Habakkuku 2:4; Romu 1:16, 17; Galatia 3:10, 11; Heberu 10:35-39; Romu 5:1-21

Lesson 313 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn olododo ni yio yè nipa igbagbọ: ṣugbọn bi o ba fa sẹhin, ọkàn mi kò ni inudidun si i” (Heberu 10:38).
Notes

Irin-ajo Kan si Romu

Ni ọjọ pupọ sẹhin, niwọn ọdun diẹ lẹhin ti Columbus ṣe awari ilẹ Amẹrika, awọn ọkunrin meji ti o ya ara wọn sọtọ fun iṣẹ isin Ọlọrun fi ile iyasọtọ wọṅ ni Germany silẹ lati lọ bé̩ olori Ijọ Aguda wò ni Romu ni ilẹ Italy. Irin-ajo naa jin, wọn si n fi ẹsẹ rin lọ bẹẹ fun ọpọlọpọ ọsẹ pẹlu aarẹ ara. S̩ugbọn inu wọn dun nitori ero yi wà ninu ọkan wọn pe iṣẹ Oluwa ni awọn n ba lọ. Rukerudò ti wa laarin Ijọ wọn ni ile, wọn si nireti lati sọ fun Olori wọn nipa rè̩ ki a ba le pari rè̩ fun ogo Ọlọrun.

Ọkan ninu awọn ọkunrin meji wọnyi ni a n pè ni Martin Luther. A ti kọ ọ ni ẹkọ lati jẹ agbẹjọro, ṣugbọn ọpọlọpọ nkan ti ṣẹlẹ ti o mu ki o pinnu lati di alufa. Ni akọkọ, o ri Bibeli kan ninu ile iṣura iwe ni ile-ẹkọ nibi ti o ti n kọ ẹkọ. Ni ọjọ wọnnì Bibeli ko wọpọ, ati pe a kọ wọn ni ede Heberu, Hellene, tabi ede awọn ara Romu. Gẹgẹ bi Luther ti n kà a, bẹẹ ni o n ni oungbẹ sii lati ni imọ sii nipa otitọ Ọlọrun. Lẹhin eyi ni ọpọlọpọ iṣẹlẹ miran tun ṣẹlẹ, eyi ti o mu ki o pinnu lati jọwọ aye rè̩ fun isin Ọlọrun. O mu ẹjé̩ rè̩ ṣẹ, o si yà ara rè̩ sọtọ fun igbesi-aye isẹra-ẹni, o si gbiyanju lati maa gbe ni iwa irẹlẹ bi o ti wà ni ipa rè̩ lati ṣe to, ki o ba le wu Ọlọrun nipa ifararubọ rè̩.

Luther ba Ijatilẹ Pade

Nigba ti Luther wọ ilu Romu, o ba ijatilẹ pade nipa gbogbo ọrọ ati ipo giga ti a fi han ti o si ri ninu Ile-isin naa. Oun ti gbagbọ pe igbesi-aye Onigbagbọ jẹ eyi ti o rẹlẹ, bẹẹ ni gbogbo ohun giga-giga ti o ri jọ eyi ti o kun fun ẹṣẹ ni oju rè̩. Bẹẹ ni o si rii pe ọpọlọpọ n ṣe ohun ti a kọ ọ pe o lodi. Olori Ijọ Aguda, ti o tọ wa fun iranlọwọ lati ba wọn ṣe iwẹnumọ Ijọ ni Germany, ko ni ifẹ si a ti ṣe atunṣe yi rara. Ninu ijatilẹ ati ipo ibanujẹ ti o wa yi, Luther bẹrẹ si i gbadura o si n ṣe ipọn-ara-ẹni-loju nipa gigun abagoke pẹtẹsi kan, Ọlọrun si da a lohun.

Ọrọ Ọlọrun

Wọnyi ni ọrọ ti Ọlọrun sọ fun Martin Luther: “Olododo yio ye nipa igbagbọ.” Gbolohun ọrọ kukuru ni; ṣugbọn otitọ nla nla ti i ṣe otitọ ayeraye ni o wà ninu ọrọ wọnni. Gbogbo iwa-mimọ ti Luther ti gbiyanju lati fi ara ṣe ko fun un ni iye-ainipẹkun. Bi oun yoo ba jẹ olododo niwaju Ọlọrun, o ni lati wá gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ti i wa lode oni: eyi nì ni gbigba Jesu Kristi gbọ si igbala. Gigun atẹgun pẹtẹsi ati sisọ-kalẹ lori ọwọ ati eekun rè̩ ko gba ọkan rè̩ là. Olododo yoo yè nipa igbagbọ!

