II Awọn Ọba 2:19-25; 3:1-27

Lesson 309 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣan-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ” (Isaiah 44:3).
Cross References

I Iṣẹ Aanu ati Idajọ

1. A fi aanu Ọlọrun han fun awọn ti n wa aanu, II Awọn Ọba 2:19-22; Ẹksodu 34:6, 7; II Kronika 30:9; orin Dafidi 103:17; 106:1

2. A ran idajọ Ọlọrun si awọn ti o sọrọ odi ti wọn si kọ lati bu ọla fun Ọlọrun, II Awọn Ọba 2:23-25; Lefitiku 26:21-39; Orin Dafidi 9:16; Sẹfaniah 3:5; Romu 2:2

II Eliṣa ati awọn Ọba Israẹli ati Juda

1. Jehoramu, ọba Israẹli ṣe iyipada diẹ, ṣugbọn ko to, II Awọn Ọba 3:1-3

2. Ko si aasiki tabi alaafia fun israẹli, II Awọn Ọba 3:4, 5; Jọṣua 1:1-9; Lefitiku 20:22-24; Deuteronomi 6:10-15; 31:20, 21; Awọn Onidajọ 2:1-3, 11-15

3. Jehoṣafati, Ọba Juda gbọjẹgẹ pẹlu Jehoramu, gbogbo wọn si bọ sinu wahala, II Awọn Ọba 3:6-10; I Awọn Ọba 15:16-20; II Kronika 18:1-34; 19:1, 2; Isaiah 30:1, 2; 31:1

4. Jehoṣafati yipada si Ọlọrun nigba ipọnju, II Awọn Ọba 3:11, 12

5. Eliṣa sọ ni gbangba pe oun ki yoo gbọjẹgẹ pẹlu Jehoramu, II Awọn Ọba 3:13, 14

6. Orin a maa wulo pupọ ti a ba ṣafẹri ifẹ Ọlọrun ti a si n ṣe e, II Awọn Ọba 3:15; Awọn Onidajọ 5:1; I Samuẹli 16:23; II Kronika 20:20-22

7. Ọlọrun ran igbala lọna ti o han gbangba pe Oun ni o ṣe e ni tootọ, II Awọn Ọba 3:16-20; Awọn Onidajọ 7;2

8. Igbala Ọlọrun fun awọn eniyan Rè̩ di ikẹkun fun awọn eniyan buburu, II Awọn Ọba 3:21-27; II Kọrinti 2:16; Ẹksodu 14:19, 20

Notes
ALAYÉ

Aanu ati Iṣeun Ọlọrun --- Apẹẹrẹ Wa

Eliṣa ti gba ilọpo meji agbara ti n bẹ lara Elijah, o si ti pada si Jẹriko. Ni Jẹriko o ba awọn wọnni pade ti wọn mọ iru ipinnu ti o ni pe oun ki yoo jẹ ki ohunkohun dena oun lati gba agbara Ọlọrun; nibẹ ni wọn si gbe sọ fun un pe ki a wa Elijah lọ. O yẹ ki awọn alaigbagbọ wọnyi ti mọ pe Elijah n bẹ lọdọ Ọlọrun ni Ọrun lọhun, ki i ṣe pe a gbe e ju silẹ lori oke tabi afonifoji kan. Itẹdo ibi ti wọn n gbe dara lọpọlọpọ ṣugbọn wọn kuna lati mu anfaani ti o ṣi silẹ fun wọn nipa ti ẹmi lo. O yẹ ki wọn gbe igbesi-aye iwabi-Ọlọrun, ṣugbọn wọn kun fun iyemeji, ọkan wọn ko si si ni ipo ti o fi le ṣafẹri akanṣe ibukun Ọlọrun. Eliṣa gbagbọ o si ri gba; o wa agbara Ọlọrun, o si pada bọ pẹlu rè̩. Lootọ ni a mọ pe ipe awọn ọmọ woli yi yatọ si ti Eliṣa, sibẹsibẹ wọn le ni itẹsiwaju nipa ti ẹmi bi wọn ba ni ọkan lati ṣafẹri rè̩. Ọkan ninu awon ohun ti o fi han pe Eliṣa ti gba agbara Ọlọrun ni wi pe, Ọlọrun fi han nipasẹ woli Rè̩ yi pe Oun ni inudidun si ire ọmọ eniyan.

