2 Awọn Ọba 6:24-33; 7:1-20; 8:1-15

Lesson 316 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitori iwọ, OLUWA, ni iṣe ābo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ. Buburu kan kì yio ṣubu luọ, bḝli arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ” (Orin Dafidi 91:9, 10).
Cross References

I Idaamu ni Samaria

1. Bẹnhadadi, ọba Siria, dó ti Samaria o si mu idaamu bá awọn ara ilu naa, 2 Awọn Ọba 6:24, 25

2. Obinrin kan sọ ibanujẹ rè̩ fun ọba, ọba si di ẹbi ru Eliṣa pe oun ni o fa gbogbo buburu naa wá bá wọn, o si ṣeleri lati pa a, 2 Awọn Ọba 6:26-31; Lefifitiku 26:25-29; Deuteronomi 28:53

3. Oluwa fi ète buburu naa hàn fún Eliṣa, ẹni ti o sọ asọtẹlẹ imukuro ìyàn naa, 2 Awọn Ọba 6:32, 33; 7:1, 2

II Ipinnu ati Iṣe awọn Adẹtẹ Mẹrin

1. Awọn adẹtẹ mẹrin ti o ti n kú lọ fun ebi lọ si ibudo awọn Siria ti o ti di ahoro, 2 Awọn Ọba 7:3-5

2. Oluwa mu ki awọn ara Siria gbọ ariwo kẹkẹ ogun nla. Wọn si salọ, wọn fi ibudo wọn silẹ ati ẹṣin wọn, 2 Awọn Ọba 7:6-8; 19:7; Owe 28:1

3. Awọn adẹtẹ naa ko ikogun, wọn si wi fun ara wọn pe: “Oni yi, ọjọ Ihinrere ni, ... ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba, 2 Awọn Ọba 7:9-11

4. Asọtẹlẹ Eliṣa ṣẹ, 2 Awọn Ọba 7:12-20

III Ọrọ Laaarin Ọba ati Gehasi

1. A sọ bi obinrin S̩unemu ti ṣe atipo fun ọdun meje, 2 Awọn Ọba 8:1, 2

2. Bi ọba ti n ba Gehasi sọrọ lọwọ nipa Eliṣa, ara S̩unemu naa pada bọ, o si bẹọba nitori ilẹ rè̩, 2 Awọn Ọba 8:1-6

IV Ikú Bẹnhadadi

1. Bẹnhadadi ṣe aisan o si rán Hasaeli si Eliṣa, 2 Awọn Ọba 8:7-9

2. Eliṣa sọ asọtẹlẹ ikú Bẹnhadadi, Hasaeli si pa ọba, 2 Awọn Ọba 8:10-15

Notes
ALAYE

Ìyàn

Igba pupọ ni Ọlọrun n rán ìyàn sori ilẹ ayé nitori è̩ṣẹ ati aigbọràn. Iyàn ti o mú ni Samaria ni akoko yii jẹère è̩ṣẹ Ahabu. Ahabu ti fé̩ Jesebẹli, obinrin abọriṣa ara Sidoni. A kàá ninu Iwe Mimọ pé “Kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rè̩ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rè̩ nti” (1 Awọn Ọba 21:25). Nikẹyin ọjọ Ahabu, o rẹ ara rè̩ silẹ niwaju Oluwa, nitori eyi Oluwa kò mu ibi ti O ti pinnu lori Ahabu wá ni ọjọ rè̩, ṣugbọn O mú ibi naa wá ni ọjọọmọ rè̩.

Ẹkọ wa bẹrẹ pẹlu Jehoramu, ọmọ Ahabu ti o n jọba ni Samaria ati bi Bẹnhadadi ọba Siria ti gbogun ti ilu naa.

