Orin Dafidi 92:1-15

Lesson 307 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn ẹniti a gbin ni ile OLUWA, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa” (Orin Dafidi 92:13).
Cross References

I Iṣẹ ati Anfaani ti o wà ninu Yiyin Ọlọrun

1. Ohun rere ni lati maa yin Ọlọrun, Orin Dafidi 92:1-3; 33:2; 89:1; 147:1; I Kronika 23:5

2. A fi titobi Ọlanla iṣẹ Ọlọrun han, Orin Dafidi 92:4, 5; 139:17; Isaiah 28:29; Romu 11:33, 34

3. Opè ati aṣiwere ko mọ ijiya ti o wà fun awọn eniyan buburu nikẹhin, Orin Dafidi 92:6-9; 94:8; 68:1; Jeremiah 12:1-3; Malaki 3:15

4. A fi ibukun ti o wà fun awọn olododo hàn, Orin Dafidi 92:10-14; 23:5; 89:24; 135:1-3; Isaiah 65:22; Hosea 14:5, 6

5. Gbogbo iṣẹ aanu ati idajọ Ọlọrun ni o fi idi mulẹ ti o si ni itilẹhin pipe Ọlọrun, Orin Dafidi 92:15; Deuteronomi 32:4; Romu 9:14

Notes
ALAYÉ

Ọjọ Idupẹ

A dupẹ wi pe Ijọba orilẹ-ede Amẹrika ya ọjọ kan sọtọ ninu ọdun kan fun ọjọ idupẹ. Ni ọjọ yi, a gba gbogbo awọn eniyan orilẹ-ede yi niyanju lati fi iyin ati ọpẹ fun Ọlọrun fun aanu ati ibukun Rè̩ ninu ọdun ti o kọja. Gẹgẹ bi orilẹ-ede, a jẹ Ọlọrun ni igbese ọpẹ fun ohun pupọ. Gẹgẹ bi ẹni kọọkan, a jẹ Ọlọrun ni igbese ọpẹ fun ohun pupọ. O dabi ẹni pe Ọlọrun ni o gbe ilẹ Amẹrika kalẹ ni akoko iṣoro nigba ti awọn eniyan ti ko ni anfaani lati sin Ọlọrun bi o ti wu wọn ni orilẹ-ede wọn n fẹ ibi aabo kan ninu aye yi.

Ni orilẹ-ede ti wa yi, ofin ilẹ wa fun olukuluku eniyan ni anfaani ati ẹtọ lati sin Ọlọrun gẹgẹ bi o ba ti wu u. Iru anfaani yi ko si ni ọpọ orilẹ-ede miran ni ẹkunrẹrẹ bi ti wa. Gẹgẹ bi orilẹ-ede, awa ni ẹtọ lati yin Ọlọrun gidigidi.

Ọpọlọpọ ni ko ni ọkan ọpẹ si Ọlọrun fun anfaani ti ofin ilẹ wa fun wa gẹgẹ bi ẹni kọọkan; kaka ki wọn sin Ọlọrun ki wọn si maa yin In, wọn ti sọ Ọjọ Idupẹ di ọjọ apejẹ ati ariya, ọti mimu ati iwa wọbia gbogbo. O yẹ ki oju ki o ti orilẹ-ede ti Ọlọrun bukun fun ṣugbọn ti wọn ko naani aanu Ọlọrun ti o pọ to bayi! Iparun n bọ wa ba awọn alaimoore wọnyi bi wọn ko ba ronupiwada.

Oko Ọka

Nigba ti a ba bojuwo oko wa ti o kun fun ounjẹ, awa pẹlu le sọ bi ti Dafidi wi pe, “O (Ọlọrun) mbomi rin awọn oke lati iyẹwu rè̩ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ té̩ aiye lọrun. O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ilo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá” (Orin Dafidi 104:13, 14).

Ki i ṣe ẹẹkan ṣoṣo lọdun, ni Ọjọ Idupẹ ni ọkan ti o kun fun ayọ n yin Ọlọrun; ṣugbọn, gẹgẹ bi Onipsalmu, ki o maa fi iṣeun ifẹ Rè̩ han ni owurọ ati otitọ Rè̩ ni alaalẹ. Lai si aniani, turari ọpẹ ati iyin ki i dẹkun lati maa goke lọ nigba gbogbo lati inu ọkan awọn ọmọ Ọlọrun. Iyin Ọlọrun a maa fun ni ni ayọ. Ọpọlọpọ ibukun ẹmi ni a n ri gba, bakan naa ni a ja ọpọlọpọ ogun ti ẹmi ni ajaṣẹ nipa iyin Ọlọrun.

