II Kronika 19:1-11; 20:1-30

Lesson 306 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Fi ọna rẹ le OLUWA lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ” (Orin Dafidi 37:5).
Notes

Aanu Ọlọrun

Jehoṣafati pada si ile rè̩ lẹhin ogun ti wọn ba awọn ara Siria ja. Gẹgẹ bi ọrọ asọtẹlẹ, a pa Ahabu, Ọba Israẹli ninu ogun naa. Ọlọrun ti da ẹmi jehoṣafati si nigba ti awọn ọta yi i ká. Ọlọrun ti fi aanu han fun Jehoṣafati nipa fifun un ni àye lati pada si ile lai lewu.

Ohun ti o jọ Ibi

A ti fọn awọn ọmọ-ogun awọn Ọmọ Israẹli ati Juda ká. Wọn ko ṣẹgun ninu ogun naa. Jehu, ọmọ woli kan sọ fun Jehoṣafati idi rè̩ ti wọn fi kuna, ati pe ibinu wa ni ori rè̩ lati ọdọ Oluwa. Jehoṣafati ti da ogun pọ pẹlu Ahabu, ẹni ti o korira Mikaiah, Woli Oluwa, ẹni ti o si pe Elijah, Woli miran pẹlu, ni ọta rè̩ (II Kronika 18:7; I Awọn Ọba 21:20). Nipa didarapọ mọ Ahabu, o dabi ẹni pe Jehoṣafati n ṣe onigbọwọ fun Ahabu ninu ẹṣẹ rè̩, ati pe Jehoṣafati n fẹ ọkunrin yi ẹni ti o korira Ọlọrun. Ki o to to akoko yi Jehoṣafati ti fi han pe oun n fẹ lati ṣe ohun ti o tọ. O ti pese ọkan rè̩ silẹ lati wá Ọlọrun. O ti tun Juda ṣe nipa mimu igbo oriṣa kuro. S̩ugbọn nisinsinyi o ṣe aṣiṣe ni fifi ohùn ṣọkan pẹlu Ahabu ati ni lilọ si ogun pẹlu rè̩.

Onipsalmu, Dafidi, wi pe oun korira awọn ti o korira Ọlọrun, pe oun gba awọn ọta Ọlọrun si ọta oun, ati pe oun ko ni irẹpọ pẹlu eniyan buburu (Orin Dafidi 139:21, 22; 26:5). Lati inu akọsilẹ Paulu Apọsteli a kà wi pe: “Ẹ mā takete si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ ohun ti iṣe rere”; ati “Ẹ mā takete si ohun gbogbo ti o jọ ibi” (Romu 12:9; I Tẹssalonika 5:22). Jehoṣafati kùna lati ṣe eyi nì, o si ṣe aṣiṣe nla.

Pada si Ọdọ Ọlọrun

Jehoṣafati pada si idi iṣẹ rè̩ eyi ti i ṣe ṣiṣakoso awọn Juda. O la ile naa kọja, “o si mu wọn pada sọdọ OLUWA Ọlọrun awọn baba wọn.” Boya didarapọ ti Jehoṣafati darapọ mọ Ahabu ti mu wọn ni ero wi pe o fara mọ oriṣa. Ki didapọ rè̩ pẹlu Ahabu má ba mu ero buburu yi wa, Jehoṣafati n lọ o si n bọ ni gbogbo ilẹ naa lati mu ọkan awọn eniyan naa bọ sipo. Bi buburu kan ba ti ṣẹ nipa isowọpọ rè̩ pẹlu Ahabu ninu ogun, o n lọ kaakiri lati ṣe atunṣe ati lati mu Judah pada lati sin Oluwa.

