Lesson 302 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun kì iṣe ojusaju enia” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34).Notes
Awọn Apẹja Mẹrin
Afẹfẹ itura n fẹ lé̩lẹ; ẹyẹ ṣaṣangele n rababa loke; itanṣan oorun ti n ran ni ilẹ Judea ntàn si wa lara bi a ti n rin lọ, ninu iwoye wa, leti bebe Okun Galili. Bi a ti gbe oju soke wo eti okun ni a ri Ẹni kan ti n bọ wa sọdọ Peteru ati Anderu bi wọn ti n pẹja. “Ẹ mā tọ mi lẹhin” ni ohun Rè̩ wi, “emi o si sọ nyin di apẹja enia” (Matteu 4:19). Bi ẹni pe awọn, ẹja, ati iṣẹ ko tilẹ jẹ nkan, Peteru ati Anderu fi wọn silẹ wọn si n tọ Alejo naa lẹhin, ẹni ti a mọ gẹgẹ bi Jesu. Bi a ti n tẹ siwaju lọ leti okun bẹẹ ni a tun ri awọn arakunrin meji miran, Jakọbu ati Johannu, wọn fi iṣẹ wọn silẹ wọn si n tọ Oluwa lẹhin.
Nisinsinyi lẹhin ti a ti ṣe alabapade awọn apẹja mẹrẹẹrin wọnyi, ẹ jẹ ki a ya Peteru sọtọ ki a si ṣe ayẹwo ọdun melo kan ninu igbesi-aye rè̩. Ẹ jẹ ki a ba a sọrọ, ki a tẹti silẹ gbọ esi ti yoo fun wa – nigba miran gẹgẹ bi ọlọgbọn ati nigba miran ẹwẹ gẹgẹ bi alailọgbọn.
Ọrọ Peteru
Inu rẹ dun gidigidi lati fi ẹja pipa silẹ lati tẹle Jesu, abi bẹẹ kọ, Peteru? Ẹni ti o kun fun ifararubọ ni iwọ i ṣe. Ni ọjọ kan, bi a ti duro ni tosi, a n gbọ bi o ti n sọ fun Jesu pe, “Awa ti fi gbogbo rè̩ silẹ, awa si ntọ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni?” (Matteu 19;27). Iwọ ko mọ pe a maa n tọ Oluwa lẹhin nitori pe a ni ifẹ si I? Iwọ ko ha si mọ pẹlu pe ni “titọ Jesu lẹhin” a ni lati ṣe tan lati kọ ile, arakunrin, arabinrin, baba, iya tabi iyawo tabi ọmo, tabi ilẹ silẹ, nitori ti Jesu? Iye-ainipẹkun n duro de awọn ti o ba tọ Ọ lẹhin lotitọ.
Lẹẹmeji ni a gbọ ti o ṣe ijẹwọ ti o le nipa igbagbo rẹ ninu Jesu, lati ẹnu iwọ tikara rẹ paapaa: “Kristi, Ọmọ Ọlọrun alāye ni iwọ iṣe” (Matteu 16:16). S̩ugbọn nigba kan ẹwẹ esi ti o fun Jesu lẹhin ti O sọ fun ọ pe Oun ni lati jiya, ki Oun si ku, ki Oun si tun jinde ni ọjọ kẹta ya wa lẹnu. Kin ni mu ọ ba Jesu wi: “Ki a ma ri i, Oluwa, kì yio ri bẹ fun ọ” (Matteu 16:22). Jesu ba ọ wi, Peteru. Boya o ko lero pe ọrẹ rẹ Matteu yoo kọ eyi silẹ ninu Iwe nibi ti ẹgbẹẹgbẹrun eniyan yoo ti kà a.
