Iṣe Awọn Apọsteli 6:1-7; I Kọrinti 12:4-6, 15-28; Efesu 4:1-8, 11-13; I Timoteu 3:1-13; 5:17-19; Titu 1:5-9; I Peteru 5:1-5

Lesson 288 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ani, gbogbo nyin, ẹ mā tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọjùjasi awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ” (I Peteru 5:5).
Cross References

I Eredi Rẹ ti A Fi Ni awọn Ojulowo Oṣiṣẹ ninu Ijọ

1. Ki iṣẹ Ọlọrun le maa lọ deede, Ọlọrun ṣe ilana pe ki awọn Onigbagbọ jẹ alajumọ rù ajaga iṣẹ Ọlọrun, I Kọrinti 12:4-6, 14, 18-20

2. Ki wọn maa bu ọla fun ara wọn, ki iṣọkan si wa laarin wọn, I Kọrinti 12:15-17, 21-26; 7:20; Efesu 4:1-6

3. Awọn oṣiṣẹ fun awọn ohun ti ẹmi ni a kọkọ yàn, niwọn bi ohun ti ẹmi ti ṣe pataki ju ohun ti ara lọ, I Kọrinti 12:27, 28; Efesu 4:8, 11-13

4. Odiwọn ti a n beere lọwọ alufa ati alabojuto jẹ eyi ti o ga pupọ, I Timoteu 2:1-7; 4:1-16; II Timoteu 2:6; 4:1, 2, 5; Romu 11:29; Efesu 4:7; Titu 1:5-9; I Peteru 5:2-5; I Kọrinti 14:32; II Kọrinti 6:1-10; Iṣe Awọn Apọsteli 20:28

II Idasilẹ Ipo Oṣiṣẹ ninu Ijọ ni Akọkọbẹrẹ

1. Bi iye awọn ọmọ-ẹhin ti n pọ si i bẹẹ ni iṣẹ n pọ si i fun awọn Apọsteli, Iṣe Awọn Apọsteli 6:1

2. Awọn Apọsteli mọ bí bibojuto ohun ti i ṣe ti ẹmi ti ṣe pataki tó ninu iṣẹ yi, wọn si pinnu lati fi gbogbo akoko wọn fun un, Iṣe Awọn Apọsteli 6:2, 4

3. A fihàn pe gbogbo ohun àmúyẹ kan naa ti awọn ti n bojuto ohun ti i ṣe ti ẹmi ni, ni awọn ti n bojuto awọn ohun ti iṣe ti ara ni lati ni pẹlu, Iṣe Awọn Apọsteli 6:3

4. A yan awọn diakoni, a si gbà wọn niyanju lati fi ọkàn kan bojuto aini awọn ọmọ-ẹhin, nipa ti ara, Iṣe Awọn Apọsteli 6:5-7; Filippi 1:1, 9-11; I Timoteu 3:8-13

5. Awọn alàgba ni ipin ninu bibojuto awọn ohun ti ẹmi, wọn si n bẹ ninu awọn alufa, alabojuto tabi oṣiṣẹ, Titu 1:5, 6; I Timoteu 5:17; Iṣe Awọn Apọsteli 11:29, 30; 14:23; 15:1-6, 22, 23; 16:4; 20:17, 28; 21:18; Jakọbu 5:14; I Peteru 5:1-5

6. Igbega laarin Ijọ Kristi ki i ṣe nipa igbekalẹ ọmọ-eniyan tabi nipa ifẹ lati ga ju ẹlomiran lọ, Orin Dafidi 75:6, 7; Galatia 5:20; I Peteru 5:2, 3; I Kọrinti 1:26-31; 9:16-23; II Kọrinti 3:5, 6; 5:18; Kolosse 1:1; I Timoteu 1:12

