Lesson 311 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Oju OLUWA mbẹ ni ibi gbogbo, o nwò awọn ẹni-buburu ati ẹni-rere” (Owe 15:3).Cross References
I Ẹri fun Ọlọrun
1. Naamani ara Siria, eniyan nla ati ọlọla, jẹ adẹtẹ, II Awọn Ọba 5:1
2. Ẹrubinrin kekere kan lati Israẹli sọ ti agbara Ọlọrun lati wo iru arun bẹẹ san, II Awọn Ọba 5:2-4; Numeri 12:13-15; Matteu 8:3, 16, 17; 10:8
II Woli Ọlọrun
1. A fi iwe ran Naamani si Ọba Israẹli, lati beere pe ki o wo o san, II Awọn Ọba 5:5-7; Gẹnẹsisi 30:1, 2; 50:19; Ẹksodu 4:16
2. Eliṣa ranṣẹ pe ki a ran Naamani wá sọdọ oun, II Awọn Ọba 5:8; Matteu 11:28; Johannu 5:40; Orin Dafidi 21:4
3. A sọ fun Naamani ki o ri ara rè̩ bọ odo Jọrdani nigba meje, oun yoo si san, ṣugbọn o kọ lati ṣe bẹẹ, II Awọn Ọba 5:9-13; 7:2; Isaiah 53:1; Orin Dafidi 78:19, 20; Matteu 13:58
4. Awọn iranṣẹ Naamani bẹ ẹ ki o dà ọrọ naa rò ki o si gbọ ti Eliṣa, II Awọn Ọba 5:13; Ẹksodu 18:19; II Awọn Ọba 12:6-8; Daniẹli 4:27; Owe 11:14
III Agbara Ọlọrun
1. Naamani san nigba ti o gbọran si aṣẹ woli, II Awọn Ọba 5:14, 15; Owe 4:20-22; Deuteronomi 7:15; Jeremiah 30:17
2. Eliṣa kọ lati gba ère fun iwosan ti Naamani ri gba lọdọ Ọlọrun, II Awọn Ọba 5:15-19, 26; Isaiah 1:23; Daniẹli 5:17; Mika 3:11; Hosea 9:1; Matteu 10:8
3. Gehasi, iranṣẹ Eliṣa gbà ẹbun lọwọ Naamani, ṣugbọn ẹtẹ Naamani lẹ mọ Gehasi nitori ojukokoro rè̩, II Awọn Ọba 5:20-27; Jọṣua 7:11, 25, 26; Iṣe Awọn Apọsteli 5:3
Notes
ALAYÉOlootọ Ẹlẹri
Bi iyemeji ba n ṣe ẹnikẹni nipa ẹri ti awọn ẹni irapada maa n sọ o yẹ ki iyemeji yi ká kuro nipa kika akọsilẹ Naamani adẹtẹ. Ọmọbinrin kekere kan, ti awọn ara ilu miran mu lẹrú, sọ nipa agbara ati ipa Ọlọrun; nitori pe o ṣe bẹẹ, iṣẹ iyanu nla ṣe, okiki orukọ Ọlọrun tan kaakiri. Ọlọrun di ayinlogo gidigidi, ọkan kan yipada si isin Ọlọrun tootọ, ẹri iwosan Naamani si n dun kikankikan lati igba naa wa.
Naamani, ẹni nla ati olokiki ni ilu rè̩, ni arun ẹtẹ. Arun yi yoo le Naamani kuro laarin ẹgbẹ ati ọgbà ati ẹbi rè̩. Arun ẹtẹ ko ṣe e wò; lai si aniani, Naamani ti ro pe oun ko ni ri ibi gbe ọran oun gba, ati pe oun yoo kú lai pẹ ọjọ.
Otitọ ayebaye ni wi pe “Nigba ti iranlọwọ eniyan ba pin, Ọlọrun yoo dide fun iranwọ” ko yipada, paapaa ju lọ nipa ti Naamani. Ọmọ-ọdọ rè̩ obinrin, ti a mu lẹru lati Israẹli wá, sọ fun iyawo oluwa rè̩ nipa woli Ọlọrun ti n bẹ ni ilu rè̩ ti o le wo ẹtẹ Naamani san. Bi eyi ti n lọ lọwọlọwọ, ọrọ ti ọmọbinrin yi sọ de eti igbọ Naamani ati ọba, ireti tun sọji lọtun lọkan Naamani.
Bi eniyan, a maa n woye pe awọn ti n kú lọ ti wọn wa ni ipo iṣoro, yoo ke pe Ọlọrun nitori pe wọn mọ iru ipo ti wọn wà. Awọn miran a maa ṣe bẹẹ, ṣugbọn awọn miran n bẹ ti ki i ṣe e. Naamani jẹ ọkan ninu awọn eniyan pataki ti o yipada si Ọlọrun alaaye tọkantọkan ni akoko iṣoro rẹ. Ẹkọ wa yi fi ye wa pe iru eniyan ti o le ṣe bi ti rè̩ ko wọpọ ni igba ti wọn.
