Iṣe Awọn Apọsteli 10:24-48

Lesson 303 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn Keferi yio wá si imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si titàn yiyọ rẹ” (Isaiah 60:3).
Notes

A Pin Ibukun Kan

Awọn ara ile Kọrneliu bẹrẹ si i foju sọna nigba ti o gbọ pe Peteru n bọ wa sọ fun un nipa Jesu, Messia awọn Ọmọ Israẹli, ati nipa agbara ti o bà le awọn ọmọ-ẹhin ni ọjọ Pẹntekọsti. Kọrneliu pe ọpọlọpọ awọn ọrẹ ati ibatan rè̩ pẹlu rè̩ lati wa gbọ ihinrere ti igbala. O n reti lati gbọ itan otitọ, o si n fẹ ki awọn ẹlomiran ṣe alabapin itan iyanu naa pẹlu rè̩. Bi a ba jẹ ki awọn ẹlomiran ba wa pin ibukun wa, ibukun naa yoo di ilọpo meji.

Ọpọlọpọ laarin awọn ọmọ-ogun Romu ti n gbe Jerusalẹmu ni kò fẹran awọn Ju bẹẹ ni wọn kò ni inudidun ninu isin awọn Ju. Were ni o jẹ loju wọn. Wọn kan wà ni Judea gẹgẹ bi ọlọpa fun ijọba Romu ni. S̩ugbọn ṣa, awọn Ju ro pe awọn wà ni abẹ isinru wọn; ṣugbọn bakan naa ni wọn ro pe awọn sàn ju awọn ara Romu lọ nitori pe awọn Ju jẹ ayanfẹ Ọlorun. Awọn Ju ka awọn ara Romu si Keferi, tabi aja paapaa; awọn Ju si ro pe awọn yoo sọ ara awọn di alaimọ bi awọn ba n ba awọn ara Romu kẹgbẹ pọ.

Lọ si Gbogbo Ilẹ

A ti sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Jesu tẹlẹ ki O to lọ si Ọrun pe wọn o waasu Ihinrere ni ilẹ gbogbo, ṣugbọn ko ye wọn pe lati waasu fun awọn ara Romu ati awọn Keferi miran paapaa wa ninu aṣẹ yi. Awọn Ju wà ti wọn fọnka ọpọlọpọ orilẹ-ede wọn si le maa ro pe niwọn bi awọn ba ti waasu fun wọn ni gbogbo orilẹ-ede awọn ti mu Aṣẹ Nla nì ṣẹ pe: “Ẹ lo si gbogbo aiye, ki ẹ si mā wasu Ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15).

Bi o ti wọ inu ile, Peteru ṣe alaye fun Kọrneliu wi pe gẹgẹ bi ofin awọn Ju, Ju kan ko gbọdọ wọ ile ọmọ-ogun Romu; ṣugbọn bi Ọlọrun ba n fẹ ki Peteru ṣe ohun ti o yatọ, o ṣe tan lati gbọran. Bi Ọlọrun ba wi pe, “Lọ wāsu fun ọmọ-ogun Keferi nā,” o ṣe tan lati lọ. Nitori eyi Peteru ti de lati sọ fun Kọrneliu nipa Ihinrere Jesu Kristi.

Iṣẹ Ododo

Kọrneliu ki i ṣe ọmọ-ogun Romu kan lasan. Ko sin ọlọrun awọn ara Romu, ṣugbọn o n sin Ọlọrun otitọ tọkantọkan. Oun ati awọn ara ile rè̩ a maa gbadura pupọ, wọn a si maa gbaawẹ pẹlu. wọn jẹ eniyan mimọ, ti a si ti sọ di mimọ, ti wọn si n rin ninu gbogbo imọlẹ ti wọn ni. Wọn ṣe e ni ohun pataki ni igbesi-aye wọn lati sin Ọlọrun. Wo iru ibukun ti wọn ri gba! Awọn ni wọn kọkọ ri Ẹmi Mimọ gba laarin awọn Keferi. A san ere sisin Ọlọrun ni otitọ fun wọn. Wọn ti ṣe iṣẹ ododo.

Nigba ti Peteru bẹrẹ iwaasu rè̩, o wi pe, “Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun ki iṣe ojusaju enia: ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ede ẹniti o ba bè̩rù rè̩, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rè̩.” Ki i ṣe pe Kọrneliu fi isin Ọlọrun ni ode ara han ṣa lasan, ṣugbọn o fi han ninu igbesi-aye ti o n gbe wi pe o bu ọla fun Ọrọ Ọlọrun.

