I Awọn Ọba 19:19-21; II Awọn Ọba 2:1-18

Lesson 308 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn ti o si wà pẹlu rè̩ ti a pè ti a yàn, ti wọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu” (Ifihan 17:14).
Notes

Ipe Naa

Igba kan wà ni igbesi-aye olukuluku eniyan nigba ti Ẹmi Ọlọrun n ke pe e ni ẹnu-ọna ilẹkun ọkan rè̩. Ki i ṣe awọ ara eniyan, tabi iru iṣẹ ti o n ṣe, bi o ti lowo tabi bi o ti ṣe alaini to, tabi bi o ti dagba tabi bi o ti ṣe ọmọde to, ni o ṣe pataki. Bi eniyan ba ti dagba to lati mọ ohun ti o jẹ lati dẹṣẹ si Ọlọrun, Ẹmi Ọlọrun jẹ olootọ lati pe e ati lati jere ọkan rè̩ pada.

Ọmọdekunrin agbẹ kan gba ipe ti rè̩ ni ọjọ kan, nigba ti o n tulẹ ni papa. Malu mẹrinlelogun ni o n tulẹ ni oko bi Eliṣa ti n rin tẹle wọn laarin afo ti o wà laarin awọn ebe oko ti a ṣẹṣẹ n tulẹ rè̩ lọwọ yi. Lojiji awọn malu naa duro, Eliṣa jowọ ohun-itulẹ naa silẹ o si sure la papa naa ja. Eniyan Ọlọrun nì, Elijah ti rekọja, o si ti da agbada rẹ bo ọdọmọkunrin agbẹ yi. Bi agbada naa ti kan an, eyi mu ki Eliṣa fẹ lati fi awon malu naa silẹ, ati ohun itulẹ naa, oko naa ti ko i ti ro tan, ati baba ati iya rè̩, lati tẹle Oluwa.

Ẹmi Ọlọrun ha ti kan ilẹkun ọkan rẹ ri? O ha ti rò o wo ri pe o yẹ ki a gbà ọ la? O ha ti sare lọ si ibi pẹpẹ adura ni idahun si pipe ti Ẹmi n pe ọ?

Didagbere

A pa meji ninu malu naa a si se e lori ina ti a fi igi ohun elo itulẹ naa dá; ounjẹ idagbere ni a si yara pese silẹ; bẹẹ ni o si yara dagbere fun awọn obi ati awọn ọrẹ -- bẹẹ ni Eliṣa si gbagbe iṣẹ agbẹ titi lae. Iṣẹ titun n bẹ fun un lati ṣe.

Si Bẹtẹli

Elijah ti pari iṣẹ rè̩ ni aye, akoko naa si ti to ti Ọlọrun yoo mu un lọ si Ọrun (II Awọn Ọba 2:1). Oun pẹlu Eliṣa si bẹrẹ irin wọn lati Gigali wa. “Joko nihinyi,” ni Elijah wi, “nitoriti OLUWA ran mi si Bẹtẹli .” Pẹlu ipinnu ti o lagbara lati tẹle ọga rè̩, Eliṣa wi pe “Emi ki o fi ọ silẹ.” Bẹẹ, bẹẹ ni wọn n rin lọ. Eliṣa mọ pe lai pẹ a o gba Elijah kuro lọ si Ọrun, bẹẹ si ni iṣẹju kọọkan si ṣe iyebiye bi akoko ti n lọ -- ibusọ kọọkan ninu irin-ajo jijin tubọ n jẹ ọwọn fun un.

Nigba ti wọn de Bẹtẹli, awọn ọdọmọkunrin ti a n pe ni awọn ọmọ awọn woli, pe Eliṣa wọn si wi fun un pe, “Iwọ ha mọ pe OLUWA yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni?” Idahun rè̩ ni pe, “Bẹni, emi mọ, ẹ pa ẹnu nyin mọ.”

