Orin Dafidi 84:1-12; Habakkuku 2:4; Romu 1:16, 17; Galatia 3:10, 11; Heberu 10:35-39

Lesson 313 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn olododo ni yio yè nipa igbagbọ; ṣugbọn bi o ba fà sẹhin, ọkàn mi kò ni inu-didùn si i” (Heberu 10:38).
Cross References

I Ayọ ati Ere ti o wa ninu Ijọsin Tootọ

1. Ile Ọlọrun nibi ti ifarahan Ọlọrun wà jẹ ibi ti o dara ju lọ layé fun awọn olododo, Orin Dafidi 84:1-4; 23:6; 26:8; 27:4; 122:1; I Kronika 29;3; Luku 2:36, 37; 24:52, 53

2. Awọn ti n sin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ jẹ ẹni-ibukun ni gbogbo ọjọ aye wọn, Orin Dafidi 84:5-8; 95:6, 7; Johannu 4:14, 23, 24

3. Anfaani ti o tobi ju lọ lo jẹ lati le sin Ọlọrun lai si idena, Orin Dafidi 84:9-12; Deuteronomi 12:5; Orin Dafidi 122:4; 65:4

II Itumọ ati Apejuwe Igbagbọ gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti Gbe e Kalẹ

1. Igbagbọ ki i ṣe ohun kan lasan ti a le fi ọgbọn ori ṣe tabi fi ọkan rò, ṣugbọn o jẹ idaniloju ohun ti a n reti ati ijẹri si ohun ti a ko ri, Heberu 11:1-3; II Kọrinti 5:7; Galatia 5:6

2. Ki a baa le wu Ọlọrun ki a si le de Ọrun, igbagbọ jẹ ohun danindanin Heberu 1:6; Jakọbu 1:5-7; I Timoteu 1:5; I Johannu 5:4; Marku 11:22; Johannu 20;27; Efesu 6;16; Filippi 3:9-11

3. Igbagbọ le dagba soke, Luku 17:5; I Tẹssalonika 5:8; I Timoteu 6:11, 12; Heberu 10:22

4. A le sọ igbagbọ nù, Luku 18:8; I Timoteu 1:18, 19

5. A maa n ni igbagbọ nipa gbigba Ọrọ Ọlọrun nipasẹ imisi Ẹmi Mimọ, Romu 10:17; Johannu 20:31; II Timoteu 3:15

6. Nipa igbagbọ ni a n ri gbogbo ibukun Ọlọrun gba, Matteu 8:13; 9:29, 30; 17:20; 21:21; Marku 9:23

III Igbesi-aye Igbagbọ

1. .Igbesi-aye igbagbọ ninu Ọlọrun ko fi àye silẹ fun ẹṣẹ tabi iṣẹ ti ara lọnakọna, Habakkuku 2:4; Romu 14:23

2. Igbesi-aye Onigbagbọ ki i bẹrẹ nipa igbagbọ nikan, ṣugbọn a maa lọ lati ipa de ipa nipa igbagbọ, ni ṣisẹ-ntẹle, Romu 1:16, 17; 5:1; 9:33; 10:9; Isaiah 41:10; Owe 4:18; II Kọrinti 3:18

3. Igbagbọ ninu Ọlọrun, ki si i ṣe iṣẹ Ofin ni o n fun ni ni idalare niwaju Ọlọrun, Galatia 3:6-14; Filippi 3:9; Gẹnẹsisi 15:6; Iṣe Awọn Apọsteli 10:43; 13:39

4. Nipa igbagbọ ni a le ni iforiti titi de opin, Heberu 10:35-39; 4:3; Deuteronomi 8:3; Johannu 5:24; 20:31; Kolosse 1:21-23; Jakọbu 2:5

Notes
ALAYÉ

Ọlọrun ti lo ẹsẹ kukuru kan niye igba ninu Bibeli lati mu igbala tọ ọkunrin ati obinrin lọ. Ibi mẹrin ni akọsilẹ ọrọ yi gbe wà ninu Iwe Mimọ, akọsilẹ kinni kún ju awọn mẹta iyoku lọ. Ọlọrun fi ọrọ yi ba ọkan Martin Luther sọrọ, nipa bẹẹ, Martin Luther ni igbala. John Wesley gbọ ọrọ naa pẹlu, itumọ ohun ti ọrọ naa jẹ ye e, o si ri i pe “ọkàn (rè̩) gbina ninu” rè̩, nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba ẹmi rè̩ jẹri si igbala rè̩. Ọrọ pataki naa ni eyi: “Olododo yio wà nipa igbagbọ rè̩.” Ẹ jẹ ki a ṣe aṣaro lori ọrọ wọnyi, itumọ wọn, ki a si wo ọna ti wọn gba jẹ mọ igbesi-aye wa.

