Matteu 1:18-25; 2:1-23; Luku 2:1-40

Lesson 312 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israẹli: nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rè̩ nide” (Luku 1:68).
Notes

Ọjọ-ibi Ọba Kan

Awọn miran ninu awọn nkan ti o ṣẹlẹ ti o fara mọ ibi Olugbala wa Jesu Kristi, le jẹ eyi ti o ṣoro lati ye wa; ṣugbọn wọn ga rekọja ti ẹda eniyan, a si mọ pe otitọ ni wọn gẹgẹ bi a ti sọ wọn fun wa ninu Bibeli. A dupẹ lọpọlọpọ pe a gba gbogbo itàn igbesi-aye Jesu gbọ, ọkan ninu eyi ti i ṣe ọna ti o gbà wọ inu aye!

Angẹli Gabriẹli ni o sọ asọtẹlẹ ibi Rè̩, nigba ti o fara han Maria. O wi fun un pe a ti yan an lati jẹ iya fun Ọmọ Ọlọrun. Idahun Maria fun Gabriẹli ni: “Wò ọmọ-ọdọ Oluwa, ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọrọ rẹ” (Luku 1:38). Angẹli naa si fi i silẹ lọ.

Irawọ, abami imọlẹ kan, ni o fi ọgangan ibi ti ìbí iyanu yi gbe ṣẹlẹ han. A ṣe amọna awọn amoye nipasẹ imọlẹ rè̩ lati ilẹ jijin wa lati wa wolẹ fun Jesu ati lati fi ẹbun fun Un. O le dabi ẹni pe gbogbo iṣẹlẹ yi ṣe ajeji, ṣugbọn nigba ti eniyan ba duro jẹ, lati ro o pe Ọmọ Ọlọrun, Olugbala ati Olurapada aye ati Ọba ayeraye, ni o fẹ fara han, n jẹ ki yoo ha tilẹ jẹ ohun ajeji ju bẹẹ lọ paapaa, bi kò ba si apẹẹrẹ ti o ṣe abami ṣaaju wiwa Rè̩?

Lọ si Bẹtlẹhẹmu

Awọn Angẹli kede fun awọn oluṣọ-agutan lẹba oke pe “Ẹnyin o ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọjá wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran” (Luku 2:12). Wọn yara lọ si Bẹtlẹhẹmu lati wa Ọmọde naa, wọn si pada si ibi ti agbo ẹran wọn wà, wọn n fi ogo ati iyin fun Ọlọrun. Awọn amoye wa lati Ilà-oorun si ilu-nla Jerusalẹmu, ilu ti i ṣe olu-ilu gbogbo aye nipa è̩sin. “Nibo li ẹniti a bi ti iṣe Ọba awọn Ju wà?” ni wọn beere. Ọna jijin ni wọn ti wá, ṣugbọn wọn ko tilẹ mọ wi pe awọn ni ẹni ti yoo wá sọ ti ibi Olugbala. Ọba Hẹrọdu ati gbogbo Jerusalẹmu daamu. Nibo ni a o ti bi Kristi? Ni ibeere ti ọba beere lowọ awọn olori alufa ati awọn akọwe. “Ni Bẹtlẹhẹmu ti Judea,” ni wọn wi. Ibeere ti o tun beere ni “nigba wo” ni irawọ naa fara hàn? Wọn ko fura si ohun ti ọba buburu yi fẹ ṣe, ṣugbọn wọn sọ ohun gbogbo fun un. Nigba naa ni Hẹrọdu wi pe, “Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ nā lẹsọ-lẹsọ; nigbati ẹnyin ba si rii, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu” (Matteu 2:8). S̩ugbọn ọba yi ko gbero lati foribalẹ fun Ọba titun ti a bi yi – o gbiyanju lati mu ki a pa A.

Awọn ara ilu Jerusalẹmu n kọ? A ko ri i pe wọn mu ọna wọn pọn lọ si Bẹtlẹhẹmu. Bawo ni o ti ri ti wọn ko mọ pe ni ibusọ mẹfa pere si ọdọ wọn, a ti bi Ọba kan? Lati Ila-oorun awọn alejo naa wá lati wadi nipa Ọba naa ti i ṣe ọmọ-ọwọ. Wọn ri I, wọn si mu ẹbun wa fun un. A sọ fun wa pe wura naa n tọka si ipo Rè̩ gẹgẹ bi Ọba, turari si n tọka si ipo Rè̩ gẹgẹ bi Ọlọrun ati ojia n tọka si ijiya Rè̩. O saa jẹ aṣa igbà naa lati fi ẹbun fun awọn ọba ati awọn alaṣẹ, bakan naa ni a si n ṣe lode oni.

“Ẹni Ikānu”

Awọn amoye naa wolẹ niwaju Jesu wọn si sin In; ṣugbọn ki wọn to pada lọ si ile, Ọlọrun kilọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe pada tọ Hẹrọdu lọ mọ, ṣugbọn ki wọn lọ si ilu wọn nipa ọna miran.

Ki a to bi Jesu, a sọ nipa Rè̩ pe O jẹ “ẹni ikānu; ti o si mọ ibanujẹ” (Isaiah 53:3). Ko pẹ naa ti o de inu aye ki awọn eniyan to “ké̩gàn rè̩ a si kọ ọ lọdọ awọn enia.” Wahala de ba A nigba ti O ṣi kere pupọ: ko si aye ni ile-ero, ibujẹ ẹran fun ibusun, bẹẹ ni nigba ti O wà ni ọmọ kekere jojolo a ni lati gbe E sa lọ si Egipti lati gba A silẹ lọwọ ipinnu ọba ti o kún fun owu.

