2 Awọn Ọba 6:8-23; Luku 11:9-13

Lesson 315 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ bi āti ifi è̩bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmi Mimọ rè̩ fun awọn ti o mbère lọdọ rè̩?” (Luku 11:13).
Cross References

I ImọỌtá di Asán

1. Ọlọrun fi ete ọta hàn fun Eliṣa, 2 Awọn Ọba 6:8, 9; 1 Awọn Ọba 20:22

2. A gba Israẹli là nipa fifi eti si ikilọ, 2 Awọn Ọba 6:10; Deuteronomi 6:24; 8:1.

3. Ọlọrun mọèro ọkàn gbogbo eniyan, 2 Awọn Ọba 6:11, 12; Orin Dafidi 139:1-4; 147:5; 1 Kronika 28:9; Heberu 4:12

II Itọju Ọlọrun fun Awọn ti Rè̩

1. Ogun nla yi Dotani ká, 2 Awọn Ọba 6:13-15; Orin Dafidi 27:3; 91:1-16; 118:6

2. Eliṣa ni igbagbọ, 2 Awọn Ọba 6:16; 2 Kronika 32:7

3. A ṣi ọdọmọkunrin naa loju, 2 Awọn Ọba 6:17; Numeri 22:31; Luku 24:31; 10:23, 24; Efesu 1:18

4. A bu ifọju lu awọn ọtá, 2 Awọn Ọba 6:18-20; Efesu 4:18; 2 Kọrinti 4:3, 4

6. “Bi ebi ba npa ọtá rẹ, fun u li onjẹ,” 2 Awọn Ọba 6:21-23; Romu 12:20; Owe 25:21

7. “Bère, a o si fifun nyin,” Luku 11:9-13; Johannu 14:12-14; 16:23, 24; Matteu 7:7-11

Notes
ALAYE

IṣẹỌtẹlẹ-múyé̩

Idagiri ojijì tabi lati daya fo ni, jé̩ ohun kan ti o ṣe pataki pupọ lati mó lò ninu ogun jijà. Ki ọmọ-eniyan baa le bori eyi, oriṣiriṣi ọtẹlẹ-múyé̩ ni wọn n rán jade lati wadii aṣiiri ọta lori ilẹ, òkun, ati ofurufu, ki a ma baa si ba awọn naa labo. Lati ọdun diẹ si akoko ti a wà yii ni a ti n lo ẹrọ amóhùn ati ẹrọ túnà-aṣiiri ti a n pe ni rádà lati fi ibi ti ọta wa han ni. Igba pupọ ni ọkọ oju omi ti bọ lọwọ agbako, ti a si ti ṣofofo fún awọn ọmọ-ogun nipasẹ awọn ẹrọ túnà-aṣiiri wọnyii. Ki a tóṣe awari awọn ohun-elo ìgbàlódé wọnyii, ni a ti n gba Israẹli là nipa Ọgbọn Arinu-rode ti o tayọọgbọn awọn ẹrọ túnà-aṣiiri ti a le ti ọwọọmọ-eniyan ṣe. Ọlọrun ti n boju wolẹ lati Ọrun wá ti o si n ka iwe aṣiiri ohun ti o wà ninu ọkàn ọmọ-eniyan, fi aṣiiri ohun ti o wà lọkan ọba Siria ninu iyẹwu rẹ hàn fun Woli Rè̩, ki a tilẹ tó gbé awọn eto naa kalẹ fun awọn olori ogun rè̩.

A gba Israẹli là nigba pupọ nipa Ọgbọn Arinu-rode yii, eyi ti o maa n mu ki wọn wà ni imurasilẹ. Orisun itura ni fun awọn ọmọỌlọrun lọjọ oni lati mọ pé ogun Eṣu kò le bá awọn Onigbagbọ lábo lai si imọtẹlẹỌlọrun ati pe Ọlọrun si ti pese awọn ohun ija ti o tó fun wọn lati dojukọ ogun ọta. “Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti ki yio jẹki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a” (1 Kọrinti 10:13).

Má Bè̩ru

Nigba ti ọba Siria gbọ pe Eliṣa ni ẹni ti Ọlọrun n fi iṣẹ Rè̩ le lọwọ, lẹsẹ kan naa o rán awọn oniṣẹ lati mú eniyan Ọlọrun yii wá. Ki ni ṣe ti eniyan ẹlẹran ara fi rò pé oun le da eto ati iṣẹ Olodumare rú? Nigba pupọ ni eniyan n rò pé oun le yọ bọ kuro lọwọ ofin ayeraye ti Ọlọrun ti ṣe. Ọba Siria lero pe ohun ti o rọrun ni lati múẹni kan ṣoṣo yii pẹlu awọn ọmọ-ogun rẹ ti o yi Dotani ká. Eyi i ba ri bẹẹ bi o ba jẹ pe eniyan nikan ni ẹgbẹ ogun naa dojukọ.

