I Awọn Ọba 22:1-40

Lesson 305 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gán Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7).
Notes

Lai si Ogun

Ọpọlọpọ ogun ni o wà laarin awọn Ọmọ Israẹli ati awọn ara Siria. Ni akoko ijọba Ahabu, a ṣẹgun Bẹnhadadi Ọba Siria. Lẹhin eyi fun ọdun mẹta ko si ogun laarin awọn orilẹ-ede mejeeji. Ni akoko yi, Ahabu bẹrẹ si i ṣe eto bi oun yoo ti ṣe le ṣẹgun ilu Ramoti-Gileadi ki o si gba a lọwọ awọn ara Siria. Ahabu gba pe ti awọn Ọmọ Israẹli ni i ṣe. Ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin, Mose ti kede pe Ramoti-Gileadi ti jẹ ilu aabo, ni iha ila-oorun Odo Jọrdani (Ẹkọ 139). Ilu Ramoti-Gileadi jẹ apa kan ninu ogún ti Gadi (Deuteronomi 4:43). Eyi yi ni ilu naa ti Ahabu gbero lati gbà lọwọ awọn ara Siria.

A ti gbe ọmọbinrin Ahabu ni iyawo fun Jehoramu, ọmọkunrin Jehoṣafati, Ọba Juda (II Kronika 21:6). Jehoṣafati lọ lati bẹ Ahabu wò, ati ni akoko yi, Ahabu pa agutan ati malu lọpọlọpọ fun àse. Ahabu ṣe oninuure pupọ si Jehoṣafati ati awọn eniyan rè̩. Nigba naa ni Ahabu ba Jehoṣafati sọrọ ki o ba oun lọ si ogun lati gba ilẹ Ramoti-Gileadi.

Adehun Kan

Jehoṣafati gbà lati ba Ahabu lọ si ogun. Jehoṣafati wi pe, “Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ, awa o pẹlu rẹ li ogun na” (II Kronika 18:3). Eyi yi jẹ gbolohun ajeji lati sọ, nitori awọn ọba meji wọnyi yatọ si ara wọn gidigidi. Ninu ẹkọ wa nipa ijọba Ahabu a ti kọ wi pe Ahabu sin oriṣa o si ṣe ibi nipa ṣiṣe iṣe buburu niwaju Oluwa (I Awọn Ọba 21:20, 25). Ni ida keji a kà wi pe Jehoṣafati wa Oluwa, “o si rìn ninu ofin rè̩” o si mu igbó ibi ibọriṣa kuro (II Kronika 17:3-6). Jehoṣafati mu apa rè̩ le si Israẹli. O fi ẹgbẹ-ogun sinu awọn ilu olodi naa, o si fi ẹgbẹ ọmọ-ogun si ilẹ Juda fun aabo. Ọlọrun bukun Jehoṣafati pẹlu ọrọ ati ọlá lọpọlọpọ.

Ki i ṣe kiki pe o jẹ ohun ajeji nikan fun Jehoṣafati lati ṣe iru adehun bẹẹ pẹlu Ahabu, ṣugbọn o lodi. A rii gẹgẹ bi a ti mu ki Jehoṣafati ṣe ohun ti ko tọ nitori pe o ba Ahabu eniyan buburu kẹgbẹ lai nidi. Ọlọrun ti kilọ fun awọn eniyan Rè̩ ki wọn má ṣe jẹ ọrẹ awọn abọriṣa, ki a má ba mu wọn dẹṣẹ si Oluwa (Ẹksodu 23:33). Ọlọrun ti sọ fun wọn pe ki wọn má ṣe ba awọn abọriṣa da majẹmu nitori pe awọn ti n sin oriṣa yoo jẹ idẹkùn fun wọn (Ẹksodu 34:12).