Awọn Onidajọ

Jehoṣafati fi idi ile-idajọ kalẹ jakejado gbogbo ilẹ naa. O fi aṣẹ pataki lelẹ fun awon onidajọ ti a yan lati ṣakoso ile-ẹjọ. O ran wọn leti pe wọn n ṣe idajọ naa fun Oluwa, ati pe wọn o jiyin fun Un. O kilọ fun wọn lati ṣe idajọ ododo lori awọn eniyan naa -- wọn ko gbọdọ ṣe ojusaju bẹẹ ni wọn ko gbọdọ gba abẹtẹlẹ. Jehoṣafati wi fun awon onidajọ pe “Jẹ ki ẹru OLUWA ki o wà lara nyin.”

Fun OLUWA

A ko gbe awọn eniyan Ọlọrun kalẹ gẹgẹ bi onidajọ lori awọn ẹlomiran ṣugbọn a fun wọn ni anfaani lati ṣiṣẹ fun Oluwa. Ohun ti wọn n ṣe, wọn n ṣe e fun ọlá ati ogo Ọlorun. Wọn ko ṣe iṣẹ wọn lati tẹ eniyan lọrun ni gbogbo ọna ṣugbọn lati tẹ Ọlọrun lọrùn. “Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun (I Kọrinti 10:31). Nigba ti a ba fun awọn ọmọde ni anfaani lati kọrin laarin ẹgbẹ akọrin Ile-ẹkọ Ọjọ-Isinmi, wọn a fi gbogbo ọkan won kọrin si Oluwa. Awọn ọmọde Onigbagbọ mọ pe Ọlorun n kiyesi i, ati pe bi awọn ba jẹ olootọ Oluwa le fun won ni awọn anfaani miran lati ṣiṣẹ fun Un. Nigba ti a ba fun awọn ọmọde Onigbagbọ ni anfaani lati ṣe iranlọwọ ni ile-isin – bi pipin iwe ati iwe itankalẹ Ihinrere, lati to awọn ijoko lẹsẹẹsẹ, ki a sure jẹ iṣẹ ti a ran wa, tabi, pẹlu ki a ṣe itọju awọn ọmọde ti o kere ju wọn lọ -- wọn a maa huwa pẹlu igbọran ati iwa-pẹlẹ bi ẹni pe Oluwa tikara Rè̩ ni O wi pe ki wọn ṣe fun Oun.

Ofin Ọlọrun

Ni Jerusalẹmu pẹlu, Jehoṣafati gbe awọn onidajọ kalẹ. Awọn wọnyi jẹ awọn ọmọ Lefi, awọn alufa, ati awọn olori awọn baba ni Israẹli. Jehoṣafati sọ fun wọn lati ṣe ohun gbogbo “ni ibẹru OLUWA, li otitọ, ati pẹlu ọkan pipe.” A yan ọkunrin meji lori gbogbo awọn onidajọ wọnyi. Amariah, olori alufa ati olori fun ohun gbogbo ti o ba ṣẹlẹ ni ti Oluwa. Sebadiah, alakoso ile Judah ni a fi ṣe olori fun ohun gbogbo ti o ba ṣẹlẹ ni ti ọba. Awọn ẹgbẹ onidajọ meji yi ni wọn yoo maa bojuto ọrọ idajọ ti o ba ṣẹlẹ laarin awọn eniyan naa, “ki nwọn ki o maṣe dẹṣẹ si OLUWA.” Ẹgbẹ naa ti Amariah i ṣe olori rè̩ ṣe akoso gẹgẹ bi igbekalẹ Ijọ Ọlọrun. Ẹgbẹ keji wa lati ṣe abojuto ọrọ ofin ilẹ naa. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ, lode oni, ni ọpọlọpọ orilẹ-ede ni ofin wà lati diwọn bi mọto ti ni lati sare to, tabi eyi ti o n sọ nipa awọn nkan ti a ko le fi ranṣẹ si ilu miran, ati iru ohun ti a le ṣe tabi ti a ko gbọdọ ṣe. Gbogbo eniyan kọ ni o n gbọran si ofin Ọlọrun: ṣugbọn ki i ṣe kiki ofin Ọlọrun nikan ni Onigbagbọ ni lati pamọ, ṣugbọn ofin ibilẹ pẹlu, niwọn igba ti ofin wọnyi kò lodi si ofin Ọlọrun (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29). Onigbagbọ jẹ ọmọ ibilẹ rere.