Bi o tilẹ jẹ pe Ẹmi Mimọ ti lo ọrọ wọnyi lati sin ọpọlọpọ ọkan de orisun ibukun ti idariji ẹṣẹ, iriri ti a n pe ni idalare nipa igbagbọ, o han gbangba pe eyi ti o jù ninu ọrọ wọnyi jẹ mọ awọn olododo -- awọn wọnni ti a ti dari ẹṣẹ wọn ji ti a si ti rapada. Gẹgẹ bi gbogbo Ọrọ Ọlọrun ti ri, ọrọ wọnyi jẹ iye fun awọn ti o fẹ iye, o si tun jẹ idalẹbi fun awọn ti o fẹ ọna okunkun. Ileri Ọlọrun Olodumare ni ọrọ wọnyi jẹ. Wọn fi ohun ti o jẹ gunmọ ti eniyan ni lati ṣe han. Wọn fi han pe eniyan le ni igbagbọ, o si le jẹ olododo. Wọn fun ni ni ireti ati itunu, wọn si fi ẹsẹ awọn eniyan Ọlọrun le ọna lati mọ ifẹ Ọlọrun, to bẹẹ ti olukuluku yoo le maa tọ ọna ti Ọlọrun la silẹ niwaju rè̩ ni ipokipo ti o wu ki a pe e si. Nipasẹ koko ilana ti iwọn iba ọrọ diẹ wọnyi fi ye ni ni a gba n ṣe iṣẹ ijọba Ọlọrun nipa mimoju to, didarí ati ṣiṣe eto rè̩. Ninu eyi ni aṣiiri igboke-gbodo wa ninu iṣẹ Ọlọrun gbe wa.

Igbala nipa Igbagbọ

“Ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin; è̩bun Ọlọrun ni” (Efesu 2:8). Lọna miran, ohun ti Iwe Mimọ n sọ fun ni ni pe ẹbun Ọlọrun ni igbala, a si n ri i gba nipa oore-ọfẹ nipa igbagbọ. “Njẹ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ awa ni alafia lọdọ Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (Romu 5:1). “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ, a si ká a si ododo fun u” (Romu 4:3; Galatia 3:6; Gẹnẹsisi 15:6). Paulu Apọsteli sọ bayi pe, “Mo ti ṣòfo ohun gbogbo, ... ki emi ki o le jère Kristi, ki a si le ba mi ninu rè̩, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ” (Filippi 3:8, 9).

O han gbangba nihin pe, bi o tilẹ jẹ pe ọrọ ti a yan fun ẹkọ wa yi jẹ ti awọn eniyan mimọ, wọn jẹ iwaasu pataki fun awọn ẹlẹṣẹ pẹlu, nitori pe bi eniyan ba fẹ rin nipa igbagbọ o ni lati kọ bọ si oju ọna igbesi-aye igbagbọ; ẹwẹ, bi eniyan ba ti bọ si oju ọna igbesi-aye igbagbọ, o si ni lati maa rin nipa igbagbọ.

Igbagbọ jẹ ohun pataki ju lọ -- lai si rè̩ a ko le wu Ọlọrun (Heberu 11:6). Igbagbọ ṣe pataki ju lọ -- lai si rè̩ ko si ẹni ti o le ni igbala (Heberu 11:6; Jakọbu 1:5-7). Igbagbọ ṣe pataki ju lọ -- lai si rè̩ a o dẹṣẹ (II Kọrinti 5:7). Igbagbọ ṣe pataki ju lọ -- lai si rè̩ a ko le duro deedee (II Kronika 20:20). Igbagbọ ṣe pataki ju lọ -- oun ni a le “fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì” (Efesu 6:16). Igbagbọ ṣe pataki ju lọ -- oun ni ihamọra ti a ni lati gbe wọ “leke gbogbo” awọn ihamọra ti ẹmi (Efesu 6;16).