Boya ninu adura ni Onipsalmu ti n yin Ọlọrun tẹlẹtẹlẹ. Inu rè̩ dun to bẹẹ ti o fi gbe ohun-elo orin rè̩ olokun mẹwa ti ọwọ rè̩ si bẹrẹ si jowere lori rè̩, ayọ nla nla gba ọkàn rè̩ kan to bẹẹ ti o n fẹ lati ni ohun-elo ti o gbamuṣe ju bẹẹ lọ lati lo lati fi ọpẹ rè̩ han. Bayi ni o gbe ohun-elo olokun mẹwa silẹ ti o si tun gbe harpu rẹ, nibẹ ọkan rẹ kuro ninu aye yi patapata, to bẹẹ ti o fi bu si orin iyin si orukọ Ọga Ogo.

Iṣẹ Nla

“Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to!” Iṣẹ Ọlọrun jẹ iyanu fun Dafidi, Onipsalmu, o si kọ akọsilẹ pupọ nipa iṣẹ ọwọ Ọlọrun. O sọ fun ni pe awọn ọrun n sọrọ ogo Ọlọrun; oorun, oṣupa ati awọn irawọ n fi agbara Ọlọrun han. Dafidi ranti iṣeun Ọlọrun si Israẹli: Okun Pupa pinya niwaju Rè̩, Odo Jọrdani pada sẹhin niwaju awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun wọn ni agbara lati ṣe ohun iyanu.

Ọlọrun kan naa ti awọn Ọmọ Israẹli sin ni awa naa n sin. Oun jẹ Ọlọrun alagbara. Ọlọrun wa le yi igbesi-aye ẹni pada. O le dari ẹṣẹ ji ẹlẹṣẹ, ki O si wẹ ẹ mọ, ki O si mu un rekọja lati inu ijọba Satani wa si Ijọba Kristi Olugbala wa. O gba agbara Ọlọrun lati yi ẹlẹṣẹ pada si Onigbagbọ. Ko si ipa tabi agbara miran ti o le ṣe eyi.

Ma ṣe jẹ ki Ọjọ Idupẹ yi kọja lai gbe ohun rẹ soke lati dupẹ lọwọ Ọlọrun ati Olugbala wa, Jesu Kristi, fun ọpọ ibukun wọnni ti O tu dà silẹ le ọ lori ninu ọdun ti o kọja yi. O daabo bo ọ ninu ewu ti ko lonkà, riri ati airi, ni ọna rẹ gbogbo. O fun ọ ni ilera, ounjẹ ati aṣọ. O fun ọ ni ẹmi rẹ, O si pa ọ mọ ni abẹ ojiji atẹlẹwọ Rè̩. O yẹ ki o ti fẹ ọ pa bi ina fitila ni iṣẹju kan. S̩ugbọn kaka bẹẹ, O bukun fun ọ lọpọlọpọ; “Enia iba mā yin Oluwa nitori ore rè̩, ati nitori iṣẹ iyanu rè̩ si awọn ọmọ enia!”

Iro-inu ti O jinlẹ

“Iro-inu rẹ jinlẹ gidigidi.” Ero ọmọ-eniyan kuru lọpọlọpọ. Awọn ẹlomiran ro wi pe ero ọmọ-eniyan jinlẹ nitori pe wọn ṣe afọnja apanirun. S̩ugbọn ohun ti a n pe ni awari ti ọmọ-eniyan ṣe fi diẹ kunun lasan han fun ni ninu awọn aṣiiri awamaridi Olodumare. Ọlọrun ni o dá ohun gbogbo. Ohun ti Ọlọrun ti dá ni ọmọ-eniyan n ṣe awari rè̩.

Lẹhin ti Paulu Apọsteli ti ṣe alaye ijinlẹ oore-ọfẹ, o sọ bayi pe “! ijinlẹ ọrọ ati ọgbọn ati imọ Ọlọrun! Awamaridi idajọ rè̩ ti ri, ọna rè̩ si ju awari lọ!” (Romu 11:33). Paulu fi ye wa wi pe nipa aigbagbọ ni a fi ke Israẹli kuro, ati wi pe nipa igbagbọ ni a lọ awọn Keferi. Otitọ yi gba ọkan rè̩ kan bi o ti n ṣe aṣaro nipa ijinlẹ iro inu Ọlọrun.

Ijinlẹ ọgbọn Ọlọrun kun Onipsalmu loju pẹlu. O rii pe aṣiwere ati ope eniyan ko ni oye nipa aanu Ọlọrun si ọmọ-eniyan; wọn ko mọ pe a ko le fi ibukun ti ara nikan diwọn rè̩. Eniyan buburu le gbilẹ bi igi ọpẹ, ṣugbọn bi o ba ṣa Ọlọrun tì ninu erò rè̩, ọjọ n bọ ti oun yoo parun titi laelae. Iwọ ha n ṣa Ọlọrun ti ninu ero rẹ loni?