Ipọnju ninu Ilu

Ìyàn ti o wa laaarin ilu rekọja àlà. Awọn eniyan wa ninu ipọnju nla. Awọn obinrin n pa ọmọ ara wọn jẹ, ègún ti Mose ti sọ wi pe yoo wa sori wọn bi wọn bá kọ Ofin Oluwa silẹ (Deuteronomi 28:51-53). Awọn miiran lero pe wọn le yan ọna ara wọn lai bikita fún aṣẹỌlọrun, sibẹsibẹ, ki idajọỌlọrun máṣẹ lé wọn lori. S̩ugbọn a n ri nigba gbogbo pe idajọỌlọrun maa n tẹle è̩ṣẹ. ỌrọỌlọrun sọ wi pe, “Ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7). Ere aigbọran buru jai. Awọn ara Samaria ri i kòrókòró.

Ọba Israẹli n fẹ di ẹbi wahala nla ti o wa laaarin ilu lé Eliṣa lori. Awọn eniyan ayé a maa fé̩ di ẹbi è̩ṣẹ ati aṣiṣe ayé wọn léẹlomiran lori. Wọn a maa fẹ lati bo ara wọn ni aṣiiri nipa didi ẹbi ru ẹlomiran. Ọlọrun mọọkàn. O le boju wolẹ ki O si wi pe “Iwọ li ọkunrin na.”

Ọba pinnu lati pa Eliṣa. Oluwa fi aṣiiri yii han Eliṣa, Eliṣa si bọ kuro ninu ìmọ buburu yii: “Oluwa mọ bi ā ti iyọ awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo” (2 Peteru 2:9). O n ṣe aniyan awọn ti Rè̩. Kò si ohun ti o le wá sọdọ awọn eniyan Ọlọrun lai si iyọnda Ọlọrun. Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun le rọ mọ ileri yii pe, “Kò si ohun-ija ti a ṣe si ọ ti yio lèṣe nkan.”

Eliṣa

Eliṣa n bá iṣẹ Elijah lọ, o dá ile-ẹkọ silẹ fun awọn ọmọ woli ni Samaria, Dotani, Bẹtẹli, Jẹriko, S̩unemu ati Kamẹli. O ṣe e ṣe ki o jé̩ pe ni ilu Samaria ni Eliṣa gbé n kọ ni lẹkọọ nigba ti ogun dó ti ilu yii. Iṣẹ iyanu pupọ ni Oluwa ti ṣe lati ọwọ Eliṣa, lai pẹ jọjọ iṣẹ iyanu àgbàyanu miiran yoo ṣe.

Oluwa kò gbagbe awọn ti Rè̩, kì yoo si fi wọn silẹ lae, nigba ìyàn pẹlu. Lai si aniani awọn eniyan wà ni ile-ẹkọ woli yii ti o ni ifẹ ododo. Awọn pẹlu Eliṣa ni “iyọ” Samaria. Ileri miiran ti o tún wà fun awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni eyi pe, “Oju ki yio ti wọn ni igba ibi: ati li ọjọ iyan a o té̩ wọn lọrun” (Orin Dafidi 37:19).

Aigbagbọ

Nigba ti Eliṣa ranṣẹ si ọba pe, “Ni iwoyi ọla li a o ta oṣùwọn iyè̩fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu-bode Samaria,” ijoye kan ni ọwọẹni ti ọba fi ara ti ké̩gàn Ọrọ naa. O beere pe, “Kiyesi i, bi Oluwa tilẹṣe ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bḝ?” Aigbagbọ kò jẹ ki o ṣe alabapin igbadun ọpọ ounjẹ pẹlu gbogbo awọn ara ilu. Ọkàn aigbagbọ a maa sé ilẹkun ibukun Ọlọrun. A yan ijoye yii lati duro si ẹnu-bode ilu Samaria, ṣugbọn ninu igboke-gbodo awọn eniyan ti o n lọ ti o n bọ lati ibudo awọn ara Siria lati ko ounjẹ, wọn ti i ṣubu, awọn eniyan si tẹẹ mọlẹ, o si kú. Awọn miiran le wi pe o ṣeeṣi ni, ṣugbọn imuṣẹỌrọỌlọrun ni. Oluwa ni ọna ti Rè̩ ti o fi n múỌrọ Rè̩ṣẹ. Igbagbọ ni o mu ki ileri Ọlọrun ṣẹ. Aigbagbọ ni o n sé ilẹkun Ijọba Ọlọrun mọ eniyan.

