II Awọn Ọba 4:1-44

Lesson 310 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun mi yio pèse ni kikun fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ rè̩, ninu ogo ninu Kristi Jesu” (Filippi 4:19).
Cross References

I Ororo ti Opo nì

1. Ọlọrun gbọ ti opó ati alainibaba, II ṣwọn Ọba 4:1; Ẹksodu 22:22-24; Deuteronomi 10:17, 18; 24:17-22; Orin Dafidi 68:5; Jakọbu 1:27

2. Eliṣa ṣe iranwọ, II Awọn Ọba 4:2

3. Wọn n fẹ ikoko ofifo, II Awọn Ọba 4:3; Matteu 5:6; Isaiah 26:9

4. A ti ilẹkun mọ ayé si ita, II Awọn Ọba 4:4-7; I Awọn Ọba 17:19; Marku 5:40; 7:33; 8:23; Iṣe Awọn Apọsteli 9:40; Metteu 6:6

II Obinrin ara S̩unemu

1. O bu ọla fun Eliṣa, eniyan Ọlọrun, II Awọn Ọba 4:8-11; Romu 12:13; Matteu 10:40-42; 25:35; Heberu 13:2

2. “Kini a ba ṣe fun ọ?” II Awọn Ọba 4:12-17; 2:9; I Awọn Ọba 3:5; Johannu 15:7

3. Obinrin naa ni igbagbọ, II Awọn Ọba 4:18-26; Gẹnẹsisi 22:5-8

4. O ni ipinnu ti o daju, II Awọn Ọba 4:27-30; Gẹnẹsisi 32:26; Luku 18:1-8

5. A san ère iṣẹ rè̩ fun un nipa jiji ọmọ rè̩ dide kuro ninu oku, II Awọn Ọba 4:31-37

III Iranlọwọ ni Igba Ipọnju

1. A sọ ikoko ẹbẹ ti o loro ninu di rere, II Awọn Ọba 4:38-41; Marku 16:18

2. A sure si ọrẹ ti a mu wa, o si di pupọ, II Awọn Ọba 4:42-44; Owe 3:9, 10; Luku 9:13-17; Matteu 15:32-38

Notes
ALAYÉ

Obinrin Opo

Ọlọrun ṣeleri ninu Ọrọ Rè̩ pe Oun yoo maa tọju awọn opó ati alainibaba. O jẹ apa kan isin mimọ ati aileeri niwaju Ọlọrun “lati mā bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn” (Jakọbu 1:27). Diẹ ninu awọn akọsilẹ igba nì sọ fun ni pe, obinrin opó ti o tọ Eliṣa wa fun iranwọ yi ni iyawo Obadiah, ẹni ti o fi awọn woli Ọlọrun pamọ nigba ti Jesebẹli n fẹ lati pa wọn. Yala bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ, Eliṣa ṣe tan lati ṣe iranwọ. Ohun ti o kọ beere ni pe, “Kini emi o ṣe fun ọ?” Ko tilẹ duro gbọ esi ki o to tun beere pe, “Kini iwọ ni ninu ile?” O si dahun wi pe, “Iranṣẹbirin rẹ kò ni nkankan ni ile bikoṣe ikoko ororo kan.”

Lilo Ohun ti A ni

Bi a ba bẹrẹ si i ṣe ayẹwo awọn iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ṣe nipasẹ awọn iranṣẹ Rè̩, a o ri i pe nigba pupọ ni o jẹ pe ohun ti o wa lọwọ awọn eniyan ti Ọlọrun ti ipasẹ wọn ṣe iṣẹ iyanu naa ni wọn lo. Ọlọrun beere lọwọ Mose pe, “Kini wà li ọwọ rẹ nì?” (Ẹksodu 4:2). Ọpa lasan ni, ṣugbọn Ọlọrun lo o bi ohun-elo lati ṣe ọpọ iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu. Ọpa yi ni Mose fi lu odo ti o di ẹjẹ. O ju ọpa yi silẹ, o di ejo; nigba ti o si tun mu un, o di ọpa pada; nigba ti o na an si okun, o pinya, ọna si la fun awọn Ọmọ Israẹli lati kọja. Ọpa darandaran ni ohun-elo ti S̩amgari lo lati fi pa ẹgbẹta eniyan; paari ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ ni ohun ti Samsoni lo lati pa ẹgbẹrun ọkunrin. Awọn akọni ninu igbagbọ ki i wa ohun ija nla, bẹẹ ni wọn ki i duro de igba ti wọn yoo le ṣiṣẹ nla kan; ṣugbọn wọn n lo ohunkohun ti o ba wa lọwọ wọn lati ṣe iṣẹ ti n bẹ niwaju wọn. Iyẹfun diẹ ati kolobo ororo kekere kan ni n bẹ lọwọ obinrin opó Sarefati nì, ṣugbọn Ọlọrun fi eyi bọ ara ile rè̩ ati Elijah fun ọjọ pupọ.