Idẹkun

Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ pa ara wọn mọ kuro ninu ẹgbẹ buburu. A ri aṣẹ yi ninu Ọrọ Ọlọrun. “Maṣe bọ si ipa ọna enia buburu, má si ṣe rin li ọna awọn enia ibi” (Owe 4:14). Onipsalmu wi pe: “Ibukún ni fun ọkụnrin nā ti ko rin ni imọ awọn enia buburu, ti ko duro li ọna awọn ẹlẹṣẹ, ati ti ko si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgan” (Orin Dafidi 1:1). Ninu Majẹmu Titun a sọ fun wa pe, “Ẹ maṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ” (II Kọrinti 6:14), awọn ti wọn si ti ṣe bẹẹ -- i baa jẹ ni dida òwo pọ ni, tabi didapọ ni igbeyawo, tabi ibakẹgbẹ ti ko nidi – ni o ti ri i pe idẹkun ni. Fun Jehoṣafati adehun yi pẹlu ẹni ti o korira Ọlorun mu ibinu Ọlọrun ati idẹkun wa. Jehu, ọmọkunrin woli kan sọ fun Jehoṣafati, pe, “Iwọ si fẹran awọn ti o korira OLUWA? njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ OLUWA” (II Kronika 19:2).

Awọn Woli Eke

Lẹhin ti o ti ṣe adehun lati ran Ahabu lọwọ, Jehoṣafati n fẹ lati beere lọwọ Oluwa nipa ọran naa. Ahabu ranṣẹ pe awọn woli eke rè̩, ti i ṣe irinwo (400). Wọn fun awọn ọba mejeeji ni idaniloju pe Oluwa yoo fi Ramoti-Gileadi le wọn lọwọ. Bi o tilẹ jẹ pe irinwo eniyan wọnni sọ ohun kan naa, Jehoṣafati mọ pe wọn ki i ṣe woli Oluwa ni tootọ. Bi a ba fẹran Oluwa ni tootọ ti a si gbọran, Oun yoo fi han awa naa pẹlu, awọn ti o n sọ otitọ ati awon ti ko sọ otitọ: “Bi ẹnyin ba duro ninu ọrọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ. Ẹ ó si mọ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira” (Johannu 8:31, 32). Ọrọ Oluwa ni wọnyi ti a ti ẹnu Dafidi sọ: “Emi o fi ẹsẹ rẹ le ọna: emi o si kọ ọ li ọna ti iwọ o rin: emi o mā fi oju mi tọ ọ” (Orin Dafidi 32:8).

Jehoṣafati beere bi ko ba si woli Oluwa ti o le ba wọn beere. Ọkunrin kan wà ti a n pe ni Mikaiah, ṣugbọn Ahabu korira rè̩ nitori pe ko n sọ asọtẹlẹ rere fun Ahabu. Woli otitọ ko le sọ ọrọ rere nipa eniyan buburu, ṣugbọn Ahabu n fẹ lati gbọ “rere” dipo ti i ba fi gbọ otitọ.

Igbọran si Ọlọrun

Iranṣẹ kan lọ lati lọ pe Mikaiah. Ni oju ọna o sọ fun woli yi ohun ti awọn iyoku ti sọ. O gbiyanju lati yi Mikaiah ni ọkan pada lati sọ bi awọn iyoku ti sọ. Mikaiah jẹ Woli olotitọ. Kiki ọrọ ti Oluwa fi fun un ni o le sọ. O wi pe, “Bi OLUWA ti wà, ohun ti OLUWA ba sọ fun mi li emi o sọ.” Awọn eniyan Ọlọrun a maa ro nipa bi wọn o ti ṣe le wu Ọlọrun ju pe ki wọn maa rò bi iṣe ati ọrọ wọn yoo ti ṣe wu eniyan lọ. Nigba ti a n ba awọn ọmọ-ẹhin Jesu sọ nipa iwaasu wọn, wọn wi pe, “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti enia lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29).

