Lesson 309 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Wò o, emi li OLUWA, Ọlọrun gbogbo ẹran-ara: ohun kan ha wà ti o ṣoro fun mi bi?” (Jeremiah 32:27).Notes
Agbara Ọlọrun lara Eliṣa
Agbara Ọlọrun ti bà le Eliṣa lẹhin ti Elijah ti lọ si Ọrun. Nisinsinyi iṣẹ wa fun un lati ṣe. Nigba ti Ọlọrun ba fun awọn eniyan Rè̩ ni agbara fun iṣẹ, O nireti pe wọn yoo ṣiṣẹ fun Oun. O fẹ ki wọn lo ohun ti O fi fun wọn, ki a ba le yin orukọ Rè̩ logo. Bi wọn ko ba ṣe bẹẹ, wọn o sọ agbara naa nu.
Iṣe ti Eliṣa ni lati ṣe ni lati ran awọn ẹlomiran lọwọ. Ọlọrun ti fi awọn eniyan Rè̩ sinu aye yi lati ran awọn ti o wa ni ipo aini lọwọ ati lati fi han wọn ọna naa ti a le fi gba wọn la kuro ninu ẹṣẹ. Jesu fi han wa bi a ti ṣe le gbe igbesi-aye wa. O lo aye Rè̩ lati fi ran ẹlomiran lọwọ.
A Wo Omi naa San
Ni Jẹriko, nibi ti Eliṣa n gbe, a ti sọ omi ti wọn n lo nibẹ di ibajẹ. Eniyan ko le gbe lai si omi, nitori eyi ilu naa wa ni ipo ti o ṣoro pupọ. Anfaani ni eyi fun Eliṣa lati ṣe iranlọwọ, bẹẹ ni o dabi ẹni pe awọn eniyan ilu naa woye pe o le ran wọn lọwọ. Wọn wa wọn si sọ fun un pe Jẹriko jẹ ilu ti o dara lati maa gbe inu rè̩, ṣugbọn kin ni awọn eniyan ti ṣe le wa lai si omi?
Eliṣa beere fun ikoko iyọ kan. Kin ni o le fi iyọ ṣe? Awọn eniyan a maa kú bi wọn ba mu omi iyọ pupọ. Omi iyọ yoo ba ilẹ jẹ to bẹẹ ti eso oko ko ni le hù. Njẹ Eliṣa ha mọ ohun ti o n ṣe? Yoo ha tun ba omi naa jẹ ju bi o ti ri tẹlẹ ri lọ? O yẹ ki awọn eniyan Jẹriko wi bayi pe: “Eliṣa ko ni ọgbọn to bi a ti lero pe o ni. Dajudaju iyọ ko le ṣe iranlọwọ fun wa.” Wọn ko tilẹ bi Eliṣa leere ohun kan, ṣugbọn wọn mu iyọ ti o beere wa fun un. Eliṣa da iyọ naa si ibi orisun omi naa; omi naa si dara fun lilo. Lati igba yi lọ, ilẹ naa si ṣe rere pẹlu ọpọlọpọ omi didara.
Lọna ti a n gba lo iyọ, ko si bi iyọ le ti pọ to ninu omi naa ti o le sọ ọ di mimọ. Ọlọrun ni o ṣiṣẹ nipasẹ Eliṣa, nigba ti awọn eniyan naa gbọran si aṣẹ Eliṣa. Ọlọrun n fẹ igbọran ninu ọkan awon eniyan Rè̩. “Bi ẹnyin ba fé̩ ti ẹ si gbọran ẹnyin o jẹ ire ilẹ na” (Isaiah 1:19).
Ọwọ fun Awọn Àgba
Eliṣa ti mu inu awọn ara Jẹriko dùn, ko si tun ni ohun miran lati ṣe fun wọn mọ, nitori eyi o fi ibẹ silẹ lati lọ si Bẹtẹli. Loju ọna o pade ẹgbẹ awọn ọmọde kan ti wọn n fi ṣe yẹyẹ nitori pe apari ni. Eyi yi jẹ ohun ailọwọ gidigidi lati ṣe. Bi wọn ko tilẹ mọ pe eniyan Ọlọrun ni i ṣe sibẹ o yẹ ki wọn bọla fun un gẹgẹ bi agba. A ka ninu Bibeli pe, “Ki iwọ ki o dide duro niwaju ori-ewu, ki o si bọwọ fun oju arugbo” (Lefitiku 19:32). Peteru sọ fun wa pe, “Ẹ ni ifẹ ara, ẹ mā ṣe iyọnu, ẹ ni ẹmi irẹlẹ” (I Peteru 3:8). Inu Jesu a maa dùn si wa nigba ti a ba n bọla fun ifẹ awọn ẹlomiran, ti a si n ṣe si wọn bi a ti n fẹ ki awọn ẹlomiran ṣe si wa.
