Iṣe Awọn Apọsteli 9:1-31; Galatia1:11-19

Lesson 301 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹmi tikararè̩ li o mba ẹmi wa jẹri pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe” (Romu 8:16).
Cross References

I Ifarahan Kristi fun Saulu ni Ọna Damasku

1. A fi aṣẹ fun Saulu lati lọ mu awọn ọmọ-ẹhin ti o wà ni Damasku, Iṣe Awọn Apọsteli 9:1, 2; 8:3; I Timoteu 1:13

2. Imọlẹ kan yọ si i lojiji, ohùn kan si fọ si i lati Ọrun wá, Iṣe Awọn Apọsteli 9:3, 4

3. Jesu di mimọ fun Saulu, ẹnu ya Saulu a si sọ ohun ti yoo ṣe fun un, Iṣe Awọn Apọsteli 9:5-7; Galatia 1:11-19; I Kọrinti 15:8; Efesu 3:3

4. Ni ai riran, Saulu gbaawẹ o si gbadura fun ọjọ mẹta ni Damasku, Iṣe Awọn Apọsteli 9:8, 9

II Saulu, Ohun-elo Aayo ti a Yàn fun Awọn Keferi

1. Anania, ẹni ti o kun fun è̩ru ni a ran si Saulu, Iṣe Awọn Apọsteli 9:10-14

2. A sọ asọtẹlẹ ipe Saulu, ati awọn ohun ti o n bọ wa jiya rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 9:15, 16; I Kọrinti 15:10; II Kọrinti 11:23

3. Saulu kun fun Ẹmi Mimọ, oju rè̩ là, agbara rè̩ si bọ sipo, Iṣe Awọn Apọsteli 9:17-19

4. Saulu bẹrẹsi i waasu Kristi ni Damasku pẹlu agbara nla, Iṣe Awọn Apọsteli 9:20-22

III Saulu Sa Asala kuro lọwọ Awọn Ju

1. Saulu sa asala kuro lọwọ awọn Ju ti n fẹ lati gba ẹmi rè̩ ni Damasku, Iṣe Awọn Apọsteli 9:23-25

2. Barnaba ṣe alaye ọran Saulu laarin awọn eniyan mimọ ni Jerusalẹmu, awọn ẹni ti o n bẹru lati gba a mọra, Iṣe Awọn Apọsteli 9:26, 27; Galatia 1:17, 18

3. Saulu waasu pẹlu igboya, o si pada lọ si Tarsu fun igba diẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 9:28-30

4. Lẹhin inunibini nla wọnyi, Ijọ Ọlọrun wa ni alaafia, Iṣe Awọn Apọsteli 9:31

Notes
ALAYÉ

Igba Ọdọ Saulu

Saulu ni a fi bẹrẹ ẹkọ wa yi, ẹni ti o ṣe inunibini si Ijọ Kristi, o n mi ẹmi ikilọ ati pipa si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa. Saulu jẹ ọdọmọkunrin. O ṣe e ṣe ki o jẹ pe igba kan naa ti a bi Kristi ni a bi oun naa. Ara Tarsu ni, ilu kan ni Kilikia, ni iha ariwa Siria, ni ẹkùn Asia. Tarsu jẹ ilu ti ẹkọ gbe dunlè̩ gidi, gẹgẹ bi Alẹksandria ati Atẹni.

Boya nigba ti Saulu di nkan bi ọmọ ọdun mẹtala ni a ran an lọ si Jerusalẹmu nibi ti o dabi ẹni pe o gbe gbiyanju lati dara pọ mọ Igbimọ nla ti a n pe ni Sanhẹdrin. Ni Jerusalẹmu, ni ẹsẹ Gamaliẹli ẹni ti i ṣe olukọni pataki laarin awọn Sanhẹdrin ni o gbe kẹkọ. Ohun iyi ti o ṣọwọn gidigidi ni lati kẹkọ ninu Iwe Mimọ ati nipa isin awọn Ju labẹ olukọni pataki bayi.