Ọrọ Ọlọrun
Oluwa wi pe: “Bẹni ọrọ mi ti o ti ẹnu mi jade yio ri: kì yio pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yio ṣe eyiti o wù mi, yio si mā ṣe rere ninu ohun ti mo rán a” (Isaiah 55:11). Nipasẹ ẹri ni ọrọ Ọlọrun gba tọ Naamani ati ile rè̩ lọ, nigba ti iwosan ara rè̩ ka a lara gidigidi, ti igbala ọkan rè̩ si jẹ aini nla nla fun un.
Bi o tilẹ jẹ pe ara Siria ni Naamani i ṣe, o si jẹ abọriṣa, bi o ba mọ nipa Ọlọrun otitọ rara, imọ rè̩ kuru lọpọlọpọ, ṣugbọn o fara mọ Ọrọ Ọlọrun ti o tọ ọ wá. Naamani dabi ọkan ninu awọn ọkan iyebiye wọnni ti Jesu n tọka si ninu owe afunrugbin ati irugbin (Ka Matteu 13:1-18, 18-23). A funrugbin naa si oriṣiriṣi ilẹ: diẹ bọ sori apata, diẹ bọ saarin ẹgún, ṣugbọn diẹ bọ si ilẹ rere. Awọn ti o bọ si ilẹ rere so eso ọgbọọgbọn, ogọtọọta tabi ọgọrọọrun. Nipasẹ ẹri ẹrubinrin kekere nì ati imọran rere ti awọn iranṣẹ Naamani, ọkan Naamani di ilẹ rere ti o ṣe tan lati gba ọrọ Ọlọrun. Ọkan rè̩ di ilẹ ẹlẹtu-loju, irugbin ti a gbin sibẹ mu eso jade fun Ọlọrun.
Naamani mu ọna ajo rè̩ pọn lọ si ilu odikeji, o gbọ ohun ti woli ni palaṣẹ, nikẹhin o rẹ ọkàn rè̩ silẹ o si gbọran. A wo ẹtẹ rè̩ san o si yipada si isin Ọlọrun. O di ẹri pataki si aanu ati oore ọfẹ igbala Ọlọrun. Ki i ṣe ni igba aye rè̩ nikan, ṣugbọn titi di isinsinyi, nibikibi ti a ba gbe n waasu ọrọ Ọlọrun. Eyi ni ẹri Naamani nigba ti o fẹ pada si ilu rè̩: “Lati oni lọ, iranṣẹ rẹ ki yio rubọ sisun, bḝni ki yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si OLUWA.”
Orukọ ninu Iwe Iye
Esekiẹli sọ asọtẹlẹ si awọn woli eke ti wọn n sọ asọtẹlẹ eke ni igba ti wọn. “Nwọn ki yio si ninu ijọ awọn enia mi, bḝni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israẹli” (Esekiẹli 13:9). Ọrọ wọnyi jinlẹ, ileri rè̩ si bani lẹru. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe, “Ẹ máṣe yọ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin, ṣugbọn ẹ kuku yọ pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun” (Luku 10:20). Jesu tẹnumọ ọn ju ohunkohun lọ, bi o ti ṣe pataki pe ki a kọwe orukọ wọn ni Ọrun. Ninu iwe ti Paulu kọ si awọn ara Heberu, o sọ bayi pe, “Ẹnyin wá si òke Sioni, ati si ilu Ọlọrun alāye, ti Jerusalẹmu ti ọrun, ati si ẹgbẹ awọn angẹli ainiye, si ajọ nla ati ìjọ akọbi ti a kọ orukọ wọn li ọrun” (Heberu 12:22, 23). Lopin gbogbo rè̩, a kà nipa Itẹ Idajọ Nla Funfun, nibi ti iku ati ipo-okú yoo gbe jọwọ okú wọn, nigba ti awọn oku, ati ewe ati agba, yoo duro niwaju Ọlọrun, ti a o si ṣi awọn iwe silẹ; a o si ṣi Iwe Iye silẹ pẹlu, a o si ṣe idajọ fun awọn oku lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe naa. “Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rè̩ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná” (Ifihan 20:11-15).
Ohun ti o wu ni lori nipa iwosan ati iyipada ọkan Naamani ni pe o mura giri lati wa woli Ọlọrun wá bi o tilẹ jẹ pe eyi ṣe oun ati awọn ẹlomiran ni wahala. Lai si aniani, ko ni rọrun fun un lati pa gbogbo ero ati imọ rè̩ nipa oriṣa ati iboriṣa tì. Ibamaṣepe awọn iranṣẹ rè̩ fi suuru rọ ọ, oun ki ba ti rẹ ara rè̩ silẹ lati gbọran si aṣẹ woli nì pe ki o lọ wẹ nigba meje ni odo Jọrdani. S̩ugbọn nitori pe o gba imọran rere yi, ti i ṣe ohun OLUWA, o ri imularada ati igbala. A kọ orukọ rè̩ sinu Iwe Iye, a si ka a kun Israẹli. Igbagbọ ati igbọran rè̩ ga to bẹẹ ti Jesu fi apẹẹrẹ igbesi-aye rè̩ ba aigbagbọ awọn ọmọ Israẹli wi. Jesu sọ fun wọn pe, “Adẹtẹ pipọ ni mbẹ ni Israẹli nigba woli Eliṣa; ko si si ọkan ninu wọn ti a wẹnumọ; bikoṣe Naamani ara Siria” (Luku 4:27).