Awọn ti n Gbe Ogun ti Wọn

Lẹhin ti Jehoṣafati ti pese idajọ ati isin Oluwa fun awọn eniyan rè̩ tan, a le nireti pe wọn o ni alaafia ati ohun rere. Dipo eyi iro igbogunti ni o wa si eti Jehoṣafati. Awọn adalu ẹgbẹ lati aarin awọn ọmọ Moabu, Ammoni, ati awọn ẹlomiran, pete lati fi ẹgbẹ ogun gbá Juda kuro. Ni igba kan sẹhin, Jehoṣafati ti pese ẹgbẹ ọmọ-ogun nla silẹ fun ogun (II Kronika 17:13-18). Ni akoko yi, a ko sọ fun ni pe a kó awọn jagunjagun jọ ati ohun ija fun ogun. Jehoṣafati kede aawẹ jakejado gbogbo ilẹ Juda. Ki i ṣe ọba ati awọn onidajọ nikan ṣugbọn gbogbo eniyan pẹlu ni a wi fun pe ki wọn wa Ọlọrun. Aawẹ wà fun ati wa Ọlọrun fun idi pataki kan. Ni akoko aawè̩, awọn eniyan a maa gbadura wọn ki i tilẹ ri aye lati jẹun paapaa, nitori pe ohun ti o leke ọkan wọn ni wiwa Ọlọrun (Wo Ẹko 267).

Adura

Jehoṣafati duro niwaju awọn eniyan naa ti o ti pejọ si ile Oluwa, si tẹmpili ti Sọlomọni kọ (Ẹko 257). Bi Jehoṣafati ti n gbadura, o jẹwọ pe Ọlọrun ni gbogbo ipa ati agbara, to bẹẹ ti ko si ẹni kan ti o le duro niwaju Rè̩. O ran Ọlọrun leti pe a ti ṣeleri ilẹ naa fun Abrahamu ati fun iru-ọmọ rè̩. O ranti bi Sọlomọni ti gbadura ni akoko iyasi-mimọ tẹmpili yi kan naa ninu eyi ti wọn pejọ. Sọlomọni ti beere lọwọ Ọlọrun pe ki O gbọ adura naa, ti a ba gbà nibẹ (II Kronika 6:40). O ti beere pe nigba iyàn, ajakalẹ-arun ati ogun, adura naa i baa jẹ ti ẹni kan ṣoṣo tabi ti gbogbo eniyan Rè̩, pe ki Ọlọrun “mu ọran wọn duro” (I Awọn Ọba 8:37, 44, 45). Nigba ti Sọlomọni ti gbadura bayi, Ọlọrun dahun: ina sọkalẹ lati Ọrun o si jo ẹbọ naa; “ogo OLUWA si kun ile na” (II Kronika 7:1). Oluwa wi fun Sọlomọni pe “Oju mi yio ṣi, eti mi yio si té̩ si adura ibi yi” (II Kronika 7:15).

Jehoṣafati mu un wa si iranti pe awọn Ọmọ Israẹli ti gbọran nipa ọrọ yi nigba ti wọn n rin irin-ajo la iju ja. Ọlọrun paṣẹ fun wọn nipa awọn ara Moabu ati Ammoni, tabi awọn ọmọ Esau ti n gbe ilẹ Seiri pe wọn ko gbọdọ bi wọn ninu, wọn ko gbọdọ tọ wọn tabi ki wọn ba wọn ja (Deuteronomi 2:4, 9, 19). Nisinsinyi awọn ogun wọnyi naa gan an ni wọn n fẹ lati le awọn eniyan Ọlọrun jade kuro lori ilẹ naa. Jehoṣafati pe Ọlọrun lati ṣe onidajọ, o si wi pe, “Awa kò li agbara niwaju ọpọlọpọ nla yi ti mbọ wá ba wa, awa ko si mọ eyiti awa o ṣe; ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ.”

