Matteu 1:18-25; 2:1-23; Luku 2:1-40

Lesson 312 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọpá-alade ki yio ti ọwọ Juda kuro, bḝli olofin ki yio kuro lārin ẹsè̩ rè̩, titi S̩iloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ tirè̩” (Gẹnẹsisi 49:10).
Cross References

I Asọtẹlẹ S̩ẹ

1. A ti ọwọ wundia kan bi Jesu Kristi, Oun ni i ṣe Kristi ti Ọlọrun gẹge bi a ti sọtẹlẹ nipa Rè̩, Matteu 1:18-25; Isaiah 7:14; 8:8; 9:6, 7; 11:1

2. A bi Kristi ni Bẹtlẹhẹmu, ni ilu Dafidi, Matteu 2:1, 5, 6; Luku 2:1-7; Johannu 7:42; Mika 5:2

3. Awọn Amoye wá lati ọna jijin rere, lati ṣe awari Kristi, Matteu 2;1-7; Luku 2:1-7, 11; Numeri 24:17-19

4. Josẹfu ati Maria gbe Jesu salọ si Egipti lati bọ lọwọ ibinu Hẹrọdu, Matteu 2:8-15; Hosea 11:1

5. Hẹrọdu pa gbogbo ọmọ wẹẹrẹ titi de awọn ọmọ ọdun meji ki o baa le pa Kristi pẹlu, Matteu 2:16-18; Jeremiah 31:15-17

6. Josẹfu ati Maria pada bọ lati Egipti lati gbe ni Nasarẹti ti Galili, Matteu 2:19-23

II Ibi Olugbala Wa

1. Awọn angẹli kede ihin rere ayọ ti ibi Kristi fun awọn oluṣọ-agutan, wọn si sọ ti ẹda Rè̩ gẹgẹ bi Ọlọrun deniyan, Luku 2:8-14; Iṣe Awọn Apọsteli 2:36

2. Awọn oluṣọ-agutan lọ lati ri Jesu, wọn si fi ogo ati iyin fun Ọlọrun, nitori ohun ti wọn ti gbọ ati eyi ti wọn si ti ri, Luku 2:15-20

3. Awọn eniyan Ọlọrun mọ, wọn si jẹwọ pe Jesu ni Kristi ti Ọlọrun, Luku 2:21-40; Isaiah 52:10; Orin Dafidi 98:2, 3

Notes
ALAYÉ

Titi S̩iloh yoo fi De

Gẹrẹ ti ẹṣẹ ti wọ inu aye ni ọmọ eniyan ti n foju sọna fun Oludande. A ṣe ileri ekinni nipa Oludande fun Adamu, ati Efa, awọn ẹni kinni ti o kọkọ dẹṣẹ si Ọlọrun, nipa bẹẹ, awọn ni ẹni akọkọ ti o n fẹ irapada. Ileri ti a ṣe fun wọn jẹ apa kan ninu egun ti Ọlọrun gun fun ejo. O lọ bayi pe, “Emi o si fi ọta sārin iwọ (ejo) ati obirin na, ati sārin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rè̩: on o fọ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ” (Gẹnẹsisi 3:15). Koko ileri yi ni pe lati inu iru-ọmọ obinrin naa ni Kristi yoo ti jade wá, ati pe yoo pa Eṣu ati gbogbo iṣẹ rè̩ run. Bi o tilẹ jẹ pe a ti pinnu rè̩ pe Satani yoo pa iru-ọmọ obinrin naa ni gigisẹ -- eyiyi ni Kristi -- ṣugbọn Kristi kan naa yi ni yoo si pa gbogbo iṣẹ eṣu run. A bi Kristi sinu aye yi lootọ, awọn eniyan buburu si kan An mọ Agbelebu, ṣugbọn O jinde bi aṣẹgun lori iku ati ipo-oku, nisinsinyi O n jọba loke.

Ọlọrun kò dẹkun lati maa sọ ileri Olurapada di ọtun lati igba ti O ti ṣe ileri kinni. Igbagbọ ninu ileri yi ko dẹkun nigba kan ri lati igba ti ẹbi kinni ti bẹrẹ ninu aye; Ọlọrun si tẹwọgba gbogbo awọn wọnni ti o gbagbọ nipasẹ igbagbọ wọn. (Ka Romu 4:3). Abẹli, Enọku, Abrahamu, Jakọbu ati Isaaki wà ninu awọn ti o ni igbagbọ ninu ileri Ọlọrun nipa Olurapada. Awọn wọnyi, ati ọpọlọpọ bẹẹ, ni o n ṣafẹri ọjọ ti Messia, ani Jesu Kristi yoo wa si aye.

