Orin Dafidi 92:1-15

Lesson 307 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi o ṣọpẹ fun ọ ninu ajọ nla: emi o ma yìn ọ li awujọ ọpọ enia” (Orin Dafidi 35:18).
Notes

Ọpẹ ati Iyin

Gẹgẹ bi ọjọ Idupẹ ti tun de, olukuluku Onigbagbọ gbe ọkan rè̩ soke si Ọlọrun ni iyin ati imoore fun gbogbo ibukun ti wọn ti ri gba. Sibẹ, ki i ṣe ni ọjọ isinmi yi nikan ṣugbọn ni gbogbo ọjọ ti o wà ninu ọdun ni ọmọ Ọlọrun n fi ọpẹ fun Un. Ẹsẹ meji ti o ṣaaju ninu Psalmu yi sọ ohun mẹta fun wa lati ṣe: akọkọ, fi ọpẹ fun Oluwa; ekeji, kọrin iyin; ati ẹkẹta, fi iṣeun-ifẹ Rè̩ han. A paṣẹ fun wa lati maa ṣe eyi ni owurọ ati ni aṣaalẹ.

Ninu Adura

Ẹ jẹ ki a wo iye ọna ti a le gba fi maa yin Oluwa. Ọna kan ni adura. Nigba ti a ba wolẹ lẹba ibusun wa, tabi ninu iyara, tabi ni ibi pẹpẹ adura ni ile Ọlọrun, ti a si bẹrẹ si i yin In fun oore Rè̩, yoo pade wa ninu adura Oun a si tu ibukun ọtun jade sori ọkan wa. Bakan naa bi a ti n lọ lẹnu iṣẹ wa ti a si n fi iyin fun Ọlọrun kẹlẹkẹlẹ ninu ọkan wa, ọpọlọpọ igba ni O maa n fi ayọ ati ifẹ bi odo ṣiṣan kun inu ọkan wa.

Ipade nibi ti a le jẹri si oore Ọlọrun jẹ ibi ti a ni anfaani lati yin Oluwa; ipade awọn ọdọ jẹ akoko ti o dara pupọ fun awọn ọdọ ati awọn ọmọde lati sọ ẹri wọn. “Jẹ ki awọn ẹni-irapada OLUWA ki o wi bẹ, ẹniti o rà pada kuro li ọwọ ota nì” (Orin Dafidi 107:2). Bi awọn ọmọde ba bẹrẹ ni kekere, yoo rọrun ninu ọpọlọpọ ọdun ti n bẹ niwaju lati dide duro laarin awujọ nla lati sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun wọn. Gẹgẹ bi ọmọ kekere kan ti dubulẹ lori ibusun rè̩ ni ilẹ ajọ-agọ wa ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin, o bẹrẹ si i ronu nipa aye rè̩ ni ọjọ iwaju. Bi ọmọbinrin yi ti n ro o bi oun yoo ti ṣe le lo ọjọ aye oun lọna ti yoo fi wulo, gẹgẹ bi o si ti n gbadura o dabi ẹni pe ohun ìlepa ti o ga ju lọ ti o le dawọle ni aye ni lati jẹ ajihinrere ni abuja ọna. Ọlọrun pese rè̩ silẹ fun iṣẹ yi, bẹẹ ni loni o n gbadun anfaani ti o ni nisinsinyi lati maa sọ ẹri rè̩ ni abuja ọna.

Ninu Orin

Ọna miran lati fi yin Oluwa logo ni nipa kikọ orin. Bi o ba ṣoro fun ọ lati kọrin, kọ ọ bi o ba ti le kọ ọ. Awọn ọmọde miran ni anfaani lati kọ ẹkọ lati tun ohùn wọn ṣe, wọn a si di akọrin daradara. Gẹgẹ bi wọn si ti n dagba, boya ohùn wọn yoo wulo lati maa gbe ogo Ọlọrun ga nibi isin apejọpọṣe, ati lati da awọn alaisan lara ya. Nibi pupọ ninu Bibeli ni a ri i pe orin kó apa kan pataki ninu isin Oluwa. Lotitọ, “ohun rere ni lati ma ... kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo” (Orin Dafidi 92:1).

Ninu Ohun-elo Orin

Ẹsẹ kẹta tun sọ fun wa ọna miran ti Onigbagbọ le fi iṣeun-ifẹ Oluwa han: “Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu.” Loni a le yin Ọlọrun pẹlu lara ohun-elo orin olokun mẹrin – fiolini, fiola, ṣẹlo, ati fioli olohun ilẹ. Piano ati harpu, ti o ni ọpọlọpọ okun, ni a n lo ninu isin Oluwa. A ko mọ oriṣiriṣi ohun-elo orin ti awọn ẹgbaaji (4,000) eniyan ti o wà ninu ẹgbẹ alo-ohun-elo orin Ọba Dafidi lò (I Kronika 23:5), ṣugbọn oriṣiriṣi ohun-elo orin ti a lo ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin ni a darukọ lẹsẹẹsẹ ninu Bibeli: ipe, psalteri, kọrneti, kimbali, dulkimeri, fere, ohun-elo orin bi àgbá, sakbuti, tabreti, timbreli, ati duru pẹlu awọn ohun-elo olokùn ti a ti darukọ tẹlẹ.