Ikoko ororo kan dabi ẹni pe ko jamọ nkankan fun obinrin opó ti a sọrọ rè̩ ninu ẹkọ wa yi, lati fi gbọ bukata rè̩, paapaa ju lọ nigba ti awọn ti o jẹ nigbese duro gangan lati mu awọn ọmọ rè̩ ni ẹru. S̩ugbọn agbara Ọlọrun ko loṣuwọn, bakan naa ni eti Rè̩ ko di si igbe awọn alaini.

Ikoko Ofifo

“Lọ, ki iwọ ki o yá ... ikoko ofo.” Ọlọrun le kun ikoko ofifo. Ororo jẹ apẹẹrẹ Ẹmi Ọlọrun, ikoko ofifo si jẹ apẹẹrẹ ọkan ti ebi n pa. Obinrin yi bẹrẹ si i tu ororo sinu ikoko ofifo, ororo naa ko si tan titi gbogbo awọn ikoko ofifo fi kún. Ọlọrun n kún ikoko ofifo titi di ọjọ oni; bi ọkan ti ebi n pa ba sa ti tọ Ọ wa ni Oun yoo kún un. Ohun ti o wa buru nibẹ ni pe awọn ikoko miran kun fun igberaga ati ijọra-ẹni-loju lọpọlọpọ, a si ni lati tu nkan wọnyi jade na ki a si wẹ wọn ki a to le lo wọn. Ko si ikoko ofifo kan – ko si si ọkan kan ti ebi n pa – ti a ki yoo kún.

Ni Ìkọkọ

“Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹkun mọ ara rẹ.” Nigba ti a ba wà ninu iṣoro tabi aini, o ṣanfaani lati sé ilẹkun mọ aye si ita, ki a si wọ iyẹwu pẹlu Ọlọrun nikan. Jesu wi pe “Nigbati iwọ ba ngbadura, wọ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkún rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba” (Matteu 6:6).

O dabi ẹni pe ohun ti o rọrun ni fun Eliṣa lati sọ fun obinrin yi ki o lọ tọrọ ikoko ofifo ki o si sé ilẹkun ki o si maa tu ororo sinu rè̩. Iwọ ha ti dan an wo ri? A ko sọ fun ni pe Eliṣa gbadura nipa rè̩ ṣugbọn iwọ naa ko ha ro pe, Eliṣa paapaa wọ iyẹwu rè̩ lọ, o si se ilẹkun, o si taku ti Ọlọrun ki ororo naa ki o le pọ si i? A ri ka wi pe, Elijah duro niwaju Ahabu o si sọ fun un pe kì yoo si iri tabi òjo fun ọdun melo kan. Akọsilẹ yi ko sọ fun ni pe Elijah gbadura, ṣugbọn Jakọbu sọ fun ni ninu Majẹmu Titun pe, o gbadura gidigidi ki òjo ki o maṣe rọ. Oniṣẹ iyanu ni Ọlọrun wa, ṣugbọn awọn iranṣẹ Rè̩ ni lati jẹ aladura agbayọri.

Oku Ji Dide

Eliṣa tun gbadura nigba kan, ṣugbọn a ko kọ ọrọ adura rè̩ silẹ fun ni. Ni akoko yi, a tẹ okú ọmọ kan sori akete rè̩. “O si wọ inu ile lọ, o si sé ilẹkún mọ awọn mejeeji, o si gbadura si OLUWA.” O si na ara rè̩ le ọmọ naa, pẹlu igbọgbẹ ọkan o n lọ soke sodo ninu ile naa. Lai si aniani, Ẹmi n bẹbẹ ninu rè̩ pẹlu “irora ti a ko le fi ẹnu sọ” gẹgẹ bi Paulu Apọsteli ti sọ fun ni (Romu 8:26). O yẹ ki o le mọ pe adura gbigbona gidigidi ni o ji oku yi dide lọjọ naa.

Ọmọ yi ni ọmọ kan ṣoṣo ti obinrin ọlọla kan ni, ẹni ti o pese yara fun Eliṣa ti o si maa n tọju ounjẹ fun un nigba ti o ba wa si ilu naa. Nigba ti ọmọ naa kú, o tẹ ẹ sori akete Eliṣa, pẹlu igbagbọ. Nigba ti o lọ beere kẹtẹkẹtẹ ti yoo gùn lọ sọdọ eniyan Ọlọrun yi, ko sọ fun ọkọ rè̩ pe ọmọ naa ti kú. Nigba ti ọkọ rè̩ beere eredi ti o fi fẹ lọ si ọdọ eniyan Ọlọrun, o dahun pẹlu igbagbọ pe, “Alafia ni.”