Eliṣa ke pe Ọlọrun lati fi iya jẹ awọn ọmọ buburu yi. Bẹẹ ni beari meji si jade lati inu igbo wá eyi ti o pa mejilelogoji ninu wọn. Eyi yi rekọja ibawi lati kọ awọn ọmọde lati bọla fun awọn agba. O fi han pẹlu pe idajọ yoo wá sori gbogbo awọn ti o ṣe alaibọwọ fun awọn eniyan Ọlọrun. A le ṣalai ri beari ki o jade lati inu igbo lati pa awọn ti n fi awọn Onigbagbọ ṣe ẹlẹya, ṣugbọn idajọ ikẹhin yoo buru pupọ bakan naa bi wọn ko ba ronupiwada.
Eto Jehoramu fun Iṣẹgun
Ni akoko yi, Jehoramu Ọba ni o n jọba lori Israẹli, ẹni ti i ṣe ọmọ Ọba buburu nì, Ahabu. Ko buru to bi baba rè̩ ti buru, sibẹ oun pẹlu ki i ṣe ọba rere. O ti pa ere Baali run ṣugbọn ko mu awọn ere wura ẹgbọrọ malu ti Israẹli n bọ kuro. Inu Eliṣa i ba dun lati ran an lọwọ lati mu ohun aimọ kuro ni ilẹ naa, ki o si yi gbogbo Israẹli pada si sisin Ọlọrun otitọ, ṣugbọn Jehoramu ko beere lọwọ rè̩.
Ọba Moabu ti maa n san owo-ode fun Ọba Israẹli; ṣugbọn nisinsinyi ti iyipada ti wà ninu Ijọba, o ro pe oun ti ri aye lati bọ kuro ninu isinru naa. S̩ugbọn Jehoramu ko fẹki ọpọlọpọ ọrọ yi ki o bọ kuro lọwọ oun, nitori naa o pinnu lati lọ si ogun lati fi Moabu sabẹ igbekun sibẹ. Nitori pe awọn ọmọ-ogun Israẹli ko lagbara to lati lọ da ja, Jehoramu bẹ Jehoṣafati, Ọba Juda, lati wa ṣe iranlọwọ fun oun.
Igbọjẹgẹ Jehoṣafati
Jehoṣafati jẹ Ọba rere; bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan rè̩ jẹ ibatan awọn Ọmọ Israẹli sibẹ ko ni ẹtọ lati gbọjẹgẹ fun ọba Israẹli ti i ṣe ẹlẹṣẹ. S̩ugbọn o ṣe bẹẹ. O wi fun Jehoramu pe: “Emi o goke lọ: emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ati ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.” Jehoṣafati n lọ lati kẹgbẹ pọ pẹlu ẹlẹṣẹ, Ọlọrun ki yoo si bukun fun un.
Wọn pinnu lati gba ọna iju Edomu lọ ni ọna wọn si Moabu ki wọn ba le gba iranwọ lọdọ Ọba Edomu. Wo o bi awọn ọba mẹtẹẹta ti ro pe wọn ni agbara to nigba ti wọn kó awọn ọmọ-ogun wọn lọ si ọna si Moabu! Nkan kan ha wà ti o le da iru ẹgbẹ ogun alagbara bayi duro! Ọlọrun le ṣe bẹẹ.
Ko si Omi
Lẹhin irin ọjọ meje, awọn ẹgbẹ ogun nla yi de ibi kan ti ko si omi. Ko ṣe e ṣe fun eniyan tabi ẹranko lati wà pẹ lai si omi. Nisinsinyi kin ni yoo ṣẹlẹ si awọn ọba agberaga wọnyi ati ọpọlọpọ ọmọ-ogun wọn! Wọn o ha ku fun oungbẹ pẹlu awọn ẹran wọn? Wo o bi ọmọ-eniyan ti ṣe alailagbara to nigba ti ko ba ni iranlọwọ Ọlọrun!
