II Awọn Ọba 5:1-27

Lesson 311 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitori ero mi ki i ṣe èro nyin, bḝni ọna nyin ki iṣe na mi, li Oluwa wi” (Isaiah 55:8).
Notes

Olori-ogun Kan

A ti kọ ẹkọ pe awọn Ọmọ Israẹli ati awọn ara Siria ti gbe ogun ti ara wọn ni iye igba. Ninu ọkan ninu awọn ogun yi awọn ara Siria mu ọmọbinrin Israẹli kan ni igbekun. A mu un lọ si ile Naamani, nibi ti o di ọmọ-ọdọ, o si n duro niwaju iyawo Naaman.

Naamani jẹ eniyan pataki ni ilẹ Siria. Ọba ti fi jẹ olori gbogbo ogun. Naamani jẹ akọni ọkunrin, o si ti ṣe iṣẹ rè̩ daradara. Awọn eniyan naa bọla fun un nitori ire ti o ṣe fun orilẹ-ede rè̩. O jẹ eniyan nla niwaju ọba nitori pe Oluwa ti ran Naamani lọwọ lati mu iṣegun wa fun ilẹ Siria.

A le ro pe Naamani ati awọn ara ile rè̩ ni lati ni inu-didun. S̩ugbọn ibanujẹ wà ninu ile Naamani. Bi o tilẹ jẹ pe gbogbo nkan rere wọnyi ni a le sọ nipa Naamani sibẹ ohun kan wà ti o mu ibanujẹ wa.

È̩tẹ

Naamani jẹ akọni ọkunrin alagbara – “ṣugbọn adẹtẹ ni.” È̩tẹ jẹ aisan ti o buru jù lọ eyi ti awọn oniṣegun ko le wosan. Gẹgẹ bi o ti jẹ adẹtẹ nì, eyi nì ni pe a o yà a sọtọ kuro lọdọ awọn ẹbi rè̩, ati awọn ọrẹ rè̩ ki wọn má baa ko arun ti a bẹru rẹ yi; eyi tumọ si pe ki yoo tun le ṣe olori-ogun mọ; eyi nì ni pe gbogbo ireti rè̩ ti o kù ni lati wà ninu aisan pipẹ titi yoo fi kú.

Naamani jẹ akọni eniyan, ṣugbọn eyi nì ko le wo o sàn. Naamani jẹ ọlọla eniyan, ṣugbọn ọla ko le wo o san. O jẹ ọlọrọ. S̩ugbọn ọrọ ko le woo san. O jẹ eniyan nla laarin ilu, ṣugbọn ipo yi ko le wo o san. Ọba, awọn ọrẹ, owo, ipo – ko si ọkan ninu gbogbo eyi ti o le wo Naamani san. Ko ha si idasilẹ kuro ninu ipo ibanujẹ yi?

Iranṣẹbinrin Igbekun Naa

Iranṣẹbinrin igbekun kekere ọmọ Israẹli ti n duro niwaju iyawo Naamani mọ nipa Oluwa. Lai si aniani, ki a to mu un ni igbekun a ti kọ ọ nipa Ọlọrun awọn Ọmọ Israẹli. Nigba ti o wà ni ilẹ ajeji ko gbagbe nipa agbara Ọlọrun. Nigba ti o gbọ nipa è̩tẹ Naamani o wi fun iyawo-oluwa rè̩ pe woli Oluwa le wo o san ninu è̩tẹ naa.

A ko tilẹ mọ orukọ ọmọbinrin kekere yi. A mọ daju pe o gbe igbesi-aye rere ati pe o sọ nipa Oluwa nigba ti o ni anfaani lati ṣe bẹẹ. Awọn eniyan naa gba a gbọ. Ko si ẹlomiran ti o le wo è̩tẹ Naamani san, ṣugbọn wọn gba ọrọ iranṣẹbinrin kekere yi gbọ.

Ẹri ti o Yè

Ọpọlọpọ awọn Onigbagbọ ni wọn n gbe ti wọn si n ṣiṣẹ laarin awọn alaigbagbọ. Wọn a maa gbe igbesi-aye wọn fun Oluwa ni gbogbo akoko, bẹẹ ni awọn ẹlomiran a maa fi ọkan tan wọn. Nigba ti anfaani kan ba ṣi silẹ wọn a sọ ohun ti Ọlọrun le ṣe, wọn a si jẹri si ohun ti O ti ṣe. Lati sọ nipa agbara ti n bẹ ninu È̩jẹ Jesu lati gbala, ni lati sọ nipa iwosan kan ṣoṣo ti o wà fun ẹṣẹ ati ikú.