Ninu Iwaasu Jesu lori Oke, O kọ ọpọ eniyan ti o tọ Ọ wa wi pe ki wọn fẹ awọn ọta wọn, ki wọn si ṣe rere fun awọn ti o korira wọn, ki wọn sure fun awọn ti n fi wọn ré, ki wọn si maa gbadura fun awọn ti n ṣe inunibini si wọn ti wọn si n fi arankan ba wọn lo. Wọn ni lati ṣe eyi bi wọn ba fẹ jẹ ọmọ Baba wọn ti n bẹ ni Ọrun, nitori pe Ọlọrun Baba jẹ Ọlọrun Alaanu, Onifẹ ati Oloore. Ọlọrun ntú awọn ibukun wọnyi dà sori gbogbo ẹda lọna kan tabi lọna miran. Awọn wọnni ti o ba ni aworan Baba wọn ti n bẹ ni Ọrun ni lati dabi Rè̩, nipa oore-ọfẹ ati agbara atunbi Rè̩, ninu gbogbo iwa rere wọnyi si gbogbo awọn ti wọn n ba rin tabi ti n bẹ labẹ akoso wọn.

Nigba ti Eliṣa de Jẹriko, o ri i pe itẹdo ilu naa dara, ṣugbọn omi rè̩ buru, ilẹ ibẹ si ṣá. Eniyan pupọ n bẹ ninu aye ti a fun ni talẹnti ati ọgbọn ti wọn le lo lati mu ire ati alaafia ba awọn ti ko nilaari to wọn, ṣugbọn wọn kuna ninu iṣẹ ati ipe yi nitori pe wọn ko ni iwa-ọrun ti o le mu wọn ṣe aṣeyọri. Gbogbo wa ni lati ni iwa-ọrun, bi aanu, ifẹ ati iṣoore ki a to le ṣe aṣeyọri fun Ọlọrun ati fun ayeraye. Bi a ko ba fẹ sọ igbala wa nu, a ni lati kun fun awọn eso ti ẹmi. Bi ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Ọlọrun ba kuna, o ni lati mu ohun ti o fa ikuna kuro ki a to le mu un pada sinu ifẹ Ọlọrun. Ki o to le ṣe eyi, o ni lati yẹ ọkan rè̩ wo, lẹhin ti o ba si ti ṣe eyi pẹlu ọpọ adura, oun yoo mu “gbongbo ikoro,” eso ikorira, afomọ aiṣedede, tabi awọn okuta ailaanu ti o wu ki ọta ti le gbin sinu ọkan rè̩ kuro.

Ikilọ Idajọ Ọlọrun ti o Daju

Bi aanu, ifẹ ati iṣeun Ọlọrun ti pọ to lori awọn ti Oun yoo ṣaanu fun, bakan naa ni idajọ Rè̩ n bọ wa sori awọn ti o kọ aanu Rè̩ lai si aniani. A ko ni ileri Ọrọ Ọlọrun ti o fi ni lọkan balẹ lati wi pe a o da ibinu Ọlọrun duro tabi ki a fa ọwọ rè̩ sẹhin fun wa, lati maa ba igbesi-aye ẹṣẹ lọ titi di ọjọ ogbo wa. Riru ẹyọ kan ṣoṣo ninu Ofin Ọlọrun to lati ran ni lọ sinu ijiya ayeraye. Olododo ni Ọlọrun, gbogbo ọna Rè̩ ni o dọgba ti o si tọ; ifẹ Rè̩ si ni wi pe ki ẹlẹṣẹ ki o tọ Ọ wa ki wọn le ri aanu, ifẹ ati oore Rè̩ gbà ni akunwọsilẹ.