Ninu aṣọ igunwa wọn, Ahabu ati Jehoṣafati joko sori itẹ lẹba bode Samaria. Nibẹ ni wọn gbọ ọrọ awọn woli eke. Ọkan ninu wọn, Sedekaiah, tilẹ ti fun wọn ni àmi pẹlu pe wọn o bori ninu ogun naa. O ṣe iwo irin, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ ọla ati agbara, lati fi gbe asọtẹlẹ rè̩ lẹsẹ.

Nigba ti Mikaiah duro niwaju awọn ọba mejeeji, a bi i leere ohun kan naa ti a beere lọwọ awọn iyoku. Mikaiah fun wọn ni esi bakan naa, ṣugbọn o ni lati jẹ pẹlu ohun ọrọ ti o fi ẹgan ati è̩fẹ han. Ọba wi fun un pe oun ko fẹ lati gbọ ohun miran ju otitọ ni orukọ Oluwa. Mikaiah sọ iṣẹ naa lati ọdọ Oluwa fun wọn. O wi pe a o fọn gbogbo Israẹli ká bi agutan ti ko ni oluṣọ. Mikaiah sọ fun wọn pe Oluwa wi pe, “Awọn wọnyi ko ni oluwa: jẹ ki wọn ki o pada olukuluku si ile rè̩ li alafia” (II Kronika 18:16).

A Fi i Sinu Tubu

Ahabu wi fun Jehoṣafati pe: “Emi ko ti wi fun ọ pe on ki isọtẹlẹ rere si mi, bikoṣe ibi?” Mikaiah wi fun wọn pe ẹmi eke wa lẹnu awọn woli eke naa, ati pe Oluwa ti sọ ibi si ete wọn. Wọn ko fẹ ọrọ lati ẹnu Mikaiah, iranṣẹ ododo lati ọdọ Ọlọrun. Wọn mu ki o jiya nitori pe o sọ otitọ. Sedekiah sọrọ si Mikaiah o si lu u ni ẹrẹkẹ. Ahabu paṣẹ pe ki a fi Mikaiah sinu tubu ki a si maa fi akara ati omi lasan bọ ọ. Gẹgẹ bi ọrọ idagbere rè̩, Mikaiah pe awọn eniyan naa lati ṣe ẹlẹri, o si wi fun Ahabu pe, “Ni pipada bi iwọ ba pada bọ li alafia, OLUWA ko ti ọdọ mi sọrọ.”

Eto Ti Wọn

Jehoṣafati ti fẹ lati mọ ohun ti Oluwa sọ nipa eto wọn lati lọ gba Ramoti-Gileadi; ṣugbọn nigba ti o mọ otitọ tan, ko fara balẹ gbọran. O yẹ ki o ti beere lọwọ Ọlọrun ki o to di pe o lọ ṣe adehun pẹlu Ahabu. Awọn eniyan miran n bẹ lode oni ti wọn feti si ọrọ Oluwa ṣugbọn ti wọn ki yoo gba ikilọ ti o n ṣe fun wọn. Awọn ẹlomiran a beere amọran lọwọ awọn aṣaaju won, wọn a si tun lọ ṣe gẹgẹ bi o ti wu wọn – lodi si amoran naa.

Ahabu ati Jehoṣafati mura lati lọ si ogun. Ahabu gbe aṣọ igunwa rè̩ fun Jehoṣafati lati wọ. Ahabu pa ara dà, lai si aniani lati gba ara rè̩ silẹ, lati fi Jehoṣafati han, ati lati di ọrọ asọtẹlẹ lọwọ lati ṣẹ.

Awọn olori ogun Siria ti gba aṣẹ lati ba Ahabu ja ni pataki. Laarin ogun won ro wi pe Jehoṣafati ni Ahabu nitori naa wọn yi i ka. Jehoṣafati kigbe soke, Oluwa si ran an lọwọ. Awọn ọta kiyesi i pe ki i ṣe Ahabu, nitori naa wọn fi i silẹ. Jehoṣafati fẹrẹ sọ ẹmi rè̩ nu nitori pe o wà ni ipo Ahabu. Nigba ti Onigbagbọ ba wọ aṣọ ẹlẹṣẹ, ti o si duro ni ipo Elẹṣẹ, o wa ni ipo ti o lewu. Aanu Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o da Jehoṣafati silẹ, bẹẹ ni agbara Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o le gba ẹni ti o wa ni ipo ti o lodi silẹ.