Awọn ẹlomiran le rò wi pe ẹsẹỌrọỌlọrun ti o sọ fun ni pe, “Angẹli Oluwa yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn” jé̩ọrọ asọdun ti awọn akewi maa n sọ, ṣugbọn Eliṣa gba ọrọ yii ni ojulowo gan an. Kò daju pe igba gbogbo ni Eliṣa n ri ogun ọrun lojukoju ṣugbọn ni akoko iṣoro, o mọ pe wọn wà ni tosi. Eliṣa jé̩ẹni ti o sunmọỌlọrun timọtimọ nigba gbogbo to bẹẹ ti o fi mọ ohun ti o tọ lati ṣe. Ọlọrun ni o n tọọ lati Ọrun wá. O n feti silẹ si ohùn Ẹlẹda rè̩. Nigba ti iranṣẹ rè̩ ri ogun Siria ti o yi ilu Samaria ká, pẹlu ijaya ni o kigbe wi pe, “Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?” Eliṣa kò jaya bẹẹ ni ẹrù kò ba a. “Má bè̩ru,” ni ọrọ ikiya ti o jade lati ẹnu ọkunrin ti o mọỌlọrun rẹ. Pẹlu adura gbolohùn kan, o bẹ Oluwa ki o ṣi ọmọdekunrin naa loju. Ki i ṣe pe ọdọmọkunrin yii kò fi oju ti ode ara riran. O sa ri bi awọn ọmọ-ogun Siria ti n sunmọ tosi lati gba ilu naa. Eliṣa n fẹ ki iranṣẹ rè̩ ri diẹ ninu ohun ti oun ti ri. “Kẹké̩ Israẹli, ati awọn ẹlẹṣin rè̩” (2 Awọn Ọba 2:12).

Oju Ode Ara ati Oju Ẹmi

O rọrun lati fi wiwo iran awọn ohun ti o yi wa ká kun oju wa to bẹẹ ti oju ẹmi wa kì yoo fi le ri ohunkohun. Iṣẹọta ni lati mú ki aniyan aye yii kún eniyan lọkàn to bẹẹ ti ilepa aye yoo fi gba gbogbo agbara ati akoko rè̩. Ilepa awọn ohun aye yii le kún eniyan lọkàn to bẹẹ ti oju rè̩ yoo fi fọ si ohun ti i ṣe ti Ọrun. Nipa ti ẹmi, irúẹni bẹẹ dabi ẹni ti o bu ina ere sisa si ọkọ ninu ikuuku nibi ti kò gbé riran, ti kò si bikita. “Nitori ero ti ara ikú ni” (Romu 8:6). “Ọtá agbelebu Kristi ni nwọn ... awọn ẹniti ntọju ohun aiye” (Filippi 3:18, 19). Ki Oluwa ma ṣalai ṣi ojú olukuluku eniyan lati riran ri awọn ohun ti o tayọ ti ayé wa yii.

Oju Eliṣa ṣi nigba ti o fi ohun gbogbo silẹ lati maa tọ Elijah lẹyin. O ri kẹkẹ ina nigba ti o pinnu lati bá Elijah lọ titi dopin. Oju wa yoo ṣi nigba ti a bá bẹrẹ si ṣafẹri awọn nnkan ti ó wà loke; bi a ba si tẹra mọ eyi tọkantọkan titi de opin ẹmi wa, ogo Ọrun yoo ṣi silẹ loju wa nigbooṣe to bẹẹ ti gbogbo afé̩ aye yii yoo dabi ohun yẹpẹrẹ ti kò nilaari loju wa, yoo si jé̩ iyanu fun wa pe kò tilẹ si ohunkohun ninu ayé. Ki ni awọn nnkan wọnni ti awọn eniyan tilẹ n fi ṣe paṣipaarọẹmi wọn? Wo bi ọjọ eniyan ti kuru tó lori ilẹ-ayé! Ọlọrun sọ fun ẹni kan ti o ti fi gbogbo ọjọ ayé rẹṣe laalaa fun ohun ini aye yii pe, “Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pese silẹ?” (Luku 12:20).