7. Awọn ti n fi gbogbo akoko wọn ṣiṣẹ ninu Ijọ Kristi ni ẹtọ lati gba iranwọ lati inu àpo Ijọ, ni akoko ti o ba tọ ti o si ṣe e ṣe bẹẹ, Matteu 10:9, 10; I Kọrinti 9:7-15, 18; 16:17; Galatia 6:6; Filippi 4:14; I Timoteu 5:18; Heberu 13:16; Iṣe Awọn Apọsteli 18:1-3; 20:33-35; I Tẹssalonika 2:9; II Tẹssalonika 3:7-9

8. Ọla ati igbọran yẹ fun gbogbo awọn ti a pè si ipò giga, I Timoteu 5:17-19; Heberu 13:7, 17, 18; I Kọrinti 16:15, 16; I Peteru 5:5; Romu 15:30; Galatia 4:14; Filippi 2:25-30; I Tẹssalonika 5:12, 13

Notes
ALAYE

Iṣakoso Ijọ Akọkọbẹrẹ

Gẹrẹ lẹhin itujade Ẹmi Mimọ ni Ọjọ Pẹntekọsti, Ọlọrun bẹrẹsi bukun Ijọ Ọlọrun igbaani, awọn àmi ti a ti ṣeleri si n tẹle iṣẹ-iranṣẹ awọn Apọsteli. “Iye awọn ọmọ-ẹhin npọ si i,” eyi si mu ki iṣoro diẹdiẹ yọju pẹlu.

Gẹgẹ bi oye ti awọn Apọsteli ni nipa ifẹ Ọlọrun fun wọn, wọn pe apejọ awọn ọmọlẹhin Kristi lati ṣe aṣaro nipa awọn iṣoro ti idagbasoke Ijọ mu lọwọ. Ninu ohun ti awọn Apọsteli ṣe yi, a le ri ọna ti Ọlọrun la silẹ, ti O si fi idi rẹ mulẹ fun iṣakoso Ijọ Rẹ ati fun abojuto awọn ohun ti Ẹmi ati ti ara laarin Ijọ. A kọwe nkan wọnyi “fun ikilọ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá” (I Kọrinti 10:11). A ni apẹẹrẹ pupọ ninu Iṣe Awọn Apọsteli ti a gbekalẹ lati fi ọna han bi a ti le ṣe iṣẹ-isin wa si Ọlọrun ati bi a ṣe le ṣe abojuto awọn iṣẹ wọnni ti o jẹ mọ ti ara ninu iṣẹ Oluwa.

Awọn Apọsteli ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ìpe ti Ọlọrun pè wọn. Bẹẹ ni wọn si mọ iṣẹ wọn niṣẹ, eyi ti wọn si ni lati fi le gbogbo awọn ọmọlẹhin Kristi lọwọ nitori Aṣẹ Nla nì (Matteu 28:18-20). Eredi rẹ ti wọn fi ṣe ohun ti wọn ṣe lakoko yi ni pe wọn fẹ kúku gbajumọ iṣẹ ti ẹmí ti o ti gba gbogbo akoko wọn látẹhinwá ati lati ri i daju pe wọn ko fi iṣẹ yi silẹ lati maa ṣe iṣẹ ti awọn ẹlomiran ti ko ti i ni ìpe lati ṣiṣẹ ti ẹmí le ṣe.