Gbogbo awọn ti o n ṣiṣẹ ododo ni ẹni itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. A ni lati fi han ninu iṣesi wa pe Onigbagbọ atunbi ni awa i ṣe. Awọn eniyan le wi pe Onigbagbọ ni awọn: ṣugbọn bi wọn ba n dẹṣẹ, Jesu ki yoo gba wọn nigba ti wọn ba duro niwaju Rè̩ ni idajọ. Ki yoo pe wọn ni ti Rè̩.

Àwọ ara wa, iye owo ti a ni, iru ọla ti awọn ọrẹ wa n bu fun wa ko ni nkankan ṣe nipa pe a o gba wa si Ọrun tabi a ki yoo gba wa. A ni lati so eso Ẹmi wọnyi, ti i ṣe ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa tutu ati ikora-ẹni-nijanu. Nigba ti Jesu ba ri eso wọnyi ninu wa, Oun yoo wi pe, “O ṣeun iwọ ọmọ-ọdọ rere, ati olõtọ; bọ sinu ayọ Oluwa rẹ.” A o jẹ ẹni itẹwọgba lọdọ Rè̩. A ko ni ṣẹṣẹ duro de igba ti a ba de Ọrun lati jẹ ẹni itẹwọgba. Taara lati inu aye yi lọ, bi a ba ti gba wa là, Oluwa mọ wa ni ti Rè̩, A si maa tú ibukun jade sori awọn ọmọ Rè̩ ọwọn. Adura wa paapaa jẹ didun inu Rè̩ nigba ti a ba n gbadura lati inu ọkan ti ko si ẹṣẹ.

Ikede Johannu

Peteru ko bẹru lati waasu fun awọn Keferi. O sọ fun wọn nipa Jesu, Ẹni ti Johannu Baptisti ti kede Rè̩. Iwaasu Johannu ni, “Ẹ ronupiwada: nitori ijọba ọrun kù si dẹdẹ.” Nigba ti Jesu si wá si ọdọ rè̩ fun iribọmi, Johannu ti kigbe pe, “Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹṣẹ aiyẹ lọ!” Ẹmi Mimọ ti bà le Jesu ni ọjọ naa lati fi agbara kun Un fun iṣẹ ti O ni i ṣe laarin awọn eniyan nigba ti O wĀ laye. O ti wo alaisan san, O ti fi iriran fun awọn afọju, O ti fi itunu fun awọn ti a kọ silẹ ati awọn ti o rẹwẹsi. Peteru wi pe O “nkiri ṣe ore.”

Gbogbo eniyan ha kọ ni yoo fẹ lati mọ iru Olugbala bẹẹ? Dajudaju awọn Keferi pẹlu yoo ni inudidun lati ni In gẹgẹ bi Oluwa wọn. Jesu ti wi pe Oun le ṣe awọn iṣẹ-iyanu nla nì nitori pe Ọlọrun wà pẹlu Rè̩.

Agbara lati Ọrun

Jesu ni apẹẹrẹ fun wa, O si fẹ ki a ràn awọn ẹlomiran lọwọ ni orukọ Rè̩. A le ṣe e bi a ba ni agbara Ẹmi Mimọ ninu aye wa. Jesu wi pe,: “Ẹnyin o gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Gẹgẹ bi Jesu si ti maa n wa ni idapọ pẹlu Baba nigba gbogbo, bẹẹ gẹgẹ ni a ni lati maa gbadura pupọ ki a si maa ba Ọlọrun sọrọ timọ-timọ bi a ba nireti lati ṣe iṣẹ ti O fẹ ki a ṣe.

Agbara wa lati ṣiṣẹ fun Jesu a maa ti Ọrun wá. A ko le ṣe ohunkohun ninu agbara awa tikara wa. Jesu wi nipa ti ara Rè̩ pe, “Ọmọ ko le ṣe ohunkohun fun ara rè̩, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, wọnyi ni Ọmọ si nṣe bḝ gẹgẹ” (Johannu 5:19). Bi Jesu ati Baba ba jẹ ọkan ṣoṣo to bẹẹ ti Jesu kò le ṣiṣẹ fun ara Rè̩, wo bi o ti ṣe pataki to fun wa lati ri agbara gbà ju bẹẹ lọ lati ọdọ Ọlọrun ki a ba le ṣiṣẹ fun Un.