Awọn iwe itan ti ko tilẹ jẹ mọ igbagbọ ati awọn iwe itan nipa igbagbọ sọ fun ni pe ninu aye ọlaju ti igba nì, awọn eniyan mọ, wọn si ni igbagbọ wi pe Messia ati Ọba Israẹli yoo wá si aye. O ṣe e ṣe ki o jẹ pe lati odọ Daniẹli ni wọn gbe ti ni iru imọ bẹẹ. Oun ni a fi iran han nipa igba ti Messia. (Ka Daniẹli 9:20-27). Daniẹli ni alabojuto agba lori gbogbo awọn ọlọgbọn Babeli, okiki rè̩ kan, a si n bu ọla fun un. O ṣe e ṣe ki imọ ati asọtẹlẹ rè̩ nipa Messia di mimọ ki wọn si maa sọrọ nipa rè̩. Ifihan Daniẹli sọ igba naa gan an ti Messia yoo de.

Asọtẹlẹ Balaamu nipa Kristi ṣaaju asọtẹlẹ ti Daniẹli. Bi o tilẹ jẹ pe iran Keferi ni Balaamu i ṣe, o sọ asọtẹlẹ ti o yanju nipa “Irawọ kan lati inu Jakọbu” ati Ọpa Alade ti yoo ti inu Israẹli dide (Numeri 24:17). Bi o tilẹ jẹ pe Israẹli ni Ọlọrun ṣeleri Messia ati Olurapada fun ni pataki, o dabi ẹni pe ọpọlọpọ eniyan ti ko ba orilẹ-ede Israẹli tan, fun oniruuru idi kan pataki ati itara ti o yatọ si ara wọn ni wọn n reti Kristi pẹlu. Fun ọpọlọpọ ọdun ṣaaju ibi Kristi ni Ọlọrun ti n kọ awọn Ọmọ Israẹli ki O ba le lo wọn bi ohun-elo lati fi ọna isin Ọlọrun han fun awọn orilẹ-ede Keferi. S̩ugbọn nigba pupọ ni Israẹli n bọriṣa dipo ki wọn sin Ọlọrun alaaye. Sibẹsibẹ Ọlọrun lo awọn kọọkan ninu wọṅ lati kede ati lati tan ihin ireti ati ileri Messia kalẹ. Bi o tilẹ jẹ pe òye ọpọlọpọ eniyan kuru nipa idi ti Jesu fi wá si aye, sibẹsibẹ ibi Rè̩ gẹgẹ bi Ọmọ-ọwọ ni Bẹtlẹhẹmu ṣiṣẹ ti rẹ.

Lati igba ti ẹṣẹ ti ṣiṣẹ ibi rè̩ ninu ọkan eniyan ni akọṣe ni ọkan ọmọ-eniyan ti n kerora fun idande. Àwọ ara wa ko ni ohunkohun i ṣe pẹlu igbala wa; bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awọn Ọmọ Israẹli jẹ ọta kikoro si Jesu, sibẹ ọpọ ọkàn ti ebi n pa ni o fi tayọtayọ gba A. A le ri ẹkọ kọ nihin fun anfaani wa, bi a ti n kà nipa awọn miran ti wọn ri ohun ribiribi gba lọdọ Ọlọrun nitori pe wọn ni igbagbọ ninu Kristi. Iwe itan awọn Ju sọ fun ni pe ireti olukuluku obinrin ni pe oun ni yoo jẹ iya Messia. A kà nipa awọn meji kan, ti ki i ṣe Ọmọ Israẹli, ti a sọ di ibatan Kristi. Awọn meji yi ni Rutu, obinrin kan ara Moabu, ti o gba isin Ọlọrun gẹgẹ bi iya-ọkọ rè̩ ti fi kọ ọ; ati Rahabu, ti o ṣe iranwọ gidigidi fun awọn meji ti o wá si Jẹriko.

Ihin Ayọ

Ni tosi ilu Bẹtlẹhẹmu ni awọn oluṣọ-agutan kan gbe wà ni papa pẹlu agbo-ẹran wọn. Awọn oluṣo-agutan yi ni angẹli Oluwa fi ara han, ti o si kede ibi Kristi fun. O wi fun wọn pe, “A bi Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa” (Luku 2:11).