Iṣẹ Ajumọṣe ninu Ile Ọlọrun

O dara pupọ, paapaa ju lọ ninu iṣẹ Oluwa, bi a ba le pin iṣẹ fun awọn eniyan pupọ. Ọna pupọ ni iru eto bayi fi dara. Lọna kinni, kò gbọdọ si “ẹniti nlo agbara lori ijọ” (I Peteru 5:3), ṣugbọn gbogbo eniyan ni lati “fi irẹlẹ wọ ara wọn li aṣọ” ki wọn si “ma tẹriba fun ara wọn” (I Peteru 5:5). Gẹgẹ bi okuta ti a ge ti a si ti gbẹ nibiti a ti n gbẹ okuta ki a to mu wọn wa si ibiti a ti n kọ Tẹmpili, bẹẹ gẹgẹ ni Ọlọrun n pese awọn eniyan mimọ fun aye kan pato ninu Ijọ Rẹ. Gbogbo ọkàn ti i ṣe eniyan Ọlọrun ni tootọ ni iṣẹ n bẹ fun ninu ọgba ajara Oluwa. A ko kọ ẹnikẹni. A ko si gbagbe ẹnikẹni. Ko si ẹni ti a ka si alaiyẹ lati ri ohun kan ṣe ninu iṣẹ Ọlọrun – ni àyè ti wọn gbe le wulo gẹgẹ bi agbara wọn ti ri – bi wọn ba jẹ ọmọ Ọlọrun ni tootọ. Ko si ẹni ti o gbọdọ wa lai ri ṣe. Afo n bẹ fun gbogbo ọmọ Ọlọrun lati di – o le jẹ eyi ti o rẹlẹ ti a ko tilẹ kà si -- ṣugbọn olukuluku ni yoo gbà èrè fun iru ẹmí ti o fi ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe le e lọwọ.

Niwọnbi gbogbo wa ti jẹ ẹda, ti oye wa si kuru lọpọlọpọ, ko si ẹni kan ninu wa ti o le ri tabi ti o le loye gbogbo awọn iṣoro ti o n yọju ninu iṣẹ Oluwa nigbakuugba. A fun awọn miran ni ẹbun fun awọn ohun kan, awọn miran si ni ẹbun ti o yatọ. Awọn miran jẹ olohùn-iyọ nigba ti awọn ẹlomiran ni ẹbun iṣẹ-ọwọ. Awọn miran jẹ opè ninu iṣẹ kan, ṣugbọn ninu iṣẹ miran wọn jẹ ogbogi. Gbogbo eniyan ni iṣẹ n bẹ fun, kò si si ẹni ti kò wulo.

Gbogbo wa ni lati wà ni ifọwọ-sowọpọ. Bi ẹni kan kò ba le ṣe iṣẹ kan, ẹlomiran ni lati dide bi ọkunrin lati di àfo yi. Bi ẹni kan kò ba ni ipa lati ṣe ohun kan, ẹlomiran ni lati ṣe iranwọ, i baa ṣe nipa ọrọ iṣiri tabi nipa adura ẹbẹ. A le ṣe ohun ribiribi fun Ọlọrun ati fun eniyan bi iṣọkan tootọ ba wa laarin awọn ti o gbagbọ.

Awọn Ohun-Amuyẹ ti Oṣiṣẹ Nilati Ni

Ohun ti o ya ni lẹnu gidigidi ni lati ṣe akiyesi bi ohun ti awọn Apọsteli wo bi ohun amuyẹ ti awọn oṣiṣẹ ni lati ni ti yatọ si eyi ti awọn eniyan aye n wò. Ohun ti awọn eniyan n wo kò si ninu awọn ohun amuyẹ rere ti awọn Apọsteli to silẹ lẹsẹẹsẹ nihinyi.

“Ọkunrin olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmi Mimọ ati fun ọgbọn” ni ẹniti Ọlọrun le lo fun iṣẹ Rẹ. Boya a le beere pe “eredi rẹ ti a fi dandan le awọn ohun àmúyẹ ti ẹmí ninu awọn ti a o yàn lati ṣe iriju ninu ọgba ajara Ọlọrun? Ki ha ṣe ipinfunni ounjẹ lasan ati nkan wọnni ti awọn ijọ ṣe alaini ni awọn eniyan wọnyi yoo maa bojuto?” Bẹẹ ni, iṣẹ wọn ni eyi, iṣẹ yi paapaa ati iṣẹ miran ti i ṣe ti Ijọba Ọrun, gbà pe ki awọn iranṣẹ Kristi jẹ “olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmi Mimọ ati fun ọgbọn.”

