Lesson 310 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọn si àiya nyin” (Luku 6:38).Notes
Obinrin Opo Kan ninu Wahala
Nipasẹ awọn iṣẹ iyanu ti o ti ṣe nipa igbagbọ ninu Ọlorun, Eliṣa ti fi han gbogbo eniyan pe eniyan Ọlọrun ni oun i ṣe. Bi awọn eniyan ba wà ninu iyọnu wọn mọ ibi ti wọn le lọ fun iranlọwọ.
Opo kan wà ninu wahala. Ọkọ rè̩, ẹni ti i ṣe ọkan ninu awọn woli ni ile-ẹkọ awọn woli ti Eliṣa i ṣe olori, ti kú o si fi i silẹ lai ni kọbọ lọwọ. Nigba ti a fẹ lati ta awọn ọmọ rè̩ nitori gbese, o kigbe tọ Eliṣa fun iranlọwọ. Eliṣa ko ni owo. Oun n lo igbesi-aye rè̩ lati ṣiṣẹ fun anfaani awọn ẹlomiran, ko si ni àye lati to ọrọ jọ ni ayé. S̩ugbọn eyi ko ni ki o ṣe alai le ran obinrin yi lọwọ. Eliṣa ni ohun kan ti o ṣe iyebiye pupọ ju owo lọ. O ni igbagbọ ninu Ọlọrun. O si ṣe tan lati lo ohun-kohun ti o ni lati fi ran opo naa lọwọ.
Jakọbu Apọsteli kọ ọ silẹ pe “Isin mimọ ati ailẽri niwaju Ọlọrun ati Baba li eyi, lati mā bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati lati pa ara rè̩ mọ lailabawọn kuro li aiyé” (Jakọbu 1:27). Awọn ẹlomiran a maa ṣọra gidigidi lati pa ara wọn mọ lailabawọn kuro ni aye, ṣugbọn wọn rò pe awọn ko laye to lati bẹ awọn alaini wo. Eliṣa ni iru “isin mimọ” naa. Opó naa tọ ẹni ti o tọ wá fun iranlọwọ.
Ororo Naa n Pọ Síi
Gbogbo ohun ti opó yi ni ninu ile rè̩ ko ju ikoko ororo kan. Eyi ko si to nkan; bi o ba ta a ki yoo mu ju owo diẹ wa fun un. S̩ugbọn Ọlọrun n bọ wa bu si ororo naa lati fi agbara Rè̩ han, gẹgẹ bi O ti bu si ororo opó nì ti o fi ounjẹ bọ Elijah nigba ti ebi n pa gbogbo eniyan.
A ran awọn ọmọ opó naa lati yá gbogbo ikoko ofifo ati paanu, ati koroba ti wọn le ri gba lọdọ awọn aladugbo wọn. Boya o n ya opó naa lẹnu bi o ti n ro nipa ohun ti Eliṣa fẹ fi awon ohun elo ofifo naa ṣe. S̩ugbọn o gbọran si aṣẹ eniyan Ọlọrun naa, lai pẹ o si ri ohun ti igbọran rè̩ le mu wa fun un. Pẹlu awọn ọmọkunrin rè̩ meji nikan, opó yi ṣe ohun ti Eliṣa ni ki o ṣe. O bẹrẹ si i da ororo naa lati inu ikoko kekere ti rè̩ sinu ikoko ofifo kan. Nigba ti ikoko nla kan ba kún, yoo wo inu ikoko ti ọwọ rè̩, bẹẹ ni o si kun gẹgẹ bi o ti wà tẹlẹ. Nibo ni gbogbo ororo naa ti wá? O dà a sinu ikoko miran, lai pẹ eyi pẹlu kún; ati omiran ati omiran. Sibẹ ikoko ọwọ rè̩ kún fun ororo gẹgẹ bi ti igba iṣaaju.
