2 Awọn Ọba 6:1-7

Lesson 314 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn, ère nla ni” (1 Timoteu 6:6).
Cross References

I Ọna Hihá ati Ọna Tooro

1. Awọn ọmọ wolii beere fun irọrun diẹ si i, 2 Awọn Ọba 6:1, 2; Matteu 7:13, 14; Luku 13:23, 24

2. A fi ibeere wọn fun wọn, 2 Awọn Ọba 6:2, 3; Orin Dafidi 106:15

II Aake ti o Sọnu

1. Wọn bá wahala pade ni ọnà gbooro, 2 Awọn Ọba 6:4, 5; Oniwasu 11:9

2. “A tọrọ rè̩ ni,” 2 Awọn Ọba 6:5; 1 Kọrinti 4:7; Matteu 25:14-30

3. A ri aake naa mu pada lọna iyanu, 2 Awọn Ọba 6:6, 7

Notes
ALAYE

Ẹnu-Ọna Hihá

“Ibiti awa gbe njoko niwaju rẹ, o há jù fun wa.” Itumọ “hihá” nihin ni ibi ti kò ni àyè tó ti kò si gbòorò. Bi o tilẹ jẹ pe ohun ti awọn ọmọ wolii n tọka si nihin yii ni ile tabi ibugbe, sibẹ igbà pupọ ni awọn eniyan lọkunrin ati lobinrin lode oni n ṣe awawi kan naa nipa Ihinrere. Jesu sọ bayii pe, “Ẹ ba ẹnu-ọna hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọna na, ati onibú li oju-ọna na ti o lọ si ibi iparun; ọpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibè̩ wọle. Nitori bi hihá ti ni ẹnu-ọna na, ati toro li oju-ọna na, ti o lọ si ibi iye, diẹ li awọn ẹniti o nri i” (Matteu 7:13, 14).

Atunṣe

“Ibẹ ... há jù fun wa.” Ohun ti ọpọlọpọ awọn ti o gbọ otitọ Ihinrere n sọ ni eyi. Awọn miiran gbọ nipa Ihinrere, wọn si fé̩ jẹ anfaani ti o wa ninu rè̩, ṣugbọn nigba ti wọn bá gbọẹri awọn ti o ti ṣe atunṣe igbesi-ayé wọn, ti wọn si ti dá owó ti wọn ti ji pada tabi ti wọn ti san gbese ti wọn jẹ, awọn eniyan wọnyi a pada pẹlu ibanujẹ wi pé “ibẹ ... ti há jù fun wa.”

Panṣaga

Awọn miiran n fẹ idariji, Ọlọrun le fi hàn fun wọn pe wọn wà ni ipò panṣaga – eyi ni ẹni ti o ti gbeyawo ti o si ti kọ iyawo rè̩ silẹ ti o si tún fara mọ alabagbe miiran nigba ti iyawo rè̩ akọkọ wà laaye sibẹ. Jesu sọ fun wa gbangba pé: “Ẹnikẹni ti o ba fi aya rè̩ silẹ, ti o ba si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga si i. Bi obirin kan ba si fi ọkọ rè̩ silẹ, ti a ba si gbé e ni iyawo fun ẹlomiran, o ṣe panṣaga” (Marku 10:11, 12). Ẹkọ yii le jù fún ọpọlọpọ eniyan. Wọn a fi ọna tooro silẹ lati wáọna gbooro ti o si jé̩ onibu nibi ti wọn gbé lè fi ara mọ alabagbe keji ki wọn si tún maa jẹwọ pe Onigbagbọ ni wọn sibẹ -- bi o tilẹ-jẹ pe Johannu Baptisti di ẹkọ yii mu ti o sọ fun Hẹrọdu pe kò tọ fún un lati gba iyawo arakunrin rè̩. Gbogbo wọn ni o ni ireti lati wọỌrun rere ṣugbọn Paulu sọ bayii pe, “awọn ti nṣe nkan bawọnni ki yio jogún ijọba Ọlọrun” (Galatia 5:20, 21).