Lai si tabitabi ẹnikẹni ti i baa ṣe ọmọ ẹgbẹ Ijọ Kristi ni lati jẹ olorukọ rere. Gbogbo iwa aiṣododo rè̩ atijọ ti kọja lọ. O ti di ẹda titun. Oun kò jẹ rin ni ọna aiṣododo mọ. Nitori naa bi ẹni kan ba fẹ di oṣiṣẹ ṣugbọn ti è̩gan tabi aiṣedede kan ba wà lọna rè̩, o hàn gbangba pe oluwarẹ ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ Ijọ Kristi, kò si ni ẹtọ lati jẹ oṣiṣẹ tabi aṣoju Ijọ.

Paulu Apọsteli ṣe àlàyé si i nipa diẹ ninu awọn amuyẹ ti awọn oṣiṣẹ ni lati ni nigbati o n gba awọn eniyan ti o wà labẹ akoso rè̩ niyanju. O sọ pe iru awọn eniyan bẹẹ ni lati jẹ alailẹgàn ati ọkọ aya kan; o ni lati jẹ ẹniti o kun fun iṣọra, ti o si jẹ alairekọja, oniwa-rere, olufẹ alejo ṣiṣe, ati ẹni ti o ni ifẹ lati gbà ẹkọ, ti o si le kọ awọn ẹlomiran, bi eyi ba jẹ ipe rẹ. Oun kò gbọdọ jẹ onija, tabi olufẹ owo, tabi ẹni ti n fi iwọra wá ere si apo ara rè̩, kò gbọdọ jẹ alasọ tabi ẹni ti o ni ohun kan ninu si ẹlomiran, dajudaju, kò gbọdọ jẹ oloju-kòkòrò. O ni lati jẹ ẹni ti o kawọ ile ara rè̩ girigiri ti o si mu awọn ọmọ rè̩ tẹriba pẹlu iwa àgba.

S̩ugbọn awọn ohun àmúyẹ rere wọnyi nikan kọ ni awọn ti o n ṣiṣẹ ninu ọgba ajara Ọlọrun gbọdọ ni. Awọn ti a yàn fun iṣẹ ni lati kún fun Ẹmi Mimọ ati ọgbọn. Ohun afiyesi ni pe a mẹnukan ọgbọn gẹgẹ bi ohun ti o ni isopọ pẹlu Ẹmi Mimọ.

Ọgbọn ti a ni lati ni bi a ba fẹ fi tọkantọkan ṣiṣẹ fun Ọlọrun, ni ọgbọn ti o ti oke wa. Eyi ki i ṣe ọgbọn ti aye, ti ara ati ti ẹmi eṣu, ti n da owu ati ija silẹ. S̩ugbọn ọgbọn ti o ti ọdọ Ọlọrun wá “a kọ mọ, a si ni alafia, a ni ipamọra, ki si iṣoro lati bè̩, a kún fun ānu ati fun eso rere, li aisi egbe, ati laisi agabagebe” (Jakọbu 3:17). A le beere rè̩ pẹlu igbagbọ, lai ṣiyemeji, nitori pe Ọlọrun n fi fun “gbogbo enia li ọpọlọpọ” (Jakọbu 1:5, 6). Nitori naa ko si awawi fun ẹnikẹni ti ko ni in. Bi ẹni kan kò bá ni in, eredi rè̩ ni pe oun ko beere ati pe o ni itẹlọrun lati maa lọ ninu ọgbọn ti ara rè̩, ninu oye ati mo-to-tan ti ara rè̩.

Olubori àmúyẹ ti oṣiṣẹ gbọdọ ni ni ifi Ẹmi Mimọ wọ ni. Eyi yi ni agbara lati oke wá ti n ba ni gbe ti o si n fun ni ni agbara fun isin. Agbara yi ni Jesu ṣeleri ki O to lọ si ori Agbelebu lati kú, ati ṣaaju igoke-re-Ọrun Rè̩. (Ka Johannu 14:15-26; 15:26, 27; 16:7-15; Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). O jẹ ẹbun atokewa ti n fun wa ni ihamọra ati aṣẹ lati ṣiṣẹ, o si n fun wa ni iranwọ lati mu awọṅ eniyan wa sọdọ Ọlọrun.

