I Awọn Ọba 19:19-21; II Awọn Ọba 2:1-18

Lesson 308 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo” (Matteu 5:6).
Cross References

I Ipe Ọlọrun

1. Elijah dá agbada rè̩ bo Eliṣa: eyi si jẹ apẹẹrẹ ipe Ọlọrun, I Awọn Ọba 19:16, 19; Ẹksodu 3:1, 2; Awọn Onidajọ 6:11, 12; Orin Dafidi 78:70-72; Amọsi 7:14, 15; Matteu 4:18, 19

2. Eliṣa fi gbogbo ini rè̩ ati ara ile rè̩ rubọ, o si jẹ ipe Ọlọrun, I Awọn Ọba 19:20; Matteu 8:21, 22; Luku 9:61, 62; Gẹnẹsisi 24:55-58

3. Eliṣa fi awọn malu rè̩ ru ẹbọ, lẹhin naa o si lọ n ṣe iranṣẹ fun Elijah, I Awọn Ọba 19:21; II Awọn Ọba 3:11, 12; Johannu 13:13-16; Luku 22:25-27; Matteu 20:28; Filippi 2:17

II Agbada ti o ti Ọdọ Ọlọrun Wa

1. Eliṣa tọ Elijah lẹhin bi o ti lẹ jẹ pe o ri idojukọ ati ọpọ iṣoro, II Awọn Ọba 2:1-8; Rutu 1:15-18; II Samuẹli 15:21; Johannu 11:16; 13:1; Romu 16:4; II Timoteu 1:16; Iṣe Awọn Apọsteli 2:42

2. Aapọn ati iduroṣinṣin Eliṣa mu ki Elijah beere ohun ti Eliṣa fẹ ki a ṣe fun oun, II Awọn Ọba 2:9, 10; II Kronika 15:12-15; Orin Dafidi 73:25; Marku 5:27-34; l0:51, 52; 7:25-29

3. A fi aaja gbe Elijah lọ si Ọrun, II Awọn Ọba 2:11; Gẹnẹsisi 5:24; Heberu 11:5; I Kọrinti 15:51, 52; Matteu 24:27, 28, 40, 41; Luku 9:30, 31; I Tẹssalonika 4:14-18

4. Eliṣa gba agbada Elijah ti o bọ silẹ -- eyi si jẹ apẹẹrẹ gbigba agbara Ẹmi Mimọ, II Awọn Ọba 2:12-18; Luku 24:49; Johannu 14:12-14; Iṣe Awọn Apọsteli 2:1-4, 16-18; Orin Dafidi 45:1, 7

Notes
ALAYÉ

A Pe e, a si Yan an

Boya ni a tun le ri apẹẹrẹ ti o dara ju ti Eliṣa ti Elijah da agbada rè̩ bo, nipa ọna ti a gba n pe eniyan sinu iṣẹ Ọlọrun ninu Ọrọ Ọlọrun. Igbesi-aye Elijah gẹgẹ bi Woli si orilẹ-ede Israẹli apẹhinda n lọ si opin. A ni lati yan ẹlomiran lati maa ba iṣẹ Ọlọrun lọ, ẹni naa si ni Eliṣa -- ẹni ti o ṣe e ṣe pe ki Elijah má mọ, ṣugbọn ti Ọlọrun mọ.

Ọlọrun ni o n yan awọn ojiṣẹ Ọlọrun ati awọn oṣiṣẹ, Ọlọrun pe wọn, O si fi wọn si àye kọọkan, O si n pa wọn mọ. Eyi di mimọ fun wa nipa ọrọ ti Jesu sọ bayi pe “Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso yin le duro” (Johannu 15:16). Paulu sọ bayi nipa iṣẹ-iranṣẹ rẹ pe, “Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere yi, emi kò ni ohun ti emi o fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mo-gbé! Bi emi kò ba wasu ihinrere. Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ” (I Kọrinti 9:16, 17). (Ka Heberu 5:1-4). Ọlọrun sọ fun Elijah wi pe, “Eliṣa, ọmọ S̩afati, ara Abẹl-Mehola ni iwọ o fi ororo yàn ni woli ni ipò rẹ” (I Awọn Ọba 19:16). Ọlọrun ko fi dá Elijah lati yàn ẹni ti yoo gba ipo rè̩, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkan eniyan.