Saulu jẹ ẹni ti a bi i re. A tọ ọ ni ile Ju. Ẹya Bẹnjamini ni o ti jade wa, Heberu lati inu Heberu, Farisi ti o muna. Loju rè̩, Jesu jẹ ọta igbekalẹ awọn Farisi. Lati pa ẹkọ igbagbọ ninu Kristi run patapata, eyi ti o gbà pe yoo bi isin awọn Ju wo, di ohun ti o leke lọkan rè̩. O pinnu lati ré̩hin Igbagbọ ninu Kristi ti o ṣẹṣẹ yọju yi. Ni ọdun pupọ lẹhin eyi, nigba ti o n kọwe si awọn ara Galatia, o sọ bayi pe, “Ẹnyin ti gburó ìwa-aiye mi nigba atijọ ninu ìsin awọn Ju, bi mo ti ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun rekọja ālà, ti mo si bà a jẹ: Mo si ta ọpọlọpọ awọn ojugba mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi” (Galatia 1:13, 14).

Ilu Damasku

Inunibini ti o ṣẹlẹ ni Jerusalẹmu ti mu ki ọpọlọpọ ninu awọn eniyan Ọlọrun sa lọ si Damasku. Boya Saulu ro pe awọn ọmọ-ẹhin Kristi ti tan patapata ni ilu Jerusalẹmu. Boya iṣẹ ti o ṣe ti wu u lori lọpọlọpọ. Nisinsinyi, pẹlu iwe aṣẹ lati ọdọ olori alufa lọwọ rè̩, o mu ọna Damasku pọn lati lọ mu ẹnikẹni ti n bẹ ni Ọna yi, ni didè wa si Jerusalẹmu, i baa ṣe ọkunrin tabi obinrin.

A sọ fun ni pe Damasku ni ilu ti o lọjọ lori ju lọ ninu aye yi. Mose mẹnukan an ninu Gẹnẹsisi 14:15. O to irin ọgọfa mile si iha oke ila oorun Jerusalẹmu, ilu ti o dara ni i ṣe, o duro bi ọṣọ olowo iyebiye laarin pẹtẹlẹ Siria ti o fuyi. Odo Abana, ti Naamani fi jalankato, ṣan kọja, ni mimọ gaara, laarin ilu yi.

Idalẹbi Ọkan

Saulu ni itara Ofin, o si ro pe oun n ṣe ifẹ Ọlọrun ninu inunibini ti o n ṣe si awọn Onigbagbọ. O fi ẹnu ara rè̩ sọ wi pe Ọlọrun ṣaanu fun oun nitori pe ni aimọ ni oun ṣe e. S̩ugbọn a gbagbọ pe ọkan rè̩ ko sinmi lati igba ti a ti sọ Stefanu ni okuta pa nitori pe ọwọ Ọlọrun wuwo si i lara. Oluwa sọ fun un wi pe, “Ohun irora ni fun ọ lati tapa si ẹgún.”

Igba pupọ ti idalẹbi ba wọ ọkan ẹni ti a ko ti i rapada, gbogbo ẹṣẹ ti o ti dá yoo wa siwaju rè̩ bi aworan ti n yi. Boya Saulu ri oju Stefanu ti o n dán ati ti ọpọlọpọ ninu awọn eniyan Ọlọrun ti o ti gbe ju sinu tubu. O jẹbi! Ẹlẹbi ni oun i ṣe; o ha le ri idariji gba bi? Majẹmu Laelae ti o mọ dunju-dunju sọ bayi pe, “Bi è̩ṣẹ nyin ba ri bi òdodo, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọn bi àlāri, nwọn o dabi irun-agutan” (Isaiah 1:18). Saulu jẹ Farisi, o gbe ododo ara rè̩ loju, ṣugbọn nigba ti Ọlọrun fi ọkan rẹ han an, o ri ara rè̩ bi olori ẹlẹṣẹ.

Awọn ẹlomiran jọ ara wọn loju pupọ ninu ododo ara wọn to bẹẹ ti wọn fi lero pe wọn ko fi bẹẹ buru, ṣugbọn Jesu sọ fun gbogbo awọn ti o wà ni iru ipo bayi pe, “Awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun” (Matteu 21:31). Niwọn igba ti ẹṣẹ ba wà ninu ọkan, ọkan naa dibajẹ, o si jẹ alaimọ. Ohun kan ni o le mu ẹṣẹ kuro -- È̩jẹ Jesu. “Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rè̩, idariji è̩ṣẹ wa” (Efesu 1:7).