Ayọ ti o Yara Fo Lọ

Onipsalmu fi iyatọ ti o wà laarin eniyan buburu ati eniyan rere han. Lai si aniani o n fi eredi ti olododo ní ni ọkan rè̩ han ki o to maa fi iyin fun Oluwa. Boya awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin miran n ro pe awọn ọdọ ti wọn n lọ si ile iran-wiwo, ijo, ibi ere ifi-ẹsẹ-gba bọlu, ibi iṣire lori yinyin, ati ibomiran ti a ti n ṣe ere idaraya a maa gbadun akoko wọn jù awọn ti wọn n lọ si ile-isin, Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi, ibi ẹkọ orin ati ibi ẹkọ ohun-elo orin ti wọn si n kọ ẹkọ orin lati pese ara wọn silẹ fun iṣẹ Oluwa. S̩ugbọn jẹ ki a wo ohun ti ẹkọ yi n kọ wa.

A ri i ti a gbe aworan igi daradara meji siwaju wa, igi kedari ati ọpẹ. Labẹ igi kọọkan ni a ri eweko tutu diẹ eyi ti o rọ lai pe gẹgẹ bi oorun ti fi ooru gbigbona rè̩ lu wọn. S̩ugbọn gbongbo igi meji wọnyi n lọ jinlẹ si isalẹ ilẹ ju bẹẹ lọ lati wa omi, wọn a si tutu minimini, wọn a si ni awọ eweko daradara sibẹ.

Igbesi-aye ẹlẹṣẹ dabi koriko nì: “Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko” (Jakọbu 1:11). “Enia buburu rú bi koriko ... ki nwọn ki o le run lailai ni” (Orin Dafidi 92:7). Nitori naa a ri pe bi o tilẹ jẹ pe eniyan buburu fi ara han bi ẹni pe o ni inudidun nigba miran, sibẹ awọn ti o gbagbe Ọlọrun ti wọn si n gbe igbesi-aye ẹṣẹ, ti wọn si n lepa afẹ ara wọn nikan ṣoṣo, ni a o da sinu ọrun apadi pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ede ti o gbagbe Ọlorun (Orin Dafidi 9:17). Awọn oluṣe-buburu ati awọn oniṣẹ ẹṣẹ “ni a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutu” (Orin Dafidi 37:1, 2).

Igi Ọpẹ ati Kedari

Ẹ jẹ ki a wo ohun ti a sọ nipa awọn Onigbagbọ wayi: “Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dagba bi igi kedari Lebanoni” (Orin Dafidi 92:12). Ni ọna wo ni olododo fi dabi igi ọpẹ ati kedari? A mọ awọn igi meji wọnyi fun ẹwa wọn. Ni tootọ ki i ṣe dandan pe eniyan ni lati ni ẹwa nipa ti ara ki a to le fẹran rè̩ tabi ki o to le ni ọrẹ. Bi a ba ri ẹwa Jesu ninu igbesi-aye Onigbagbọ, o le jẹ ẹni ti a ko ka si laarin awọn ẹlẹṣẹ, ṣugbọn yoo ri ọpọlọpọ ọrẹ laarin awọn Onigbagbọ, nitori pe awọn eniyan Ọlọrun n fẹ lati wa pẹlu awọn ti o ni inurere, ti wọn kun fun ironu rere, ti wọn si jẹ mimọ ninu ọrọ wọn, ti wọn jẹ olootọ ati ẹni ti iwa rè̩ gún.

Kedari tun jẹ igi kan ti a mọ fun oorun didun rè̩. Nigba ti Jesu, Itanna eweko didun S̩aroni, ati Itanna Lili awọn Afonifoji (Orin Sọlomọni 2:1) ba wọ inu ọkan ẹni kan, iwọ ko ha gbagbọ pe yoo mu adun kan wa sinu igbesi-aye naa? A n kọ orin kan:

“Jesu, Itanna S̩aroni, tan ninu ọkan mi

Fi ẹwa otitọ ati iwa-mimọ Rẹ fun mi,

Pe nibikibi ti mo ba lọ ki aiye mi le mā tan kalẹ

run didun ti imọ ifẹ Ọlọrun.”

A maa n fi imọ ọpẹ tabi ki a mu un lọwọ gẹgẹ bi apẹẹrẹ iṣẹgun, inudidun, ati aja-bori. A mọ pe a té̩ imọ-ọpẹ si oju ọna nigba ti Jesu n wọ Jerusalẹmu gẹgẹ bi aṣẹgun. Onigbagbọ tootọ jẹ aṣẹgun nipa È̩jẹ Jesu. Ni ọjọ kan yoo lọ pẹlu ọpọlọpọ eniyan ti ẹnikẹni ko le kà, lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹya ati eniyan, ati lati inu ède gbogbo wa – a wọ wọn ni aṣọ funfun, imọ ọpẹ si n bẹ ni ọwọ wọn (Ifihan 7:9).