Dajudaju iṣẹ iyanu Ọlọrun ni eyi. Ororo naa n ṣàn jade titi gbogbo ikoko ti o wà ninu ile naa fi kún. Nigba yi ni ororo naa to dẹkun lati maa ṣan jade. Wọn sare lati lọ sọ fun Eliṣa nipa ohun ti o ṣẹlẹ. Ko jẹ iyalẹnu fun un. O mọ ohun ti Ọlọrun le ṣe. Eliṣa ni igbagbọ; obinrin naa gbọràn; Ọlọrun si mu ibisi wá. Eliṣa ran opó naa lọ lati ta ororo naa ti o ni; bẹẹ ni owo naa to lati san gbogbo gbese rè̩, o si tun ni owo sibẹ ti o to fun ara rè̩ ati fun awon ọmọkunrin rè̩ lati ná.
Ororo ti Ẹmi
Awa pẹlu le mu ikoko ofifo wá sọdọ Oluwa ki o le kun un. A le jọwọ ara wa gẹgẹ bi ikoko ofifo, ki Ororo Ẹmi Mimọ ba le ṣan sinu aye wa. S̩ugbọn ikoko naa ni lati ṣofo, ki o má ṣe si ilepa ati ifẹ-inu ti wa ninu rè̩ mọ. Boya ikoko ẹni kan kan fun igberaga, tabi ifẹ awọn ohun aye yi, tabi ifẹ owo. Ẹmi Ọlọrun ki yoo da pọ mọ awọn nkan bawọn nì.
Gbogbo ifẹ ti ara ni lati kuro ninu wa, Ẹjẹ Jesu ni lati fọ wa mọ nipa isọdi-mimọ, nigba naa ni a ṣe tan fun Ororo Ẹmi lati ṣan wa sinu aye wa. Yoo ṣan lọpọlọpọ bi a ba jọwọ ara wa patapata fun Oluwa.
Ikini-kaabọ fun Eniyan Ọlọrun
Ni ọna ti Eliṣa n ba kọja bi o ti n lọ ni ẹnu iṣẹ rè̩ fun Oluwa ni awọn ẹbi kan ti o fẹran Ọlọrun n gbé, awọn ti o ni inudidun lati gba Eliṣa ni alejo sile wọn. Wọn kà a si iwa ọmọluwabi lati gba ẹnikẹni ti o n kọja lọ si ile wọn bi o ba ṣe alẹ ti o si n fẹ ibi kan lati wọ si. S̩ugbọn nigba ti iyawo ile naa kiyesi i pe Eliṣa jẹ eniyan Ọlọrun, o pese yàra kekere kan silẹ pẹlu ibusun ati tabili, ati fitila sibẹ ki o ba le ni itura nigbakuugba ti o ba wọ si ọdọ wọn. O fẹ lati ṣe iṣẹ isin kekere yi bi i fun Oluwa.
Ọkan rẹ ha ṣipaya to bẹẹ ti o le pe Olugbala lati wọle lati maa gbe ibẹ? O ha ni aye kan fun Un to bẹẹ ti o fi ṣe tan lati gba A sile nigbakuugba? Jesu ki yoo fi agbara ti ara Rè̩ mu ẹnikẹni lati gbà A; ṣugbọn ayọ Rè̩ pọ pupọ lati ri ọkan kan ti o mura silẹ fun Un, nibi ti aye n bẹ fun Un nigba gbogbo, nibi ti iṣẹ ki i ṣe idiwọ fun eniyan lati ni ki O wọle. Oluwa a maa bukun fun ni nigba ti O ba wọle lati ba wa gbe.
Ère Obinrin Naa
Eliṣa mọ riri ifẹ ti a fi hàn fun un ninu ile kekere yi, o si fẹ lati ṣe ohun kan fun awọn eniyan ti wọn ṣe oninuure bẹẹ si i. O beere lọwọ obinrin naa bi o ba fẹ ki a sọrọ oun fun ọba, tabi ki oun lo ayè rè̩ lati fi wa ojurere kan fun un. S̩ugbọn o ni itẹlorun nibi ti o wà nitori pe o n gbe laarin awọn eniyan rè̩, bẹẹ ni ko ni ojurere kan lati beere. Sibẹ Eliṣa fẹ ran an lowọ. Boya Gehasi ti ba awọn ẹbi naa lo timọtimọ ju ti Eliṣa lọ, nitori pe o mọ pe o jẹ ẹdun ọkan wọn gidigidi lati ni ọmọkunrin kan; nitori naa Eliṣa pe obinrin naa o si wi fun un pe o n bọ wa di iya ọmọ. Ko ka ọrọ rè̩ si otitọ bẹẹ ni ẹdun ọkan rè̩ yi jẹ ohun ti o tobi fun un to bẹẹ ti ko ka a si ọrọ ti a le fi ṣe yè̩yẹ. O da a lohun pe, “Bẹkọ, oluwa mi, iwọ enia Ọlọrun, maṣe purọ fun iranṣẹbinrin rẹ.” S̩ugbọn otitọ ni Eliṣa n sọ, lai pẹ jọjọ o si ni ọmọkunrin kan. Iwọ ro o wò bi Eliṣa ti n mu inu awọn eniyan ti o n ba pade dun to! Ibikibi ti o ba lọ ẹni kan yoo ri ohun rere gbà nipasẹ ibẹwo rè̩.