Ihin Ayọ

Adẹtẹ mẹrin naa jé̩ awọn ẹni ti ebi ti pa. Wọn kò ni ireti lati ri ounjẹ jẹ ni ilu. Bi wọn bá duro lẹyin odi ilu, wọn yoo kú. Bi wọn ba lọ si ibudo awọn ara Siria, wọn le ṣaanu fun wọn ki wọn si dá wọn si. Wọn ni lati pinnu, boya wọn rò pé wọn yoo gbekuta.

Ireti kò si fun ẹlẹṣẹ niwọn-igba ti o bá taku sinu è̩ṣẹ. Oun yoo ṣegbe. S̩ugbọn nigba ti ẹlẹṣẹ ba pinnu lati tọ Jesu wa ireti wa. Ninu owe Jesu, a ri i pe nigba ti ebi n pa ọmọ oninakuna kú lọ, ori rè̩ walé, o si mọ pe ounjẹ ajẹyo ati ajẹti wa ni ile baba oun. O pinnu, o si dide lati lọ si ile, o ṣe ohun ti o ti pinnu ninu ọkan rè̩. Ohun kan naa ni awọn adẹtẹ mẹrin wọnyi ṣe.

A kò mọ boya Oluwa ni o mu ki ìróẹsẹ wọn dabi iro ogun nla bi wọn ti n rin lọ ni opopo ọna, ṣugbọn awa mọ pé awọn ọmọ-ogun Siria gbọ iro ogun nla lẹyin wọn. Ẹru bà wọn gidigidi, wọn si salọ, wọn fi agọ wọn ati ounjẹ wọn silẹ.

Nigba ti awọn adẹtẹ naa dé ibudo, wọn ri ọpọ ounjẹ ati aṣọ. Fun iwọn igba diẹ wọn joko ti ounjẹ, lẹyin eyi wọn ri i pe ọpọ ounjẹ ti o le tó fun awọn ara Samaria lati jẹ wà ni ibudo ti awọn ara Siria fi silẹ. Wọn wi fun ara wọn pe, “Awa kòṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba.”

Sisọ Itan Naa

Bíbọ ti awọn adẹtẹ wọnyi bọ sinu ọpọ ounjẹ lojiji lẹyin ti ebi ti fẹrẹ yọ oju wọn, to lati sọọjọ yii di ọjọ Ihinrere fun wọn. Ọjọ ayọ ni pẹlu fun ẹlẹṣẹ nigba ti o ba bọ kuro ninu igbekun è̩ṣẹ ti o si ni ominira ologo ti Ihinrere Jesu Kristi n fi fun ni. Nipa ti ẹmi, oun ti inu aini bọ sinu ọrọ, o ti inu okunkun bọ sinu imọlẹ ati lati inu igbekun bọ sinu ominira. Itumọ“Ihinrere” ni “Ihin ayọ.”

Lẹsẹkẹsẹ awọn adẹtẹ yii fé̩ royin naa fun awọn ara ile ọba. Ihin yii ko ṣe e pamọra; wọn fé̩ ki awọn ẹlomiran gbọ. Nigba ti a bá ri igbala, a ni ohun iyanu kan ti ọkan wa fé̩ lati jé̩ ki o di mimọ fun awọn ẹlomiran, nitori ibukun ọpọlọpọ ni igbala yii jé̩.

“Sọ itan na! Sọ itan na!

Sọ itan igbala, sọ lasọ-tun-sọ,

Tobẹ t’ẹnikẹni ko ni le sọ pe,

Nko r’ẹnikan lati sọ fun mi!”