S̩ugbọn bi eniyan buburu ba taku sinu iwa buburu rè̩, ko si ohun miran ti wọn le maa reti bi ko ṣe idajọ Ọlọrun – ijiya ti o tọ fun ẹṣẹ ati iṣọtẹ wọn. Bi Ọlọrun ti o mọ ohun gbogbo, ti o si mọ ibẹrẹ ati opin ba ke ẹlẹṣẹ kuro ni ibẹrẹ igbesi-aye ẹṣẹ rè̩, ododo ni idajọ yi. Ọlọrun mọ bi eniyan yoo jẹ ronupiwada; nipa ti awọn ọmọde ti n fi Eliṣa ṣe ẹlẹya ti wọn si ṣaibọwọ fun Ọlọrun nipa iwa ti wọn hu si aṣoju Rè̩ yi, Ọlọrun ko kuna lati ran idajọ ojiji sori wọn. (Ka Oniwasu 8:11-13).

Iwa Omugọ ti n bẹ ninu Imulẹ ati Idapọ pẹlu awọn Ẹlẹṣẹ

Apa keji ẹkọ wa sọ nipa awọn ọba mẹta kan ati iṣe wọn, ti ko fa ọgbọn yọ pupọ. Jehoramu jẹ ọba Israẹli, orilẹ-ede ti o ti fasẹhin sinu ibọriṣa. Ohun ti o dara ju lọ ti a ri gbọ nipa rè̩ ni pe, “o si ṣe buburu li oju OLUWA; ṣugbọn ki iṣe bi baba rè̩ ati bi iya rè̩: nitoriti o mu ere Baali ti baba rè̩ ti ṣe kuro.” Oun ko fara mọ ibọriṣa awọn ti o wà ṣaaju rè̩, ṣugbọn ko mọwọ kuro ninu ẹṣẹ ti ibọriṣa wọn mu wa. Ohun daradara ni ibọriṣa ti o mu kuro ṣugbọn ko dara to.

Ọpọlọpọ ti o gbọ ipe Ọlọrun ro pe wọn ti kogo ja bi wọn ba ti kọ oriṣa ti wọn n sin silẹ ti wọn si n jẹ orukọ Onigbagbọ. Wọn ro pe wọn n lọ si Ọrun nipa ṣiṣe bẹẹ. S̩ugbọn eyi ko to. Ibọriṣa ni sisin ohun miran yatọ si Ọlọrun otitọ, ọpọlọpọ abọriṣa ni o si n bẹ laye yi nitori wọn n bọ iṣẹ ọwọ wọn, imọ ati ọgbọn wọn. Bi wọn ba fẹ ohunkohun ju Ọlọrun, ohun ti wọn ba fẹ naa di oriṣa. Lati bọ kuro ninu ibọriṣa gbà pe ki a fẹ Ọlọrun ju ohunkohun lọ.

Ki i ṣe ohun kekere ni fun ẹni ti o ti n bọriṣa gidi lati kó oriṣa rè̩ sọnu ki o si pa gbogbo ọna ibọriṣa tì lati dara pọ mọ awọn Onigbagbọ. Nigba pupọ ni iru awọn bẹẹ yoo ba inunibini kikoro pade nitori iduro ti wọn mu. Ọpọlọpọ la a ja nipa ipinnu ti o gbona girigiri, ati nitori ẹru ati iwaya-ija ti n bẹ ni ookan-aya wọn. Ohun ti wọn ṣe nipa kikọ ibọriṣa silẹ, nigba ti wọn ko mọ ohunkohun yatọ si iru ẹsin bẹẹ ni gbogbo ọjọ aye wọn, tayọ ohun ti ọpọlọpọ ṣe ti o kan gba Jesu ni Olugbala wọn ṣa ti wọn ko si ni iyipada kan ti o dan mọran ni igbesi-aye wọn.