“O mọ pe mo nṣaniyan, k’alarè̩ le wale

O si paṣẹ pe ki n lọ sọrọ `fẹ na fun Oun,

Ki nsọ ti `fẹ iyanu Rè̩ ati pe O ti kú

Bẹ l’emi pẹlu Oluwa, jumọ ṣiṣẹ.”

Kristi gẹgẹ bi Ọlọrun

Kóko pataki ti o wà ninu iwaasu awọn ọmọ-ẹhin ni otitọ yi pe Jesu jẹ Ọmọ mimọ ti Ọlọrun. Nibikibi ti wọn lọ, wọn n sọ nipa iku kikoro ti Jesu ku lati ọwọ awọn Ju, ati pe O ti jinde ni ọjọ kẹta. Ko si woli miran tabi aṣaaju ẹsin miran ti o tobi ti o tii jinde bẹẹ ninu oku. Lai si ojiji iyemeji kankan, Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun. Ki i si i ṣe pe Jesu jinde gẹgẹ bi ẹmi nikan, ṣugbọn ninu ara pẹlu. O ba wọn jẹun, wọn si di ara Rè̩ mu. Ni tootọ O ti jinde ninu ara. Dajudaju Ọmọ Ọlọrun ni eyi!

Onidajọ Nla

Jesu rin laarin awọn eniyan gẹgẹ bi eniyan, O si kọ ni pe Oun ko le ṣe ohunkohun lẹhin Baba. Sibẹ naa O paṣe fun awọn ọmọ-ẹhin lati waasu pe lọjọ kan, Oun Jesu yoo ṣe idajọ aye. Baba n bọ wa fi gbogbo idajọ le E lọwọ. Jesu yi, Ẹni ti o ti n rin ni irẹlẹ lori ilẹ aye, O n pada bọ wa ṣe Onidajọ gbogbo aye – ati Ọrun pẹlu. Wo o bi o ti ṣe pataki to fun wa lati di ọrẹ Jesu nisinsinyi nigba ti O ṣi n fi aanu pe wa. Nigba ti O ba de gẹgẹ bi Onidajọ yoo ti pẹ ju lati yipada si I.

Nigba idajọ, Jesu ni yoo ṣe ipinya laarin awọn eniyan mimọ ati awọn ẹlẹṣẹ. Yoo mu gbogbo awọn oku pada bọ si aaye lati ṣe idajọ wọn; yoo si san an fun wọn gẹgẹ bi iṣẹ wọn (Ifihan 20:12, 13). Jesu yi kan naa ti awọn Ju kàn mọ agbelebu yoo tun pada wa gẹgẹ bi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa. Nigba naa gbogbo awon ti o ti kọ Jesu yoo maa sọkun wọn o si maa ṣọfọ ninu ẹṣẹ wọn, wọn o si gbọ awọn ọrọ ti o ba ni lẹru wọnnì: “Emi kò mọ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ ẹṣẹ” (Matteu 7:23).

Kọrneliu Yọ

Wo o bi inu Kọrneliu ati awọn ọrẹ rẹ yoo ti dun to lati gba iwaasu Peteru gbọ! Wo o bi inu wọn yoo ti dun to pe awọn pẹlu le di ọrẹ Jesu ki wọn si maa ba A gbe titi lae! Wọn o wà ninu Ijọba Kristi nigba ti O ba wa gbe Ijọba Rè̩ kalẹ laye, wọn o si ṣe alabapin ninu gbogbo ibukun ti Jesu ti lọ pese silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ.

O ti jẹ ibanujẹ fun Peteru to pe ọpọlọpọ awọn Ju ẹlẹsin ni o ti sọ ibukun wọnyi nu nitori pe wọn ko gba Jesu gbọ; ṣugbọn nisinsinyi o jẹ iṣiri fun un nigba ti Kọrneliu ati ẹgbẹ ọmọ-ogun rè̩ gbagbọ. Wọn ti pese ọkan wọn silẹ fun wakati yi ti wọn o gbọ otitọ nla nì eyi ti awọn woli ti sọ, eyi ti awọn angẹli paapaa n fẹ lati mọ sii – itujade Ẹmi Mimọ. Bi wọn ti n feti si gbogbo eyi ti Peteru n sọ, wọn gbagbọ pẹlu gbogbo ọkan wọn, Ẹmi Mimọ si bà le wọn.