Lai si aniani, imurasilẹ eniyan paapaa, wa lara nkan ti Ọlọrun n wo ki o to yan ẹni naa sinu iṣẹ Rè̩. Ọlọrun ki i yan ọgbẹri sinu iṣẹ Rè̩ (Ka I Timoteu 3:6). Oun a saaba maa pe awọn wọnni ti igbesi-aye wọn atẹhinwa ati iwa wọn fi han pe wọn jẹ olootọ ati ẹni ti o ṣe e fọkan tan lọna ti yoo wulo fun iṣẹ Ọlọrun ni ọjọ iwaju. Dafidi jẹ iru ẹni bẹẹ. “O si yàn Dafidi iranṣẹ rè̩, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá: lati má tọ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ Jakọbu, enia rè̩ ati Israẹli, ilẹ-ini rè̩. Bḝli o bọ wọn gẹgẹ bi iwatitọ inu rè̩, o si fi ọgbọn ọwọ rè̩ ṣe amọna wọn” (Orin Dafidi 78:70-72). Bakan naa ni Ọlọrun yàn Josẹfu lati ṣe iṣẹ ribiribi fun Un, bi o tilẹ jẹ pe ọdọmọkunrin ni oun i ṣe. (Wo Orin Dafidi 105:17-22).

Ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣiṣẹ fun Ọlọrun yoo sa gbogbo ipa rè̩ lati fi ara rè̩ si ipo ti yoo gba yẹ fun iṣẹ naa. Nigba ti akoko ba to, oun yoo ti wà ni imurasilẹ. Dafidi, oluṣọ-agutan kekere, ko lọra lati pe Goliati, ọta israẹli nija, ni orukọ Oluwa, nitori pe Dafidi ti pa beari ati kinniun ni igba ewe rè̩ nipa iranlọwọ Ọlọrun. Nigba ti afo ṣi silẹ pe ki ẹni kan gbe ida Oluwa, igbagbọ atẹhinwa ninu Ọlọrun jẹ amure fun Dafidi o si dide lati jẹ ipe naa. Ọlọrun ko kọ ọ nitori pe o ti wà ni imurasilẹ. Ko si ẹlomiran ni Israẹli ti o jẹ daba lati ba Goliati jà ni orukọ Oluwa.

Bi o ti n ṣiṣẹ oojọ rè̩, lojiji Eliṣa ri i pe a ti da agbada Elijah bo oun. Iwuwo ti n bẹ lọkan rè̩ lati ṣiṣẹ fun Oluwa tayọ iwuwo agbada ti a da bo o, ninu ọkàn rè̩ lọhun; o gbọ ohun Ọlọrun ti n sọ orọ ti o lọwọ nì ti awọn ẹlomiran lati igba nì gbọ wi pe “Tẹle Mi.”