Yoo Gbilẹ bi Igi

“Olododo yio gba bi igi ọpẹ.” Nipa eyi, a le rii wi pe ireti olododo yatọ si ti awọn eniyan buburu ti a fi we koriko ti a o ke kuro ti yoo si rọ. Igi ọpẹ jẹ apẹẹrẹ ẹwa ati eso siso nigba gbogbo. Ẹyìn rè̩ a maa fun ara ni ilera. Ko si akoko kan laarin ọdun yipo ti eso n dasẹ lori rè̩ patapata, nigba ti o tilẹ yẹ ki o ni isinmi fun iwọn igba diẹ lai so eso. Igba gbogbo ni o n mu eso jade. Eyi fara jọ igbesi-aye Onigbagbọ. O n so eso nigba gbogbo. Oun ko ni anfaani lati sinmi ninu iṣẹ yi rara. Bi iwuwo iṣẹ rè̩ si Ọlọrun ati eniyan ti ka a laya to, bẹẹ ni yoo maa gbilẹ sii ninu ẹmi.

“Oun yio dagba bi igi kedari Lẹbanoni.” Igi Kedari lẹwa, o lagbara, o si ni alotọ. Kokoro ki i jẹ igi yi, o n wà fun ọdun pupọ. A n gbin awọn olododo si Ijọba Ọrun nipa igbagbọ. Ọrọ Ọlọrun n bọ wọn, o si n bomi rin wọn. Wọn fidi mulẹ ṣinṣin ninu ifẹ. Wọn lagbara, wọn si singbọnlẹ, bi igi ọpẹ ati igi kedari. Wọn n so eso nigba gbogbo, wọn si wulo lọna pupọ. Pẹlupẹlu “nwọn o mā so eso sibẹ ninu ogbo wọn.” Eyi jẹ itunu fun gbogbo wa!

Bi o tilẹ jẹ pe Simeoni ati Anna ti di arugbo, wọn n jọsin ni Tẹmpili nigba ti awọn obi Jesu gbe Ọmọ-ọwọ naa wa. Simeoni ti gbe igbesi-aye iwa mimọ. O ti n ba Ọlọrun rin lati ọjọ pipẹ. O jẹ ẹka ti o n so eso lara Ajara Tootọ fun ọdun pupọ, nisinsinyi ti oju rè̩ ti ri Messia, o si ṣetan lati lọ ni alaafia. Anna pẹlu sin Ọlọrun pẹlu aawẹ ati adura ni ọsan ati ni oru. Nigba ti o ri Kristi, o fi han ninu ẹri fun awọn ti n wọna fun idande Israẹli. Simeoni ati Anna dabi igi ọpẹ, bi igi kedari Lẹbanoni; wọn so eso ni ọjọ ogbo wọn, ati ni igba ọdọ wọn pẹlu. Awa naa pẹlu mọ awọn eniyan Ọlọrun lọkunrin, lobinrin ti o gbe igbesi-aye ti o mu eso jade fun Ọlọrun, ti wọn si sin In titi de opin ẹmi wọn. Bi awọn miran ti n pari adura wọn fun aye ẹṣẹ yi ni a gba wọn lọ soke Ọrun. Awa ha fẹ dabi awọn wọnyi? O ṣe e ṣe fun wa bi a ba fẹ bẹẹ!

Asunkun Ilẹ

Ni akoko idupẹ yi, ẹ jẹ ki a ranti ọwọ aanu Ọlọrun ti O nà si wa ninu ọdun ti o kọja, ki a si kọrin iyin si orukọ Rè̩. Nitori pe awa pẹlu le sọ pẹlu Dafidi wi pe, “Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ, odo Ọlọrun kún fun omi: iwọ pese ọkà wọn, nigbati iwọ ti pese ilẹ bḝ. Iwọ fi irinmi si aporo rè̩ pipọpipọ: iwọ si té̩ ogulutu rè̩: iwọ fi ọwọ òjo mu ilẹ rè̩ rọ: iwọ busi hihu rè̩. Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkàn ni ipa ọna rẹ. Papa-tutù aginju nkán: awọn oke kekeke fi ayọ di ara wọn li amure. Agbo ẹran li a fi wọ papa-tutu na li aṣọ: afonifoji li a fi ọka bò mọlẹ: nwọn nho fun ayọ, nwọn nkọrin pẹlu” (Orin Dafidi 65:9-13).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eeṣe ti a fi n ṣe iranti Ọjọ Idupẹ?
  2. Bawo ni a ti ṣe ni lati ṣe e? Eeṣe?
  3. Bawo ni awọn aṣiwere ati ope eniyan ti ṣe n wo ọrọ awọn eniyan buburu?
  4. Bawo ni Ọlọrun ṣe n wo ọrọ awọn eniyan buburu?
  5. Iru igi wo ni a fi awọn olododo we?
  6. Sọ awọn ohun diẹ ti o dara nipa igi wọnyi?
  7. Kin ni a sọ pe awọn olododo yoo ṣe ni ọjọ ogbo wọn?
  8. Darukọ awọn olododo diẹ ti o so eso ni ọjọ ogbo wọn?
1