Ọba Hẹrọdu ro pe oun di ẹni itanjẹ lọdọ awọn amoye nigba ti o rii pe Ọmọ kekere naa ati awọn obi Rè̩ ti rekọja ibi ti ọwọ rè̩ le tè̩ wọn. Bẹẹ kọ, Hẹrọdu, ki i ṣe awọn amoye ni o fi ọ ṣe è̩sin, ṣugbọn Ọlọrun, Ẹni ti o joko lori Itẹ ni O fi ọ ṣe ẹlẹya. O n ṣọ ẹṣọ lori Ọmọ Rè̩ alabukunfun, Jesu Ọmọde naa, Ẹni ti yoo ni lati kú ni ọjọ kan, ṣugbọn ki i ṣe nipa ọwọ rẹ.

Ninu ibinu nla rè̩, ọba rán ẹgbẹ awọn apaniyan kan lọ lati pa gbogbo awọn ọmọ wẹẹrẹ ni Bẹtlẹhẹmu lati ọmọ ọdun meji de isalẹ. Ọmọ ọkunrin buburu, Hẹrọdu miran, ni o pa Johannu Baptisti, ti o si fi Kristi ṣẹsin; ọmọ-ọmọ rè̩ ni o pa Jakọbu Apọsteli; niwaju ọmọ-ọmọ-ọmọ rè̩, Hẹrọdu Agrippa Keji, ni a ti wadi ẹjọ Paulu Apọsteli. Wo iru ijiya ti o n duro de ẹbi alaṣẹ wọnyi, awọn ti o huwa ailaanu si Jesu, Ọmọ Ọlọrun, ati awọn ọmọ-ẹhin Rè̩!

Nipasẹ ala ti Oluwa rán, a sọ ibi ti Josẹfu ni lati lọ fun un. O gbọran o si mu Ọmọde naa ati iya Rè̩ lọ si Egipti, o si wà nibẹ titi ọba Hẹrọdu fi kú. Nigba ti wọn wà ni Egipti Oluwa tun sọ fun Josẹfu nipa ibi ti o yẹ ki o lọ -- nigba yi si Nasarẹti ti o wà ni Galili. Eyi yi ni a n pè ni “ilu wọn” (Luku 2:39), ibi ti Josẹfu ati Maria ti bẹrẹ irin-ajò wọn, nigba ti wọn n lọ si Bẹtlẹhẹmu fun ifi-orukọ silẹ, ki a to bi Jesu. Nihin ni Nasarẹti ni Jesu n gbe pẹlu Maria ati Josẹfu nigba ti O si di ọmọ ọdun mejila O ba wọn lọ si Jerusalẹmu fun Ajọ Irekọja (Luku 2:41, 42).

Ohun ti O Jẹ fun Wa

A kà ninu Bibeli pe, “On fẹ wa, O si ran Ọmọ rè̩” (I Johannu 4:10). Bi o tilẹ jẹ pe awọn kan n wi bayi pe a ran Jesu wá fun kiki lati fi han awọn eniyan bi a ti ṣe ni lati gbe ni aye, awa mọ pe wiwá si aye Rè̩ ja si ohun ti o jù eyi yi lọ fun ọmọ-eniyan. “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ gẹ ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ má ba ṣegbe, ṣugbọn ki o le ni ìye-ainipẹkun” (Johannu 3:16). Sibẹsibẹ lode oni bi o tilẹ ṣe pe o ti le ni ẹgbaa ọdun (2,000) ti a ti bi Kristi Olugbala, gbogbo awọn ti o gba A gbọ lati inu ọkan wa ti wọn si ronupiwada ẹṣẹ wọn, ti wọn si pe È wọ inu ọkan wọn, le ri idariji ẹṣẹ wọn gbà nipasẹ È̩jẹ Jesu ti a ta silẹ lori Agbelebu ni Kalfari. A ti pese ile kan silẹ ni Ọrun fun awọn ti a dari ẹṣẹ wọn ji ti a si kọ orukọ wọn sinu Iwe Iyè.

Njẹ Ajọdun Keresimesi ha jẹ igba fifi ọrẹ ohun aye yi fun awọn olufẹ ati ọrẹ lasan? Fun olukuluku Onigbagbọ Keresimesi jẹ iranti ibi Jesu Olugbala, Olurapada ati Ọba ti n bọ wa lai pẹ. Kin ni Keresimesi jẹ fun ọ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Awọn orukọ miran wo ni a fi n pe Jesu?

  2. 2 Bawo ni Hẹrọdu ti ṣe gba irohin nipa ibi Jesu?

  3. 3 Awọn ibeere wo ni o beere lọwọ awọn amoye?

  4. 4 Sọ bi a ti ṣe ṣamọna awọn amoye lọ si ọgangan ibi ti a bi Jesu.

  5. 5 Bawo ni a ti ṣe kilọ fun wọn pe ki wọn má ṣe pada lọ sọdọ Hẹrọdu?

  6. 6 Bawo ni a ti ṣe kilọ fun Josẹfu nipa iwa ika ti Hẹrọdu pinnu rè̩?

  7. 7 Sọ ohun ti ọba Hẹrọdu ṣe nigba ti o rii pe a fi oun ṣe ẹlẹya.

  8. 8 Ilu wo ni a n pe ni “ilu wọn” nigba ti a ba n sọrọ nipa ẹbi mimọ yi?

  9. 9 Sọ nipa ibẹwo awọn oluṣọ-agutan si Bẹtlẹhẹmu.

2