Lọ si Jẹriko

Eniyan Ọlọrun naa n rin lọ ni ọna Jẹriko, bẹẹ ni Eliṣa si n rin timọtimọ lẹgbẹ rè̩. Lẹẹkan sii, Elijah tun dan ipinnu ọdọmọkunrin yi wo, ẹni ti yoo gba ipo rè̩ lai pẹ lati maa ba iṣẹ rè̩ lọ. “Emi bẹ ọ, joko nihinyi: nitoriti OLUWA ran mi si Jọrdani.” Ki o ha joko ni Jẹriko pẹlu awọn ọmọ woli? Ki a fi i silẹ nigba ti Elijah ba n lọ? Ki o ha padanu ibukun ti o tobi ju lọ? Ki a ma ri i! “Emi ki o fi ọ silẹ!”

Si Jọrdani

Nikẹhin wọn de bebe Odo Jọrdani. Lokeere ni a ri aadọta ọkunrin ti ile-ẹkọ naa duro, wọn si n woye. Kin ni wọn ri? Kin ni Eliṣa ri? Kin ni awa naa ri, gẹgẹ bi a ti n ri aworan ohun ti o n ṣẹlẹ yi? Ẹni ọwọn, Elijah arugbo, mu agbada rè̩, o si lọ ọ lu, o si fi lu omi odo nla nla ti o n tu jade yi. Omi naa dawọ ṣiṣan rè̩ duro. Ilẹ gbigbẹ si han, awọn mejeeji si la odo naa kọja lori ilẹ gbigbẹ.

Nisinsinyi Eliṣa, a san an fun ọ pada fun titẹle e titi. Irin-ajo ọpọlọpọ mile ti o kun fun aarẹ ko ja si asan. O ti tun ri iṣẹ-iyanu ti agbara Ọlọrun eyi ti o ti bà le Elijah. S̩ugbọn ere nla miran ṣi tun n bẹ fun ọ sibẹ bi o ba le maa tọ ọ lẹhin si i.

Ibeere Ikẹhin

Nisinsinyi awọn ọkunrin mejeeji duro ni odi keji odo. Wakati Elijah ti to lati lọ si Ọrun. S̩ugbọn tani yoo maa ba iṣẹ naa lọ nihin? A ni lati mu awọn alaisan larada, ki a sọ fun awọn eniyan nipa Ọlọrun, ki awọn ẹni ti o ti ku tun ri iye. Tani yoo ja ogun wọnyi fun Oluwa ni ajaṣẹgun? Eliṣa mọ ohun ti oun n fẹ ati ohun ti oun ko le ṣai ni lati maa ba iṣẹ pataki naa lọ. O ni lati nii nitori naa nigba ti Elijah wi pe, “Bẽre ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ.” Eliṣa fi irẹlẹ dahun pe, “Emi bẹ ọ, jẹ ki iṣẹpo meji ẹmi rẹ ki o bà le mi.”

Wo iru ibeere ọlọgbọn yi. Kin ni ibeere miran ti o san ju eyi lọ? Iru ilepa wo ni eniyan i ba tun ni ju pe ki a fi iṣẹpo meji Ẹmi Ọlọrun wọ ọ? Njẹ o mọ pe o wà ni agbara gbogbo eniyan ti n bẹ ni aye loni lati ni ẹkun rẹrẹ Ẹmi ati agbara Ọlọrun? S̩ugbọn nigba ti a ba n beere fun Ẹmi Mimọ Ọlọrun ati ina pe ki a fi wọ wa, bakan naa ni gẹgẹ bi Elijah ti wi “Iwọ bẽre ohun ti o ṣoro.” Sibẹsibẹ awọn ti a ti gba ọkan wọn la, ti a si ti sọ ọkan won di mimọ, ti wọn si ṣe ifararubọ kikún, bi wọn ba beere pẹlu igbagbọ, wọn a maa ri ibukun nla yi gba ni igba ikẹhin ọjọ yi.