Lẹhin oṣu kan ni Romu, Martin Luther ati ọrẹ rè̩ rin pada lọ si Germany. Bẹẹ ni ọrọ yi sa n ṣiṣẹ bi aago ni ọkan rè̩, “Olododo yio ye nipa igbagbọ” -- igbagbọ ninu Jesu Kristi. Nipa igbagbọ Martin Luther ri alaafia ti ọkan rè̩ ti n poungbẹ fun gba.

Nigba ti o pada de ile o bẹrẹ si i waasu ododo yi, o si n kọ iwe nipa rè̩ pẹlu. S̩ugbọn Ijọ Aguda ni ijọ ti o ni aṣẹ ni akoko naa, bẹẹ ni a si n kọ awọn eniyan pe ọrọ olori Ijọ Aguda ṣe pataki jù Ọrọ Ọlọrun lọ. Nitori idi eyi ọpọlọpọ ariyanjiyan bẹrẹ lori iwaasu Luther.

A Yọ ọ kuro ninu Ijọ

Martin Luther ti ni igbẹkẹle ninu Ijọ, ko si ni ero lati fa sẹhin kuro ninu rè̩. O ti ro wi pe rukerudo naa wà lọwọ awọn kan ti o wà ninu Ijọ naa, ati pe bi a ba le ba wọn wi bi o ti tọ ki a si mu ki wọn ri otitọ, ohun gbogbo yoo maa lọ deedee. S̩ugbọn o wa rii dajudaju nikẹhin pe bi oun yoo ba mu iduro fun otitọ ti o wà ninu Bibeli oun ni lati mu iduro naa lodi si Ijọ.

Ọjọ naa de ti a ni lati pe Martin Luther lati duro fun otitọ Ọrọ Ọlọrun niwaju awọn alaṣẹ giga ti o le ni igba (200); a ran awọn miran wá lati ọdọ Olori ẹsin Aguda, awọn miran si jẹ alaṣẹ ni Germany. A pe orukọ ipade yi ni Dieti a si ṣe e ni ilu ti a n pe ni Worms, ni ilu Germany, nitori naa ni a ṣe pe ipade naa ni Dieti ti ilu Worms.

Awọn eniyan ti o to iwọn ẹgbaaji (4,000) ni o ti pejọ lati tẹti silẹ si ayè̩wo ẹjọ Luther. Pẹlu iwa pẹlẹ ni o duro niwaju awọn alatako rè̩ ti o kun fun irunu yi, pẹlu ifọkanbalẹ pe oun ni o wa lori ẹtọ ati pe Ọlọrun ki yoo kọ oun silẹ.

Wọn bere lọwọ rè̩ bi o ba ṣe pe oun ni o kọ awọn iwe ti o wa niwaju rè̩, o si dahun pe oun ni o kọ wọn. Bi wọn ba le fi eyikeyi ninu wọn han pe o lodi si Ọrọ Ọlọrun, o ti ṣe tan lati pa iwe bẹẹ run; ṣugbọn bi a ko ba le ri ọkan bẹẹ, oun ki yoo yọ ọrọ kan ṣoṣo kuro ninu wọn.

Bawo ni awa i ba ti kun fun ọpẹ to fun iru ọkunrin yi ẹni ti o ṣe tan lati mu iduro rè̩ fun Ọrọ Ọlọrun lodi si awọn ọba, awọn ọmọ-alade ati awọn biṣọpu. Eyi le yọri si iku fun un; ṣugbọn iye ainipẹkun ṣe iyebiye jù lọ fun ẹni irẹlẹ ọmọ Ọlọrun yi. Ki Ọlọrun jọwọ fi ipinnu ati ẹmi iduroṣinṣin bẹẹ sinu ọkan wa ki a má ṣe gba agbara eṣu laye, ṣugbọn ki a fi igboya duro fun otitọ bi yoo tilẹ gba ẹmi wa!

A fun Luther ni anfaani miran lati yi ipinnu rè̩ pada, ṣugbọn o fi igboya dahun pe: “Emi ko le, bẹni emi ki yio sẹ ohunkohun. Mo duro nihin. Emi ko le ṣe nkan miran. Nitori naa ràn mi lọwọ Ọlọrun, Amin.”

Idarudapọ gidi wa ninu ile naa to bẹẹ ti o fi jẹ pe pẹlu agbara ni a le fi gbọ awọn ọrọ ti o sọ kẹhin. Bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan naa kun fun irunu nitori o gboya to bẹẹ lati lodi si ọrọ Olori Ijọ Aguda, wọn ko jẹ daba lati fi ọwọ kan an, nitori pe a ti ṣeleri fun un tẹlẹ pe a o rii daju pe o wa si ipade naa, o si pada lọ ni alaafia.

