Owe 1:1-33; 2:1-22

Lesson 275 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ibè̩ru OLUWA ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọn ati ẹkọ” (Owe 1:7).
Cross References

I Ipe Ọgbọn

1. A fi owe fun ni lati kọ ni ni ọgbọn, Owe 1:1-6; Matteu 13:10, 11; Marku 4:10-12

2. Ẹkọ obi jé̩ ọṣọ oore-ọfẹ iyebiye, Owe 1:7-9; Ẹksodu 20:12

3. Kọ è̩tan buburu silẹ, Owe 1:10-19; 1Tẹssalonika 5:22; 1Kọrinti 15:33

4. A gbọ ohun ọgbọn nibi gbogbo, Owe 1:20-23; Orin Dafidi 19:1-6; Luku 9:6; Iṣe Awọn Apọsteli 8:4; Romu 1:18-21

5. A ṣe idajọ ẹlẹgan, Owe 1:24-32; 29:1

II Èrè jijẹ Ipe naa

1. Ifetisilẹ lere, Owe 1:33; Jeremiah 38:20

2. Ẹni ti o fara balẹ wa Ọlọrun yoo ri I, Owe 2:1-5; Jeremiah 29:13; Matteu 5:6; 13:44

3. Ọlọrun ni o n fun ni ni ọgbọn, Owe 2:6-9; Jakọbu 1:5

4. Imoye yoo pa ọ mọ, Owe 2:10-22; Daniẹli 4:27

Notes
ALAYÉ

Ọgbọn di Eniyan

“Ọgbọn nkigbe lode; o nfọhùn rè̩ ni igboro:

“O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọrọ rè̩” (Owe 1:20, 21).

Iwe Owe kún fun ọpọ asọtẹlẹ. Dajudaju ẹmi kan wà ninu Sọlomọni ti o ni imọ nipa eto Ọlọrun fun araye ni ọjọ iwaju nigba ti o n kọ awọn ọrọ ti o mu ni lọkan ṣinṣin wọnyii. Ọgbọn ti a n sọrọ rè̩ yii ki i ṣe ohun miiran bi ko ṣe Ẹni kan ani Kristi Jesu ti i ṣe Ọgbọn ti o gbe ara eniyan wọ -- ki i ṣe ọgbọn aye yii, ki i ṣe ọgbọn ti awọn eniyan n wá kiri ninu aye lode oni, ṣugbọn ọgbọn ti o ti oke wá.

Ọmọ Ọlọrun dide duro ni ọjọ nla nì ti i ṣe ọjọ ti o kẹyin ajọ, O si wi pe, “Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu” (Johannu 7:37). Ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii, a ri i pe “Ọgbọn nkigbe lode; o nfọhùn rè̩ ni igboro.” Jesu duro ni igboro; a ri I ni ọja, O n kọ ni ni awujọ nibi ti ọpọ eniyan pejọ si.

Ọgbọn Ọlọrun

Gbogbo ọgbọn Ọlọrun n gbe inu Jesu Kristi. Ninu akọsilẹ ti o wà ninu awọn Episteli, a ka a pe, ninu Rè̩ ni “gbogbo è̩kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara,” ati ninu Rè̩ ni “a ti fi gbogbo iṣura ọgbọn ati ti ìmọ pamọ si” (Kolosse 2:3, 9). Ọrọ Ọlọrun ni ọgbọn Ọlọrun; nigba ti ọkunrin tabi obinrin ba n ṣe afẹri Ọrọ Ọlọrun, bi a ba si kọ ilana wọnni sinu tabili ọkàn ẹran, yoo di ọlọgbọn si igbala; nigba naa ni yoo mọ ohun ti o yẹ ni mimọ ju ohun gbogbo lọ -- iduro rè̩ nipa ti ẹmi niwaju Ọlọrun. Nigba ti Paulu n ba awọn ara Kọrinti sọrọ, o sọ bayii pe, “Awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsè̩ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene; ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọn Ọlọrun” (1Kọrinti 1:23, 24).

