Lesson 301 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikẹni ti o ba sá pe orukọ OLUWA, li a o gbala” (Romu 10:13).Notes
Damasku
Ninu ẹkọ yi a ka nipa ẹgbẹ kan ti wọn n rin irin-ajo ni ilẹ Siria. Damasku ni wọn n lọ, eyi ti a gba pe o jẹ ọkan ninu awọn ilu ti o ti wà ni ọjọ pipẹ ti o si ṣe pataki ju lọ ni ilẹ Siria. A darukọ ilu yi ninu Gẹnẹsisi, Iwe Kinni ninu Bibeli (Gẹnẹsisi 14:15). O wà ni iwọn ọgọfa (120) mile si iha ariwa Jerusalẹmu. A sọ fun wa pe Damasku jẹ ilu ti o lẹwa, pẹlu Abana, odo ti omi rè̩ mọ gaara ti o si n dan ti o la ilu yi já. Siẹ ninu awọn ọmọ-ẹhin Jesu n gbe ninu ilu yi. Awọn ẹgbẹ arinrin-ajo yi n ba ọna wọn lọ si Damasku ilu daradara yi.
Saulu
Tani wà laarin awọn ẹgbẹ yi? Ọkunrin kan ti a n pe ni Saulu ni. A gbọ nipa rè̩ nigba ti a n kọ ẹkọ nipa bi a ti ṣe sọ Stefanu ni okuta pa, ẹni ti i ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin Jesu (Ẹkọ 289). Saulu duro nitosi, o si n wo gẹgẹ bi awọn ẹlẹri-eke ti n sọ Stefanu ni okuta (Iṣe Awọn Apọsteli 6:3; 7:58). Lai si aniani Saulu ri oju Stefanu ti o n dan, o si gbọ adura ti Stefanu gbà fun awọn ti n sọ ọ ni okuta pa (Iṣe Awọn Apọsteli 6:15; 7:60).
Saulu jẹ ọdọmọkunrin ti a kọ ni ẹkọ daradara, o si kọ ẹkọ Ofin lẹsẹ Gamalieli, ọkan ninu awọn olukọ nla laarin awọn Ju. Ni ọna ti rè̩, Saulu jẹ olufọkansin ati “onitara fun Ọlọrun” (Iṣe Awọn Apọsteli 22:3). Farisi ni i ṣe, o si gbe igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi ẹya isin awọn Ju ti o le ju lọ (Iṣe Awọn Apọsteli 26:5). Awọn Farisi fi dandan le ọran pipa atọwọdọwọ eto isin wọn mọ, ṣugbọn wọn gboju fo idajọ, aanu, igbagbọ ati ifẹ Ọlọrun (Matteu 23:23; Luku 11:42). Wọn kun fun igberaga ati ododo ti ara wọn. Jesu wi nipa awọn Farisi pe, “Gbogbo iṣẹ wọn ni nwọn nṣe nitori ki awọn enia ki o ba le ri wọn” (Matteu 23:5). Ninu ẹsẹ meje ọtọtọ ninu Matteu ori kẹtalelogun, Jesu wi pe awọn Farisi jẹ “agabagebe.”
Lati inu igbesi-aye Saulu a kọ ẹkọ yi pe awọn eniyan le jẹ onitara ninu ohun ti wọn gbagbọ ti wọn si n ṣe, sibẹsibẹ ki wọn si jẹ alaigbọran si Jesu. Ki a to le wu OLUWA, a ni lati gba Bibeli gbọ, ki a si gbọran si aṣẹ Rè̩.
Oninunibini
Saulu jẹ gẹgẹ bi ọkan ninu awọn Ju iyoku ti ko gba pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi i ṣe. Johannu Apọsteli sọ nipa Jesu pe: “O tọ awọn tirè̩ wá, awọn ará tirè̩ ko si gba a. S̩ugbọn iye awọn ti o gba a awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gba orukọ rè̩ gbọ” (Johannu 1:11, 12).