Kinni kan wa ti Eliṣa ni lati ṣe: “Bi iwọ ba ri mi nigba ti a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ fun ọ, ṣugbọn bi bẹẹ kọ, ki yio ri bḝ.” Eliṣa ti tọ ọ lẹhin de Bẹtẹli; o ti tọ ọ lẹhin de Jẹriko; ati lẹhin eyi titi de Odo Jọrdani. Eyi yi ki i ṣe akoko fun un lati mu oju kuro lara ọga rè̩. Ko le gbà pe ki o sọ ibukun yi nu lẹhin ti o ti ba a rin de ọna ti o jin to bayi.

Njẹ o ha jẹ ohun kekere fun awọn ti a ti gbala tabi ti a ti sọ di mimọ lati pada sẹhin? Njẹ o ha dara fun ẹni ti a ti sọ di mimọ lati ṣe alaibikita lati wa ẹkunrẹrẹ Ẹmi Mimọ? Lẹhin igba ti o ba si ti ri i gba tan, igba kan ha wa ti awọn Onigbagbọ le daba lati mu oju wọn kuro lara Oluwa ati Ọga wọn? Wọn ha le gba lati mu oju wọn kuro lara opin ire-ije wọn ti n bẹ niwaju? Wọn le padanu mimu lọ nipa Ipalarada bi wọṅ ba ṣe bẹẹ.

Kẹkẹ Ina

“Bi nwọn ti nlọ, nwọn nsọrọ.” A gbagbọ dajudaju pe ọrọ wọn jẹ nipa Oluwa ati Ọrun. Lojiji “kẹkẹ iná ati ẹṣin iná si là ārin awọn mejeji.” Iṣẹlẹ yi ko le ṣe e ṣe apejuwe rè̩, ṣugbọn a le fi ọkan ri aworan ogo nla nla naa. Lojiji gẹgẹ bi kẹkẹ iná ti fara han, bẹẹ gẹgẹ ni o yara ba aaja goke, ti a ko si ri i, Elijah si lọ si Ọrun, ọkan ninu awọn meji ti o lọ lati aye yi si Ọrun lai tọ iku wò. Ko si iku fun Elijah; ṣugbọn, gẹgẹ bi Enoku, “a kò si ri i, nitoriti Ọlọrun ṣi i nipò pada” (Heberu 11:5).

Lode oni nigba ti a ba mu awọn olufẹ wa lọ kuro ni ẹgbẹ wa, eyi a mu ki ọkan wa rẹwẹsi pupọ nitori iṣipopada wọn. Bi o tilẹ jẹ pe Eliṣa mọ pe a ni lati mu Elijah lọ si Ọrun ni ọjọ yi, sibẹsibẹ bi o ti n wo kẹkẹ iná naa, bi o ti n gbe ọga rè̩ lọ, ti o si parẹ sinu awọsanma, o ya Eliṣa lẹnu, nitori pe a ka a wi pe “o si di aṣọ ara rè̩ mu, o si fa wọn ya si meji.”

Agbada Naa

Agbada Elijah bọ silẹ lati ojusanmà. Eyi ni agbada nì ti o ti kan ara Eliṣa ni ọjọ nì lori papa: eyi ni agbada naa ti ọga rè̩ ti wọ; eyi ni agbada naa ti Elijah ti lọlu ti o si fi lu omi Odo Jọrdani. Nisinsinyi o di ti Eliṣa. Njẹ ọwọ rè̩ tẹ ohun ti o beere lọwọ ọga rè̩? Njẹ o ha ri iṣẹpo meji ẹmi Elijah gbà? Ẹ jẹ ki a wo o!

O pada lọ si eti bebe odo naa. Boya apa ẹsẹ Elijah, ẹni ti o ti lọ si Ọrun, han lori iyanrin. S̩ugbọn Ọlọrun Elijah wà sibẹ, nitori bi Eliṣa ti fi agbada nì lu omi naa, Oluwa kan naa dahun o si mu ki omi naa pinya. Eliṣa ko dá nikan wà bi o ti n la ọna naa kọja laarin omi. Oju rè̩ ko le ri Ẹni naa ti n ṣamọna rè̩ lọ, sibẹsibẹ oju ẹmi Eliṣa ko si lara ẹlomiran ju Oluwa Ọlọrun lọ. Agbada naa n bẹ lọwọ Eliṣa; agbara naa n bẹ pẹlu rè̩; o ti ri idahun si ibeere rè̩ gbà: “iṣẹpo meji” ẹmi Elijah.