Ọba Israẹli kigbe pe: “O ṣe! ti Oluwa fi pe awọn ọba mẹtẹta wọnyi jọ, lati fi wọn le Moabu lọwọ!” S̩ugbọn ki i ṣe Ọlọrun ni o pe awọn ọba wọnyi jọ. Ọwọ ara wọn ni wọn fi fa a. Ọlọrun ki i pe awọn eniyan Rè̩ lati ba ẹlẹṣẹ dimọ pọ. Jehoramu ti ṣe gbogbo eto ogun yi lai beere fun amọran lọdọ Ọlọrun, ko tilẹ ba Eliṣa sọrọ paapaa. Nisinsinyi nigba ti o bọ sinu wahala o n da Ọlọrun lẹjọ. Wo o bi o ti maa n ṣẹlẹ ni ọpọlọpọ igba nigba ti ẹni kan ba taku lati gba ọna ti ara rè̩, nigba ti o ba si bọ sinu iṣoro a fẹ lati di ẹru naa le ẹlomiran lori – o le da Ọlọrun paapaa lẹbi!
A Mọ Woli Naa
Jehoṣafati ti yapa kuro ninu ọna tootọ, ṣugbọn o mọ ibi ti o le lọ nigba ti o bọ sinu wahala. O beere fun Woli Ọlọrun otitọ, nigba ti ẹni kan si sọ fun un nipa Eliṣa, o wi pe, “Ọrọ OLUWA mbẹ pẹlu rè̩.” O mọ ẹni ti i ṣe Woli otitọ ni Israẹli o si ṣe tan lati tẹti si amọran rè̩. S̩ugbọn nigba ti a pe Eliṣa, o wi fun Jehoramu pe, “Ba ara rẹ lọ sọdọ awọn woli baba rẹ, ati awọn woli iya rẹ.” Jehoramu jẹ ẹni ti o n sin oriṣa nigba ti ohun gbogbo n lọ deedee fun un, o si ti kọ Ọlọrun otitọ silẹ patapata. Jẹ ki awọn ere nì ran an lọwọ nisinsinyi bi wọn ba le ṣe e. Eeṣe ti o fi duro de igba ti o bọ sinu iyọnu ki o to wa Ọlọrun?
A dupẹ pe Ọlọrun jẹ alaanu lọpọlọpọ ati pe yoo gbọ adura iru eniyan bẹẹ bi o ba tọ Ọ wa ni ironupiwada. S̩ugbọn o dara jù lati jẹ ọrẹ Ọlọrun ki wahala to de, to bẹẹ ti o jẹ pe nigba ti a ba bọ sinu wahala lojiji ti a si n fẹ iranlọwọ Rè̩ a le gbadura pẹlu igboya. A ni ileri naa pe yoo tọju ti Rè̩, bẹẹ ni Oun ki yoo yipada kuro ninu Ọrọ Rè̩.
Jehoramu bẹ Eliṣa lati gbadura fun oun. O mọ nisinsinyi pe lai si iranlọwọ Ọlọrun, gbogbo wọn yoo di oku eniyan lai pẹ.
Wíwà Iho
Eyi yi ni iranṣẹ lati ọdọ Ọlọrun: “Wà iho pupọ li afonifoji yi ... Ẹnyin kì yio ri afẹfẹ, bẹni ẹnyin ki o ri òjo; ṣugbọn afonifoji nā yio kún fun omi, ki ẹnyin ki o le mu, ati ẹnyin, ati awọn ẹran-ọsin nyin, ati ẹran nyin.” Wọn yoo ri omi -- ọpọlọpọ omi. S̩ugbọn wọn ni lati ṣiṣẹ fun un. Wọn ni lati wa awọn iho. Lati wa koto jẹ iṣẹ ti o nira, paapaa nigba ti wọn n kú lọ fun oungbẹ. Wọn ni lati wa iho tabi ki wọn kú. Ọlọrun ko fẹ iranlọwọ wọn ki O to le ran omi si wọn, ṣugbọn O mọ pe o dara fun wọn lati ṣe ohun kan. Bẹẹ ni O si fẹ lati wo bi wọn o gbọran si aṣẹ Oun.
Ohun Kekere
Gẹgẹ bi o ti maa n ṣe ki ojo to rọ a maa n kiyesi pe afẹfẹ a maa gbe ikuuku kọja ni ọna wa. Tabi bi a ko ba tilẹ fiyesi eyi, a le rii bi ikuuku ti n wọ kọja. Nigba miran afẹfẹ a maa fẹ omi dà si oju ọna lati inu adagun tabi odo ṣiṣan. S̩ugbọn Ọlọrun ki yoo lo afẹfẹ rara ni akoko yi. Omi naa yoo deedee ṣan sinu awọn koto naa, lai si iranlọwọ kankan. Ọlọrun wi pe “Ohun kikini si li eyi loju OLUWA.” Ọlọrun naa ti o da omi, dajudaju O le dari diẹ ninu rè̩ sinu ilẹ aṣalẹ alailọra. Ohun kinnkinni ni eyi fun Ọlọrun, ṣugbọn ṣiṣe eyi nikan ṣoṣo ni a le fi gba ẹmi awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun ilu mẹtẹẹta yi là lati inu iku si iyè.