Nibi Ifarapamọ

Ni ọna àjo rè̩ si ile, irin ajo ọpọlọpọ ọjọ, awọn ọrẹ Luther ji i gbe sa lọ bẹẹ ni a si fi i pamọ sinu ile-iṣọ kan lori oke fun bi ọdun kan. Laarin akoko yi ni o kọ ọpọlọpọ iwe imu-lọkan-le si awọn eniyan ti wọn ti gba ẹkọ rè̩. Eyi ti o ṣe pataki jù lọ ninu iṣẹ rè̩ ni itumọ Majẹmu Titun si ede Germany. Lẹhin eyi o tun tumọ Majẹmu Laelae, pẹlu; bi o tilẹ jẹ pe ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin ni ọdun 1521 ni o ti ṣe eyi, sibẹ a ko i ti ri itumọ Bibeli si ede Germany ti o tun san jù eyi ti o ṣe lọ.

Ibẹrẹ Igba Atunṣe Ẹsin

Bayi ni Igba Atunṣe ninu ẹsin bẹrẹ nipasẹ igboya, igbagbọ, ati ifẹ fun otitọ lati ọdọ ẹni kan. Imọlẹ Ihinrere tun bẹrẹ si i tan lẹẹkan si i lẹhin ọpọlọpọ ọdun ti a pe ni Igba Okunkun eyi ti o bori aye lẹhin iku awọn ti o jẹ ìpilẹ Ijọ akọkọ. Nitori pe o ni igboya lati duro fun otitọ ti Ọlọrun fi fun un – “Olododo ni yio ye nipa igbagbọ” – Luther fa agbara nla nla ti Ijọ Aguda nì ya, o si fi han gbangba pe gbogbo eniyan ni o ni anfaani lati ronupiwada ẹṣẹ won ki won si wa idariji ẹṣẹ wọn nipasẹ Jesu ati È̩jẹ ti O ta silẹ ni Kalfari.

A ti kọ Luther tẹlẹ pe o ni lati ṣe etutu fun ẹṣẹ rè̩ nipa fifi iya jẹ ara rè̩ ati nipa ṣiṣe irubọ. O ti sa gbogbo ipa rè̩ lati fi iṣẹ ọwọ ara rè̩ la ọna si Ọrun silẹ fun ara rè̩, ṣugbọn ko ri alaafia rara. Ko ni idaniloju nigba kan ri pe oun jẹ ẹni itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. Nisinsinyi o wá mọ otitọ Bibeli: “Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ, a o si gbà ọ là” (Iṣe Awọn Apọsteli 16:31). “Ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikara nyin: è̩bun Ọlọrun ni: kì iṣe nipa iṣẹ ki ẹnikẹni má bā ṣogo” (Efesu 2:8, 9). Ọpọlọpọ igba ni o ti ronupiwada ẹṣẹ rè̩, ti o si ti mu ifẹ-inu Oluwa ṣẹ bayi (Marku 1:15), ṣugbọn ko i ti gbagbọ si igbala. Nisinsinyi Luther ni idaniloju pe Ọlọrun ti dariji oun nitori Ẹmi Ọlọrun jẹri si i; o si n lọ kaakiri o n waasu fun awọn eniyan pe o ṣe e ṣe fun wọn lati mọ daju pe a gba wọn kuro ninu ẹṣẹ wọn.

Ki i ṣe Ẹkọ Titun

Otitọ pe a le ri igbala nipa igbagbọ ninu Jesu ki i ṣe ohun titun nigba ti Luther waasu rè̩. Imọlẹ naa tun tan lọtun ni lẹhin Igba Okunkun. Awọn Apọsteli ati awọn ọmọ-ẹhin ti akoko Jesu ti kọ ni bẹẹ, awọn eniyan mimọ ti igba Majẹmu Laelae tilẹ ti gba ẹkọ yi gbọ, wọn si ti gbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi ẹkọ yi. “Olododo yio yè nipa igbagbọ” ti jẹ ofin Ọlọrun fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lati igba ti Ọlọrun ti n ba ọmọ eniyan lo. (Igbagbọ ni wi pe ki eniyan gba Jesu gbọ tọkan-tọkan to bẹẹ ti eniyan yoo fi mura tan lati kọ ẹṣẹ rè̩ silẹ. Awọn olododo ni awọn ẹni-iwa-bi-Ọlọrun ti yoo wà ni imurasilẹ lati pade Jesu nigba ti o ba de).