Ko si Ibi Aabo

Lai si aniani, Ahabu ro pe oun yoo ri aabo ninu piparada rè̩ ti o ṣe. S̩ugbọn piparada ko le fi ẹnikẹni pamọ kuro lọwọ Oluwa. Bi o tilẹ jẹ pe ọta ko mọ ẹni ti Ahabu i ṣe, Oluwa mọ ọn. Ọpọlọpọ ọrọ ni a ti sọ si Ahabu ati si iwa buburu rè̩. A ti ba Ahabu wi ni iye igba, o si ni anfaani lati ronupiwada. Mikaiah ti kilọ fun Ahabu pe ki yoo pada bọ bi o ba lọ si ogun yi. Ahabu ko gbẹkẹle Ọlọrun bẹẹ ni ko gba Ọlọrun gbọ. Ahabu yan lati gba awọn woli eke nì gbọ ati lati gbẹkẹle awọn ère oriṣa rè̩. S̩ugbọn ọrọ Ọlọrun yoo ṣẹ.

Eyi yi ni ogun ti Ahabu ja kẹhin. Lai pete, tafa-tafa kan fa ọrun rè̩ o si ba Ahabu. O gbọgbé̩ lọpọlọpọ o si ṣubu sinu kẹkẹ rè̩. Olutọju-kẹkẹ rè̩ fi oju-ogun silẹ, Ahabu si ku ni akoko iwọ-oorùn. Nigba ti ọba ku, a paṣẹ fun awọn eniyan naa lati pada si ile wọn. Awọn eniyan naa ko ni aṣaaju, nitori naa wọn fọnka. Asọtẹlẹ Mikaiah ṣẹ: “Mo ri gbogbo Israẹli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti ko ni oluṣọ.”

Asọtẹlẹ Otitọ

Ọrọ Elijah pẹlu ṣẹ ni iku Ahabu. Nigba ti Ahabu lọ gba ọgba ajara Naboti, a ran Elijah lati jẹ iṣẹ yi fun un: “Bayi li OLUWA wi pe, Ni ibiti aja gbe la ẹjẹ Naboti, ni awọn aja yio la ẹjẹ rẹ, ani tirẹ” (I Awọn Ọba 21:19).

A ti sọ Naboti ni okuta pa lẹhin ilu Jesreeli nibi ti Ahabu n gbe. Boya Ahabu ti ro pe asọtẹlẹ Elijah ati Mikaiah ko le ṣẹ papọ. Mikaiah wi pe Ahabu ki yoo pada lati ogun ti wọn lọ ba awọn ara Ramoti-Gileadi ja. Elijah wi pe aja yoo la ẹjẹ Ahabu ni Samaria. Ọlọrun ti sọrọ nipa awọn ọkunrin meji wọnyi, asọtẹlẹ wọn si ṣẹ. A pa Ahabu ni ogun. A si gbe e pada si Samaria a si sin in. Nigba ti a n wẹ kẹkẹ rè̩ ninu omi Samaria awọn aja wà nibẹ wọn si mu ọrọ asọtẹlẹ naa ṣẹ.

Aanu

Ninu Bibeli awọn asọtẹlẹ kan ṣi wà ti a ko i ti mu ṣẹ. S̩ugbọn wọn o ṣẹ. Ninu Majẹmu Laelae a kà pe, “Ọrọ Ọlọrun wa yio duro lailai” (Isaiah 40:8); ati pe “OLUWA lai, ọrọ rẹ kalẹ li ọrun” (Orin Dafidi 119:89). Ninu Majẹmu Titun a ka pe: “Ọrọ Oluwa duro titi lai. Ọrọ na yi si ni ihinrere ti a wāsu fun nyin” (I Peteru 1:25). Ọrọ Jesu ni wọnyi: “Ọrun on aiye yio rekọja, ṣugbọn ọrọ mi ki yio rekọja” (Majẹmu 24:35) ati “Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin ki yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rè̩ yio fi ṣẹ” (Matteu 5:18). Ọrọ inu Bibeli jẹ otitọ, wọn o si ṣẹ. Awọn eniyan le gbiyanju lati ṣe idena ki wọn si fara pamọ, ṣugbọn ohun ti Ọlọrun ti sọ O lagbara lati mu un ṣẹ.

