Iṣe Awọn Apọsteli 11:1-26

Lesson 304 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọpọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrun ati ìha ìwọ-õrun wá, nwọn a si ba Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun” (Matteu 8:11).
Notes

Lati Ila-oorun ati lati Iwọ-oorun

O ṣoro fun awọn Ju lati gbagbọ pe Ihinrere Jesu Kristi wà fun awọn Keferi pẹlu. O gba pe ki Peteru ri iran ki o to le gba eyi gbọ. Awọn eniyan mimọ ti o ba a lọ si ile Korneliu, balogun ọrún ti gbọ nigba ti awọn ara Romu wọnyi n fi ede titun sọrọ lati fi han pe wọn ri Ẹmi Mimọ gbà; nigba yi ni awọn ti o wà pẹlu Peteru gbagbọ. Sibè̩ awọn Ju bẹrẹ si ro o bi eyi ba le ri bẹẹ.

Balogun ọrún kan ti wà nigba ti Jesu wà ni aye, ẹni ti o ti gba A gbọ. Nigba ti ọmọ rè̩ ṣe aisan de oju ikú balogun ọrún yi ti tọ Jesu wá fun iranwọ. O ti jẹ bi ohun iyanu fun awọn ọmọ-ẹhin pe Jesu yoo wo Keferi sàn, ṣugbọn O ti sọ fun wọn pe “Mo wi fun nyin, ọpọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrùn ati ihà ìwọ-õrùn wá, nwọn a si ba Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun” (Matteu 8:11). Ni ọna yi Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe ọpọlọpọ ni yoo wà ni Ọrun yatọ si awọn Ju. Wọn o si tobi gẹgẹ bi Baba Abrahamu, wọn o si gba èrè pẹlu Isaaki ati Jakọbu. S̩ugbọn òye ko yé awọn ọmọ-ẹhin.

Awọn Ju ti o ni iyipada ọkan ti o wà ni Jerusalẹmu pẹlu ko mọ pe awọn Keferi le di Onigbagbọ. Wọn ro pe Peteru ti sọ ara rè̩ di aimọ nipa biba Kọrneliu ati awọn ọrẹ rè̩ jẹun pọ.

Iran Peteru

Peteru tun gbogbo itan naa sọ lẹẹkan si i, gẹgẹ bi oun ti ri iran ohun-elo kan ti a sọ kalẹ lati Ọrun wa ninu eyi ti oriṣiriṣi ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aye gbe wà, ati awọn ti ofin ti pe ni alaimọ ati awọn mimọ. O ti gbọ ti ohun kan n wi pe, “Dide Peteru, mā pa, ki o si mā jẹ.” Peteru kun fun itara gẹgẹ bi ẹnikẹni laarin awọn Ju; nigba ti o si dahun, ohun ti o ni lọkan ni pe, “Emi kò lè ṣe bẹẹ.” Oun ko i ti i jẹ ohunkohun ti Ofin pe ni alaimọ ri. S̩ugbọn Ọlọrun fi han fun un pe bi Oun ba pe ohun kan ni mimọ, Peteru ko gbọdọ pe e ni alaimọ.

Otitọ ni pe Ọlọrun ni o fi ofin ti o pe awọn ẹranko iru kan ni alaimọ lelẹ; ṣugbọn eyi yi ni ami miran pe a ti mu Ofun ṣẹ, bẹẹ ni ko tun nipa lori awọn Onigbagbọ mọ. Awọn ilana ati irubọ ti a ti fi lelẹ fun Israẹli gẹgẹ bi apẹẹrẹ lati kọ wọn nipa Jesu ati Ihinrere ti yoo mu wa, ko tun jẹ ohun ti a tun ni i ṣe mọ. Jesu tikara rè̩ ti wa, ko si tun si idi kan lati tun maa ṣe apẹẹrẹ mọ. Iru ẹran ti eniyan n jẹ ko yi iru ipo ti ọkan rè̩ wà pada. Bi o ba jẹ ẹlẹṣẹ, wiwà lai jẹ ẹran ko le sọ ọ di Onigbagbọ (Matteu 15:17-19).

Lai si Ojusaju Eniyan

Peteru ti n ro o wo lati mọ iru ẹkọ ti a fẹ lati fi kọ oun ti a fi ran iran yi wa, eyi ti o rekọja jijẹ ẹran. Nigba ti awọn ọmọ-ogun nì de lati odọ Kọrneliu, Peteru bẹrẹ si i ro nipa iyatọ ti o wà laarin awọn eniyan mimọ ati alaimọ -- gẹgẹ bi awọn Ju ti gba pe iyatọ n bẹ. O wa moye pe a fi iran naa han oun lati kọ ọ pe ẹnikẹni ti Ọlọrun ba ti sọ di mimọ oun ko gbọdọ pe e ni “alaimọ.” Ọlọrun ti fi anfaani silẹ fun olukuluku eniyan lati ri igbala bi o ba le kọ ẹṣẹ rè̩ silẹ.