Igbagbọ Rè̩
A ranti ọjọ kan, ni owurọ kutukutu, gẹgẹ bi Jesu ti n rin sun mọ tosi ọkọ rẹ nigba ti igbi n da a laamu (Matteu 14:25). Igbagbọ rẹ ninu Ọga rẹ mu ki o wi pe, “Oluwa bi iwọ bá ni, paṣẹ ki emi tọ ọ wa lori omi.” Nipa igbagbọ o sọkalẹ lati inu ọkọ o si n rin loju omi lati tọ Jesu wa. S̩ugbọn ibẹru yọ wọ inu ọkan rẹ nigba ti o bẹrẹ si wo awọn igbi omi nla – o si bẹrẹ si i rì.
Bakan naa ha kọ pẹlu awa ti igba isinsinyi – nkan le maa lọ deedee fun wa fun igba diẹ, a si dabi ẹni pe geerege ni a n rin lọ loju omi. Lojiji iyiiriwo kan tabi idanwo kan dojukọ wa, a si ṣi oju wa kuro lara Jesu fun igba diẹ, bẹẹ ni a bẹrẹ si i rì. S̩ugbọn gẹgẹ bi Peteru bi a ba le rin sun mọ Ọn a le na owọ wa si I pe, “Oluwa, gba mi,” ọwọ agbara Rè̩ yoo yọ wa, a o si tun pada bẹrẹ si irin loju omi. Igbi ti wa le jẹ awọn idojukọ kekeke lati ọdọ awọn ọrẹ wa ni ile ẹkọ; ṣugbọn, fun ọmọde awọn nkan wọnyi dabi igbi nla loju okun.
Iriri ti o kun fun Ibanujẹ
Peteru, gẹgẹ bi Oluwa ti n gbadura ni oru ọjọ nì pẹlu ibanujẹ ninu Ọgba Gẹtsemane, o bà wa ninu jẹ pe oorun ni iwọ n sun dipo ki o maa ṣọna, fun wakati kan ṣoṣo nì (Matteu 26;40); pẹlupẹlu, gẹrẹ lẹhin eyi, a rii pe o n tọ ọ lẹhin ni okeere (Matteu 26:58). Inu wa bajẹ gẹgẹ bi a ti n gbọ ni è̩rin-mẹta ọtọtọ ti o sẹ Oluwa ati Ọga rẹ. Aanu ṣe wa lati ri irobinujẹ nlá nlà loju rẹ fun kikabamọ ohun ti o ṣe; nigba ti akukọ kọ, o ranti ọrọ Jesu, “Ki akukọ to kọ iwọ o sẹ mi larinmẹta” (Matteu 26:75). Wò o bi o ti ya ojo to! A ri ọ bi o ti sọkun kikoro, awa naa si jade kuro ninu yara a si ba ọ sọkun. Iru eyi nì ki yoo tun ṣẹlẹ mọ, abi bẹẹ kọ Peteru? O ti kọ ẹkọ kikoro naa, abi bẹẹ kọ? Ọga rẹ ko sẹ ọ, Peteru, ṣugbọn O nduro, O ṣetan lati dariji.
Bawo ni a ti ṣe n tọ Jesu lẹhin loni? A ha n tọ Ọ lẹhin ni okeere. Awa naa o ha sẹ Jesu bi ẹni kan ba tọka si wa ti o si wi pe, “Iwọ pẹlu wà pẹlu wọn” (Matteu 26:71-73)? tabi boya, “Ọmọdekunrin yi pẹlu fẹran Jesu”? Jẹ ki a wadi ọkan wa ki a si rii pe a ko tiju lati jẹwọ Jesu ni Oluwa wa.
Peteru Okuta naa
S̩ugbọn wo o! wo o bi inu wa ti dun si ọ to lẹhin eyi, Peteru, nigba ti o wà ni Jerusalẹmu, gẹgẹ bi o ti duro pẹlu igboya ti o si sọ gbangba fun awọn igbimọ ati olori alufa pe, “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti enia lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29). Lẹhin eyi pẹlu, bi o tilẹ jẹ pe a nà ọ fun fifi igboya waasu Kristi, a ri ọ pe o n yọ nitori pe a kà ọ yẹ lati fara da itiju nitori Orukọ Rè̩ (Iṣe Awọn Apọsteli 5:41). A n sọ ninu ọkan wa lọhun pe, “A! a ba le jẹ ni diẹ ninu iru ẹmi bẹẹ!”