Lati kọ wá Ọlọrun

Nigba idaamu, awọn ẹlomiran a maa gbiyanju amọran awọn ọrẹ, agbara wọn, ati gbigbẹkẹle ọna awọn eniyan. Nigba miran nigba ti gbogbo wọnyi ba kuna, wọn a kọju si Ọlọrun fun iranlọwọ gẹgẹ bi ọna ti a le gbidanwo kẹhin. Wo o bi i ba ti dara ju lọ lati kọkọ gbadura ki a si wa Ọlọrun lakọkọ. Bibeli wi pe “O ya lati gbẹkẹle OLUWA ju ati gbẹkẹle enia lọ” (Orin Dafidi 118:8); “OLUWA awọn ọmọ-ogun, ibukún ni fun oluwarè̩ na ti o gbẹkẹle ọ” (Orin Dafidi 84:12); “Ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rè̩ le OLUWA li a o gbe leke” (Owe 29:25). Kin ni ohun ti iwọ maa n ṣe nigba idaamu – o ha n pe awọn ọrẹ lati ran ọ lọwọ? o ha n ṣe eto nipasẹ eyi ti o le fi tan awọn ẹlomiran jẹ? o ha n fi ọrọ ẹnu rẹ yọ ara rẹ kuro? Tabi o maa n gbadura ki o si wa Ọlọrun ṣaaju?

Idahun

Oluwa ran idahun si adura Jehoṣafati. O ti ipasẹ Jahasieli, ọmọ Lefi kan ninu awọn ọmọ Asafu, akọrin, alohun-elo-orin, ati ẹni ti o kọ akọsilẹ diẹ ninu Psalmu sọrọ. Jahasieli sọ ọrọ yi si gbogbo Juda: “Bayi li OLUWA wi fun nyin, Ẹ máṣe bè̩ru, bẹni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọpọlọpọ enia yi; nitori ogun na ki iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun. ... ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala OLUWA lọdọ nyin.” Nigba ti wọn gbọ ọrọ imulọkanle, Jehoṣafati ati gbogbo eniyan naa sin Oluwa. Awọn ọmọ Lefi “dide duro, lati fi ohùn rara kọrin iyin soke si OLUWA Ọlọrun Israẹli.” Awọn eniyan wọnyi sin, wọn si yin Oluwa lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti ri ileri gba fun iranlọwọ ati idasilẹ. Wọn gbagbọ pe Ọlọrun lagbara lati mu eyi ti o ti ṣeleri ṣẹ.

Igbagbọ

Awọn ẹlomiran kun fun è̩ru to bẹẹ gẹ ti o jẹ pe a ni lati gba wọn la patapata ki wọn to le gbagbọ ki wọn si dupẹ lọwọ Ọlọrun. Ninu Bibeli a sọ fun wa pe “olododo ni yio ye nipa igbagbọ” (Heberu 10:38). A maa n wu Ọlọrun nigba ti a ba gbà A gbọ, nitori pe “nipa igbagbọ li awa nrìn, ki iṣe nipa riri” (II Kọrinti 5:7). Jesu wi fun awọn ọkunrin afọju kan pe, “Ki o ri fun nyin gẹgẹ bi igbagbọ nyin.” Oju wọn si là (Matteu 9:29, 30). Jesu wi pẹlu pe, “Ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ” (Marku 9:23).