S̩ugbọn bi kikọ ti wọn kọ oriṣa silẹ ti jọ ni loju to, eyi nikan ko to. Gbogbo eniyan ni o ti ṣẹ, olukuluku si ni lati wá idariji ẹṣẹ ati agbara lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ, ti Ọlọrun ti ṣe tan lati fi fun olukuluku ọkan ti o ba fi tọkantọkan ṣe afẹri ododo. Lai si idariji ẹṣẹ yi, ki a si tun ẹni naa bi gan an, gbogbo fitafita wọn ko ni jamọ nkankan. O wà ninu ẹṣẹ rè̩ sibẹ, owọ Ọlorun yoo wuwo si i lara nitori ẹṣẹ rè̩. Jehoramu mu ere oriṣa kuro, ṣugbọn ko kuro ninu ẹṣẹ rè̩.

A ko sọ ohun pupọ fun ni nihin nipa ọba Edomu, ṣugbọn a gba pe iwa rè̩ ko dara niwaju Ọlọrun. Oun ko ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun, ṣugbọn gbogbo igbẹkẹle rè̩ n bẹ ninu ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ ati ọgbọn ọmọ-eniyan. Idapọ pẹlu ọba ti i ṣe ẹlẹṣẹ lati ṣe iranwọ fun un to lati fi iru ipo ẹṣẹ ti o wà han fun ni.

S̩ugbọn Jehoṣafati ni ariwisi pupọpupọ. O dabi ẹni pe Jehoṣafati ni ailera lati maa ba awọn alaiwabi-Ọlọrun ṣọrẹ nitori pe o ti ṣe bẹẹ nigba meji pẹlu awọn ti ko si ni irẹpọ pẹlu Ọlọrun, igba mejeeji ni idajọ Ọlọrun si ti wá sori rè̩. (II Kronika 18:1-34; 20:35-37). Sibẹsibẹ pẹlu gbogbo imọ rè̩ ati ohun ti oju rè̩ ti ri, o tun gba ipe lati dara pọ mọ ọba Israẹli lati ṣe iranwọ fun un lati ba Moabu ti o ṣọtẹ si Israẹli jagun.

Ko si idi pataki kan fun Juda lati ṣe aniyan nipa eto inawo Israẹli. A ko pin fun Juda ninu owo-ori ti Moabu n mu wa fun Israẹli. Juda ko padanu ohunkohun nipa kikọ ti Moabu kọ lati mu owo-ori wa fun Israẹli. Ko ye ni bi Juda ṣe le gba lati dara pọ mọ Israẹli lati ran an lọwọ ki Jehoṣafati si tun jẹ ẹni iwabi-Ọlọrun sibẹ. Lootọ o ni ibẹru Ọlọrun, o n bu ọla fun Ọlọrun, o si n fẹ aabo Rè̩. O ka awọn woli Ọlọrun si (I Awọn Ọba 22:7), ṣugbọn ki i ṣe igba gbogbo ni o n tẹle ọrọ Ọlọrun ti a ti ẹnu awọn woli yi sọ, paapaa ju lọ ti ọrọ naa ba lodi si ifẹ inu rè̩.

Lakoko yi, Jehoṣafati ko beere lọwọ Ọlọrun nipa ipinnu ti o ṣe yi, bakan naa ni ko si ṣe ohun ti o han gbangba pe o tọ lati ṣe, bi iriri atẹhinwa ba jẹ arikọgbọn fun un rara. Ko bojuwo ẹhin rara ki o to dara pọ mọ awọn alaiwabi-Ọlọrun wọnyi, o si fidi idapọ rè̩ mulẹ nipa ọrọ wọnyi: “Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.” Bi ọrọ yi ba jẹ otitọ, ko si ohun rere kan ti a le ri sọ nipa awọn eniyan Juda. S̩ugbọn bi o ba jẹ wi pe ọrọ ẹtan ti a sọ ninu ọgbọn ẹwẹ ti awọn oṣelu ni, eyi fi han wi pe alakoso awọn eniyan Juda ko si ni iru ipo ti o yẹ ki o wà ti o fi sọ ọrọ yi.