Ifararubọ

Ki a mọ pe Ọlọrun n pe wa lati ṣiṣẹ fun Un lọna kan tabi lọna miran ko fi han pe a ko ni fi ara wa ji fun iṣẹ naa. Bi a ti n jẹ ipe Ọlọrun, a ni lati fi ara wa rubọ gidigidi ki a ba le ṣe iṣẹ naa ti a pe wa si daradara. Eliṣa kò yatọ si gbogbo eniyan. O mọ iwuwo ipe rè̩ o si mọ pe yoo gba gbogbo aye oun, yoo si leke ohunkohun miran ninu igbesi-aye oun. Iṣẹ Ọlọrun ni iṣẹ ti o ga julọ ti eniyan le ṣe ninu aye yi, ère rè̩ ko si ṣe fẹnu sọ; ṣugbọn nipa ifara-ẹni-ji ti o ga fun iṣẹ Ọlọrun nikan ni ọmọ-eniyan gbà le ṣe ifẹ Rè̩. A le mọ bi Eliṣa ti n ba Ọlọrun jijakadi ninu ọkan rè̩ nigba ti o ke si Elijah wi pe, “Emi bè̩ ọ, jẹki emi lọ ifi ẹnu ko baba ati iya mi li ẹnu, nigba naa ni emi o tọ ọ lẹhin.” Idahun Elijah wi pe, “Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ?” fi han ni kukuru pe, “Iwọ ni lati pinnu rè̩ pẹlu Ọlọrun, Oun ni o pe ọ ki i ṣe emi; o si ni lati jẹ ipe Rè̩.”

Fi ọrọ yi we ohun ti Jesu sọ fun ọkunrin kan ti n fẹ ṣe ọmọ-ẹhin ṣugbọn ti o n fẹ ki a fun oun ni aye lati lọ sin baba rè̩, “Iwọ mā tọ mi lẹhin; si jẹki awọn okú ki o mā sin okú ara wọn” (Matteu 8:22).

Iṣẹ-Isin

Eliṣa fi ile rè̩ silẹ lati tẹle Elijah lẹhin ti o ti ṣe irubọ tan. Iwe Mimọ sọ fun ni pe, o “ntu omi si ọwọ Elijah” (II Awọn Ọba 3:11), eyi fi han wi pe, o n ṣe iranṣẹ fun Elijah lọnakọna ti o gba le ṣe iranlọwọ fun Woli Ọlọrun yi. Ipe Ọlọrun si ọkan kọọkan jẹ ipe lati ṣe iranṣẹ fun awọn ẹlomiran -- gẹgẹ bi fun Kristi. (Wo II Kọrinti 5:20). Jesu wi pe, “Emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ” (Luku 22:27). Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe “Ẹniti o ba pọju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ” (Luku 22:26). Jesu tun sọ pẹlu pe, “Ọmọ-enia ko ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ fun-ni ati lati fi ẹmi rè̩ ṣe irapada ọpọlọpọ enia” (Matteu 20:28).

Igbesi-aye ti a fi fun Ọlọrun yoo jẹ eyi ti a lo lati ṣe iṣẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ Ọlọrun nibikibi ti o ba wu Ọlọrun. A ni lati sọ ẹmi wa nu ki a ba le jere rè̩ si iye ainipẹkun. Gbogbo Onigbagbọ ni o ni lati fi eyi sọkàn bi wọn ti n jọsin fun Ọlọrun, ni ireti ati jere iye ainipẹkun.

Igbọran si aṣẹ Kristi saba maa n gbe ni de ibi ti o jinna rére ni ilẹ Keferi, nibi ti wọn yoo ba ọpọlọpọ iṣoro pade, nigba miran wọn le sọ ẹmi wọn nu nibi ti wọn gbe n waasu Ihinrere ki awọn eniyan ba le bọ kuro ninu ẹṣẹ wọn. Ifara-ẹni-ji fun iṣẹ Ọlọrun ni eyi, nitori pe iranṣẹ ko pọ ju Oluwa rè̩ lọ. Bi Jesu ti fi ẹmi Rè̩ lelẹ, bakan naa ni a le ke si Onigbagbọ lati fi ohun gbogbo silẹ fun ogo Ọlọrun ati nitori pe Oluwa rè̩ beere lọwọ rè̩ pe ki o ṣe bẹẹ.