Iku Ọmọ Naa
Lẹhin ọdun ti o niye, nigba ti ọmọ naa dagba, o lọ si oko nibi ti baba rè̩ n ṣiṣẹ pẹlu awọn olukore. Lojiji ni irora ti o nira de si i ninu ori rè̩, a si gbe e pada lọ si ile. O si kú. Wo o bi iru idagiri ibanujẹ naa yoo ti pọ to fun iya rè̩ ẹni ti o ti ni ayọ ti o pọ bẹẹ lori ọmọkunrin rè̩ fun iye ọdun wọnyi! Omọkunrin rè̩ ti kú -- ṣugbọn igbagbọ rè̩ ko kú.
Iya ti o kun fun ibanujẹ yi sare tọ Eliṣa lọ fun iranlọwọ. O ri i bi o ti n bọ o si ran ọmọ-ọdọ rè̩ lọ pade rè̩. O ri i pe obinrin naa wà ninu wahala ṣugbọn Ọlọrun ko fi han fun un. Obinrin yi ko saa ni itẹlọrun lati ba ọmọdọ ni sọrọ. O wa lati ri eniyan Ọlọrun nì, bẹẹ ni ko duro titi o fi de ọdọ rè̩. Bi o ti kunlẹ lẹsẹ Eliṣa, o dabi ẹni pe ibanujẹ rè̩ pọ pupọ jù fun un. O ti n bẹru pe ayọ nla ti oun ti ni le pari si ijatilẹ. Ibanujẹ rè̩ nisinsinyi pọ jù igba ti ko ni ọmọ lọ. Eliṣa fi ọpa rè̩ le Gehasi lowọ o si ran an si ọmọkunrin ti o kú naa, ṣugbọn iya rè̩ ko jẹ fi Eliṣa silẹ. O mọ pe agbara Ọlọrun n bẹ lara Eliṣa, ṣugbọn ko le sọ dajudaju nipa ti Gehasi.
Eliṣa gba lati ba a lọ. Loju ọna wọn pade Gehasi bi oun ti n pada bọ o si wi pe ni tootọ omọ naa kú. S̩ugbọn Ọlọrun tun fẹ ṣe iṣẹ-iyanu kan. Ninu yara kekere nì ti obinrin naa ti pese fun Eliṣa ni a tẹ ọmọ naa si lori ibusun Eliṣa. Eliṣa bẹrẹ si gbadura. Elijah ti ji ọmọkunrin kan ti o kú dide ri, Eliṣa ko ha si ti gba iṣẹpo meji agbara ti o wà lara Elijah? Dajudaju Ọlọrun yoo ṣe iṣẹ-iyanu miran nipasẹ iranṣẹ Rè̩ olootọ yi. Bi Eliṣa ti na ara rè̩ sori ọmọ naa, o ri i pe ara ọmọ naa gbona. Ẹmi ìye ti pada sara ọmọ ti o kú naa. Wo o bi eyi ti jẹ ọjọ ayọ to ni ile yi nigba ti Ọlọrun fi agbara Rè̩ han!