Ewu Ijafara

Igbe ti ọgbọn n ke ni igboro ni eyi, pe, “Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọkan ti ẹnyin yio fi ma fẹ aimọkan?” Awọn “alaimọkan” ni awọn wọnni ti o n gbe igbesi-aye ainaani, wọn kò rò nipa Ọlọrun igbala wọn, wọn kò si ro igbẹyin wọn. Ikilọ kan wà ninu Ọrọ Ọlọrun ti o wi pe, “Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi” (Heberu 2:3). Awọn miiran kò naani igbala ọkàn wọn, wọn si lero wi pe aanu Ọlọrun yoo gboju fo ainaani wọn dá, yoo si ṣi Ilẹkun Ọrun silẹ fun wọn, yoo si gbà wọn tọwọ tẹsẹ si Ita Wura nì; ṣugbọn Iwe Mimọ sọ fun ni gbangba kedere wi pe “awọn alaimọkan” ti o ṣe alainaani igbala nla bayii ki yoo le sa asala.

Ọgbọn Ayé

O le jẹ pe ọgbọn aye ni iwọ n lepa, o si le jẹ pe ọna ti aye n rin lode oni naa ni iwọ naa n tọ. Awọn eniyan n wara pàpà lati ni ọgbọn aye yii, wọn n ṣe afẹri imọ ati ẹkọ giga. Ile ẹkọ awọn alakọbẹrẹ, ile ẹkọ giga ati ile ẹkọ ti o ga julọ ti yunifasiti ti a n kọ kaakiri ni gbogbo aye jẹ ẹri bi ọkàn ọmọ eniyan ti n wara pàpà to lati ni imọ ati oye. A kò le mọ gbogbo awari ti o ya ni lẹnu ti ọmọ eniyan ti ṣe lọjọ oni. S̩ugbọn pẹlu gbogbo ọgbọn aye yii, sibẹ ọkan ọmọ eniyan n ṣegbe – o n ṣegbe bi awọn alailẹkọọ wọnni ti kò ronupiwada ti o wà ninu ilu wọnni ti kò laju.

Ẹlẹgàn

Ọgbọn n kigbe lode; imọ n fọhun rè̩ ni igboro: “Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọkan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọkan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu è̩gan wọn?” (Owe 1:22). Awọn kan wà ti wọn tilẹ n da ṣiọ orukọ Jesu, wọn a si maa sọrọ alufanṣa si Iwe Mimọ wi pe, “Awa n fẹ Bibeli asiko ti o ba ode-oni mu.” Ero ọrun apaadi ni wọn gẹgẹ bi awọn wọnni ti kò naani iru igbala nla bi eyi. “Yio ti pẹ tó ... ti ... awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ?” (Owe 1:22).

Ọlọrun ki i pe eniyan ni aṣiwere nitori ti ẹni naa jẹ ọdè̩ -- rara o! A pe wọn ni aṣiwere nitori ti wọn kò ro igbẹyin wọn, wọn kò si naani ohun ti o ṣe pataki ju lọ fun ire ọkàn wọn ti ki i kú.

Jesu sọ nipa ọkunrin kan ti o fi ọdun pupọ to ọpọlọpọ ọrọ jọ sinu aka, ṣugbọn nigba ti ọkàn rè̩ wa balẹ lori ọrọ yii, Ọlọrun fọhùn lati Ọrun wa wi pe, “Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ” (Luku 12:20). Ọlọrun kò pe e ni aṣiwere nitori ti ori rè̩ kò pé, Ọlọrun ba a wi nitori ti kò naani ọgbọn ti o ti oke wá. O jọ ara rè̩ loju, awọn nnkan wọnni ti yoo tẹ ifẹkufẹ ọkàn rè̩ lọrun nikan ni o lepa, ọwọ rè̩ si tẹ ẹ; ṣugbọn laaarin gbogbo ọrọ ti o yi i ka, o gbọ ohùn Ọlọrun ti o wi pe, “Iwọ aṣiwere.” Oun kò tẹtilelẹ si Ohun Ọgbọn ti n ke si gbogbo eniyan nibi gbogbo wi pe, “Ẹ yipada ni ibawi mi” -- ẹ ronupiwada, mura lati pade Ọlọrun.

Igbẹyin Awọn ti o Kọ

Wo bi ibanujẹ awọn ti o kọ lati yipada kuro ninu è̩ṣẹ yoo ti pọ to, awọn ẹni ti ohun Ọlọrun yoo fọ si wi pe, “Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si: ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi: Emi pẹlu o rẹrin idāmu nyin; emi o ṣe è̩fẹ nigbati ibè̩ru nyin ba de” (Owe 1:24-26). Ọrọ Ọlọrun sọ fun ni pe gbogbo awọn ti o kọ Ọ ati ipe Rè̩ yoo “jẹ ninu ère iwa ara wọn” (Owe 1:31).