Ibi Kristi ko ṣalai ni ami iyanu ninu, awọn ogun ọrun si fi ayọ wọn han pẹlu. Ikede angẹli Ọlọrun fun awọn oluṣọ-agutan jẹ ami iyanu kan. Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ òpe ni igbesi-aye wọn, bọya, sibẹ, o ni lati jẹ pe wọn jẹ ọlọgbọn nipa ti Ọlọrun ki a to le fi ikede bayi nipa ibi Kristi da wọn lọlá. Bi wọn ti lọ lọgan lati wo ohun ti o ṣẹlẹ, wọn ri Jesu, Ọmọ-ọwọ naa, gẹgẹ bi angẹli nì ti kede fun wọn. Lẹhin ti wọn pada si ibi ti agbo-ẹran wọn wà, wọn yin Ọlọrun logo fun ohun nla ti wọn ti gbọ ati eyi ti wọn ti ri, wọn si tan ihin ohun ti a sọ fun wọn nipa Ọmọ naa kalẹ.

Ni nkan bi ogoji ọjọ lẹhin eyi, lẹhin ti ọjọ iwẹnumọ Maria ti pe gẹgẹ bi Ofin Mose, awọn obi Jesu gbe E wa si Tẹmpili, lati fi I fun Oluwa. (Wo Lefitiku 12:2-4). Ọkunrin kan si n bẹ ninu Tẹmpili, ẹni ti a n pe ni Simeoni, olootọ ati olufọkànsin, ti o n reti itunu Israẹli. A ti fi han an lati ọdọ Ẹmi Mimọ wá pe, oun ki yoo ri iku ki o to ri Kristi Oluwa. Ẹmi Ọlọrun dari rè̩ lati lọ si Tẹmpili nigba ti Josẹfu ati Maria gbe Jesu wa sibẹ. Bi Simeoni ti ri Jesu, o gbe Ọmọ naa li apa rè̩, o si sọ asọtẹlẹ nipa Rè̩ pe, “Oju mi ti ri igbala rẹ na” (Luku 2:30). Ọrọ yi jẹ iyanu, ohun ti Simeoni sọ nipa Jesu ya Josẹfu ati Maria lenu. Gẹrẹ ti o ṣe tan ni Anna, woli obinrin wọle wá, oun naa si fi iyin fun Oluwa; o si “sọrọ rè̩ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalẹmu.”

Awọn Amoye lati Okeere

Lai pẹ pupọ lẹhin ti a bi Jesu, awọn amoye kan wá lati ila-oorun, wọn ti beere lọwọ awọn ijoye ni Jerusalẹmu pe “Nibo li ẹniti a bi ti iṣe ọba awọn Ju wà?” Iwadi wọn daamu awọn ara Jerusalẹmu gidigidi; ọkan Hẹrọdu ọba paapaa ko lelẹ. Ọwọ lile ati è̩ru ni Hẹrọdu fi n ṣe akoso orilẹ-ede naa, o si mọ ohun ti o le ṣẹlẹ bi Messia kan ba de. Hẹrọdu ati ọpọ awọn miran pẹlu n fojusọna pe Kristi yoo gbe ijọba Rè̩ kalẹ ni aye gẹgẹ bi oṣelu, yoo si pa gbogbo eto iṣakoso igba ti o ti wà tẹlẹ run patapata. È̩ru ati owu kún Hẹrọdu lọkan lati gbọ pe ẹni kan yoo dide lati doju ijọba rè̩ bolẹ, nitori naa o yara pe awọn olori alufa ati awọn akọwe, o si beere lọwọ wọn ibi ti a o gbe bi Kristi. Nigba ti a sọ fun un pe asọtẹlẹ ti wi pe Bẹtlẹhẹmu ni, o ran awọn amoye naa lati wa Kristi, Ọmọ-ọwọ naa. Ko pẹ ti ohun ti n bẹ lọkan Hẹrọdu fara han. Bi ko ti ri Kristi nigba ti o kọ wa A, o paṣẹ fun awọn ọmọ-ogun rè̩ lati pa awọn ọmọ ọdun meji jalẹ ni gbogbo ilẹ naa, ni ireti lati da eto pe, Kristi yoo bi ijọba rè̩ wó ru.

Bi o tilẹ jẹ pe ikorira ati owu n bẹ ninu ọkan Hẹrọdu si Kristi, sibẹ o mọ pe Kristi yoo di ẹni nla ati alagbara. Bawo ni aigbagbọ awọn alufa ati awọn akọwe ti jẹ iyanu to! Wọn mọ awọn asọtẹlẹ ti a ti sọ nipa Kristi, awọn ni o sọ fun Hẹrodu ibi ti a o gbe bi I, wọn ri awọn ti o ti okeere wá lati ri I, sibẹ wọn ko ni in lọkan lati le ri I tikara wọn. Iru aigbagbọ kan naa ni o n bẹ lọkan awọn eniyan lọjọ oni. Ihinrere sun mọ awọn ẹlomiran pẹkipẹki bayi sibẹ wọn ko bikita lati gba a; bẹẹ ni ẹlẹṣẹ paraku miran ti o jinna rére si Ijọba Ọlọrun wà, bi imọlẹ ogo Ọlọrun ba ti tan sọna rẹ diẹ kinun, ni yoo yipada si Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkàn rè̩ ti yoo si ri Kristi tikara rè̩.