Awọn Ojuṣe Pataki ninu Iṣẹ Ijọ Igbagbọ Apọsteli

Pẹlu ikiyesara gidigidi, Alabojuto wa àgbà kinni ati awọn isọngbe rẹ fi ipilẹ Ijọ yi lelẹ lọna ti o bá ẹkọ Ọrọ Ọlọrun mu lọnakọna. Bi wọn ti woye pe awọn ojuṣe ti ẹmí ni a kọ mẹnukan, ti a si kọ yan awọn oṣiṣẹ si ninu Ijọ Akọkọbẹrẹ, awọn àye wọnyi naa ni a kọ bojuto ti a si yan awọn oṣiṣẹ si ninu iṣẹ Ijọ Igbagbọ Apọsteli.

“Oniruru iṣẹ-iranṣẹ li o si wà” ati “oniruru iṣẹ li o si wà” ninu iṣẹ wa gẹgẹ bi ti igba aye awọn Apọsteli. Lati waasu Ọrọ Ọlọrun ni iṣẹ ti o ṣe pataki ju lọ ninu Ijọ, awọn ti o ni ipè ati gbogbo ẹbun ati oore-ọfẹ fun iṣẹ ti o beere ijolootọ patapata ati ifi ara ẹni rubọ kíkún yi ni a gbọdọ fi iṣẹ naa le lọwọ. Iṣẹ yi ni o ni lati gba ipò kinni ninu gbogbo iṣẹ ti a n ṣe ninu Ile Ọlọrun. Oun ni o gbọdọ leke ki o si jẹ pataki ju lọ ninu ohunkohun ti Ijọ n dawọle lati ṣe. O jẹ dandan pe àyè woli (awọn oniwaasu Ọrọ Ọlọrun) ajihinrere, oluṣọ-agutan ati awọn olukọni, kò gbọdọ wà lofo, ki a ba le ṣe awọn eniyan mimọ ni aṣepe ati lati mu awọn Onigbagbọ dàgba.

Lẹhin ti a ti dí awọn àyè wọnyi ti i ṣe ti ẹmi tan ni anfaani ṣẹṣẹ ṣi silẹ lati bojuto awọn àfo miran ti o ṣe pataki fun itankalẹ Ihinrere Kristi. Lati igbati iṣẹ Ijọ Igbagbọ Apọsteli ti bẹrẹ ni a ti fi kọ ni wi pe ko gbọdọ si adamọ tabi iyapa ninu ara Kristi. Gbogbo wa ni lati wa ni iṣọkan ti ko ṣe e fẹnu sọ iru eyi ti o ṣe pe laarin awọn ti a sọ di mimọ patapata nikan ni a gbe le ri i (Ka Heberu 2:11; Johannu 17:9-23; Efesu 5:22-32). A fi ye ni wipe a ni lati ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati letoleto lati gbé ni ro (I Kọrinti 14:26, 40) nitori pe Ọlọrun ki i ṣe olupilẹṣẹ ohun rudurudu (I Kọrinti 14:33). Ẹmi awọn alufa Ihinrere ni lati maa tẹriba fun ara wọn (I Kọrinti 14:32; I Peteru 5:5, 6). Awa pẹlu ti a jẹ ọkan lara awọn ti o gbagbọ ni lati maa tẹriba fun ara wa gẹgẹ bi a ti fi le awọn alufa Ihinrere lọwọ lati fi ọgbọn, oye ati imọ nipa ti ẹmi ti awọn alufa ẹlẹgbẹ wọn ni pè. Ẹnikẹni ninu wa yala alufa tabi ọmọ Ijọ kò gbọdọ fi iwa ‘mo-le-dá- wà’ hàn ninu iwa tabi iṣe wa si ara wa, bẹ ni a kò gbọdọ ro pe a to tan loju ara wa lọnakọna. Paapaa ju lọ, ni akoko yi ti ipadabọ Oluwa sunmọ tosi, ti ẹtan n pọ si i ninu aye, a ni lati fi ọkàn tán ara wa, ki a si maa ran ara wa lọwọ ninu gbogbo aini wa nipa ti ẹmi.

