kan -- ṣugbọn Ọlọrun fun wọn ni iṣẹgun. Ohun kan ti Juda saa ṣe ni pe ki wọn ki o maa kọrin ki wọn si ko ikogun, ki wọn si pada pẹlu iyin Ọlọrun ni ẹnu wọn. Apata igbagbọ ati ida nì ti i ṣe Ọrọ Ọlọrun ni ohun ija wọn. Ohun ija wọn lagbara, iṣẹgun wọn ko si kere. “Ibè̩ru Ọlọrun si wà lara gbogbo ijọba ilẹ wọnni, nigbati nwọn gbọ pe OLUWA ti ba awọn ọta Israẹli jà.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eeṣe ti ko fi tọna fun Jehoṣafati lati ran Ahabu lọwọ?
  2. Ihà wo ni Jehoṣafati kọ si ibawi Jehu Woli?
  3. Kin ni Jehoṣafati ṣe ki ijọba rere ki o le wa?
  4. Kin ni Jehoṣafati ṣe nigba ti ọta ti o lagbara gbogun ti i?
  5. Lọna wo ni a ni lati gbà ya ara wa sọtọ kuro ninu aye?
  6. Bawo ni Jehoṣafati ṣe fi igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun hàn?
  7. Kin ni Ọlọrun lo lati fi bi awọn ọta Juda wó?
  8. Ronu lori adura Jehoṣafati ki o si sọ fun ni eredi rè̩ ti o fi jẹ apẹẹrẹ rere.
  9. Kin ni ipa ti Juda mu ninu ogun ti wọn ba awọn ọta wọn ja?
  10. Eredi rè̩ ti iṣẹ ọkọ oju-omi ti Jehoṣafati ṣe fi kuna?
1