Itumọ ohun ti Jesu sọ yi ni pe Naamani nikan ni o lo anfaani aanu ati oore-ọfẹ Ọlọrun, lati gba imularada ati igbala, bi o tilẹ jẹ pe alejo ati ajeji si anfaani awọn ọlọtọ Israẹli ati agbo-ile Ọlọrun ni oun i ṣe. S̩ugbọn nitori pe o gbagbọ, a ti kọwe orukọ rè̩ sinu Iwe Iye, a ki yoo si mu un kuro nibẹ titi laelae. Lai si aniani, ọpọlọpọ adẹtẹ ni n bẹ ni Israẹli ni akoko Eliṣa, gẹgẹ bi Jesu ti wi, wọn mọ Eliṣa, woli Ọlọrun, wọn si mọ nipa isin Ọlọrun tootọ; ṣugbọn bi wọn ti kawọ gbera lai wa Ọlọrun lati ba wọn tan aini wọn, wọn ko ri nkankan gba. A ko kọ orukọ wọn sinu Iwe Iye pẹlu awọn wọnni ti i ṣe Israẹli tootọ. (Ka Efesu 2:11-13; Romu 9:4-8; 2:28, 29).
Ojukokoro
A ri iyatọ laarin Naamani olootọ ninu ẹni ti ko si ayidayida ati Gehasi opurọ ati alayidayida, iranṣẹ Eliṣa. Eyi ko ha to fun ikilọ fun awọn wọnni ti o fara mọ Ihinrere timọtimọ, lati kó ọkan ati ẹmi wọn nijanu pẹlu ipa gbogbo ki wọn má ba bọ sinu idẹwo, ki awọn otitọ Ọlọrun ki o má baa di ohun yẹpẹrẹ loju wọn?
O ṣe e ṣe ki o jẹ pe Gehasi ni i ba gba oye Eliṣa ninu iṣẹ woli, gẹgẹ bi Eliṣa ti ṣe iranṣẹ fun Elijah tọkantọkan ti a si yan an lati dipo rè̩. Ohun ti o bani-ninujẹ ni pe Gehasi ko jẹ olootọ si ipe giga ti Ọlorun pe e, ojukokoro ni o si ṣe okunfa iṣubu rè̩. Bi o ti ri i pe Naamani lawọ, o purọ fun un o si gba ẹbun lọwọ rè̩. Ẹṣẹ Gehasi ko fi ara pamọ fun Eliṣa, ẹtẹ Naamani si lẹ mọ Gehasi nitori iwa ẹṣẹ rè̩.
Naamani wá Ọlọrun, o pada si ile rè̩ pẹlu ajinde ara ati ọkan titun; ṣugbọn Gehasi ẹni ti o n gbọ otitọ Ọlọrun lojoojumọ kuna oore-ọfẹ Ọlọrun, o dẹṣẹ o si di adẹtẹ. Ẹkọ nla nla ti a ri kọ nibẹ ni pe bi eniyan tilẹ jẹ ope nipa awọn ileri ati majẹmu Ọlọrun, sibẹ Ọlọrun jẹ olootọ si oluwarẹ nigba gbogbo, Oun yoo si mu un de ibi ti yoo gbe mọ otitọ, lọna kan tabi lọna miran. Bi ẹnikẹni ko ba ṣe ainaani, a o kọ orukọ rè̩ sinu Iwe Iye. Bi eniyan tilẹ ni anfaani lati gbọ otitọ ọrọ Ọlọrun, ṣugbọn ti o kuna lati gbọran si aṣẹ rè̩ ti ko si rin ninu imọlẹ otitọ rè̩, oun yoo jiya ẹṣẹ rè̩ gẹgẹ bi ti Gehasi.
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni Naamani ṣe gbọ pe agbara Ọlọrun le wo oun san?
- Eeṣe ti inu fi bi Ọba Israẹli nigba ti a sọ fun un pe ki o wo Naamani san?
- Eeṣe ti Naamani kọ lati lọ wẹ ninu odo Jọrdani nigba meje?
- Eeṣe ti Naamani yipada lati lọ wẹ ninu odo Jọrdani nigba meje?
- Eeṣe ti Jesu fi yin Naamani?
- Eeṣe ti a ko wo adẹtẹ miran san ni Israẹli?
- Njẹ Naamani ni iyipada ọkàn tootọ si isin Ọlọrun? Bawo ni a ti ṣe mọ?
- Bawo ni Naamani ṣe lorukọ ninu Iwe Iye?
- Kin ni ẹṣẹ Gehasi?
- Kin ni ṣẹlẹ si Gehasi nitori ẹṣẹ rè̩?