A ni lati fi “itara ṣafẹri ẹbun ti o tobi ju” ki “a si mā jà gidigidi fun igbagbọ ti a ti fi le awọn enia mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” (I Kọrinti 12:31; Juda 3). A ni lati “ru ẹbun Ọlọrun soke” eyi ti o wà ninu wa (II Timoteu 1:6). A ni lati fi agbara wa ṣe ohunkohun ti ọwọ wa ba ri ni ṣiṣe (Oniwasu 9:10). Nigba ti a ba ti ṣe eyi pẹlu gbogbo ipa wa, a ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo tu ibukun Rè̩ si ori iṣẹ wa. Bi a ti n ba iṣẹ Ihinrere yi lọ ni Ọlọrun n gbe e niyi ti o si n bukun un. Bi Ẹmi Mimọ ti ṣe ti iṣẹ yi lẹhin, ti àmi ti Ọlọrun ṣeleri si n tẹle iṣẹ wa ati adura atọkanwa ti a n gbà, fun ni ni idaniloju pe ọna ti a n gba ṣe iṣẹ naa jẹ ọna ti o tọna.

A ni Alabojuto Agba ati Igbakeji Alabojuto Agba, lori awọn ẹni ti pataki ẹru Ijọ Igbagbọ Apọsteli wà. Ẹka Ijọ Igbagbọ Apọsteli kọọkan si wà labẹ akoso Alabojuto Agba ti n bẹ ni Iya Ijọ wa. Ki a to le ṣe awọn èto ti o jẹmọ ofin ijọba ati abojuto awọn ọran ti o jẹmọ akoso Ijọ Igbagbọ Apọsteli ti Portland Oregon ati gbogbo awọn ẹka rẹ, ofin ijọba beere pe ki a ni Igbimọ Alabojuto Ohun-ini Ijọ ni ibujoko Iya Ijọ wa. Ninu awọn alufa ni a ti n yàn awọn Igbimọ yi, Ijọ yoo si fi ọwọ si i ninu ipade awọn ọmọ Ọlọrun. Akọwe ti n ṣe Akapo pẹlu, ni n ṣe abojuto owo ati awọn ọran ti o ba jẹmọ ofin. Oun ati awọn Igbimọ Alabojuto Ohun-ini Ijọ ni apapọ ni a n pe ni Igbimọ Alabẹ S̩ékélé.