Ẹkọ yi n fi han wa pe awọn ọmọde le tan Ihinrere kalẹ ki wọn si ran awọn ẹlomiran lọwọ. Njẹ o ti sọ fun ẹni kan ri nipa Jesu ati nipa agbara Rè̩ lati gbala kuro ninu ẹṣẹ? O ha n gbe iru igbesi-aye naa ni ile ati ni ile-ẹkọ ti o le mu ki awọn ẹlomiran gba ohun ti o n sọ gbọ?

Iranṣẹbinrin kekere ti o wa ni ile Naamani sọ otitọ, olukuluku si gba a gbọ. Bẹnhadadi, ọba paapaa gba ihin naa gbọ. O wi fun Naamani pe ki o lọ si ilẹ Samaria. O fi iwe ran Naamani si Jehoramu ọba Israẹli. Naamani mu ọpọlọpọ ẹbun fadaka, wura, ati aṣọ lọwọ.

Iwe Kan

Naamani mu iwe naa tọ ọba lọ. A kọ ọ sinu iwe naa pe ki ọba wo è̩tẹ Naamani san. Nigba ti Jehoramu ka iwe naa, o wi pe, “Emi ha iṣe Ọlorun, lati pa ati lati sọ di āyè?” O daju pe ọba mọ pe Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o le wo è̩tẹ san. Ibeere ti ko tọna rara ni lati ni ki ọba ṣe iru eyi. Ko si ninu agbara ọba Israẹli lati wo ẹnikẹni san ninu arun buburu bi è̩tẹ tabi arunkarun. Nigba kan sẹhin, Bẹnhadadi ti beere ẹrù ati ohun iyebiye lọwọ awọn Ọmọ Israẹli ki o má ba gbogun ti wọn (I Awọn Ọba 20:1-6). Jehoramu ro wi pe Bẹnhadadi tun n fẹ lati fa ijọngbọn ni nipa wiwa oun nija.

Ẹni Ti Ko Tọ

Ko ha si iranlọwọ fun Naamani? Kin ni ọmọdebinrin iranṣẹ naa wi? “Woli ti mbẹ ni Samaria ... iba wo o san kuro ninu è̩tè̩ rè̩.” Naamani ti tọ ẹni ti ko tọ lọ. Woli ni o ni agbara Ọlọrun, ki i ṣe ọba. Nipa lilọ si ọdọ ẹni ti kò tọ è̩tẹ Naamani wà sibẹ, eyi yi si ru ibinu soke. O jẹ ohun pataki fun awọn eniyan lode oni lati lọ sọdọ Ẹni ti o tọ fun iranlọwọ. Ẹni naa ni Jesu. Oluwa nikan ṣoṣo ni o le gba eniyan kuro ninu ẹṣẹ rè̩. Oluwa nikan ṣoṣo ni o le fi agbara Rè̩ mimọ wo ara eniyan san. Awọn ojiṣẹ ati awọn ọmọ-ẹhin Oluwa le gbadura ki wọn si tọka eniyan si Jesu, ṣugbọn ko si ẹni kan ti o le gba ẹlomiran la kuro ninu ẹṣẹ rè̩. “Kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12).

Woli Naa

Eliṣa gbọ nipa idaru-dapọ ti iwe naa da silẹ. O ran ọrọ yi si ọba: “Jẹ ki o tọ mi wa nisisiyi, on o si mọ pe woli kan mbẹ ni Israẹli.” Naamani de pẹlu kẹkẹ ati ẹṣin rè̩ si ile Eliṣa o si duro ni ẹnu ọna. Iranṣẹ kan jade wa lati jẹ iṣẹ ti Eliṣa ran an. O wi pe, “Lọ, ki o si wè̩ ni Jọrdani nigba meje, ẹran-ara rẹ yio tun bọ sipo fun ọ, iwọ o si mọ.”

Dipo ti i ba fi maa yọ fun iru iwosan ti o rọrun bẹẹ, Naamani binu. Ki i ṣe ohun ti o n reti ni eyi. Oun ha kọ ni olori ogun Siria? Bẹẹ ni woli naa ko tilẹ jade lati ki i paapaa!

Ọna Ọlọrun

Ọlọrun maa n ṣiṣẹ ni ọpọlọpọ igba ni ọna ti eniyan ko nireti. Ọna eniyan yatọ si ti Ọlọrun. “Ero mi kì iṣe ero nyin, bẹni ọna nyin kì iṣe ọna mi, li OLUWA wi. Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bẹni ọna mi ga ju ọna nyin lọ, ati ero mi ju ero nyin lọ” (Isaiah 55:8, 9). “Ọna kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rè̩ li ọna ikú” (Owe 16:25). Eniyan ni lati gbọran si aṣẹ Ọlọrun ki o ba le ri ibukun Oluwa gba.