Ọrun apaadi ti o gbona janjan ati ìṣé̩ oró ti kò lopin jẹ ohun ti o lẹru pupọ to bẹẹ ti kò fi yẹ ki a ri ẹnikẹni ti o lọgbọn lori tabi ti oye rẹ pé ti yoo kuna lati fetisi ohun Ọlọrun. Sibẹ ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ni o ntọ ọna iparun ti wọn kò naani ibi ti wọn yoo gbe lo ayeraye. Wọn a maa rẹrin ninu ọna egbe ti wọn n rìn, wọn a si maa fi ipe Ihinrere ṣẹsín; ṣugbọn kì yoo ri bẹẹ mọ nigba ti bìrí ba yi mọ wọn, ti Ọlọrun si wi pe, “Emi pẹlu o rẹrin idāmu nyin.” Ki ni yoo de ba ẹrin iyangi awọn ẹlẹgan nigba ti “Ẹni ti o joko li ọrun yio rẹrin;” ti “Oluwa yio yọ ṣùti si wọn” (Orin Dafidi 2:4).

Wiwá Ọlọrun

Ẹni ti o ba fẹ bọ kuro ninu idajọ Ọlọrun ni lati fetisi ipe Rè̩. Alaanu ati Oloootọ ni Ọlọrun; ṣugbọn ẹnikẹni kò le ni igbala lai jẹ pe o fi tọkàntọkàn wa a pẹlu ironupiwada. A kò pe wa lati fetisi ipa ọgbọn nikan, bì ko ṣe lati fi ọkàn si i pẹlu. “Ani bi iwọ ba nke tọ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye; Bi iwọ ba ṣafẹri rè̩ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ; Nigbana ni iwọ o mọ ibè̩ru OLUWA, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun” (Owe 2:3-5).

Awọn eniyan ti fi ori la igbo didi kọja, wọn la ọna, wọn gba inu yinyin tutu ninnin, wọn mookun ninu òkun jijin, wọn si fi ẹmi wọn wewu ni oniruuru ọna lati wa alumọni aye yii. Idahun ati itara ti ìpe ọgbọn n beere lọwọ olukuluku kò dinku si eyi lọnakọna. Ọlọrun fẹ ki gbogbo eniyan ki o ni iru itara kan naa, ki wọn ja pẹlu ọkàn akin bakan naa, ki wọn si ṣe aapọn bakan naa, ki aṣiiri Ijọba Ọlọrun le tẹ wọn lọwọ.

Ọrọ ti o tayọ ti aye yii wà ninu ìmọ Ọlọrun. Ọrọ aye kò duro pẹ, ṣugbọn ọgbọn Ọlọrun duro titi laelae. Ọpọlọpọ ilepa ọrọ aye yii ti yọri si ikú ati ijanba, ṣugbọn ibẹru Oluwa a maa fun ni ní iye ainipẹkun. Ihinrere n fẹ awọn wọnni ti o le duro bi akin lati fara da iyọṣutisi, ẹsín ati è̩gan awọn ẹlẹgan, lati kọjuja si ogun Satani ati lati di otitọ Ọrọ Ọlọrun mu. Ọna ododo, idajọ, otitọ ati ọna rere gbogbo ṣi silẹ fun awọn ti o ba fi ọkàn wọn si ipa ọgbọn lati moye ọna Ọlọrun.

“Ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rè̩.

“S̩ugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rè̩” (Owe 2:21, 22).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni owe wà fun?
  2. Iha wo ni aṣiwere kọ si ẹkọ?
  3. Ki ni a fi imọran awọn obi wé?
  4. Ki ni ọna awọn wọnni ti n ṣe ojukokoro èrè?
  5. Awọn ta ni a pe ni “alaimọkan” ninu Owe 1:22?
  6. Ki ni opin awọn ti o kọ ipe Ọlọrun?
  7. Owe wo ni Jesu pa ti o fara jọ eyi ti o wà ninu Owe 2:1-5?
  8. Nibo ni ibujoko “Ọgbọn” wà ninu olukuluku?
  9. Sọ diẹ ninu awọn èrè ti yoo jẹ ti awọn ti o ba wa ọgbọn ri.