Saulu ro pe Jesu ko ni ẹtọ lati pe ara Rè̩ ni Ọmọ Ọlọrun ati Messia. Ki i ṣe pe Saulu ṣiyemeji nipa Jesu nikan ṣugbọn o korira Rè̩ pẹlu. Saulu wi pe, “Emi tilẹ ro ninu ara mi nitõtọ pe, o yẹ ki emi ki o ṣe ọpọlọpọ ohun odi si orukọ Jesu ti Nasarẹti” (Iṣe Awọn Apọsteli 26:9). Eyiyi ni ọdọmọkunrin naa Saulu, ti o n rin irin-ajo lọ si Damasku.
Iwe Aṣẹ
Kin ni ṣe ti Saulu n lọ si Damasku? O n lọ lati ṣe inunibini si awọn ọmọ-ẹhin Jesu. Saulu korira Kristi ati awọn ọmọ-ẹhin Rè̩. Saulu mu ki a fi ọpọlọpọ ninu awon ọmọ-ẹhin Jesu sinu tubu ki a si pa wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 26:10). Saulu “ndà ijọ enia Ọlọrun ru” nipa mimu ki a fi iya jẹ wọn ati nipa mimu ki a ṣe inunibini si wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 8:3). Saulu ro pe oun n ṣe ohun ti o tọ fun Ọlọrun. Ko mọ pe Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun, ati pe Ọlọrun ran Jesu wa si aye yi fun wa.
Saulu sa n ṣe inunibini si awọn ọmọ-ẹhin sibẹ nipa didẹruba wọn ati pipa wọn, paapaa lẹhin ti o ti fi oju rè̩ ri i nigba ti a n sọ Stefanu ni okuta, nigba ti Stefanu ri iran ologo ti Jesu, ti o si wi pe “OLUWA má ka ẹṣẹ yi si wọn li ọrùn” (Iṣe Awọn Apọsteli 7:60). Saulu ti lọ si ọdọ awọn olori alufa fun aṣẹ lati ṣe inunibini si awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti o wà ni Damasku (Iṣe Awọn Apọsteli 22:5). Ninu iwe rè̩ ni aṣẹ wà fun un lati mu ẹnikẹni ninu awọn ọmọ-ẹhin Jesu – i baa ṣe ọkunrin tabi obinrin. Saulu ti pete lati dè wọn bi arufin ki o si mu wọn wa si Jerusalẹmu.
Imọlẹ kan ati Ohùn kan
Gẹgẹ bi Saulu ati awọn ẹgbẹ rè̩ iyoku ti sunmọ Damasku, ohun kan ṣẹlẹ. Lojiji imọlẹ nla kan tàn lati Ọrun wá, “o ju riran ôrun lọ.” Saulu ṣubu lulè̩ o si gbọ ti a pe orukọ rè̩. Ohùn kan wi pe, “Saulu, Saulu ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?” Nigba ti Saulu beere ẹni ti n sọrọ, OLUWA wi pe, “Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapa si è̩gún.”
Nibẹ, niwaju Oluwa, Saulu yoo ti mọ pe ohun ti oun ṣe si awọn eniyan Oluwa, Oluwa gan an ni oun ṣe e si. Nigba ti Saulu n ṣe inunibini si awọn ọmọ-ẹhin, Jesu gan an ni o n ṣe inunibini si. Saulu yoo ti wá rii pe “li aimọ ninu aigbagbọ” ni oun ti jẹ ọta si Oluwa (I Timoteu 1:13).
Lodi si Jesu
Lode oni, iwa ti awọn eniyan n hu si awọn eniyan Ọlọrun ni iru iwa gan an ti wọn n hu si Ọlọrun. Nigba ti ẹni kan ba ṣe ohun rere kan si awọn eniyan Oluwa, tabi o sọ ọrọ inu rere kan si wọn, Oluwa gan an ni o ṣe e si. Bi ẹni kan ba fi ikanra sọrọ lodi si awọn eniyan Oluwa tabi ti o huwa aitọ si wọn, a ka a si pe o sọrọ ati pe o ṣe lodi si Oluwa tikara Rè̩. Jesu kọ wa nipa igba ti a o ṣe ipinya laarin awọn olododo ati awọn alaiṣododo. Awọn olododo yoo gba ere fun ohun ti wọn ti ṣe -- ṣiṣe iranlowọ fun ẹlomiran, biba awon eniyan kẹdun, ṣiṣe ibẹwo awọn alaisan, ati nini ẹmi ikaanu fun awọn ẹlomiran. Wọn o gbọ awọn ọrọ wọnyi: “Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ, ẹnyin ti ṣe e fun mi” (Matteu 25:40). A o jẹ awọn alaiṣododo ni iya fun iṣe wọn – iwa imọ-tara-ẹni-nikan, ainaani awọn alaini, fifa owọ aanu sẹhin, ati aini inu rere. Yoo jẹ iyalẹnu fun wọn lati mọ pe wọn ti hu irú iwa bẹẹ si Jesu. Wọn o gbọ awọn ọrọ wọnyi: “Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ko ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin ko ṣe e fun mi” (Matteu 25:45).