Nigba ti Gehasi, iranṣẹ Eliṣa lọ pade rè̩, o beere pe, “Alafia ki ọmọde wà bi?” Oun si dahun wi pe “Alafia ni.” S̩ugbọn nigba ti Eliṣa ran Gehasi lati fi ọpa rè̩ le ọmọ naa, o wi fun Eliṣa pe, “Bi OLUWA ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi ki o fi ọ silẹ.” Ni akoko iṣoro yi, o tọ ẹni ti o ni agbara Ọlọrun lati fi ororo kun ikoko ofifo lọ. O n fẹ ki eniyan mimọ Ọlọrun ba a gbadura agbayọri lati mu un la idanwo yi ja. Iforiti ati igbagbọ rè̩, ati ti Eliṣa ji ẹmi kan dide kuro ninu okú. O jẹ ọkan ninu awọn obinrin ti a tọka si ninu Heberu ori kọkanla, wi pe wọn gba okú wọn pada nipa igbagbọ. Igbagbọ a maa ṣe ohun ti o ṣoro loju ẹda.

Titan Aini

Gẹgẹ bi awọn iṣẹ iyanu Jesu ti jẹ ti aanu lati tan aini, bakan naa ni o ri pẹlu awọn iṣẹ iyanu ti Eliṣa ṣe. Ororo obinrin opó ti a mu pọ si i, ki i ṣe lati tẹ awọn ọlọfintoto lọrun, bẹẹ ni a ko ji ọmọ obinrin S̩unemu ni dide kuro ninu okú ki a ba le maa pokiki rè̩ kaakiri, nitori pe ni iyẹwu ni iṣẹ iyanu wọnyi ti ṣe, lẹhin ti a ti sé ilẹkun. Nigba ti Eliṣa ran iranṣẹ rè̩ lati se ọbẹ ẹfọ fun awọn ọmọ woli, o jẹ akoko iyàn. Nipa bi ohun gbogbo ti ri, o daju pe Eliṣa ṣe awotan ipẹtẹ naa nitori pe iyan mu, ko si si ounjẹ, ki i ṣe lati fi han pe oun ni agbara Ọlọrun. Nigba ti Jesu wi pe, “Nwọn o si ma gbé ejo lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró ki yio pa wọn lara rara” (Marku 16:18), eyi ko fi han pe O fẹ ki awọn ọmọlẹhin Rè̩ maa mọọmọ dan Ọlọrun wo ni ti pe ki wọn mọọmọ lọ maa gbe ejo lọwọ tabi ki wọn lọ gbe majele mu. Bi Onigbagbọ ba ṣeeṣi mu ohun ti o ni oro tabi ti ejo ba bu u ṣan, ileri Ọlọrun n bẹ fun aabo rè̩.

Nigba ti ẹni kan mu akọso eso oko rè̩ wa fun Eliṣa, ọkan rẹ lọ taara sọdọ awọn ti ko ni ounjẹ to. Iru ẹmi ti Jesu ni ti O fi wi pe, “Anu ijọ enia nṣe mi, nitori o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn ko si li ohun ti nwọn o jẹ” (Matteu 15:32); ni o wa lọkan Eliṣa. Gẹgẹ bi o ti ri pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Jesu nigba kan, awọn iranṣẹ Eliṣa n wo bi eniyan pupọ ti ṣe le jumọ pin iwọn iba ounjẹ diẹ ki wọn si yo, ṣugbọn Eliṣa ti mu ọran naa tọ Ọlọrun lọ. Ọlọrun sọ fun un wi pe, “Nwọn o jẹ, nwọn o si ku silẹ.” Rere ni Ọlọrun, On yio si pese ounjẹ fun awọn enia Rè̩ ni igba ọdá. “Nwọn si jẹ, nwọn si kù silẹ gẹgẹ bi ọrọ Oluwa.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eeṣe ti o fi jẹpe ikoko ororo ni a yàn lati pese fun aini obinrin opó nì?
  2. Igba miran wo ni a mu ororo pọ si i lọna iyanu?
  3. Apẹẹrẹ kin ni ikoko ofifo jẹ?
  4. Sọ diẹ ninu ohun ti ara S̩unemu ti a pe ni “obinrin ọlọla” nì ṣe.
  5. Bawo ni a ṣe san ẹsan awọn ohun ti o ṣe fun un?
  6. Lọna wo ni o gba lo igbagbọ?
  7. So awọn iṣẹ iyanu ti a ṣe ninu Bibeli lẹhin ti a ti sé ilẹkun.
  8. Iru ipo wo ni ilu wà nigba ti a ṣe awotan ipẹtẹ?
  9. Fi ọran ọgọrun eniyan ti Eliṣa bọ we iru iṣẹ iyanu ti o fara jọ eyi ti Kristi ṣe?
1