Naamani ro nipa awọn odo ilẹ ti rè̩ ati ti Samaria. Awọn eniyan ti o ti ri odo wọnyi wi pe odo Damasku mọ gaara o si n kọ bi digi ṣugbọn odo Jọrdani ri rọkurọku. Naamani i ba ti yàn lati wè̩ ninu awọn odo ilẹ ti rè̩, ṣugbọn ọrọ Oluwa lati ẹnu woli Rè̩ ti wi pe “Jordani.” Naamani si yipada lọ ni irunu nitori pe ko le rẹ ara rè̩ silẹ lati wẹ ninu Odo Jọrdani.

Riri Ara bọ inu Jọrdani

Awọn ọmọ-ọdọ Naamani gbà a niyanju pe ki o gbọran. Wọn wi fun un pe oun i ba ṣe ohun nla kan bi woli naa ba paṣẹ fun un lati ṣe e, nitori naa eeṣe ti ki yoo fi ṣe ohun kekere yi – “Wè̩ ki o si mọ?” Naamani gba amọran awọn iranṣẹ rè̩. O sọkalẹ lọ sinu Odo Jọrdani. O tè̩ ara rè̩ bọ ọ nigba meje gẹgẹ bi ọrọ eniyan Ọlọrun naa. Lẹẹkọọkan bi o ti n tẹ ara rè̩ bọ omi ti o n jade, boya Naamani fi iyemeji wo ara rè̩ lati wò bi iyipada ba wà. A ko ka a pe iyipada naa de diẹdiẹ. Lẹhin ti Naamani ti gbọran nipa titẹ ara rè̩ bọ omi nigba meje, nigba yi ni “ẹran-ara rè̩ si tun pada bọ, gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ.”

Bakan naa ni nigba ti eniyan ba n wá Ọlọrun ni ode oni. O ni lati gbọran si Ọrọ Oluwa. Ẹni kan le fẹ wá Ọlọrun nibomiran tabi nigba miran, ṣugbọn nipa gbigbọran si aṣẹ Ọlọrun ni o le fi ri ibukun Ọlọrun gbà, i baa gbadura nigba meje tabi lẹẹkan.

Naamani le tẹ ara rè̩ bọ omi nigba mẹfa ki o si maa lọ, lai si iwosan, ki o si maa wi pe Ọlọrun ko fẹ lati wo oun san. Naamani dán Ọlọrun wò nipa gbigbọran si aṣẹ Rè̩, a si wè̩ ẹ mọ. Awọn ẹlomiran n gbiyanju lati ba Ọlọrun jiyan. Wọn a maa gbiyanju lati ri ibukun Ọlọrun gbà nipa gbigbọran niwọn: ṣugbọn Ọlọrun n beere igbọran kikún.

Ẹri Rè̩

Nigba ti a wo Naamani san ninu è̩tẹ rè̩, o pada lọ sọdọ woli naa. O jẹri pe, “Nisisiyi ni mo to mọ pe, ko si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikoṣe ni Israẹli.” Wo o bi o ti kun fun ọpẹ to lati ri imularada gbà kuro ninu è̩tẹ rè̩. Naamani wi pe lati igba naa lọ oun ki yoo tun sin awọn ọlọrun miran mọ. Naamani ṣe tan lati maa sin Ọlọrun otitọ ati Ọlọrun alaaye. O beere fun “erupẹ ẹru ibaka meji” lati mu pada pẹlu rè̩. Boya o fẹ lati ṣe pẹpẹ erupẹ nibi ti o le ṣe irubọ ẹbọ sisun si Oluwa (Ẹksodu 20:24). Naamani fi iyin fun Ọlọrun fun idasilẹ rẹ, o si pada lọ si ilu rè̩ pẹlu ibukun lati ẹnu Eliṣa.

Olojukokoro

Gehasi iranṣẹ Eliṣa tẹle Naamani. Gehasi n fẹ ère naa ti Naamani ti fi lọ ọga rè̩, ti Eliṣa si ti kọ. Gehasi purọ fun Naamani o si wi pe ọga oun n fẹ ẹbun naa fun ẹlomiran. Lẹhin ti Gehasi gba nkan wọnyi o fi wọn pamọ ki o to pada sọdọ oluwa rè̩. Eliṣa mọ pe Gehasi ti ṣe ojukokoro ère naa; o bi i leere nipa agbada ati owo. Gehasi ko sọ otitọ fun Eliṣa.