Aṣẹ
Lai si aniani, ẹri ọkan Saulu yoo ti maa gun un ninu ni iye igba. Ni akoko yi o gba pe oun n ṣe ohun ti o lodi. Nigba ti a fi iṣipaya Jesu han fun un, Saulu rẹ ara rè̩ silẹ. O ya a lẹnu, o si n wariri, ṣugbọn o jọwọ ara rè̩ fun Jesu, bẹẹ ni o si ṣe tan lati ṣe gẹgẹ bi Jesu ba ti palaṣẹ fun un. Saulu wi pe “Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe?” Oluwa fun un ni itọsọna ti o daju, gẹgẹ bi O ti maa n dá awọn ti o ba beere lọwọ Rè̩ lohun lode oni. A sọ fun Saulu pe ki o lọ si Damasku ki o si lọ duro de itọni ti yoo tun tẹle e.
Awọn ti o wà pẹlu rè̩ ko le sọrọ nigba ti wọn gbọ Ohùn naa ti wọn ko si ri ẹni kan. O ṣe e ṣe fun awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rè̩ lati gbọ Ohùn naa ṣugbọn ki i ṣe ọrọ wọnnì ti a sọ. Ọrọ wọnnì jẹ iṣẹ si Saulu lati ọdọ Jesu.
Nigba ti Saulu dide lati gbọran si aṣẹ Jesu, ko le riran “nitori itanṣan imọlẹ na” (Iṣe Awọn Apọsteli 22:11). Saulu wọ ilu Damasku ni ọna ti o yatọ si eyi ti o ro tẹlẹ. Dipo ti i ba fi lọ ni igboya lati lẹpa awọn ọmọ-ẹhin, o di ọranyan pe ki a ṣamọna Saulu nipa fifa a lọwọ. Fun ọjọ mẹta ni o wà ni airiran. Ko jẹun bẹẹ ni ko si mu. O gbadura lai si aniani lọna ti o yatọ si eyi ti o ti n gba gẹgẹ bi Farisi.
Anania
Ni Damasku ni ọmọ-ẹhin kan wa ti a n pe ni Anania. Oluwa ba a sọrọ nipa Saulu. Anania ti gbọ bi Saulu ti n ṣe inunibini si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa. O sọ fun Oluwa pe Saulu n bọwa si Damasku lati tun ṣe bẹẹ gẹgẹ. Oluwa mu ibẹru Anania kuro O si wi fun un pe ki o lọ ran Saulu lọwọ. Anania gbọran. O lọ si ita kan ti a n pe ni Ọganran, si ile Juda. Anania ri Saulu nibẹ gẹgẹ bi Oluwa ti wi.
Saulu Arakunrin
Oluwa ti fi han Anania pe “Ohun elo āyo,” ni Saulu i ṣe, pe Saulu yoo waasu Ihinrere, yoo si ṣe ẹlẹri ti Kristi fun ọpọlọpọ eniyan. Gẹgẹ bi a ti palaṣẹ fun un, Anania gbe ọwọ le Saulu fun iwosan, gẹgẹ bi apẹẹrẹ ti jesu fi lelẹ nigba ti O wà ni aye (Marku 6:5; 7:32; Luku 4:40), ati gẹgẹ bi Jesu ti wi pe awọn ti o gba Oun gbọ yoo ṣe. “Àmi wọnyi ni yio si mā ba awọn ti o gbagbọ lọ ... nwọn o gbé ọwọ le awọn olokùnrun ara wọn o da” (Marku 16;17, 18). (Wo Ẹkọ 252). Saulu si riran. “Nkan si bọ kuro loju rè̩ bi ipé̩pé̩.”