Igbagbọ Abẹli

Awọn ọmọde meji ti a kọkọ bi lori ilẹ aye yi mu ẹbọ wá sọdọ Ọlọrun. A kọ ẹbọ Kaini nitori pe kò wá si ọdọ Ọlọrun ni ọna ti o tọ. Ọlọrun wi fun un pe “Bi iwọ ba ṣe rere ara ki yio ha yá ọ? Bi iwọ ko ba si ṣe rere, è̩ṣẹ ba li ẹnu-ọna” (Gẹnẹsisi 4:7). Bi o ba ṣe pe o ti ni iru igbagbọ ti aburo rè̩ Abẹli ní, oun i ba ti jẹ olododo, i ba si ṣe rere pẹlu. Nipa igbagbọ ni “Abeli rú ẹbọ si Ọlorun ti o sàn ju ti Kaini lọ, nipa eyiti a jẹri rè̩ pe olododo ni” (Heberu 11:4). Ododo Abẹli, lati igba iṣẹdalẹ aye, wá nipa igbagbọ.

Igbagbọ Awọn Baba-nipa-igbagbọ

Paulu Apọsteli sọ fun wa pe, “Abrahamu ti gba Ọlọrun gbọ a si kà a si fun u li ododo” (Galatia 3:6). Abrahamu olododo yè nipa igbagbọ.

Noa gbadun ododo eyi ti i ṣe nipa igbagbọ, ki a to fi Ikun-omi pa aye ré̩ paapaa. Paulu wi pe: “Nipa igbagbọ ni Noa, nigba ti Ọlọrun lọ ohun ti a koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun o si kàn ọkọ fun igbàla ile rè̩, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo nipa igbagbọ” (Heberu 11:7).

Igbagbọ yi jẹ igbẹkẹle ninu Jesu Ẹni ti a ko i ti bi. Jesu sọ nipa Abrahamu pe: “Abrahamu baba nyin yọ lati ri ọjọ mi: o si rii o si yọ” (Johannu 8:56). Jobu si wi pe “Emi mọ pe oludande mi mbẹ li āye ati pe on bi Ẹni-Ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ ... ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò” (Jobu 19:25-27). Dafidi si wi pe: “Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba ji” (Orin Dafidi 17:15). O da a loju gbangba pe Jesu n bọ wá, ati nipa igbagbọ yi a gbá ọkan rè̩ la, a si pese rè̩ silẹ lati pade Rè̩.

Igbagbọ si Igbala

Nigba ti Paulu Apọsteli wi pe, “Gba Jesu Kristi Oluwa gbọ, a o si gbà ọ là” (Iṣe Awọn Apọsteli 16:31), o dabi ẹni pe ohun ti o rọrun ni. S̩ugbọn nigba miran o tun ṣe alaye diẹ sii nipa bi a ti ṣe le ri igbala nigba ti o wi pe: “Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu òkú, a o gbà ọ là” (Romu 10:9). A ni lati gbagbọ lati inu ọkan pe Jesu ni Ọmọ mimọ Ọlọrun, ki a to le ri igbala. Ẹmi Ọlọrun si ni lati kọ wa bi a ti ṣe le ṣe eyi. A ko le gba wa là lai si iranlọwọ Ẹmi Ọlorun lati fa wa sun mọ ọdọ Rè̩.

Nigba ti Jesu beere lọwọ awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe “Tali ẹnyin nfi mi pe?” bẹẹ ni Peteru dahun pe “Kristi Ọmọ Ọlọrun alāye ni iwọ iṣe,” Jesu sọ fun un pe “Ki iṣe ẹran ara ati è̩jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun”(Matteu 16:13-17). O gba pe ki Ẹmi Ọlọrun fi han fun Peteru otitọ nì pe Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun.

Inu wa dun loni pe Ihinrere wà fun ẹnikẹni ti o ba fẹ. A dupẹ pe a ni Bibeli ti olukuluku eniyan ni anfaani lati kà, ninu eyi ti a le ri otitọ ti o le sọ wa di ominira. A si yọ ninu agbara ti o wà ninu È̩jẹ Jesu lati pa awọn eniyan Rè̩ mọ lati maa gbe lai dẹṣẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Tani a le kan saara si pe o bẹrẹ Igba Atunṣe ẹsìn?

  2. 2 S̩e apejuwe ohun ti o ṣẹlẹ ni ibi ipade ti a n pe ni Dieti ti ilu Worms.

  3. 3 Ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wo ni o jẹ koko Igba Atunṣe Ẹsìn yi?

  4. 4 Tani ẹni kinni ti a ni akọsilẹ rè̩ ninu Bibeli, ti a gbala nipa igbagbọ?

  5. 5 Ọna wo ni Abrahamu, Noa, ati Jobu gbà di olododo?

  6. 6 Bawo ni a ti ṣe mọ pe Abrahamu gba Jesu gbọ?

  7. 7 Bawo ni Peteru ti ṣe mọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu I ṣe?

  8. 8 Kin ni eniyan ni lati ṣe ki o le ri igbala, ti o ni lati fi kun igbagbọ ninu Oluwa Jesu Kristi?

  9. 2