Afé̩Ayé

Ọpọlọpọ obinrin ni a mọ ti o ti pẹyinda kuro ninu Igbagbọ nitori pe wọn fẹ lati maa gẹ irun wọn bi ti ọkunrin. Bibeli kọ wa pe, “itiju ni fun obirin lati ré̩ irun tabi lati fári rè̩” ati pe “bi obirin ba ni irun gigun, ogo li o jẹ fun u: nitoriti a fi irun rè̩ fun u fun ibori” (1 Kọrinti 11:6, 15). Loju wa, o le dabi ẹni pé irun gigè̩ lati bá aṣa ti o wà lode mu kere si ọràn iye ainipẹkun, ṣugbọn ogunlọgọ eniyan ni o yá lara lati kọọna tooro silẹ dipo ki wọn fi àṣà ayé silẹ.

“Ki ẹ má si da ara nyin pọ mọ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun” (Romu 12:2). Igba pupọ ni awọn ti ayé maa n dáṣiọ awọn ti o kọ lati dara pọ mọ afẹfẹyè̩yè̩ ati àṣa rè̩. Gbogbo awọn ti o ba ẹnu ọna tooro wọle ni a paṣẹ fun pe ki wọn “máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rè̩” (1 Johannu 2:15).

Afé̩ ati Iṣura Ayé

Igbe ti ọpọlọpọẹlé̩ṣè̩ n ké ni pé “Ọna na há jù” nigba ti wọn bá gbọ nipa iduro Onigbagbọ ati bi o ṣe ni lati pa ara rè̩ mọ lailabawọn kuro ninu ifẹkufẹ ayé – iran wiwò, ijó, tábà ati ọti mimu. Ọdọmọkunrin ijoye ọlọrọ kan tọ Jesu wa lati beere ọna si iye ainipẹkun; ṣugbọn nigba ti a sọ fun un lati fi ohun ini rè̩ fún awọn talaka, ki o fi awọn ọrẹ rè̩ silẹki o si maa tẹle Kristi, o pada pẹlu ibanujẹ. Jesu fẹran rè̩. A fi iṣura Ọrun lọọdọmọkunrin yii ṣugbọn ọna naa há jù fún un.

Igbesi-Ayé Ailẹṣẹ

Awọn miiran a maa rò péọna naa há jù nigba ti a ba sọ fún wọn pe Onigbagbọ a maa gbé igbesi-ayé ailẹṣẹ. Ki ni o tun le rọrun lati yé wa bi ọrọ wọnyii pé “Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni” (1 Johannu 3:8). Ẹnu-ọna naa há, oju-ọna si ṣe tooro, ṣugbọn wọn lọ si Ọrun. Ọpọlọpọ ni o wà ni ọna gbooro ti wọn si lero pe ohun gbogbo rọrun fun wọn ati pe kòṣanfaani lati jé̩ Onigbagbọ pa-mi-nku bi ti awọn ti igba nì, ṣugbọn iparun ni ọna naa pẹkun si. Kò ha yẹ ki a há mọra giri ki ọna tooro ki o gbà wá, ju pe ki o di ikẹyin ki a wa ri i pe a ti tobi jù tó bẹẹ ti ẹnu ọna há jù fun wa, a kò si le gba ẹnu ọna naa wọle?

Titè̩ si Ibi ti Ayé Tè̩ Si

Ọpọlọpọ ijọ ti ó bẹrẹ daradara ti kú ikúẹmi nitori gbigba è̩ṣẹ laaye, rirẹ asia igbagbọ silẹ ati nipa ifẹ si ohunkohun gbogbo tó bẹẹ ti wọn fi fọwọ yẹpẹrẹ múọran ifẹ ayé. Isọji pupọ ni o dide nipasẹ awọn alakoso ti o gbe ọpa igbagbọ ga soke; ṣugbọn lẹyin ti awọn alakoso wọnyi ba ti fi ayé silẹ, awọn ijọ wọn a pada sẹyin gẹgẹ bi awọn Ọmọ Israẹli ti wọn “sin OLUWA ni gbogbo ọjọ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua” (Awọn Onidajọ 2:7), ṣugbọn ti wọn si pada sinu ibọriṣa. Jẹ ki awọn ọdọ ki o ṣọra ki igbe ti wọn n ké pé wọn n fé̩ọwọ rírọ ati ominira diẹ si i ki o máṣe fà wọn lọ si ọna gbooro!