Jesu ni Imuṣẹ Ofin

Imọlẹ lati Ọrun wá ati ohùn Jesu kan Saulu ati awọn ẹgbẹ rè̩ lara lojiji bi wọn ti n sun mọ ilu Damasku. Saulu ati awọn ti o wà pẹlu rè̩ mọ wi pe ohun iyanu kan n ṣẹlẹ. Saulu ṣubu lulẹ nigba ti ohùn nì fọ wi pe, “Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si,” o jọgọ silẹ fun Ọlọrun o si dahun wi pe, “Oluwa kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe?”

Wo oriṣiriṣi ero ti o le sọ si i lọkan laarin iṣẹju kan. O ti ṣe aṣiṣe! Aṣiṣe ni gbogbo ohun ti o ti n ṣe! Jesu ti Nasarẹti ni Kristi naa! Ọmọ Ọlọrun ni I ṣe! Saulu ri i pe a mu Ofin ti o ti n fi itara tẹle ṣẹ ninu Kristi, awọn ọmọlẹhin Ẹni ti o ti n ṣe inunibini si kikan kikan.

Adura ati Aawẹ

Aawẹ ati adura ni Saulu fi ọjọ mẹta ti o tẹle eyi gbà. Wo bi ọkan rè̩ yoo ti wà ni ironu pọ to, ati bi yoo ti di okú si ara pọ to laarin ọjọ mẹta wọnni, ati bi yoo ti layọ to nigba ti o ba ranti bi aanu Ọlọrun si i ti pọ to lati pe e ati lati yan an lati kede Orukọ Rè̩! Onigbagbọ nikan ṣoṣo ni o le mọ bi ayọ ọkunrin yi ti o ti jẹ ọta Kristi nigba kan ri ti pọ to. Nitori pe a dari pupọ ji i, o fẹ Kristi ni afẹtan nisinsinyi. O ti jọgọ silẹ patapata fun Ọlọrun ni ọna Damasku, nibi ti o gbe ni iyipada ọkan lai si tabitabi. Ijọwọ ara ẹni lọwọ patapata fun ifẹ Ọlọrun ati awọn ẹri miran ti o fidi eyi mulẹ fara han ninu rè̩ nibẹ.

Nigba ti Anania de ile ibi ti Saulu gbe n gbadura, o sọ fun Saulu wi pe: “Saulu Arakunrin, Oluwa li o ran mi, Jesu ti o fi ara han ọ li ọna ti iwọ ba wá, ki iwọ ki o le riran, ki o si kún fun Ẹmi Mimọ.” Ko si ẹni ti a kò ti i sọ di mimọ ti o le gba Agbara Ẹmi Mimọ, bẹẹ ni kò si alaiwa bi Ọlọrun ti a le sọ di mimọ. Eso isọdimimọ ti fara han ni igbesi-aye Saulu ná, nitori naa, o ti ni iyipada ọkàn ki Anania to tọ ọ wá. Ọlọrun pe e ni ohun-elo aayo. O ti gbadura si Ọlọrun, Ọlọrun si ti fi hàn fun un ninu iran wi pe Anania n bọ wa gbadura fun un ki oju rè̩ ti o fọ le là.

Ifọju Saulu jẹ oju fifọ ti ara, ni ọna Damasku ni o ti bẹrẹ nigba ti Oluwa fi ara hàn an. Bi o ba jẹ pe ifọju ti Ẹmi ni, ki yoo jẹ pe ọna Damasku ni o gbe bẹrẹ, nitori pe Saulu ti wà ninu ifọju-ọkan ṣaaju akoko yi. Nigba ti Anania gbadura fun Saulu “nkan ṣi bọ kuro li oju rè̩ bi ipẹpẹ, o si riran loju kan naa.” O ri iwosan gba! O ṣe tan lati ṣe iribọmi. Eyi kọ ni bi o ti ṣe pataki lati ṣe iribọmi lẹhin ti eniyan ba ti di atunbi. Awọn Kristiani igba nì kiyesara gidigidi lati ri i daju pe wọn kò fi ilana pataki yi falẹ.

Iyipada

Iyipada ọkàn Saulu, ẹni ti a yi orukọ rè̩ pada si Paulu nigbooṣe, jẹ ọkan pataki ninu iṣẹ iyipada nla nla ti o tii ṣẹlẹ ri ninu igbesi-aye ọmọ-eniyan. “Agbara Ọlọrun” yi i pada, o “sọ aye rè̩ dọtun.”