Idasilẹ ati Ikogun

Jehoṣafati wi fun awọn eniyan naa pe ki wọn gba Oluwa gbọ pe wọn o ṣe rere. Wọn mura lati lọ si ogun, pẹlu awọn akọrin niwaju awọn ọmọ-ogun. Nigba ti wọn bẹrẹ si i kọ orin ti wọn si n yin Oluwa, wi pe, “Ẹ yin OLUWA; nitoriti ānu rè̩ duro lailai,” Oluwa bẹrẹ si ṣiṣẹ laarin awọn ọta. Ogun-ẹhin dide si wọn. Awọn ọta bẹrẹ si i ṣubu le ara wọn; “ẹnikinni nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji” titi gbogbo wọn fi kú, “ẹnikan kò sá asalá.”

Jehoṣafati ati awọn eniyan rè̩ ko ja ija kankan, sibẹ awon ni aṣẹgun. Wo o bi ogun yi ti yatọ to si eyi ti wọn gbẹkẹle eniyan ti a si fọn wọn ká. Ni akoko yi ogun naa jẹ ti Oluwa, ati ni ọna ti o ṣajeji a pa ogun ọta run. Ikogun inu ogun yi jẹ ti awọn ọmọ Juda. Ọpọlọpọ ikogun ni o wà, ati ohun-elo iyebiye eyi ti won kó fun ara wọn. Ki i ṣe kiki dida silẹ ni Ọlọrun da Juda silẹ nikan ṣugbọn o fi ọpọlọpọ ikogun fun wọn to bẹẹ ti o fi gbà woṅ ni ọjọ mẹta lati kó wọn.

Jehoṣafati ati awon eniyan rè̩ mọ riri ohun ti Ọlọrun ṣe fun wọn. Ki wọn to pada wale paapaa, wọn pejọ pọ lati dupẹ lọwọ Ọlọrun ati lati fi ibukun fun orukọ Rè̩. Lẹhin eyi wọn pada si ile pẹlu ayọ nitori pe Ọlọrun “ti mu wọn yọ lori awọn ọta wọn.” Nigbakuugba ti Ọlọrun ba ràn wa lowọ ti o si ran idasilẹ kuro ninu irora, idaamu, idanwo tabi ewu, a le yin In, o si yẹ ki a yin In lẹsẹkẹsẹ. Ko tọ ki a duro de igba isin agbole. Ko tọ ki a ṣẹṣẹ duro de igba ti a le lọ si ile-isin. Nibikibi ti a le wà, o yẹ ki a gbadura ọpẹ ati iyin si Ọlọrun. Oluwa le gbọ, i baa ṣe pe iyin wa jẹ eyi ti a kigbe soke ni ṣiṣe e tabi a sọ ọ kẹlẹkẹlẹ ninu ọkan wa. Nigba naa awa pẹlu yoo le pada si ile wa pẹlu ayọ.

Lai pẹ ọrọ bẹrẹ si tàn kalẹ kaakiri pe Ọlọrun ti ba awọn ọta Juda ja. Awọn eniyan naa bẹru Oluwa nitori pe wọn mọ pe O ti ṣiṣẹ fun awọn eniyan Rè̩. “Bẹni ijọba Jehoṣafati wà li alafia: nitoriti Ọlọrun rè̩ fun un ni isimi yikakiri.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni ṣe ti o fi dabi ẹni pe Jehoṣafati fẹran awọn ti o korira Ọlọrun?

  2. 2 Kin ni ṣe ti Jehoṣafati la gbogbo ilẹ Juda ja?

  3. 3 Bawo ni awọn onidajọ ṣe ni lati maa ṣe idajọ?

  4. 4 Lori oriṣi aye meji wo ni a yan awọn onidajọ si?

  5. 5 Kin ni ṣe ti Jehoṣafati kede aawẹ?

  6. 6 Kin ni aawẹ jẹ?

  7. 7 Nibo ni wọn pejọ pọ si lati gbadura?

  8. 8 Tani wọn gbẹkẹle fun idasilẹ?

  9. 9 Tani ja fun Jehoṣafati ati awọn eniyan rè̩?

  10. 10 Kin ni ṣe ti awọn eniyan naa yin Oluwa? Nigba wo ni wọn yin Oluwa?

2