Awọn ẹlomiran n gbiyanju lati bo ẹṣẹ wọn mọlẹ nihin ṣugbọn Ọlọrun mọ nipa wọn nitori pe “ohun gbogbo ... ṣipaya fun oju rè̩ ẹniti awa ni iba lo” (Heberu 4:13). Wo o bi eniyan ti jere to nipa jijẹwọ aye rè̩ niwaju Oluwa dipo ti i ba fi duro de akoko ti yoo duro niwaju itẹ Ọlọrun! Bi o ba jẹwọ nisinsinyi yoo ri aanu gbà; ṣugbọn bi o ba duro de igba idajọ, ki yoo si aanu. “È̩ṣẹ awọn ẹlomiran a mā han gbangba, a mā lọ ṣaju si idajọ; ti awon ẹlomiran pẹlu a si mā tẹle wọn” (I Timoteu 5:24). Ọna kan ṣoṣo ti eniyan le gba nireti lati ri aanu gbà ni lati jẹwọ ẹṣẹ rè̩ ki o si kọ ẹṣẹ rè̩ silẹ. “Ẹniti o bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ ki yio ṣe rere” (Owe 28:13).

Ko si Ère

Jehoṣafati ko jere ohunkohun nipa didarapọ mọ Ahabu eniyan buburu. A ti i lati ṣe lodi si ọrọ asọtẹlẹ Ọlọrun. O fẹrẹ sọ ẹmi rè̩ nu nitori pe o parada bi Ahabu. Nigba ti o ba Ahabu lọ, Jehoṣafati ko le ṣakoso awọn eniyan rè̩ daradara. A ba a wijọ pe o fẹ awọn ti o korira Oluwa, ibinu Oluwa si wa lori rè̩. Bakan naa ni o ri lode oni pe eniyan ki i jere nigba ti o ba yan lati gba ọna ti rè̩ ju lati gbọran si Ọrọ Ọlọrun ti wọn si kọ lati gba amọran awọn alufa Ọlọrun ati Bibeli.

Ère ti eniyan yoo gba bi o ti duro niwaju Ọlọrun yoo jẹ gẹgẹ bi o ti ṣe lo igbesi-aye rè̩ si nihin. Bi igbesi-aye rè̩ ba ti dara gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun, ère rè̩ yoo dara. Bi igbesi-aye rè̩ ko ba ti dara, gẹgẹ bi Ọrọ Bibeli, ère rè̩ ki yoo dara, “Nitori ikú li ère ẹṣẹ; ṣugbọn ẹbun ọfẹ Ọlọrun ni iye ti ko nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6:23).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Tani Ọba Judah?

  2. 2 Kin ni ṣe ti o lọ si ogun lati ba ilu Ramoti-Gileadi jà?

  3. 3 Amọran wo ni awọn irinwo (400) woli Ahabu fi fun un?

  4. 4 Tani Mikaiah i ṣe?

  5. 5 Kin ni asọtẹlẹ rè̩?

  6. 6 Kin ni ṣe ti Ahabu korira Mikaiah?

  7. 7 Kin ni ṣe ti awọn ọba parada ninu ogun?

  8. 8 Kin ni ṣe ti a da ẹmi Jehoṣafati si?

  9. 9 Bawo ni a ṣe pa Ahabu loju ogun?

  10. 10 Awọn ọrọ asọtẹlẹ wo ni a muṣẹ ninu ikú Ahabu?

2