O ki i tun ṣe alailera mọ, abi bẹẹ kọ Peteru? O ni lati jẹ pe nitori ti o jẹ ọkan ninu awọn ti o gba ohun Jesu gbọ pe ki wọn duro ni Jerusalẹmu titi a o fi fi agbara wọ wọn lati oke wá ni. O wà ni yara oke nì nigba ti a gbọ iró naa “lati ọrun wa gẹgẹ bi iro ẹfufu lile, o si kun gbogbo ile nibiti wọn gbé joko.” Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o si bà le olukuluku wọn. Gbogbo wọn si kun fun Ẹmi Mimọ, wọn si bẹrẹ si i fi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmi ti fun wọn ni ohun (Iṣe Awọn Apọsteli 2:2-4).
Ẹnu ya wa bi a ti n tẹti silẹ gbọ iwaasu ti o wà ni ọjọ afiyesi naa. A fẹrẹ ma gbagbọ pe iwọ ni, Peteru, nitori pe pẹlu ipa ati agbara ni iwaasu naa n jade. Iwọn ẹgbẹẹdogun eniyan (3,000) ni a ka kun Ijọ ni ọjọ naa nipasẹ iwaasu naa (Iṣe Awọn Apọsteli 2:41). Asọtẹlẹ Jesu si ṣẹ: “Kefa ni a o si mā pe ọ,” itumọ eyiti iṣe “Peteru” (Johannu 1:42).
Agbara lati Wosan
Ẹnu yà wa si iru iṣẹ-iyanu nla ti o ṣẹlẹ. Nipasẹ agbara Ọlọrun, a mu ayarọ kan larada ni ẹnu ọna Tẹmpili (iṣe Awọn Apọsteli 3:6). O ṣọra gidigidi pe ki o ma ba gba ogo naa fun ara rẹ, ṣugbọn o fi gbogbo ogo naa fun Ọlọrun. A ri awọn alaisan ti wọn dubulẹ lori ibusun wọn, wọn si n duro de igba ti iwọ o kọja, Peteru, ki ojiji rẹ ba le bà le wọn ki a si wo wọn san (Iṣe Awọn Apọsteli 5:15). A n jẹri pẹlu, gẹgẹ bi a ti n fi oju inu wo o, bi a ti gbé Enea dide, ẹni ti o ti wà ninu aisan fun ọdun mẹjọ; arabinrin ni Dọrka, ẹni ti o ku, ti a si mu pada sipo laaye! Wo o bi awọn iṣẹ-iyanu wọnyi ti tobi to!
Fun Gbogbo Ẹda
Ohun kan ṣi kù, Peteru, ti o ni lati kọ. Bi o ti wu ki eniyan le ti rin jinna to ninu ọna igbagbọ, yoo sa tun ri ohun kan kọ sibẹ. Ko i ti si ẹni kan ti o ti i de kikun iwọn oore-ọfẹ, imọ ati agbara pẹlu Ọlọrun
Nigba ti o wà ni Joppa, Peteru, lẹhin ti a ti ji Dọrka dide, o ri iriri ajeji kan. Ninu ala Oluwa fi han fun ọ pe Oun ki i ṣe ojusaju eniyan. O fẹran gbogbo eniyan lọkunrin ati lobinrin, Ju ati Keferi bakan naa, O si n fẹ ki a waasu Ihinrere Oluwa fun gbogbo eniyan. Jesu ti sọ fun iwọ ati awọn Apọsteli iyoku pe ki ẹ waasu Ihinrere fun gbogbo ẹda (Marku 16:15). Jesu fi han ọ ninu ala pe o ko gbọdọ pe awọn Keferi ni eewọ tabi alaimọ. Bi o tilẹ jẹ pe awọn Ju jẹ ayanfẹ Ọlọrun, o si jẹ ohun ti o lodi si ofin fun Ju lati ba awọn orilẹ-ede miran kẹgbẹ pọ (Iṣe Awọn Apọsteli 10:28), ko si iyatọ ninu Ọlọrun. O fẹ ki gbogbo eniyan aye yi gbọ nipa Ihinrere ki wọn si là.