Igi ori-amọ ti fi ounjẹ-oojọ fun ọpọlọpọ ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ni apa Ila-oorun; a n yi eso rè̩ pada si ounjẹ fun ibakasiẹ; bẹẹ ni a si n fi awọn okun tinrin-tinrin ti o wà lara igi-ewe rè̩ hun okun ati okun-nla ti ọkọ. Opó igi rẹ jẹ igi lilo ti o niyelori; bẹẹ ni oriṣiriṣi ohun-elo ni a n ṣe lati inu ewe rè̩.

O n so Eso

Onigbagbọ pẹlu a maa so eso a si maa fẹ lati wulo ati lati ṣe iranlọwọ. Inu Jesu a maa dun nigba ti a ba n so eso pupọ. A ranti pe a ti kọ nipa eso ti ẹmi: ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa tutu ati ikora-ẹni-nijanu (Galatia 5:22). Nigba ti awọn ẹlomiran ba ri ifẹ Jesu bi o ti n tan ninu aye wa, bi wọn ba si ri i bi a ti kun fun alaafia to nigba ti nkan ba tilẹ lodi paapaa, wọn o mọ pe a ni Jesu ninu ọkan wa. Ọna miran lati “so eso” ni lati mu ẹlẹṣẹ wa sọdọ Jesu. Beere lọwọ Rè̩ ni owurọ ki o to lọ si ile-ẹkọ pe ki O ran ọ lọwọ lati sọ ọrọ kan fun Un; beere pe ki o fun ọ ni anfaani lati pe ọmọdekunrin kan, tabi ọmọdebinrin kan wa si ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi ti iwọ n lọ.

Awọn Ọmọ Ọlọrun

Igi Kedari ati igi ọpẹ ni a si tun maa n lo gẹgẹ bi apẹẹrẹ ipo-nla. Ki a ni iru ipo-nla bẹẹ ni pe “ki a bi enia li ẹni giga” tabi “ibi ti o ga” tabi “ipo giga.” A bi eniyan sinu ẹbi Ọlọrun nigba ti a ba tun un bi. Nipa bẹẹ, n jẹ a ko fun un ni ọla-nla nipa eyi pe o di ọmọ Ọba? Awọn Onigbagbọ ni “ọmọ Ọlọrun: bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa; ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi” (Romu 8;16, 17). Eyi yi fi awọn Onigbagbọ sinu Ẹbi Ọba; bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹlẹṣẹ le ṣe alaimọ eyi, dajudaju Onigbagbọ ni ipo giga tabi aye giga, paapaa ninu aye ẹṣẹ yi. “Ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a ko si ti ifihan bi awa ó ti ri” (I Johannu 3:2).

Oluwa Olododo

“Ẹni diduroṣinṣin ni OLUWA: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rè̩” (Orin Dafidi 92:15). O ha mu ki iyin kun ọkan rẹ, o ha si mu ki orin kun ẹnu rẹ lati ro pe ni ọjọ kan Oluwa olododo yoo mu awọn ti Rè̩ lọ si ibi ẹwa nì ti a n pe ni Ọrun? Olukuluku eniyan ni o ni anfaani lati mura silẹ fun Ọrun, ṣugbọn awon ti o ti ṣe buburu ti wọn ko si ronupiwada ẹṣẹ wọn ni a o ran lọ sinu iparun ayeraye lati ọwọ Oluwa yi kan naa ninu Ẹni ti ko si aiṣododo kan.

Ẹ jẹ ki a pinnu ninu ọkan wa lati maa wa ilẹ jin ju bẹẹ lọ ninu Ọrọ Ọlọrun ati ninu adura. Bi “gbongbo” igbala wa ba lọ jinlẹ sinu ifẹ Ọlọrun, a o dabi “igi ti a gbìn si eti ipa odo, ti nso eso rè̩ jade li akoko rẹ” (Orin Dafidi 1:3). Nigba naa a le yin Oluwa, ki i ṣe ni Ọjọ idupẹ nikan, ṣugbọn ni ojoojumọ bi ọdun ti n yi po.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Iye igba melo ni o yẹ fun wa lati maa fi ọpẹ fun Oluwa?

  2. 2 Darukọ ọna marun o kere tan, ti a le gba yin Oluwa logo.

  3. 3 Darukọ idi mejila ti o fi yẹ ki a kún fun ọpẹ si Oluwa.

  4. 4 Kin ni a fi eniyan buburu we?

  5. 5 Bawo ni Onigbagbọ ti ṣe dabi igi kedari ati igi ọpẹ?

  6. 6 Fi igbẹhin eniyan buburu we igbẹhin olododo.

  7. 7 Tani ẹni ti o n gbadun aye ju -- Onigbagbọ ni, tabi ẹlẹṣẹ? Kin ni ṣe!

2