Lati purọ jẹ ẹṣẹ. Ẹṣẹ kan ṣoṣo yoo ba igbesi aye ti o dara jẹ. Nigba ti eniyan ba fi ara fun idanwo ti o si dẹṣẹ, nigba pupọ ni ẹṣẹ kan yi maa n mu ni lọ sinu ẹṣẹ miran. Gehasi kọkọ ṣe ojukokoro; lẹhin eyi, o purọ fun Naamani; lẹhin eyi o gbiyanju lati bo ẹṣẹ rè̩ mọlẹ; bẹẹ ni ko si sọ otitọ nigba ti Eliṣa bi i leere pe nibo ni o ti n bọ. Ninu igbesi-aye Gehasi, ẹṣẹ kan tun fa ẹṣẹ miran. Gẹgẹ bi ijiya a mu ki è̩tẹ Naamani ki o lè̩ mọ Gehasi. Bayi a ti kọ ninu ẹkọ wa yi, gẹgẹ bi ọkunrin kan, Naamani, ti ṣe ri iwosan kuro ninu è̩tẹ rè̩, ati gẹgẹ bi ẹlomiran, Gehasi, ti ṣe ru è̩tẹ yi kan naa.

È̩tẹ ati Ẹṣẹ

A n sọ nipa è̩tẹ gẹgẹ bi apẹẹrẹ ẹṣẹ. Laarin ọlá Naamani, è̩tẹ n bẹ lara rè̩. Bẹẹ ni o ri ni igbesi-aye ọpọlọpọ lode oni. Laarin ọlá, ọlà, ọrẹ, ati ipo, ẹṣẹ wà sibẹ. Awọn eniyan naa le ni iwa rere kan ti yoo maa gbé wọn ga, ṣugbọn ẹṣẹ wà sibẹ. Woli Isaiah gbadura fun awọn eniyan, pe, “Gbogbo wa si dabi ohun aimọ, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin” (Isaiah 64:6). Oluwa sọ ọrọ wọnyi lati ọwọ Jeremiah: “Nitori iwọ iba wẹ ara rẹ ni ẽru, ki o si mu aró-è̩ba pupọ, ẽri ni è̩ṣè̩ rẹ niwaju mi sibẹsibẹ, li Oluwa ỌLỌRUN wi” (Jeremiah 2:22).

Iwosan kan ṣoṣo ti n bẹ fun è̩tẹ Naamani n bẹ ninu Oluwa. Bakan naa ni pẹlu ẹṣẹ. Iwosan kan ṣoṣo ti n bẹ fun ẹṣẹ wà ninu È̩jẹ Jesu. Ẹṣẹ a maa mu iyapa kuro lọdọ Ọlọrun wá. A maa mu ègbe ati iku wa bi è̩tẹ. Naamani mu ọrẹ wa lati fun woli. Wọnyi dabi ifararubọ ti awọn eniyan n ṣe si Ọlọrun nigbà ti wọn ba gbadura ti wọn si fi aye wọn fun Un. A ko le fi owo ra ẹbun Ọlọrun (Iṣe Awọn Apọsteli 8:20). Eniyan a maa fẹ lati fi iyin ati ifararubọ han fun awọn ibukun Rè̩. O jẹ ọranyàn fun Naamani lati gbọran patapata si Ọrọ ti Ọlọrun ran. Nigba ti awọn eniyan ba gbọran si Ọlọrun lode oni ti wọn si ṣe gẹgẹ bi O ti paṣẹ, a o wẹ ẹṣe wọṅ nù a o si dariji wọn. A ha ti wẹ ẹṣẹ rẹ nù nipa È̩jẹ Jesu? O ha n gbe igbesi-aye rẹ fun Un lojoojumọ?

“Ki l’o le w’ẹṣẹ mi nu?

Ko si lẹhin È̩jẹ Jesu;

Ki l’o tun le wo mi san?

Ko si lẹhin È̩jẹ Jesu.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Tani i ṣe olori ogun Siria?

  2. 2 Ọna wo ni iranṣẹbinrin ara Israẹli gbà de ile Naamani?

  3. 3 Kin ni ohun ti n ṣe Naamani?

  4. 4 Kin ni ọmọdebinrin naa sọ pe ki o ṣe?

  5. 5 Aṣiṣe wo ni Naamani ṣe?

  6. 6 Eeṣe ti ọba fi ro pe awọn ara Siria n wá oun ni ija?

  7. 7 Bawo ni Naamani ṣe bọ ninu è̩tẹ rè̩?

  8. 8 Kin ni ohun kan ṣoṣo ti o le wo è̩tẹ Naamani san?

  9. 9 Sọ bi ẹṣẹ ati è̩tẹ ti ṣe jọ ara wọn.

  10. 10 Ọna wo ni eniyan le gbà bọ ninu ẹṣẹ rè̩?

2