Eliṣa jẹ ẹni ti o tẹle Ọlọrun lẹhin timọtimọ nitori pe o yan lati ṣe iranṣẹ fun Woli Ọlọrun ni ipokipo ti o wu ki o jẹ. Awọn miran n bẹ ti ko naani awọn iṣẹ wọnni ti wọn n pe ni iṣẹ ti ko nilaari ninu Ihinrere, wọn ro pe ohun abuku ni fun wọn lati ṣe iru iṣẹ bẹẹ. Ko si iṣẹ ti ko ṣe pataki lọdọ Ọlọrun; ko ti i si ẹni ti a ke si lati rẹ ara rè̩ silẹ de ibi ti Jesu rẹ ara Rè̩ silẹ de nigba ti O gba ki awọn eniyan yọṣuti si I, ki wọn si fi I ṣẹsin, ki wọn lu U, lẹhin gbogbo rè̩ ki wọn si pa A. O “bọ ogo rè̩ silẹ, o si mu awọ iranṣẹ, a si ṣe e ni aworan enia. Nigbati a si ti ri i ni iri enia, o rẹ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani iku ori agbelebu” (Filippi 2:7, 8). “Bi on ti jẹ ọlọrọ ri, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ nipa aini rè̩” (II Kọrinti 8:9). Apẹẹrẹ ti Jesu fi lelẹ ni eyi, O fi ẹmi Rè̩ ati ohun gbogbo ti O ni lelẹ fun Ọlọrun Baba rè̩, nitori igbala ọkan eniyan; a ko si gbọdọ din ohun ti Ọlorun ba beere lọwọ wa kù.

Agbara Ọlọrun

Nigba ti Ọlọrun yoo fi aaja gbe Elijah lọ soke Ọrun, Elijah, wi fun Eliṣa pe “Joko nihinyi.” S̩ugbọn Eliṣa ko jẹ fi Elijah silẹ. Ohun ti Eliṣa n ṣe tẹlẹ ri ni lati ṣe iranṣẹ fun Elijah; Eliṣa si mọ pe ni aipẹ jọjọ a o mu oluwa oun lọ. Ọkan Eliṣa gbina ninu rè̩, nitori pe, ju ohun gbogbo lọ, o fẹ lati ni iru agbara ati Ẹmi ti Elijah ni. Ko si iṣẹ-isin ti a le ṣe fun Ọlọrun ni aṣeyọri bi ko ṣe pe a ba ṣe e pẹlu agbara Ẹmi Ọlọrun. Eyi di mimọ fun Eliṣa, oun ko si jẹ fi Elijah silẹ ni iṣisẹ kan titi yoo fi gba iru agbara ti Elijah ni.

Awọn ọmọ woli sọ fun Eliṣa wi pe Elijah yoo fi i silẹ ni aipẹ jọjọ, wọn si fẹ lati de e lọna bi o ti n tẹle Elijah. Eliṣa ko jẹ ki ẹnikẹni ṣi oun lọna. Ni ikẹhin Elijah beere ohun ti Eliṣa n fẹ. Idahun Eliṣa, wi pe “Iṣẹpo meji ẹmi rẹ,” jẹ iru idahun ti o ti ẹnu awọn wọnni ti wọn n fẹ ni agbara Ẹmi Mimọ jade. Bi a ba “fi igboya wa si ibi itẹ aanu,” ti a si beere Ẹmi Ọlọrun ti Jesu ti ṣeleri, a o ri I gba.

Elijah jẹ ki ohun ti Eliṣa yoo ṣe ki o to ri ibeere rẹ gba di mimọ fun un. Bakan naa ni Ọlọrun lana ohun ti Onigbagbọ ni lati ṣe silẹ ki o to ri agbara Ẹmi Mimọ gba. O ni lati ni igbala –idariji ẹṣẹ -- nipasẹ itoye È̩jẹ Jesu Kristi, ki o si di ẹda titun ninu Kristi Jesu. Lẹhin naa, o ni lati ni isọdi-mimọ, ti i ṣe iṣẹ oore-ọfẹ keji. Lẹhin eyi, o ni anfaani lati wa oju Oluwa fun itujade agbara Ẹmi Mimọ.