Adura Kan

Eyi i ba le jé̩ adura gbogbo awọn Onigbagbọ: “Oluwa, ṣi awọn ẹlẹṣẹ loju ki wọn le ri aṣiṣe wọn, ki wọn si le ri ẹwà ati anfaani Ihinrere. Jọwọ jẹ ki wọn le mọ iyatọ ti o wa ninu ohun igba isisiyi ati ohun ayeraye; si jẹ ki oju awọn ti o mọỌlọrun ki o le mọlẹ kedere si ipa ọna nì “ti o ntan siwaju ati siwaju titi di ọsangangan” (Owe 4:18). Oluwa ṣi awọn ọdọmọkunrin loju, awọn ti n fi akoko wọn ṣofo lori awọn nnkan wọnni ti kò nilaari lai bikita fun iwa-bi-Ọlọrun ti o “li ère fun ohun gbogbo” (1 Timoteu 4:8).

Abo ti o Daju

“OLUWA si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran” – iran yii ti logo to! Gbogbo oke naa kun fun ẹṣin ati kẹkẹ-iná yi Eliṣa ká. Agbara wo ni o wa fun ọta lati le bi odi yi wo? “Kò si ohun-ija ti a ṣe si ọ ti yio lèṣe nkan; ... Eyi ni ogún awọn iranṣẹ OLUWA” (Isaiah 54:17). Satani sọ nipa Jobu pe, “Iwọ kò ha ti sọgbà yi i ká, ati yi ile rè̩ ati yi ohun ti o ni ká ni iha gbogbo?” (Jobu 1:10). Ọlọrun ti pese ihamọra fun olukuluku awọn ọmọ Rè̩ ti Eṣu tabi ogun ọrun apaadi kò le bori.

Nigba ti awọn ọta déọdọ Eliṣa, o bẹbẹ pe ki Oluwa ki o bu ifọju lù wọn. Ọlọrun gbọ ti rè̩, eniyan Ọlọrun yi si dari awọn ọmọ-ogun ti a ti bu ifọju lù yii lọ si aarin ilu Samaria. Wo bi ipaya ati idaamu wọn yoo ti pọ tó nigba ti oju wọn ṣi ti wọn si bá ara wọn ni igbekun ni aarin Samaria. Nigba ti ojú iranṣẹ Eliṣa ṣi, o ri iṣẹgun. Nigba ti ojú awọn ara Siria ṣi, wọn ri iṣubu.

Igbagbọ Kekere

Wo bi igbagbọ Eliṣa ti duro ṣinṣin tó nigba ti o n báỌlọrun sọrọ! O duro titi ogun naa fi yi i ká, o si beere lọwọỌlọrun ki o bu ifọju lù wọn, Ọlọrun si ṣe e. Jesu n kọ wa lati ni iru igbagbọ ti o duro ṣinṣin bayii nigba ti o wi pe, “Ẹ bère, a o si fifun nyin.” Bi O ti mọ aigbagbọ wa, O ṣe apẹẹrẹ kekere yii fun wa wi pe: “Ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rè̩ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u?” Ifọkànbalẹ wo ni ẹnikẹni ha le ni ju eyi lọ wi pe bi oun bá beere pẹlu igbagbọ, Ọlọrun yoo dahun ibeere naa? “Melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ?”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Fi ikilọ ti Eliṣa fun Ọba Israẹli wé awọn ẹrọ ti o n fi aṣiiri awọn ọta hàn lode oni.
  2. Igba meloo ni a gba Israẹli la nipa titẹle ikilọ yii?
  3. Bawo ni ọba Siria ṣe rò pé a n da ipinnu oun rú?
  4. Ki ni Eliṣa sọ nigba ti o gbọ pe ọta yi oun ká?
  5. Ki ni ọdọmọkunrin nì ri nigba ti a la a loju?
  6. Bawo ni Eliṣa ṣe bá awọn ọmọ-ogun Siria lò?
  7. Fi lilà ti a la iranṣẹ Eliṣa loju ati lilà ti a la awọn ọmọ-ogun Siria loju wé ara wọn.
  8. ẸsẹỌrọỌlọrun wo ni o fi iwa ti Eliṣa hu nipa fifun awọn ọmọ-ogun Siria ni ounjẹ mulẹ?
  9. Jesu wi pe, “Ẹ bère, ẹ o si ri gbà.” Fi ẹsẹ Bibeli gbe e lẹsẹ eredi rè̩ ti a fi n bere nigba miiran ti a ki i ri gbà.
  10. Ki ni Jesu fi bibeere wa wé?