Nigba ti ẹlẹṣẹ ba tọ Ọlọrun wá, Ọlọrun yoo dari ẹṣẹ rè̩ ji, oore-ọfẹ Ọlọrun yoo da a lare lọfẹ, yoo di atunbi nipa È̩jẹ nì, yoo si di ẹbi Ọlọrun nipa aanu Ọlọrun, “nipa ore-ọfẹ ... nipa igbagbọ.” Ko si ọkan ninu awọn ẹbun rere igbala Ọlọrun yi ti o le tẹ ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada lọwọ bi o ba ṣiyemeji si Ọlọrun tabi ki o kuna lati gba ileri Rè̩ ti o ṣe fun un gbọ. Nipa igbagbọ nikan ni a le gba tọ Ọlọrun wá; iwọn iba igbagbọ diẹ si n bẹ ninu adura kọọkan ti n lọ siwaju Itẹ; bawo ni ẹnikẹni ṣe le gbadura si Ọlọrun bi ko ba ni igbagbọ ninu Ọlọrun bi o ti wu ki igbagbọ naa kere to? “Ẹniti o ba nṣiyemeji, o jẹbi” (Romu 14:23), ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbagbọ ki yoo ṣegbe, ṣugbọn yoo ni iye ti ko nipẹkun (Johannu 3:15), “Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ ... a o gbà ọ là” (Romu 10:9).

Igbesi-aye Olododo jẹ Igbesi-aye Igbagbọ

Bi a ba ṣe ayẹwo awọn ọrọ ti a yan fun ori ẹkọ wa yi gẹgẹ bi o ti ri gan an nibi ti akọsilẹ akọkọ (ti a le ri ninu Majẹmu laelae) gbe wa, a o ri i pe ọrọ ti a maa n lo nigba ti a ko ba darukọ eniyan n bẹ nibẹ. Ọrọ kekere naa ni “rè̩.” Otitọ nlá nlà ni eyi fi han ti o si kọ ni. Lootọ, “Olododo ni yio ye nipa igbagbọ,” ṣugbọn lai si aniani, nipa igbagbọ “rè̩” ni.

Ẹlomiran le ro wi pe ọwọ oun ti tẹ eeku idà igbagbọ nitori pe awọn obi oun tabi awọn alabagbe oun jẹ Onigbagbọ. O tilẹ le lọ Ọrọ Ọlọrun ti o wi pe: “A sọ alaigbagbọ ọkọ di mimọ ninu aya rè̩, a si sọ alaigbagbọ aya na di mimọ ninu ọkọ rè̩,” ohun ti o fẹ fi ye ni ni pe a o ṣe oun ni olododo nipa adura awọn ẹlomiran. Ọmọ ti o ni obi Onigbagbọ paapaa le fẹ fi ori pamọ sabẹ ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yi: “Gba Jesu Kristi Oluwa gbọ, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu” (Iṣe Awọn Apọsteli 16:31), ki o si dori itumọ rè̩ gan an kodo lati wi pe oun ko le ṣegbe nitori pe baba tabi iya oun gbadura fun oun. Awọn miran ro pe nitori ti wọn ni awọn obi Onigbagbọ, awọn yoo là nigbooṣe, bi o ti wu ki wọn ṣe buburu to ni ọjọ aye wọn, bi o si ti wu ki wọn ṣe ainaani aanu Ọlọrun to. S̩ugbọn awọn ọrọ kukuru ti ẹkọ wa yi duro le lori fi han pe ero asan ti wọn gbe kalẹ ninu ọkàn wọn yi ko fẹsẹ mulẹ nitori pe “Olododo yio wà (yè) nipa igbagbọ rè̩.”

Eyi fi han wa pe gbogbo wa ni o ni lati tọ Ọlọrun wá, ki a tọrọ idariji ẹṣẹ, ki a si ni igbagbọ nla ti a n fi fun onirobinujẹ ọkan ti o lo igbagbọ kekere ti o ti wà lọkan rè̩ tẹlẹ. Bi o ba fẹ wà nipa “igbagbọ rè̩,” o daju pe o ni lati ni igbagbọ. Bi o ba wa ni ipo iṣọtẹ si Ọlọrun, o han gbangba pe ko ni igbagbọ ti o ni lati ni ki o ba le yè, ki a má tilẹ mẹnukan igbagbọ pa-mi-nkú. Igbagbọ ti Ọlọrun n beere lọwọ wa ni igbagbọ ti yoo wà lọkàn wa nigba gbogbo, ni gbogbo ọjọ, lọsan ati loru.