O to ọdun meje tabi mẹjọ lẹhin ọjọ Pẹntekọsti, nigba ti ọgọfa ni iyara oke ti ri Ẹmi Mimọ gba. Lẹhin eyi awọn miran ni Samaria pẹlu ti ri iriri yi gba. Nisinsinyi a wa n tu U jade sara awọn Keferi, lati fi otitọ asọtẹlẹ Joẹli han, “Yio si ṣe, nikẹhin emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo” (Joẹli 2:28). Ẹnu ya awọn Ju ti wọn wa pẹlu Peteru. O ha ṣe e ṣe pe ki awọn Keferi pẹlu ri Ẹmi Mimọ gba? Wọn ha dara to bẹẹ? Ẹmi Mimọ yoo ha tun bà le awọn ẹlomiran ju awọn ayanfẹ diẹ lọ?

Ayọ wa ti pọ to pe ileri yi wa fun “enia gbogbo”! Ẹnikẹni ti o ba n ṣiṣẹ ododo – ti a ti sọ di mimọ patapata – ni o yẹ lati ri Ẹmi Mimọ gbà. “Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa o pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39).

Awọn Ju wọnyi kò le ṣiyemeji pe awọn ara Romu naa ri Ẹmi Mimọ gba, nitori pe wọn gbọ bi wọn ti n fi ede miran sọrọ (ni ede miran ti o yatọ si eyi ti wọn ti mọ ri), gẹgẹ bi awọn ọgọfa nì ti ṣe ni Ọjọ Pẹntikọsti.

Baptismu ti Iribọmi

Nisinsinyi a ti gba ọkan awọn ara Romu wọnyi là, a ti sọ wọn di mimọ, a si ti fi Ẹmi Mimọ kún wọn, ṣugbọn a ko i ti baptisi wọn ninu omi. A ti dari ẹṣẹ wọn ji wọn; a si ti sọ wọn di mimọ; wọn si ti ri ifi-ororo yàn lati ọdọ Ọlọrun gba. Kin ni ṣe ti o ṣe dandan pe ki a tun baptisi wọn ninu omi? Iribọmi jẹ ẹri kan nipasẹ eyi ti aye yoo fi mọ pe a ti di ọmọ-ẹhin Kristi. Olukuluku Onigbagbọ atunbi ni lati ṣe baptismu nipa iribọmi lẹsẹkẹsẹ ti o ba ti ni anfaani lati ṣe e. Ko tọ pe ki o ṣẹṣẹ duro de igba ti o ba ni isọdi-mimọ tabi ki o ri Ẹmi Mimọ gba ki o to ṣe e. Lọgan bi a ba ti gba a la, o di ẹda titun ninu Kristi; ati nipa iribọmi o fi han fun aye pe oun di Onigbagbọ nisinsinyi. Nigba ti Peteru paṣẹ fun wọn lati ṣe iribọmi ni orukọ Jesu, o ni in lọkan wi pe ki a ṣe e gẹgẹ bi aṣẹ ti Jesu ti pa – ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ ati ni ti Ẹmi Mimọ. Eyi yi ni a fi n ṣe iranti iku, isinku, ati ajinde Jesu; o si tun n fi ye wa pe a di oku si ẹṣẹ a si jinde lati maa rin ni ọtun iwa.

Nigba ti Peteru pada bọ si ile rè̩ o fi ẹgbẹ awọn ti o gbagbọ ti o lagbara silẹ laarin awọn Keferi ni ile Kọrneliu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni Kọrneliu ṣe nigba ti o gbọ pe Peteru n bọ wá?

  2. 2 Kin ni ero awọn Ju nipa awọn ara Romu?

  3. 3 Eeṣe ti Peteru fi lọ waasu fun Kọrneliu?

  4. 4 S̩e apejuwe ẹsin Kọrneliu ati awọn eniyan rè̩.

  5. 5 Kin ni awọn ọrọ iṣaaju ti Peteru sọ nigba ti o bẹrẹ iwaasu fun Kọrneliu?

  6. 6 Tani ẹni itẹwọgba niwaju Ọlọrun?

  7. 7 Kin ni yoo jẹ ipo Jesu nigba ti yoo tun pada wá?

  8. 8 Kin ni ṣẹlẹ si Kọrneliu ati awọn eniyan rè̩ nigba ti wọn gba iwaasu Peteru gbọ?

2