Ọlọrun tun wi ni igba miran pe, “Ohun kan ha wà ti o ṣoro fun mi bi?” (Jeremiah 32:27). Ohun kan ha wà ti Ọlọrun ko le ṣe? Nigba ti a ba n gbadura si I, njẹ a ha n sọ ẹdun wa fun Un pẹlu idaniloju nì pe a mọ pe Ọlọrun le ṣe ohun gbogbo? Nigba ti a ba bẹ Ẹ pe ki O wo ara wa san, njẹ a ha n ranti pe ohun kinnkinni ni fun Un lati ṣe?
Ronu bi Ọlọrun ti ṣe dahun adura Jobu. Nitori pe Jobu gba ileri Ọlọrun gbọ ni. Ohun ti Jobu wi niyi: “Emi mọ pe iwọ le ṣe ohun gbogbo, ati pe ko si iro-inu ti a le ifasẹhin kuro lọdọ rẹ” (Jobu 42:2). Ọlọrun mọ ohun ti a n ro, nigba ti ẹlomiran ko mọ ọn. Bi Ọlọrun ba le ṣe eyi nì, njẹ ohun kan ha wà ti ko le ṣe?
Oorun Lori Omi
Omi ṣan sinu awọn koto naa, gẹgẹ bi Ọlọrun ti wi pe yoo ri. Nigba ti oorun yọ ti o si ràn lori omi naa, awọn ara Moabu ro pe ẹjẹ ni. Wọn ro pe wahala ti wà ninu agọ awọn Ọmọ Israẹli, ati pe awọn ọmọ-ogun naa ti pa ara wọn. Wọn ro wi pe awọn le wọ inu agọ Israẹli lọ ki wọn si ko ohun gbogbo ti awọn Ọmọ Israẹli ti fi silẹ.
Wo o bi o ti jẹ iyanu fun wọn to nigba ti wọn wọ inu agọ awọn Ọmọ Israẹli ti wọn ba awọn ọmọ-ogun ninu imurasilẹ pẹlu gbogbo agbara lati jagun! Olukuluku ni o ti di ihamọra ti o si wà ni imurasilẹ lati jagun. Awọn ara Moabu yipada wọn si sa, awọn Ọmọ Israẹli si lepa wọn. Wọn le awọn ara Moabu titi de inu ilu wọn, wọn pa ilu naa run, wọn si di gbogbo kanga omi, wọn si bé̩ gbogbo igi rere, wọn si tun ju okuta si gbogbo oko wọn. Nigba ti ọba Moabu ri ilu rè̩ bi a ti pa a run, o si tun gbiyanju lati gbogun ti ọba Edomu pẹlu awọn ọmọ-ogun diẹ, ṣugbọn ko ri agbara kan sa lati le bori.
Bayi ni Israẹli ni iṣẹgun nigba ti wọṅ ke pe Ọlọrun fun iranlọwọ. Nigba ti wọn wà nikan wọn jẹ alai ni oluranlọwọ, wọn si ṣe tan lati kú; pẹlu Ọlọrun wọn lagbara lati ṣẹgun ọta wọn, ki wọn si pa a run tuutu. Ẹ jẹ ki a ranti pe, pẹlu Ọlorun ni iha wa, a le bori gbogbo agbara Satani.
Questions
AWỌN IBEERE1 Fun idi wo ni Eliṣa fi gba agbara Ọlọrun?
2 Kin ni iṣẹ iyanu kinni ti Eliṣa ṣe lẹhin ti o kọja odo Jọrdani?
3 Kin ni Bibeli sọ nipa awọn ti n fẹ lati ṣe, ti wọn si gbọran?
4 Kin ni ṣẹlẹ si awọn ọmọde ti o fi Eliṣa ṣe ẹlẹyà?
5 Ẹkọ wo ni a ri kọ lara ijiya awọn ọmọde wọnyi?
6 Tani n jọba ni Israẹli ni akoko yi? Iru ọba wo si ni?
7 Kin ni ṣe ti o fẹ lọ ba Moabu jagun?
8 S̩e apejuwe eto ti ọba Israẹli ṣe lati ṣẹgun Moabu.
9 Kin ni mu ki eto rè̩ kuna?
10 Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli ti ṣe bori ninu ogun naa nikẹhin?