Peteru ti mu ẹlẹri mẹfa pẹlu ara rè̩ nigba ti o lọ sọdọ Kọrneliu. Ohun rere ni nigba ti a ba rii pe o di ọranyan fun wa lati ṣe ohun kan ti a ro pe o le mu ba-wo-lo-ti-ri wá, ki a mu ẹlẹri pẹlu wa lo. Peteru fi suuru ṣe alaye gbogbo iriri rè̩ pẹlu Kọrneliu ati awọn Keferi naa ti o gbagbọ, bẹẹ ni awọn eniyan mimọ ti i ṣe Ju wọnyi si ni itẹlọrun. Wọn ri i gbangba pe Ọlọrun ni O ran an. Nigba ti wọn si gbọ pe awọn Keferi pẹlu ti ri Ẹmi Mimọ gba, wọn yọ.

Titan Ihin naa Kalẹ

Ihinrere ni lati tàn kalẹ. Ki i ṣe kiki pe a o tú Ẹmi Mimọ jade ni Jerusalẹmu ati ni awọn ilu ti o wà ni agbegbe rè̩, ṣugbọn a ni lati mu ọrọ Ihinrere lọ si awọn ilẹ miran gbogbo. O le jẹ pe awọn Onigbagbọ naa ko i ti lọ si irin-ajo ọna jijin ri, lai ṣiyemeji wọn i ba ni itẹlọrun lati maa gbe ibi ti wọn wà titi wọn o fi kú. Fun iran-iran, awọn ẹbi kan naa i ba wa lori ilẹ kan naa. S̩ugbọn ayọ lati sọ Itan iye ti gba ọkan wọn kan. Wọn ni lati mu ọna wọn pọn lati kede Ihinrere naa. A ni lati kede ihin igbala nipa ọrọ ẹnu ati nipa igbesi-aye awọn Onigbagbọ laarin awọn ti a ko i ti gbala ni ilẹ okere.

Inunibini

Nigba ti a sọ Stefanu ni okuta pa, inunibini ti o le ti dide o si ti mu ki awọn Onigbagbọ jade kuro ni Jerusalẹmu. Nigba miran wọn ni lati rin jinna, nitori pe gẹgẹ bi Paulu (ẹni ti a n pe ni Saulu nigba naa) ti wi nipa ara rè̩, “Mo ṣe inunibini si wọn de ajeji ilu.” Bẹẹ ni a ri ọpọlọpọ eniyan bi Paulu ki a to gba ọkan rè̩ la, ti wọn sa gbogbo agbara wọn lati lé gbogbo awọn ti o gbagbọ ninu Jesu lọ tabi lati jẹ wọn ni iyà. Kin ni iwọ ti ro ti awọn eniyan bẹẹ si ti wọn n fẹ lati ṣe bẹẹ si Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin Rè̩, nigba ti o jẹ pe rere ni wọn n ṣe lai ṣe ibi?

Nibikibi ti awọn Onigbagbọ ti a n ṣe inunibini si wọnyi ba lọ, wọn a maa waasu Jesu -- ṣugbọn fun kiki awọn Ju nikan. Boya ọpọlọpọ ninu wọn ko i ti gbọ nipa ibẹwo Peteru sọdọ Kọrneliu, wọn ko si ti i mọ pe Ihinrere wà fun gbogbo eniyan.

Jesu ti rán awọn ọmọ-ẹhin si gbogbo aye lati waasu Ihinrere, O si ti ṣeleri pe, “Ẹ si kiyesi i, emi wa pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye.”

Ọwọ Ọlọrun lara Wọn

Nigba ti Jesu ṣeleri pe Oun yoo maa ba awọn eniyan Rè̩ lọ, O sọ fun wọn pe a ni lati kọkọ fi agbara wọ wọn lati Ọrun. Agbara nì sọkalẹ pẹlu Ẹmi Mimọ. Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin waasu ni ilu Kipru, Fẹnike, ati Antioku, wọn ni agbara naa, “ọwọ Oluwa si wa pẹlu wọn.” Ko si bi awọn eniyan naa ti le waasu to nipa Jesu, bi Ẹmi Ọlọrun ko ba ba wọn ṣiṣẹ, awọn eniyan ki ba ti le ri igbala. Lẹhin eyi Paulu fi iṣẹ isin tirè̩ we ti Apollo o si wi pe: “Emi gbìn, Apollo bomirin; ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wá” (I Kọrinti 3:6). Ko si ohun ti a le ṣe fun Oluwa ti o le mu ere wá, afi bi a ba ṣe e labẹ itọni Ẹmi Ọlọrun.