Awọn Ẹlẹri Ọlọrun

Nipa awọn ohun ti o ṣẹlẹ wọnyi, Ọlọrun ṣe iṣẹ iyanu pupọ lati fi han fun olukuluku eniyan pe a bi Olugbala. Oriṣi ẹgbẹ mẹta ọtọọtọ ni o ro ihin yi kaakiri.

Awọn oluṣọ-agutan ro ihin ayọ ti awọn ogun Ọrun sọ fun wọn nipa ibi Kristi fun awọn ọrẹ ati ojulumọ wọn, eyi fi han pe awọn mẹkunnu, ani awọn oṣiṣẹ gbọ ihin ayọ naa. Awọn ara ti o n reti idande Israẹli gbọ nipa Kristi lati ẹnu awọn ẹlẹgbẹ wọn meji: Simeoni, olootọ ati olufọkansin, ati Anaa, woli obinrin. Lopin gbogbo rè̩, awọn amoye wá lati okeere rére lati wá foju kan Kristi. Amoye wọnyi sọrọ nipa Kristi fun awọn ẹni giga ju lọ ati awọn alagbara ju lọ ni ilẹ naa. Hẹrọdu, awọn akọwe, awọn alufa, ati awọn ẹlẹgbẹ wọn gbọ ihin ohun nla ti o ṣẹlẹ yi lati ẹnu awọn wọnni ti o wá lati ọna jijin lati wa fi oju wọn ri I. Bi ijolootọ Ọlọrun si ọkan ọmọ-eniyan ti pọ to lati jẹ ki o di mimọ fun wọn pe Olugbala kan n bẹ ti o le gba awọn ẹni iṣubu kuro ninu ẹṣẹ wọn!

Ni ọdun pupọ lẹhin eyi, nigba ti Paulu Apọsteli n sọ ẹri rè̩ niwaju awọn alaṣẹ Romu, o sọ bayi pe, “Ọba mọ nkan gbogbo wọnyi, niwaju ẹniti emi nsọrọ li aibè̩ru: nitori mo gbagbọ pe ọkan ninu nkan wọnyi kò pamọ fun u nitoriti a kò ṣe nkan yi ni ìkọkọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 26:26).

Ọlọrun ti mu ileri Rè̩ ṣẹ fun araye. Isaiah sọ asọtẹlẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin, ọpọlọpọ ọdun ṣaaju ibi Kristi ni asọtẹlẹ jade nipa Ẹni ti o n bọ wá. O sọ bayi pe, “Dide, tàn imọlẹ: nitori imọlẹ rẹ dé, ogo OLUWA si yọ lara rẹ. Nitori kiyesi i, okùnkun bò aiye mọlẹ, ati okùnkun biribiri bò awọn enia: ṣugbọn OLUWA yio yọ lara rẹ, a o si ri ogo rè̩ lara rẹ” (Isaiah 60:1, 2).

Ki Ọlọrun má ṣai jẹ ki olukuluku ọkan ti o n ka ẹkọ yi ṣe afẹri Olugbala araye lati jẹ Oluwa ninu ọkan rè̩. “Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lẹkanṣoṣo lati ru è̩ṣẹ ọpọlọpọ; yio farahan nigbakeji laisi è̩ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rè̩ fun igbala” (Heberu 9;28). Ko si aye fun Un ni ile-ero nigba ti a bi I. Ẹ jẹ ki a wá aye fun Un ninu ọkàn wa, nipa ṣiṣe bẹẹ ki a le fi ọpẹ fun Ọlọrun nitori igbala nla Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ ileri kinni ti a ṣe nipa Olurapada.
  2. Sọ ọpọlọpọ asọtẹlẹ ti a muṣẹ nipa ibi Kristi.
  3. Sọ ọna mẹta ti ihin ibi Kristi gba fi di mimọ.
  4. Eeṣe ti awọn amoye fi wá lati Ila-oorun lati wa bẹ Kristi wò?
  5. Bawo ni a ṣe mọ pe ireti Messia di mimọ fun eniyan gbogbo?
  6. Eeṣe ti Hẹrọdu fi pa gbogbo awọn ọmọ ọdun meji si isalẹ?
  7. Bawo ni ibi Kristi ti ṣe pataki fun wa to lọjọ oni?
1