Igbagbọ ti a ni lati ni gbọdọ jẹ igbagbọ ti n wo Ọlọrun fun itọni, nitori ti a ni igbagbọ pe Oun yoo tọ wa. Igbagbọ ti a ni lati ni gbọdọ jẹ igbagbọ ti o gbẹkẹle Ọlọrun fun aini wa igbagbogbo, nitori ti a gbagbọ pe Oun yoo bojuto wa. Igbagbọ ti a ni lati ni jẹ eyi ti yoo maa wo Ọlọrun fun idagbasoke nipa ti ẹmi, nitori ti a gbagbọ pe yoo fi Ọrọ Mimọ Rè̩ bọ wa. Igbagbọ ti a ni lati ni jẹ eyi ti yoo maa wo Ọlọrun fun igbala wa ati ireti wa ayeraye, nitori ti a gbagbọ pe ifẹ inu Rè̩ ni lati fi Ijọba Ọrun fun wa. Igbagbọ ti a ni lati ni jẹ eyi ti yoo gba gbogbo ẹya ara wa kan, igbagbọ ti yoo fi ọkan wa balẹ pe Ẹmi Mimọ yoo sọ ara wa kikú yi di aaye to bẹẹ ti a o fi le pade Oluwa ati Olugbala wa ni awọsanma ni abọ Rè̩. Igbagbọ ti a ni lati ni niyi, oun ni a si ni lati ba kú.

Ni iwọn akoko kukuru ti a ni gbe nihin, ẹgbaagbeje igba ni o ṣe pe a ni lati fẹhin ti igbagbọ wa ninu Ọlọrun lati mu wa la a ja. Paulu sọ nipa ipọnju, inunibini, ikerora ninu ara ati ninu ẹmi, a si mọ pe ko le ṣe e ṣe fun un lati fara da nkan wọnyi bi ko ba ni igbagbọ ninu Ọlọrun. Bi awa ko ba tilẹ ni jiya lọna kan naa, sibẹ a ni lati ba Ọlọrun rin pẹlu igbagbọ.

Nigba ti ọmọ Ọlọrun ba ji ni owurọ lati bẹrẹ iṣẹ oojọ rè̩, ki i ṣe pẹlu ijọra-ẹni-loju ti o wọpọ laarin awọn alaiwabi-Ọlọrun, ṣugbọn pẹlu igbagbọ ti o fọkan tan Ọlọrun. Ọmọ Ọlọrun a maa beere pe ki Ọlọrun ṣe amọna oun ni gbogbo ọjọ, ki O si fun oun ni agbara lati ṣe iṣẹ oojọ oun, ati fun ọgbọn ati oye ninu ohun gbogbo ki igbesi-aye oun le jẹ ibukun fun ọpọlọpọ eniyan. Oun yoo fi ẹmi rè̩ ati gbogbo ọna rè̩ ni ọjọ naa le Ọlọrun lọwọ. Oun yoo tọrọ aabo Ọlọrun lori awọn ti n bẹ ni tosi ati awọn ti o ṣọwọn fun ọkan rè̩, yoo si gbadura pe ki ibukun Ọlọrun le wa lori ohun gbogbo ti a ba n ṣe fun ọla ati ogo Ọlọrun ni ọjọ naa. Oun yoo gbadura fun awọn ti o ni irora ninu ara. Oun yoo gbadura fun awọn iranṣẹ Ọlọrun ti o n ṣaapọn lati jẹ ki Kristi di mimọ. Oun yoo fi ọna rè̩ le Ọlọrun lọwọ. Ọmọ Ọlọrun yoo ṣe gbogbo eyi nitori ti o ni igbagbọ ninu Ọlọrun. O mọ pe Ọlọrun ti n dahun adura ni oun n gbadura si.