Ajara Igbẹ ti o ni Majele
Bi Eliṣa ti n lọ kaakiri ninu iṣẹ rè̩ o tun pada wá si ile-ẹkọ awọn woli ni Gilgali. Awọn akẹkọ nihin ti wà ninu iṣoro kan nitori pe ọdá wa ni ilẹ naa. Ki wọn ba le ri ounjẹ jẹ, awọṅ diẹ ninu wọn ti lọ wa ewebẹ ninu igbo, wọn si ti ka eso ajara-igbẹ ti o ni majele ninu. Nigba ti wọn bẹrẹ si jẹun, wọn woye pe oró majele naa bẹrẹ si i mu wọn. Lẹẹkan si Eliṣa n bẹ ni tosi lati ràn wọn lọwọ. Njẹ ohun rere ha kọ ni pe Eliṣa a maa wà ni tosi nigbakuugba ti awọn eniyan ba n fẹ iranlọwọ rè̩? Oluwa wa nitosi nigbakuugba ti awa pẹlu ba n fẹ iranlọwọ Rè̩, bi a ba gbe igbesi-aye ti o wu U ti a si bẹ Ẹ pe ki o wá gbe inu wa. Eliṣa sọ fun awọn ọdọmọkunrin woli wọnyi pe ki wọn dà iyẹfun diẹ sinu ikoko naa ati pe ohun gbogbo yoo lọ deedee. Wọn ṣe bẹẹ, bẹẹ ni wọn si pari ounjẹ wọn lai sewu.
Akara naa n Pọ Si i
Ọlọrun n pese fun awọn woli Rè̩ nigba ti eso oko ko ṣe deedee mọ. Ọkunrin kan wa lati fun Eliṣa ni ogun iṣu akara ati ṣiiri ọka diẹ. Awọn iṣu akara naa kere, boya ko tilẹ ju eyi ti Eliṣa le nikan jẹ tan, ṣugbọn o n fẹ ki awọn ọmọkunrin ti ebi n pa wọnyi pẹlu jẹ ninu rè̩. O ni ẹmi ti o n fẹ lati fi fun ẹlomiran. Jesu wi pe, “Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara akìmọlẹ, ati amipọ, akúnwọsilẹ, li a o wọn si aiya nyin” (Luku 6:38).
Gehasi ro pe eyi ti kere ju lati gbe siwaju ọgọrun eniyan, ṣugbọn Eliṣa sọ fun un pe ki o gbe e kalẹ ki o si gbọran nitori pe Ọlọrun ti ṣeleri pe yoo to; ati pe diẹ yoo ṣẹku silẹ pẹlu. Nigba ti a bẹrẹ si i pin akara yi, wọn n pọ sii gẹgẹ bi iṣu akara marun ati ẹja wẹwẹ meji ti ri, eyi ti Jesu fi bọ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan. Gbogbo awọn ọgọrun ọkunrin nì ni o jẹ ajẹtẹrùn. Bẹẹ ni diẹ si ṣẹku silẹ pẹlu, gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣeleri.
Eliṣa ko ṣiyemeji ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi a ti ri i. Bi Ọlọrun ba sọrọ, yoo ri bẹẹ dandan. Ọlọrun yoo ṣe ju eleyi lọ fun wa bi a ba le gba A gbọ pẹlu igbagbọ kan naa ti Eliṣa ni. Ọlọrun ti fun wa ni ọpọlọpọ ileri; bi a ba si le mu iduro wa lori wọn, ki a jọwọ ara wa patapata fun Un ki a si gbagbọ, awa pẹlu yoo gbadun awọn ibukun Ọlọrun.
Questions
AWỌN IBEERE1 Kin ni wahala ti obinrin opó naa ni?
2 Tani o tọ lọ fun iranlọwọ?
3 Kin ni opó naa ni ninu ile? Ọna wo ni a si gba lo o lati ran an lọwọ?
4 Kin ni ororo n ṣe apẹẹrẹ rè̩ ninu Bibeli?
5 Ọna wo ni a le fi ni Ororo yi ninu aye wa?
6 Ère wo ni a fun obinrin naa ti o pese yara kan fun Eliṣa?
7 Ọna wo ni Eliṣa gba ran an lọwọ lẹhin eyi?
8 S̩e alaye ohun ti o ṣẹlẹ nipa eso ajara-igbẹ ti o ni majele ninu?
9 Kin ni Eliṣa ṣe si iṣu-akara ati ṣiiri ọka ti a mu wa fun un?
10 Kin ni ṣe ti Eliṣa le ṣe iṣẹ-iyanu fun Ọlọrun?