Ibeere ti a Muṣẹ

Nigba ti awọn ọmọ wolii n ráhùn pe ibi ti wọn n gbe ti há jù ti wọn si beere pe ki wọn lọ si ibi ti o gbooro, Eliṣa dahun pe, “Ẹ mā lọ.” Onipsalmu sọ fun ni pe awọn Ọmọ Israẹli ṣe ifẹkufẹ ni aginju Ọlọrun si “fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn” (Orin Dafidi 106:15). Wọn n fé̩ẹran, Ọlọrun si fun wọn ni ẹran; ṣugbọn bawo ni i ba ti dara fun wọn tó bi wọn bá ni itẹlọrun lati maa jẹ “onjẹ awọn angẹli.”

Igbà pupọ ni awọn eniyan n fé̩ yan ọna ara wọn, Ọlọrun a si gbà bẹẹ fun wọn ṣugbọn Oun a si rán rirù si ọkàn wọn.

Kò pé̩ ti awọn ọmọ wolii lọ si ibi ti o gbooro, ti ọkan ninu wọn sọ ori aake rè̩ nù. Eyi jé̩ apẹẹrẹẹni ti o fi ọna tooró silẹ. O le maa gboke-gbodo pẹlu eku aake nikan ṣugbọn irin mimú rè̩ ti bọ sọnù, ọrọ rè̩ kò nilaari mọ. O le jù sihin jù sọhun; ṣugbọn lai si ida mimú ti Ẹmi, otubantẹ ni.

Ori Aake ti a Yá

Ọmọ wolii ké pé, “Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rè̩ ni” nigba ti aake naa yọ bọ kuro ninu eku rè̩ ti o si rì si isalẹ omi Jordani. Ọkunrin yii mọ pé a ya oun ni aake yii ni ati pé lọwọ oun ni a o gbé beere rè̩. Ọpọlọpọ eniyan ni o lero pe wọn le lo akoko, talẹnti ati ohun ini wọn bi o ti wù wọn; ṣugbọn ni tootọ, a fi eniyan ṣe iriju awọn ohun wọnni ti Ọlọrun fi fún un ni. Eyi hàn fun ni gbangba ninu Owe Mina. Kristi, Ọkunrin ọlọla naa wi fun iranṣẹ ti o fi owó Oluwa rè̩ pamọ pe: “Ẽha si ti ṣe ti iwọ ko fi owo mi si ile elé, nigbati mo ba de, emi iba si bère rè̩ ti on ti elé?” (Luku 19:23). Oluwa yoo pada ni aipẹ. Iwọ yoo ha le jihin rere nigba ti iwọ báṣiro iṣẹ iriju rẹ nipa nnkan wọnni ti Ọlọrun fi si ikawọ rẹ? Iwọ yoo ha le sọ bayii pe “Mina rẹ jère mina mẹwa si i?” tabi iwọ yoo ha sọ pẹlu ohun reréẹkun pé, “yẽ! Oluwa mo ti sọọ nù?”

Opin

Nigba ti ẹni kan bá duro niwaju Ọlọrun ni ọjọ iṣiro nì, lati jihin ohun ti o ti ṣe, ki yoo si Eliṣa lati mu “ori āke” pada mọ bẹẹ ni kì yoo si aayè nigba naa lati pe awọn anfaani wọnni ti o ti bomi lọ pada bọ. Ẹni ti o ba fi ọna hihá ati ọna tooro silẹ yoo ri i pe oun ti sọ kọkọrọ iye ainipẹkun nù nigba ti o sọ ori aake nù.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni itumọ “hihá”?
  2. S̩e awari nipa “awọn ọmọ woli” ninu Bibeli ki o si sọ ohun ti o mọ nipa wọn.
  3. Ki ni Jesu sọ nipa ọna ti o lọ si ibi iye?
  4. Ki ni idahun Jesu si ibeere yii pe “Diẹ ha li awọn ti a o gbalà”?
  5. Fi ọna gbooro ati ọna tooro wé ara wọn.
  6. Ọna wo ni idahun Eliṣa si ibeere awọn ọmọ wolii lati ṣi kuro, fi bá ibalo Ọlọrun pẹlu awọn ọmọ-eniyan mu?
  7. Ẹkọ wo ni a ri kọ nipa ti ẹmi ninu sisọ ori aake nù?
  8. Ki ni awa ni ti a le sọ pe a “yá”?