Agbara iṣẹpo meji naa ṣe dandan fun Eliṣa lati ni, o si lo o pẹlu. O ṣe ọpọlọpọ iṣẹ-iyanu nlá, gẹgẹ bi a o ti kọ ninu awọn ẹkọ wa lọjọ iwaju. Bi o tilẹ je pe ki i ṣe gbogbo iṣẹ agbara nla ti a ṣe nipasẹ agbara Ọlọrun ni a kọ silẹ ninu Bibeli, a ri i ninu Ọrọ Ọlọrun pe ilọpo meji iṣẹ-iyanu ti a kọ silẹ nipa Elijah, ni a kọ silẹ pe Eliṣa ṣe.

Aigbagbọ

Awon ọdọmọkunrin, awọn ọmọ woli ti o wà ni Jẹriko woye pe ẹmi Elijah ba le Eliṣa. S̩ugbọn wọn bẹrẹ si ṣiyemeji bi Elijah lọ si Ọrun ni tootọ tabi bẹẹ kọ. Wọn bẹ Eliṣa pe ki o jẹ ki awọn lọ wá a lori awon oke ati ni afonifoji gbogbo. Eliṣa ko gba fun wọn lati lọ, ṣugbọn wọn rọ ọ, o si gbà fun wọn lati lọ. Fun ọjọ mẹta, awọn aadọta ọkunrin alagbara yi n wa a, ṣugbọn wọn ko le ri eniyan Ọlọrun yi, nitori pe o ti lọ si Ọrun.

Ipalarada

A o tun ri iriri yi lẹẹkan si i nigba ti Ipalarada ba ṣẹlẹ. Awọn ti o kù silẹ ki yoo gbagbọ pe a ti mu Iyawo Kristi lọ. Wọn o maa wa Iyawo Kristi kiri -- ṣugbọn lasan ni. Ki i ṣe kiki awọn oniwaasu ati woli Ọlọrun nikan ni yoo lọ soke nigba Ipalarada Ijọ, ṣugbọn gbogbo awọn ti wọn ti mura silẹ pẹlu fun bibọ Rè̩ nipa riri i pe a dari ẹṣẹ wọn ji, ati pe a sọ ọkan wọn di mimọ nipa È̩jẹ iwẹnumọ nì, ati riri ẹbun agbara gbà eyi ti a ri gba nigbà ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ wa. Bi iwọ yoo ba jẹ ọkan ninu wọn, maa tọ Jesu lẹhin timọtimọ. Ni ipinnu kan, gẹgẹ bi Eliṣa ti ni, “Emi ki o fi ọ silẹ.” Loni Iyawo Kristi n wọna fun bibọ Oluwa, a si le wà laarin awọn ti ki yoo ri iku, ṣugbọn “a o si gbà wa soke ... lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹli awa o si mā wà titi lai lọdọ Oluwa” (I Tẹssalonika 4:17).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Kin ni Elijah ṣe fun Eliṣa gẹgẹ bi o ti n tulẹ?

  2. 2 Sọ ohun ti Eliṣa ṣe lẹhin naa.

  3. 3 Iriri nla nla wo ni o n bọ wa ṣẹlẹ si Elijah?

  4. 4 Njẹ Eliṣa mọ nipa eyi? Kin ni ṣe?

  5. 5 Sọ nipa ipinnu rè̩ lati tẹle Elijah.

  6. 6 Kin ni ṣẹlẹ leti Odo Jọrdani?

  7. 7 Kin ni ohun ti Eliṣa beere lọwọ Elijah ki a to mu un lọ?

  8. 8 Bawo ni a ti ṣe mọ boya a ṣe eyi fun un tabi bẹẹ kọ?

  9. 9 Nipasẹ kin ni Elijah fi lọ si Ọrun?

  10. 10 Ẹri wo ni a ni pe ẹmi Elijah bà le Eliṣa?

2