Anania wi pe, “Arakunrin Saulu” – nitori pe Ọlọrun ti yi ọkan Saulu pada. Saulu ko tun dojuja kọ Jesu mọ. Saulu ke pe orukọ Oluwa; o gba ohun Jesu gbọ; o gbadura; iṣe rè̩ fi han pe a ti gba ọkan rè̩ la. Eyiyi jẹ apẹẹrẹ nlá nlà nipa aanu Oluwa – a dariji Saulu. Ko tun dẹru ba awọn ọmọ-ẹhin mọ -- oun paapaa di ọkan ninu wọn. Ẹni ti o ti n ṣe inunibini si wọn si tun pada di ẹni ti wọn fẹran. A n pe e ni arakunrin, gẹgẹ bi a ti maa n pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu lode oni ni arakunrin ati arabinrin
Ẹri Kan
Saulu ba awọn ọmọ-ẹhin duro fun igba diẹ. Ninu sinagọgu o waasu pe Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun. O jẹ iyalẹnu fun awọn ti o n gbọ ọrọ rè̩ lati ri iyipada ti o ṣẹlẹ ninu aye Saulu. Nigba ti a ba gba ọkan awọn eniyan là lode oni, wọn a yipada bakan naa. Wọn a fẹran Jesu ati awọn eniyan Rè̩. Wọn a fẹ wa pẹlu awọn eniyan Oluwa. Wọn a fẹ lati lọ si ile Ọlọrun. Ẹni ti a ba gba ọkan rè̩ là a fẹ lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Jesu, gẹgẹ bi Saulu ti bẹrẹ si “njẹri fun ati ewe ati agba” (Iṣe Awọn Apọsteli 26;22). iwọ ha ti ri igbala bi? Njẹ o mọ pe o le gbadura ki o si beere pe ki Jesu gba ọ là? Ninu Bibeli a ka pe, “Nitori ẹnikẹni ti o ba sa pe orukọ Oluwa, li a o gbala” (Romu 10:13).
Ọdun mẹta lẹhin eyi ni Saulu to pada lọ si Jerusalẹmu (Galatia 1:18). Awọn kan laarin awọn Ju ko fẹran Saulu ati iwaasu rè̩. Wọn pinnu lati pa a, ṣugbọn o bọ lọwọ wọn nipa iranlọwọ awọn ọmọ-ẹhin. Ni alẹ ọjọ kan awọn ọmọ-ẹhin sọ Saulu kalẹ si odikeji odi ilu ninu apè̩rẹ. Nigba naa ni o lọ si Jerusalẹmu. Diẹ laarin awọn ọmọ-ẹhin bẹru rè̩ nitori wọn ranti pe o ti n wa ọna lati pa wọn tẹlẹ, ṣugbọn Barnaba ba a ṣọrẹ o si sọ fun awon ọmọ-ẹhin nipa iyipada ti o ni. Nisinsinyi o wa n gbadun idapọ mimọ pẹlu wọn. Saulu ko tun ba awọn ọrẹ rè̩ atijọ dapọ mọ laarin awọn olori alufa ati awọn Farisi – o fẹ lati wà laarin awọn eniyan Ọlọrun. Nibikibi ti o ba lọ, Saulu a maa waasu nipa Jesu. Oluwa si wà pẹlu rè̩, Saulu si di oniwaasu nla ati ajihinrere.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ilu wo ni Saulu n rin irin-ajo lọ?
2 Kin ni ṣe ti Saulu n lọ sibẹ?
3 Kin ni ṣe ti Saulu fi rò pe oun n ṣiṣẹ fun Ọlorun?
4 Tani fara han Saulu bi o ti n rin irin-ajo lọ?
5 Bawo ni imọlẹ ti o ti Ọrun wa ti mọlẹ to?
6 Bawo ni Saulu ti ṣe tun pada riran?
7 Bawo ni a ti ṣe mọ pe Saulu ri igbala?
8 Lẹhin iyipada rè̩, kin ni Saulu ṣe fun Jesu?
9 Orukọ wo ni a yi orukọ Saulu pada si?
10 Bawo ni awọn ọmọ-ẹhin ti ṣe ran Saulu lọwọ lati bọ lọwọ awọn Ju ti o fẹ lati pa a?