A gba ọkan wọnni la ni ilu wọnni nitori pe awọn alufa ati awọn oṣiṣẹ ti gbadura pupọ, Ẹmi Ọlọrun si le ti ipasẹ wọn ba ọkan awọn ẹlẹṣẹ sọrọ. Ọrọ olohun-iyọ le mu inu eniyan dun, ṣugbọn Ẹmi Mimọ Ọlọrun ni O le fi ọwọ tọ ọkan. Nigba ti a ba n gbiyanju lati sọ fun ẹni kan pe Jesu le gba a kuro ninu ẹṣẹ rè̩, awa pẹlu ni lati ni Ẹmi Ọlọrun ninu aye wa ki ọrọ wa ba le mu un lọkan.

Ọlọrun a maa fun ni ni Ẹmi Mimọ Rè̩ ni ẹkunrẹrẹ nigba ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ wa; ṣugbọn a ni lati maa beere fun ibukun Ọlọrun lori iṣẹ wa, ki a si maa fi ohun gbogbo ti a ni rubọ si I, ki a ba le rii pe Ọlọrun n ti ipasẹ wa ṣiṣẹ. A ti maa n gbọ gbolohun yi, “A ki i fi eto lasan gbe isọji dide, ṣugbọn a maa n fi adura fa isọji sọkalẹ.” Adura pataki ni pe ki awọn eniyan Ọlọrun le ni iwuwo ninu ọkan wọn lati gbadura fun igbala awọn ti o ti sọnu!

Awọn Ipade ni Antiọku

Antiọku jẹ ọọdunrun ibusọ si iha ariwa Jerusalẹmu, eyi ti i ṣe ọna ti o jin pupọ ni akoko ti awọn eniyan n fi ẹsẹ rin. S̩ugbọn ninu ilu nla yi ọpọlọpọ ni awọn ti o gba iwaasu awọn ọmọ-ẹhin gbọ, isọji nla si bẹrẹ. Nigba ti awọn ti o gbagbọ ni Jerusalẹmu gbọ nipa rè̩, wọn ran Barnaba lọ ṣe ẹfangẹlisti lati ṣe alakoso awọn isin wọn. Inu Barnaba dun lati ri i pe ọpọlọpọ n ri igbala ati bi agbara Ọlọrun ti n sọkalẹ sori wọn; o si lọ si Tarsu lati wá Paulu ki o le wá lati ṣe iranlọwọ ninu ipejọpọ wọnyi.

Paulu ati Barnaba jumọ ṣe alabaṣiṣẹ rere pọ ninu iṣẹ isin wọn, wọn si duro ni Antiọku fun odindi ọdun kan, wọn si n fi iru agbara nla waasu to bẹẹ ti ọpọlọpọ eniyan fi ri igbala. Awọn tikara wọn jẹ ẹni ti a ti kọ ninu igbagbọ, wọn si ṣe tan lati lọ ṣe iṣẹ iranṣẹ titun. Gẹgẹ bi wọn ti n gbadura ti wọn si n gbaawẹ pẹlu awọn ẹlomiran ninu Ijọ, Ẹmi Mimọ wi pe: “Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si” (Iṣe Awọn Apọsteli 13:2). Eyi yi ni pe wọn o jẹ ajihinrere fun awọn Keferi. Ilẹkun naa ṣi silẹ fun olukuluku lati gbọ Ihinrere ati lati ri igbala.

Awọn Onigbagbọ

Ni Antiọku ni a kọ pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni Kristiani. Ẹ jẹ ki awa ti a jẹ Kristiani rii daju pe a n tẹle Kristi ati pe a n gbe igbesi-aye wa ninu iwa ti Oun ki yoo tiju lati pe wa ni ti Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni Balogun-ọrùn jẹ?

  2. 2 Ọna wo ni Ọlọrun gba fi han Peteru pe awọn Keferi le ri igbala pẹlu?

  3. 3 Kin ni mu ki awọn ọrẹ Peteru gbagbọ pe awọn Keferi le ri igbala?

  4. 4 Kin ni ṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Jesu fi Jerusalẹmu silẹ?

  5. 5 Kin ni wọn ṣe nibikibi ti wọn ba lọ?

  6. 6 Tani lọ si Antiọku lati fi idi ijọ kan kalẹ?

  7. 7 Bawo ni Paulu ati Barnaba ṣe mọ pe awọn yoo jẹ ajihinrere fun awọn Keferi?

  8. 8 Bawo ni Paulu ati Barnaba ti duro pẹ to ni Antiọku?

  9. 9 Kin ni itumọ ọrọ yi “Kristiani”?

  10. 10 Nibo ni a kọ gbe lo ọrọ naa?

2