Igba ko le yi eniyan pada. Ipinnu ọkan ko le yi eniyan pada. S̩ugbọn Jesu le ṣe e, ani O n ṣe iyipada ọkan ati iwa awọn ẹni ti o ba tọ Ọ wa pẹlu irobinujẹ ọkàn. Kò si ohun kan ti o le ṣe iṣẹ iru iyipada ti o ṣe ninu Saulu lẹsẹ kan naa bi ko ṣe agbara Ọlọrun. Ara Etiopia kò le yi àwọ rè̩ pada, bẹẹ ni ẹkùn kò le yi ila ara rè̩ pada. Bi wọn ba le ṣe e, “bẹni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ ni ìwa buburu?” (Jeremiah 13:23). Agbara Ọlọrun nikan ni o le ṣe iṣẹ iyipada bayi ninu ọkan alaiwabi-Ọlọrun; “enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe” (Matteu 19:26).

Ọlọrun ni o da ọkàn. Oun nikan ni o si ni agbara lati yi i pada. Ibi titun ni o n mu iyipada yi wá. Jesu ba Nikodemu sọrọ nipa rè̩. O ru Nikodemu loju bi a ti ṣe le tun ẹni ti o ti di agbalagba bi. Jesu fi iṣe afẹfẹ ṣe apejuwe lati ṣe alaye ibi titun. A kò le fi oju ri afẹfẹ, ṣugbọn a mọ ọn lara a si le ri ipa rè̩ lara ewe ti n bẹ lori igi. Nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba sọ ọkàn di alaaye, a kò le ri I bi O ti n ṣe e, ṣugbọn a le mọ ninu ọkàn wa. Awọn ẹlomiran si le ri eso iyipada yi ninu igbesi-aye wa. Jesu wi pe, “Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun” (Johannu 3:3).

Lọjọ oni, awọn eniyan n fẹ lati fi iṣẹ rere dipo atunbi. S̩ugbọn ko si ohun ti a le fi dipo rè̩. Ihinrere ayebaye nikan ni ọna si Ọrun. Ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni fi agalamaṣa igbagbọ ninu Jesu tan ọ jẹ. “A kò le ṣe alaitun nyin bi.” Ẹnikẹni ti o ba di atunbi ti di ẹda titun. Saulu ti di ẹda titun ninu Kristi Jesu. Itara ọtun wọ inu ọkàn rè̩ -- kò fẹ mọ ohunkohun bi ko ṣe Jesu Kristi ti a kan mọ agbelebu.

Iṣẹ iyanu ti kò lẹgbẹ! Saulu ara Tarsu di atunbi, o yipada kuro ni Saulu oninunibini, o di Paulu Apọsteli!

Ẹri rè̩ jẹ agbayanu to bẹẹ ti a fi ni akọsilẹ rè̩ ni ibi mẹta ninu Iwe Mimọ. Paulu Apọsteli jẹ ẹni pataki ninu awọn ẹda ni orilẹ aye yi. Oore-ọfẹ igbala mu ki igbesi-aye rè̩ kun fun iṣẹ ṣiṣe, o si fi tayọtayọ fi igbesi-aye rè̩ ṣiṣẹ karakara fun Oluwa ati Olugbala rè̩, ani Jesu Kristi. Imọ ati iranwọ ẹmi ti o ni mu ki o jẹ oniwaasu pataki, olukọni ninu Ọrọ Ọlọrun, ojiṣẹ Ọlọrun ti o n lọ lati ilu de ilu, ati akewi ti kò lẹgbẹ ninu itàn Onigbagbọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ihà wo ni Saulu kọ si awọn Onigbagbọ?
  2. Eredi rè̩ ti o fi ro pe oun n ṣiṣẹ fun Ọlọrun?
  3. Kin ni mu iyipada ba igbesi-aye rè̩?
  4. S̩e alaye ibi titun.
  5. Eredi rè̩ ti iwọ fi ro pe iribọmi ṣe pataki?
  6. Kin ni ṣe ti Saulu fi sa kuro ni Damasku?
  7. Bawo ni Saulu ṣe fi ilu naa silẹ?
  8. Bi iwọ ba ro pe ẹkọ ti Saulu ni ni o jẹ ki oye ofin tubọ ye e yekeyeke, ṣe alaye eredi rè̩.