Eliṣa ko jẹ ki oju rè̩ yẹ kuro lara Elijah, ṣugbọn o tẹle e timọtimọ sihin, sọhun. Lojiji, bi kẹkẹ ina ti pin wọn niya, a fi aaja gbe Elijah lọ soke Ọrun. Eliṣa ri i bi o ti n lọ, o fa aṣọ ara rẹ ya, o si gbe agbada Elijah ti o bọ silẹ wọ. Bi Eliṣa ti fi agbada yi lu odo Jọrdani, ti o si kigbe wi pe, “Nibo ni OLUWA Ọlọrun Elijah wa?” Ọlọrun fi ara Rè̩ han O si pin odo Jọrdani niya fun Eliṣa lati kọja. Awa pẹlu le dan otitọ Ọlọrun wo ki a si mọ pe O wa laaye sibẹ. Nipa igbọran si aṣẹ Ọlọrun ati nipa wiwa oju Ọlọrun lọna ti o tọna, awa pẹlu yoo ri agbara Ọlọrun gbà, gẹgẹ bi Eliṣa ti ṣe.

Ọgọfa ọmọ-ẹhin Jesu pejọ pọ ni ọkan kan, wọn gbadura fun ọjọ mẹwa fun Ẹmi Ọlọrun ti O ti ṣeleri, nigba ti Ọjọ Pẹntikọsti kò, Ọlọrun tú Ẹmi Rè̩ si gbogbo wọn lori.

O dabi ẹni pe awọn ọmọ woli mọ pe Elijah n lọ gẹgẹ bi o ti di mimọ fun Eliṣa, ṣugbọn Eliṣa nikan ni o ṣafẹri agbara Ẹmi Ọlọrun ti n bẹ lara Elijah, oun nikan ṣoṣo ni o si gba Ẹmi yi. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ni ileri Jesu di mimọ fun wi pe Oun yoo ran Olutunu nì, ani Ẹmi Mimọ, o si to ẹẹdẹgbẹta eniyan ti o ri Jesu lẹhin ti O jinde, sibẹ ọgọfa eniyan pere ni o ṣafẹri lati wa nibẹ nigba ti Ẹmi Mimọ sọkalẹ. Bakan naa ni o ri lọjọ oni. Awọn ti n fẹ agbara Ọlọrun n ṣafẹri rè̩, wọn yoo si ṣe ohun ti Ọlọrun beere lọwọ wọn lati ri i gba; wọn yoo fi ara wọn si ipo ti o dara, iduro wọn nipa ti ẹmi ki yoo si ni abuku ki Ọlọrun ki o ba le fi ibeere wọn fun wọn.

Agbara Ọlọrun yoo sọkalẹ sori awọn wọnni ti o fi ohun gbogbo silẹ lati tẹle Jesu Kristi. Ileri Ọlọrun daju, gẹgẹ bi Peteru ti sọ ni Ọjọ Pẹntikọsti wi pe, “Eyi li ọrọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joẹli wá pe: Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin ọkọnrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio mā sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkọnrin nyin yio si mā ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá: Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkọnrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obirin li emi o tú ninu Ẹmi mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si mā sọtẹlẹ” “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:16-18, 39).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Tani yan Eliṣa ni arọpo Elijah?
  2. Tani n yan awọn ojiṣẹ Ọlọrun lọjọ oni?
  3. Eeṣe ti Elijah fi sọ fun Eliṣa pe ki o pada nigba ti Eliṣa n tẹle e?
  4. Eeṣe ti a fi ni lati fi ayé wa ji fun iṣẹ Ọlọrun?
  5. Bawo ni Eliṣa ṣe gba Ẹmi Ọlọrun ti n bẹ lara Elijah?
  6. Bawo ni a ṣe le gba Ẹmi Ọlọrun lọjọ oni?
  7. Awọn tani le ri Ẹmi Ọlọrun gba lọjọ oni? Fi ẹsẹ Bibeli melo kan gbe idahun rẹ lẹsẹ.
1