Igbesi-aye ẹlẹṣẹ yatọ si eyi! Oun ki i tilẹ lo iwọn iba igbagbọ diẹ ti o ni. Ọgbọn ara rè̩ ni o gbẹkẹle -- ọgbọn ti ko tayọ ọgbọn kukuru rè̩. O gbẹkẹle imọtẹlẹ rè̩ -- imọtẹlẹ ti ko tayọ ọgbọn ti o ri kọ nipa iriri ara rè̩ tabi ti awọn ẹlomiran. O gbẹkẹle agbara ara rè̩ -- agbara ti o ṣe pe Ọlọrun ninu aanu Rè̩ ti fi fun un tẹlẹ ṣugbọn ti o fẹ maa fi ọgbọn ọmọ-eniyan kun un. Ẹlẹṣẹ a saba maa fi igbesi-aye rè̩ ji fun awọn ẹbi rè̩ ti o sun mọ ọn timọ-timọ; bi o ba si jẹ pe o jẹ ọkan ninu awọn ti ifẹ wọn tayọ awọn iyekan wọn nikan, oun yoo fi aye rè̩ ji fun ire ọmọ-eniyan lapapọ. Anfaani ati ire ti o n wá fun awọn ti n bẹ labẹ akoso ati itọju rè̩ ko tayọ nkan wọnni ti owo le ra tabi ti o le fi agbara ọwọ rè̩ ati ọgbọn ori ara rè̩ ṣe. Oun ko ni ireti iye ainipẹkun tikara rè̩, bẹẹ ni ko ni ọrọ itunu ti o le fi tu ẹlomiran ninu nigba ti ayeraye sun mọ ọn gbọngbọn. Gbogbo ilepa ati ero ẹlẹṣẹ ko tayọ nkan aye yi, nigba pupọ ni ko tilẹ tayọ ọdọ awọn wọnni ti o fi ṣe ẹgbẹ ati ọgba rè̩.

Yatọ si eyi, olododo a maa lọ lati “ipa de ipa,” ibaa tilẹ ṣe ninu afonifoji omije. Nigba ti wahala tabi iṣoro ba de, igbagbọ ati igbẹkẹle olododo nbẹ ninu Ọlọrun, Oun yoo ri ọwọ igbala Ọlọrun, itura ati itunu kan yoo wa nisalẹ ọkan rè̩, bi igbi tilẹ n lu u lode ara. Ninu afonifoji omije, olododo yoo ri ọwọ ifẹ Ọlọrun ti o n fa a lọ pẹlẹpẹlẹ, si iṣẹgun ati è̩kun ayọ. Agbara rè̩ n bẹ ninu Ọlọrun, nitori naa oun jẹ ọkan ninu awọn ẹni alaafia ati ẹni ibukun. Iyin Ọlọrun yoo wà lẹnu rè̩ bi igbi wahala tilẹ yi i kaakiri.

Iriri ti o logo ni lati maa lọ lati “ipa de ipa.” A n ṣí ododo Ọlọrun paya fun wa lati “igbagbọ de igbagbọ.” Awọn iriri meji wọnyi lọ lọwọ-kọwọ, nitori pe bi a ba fẹ lọ lati “ipa de ipa” a ni lati lọ lati “igbagbọ de igbagbọ.”

Ẹ jẹ ki a fi ọmọ-ọwọ ninu Kristi ti o ba idojukọ rè̩ ekinni lẹhin ti o di ọmọ Ọlọrun pade ṣe apẹẹrẹ. Idojukọ yi jẹ idanwo igbagbọ rè̩. Nigba ti ọmọ Ọlọrun ba fara mọ Ọlọrun gidigidi ninu idanwo, oun yoo ri i pe a o yé̩ igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun si, yoo si ni iṣẹgun. Iriri yi yoo tubọ fun un lagbara, nitori pe nipa lilo igbagbọ ti o ni ninu Ọlọrun, Ọlọrun yoo tubọ sọ agbara rè̩ di ọtun. Lai pẹ jọjọ ọmọ Ọlọrun yi yoo tun ba iṣoro miran pade, boya lọna ti o yatọ si ti iṣaaju. Ẹwẹ, oun yoo gbe ara le Ọlọrun, pẹlu ifẹ ati igbagbọ ọtun, nitori pe o mọ pe nigba ti oun ṣe bẹẹ ni akọkọ, Ọlọrun dide fun iranwọ oun. Ẹwẹ, Ọlọrun yoo tun yẹ igbagbọ rè̩ si, yoo si fun un ni agbara si i.