Fifi Idi Otitọ Mulẹ

Asọtẹlẹ Eliṣa ati ọna iyanu ti Oluwa gbà lati pese ounjẹ tó lati mu ki ọkan ọba rọ. A ri i pe ọba n ba Gehasi sọrọ o si n fẹ mọ gbogbo ohun ribiribi ti Eliṣa ti ṣe. Awọn miiran gbà pé Gehasi jé̩ọkan ninu awọn adẹtẹ mẹrin ti o lọ si agọ awọn ọmọ-ogun Siria. Dajudaju Gehasi kò ni ikoro ọkàn si Eliṣa nitori egun ti o fi gún un nigba ti o lọ fi oju kokoro gba ọrẹ lọwọ Naamani. A ri i bi o ti fi tayọtayọ sọ nipa awọn iṣẹ-iyanu ti Eliṣa ti ṣe. Bi o ti n sọ nipa ọdọmọkunrin ti a ji dide kuro ninu okú lọwọ, lẹsẹkanna Oluwa mú ki obinrin ara S̩unemu nì wa sọdọọba. O wá sọdọọba lati bẹbẹ pé ki o bá oun gba ile oun ti o ti bọ lọwọ oun ni akoko iyàn ọdun meje pada. Nipa ọrọ Eliṣa ni obinrin naa fi lọ si ilẹ awọn Filistini lati ṣe atipo nibẹ ki o ba le bọ lọwọ iyan. Nigba ti Gehasi ri i, o kigbe lohun rara wi pe, “Oluwa mi, ọba, eyi li obirin na, eyi si li ọmọ rè̩ ti Eliṣa sọ di āyè.”

Nigba ti Oluwa bá fé̩ fi idi otitọ mulẹ, O ni ọna ti Rè̩ ti O n gbà lati ṣee. O le jẹ pe Oluwa fẹ ki ọkan ọba rọ ki o baa le dá ilẹ obinrin yii pada fun un ni. Igba pupọ ni è̩ri awọn ọdaran ti Ọlọrun ti yi pada ti rọ awọn oniṣẹọba lọkan to bẹẹ ti wọn fi dáọdaran naa silẹ lọfẹ.

Ikú Bẹnhadadi

Ni ipari ẹkọ wa yii, a ri i bi Eliṣa ti n lọ si Damasku ti i ṣe olu-ilu Siria. Bẹnhadadi ṣaisan, o si rán Hasaeli, boya ẹni ti o ga ju ninu ijoye rè̩ si Eliṣa lati beere bọya oun yoo sàn ninu aisan naa tabi bẹẹkọ. Bi Hasaeli ti duro niwaju Eliṣa, Oluwa fihàn fun Eliṣa pe Hasaeli yoo jọba lori Siria. Eliṣa tun ri awọn iwa ibajẹ ti ọkunrin yii yoo ṣe si awọn Ọmọ Israẹli. Eliṣa sọkun. Hasaeli bẹrẹ iwa buburu rè̩ nigba ti o pada de ọdọọba ti o di aṣọ ti o nipọn mọọba loju, o pa a, o si gba ijọba Siria lọwọ rè̩. Eyi ni igbẹyin Bẹnhadadi, ẹni ti o gbogun ti awọn ọmọ Israẹli nigba pupọ. Ọlọrun wipe, “Ifibu si ni ẹniti o fi ọ bú” (Numeri 24:9).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni o fa ìyàn ni Samaria?
  2. Ta ni ọba di ẹbi ìyàn naa le lori?
  3. Sọ bi Eliṣa ṣe bọ kuro ninu ibinu ọba?
  4. Ki ni o lé ogun awọn Siria sá? Ta ni o di mimọ fun pe wọn ti sá?
  5. Sọ nipa iwa-aimọ-tara-ẹni-nikan ti awọn adẹtẹ hù.
  6. Nigba ti ẹlẹṣẹ kan ba ri igbala, ki ni ṣe ti ọkàn rè̩ fi n fẹ lati tan ihin naa kalẹ?
  7. Ki ni ṣe ti Eliṣa fi sọkun?
  8. Sọ bi Bẹnhadadi ṣe kú.