S̩ugbọn ohun ti o buru ju ninu idapọ wọn yi ni pe lẹhin ti wọn ti ṣe ipinnu wọn lai beere lọwọ Ọlọrun awọn baba wọn, wọn di ẹbi ikuna wọn ru Ọlọrun. Nigba ti iṣoro kinni yọju – ki wọn tilẹ to fi oju kan ọta wọn rara -- wọn sun Ọlọrun ni è̩sun pe O fi wọn sinu iké̩kun. Awọn tikara wọn ni o yan ọna yi, ki i ṣe Ọlọrun. Awọn tikara wọn ni o ṣe eto yi, ki i ṣe Ọlọrun. Awọn tikara wọn ni o pinnu lati ba ara wọn ṣọrẹ, ki i ṣe Ọlọrun. S̩ugbọn gẹgẹ bi ero wọn, wọn wi pe Ọlọrun ni O jẹ ki wọn kuna.

Ko di igba ti a ba ṣẹṣẹ bojuwo ẹhin fun nkan bi ẹẹdẹgbẹrun ọdun ṣaju akoko ti a bi Kristi gẹgẹ bi Ọmọ-ọwọ Bẹtlẹhẹmu ki a to ri iru iwa segesege yi. Ọpọlọpọ eniyan ni n ṣe ohun kan naa lọjọ oni. Ọpọlọpọ ni o yan ọna buburu, ti wọn si n da Ọlọrun lẹbi nigba ti abuku ba kan wọn lọna naa. Wọn gbin ebu ika, wọn si n di ẹbi ikore rè̩ ru Ọlọrun. Wọn pa Ọlọrun tì ninu eto wọn, wọn si n da Ọlọrun lẹbi wi pe ko jẹ ki o yọri si rere. Wọn kuna lati wá itọni Ọlọrun, wọn a si maa da A lẹbi nigba ti wọn ba ri i pe ọna wọn ko tọ.

Onirẹlẹ Ojiṣẹ Ọlọrun ati Akọrin Kan

S̩ugbọn awọn ibi kan wa ninu akọsilẹ yi ti o fun wa ni iwuri; awọn ohun ati awọn ọkan kan si wa ti a le fi ṣe awokọ. Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba mọ Eliṣa gẹgẹ bi iranṣẹ fun eniyan Ọlọrun kan ti o ti ṣalai si, Jehoṣafati si gba ijafara ati ẹbi rè̩ pe oun ko beere kin ni ifẹ Ọlọrun lọwọ Eliṣa nitori pe o gba pe ọrọ Ọlọrun wà pẹlu Eliṣa. Awọn ohun rere kan n bẹ ninu igbesi-aye Jehoṣafati nigba kan ri, woli Ọlọrun yi si ranti ire yi, nitori naa o bẹbẹ fun awọn eniyan yi nitori ọwọ ti o bu fun ọba Juda. O beere fun akọrin; bi ohùn orin si ti n dun, Ẹmi Ọlọrun ba le woli Ọlọrun yi.

Ọna pupọ ni Ọlọrun n gba lati ba ọkan eniyan sọrọ. S̩ugbọn ọna kan ti O n lo lẹhin iwaasu Ọrọ Ọlọrun ti i ṣe ọna ti o dara ju lọ lati tan Ihinrere kalẹ, ni orin aladun ati ohun-elo orin. Ọpọ ogun ni a ti ṣẹ nipa orin kikọ -- ki i ṣe ogun nipa ti ẹmi nikan bi ko ṣe ogun ti ara pẹlu. Orin ti mu ọkan awọn ti ẹmi eṣu n da loro walẹ to bẹẹ ti wọn fi gbọ ohùn kẹlẹkẹlẹ Ọlọrun. Igba pupọ ni orin ti o kun fun imisi Ọlọrun ti ṣi ọna silẹ fun iwaasu Ihinrere. Ọlọrun si ti lo orin ni igba nì ati ni akoko ti wa yi, gẹgẹ bi iwaasu gan an lati ba ọkan sọrọ ki o si da a lẹjọ nipa ti ẹṣẹ to bẹẹ ti ipo ti wọn wà niwaju Ọlọrun yoo fi di mimọ fun wọn.