Idanwo ti o tobi beere igbagbọ ti ko kere, eyi yi yoo si mu ki Ọlọrun fun un ni agbara ti o pọju ti atẹhinwa lọ. Oluwarẹ ti lọ lati “igbagbọ de igbagbọ” ati lati “ipa de ipa.”

Bi o ti ri niyi ni gbogbo igbesi-aye Onigbagbọ. Idanwo kọọkan a maa fun ọmọ Ọlọrun lagbara si i, yoo si ni okun lati doju kọ iṣoro ti n bọ wá; nigba ti o ba si wo Ọlọrun fun iranwọ, nigba ti o n bẹ ninu ina ileru sibẹ, agbara yoo de, igbẹkẹle ninu Ọlọrun yoo tubọ fi ẹsẹ mulẹ. Igbagbọ ti o ti wà lọkan rè̩ tẹlẹ ri ti pọ si i o si ti lagbara si i nipa iṣoro ti o doju kọ ti o si bori nipa ifẹ ati aanu Ọlọrun ti a fi han fun un.

Olododo a maa wo ọjọ ọla ọla pẹlu ifọkanbalẹ, oju igbagbọ ninu Ọlọrun ni o fi n wo awọn iṣoro ti o mọ pe yoo de ba oun lati dan igbagbọ oun wo. Ninu eyi, o “nrin nipa igbagbọ.” Adura ati igbagbọ rè̩ ni pe, “On mọ ọna ti emi ntọ, nigbati o ba dan mi wo, emi o jade bi wura.” “Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o maa gbẹkẹle e.” Nihin yi pẹlu, o n rin “nipa igbagbọ rè̩.” Nigba ti o ba bojuwo ẹhin wo awọn iṣẹgun ati aṣeyọri ti o ti ṣe kọja, oun ki yoo fọwọ sọya pe oun ni o ṣe eyikeyi ninu rè̩, ṣugbọn yoo sọ ninu ara rè̩ pe “Kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, ẽhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ bi ẹnipe iwọ ko gbà a?” (I Kọrinti 4:7). O mọ Ẹni ti ogo i ṣe ti Rè̩, o si mọ bi o ti ṣe pe lati ọdọ Rè̩ ni oun gbe ri iṣẹgun ati iranwọ aṣeyọri gbà.

Mimọ Ifẹ Ọlọrun nipa Lilo Igbagbọ

Ọpọlọpọ ọna si ibukun ati iriri Onigbagbọ ni n bẹ ti a ko i ti mọ. Ijinlẹ n bẹ ti a ko ti i de, oke giga n bẹ ti a ko ti i gun gẹgẹ bi ẹni kọọkan. A ni lati “ja gidigidi fun igbagbọ ti a ti fi lé awọn eniyan mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” (Juda 3). Ẹni kan le ti de giga kan nigba ti o ṣe pe ẹlomiran yoo ti gun oke de giga miran. S̩ugbọn gbogbo wa ni o ni lati maa tẹ siwaju ninu Ọlọrun bi a ba fẹ “jẹ pipe ati ailabuku ki o má ku ohun kan fun ẹnikẹni” (Jakọbu 1:4). Ohun ti o ba ni ninujẹ ni pe ọpọlọpọ n bẹ ti ko i ti bẹrẹsi dan iṣeun ati ifẹ Ọlọrun wò ki wọn si mọ bi O ti fẹran wa to, ninu ohunkohun ti a jẹ tabi ti a n ṣe fun Un.

Ohun ti o leke lọkan Onigbagbọ ni lati wà ninu pipe ifẹ Ọlọrun. Lati wà ni ọgangan ifẹ Ọlọrun ni ifẹ ọkan ẹni iwabi-Ọlọrun. Bawo ni o ṣe le mọ ifẹ pipe Ọlọrun ki o si le rin ninu rè̩ lẹhin ti o ti mọ ọn? Idahun si ibeere yi n bẹ ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun kukuru yi: “Olododo yio wà nipa igbagbọ rè̩.”