A ni awọn Alàgbà ati diakoni l’ọkunrin ati l’obinrin ninu Ijọ wa bi o ti wà ni Ijọ igbaa nì. Iṣẹ awọn alagba ni lati maa ran awọn Ojiṣẹ Ọlọrun lọwọ, lati duro ti wọn gbọningbọnin pẹlu ọkàn kan ninu ohun gbogbo ti a n ṣe fun itẹsiwaju Ihinrere. Awọn eniyan Ọlọrun wọnyi l’ọkunrin ati l’obinrin a maa ṣe iṣẹ ti o jẹ mọ ti ẹmi, eyi ti o ṣe pe awọn alufa nikan ni o tun le ṣe. Wọn le gbadura fun awọn alaisan, i baa ṣe pẹlu alufa tabi pẹlu alagba miran. Nigba ti alufa ba n gba ni niyanju tabi o n ba ni wi, oun a saba maa pe alàgba kan lati wà ni ijoko bi ẹlẹri lati fi idi otitọ ati ibawi naa mulẹ. Igba pupọ ni awọn alufa i maa fẹ ki awọn alàgba wà pẹlu wọn nigbati wọn ba n dán awọn ẹmi wò bi wọn ba i ṣe ti Ọlọrun (I Tẹssalonika 5:21; I Johannu 4:1). Awọn alagba wọnyi jẹ ojulowo oṣiṣẹ ti o ni ìpe lati ọdọ Ọlọrun wa, ti ifẹ wọn fun igbala ọkàn awọn eniyan kò kere, bẹẹ ni igbagbọ wọn ninu ẹkọ Ọrọ Ọlọrun ati ijolootọ wọn si Ihinrere kò kẹrẹ. Igba pupọ ni ọlọgbọn alufa i maa beere imọran lọwọ wọn, igba pupọ ni a si maa n ke si wọn lati kún igbimọ ti n ṣe akoso nigbati ọran pataki ba delẹ. Igba pupọ ni a n pe wọn ni igi lẹhin ọgba laarin ijọ Ọlọrun, igbagbọ ati adura wọn si jẹ eyi ti o niyelori lọpọlọpọ.

Awọn diakoni lọkunrin ati l’obinrin ni n ṣe abojuto oniruuru iṣẹ ọwọ ninu ile Ọlọrun. Awọn ni a fi iṣẹ itọju ile Ọlọrun ati awọn nkan ti iṣe ti Ọlọrun le lọwọ. Awọn ni o si n bojuto awọn ohun-elo wọnni ti a n lò lati fi tan Ihinrere kalẹ.

Ninu ijọ wa, a kò gbe oyè tabi ipò pọn gẹgẹ bẹẹ ni a kò ni aṣọ tabi ẹwu oyè; ṣugbọn a mọ iyì iṣẹ pataki ti awọn wọnni ti n bẹ ni àyè wọnyi n ṣe. Olukuluku wọn ni Ọlọrun pè lati ṣiṣẹ, Ẹmí Mimọ ni o si n wa awọn ti o jafáfá ju lọ fun iṣẹ ati àyè kọọkan ninu Ijọ Kristi. Ifẹ ati ipinnu wa ni lati ri i pe lọna bayi ni igbega ti n wá. Nitori idi eyi, ati lati gba Ẹmi Ọlọrun laaye lati jẹ alakoso ninu Ijọ wa, a ṣe èto igbekalẹ ilana ti a n tẹle lati ṣiṣẹ ni iwọntúnwọnsi.

O daju pe gbogbo awọn ti Ọlọrun pè ni o yẹ ki awọn eniyan Ọlọrun maa bọwọ fun. Iṣẹkiṣẹ tabi ayekaye ninu Ijọ Ọlọrun ni o ṣe pataki, ipo tabi àye ti o wu ki ẹni kọọkan wà ni o ṣe pataki ti o si gba pe ki a sa ipa wa. Ki a to le kà wa si olootọ, a ni lati fi gbogbo agbara wa ṣiṣẹ ti a pè wa si; nipa ṣiṣe bayi ni a fi le ka wa yẹ fun iṣẹ ti o ga ju ti iṣaaju.

Filippi ati Stefanu jẹ olootọ ninu iṣẹ wọn, nitori naa, a fi wọn si àye ti o ga si i ninu iṣẹ iwaasu Ọrọ Ọlọrun. Iwaasu Stefanu ru awọn akorira-Kristi ti o wà nigba ti rẹ ninu, ṣugbọn o gba iyin o si ṣe aṣeyọri iṣẹ ti a fẹrẹ sọ pe iwọn iba eniyan diẹ ni o ti i ṣe iru rè̩ bi o ba tilẹ wà rara. Filippi waasu Ihinrere fun ọpọlọpọ ọdun ni ibi pupọ, Ọlọrun si lo o ni ọna iyanu lati mu Otitọ tọ awọn ti o wà ninu aini lọ. Apẹẹrẹ mejeeji wọnyi fi hàn wa pe ijolootọ lere ti rè̩, a si le ri i pẹlu pe iyìn ati ọlá yẹ fun awọn ti a pè si iṣẹ-ianṣẹ, nitori ninu awọn wọnyi ni a gbe le ri awọn alufa ati awọn aṣaaju ninu iṣẹ ti ẹmí lẹhinwa ọla.