Wọn ni lati ṣe Ohun kan fun Igbala Ọlọrun

Ọna ti eniyan Ọlọrun la silẹ fun idande ẹgbẹ ogun Israẹli, Juda ati Edomu ṣajeji. O fẹrẹ le ṣe ni ni kayefi eredi rè̩ ti a fi ni lati wa iho ninu aṣalẹ. Eeṣe ti a ko fi wa koto bi a ba n fẹ omi? S̩ugbọn nigba ti Ọlọrun ba sọrọ, ohun kan ni aigbọdọ má ṣe – sa gbọran.

A ko le ni iṣẹgun nipa titẹle ọna ara wa niwọn igba ti o ṣe pe iparun ni opin ọna naa. Ọna kan ti a gba le ni iṣẹgun ni nipa titọ ọna ti Balogun wa la silẹ ati igbọran si aṣẹ Rè̩. O gba pe ki a walẹ jin. A ni lati ṣaapọn. Ọkunrin afọju ti igba aye Jesu ni lati wẹ amọ kuro ni oju rè̩; alarun ẹgba nì ni lati gbe akete rè̩ ki o si maa rin; obinrin ti o wa ni ibi kanga nì ni lati fa omi ki o si fun ẹni ti i ṣe Ju mu. Ki i ṣe ohun ti awọn ti o gbọran si aṣẹ Jesu ṣe ni o wo wọn san tabi ti o fun wọn ni igbala; ṣugbọn ohun ti o fa a ni pe wọn gbọran si aṣẹ Rè̩. Awọn ẹgbẹ ogun wa iho, Ọlọrun si ṣe eyi ti o kù. Ohun ti o jẹ iyanu ju lọ ni pe omi tu jade fun igbala wọn nibi ti eniyan kò foju si rara. Omi tu jade ninu aṣalẹ.

Bi ọna Ọlọrun ti yatọ si ti wa to! Ọpọlọpọ wahala ni yoo fo wa dá bi a ba jẹ tẹti lelẹ si aṣẹ Ọlọrun, bi a si ti n gbọ, ki a ṣe ohun ti o palaṣẹ lẹsẹkẹsẹ. A ko ni lati mọ bi yoo ti gba wa. Ki i ṣe ti wa lati maa ṣe aṣaro bi yoo ti ṣe e ṣe fun Un lati mu omi jade ninu aṣalẹ lati tẹ oungbẹ wa lọrun. Iṣẹ ti wa ni lati ṣe ohun ti O ba palaṣẹ ki a si jẹ ki O fi wa ṣe ohun ti O ba fẹ. Alaafia yoo wà nibikibi ti O ba gbe n ṣe akoso. Iṣẹgun n bẹ nibikibi ti O ba gbe n ṣe Amọna.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ẹkọ wo ni o ri kọ nipa awotan ti Eliṣa ṣe fun omi?
  2. Eredi rè̩ ti a fi le sọ pe idajọ Ọlọrun ti O ran si awọn ọmọ ti n fi Eliṣa ṣe ẹlẹya tọ?
  3. Kin ni ohun ti o dara ju lọ ti Iwe Mimọ sọ fun ni nipa Jehoramu, ọba Israẹli?
  4. Nigba wo ni Jehoṣafati yan awọn ọrẹ ti o fara jọ eyi?
  5. Kin ni Jehoṣafati ṣe, kin ni o si sọ nigba ti o ba Jehoramu ṣọrẹ?
  6. Eeṣe ti Jehoramu fi fẹ ba Jehoṣafati ṣọrẹ? Kin ni anfaani ti Jehoṣafati ati Juda yoo ri gba ninu ibaṣepọ yi?
  7. Kin ni iduro ti Eliṣa mu nigba ti wọn ranṣẹ pe e?
  8. Kin ni ohun ti Jehoṣafati sọ nigba ti wọn pe Eliṣa, ti o fi han pe o jẹbi lati má pe woli Ọlọrun yi ṣaaju akoko yi?
  9. Kin ni ipa ti orin kó ninu iṣẹlẹ yi?
  10. Sọ eredi rè̩ ti orin “Sa gbẹkẹle,” fi ba ẹkọ yi mu rẹgirẹgi.
1