Nigba ti o taji, Peteru, ti o si bẹrẹ si i ro o wo ohun ti ala naa ja si, awọn ọkunrin mẹta duro ni ẹnu ọna wọn n beere rẹ. Ẹmi Ọlọrun wi fun ọ pe ki o lọ ba wọn ki o si maa ba wọn lọ, lai ṣiyemeji. Bẹẹ ni o gbagbe ebi ti n pa ọ, o gbọran si Ohun naa, o si lọ si ẹnu ilẹkun, o wi pe, “Emi li ẹniti ẹnyin nwa.” O pe wọn wọle lati wọ sibẹ di ọjọ keji, ni ọjọ keji iwọ ati awọn iyoku si lọ si Kesarea. Nibẹ ni iwọ ni anfaani lati waasu Kristi fun awọn Keferi.
Ẹkọ ti O ti Kọ Wa
Ọpọlọpọ ni ẹkọ ti o le ran ni lọwọ ti o kọ lọdọ Ọga rẹ, o si ti fi wọn le wa lọwọ. A dupẹ lọwọ rẹ lọpọlọpọ, Peteru, fun ẹkọ ti a ti kọ ninu akọsilẹ igbesi-aye rẹ. Nigba ti o dẹṣẹ, o tete ṣe giri lati ronupiwada o si pada sọdọ Oluwa rẹ. A ti ka Episteli rẹ Ikinni ati Ekeji, a si ri imisi ati ibukun gba ninu awọn akọsilẹ rẹ. Awọn igbimọ nì ni Jerusalẹmu, niwaju ẹni ti iwọ sọrọ (Iṣe Awọn Apọsteli 4:8-12) wi pe, bi o tilẹ jẹ pe alailẹkọ ati ope eniyan ni iwọ i ṣe, wọn woye pe o ti ba Jesu gbe. Oun ni Olukọ rẹ Nla, abi bẹẹ kọ, Peteru? Lati ọdọ Rè̩ ni o ti ri ọgbọn rẹ, igboya rẹ, ati agbara lati waasu Kristi.
Iwọ jẹ ọkan ninu awọn Apọsteli mejila, Peteru, a si kọ orukọ rẹ sara ọkan ninu awọn okuta mejila nì ti a fi ṣe ipilẹ Ilu Ọlọrun. A nireti lati ri ọ loke lọhun ninu Ilu nì lọjọ kan.
“A o jumọ sọ ọrọ na nigbõṣe,
‘Gba temi ti rẹ ba de ‘lu mimọ nì,
P’ore-ọfẹ mu wa bori, a si de ‘le wa ọrun;
A o jumọ sọ ọrọ na nigbõṣe,
Pẹlu Mose at’Elijah, Peteru ati Paulu.
A o sọ t’iṣẹgun iṣẹ ore-ọfẹ:
A o ri Olugbala wa, a o ṣe l’Ọba awọn ọba
A o si jumọ ma kọrin ‘yin Rè̩ titi.”
Questions
AWỌN IBEERE1 Sọ diẹ ninu iṣẹ iyanu ti Peteru ṣe.
2 Nigba wo ati lati ibo ni Peteru ti ri agbara gbà lati ṣe nkan wọnyi?
3 Tani fi iṣipaya naa han Peteru?
4 Iṣẹ wo ni Peteru n ṣe ki Jesu to pe e?
5 Sọ nkan kan nipa ikuna Peteru?
6 Bawo ni a ṣe mọ pe a tun mu un pada sinu igbala?
7 Kin ni a ṣe ileri fun awọn ti o fi ohun gbogbo silẹ lati tẹle Jesu?
8 Sọ diẹ ninu awọn iṣoro ti awọn ti o tẹle Jesu n fara dà.