Eto iṣakoso kan naa ni awọn ẹka ijọ wa ati Iya Ijọ wa n tẹle. Awọn alufa, awọn alagba, diakoni l’ọkunrin ati l’obinrin a maa ṣe iranwọ fun alufa tabi alakoso ti o wà lori Ijọ kọọkan, gẹgẹ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ: gẹgẹ bi ijọ ba ti pọ to. A le yan ẹni kan lati maa ṣe abojuto ọran owo gẹgẹ bi a ti n ṣe ni Iya Ijọ wa. Bi o tilẹ jẹ pe a kò yan awọn ti a mọ ni Igbimọ ti o n ṣe Abojuto Ohun-ini Ijọ, sibẹ ọlọgbọn alufa kò ni ṣalai ni awọn wọnni ti o ni ọgbọn ati imọ nipa ohun ti i ṣe ti Ẹmi lati maa ran an lọwọ ninu awọn ọran ti n ṣẹlẹ nigbakuugba ninu iṣẹ Ọlọrun.

Wo bi anfaani ati jẹ ọkan ninu ijinlẹ ara Kristi ti pọ to – Iyawo Kristi – ani lati jẹ alabaṣiṣẹpọ pẹlu Kristi ninu iṣẹ irapada ọkàn! Awa ni a fi iṣẹ iranṣẹ ati ọrọ ìlaja le lọwọ (II Kọrinti 5:18, 19). Awa jẹ “iriju awọn ohun ijinlẹ Ọlọrun” (I Kọrinti 4:1). Ẹmi Mimọ ati Iyawo Kristi ni o n mu Ihinrere tọ awọn ọkàn ti n ṣegbe lọ lọjọ oni, ni imurasilẹ fun Ọjọ Oluwa (Ifihan 22:17).

Ogun n bẹ lati jà fun Ọlọrun, ṣugbọn “ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ” (II Kọrinti 10:4). A ni iṣẹ ribiribi lati ṣe, àfo si n bẹ lati di. Wo bi anfaani wa ti pọ to! Wo bi eso iṣẹ wa fun Ọlọrun yoo ti pọ to, bi a ba fi tọkantọkan ṣe ohun ti a fi le wa lọwọ lati ṣe! Ere wa yoo ti logo to bi a ba foriti i titi de opin ti a si ru iti wa wọle si ẹsẹ Rẹ nitori ti a ti fi otitọ, ikiyesara ati itara mimọ ṣe ohun wọnni ti O fun wa lati ṣe!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Kin ni iyatọ ti o wà laarin ọmọ-ẹhin ati Apọsteli?
  2. Kin ni iṣẹ oluṣọ-agutan? ẹfangẹlisti? olukọ?
  3. Eredi rẹ ti a fi yàn awọn diakoni meje ni akoko yi?
  4. Iṣẹ wo ni o ṣe pataki ju lọ ninu Ijọ Kristi?
  5. Sọ diẹ ninu awọn ohun àmúyẹ ti oṣiṣẹ ninu ijọ ni lati ni.
  6. Kin ni iṣẹ awọn alàgba?
  7. Ninu awọn wo ni a ti n yàn awọn alàgba ninu Ijọ?
  8. Kin ni iṣẹ diakoni l’ọkunrin ati l’obinrin?
  9. Awọn meji wo ninu awọn diakoni meje ni ni o di oniwaasu nla?
  10. Tani n fun ni ni igbega ninu Ijọ Kristi? Iru ọkan wo ni kò dara lati ni nipa igbega?