Lọna kinni, a ni lati mọ pe, Ọlọrun ti o mọ bi ologoṣẹ ba ṣubu silẹ, ti o mọ iye irun ori wa, ti o si mọ gbogbo aini wa, ni ifẹ atọkanwa si wa lọpọlọpọ. A ni lati mọ pe O fẹ wa. A ni lati mọ pe Oun n ṣaniyan fun wa, nipa ohunkohun ti o wu ki o de ba wa ni igbesi-aye wa. Bi a ba gbagbọ pe eyi ri bẹẹ, a o le tọ Ọ wa pẹlu igboya, fun iranwọ, itọni, agbara tabi fun ohunkohun ti a ba n fẹ. O ti ṣeleri wi pe Oun yoo dahun gbogbo adura, bi a ba beere gẹgẹ bi ifẹ Rè̩. Nihinyi ni a gbe le mọ ifẹ Ọlọrun nigba naa. Bi a ba ni igbagbọ ninu Ọlọrun to bẹẹ ti a fi rọ mọ ileri Rè̩ pẹlu igboya, ti a si fi tọkantọkan ṣe ohun ti O palaṣẹ fun wa lati ṣe, o yẹ ki o da wa loju pe a o mu ifẹ Rè̩ fun wa ṣẹ.

Bi a ba n woye pe Ọlọrun pe wa lati ṣiṣẹ kan, a le mọ bi eyi ba ri bẹẹ ni tootọ, bi O ba ṣi ọna ti iṣẹ naa yoo gba ṣe silẹ. Awọn eniyan Ọlọrun lọkunrin ati lobinrin ti igba nì a maa dide pẹlu igbagbọ nigba pupọ, ni igbẹkẹle pe Ọlọrun yoo mu wọn la a ja, yoo si pese fun gbogbo aini wọn. Bi Ọlọrun ba fẹ ki a sọrọ, Oun ti ṣeleri lati fun wa ni ọgbọn ti a o lo. Bi O ba fẹ ki a lọ, Oun yoo pese ohun ti a o mu lọ. Bi O ba fẹ ki a fara da, Oun yoo fun wa ni oore-ọfẹ lati ṣe bẹẹ. Igbagbọ wa ni yi! Igbẹkẹle wa ni yi! Eyi da wa loju! A n rin nipa igbagbọ. Bi a ko ba le ṣe eyi, a ko ni ohun ti a le rọ mọ.

Bawo ni aanu ati ifẹ Ọlọrun ti pọ to! Bawo ni eto Rè̩ fun wa ti dara to! Bawo ni eto naa ti rọrun to, bawo ni o si ti lodi si ẹmi aye isinsinyi to! Bi o tilẹ jẹ pe o tayọ imọ wa, sibẹ ọwọ wa le tẹ ẹ. Igbesi-aye igbẹkẹle ninu Ọlọrun bi ọmọ kekere ni – igbesi-aye igbagbọ. Dandan-gbọn ni fun awọn ti n jẹ orukọ mọ Kristi, nitori pe “olododo yio wà nipa igbagbọ rè̩.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Wo ibi mẹrin ti a gbe kọ akọsilẹ “olododo yio ye nipa igbagbọ” ninu Bibeli. Ka ẹsẹ ti o ṣaaju ati eyi ti o tẹle orọ wọnyi.
  2. Kin ni itumọ lilọ “lati ipa de ipa”?
  3. Lọna wo ni lilọ “lati inu igbagbọ de igbagbọ” ati lilọ “lati ipa de ipa” fi lọ bakan naa?
  4. Kin ni ohun ti Onipsalmu sọ nipa isin ninu Ile Ọlọrun nigba ti a ba fi we igbesi-aye awọn ẹlẹṣẹ?
  5. Kọ Orin Dafidi 84:11 sori.
  6. Lọna wo ni Luku 2:36-38 fi jẹ imuṣẹ Orin Dafidi 84?
  7. Awọn eniyan meji pataki wo ninu Ijọ ni o ri igbala nipasẹ awọn ọrọ ti a yàn fun ori ẹkọ yi?
  8. Sọ itumọ igbagbọ gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti sọ ọ fun ni.
  9. S̩e alaye eredi rè̩ ti igbagbọ fi ṣe danindanin ki o si fi Iwe Mimọ gbe idahun rẹ lẹsẹ.
  10. Bawo ni a ṣe le mọ ifẹ Ọlọrun nipa igbesi-aye igbagbọ?
1